Friday, 12 June 2015

ÌJÀA DÁNFÓ



Ẹ̀rín pa mí ńjọ́ à ń wí
Ọ̀̀rọ̀ ò wọ̀
Ìdò ni mò ń lọ látÌdúmọ̀tà
Tí mo dá dáńfó dúró
Àwa mẹ́ta la wọkọ̀ yìí             5
Mo gbàgbé n yán an fún ẹ
Èmi ṣení 
Omidan ọlọ́rùn-un jọ̀lọ̀ ṣèjì
Abilékọ olójú ẹgẹ́ ṣẹ̀ta
N là ń lọ, n la ń lọ, n là ń lọ                       10
La débìkan, lèró p̣é pìtìmọ̀
Èrò ọ̀ún pọ̀ bí ewé orúmọ̀, a ò rírú ẹ̀ rí
Tí gbogbo wọn figbe Àkọkà bọnu
Ṣówó gọbọi ni wọ́n ń wọkọ̀ Àkọkà lọ́jọ́ òun àná
Èyí náà ló kúkú wọlọ́kọ̀ lójú lọ́jọ́ ọ̀ún o jàre                            15
Tó forin ajé sẹ́nu kó lè jèrè
Pẹ́ni ò bá kọrin ajé è é jèrè
“Ajé dákun jé ń jèrè”
Àgbàdo ìgò wáá bọ́dẹ níjù, ó doyin mọmọ
N làwé bá ní á sọ̀, kí  á gbowóo wa        20
Kí a wọ́kọ̀ míìn wọ̀
Àwa mẹ́ta la wà lọ́kọ̀, èrò sì ré ńlẹ̀ yìí
Gbogbo yín lẹ kúkú mọ̀ péèyàn tútù ni mí, n ò fẹ́jà
Mo taari àbìlíì síwájú
Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin méjì yìí fárígá, wọ́n faraya                      25
Àwọn là bá máa pè lóbìnrin-kọ̀yà
Àtèyí ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ tó jábilékọ
Àtọmọge abìdí jìwo
Gbogbo wọn ni wọ́n ta pańpa
Tí wọ́n ń ra fańda                    30
N ò mọ̀ pé torí ìjà ni wọ́n ṣe dárùgbọ̀n sí
Tí wọ́n sọraa wọn dỌya kalẹ̀
Ìjà ọ̀ún pọ̀ ńjọ́ ọ̀ún, ọ̀rẹ́ẹ wa
Leruku ń tu, táriwo ń ta gèè.
Gbogbo aṣọ ara baba ni wọ́n ya kanlẹ̀ kanlẹ̀                            35
Ìgbàa wọ́n tiwọ́ bọ pátá tó kù sídíi baba
Tí wọ́n fẹ́ẹ́ yọjú ẹlẹ́kẹrú sóde
N ni mo pẹ̀yìndà
Tí mo gbọ̀nà ilée mi lọ
N ò ní í réèmọ̀!                         40

No comments:

Post a Comment