Thursday, 11 June 2015

Ipò Obìnrin nínú Iwé Ìtàn Àròsọ Yorùbá




Ní àwùjọ wa ní òde òní, a kì í fẹ́ fi obìnrin sí àyè kan tí ó dáńgájíá, bẹ́ẹ̀ ni a máa ń fẹ́ kí ìyàtọ̀ wà láàrin bí a ṣe ń hùwà sí obìnrin ati ọkùnrin. Kì í ṣe pé kí ìyàtọ̀ yìí wà nìkan, a máa ń fẹ́ kí ó hàn sí gbogbo aráyé rí pẹ̀lú. Nígbà tí ọkùnrin máa ń jẹ́ ẹni àpọ́nlé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ojú ẹni “hẹ̀ẹ̀” ni a máa ń sábaá fi wo obìnrin. Paríparí gbogbo rẹ̀ ni pé àyè máa ń ṣí sílẹ̀ fún ọkùnrin láti gbé igbá orókè ju obìnrin lọ nitorí òmìnira àti àyè tí ó wà fún ọkùnrin tí ó pọ̀ ju ti obìnrin lọ.
Tí irú èyí bá ń ṣẹlẹ̀ sí obìnrin ní àwùjọ wa, a lè wá bèèrè pé báwo ni ipò obìnrin ṣe rí nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá? Ó ṣe ni láàánú púpọ̀ láti rí i pé ó fẹ́rẹ̀ máa sí nǹkan tuntun kan dàbíalárà tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé wa mẹ́nu bà nípa obìnrin ju àwọn ohun tí a máa ń gbọ́ nípa wọn láwùjọ lọ. Àwùjọ wa tí ó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọkọ lolórí aya ni ó jẹ wá lógún tí kì í ṣe ọkọ gbégbá-n-gbágbọ̀n. Àwùjọ tí ó jẹ́ pé o fẹ́rẹ̀ sàn pé kí ènìyàn máa bímọ rárá ju pé kí ó bí obìnrin lọ. Wọn kò ka obìnrin sí ẹnì kan tí ó gíríkì ní àwùjọ wa. Tí ọkùnrin bá jẹ́ iyán tí a mọ̀ sí oúnjẹ àti ọkà tí a mọ̀ sí oògùn, obìnrin kò ju ohun tí àwọn ènìyàn wa gbàgbọ́ wí pé àìrí rárá tí a fi ń jẹ ẹ̀kọ àti kí ẹnu máà dilẹ̀ tí a fi ń jẹ gúgúrú lọ. Àwọn ni àìrí ọ̀run lọ tí ènìyàn fi ń lọ sí ọ̀run àpáàdì.
Kì í kúkú ṣe pé àwọn tí ń kọ ìtàn àròsọ wa kò sọ̀rọ̀ nípa obìnrin rárá àti rárá. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa wọn mọ̀nà. Ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ máà sí ìtàn àròsọ wa tí a lè sí tí kò mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ obìnrin ní ọ̀nà kan tàbí òmiràn. Ṣùgbọ́n ohun tí a ṣe àkíyèsí ni pé, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ohun tí àwọn aṣáájú wa ti fi lélẹ̀ wí pé kí á gbàgbọ́ nípa obìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹkọ̀wé tí a ń sọ̀rọ̀ nípa wọn máa ń sọ.́ mẹ́nu bà nípa obìnrin ni owú jíjẹ, ìkóbìnrinjọ, afẹfẹyẹ̀yẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọn a ní ọ̀rọ̀ kí á ṣe afẹ́ ayé, kí á gbádùn ara ẹni, kí á tọ́ ojú, kí a tọ́ imú, ọwọ́ obìnrin ló wà. Fágúnwà ní
Igbati Adiitu-Olodumare ti di olowo tan, awọn obinrin ilu Ifẹhinti ko jẹki o simi. Omiran a ko golu pa ori, a ko o pa ẹsẹ, a ko o bọ ọrun, a fi tojutimu kun atike, a kun sapa, a kun sẹsẹ (Àdìítú Olódùmarè, Pg. 45).
Bákan náà ni Yemitan tún ṣe mú ẹnu ba àṣehàn àwọn obìnrin nígbà tí wọ́n fẹ́ fi Bámidélé joyè, ó ní
Awọn obìnrin-ile ti di irun wọn oriṣiriṣi. Nwọn ro aṣọ òkè mọ igbaya... Nwọn ko ilẹkẹ lágídígba sọ́rùn (Gbọ́baniyi, Pg. 94)

Lójú àwọn òǹkọ̀wé wa, kì í ṣe dandan ni pé ọ̀wọ́ ìgbà tí wọ́n bá ní nǹkan-án ṣe ni ọ̀rọ̀ afẹ́ ayé yìí máa ń jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n dá wà, wọ́n lè máa dá tojọ́ nípa bí ó ṣe yẹ kí nǹkan dára tó ní ara wọn. Àbẹ̀kẹ́ ní
Tabi oloriburuku ni iya onidiri yi kẹ? Ẹ wo ori ti mo ni ki o di fun mi ni kolẹsẹ... papin ni mo ma sọ pé ki o di fun mi o (Ọmọ Òkú Ọ̀run, Pg. 8)
Irú èrò yìí kan náà ni ó wà ní inú Àṣàbí nígbà tí ó wo ara rẹ̀ títí tí ó sọ pé
Emi awẹlẹewa obinrin, ọpẹlẹngẹ ṣubu lawo, awo o fọ (Aiye Daiye Oyinbo, Pg. 7)

Nígbà tí Àdììtú Olódùmarè sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ Adémẹ̀tọ́ pé kí ó máa retí òun ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ní àárọ̀ ọjọ́ yìí, Iyùnadé tí kì í ti í tètè jí tẹ́lẹ̀
ti ji, o ti wẹ... ọtọ ni o fi nkan ra oju ọtọ ni nkan ti o tọ si ipenpeju, ekan ọwọ, ekan ẹsẹ, o tun ṣe o tọ si ete, o tọ si ahọn (Àdììtú Olódùmarè, Pg. 65)
Ara ṣe-á-rí-mi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé wa máa ń ṣe àkíyèsí nípa obìnrin náà nì yẹn.
  ojú ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọwé wa, díẹ̀ ni a lè fi inú tán nínú àwọn obìnrin. Àwọn ló máa ń fi ẹ̀jẹ̀ sínú tu itọ́ funfun jáde. Nípa wọn ni Fágùnwà ṣe sọ pé
ṣugbọn inu obinrin jinlẹ lọpọlọpọ, ibu omi okun ni, isalẹ rẹ ṣoro lati mọ, nitori nkan ti o ba ro pe wọn nro kọ ni nwọn nro, eyiti o ba ro pe nwọn o ṣe kọ ni nwọn ma ṣe. Iba diẹ ninu wọn si ni enia le gbẹkẹle nitori ẹniti o ba ro pe nwọn ko fẹ ni nwọn nfẹ, eyiti o ba ro pe nwọn ma ṣe ni nwọn ko ni ṣe (Àdììtú Olódùmarè, Pg. 65)
Ọ̀pọ̀ ohun míràn ni a tún ṣe àkíyèsí tí ọ̀pọ̀ ònkọ̀wa mẹ́nu bà nípa àwọn obìnrin wa. Àwọn ló máa ń di ẹrù tí ó pọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ lọ sí ibì kan. Ẹ̀rù kì í pẹ́ bà wọ́n. Ní ìlú obìnrin pàápàá tí Fágùnwà fi ṣe àpẹẹrẹ, ohun kan náà ni a rí. Agbọ́tekuwífẹyẹ ni wọn. Fágùnwà ní
nwọn gbadun ati ma sọrọ ara wọn lẹhin kiri, ninu gbogbo awọn ti a ba pade nibẹ ṣaṣa ni ẹniti ko sọrọ ẹlomiran loju wa... nwọn le di ẹru pupọ si iyara wọn, bi nwọn ba si nlọ si idalẹ nwọn a di ẹru kítikìtì, ko si nkan ti wọn ko ni di tan... ṣugbọn nwọn le bẹru pupọ, bi ilẹ ba ti ṣu diẹ nwọn ko ni le nikan rin lọ si ibikibi (Ìrèké Oníbùdó, Pg. 111-112)

A kúkú ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé wa ló gbàgbọ́ pé obìnrin kò ṣeé fọkàn tán gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ìwé wọn. Èyí nìkan kọ́, lójú wọn, àwọn obìnrin yìí kì í lèé dúró ti ni ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ìyẹn ni pé aríre-bánijẹ ni wọ́n abàgbọ́n-ìsàlẹ̀-bí-ìkéèmù. Bí nǹkan bá sì ń dára fún ènìyàn, wọn yóò dúró ṣùgbọ́n tí ó bá yí padà pẹ́rẹ́, ṣe ni wọn yóò bá ẹsẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ tí wọn yóò kọ ìpàkọ́ sí ilé ẹni náà, wọ́n lọ nì yẹn. Ọlọ́runṣògo ni ti wọn, wọn ò sí ni Sùúrùlérè. Fágùnwà ní
kini ẹnyin obinrin mọ nipa ọkunrin ju pe ki ẹ duro bi apata lẹhin rẹ nigba igbadun, ki ẹ sa bi igbati ọmọ ẹran ba sa fun kiniun nigba wahala, ki ẹ ko dukia rẹ fun ilo ara yin, ki ẹ ma lo ọla ki ẹ si ma yọ ninu aṣọ olowo iyebiye, ki ẹ ma pe pẹlu awọn enia pataki, ṣugbọ́n ẹ dabi ejo oloro labẹ korko, paramọlẹ ti nbu enia lẹsẹ jẹ, ẹniti o n da ija silẹ ti o nta kete, bayi ni ẹ jẹ, ẹnyin obinrin. (Ìrèké Oníbùdó, Pg. 88-89)

Ohun tí Fágúnwà ń sọ yìí náà ni ó dàbí ìgbà pé Ládélé fi ara mọ́. Ní ojú tirẹ̀, ẹni tí a lè tàn kí ó sì ṣe ọkọ rẹ̀ ní ìjàmbá ni àwọn obìnrin, ó ní:
Bayi ni nwọn ṣe gbe majele ọlọ́ọ̀rẹ̀rẹ̀ lé Torera, iyawo Bankọ́lé lọ́wọ́, o gbà á, o si fi sinu ounjẹ fun baálé rẹ̀. Nwọn kije tán, o di ọjọ keje ni aarẹ ọ̀gẹ̀u de si Bankọle (Jẹ N Logba Temi, Pg. 17)

Ohun míràn tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé yìí máa ń ṣe àkíyèsí ni ìkóbìnrinjọ. Bí ó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ wa kì í ṣe ohun tí ó máa ń tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tí ó ṣẹlẹ̀ sí ba olú-ẹ̀dá-ìtàn nínú Igbó Olódùmarè, ohun tí ó fà á kò ju ti pé ó kó obìnrin jọ lọ. Ó tilẹ̀ ṣe, Fágúnwà wá sọ ọ̀rọ̀ ìkó obìnrin jọ di orin, ó ní
Obìnrin kan, ìgbaudn pupọ
Obìnrin meji, ijangbọn meji
Obìnrin mẹta, ijangbọn mẹta (Igbó Olódùmarè, Pg. 132)
Ó tún ṣe, ó ní
iyawo bẹrẹ, ijangbọn bẹrẹ ni, bi iyawo ti npọ si i, bẹẹni ifẹ wọn ndin si i            (Igbó Olódùmarè, Pg. 102)
Ohun tí ó fa wàhálà yìí lójú àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí ni ìnáwó tí àwọn obìnrin yìí  yóò máa kó ọkọ wọn sí àti ni pàtàkì jù lọ, owú ara wọn tí wọn yóò máa jẹ. Gbogbo ibi tí àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí bá ti ń mẹnu ba ilé aláya púpọ̀ ni wọ́n ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí ìjà àti asọ̀ ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ láàrin wọn. Nínú kí ìyàwó kan fẹ́ ṣe èkejì rẹ̀ ní ibi tàbí kí ó fẹ́ fi ibi ṣe àwọn ọmọ rẹ̀. Nínú Ìrèké-Oníbùdó, a rí i pé wàhálà tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ láàrin ìyàwó méjìlélógún tí Ìrèké-Oníbùdó ní ni ó fa ìparun rẹ̀. Nínú ìwé kan náà, a ri i pé orogún ìyá Ìfẹ́pàdé, ìyẹn ìyá Ìfẹ́pínyà, gbìyànjú láti fi ọmọ rẹ̀ fún Ìrèké-Oníbùdó. Ó tilẹ̀ tún gbìyànjú láti fún ìyá Ìfẹ́pàdé ní májèlè jẹ. Ohun tí ó sì fa gbogbo eléyìí kò ju owú ìyàálé rẹ̀ tí ó ń jẹ lo wí pé ọmọ rẹ̀ rí Ìrèké-Oníbùdó fẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni nínú Àdììtú Olódùmarè, gbogbo ìtàn Ẹ̀san-mbọ tí a sọ fún wa, a sọ ọ láti fi bí àwọn obìnrin ṣe máa ń jowú ara wọn hàn ni. Kò tẹ́ ìyàwó ọba kìíní, ìyẹn Ọmọ-owu, lọ́rùn bí ọba ṣe fẹ́ràn Ẹsan-mbọ, nítorí náà, ó sa gbogbo agbára rẹ̀ láti pa á. Gbogbo ohun tí ìyá Ìfẹ́pàdé rò pọ̀ nì yí tí ó fi sọ pé:
Bi orogun ba nfi oju rẹrin ọ̀rọ̀ ejo mbẹ ni ookan aiya wọn (Ìrèké Oníbùdó,    Pg. 85)
Tí a bá tún wo inú Aiye Daiye Oyinbo, Àṣàbí tún kín ọ̀rọ̀ ìyá Ìfẹ́pàdé lẹ́yìn ni nígbà tí ó sọ pé:
(baba mi) sa fẹran mi pupọ ju gbogbo awọn orogun iya mi iyoku lọ. Ifẹ yi ran gbogbo awọn ọmọ inu iya mi. Iyawo ti a ba fẹran ni ọmọ rẹ nwu ni. Baba wa fẹran wa ju ọbakan ati iyekan wa iyoku lọ... ifẹ na fẹrẹ di ọtẹ o fẹrẹ di ija igboro, nitoripe gbogbo wa ni gbogbo ile doju sọ, awọn a ma suka si wa, nwọn a wipe: “ọwọ a tẹ yin lọjọ kan...” nigbati Ọbafunkẹ ẹgbọn mi ku, awọn ọmọ araiye wipe awọn orogun iya mi li o pa a. Baba wa gba eyi gbọ, bẹni iya wa gba a gbọ pẹlu. (Aiye Daiye Oyinbo, pg. 1-2)
Ọ̀rọ̀ ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa máa ń mẹ́nu bà yìí tilẹ̀ wá ká Bamgboṣe (1974: 61)28 lára tí ó fi sọ pé:
... there is no profound observation on woman in the novels. The opinions expressed by the various charactes are merely commonly-held prejudices... (they) merely follow views commonly held by the Yorùbá.

Ìyẹn ni pé yàtọ̀ sí ohun tí a ti mọ̀ nípa àwọn obìnrin wa àti àwọn ohun tí a ti máa ń gbọ́ nípa wọn, kò tún sí nǹkan titun míràn dàbíalárà tí àwọn òǹkọ̀wé wa mẹ́nu bà nípa wọn. Ọ̀pọ̀ ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa mẹ́nu bá yìí wá dàbí ìtàn ojú ayé èyí tí Darthorne (1965: 88)29 pè ní “almost a manual of social anthropology”. A kò sọ pé irú àwọn ìtàn àròsọ báyìí kò dára. Àwọn náà ní ògo ti wọn. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá, àṣejù a máa ba ẹkùn sàárẹ́ jẹ́. Kò yẹ kí ó jẹ́ pé ibì kan ni gbogbo wa ó sùn tí a ó kọ orí sí. Darthorne (1965: 88)30 náà gbà pẹ̀lú wa wí pé irú ìtàn báyìí náà dára tí a bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ìtàn gidi inú rẹ̀ ní ìwọ̀ntunwọ̀nsì tí a sì tẹnpẹlẹ mọ́ àwọn ohun míràn tí ó máa ń gbé ìtàn àròsọ níyì, ó ní:
The ‘anthropological’ novel can be a successful novel; but it fails when ti indulges in overt documentary excessiveness to the detriment of clear-cut chacterization, well developed narrative sequences and forceful relevant environment.


Gbogbo nǹkan tí Darthorne (1965) sọ pé ó tọ́ kí òǹkọ̀wé ṣe kí ìwé ìtàn àròsọ rẹ̀ lè gbégbá orókè ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé wa ń ṣe síbẹ̀ ó yà wá lẹ́nu bí ó ṣe jẹ́ pé irú ìhá tí a ṣe àlàyé sí òkè yẹn ni wọ́n kọ sí obìnrin nínú ìwé wọn. Ohun tí a wá rò ni pé bóyá nítorí pé ọkùnrin ni ó pọ̀ jù nínú àwọn òǹkọ̀wé yìí ni ó fà á. Ṣùgbọ́n eléyìí nìkan kò tó ní ìdí tí ó gíríkì fún àwọn ohun tí a rí nínú ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ wa nípa obìnrin. Àfi bí ìgbà pé wọ́n f’ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn “Movements for Progressive Nigerians” (1978: 23)31 ṣẹ wí pé:
Everyone speaks of socialism but no one was willing to surrender the privilege or even the separateness of his group.


ìyẹn ni pé gbogbo ènìyàn ló ń sọ̀rọ̀ nípa jẹ-kí-n-jẹ ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó fẹ́ jọ̀wọ́ ìgbádùn tí ó ń gbádùn tàbí kí ó gbà kí gbogbo wa di ọ̀kan náà láìsí ìyàtọ̀. Nítorí ìfẹ́ tí a ní sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà tí àwa fúnra wa wà, ọ̀rọ̀ pé nǹkan ń yí padà sí rere kì í jẹ wá lógún. Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni a máa ń sọ ọ dà, a kì í kù gìrì ṣe ohun tí ó lè mú àyípadà yìí wá. Bẹ́ẹ̀ rèé, a fẹ́ a kọ̀, nǹkan gbọ́dọ̀ yí padà ni mọ̀nà nítorí kò tí ì sí àwùjọ tí ó wà tí ó tiiri sí ojú kan bí omi. Àkíyèsí eléyìí ni May (1965: 44)32 ṣe nígbà tí ó ní:
In our group interest, we have yet to learn to adjust ourselves to change. Nearly every group is striving to protect its status quo. But none can hope to do so... There is no permanency anaywhere. Nor will there be.

Ohun tí May (1965) sọ yìí kò tilẹ̀ tànmọ́-ọ̀n sí àwọn òǹkọ̀wé wa páà. Ń ṣe ló dàbí ìgbà pé wọ́n ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ dẹ́yẹ sí àwọn obìnrin wa ni. Wọn kì í tò wọ́n sí ipò kan náà pẹ̀lú ọkùnrin. Wọn a fi ọkùnrin jẹ gàba le obìnrin lórí. Wọn a máa lò wọ́n bí ẹni lo omi òjò. Bẹ́ẹ̀ rèé, nínú ìtàn gidi tí a rí kà, a mọ ipa tí obìnrin ń kó ní ilẹ̀ wa. Johnson (1921: 201)33 ní:
On the whole women seem to be far more industrious than men, for whereas the men always continue to have leisure hours and off days from work, the women seem to have none.


ìyẹn ni pé àwọn obìnrin máa ń ṣiṣẹ́ ju ọkùnrin lọ. Níbi tí ọkùnrin yóò ti ní àyè tí yóò fi simi, àwọn obìnrin kì í ní. Bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ oko ni wọ́n ń ṣe ti ilé. Àwọn obìnrin yìí ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé wa wá to sí ipò yẹpẹrẹ. Ọ̀nà tí obìnrin tilẹ̀ fi wúlò ju èyí tí Johnson (1921) mẹ́nu bà lókè yìí lọ. Òun ló ń bí ọmọ tí ó ń tọ́ ọmọ. Yóò ṣiṣẹ́ ohun tí ọmọ yóò jẹ. Òun kan náà yìí ni yóò wá oúnjẹ fún ẹbí rẹ̀ láti jẹ. Gẹ́gẹ́ bí Benjamin (1977: 34)34 ṣe ṣe àkíyèsí, ó ní:
the woman in her role as mother and wife is both the producer of man (or rather of man and woman) and the reproducer of his working strength.


ìyẹn ni pé obìnrin kan náà tí ó ń ṣe ọ̀nà àtiwáyé takọtabo ló ń ṣe oúnjẹ tí a ń jẹ tí a fi ń lókun lára láti ṣiṣẹ́. Ní ààrin àwọn ẹbí pàápàá, òun ló ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé. Oùn ni gbogbo ẹbí máa ń sọ di kááyá tí yóò máa ṣe gbogbo iṣẹ́. Láti kékeré ni àwọn òbí ti máa ń ya iṣẹ́ obìnrin sọ́tọ̀ sí ti ọkùnrin. Wọn yóò máa kọ́ ọ bí yóò ṣe lè ṣe iṣẹ́ ilé bí ó bá dàgbà.
Lékèé wí pé ipa tí obìnrin ń kó láàrin wa pọ̀ gan-an, yàtọ̀ sí irú Ìbíwùmí nínú Ọmọ Olókùn Ẹsin, (a ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níwájú) àti àwọn bí i mélòó kan nínú àwọn ìwé míràn, ipò tí a máa ń to àwọn obìnrin sí nínú púpọ̀ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ wa kò ní láárí tó. Nínú ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé wọ̀nyí, obìnrin kò pé láìṣe pé lọ́kọ bẹ́ẹ̀ rè é a kì í fi ojú tìṣẹ́ tìyà wo ọkùnrin tí kò bá láya, a ó sì máa fi ojú tẹ̀gbin tòṣì wo obìnrin tí kò lọ́kọ. Bí obìnrin bímọ láìlọ́kọ, ọ̀ràn. Irú èyí gan-an ni ó ṣẹlẹ̀ sí Abíkẹ nínú Jẹ́ N Logba Temi. Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Ẹẹ́sítà dá tó bẹ́ẹ̀ nínú ìwé yìí kan náà bí kò ṣe ohun tí àwọn “Movement of Progress Nigeria” (1978: 23)35 sọ tí ó bá òǹkọ̀wé yìí, ìyẹn Ládélé, mu gan-an ni. Wọ́n ní:
A radical woman engenders condemnation, opposition or social applause mixed with surprise. Even the applause and surprise when not immediately replaced by derogatory explanations as regards the root of the radicalism is itself the expression of the social limitation.


Ìyẹn ni pé obìnrinkóbìnrin tó bá gbìyànjú àtifa akọ yọ, tí ó bá fẹ́ ṣe ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, ohun tí àwọn ènìyàn yóò ṣe ni pé yálà kí wọ́n ta kò ó tàbí kí wọ́n pa àtẹ́wọ́ fún un. Àtẹ́wọ́ tàbí oríyìn tí wọn yóò fún un yìí kì í ṣe ti pé o-ṣe-é-o-kú-iṣẹ́. Tí kì í báá ṣe ti ìbu ẹnu àtẹ́ lù, a jẹ́ pé wọ́n ń sọ fún un pé ó ṣe ohun tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kò lè ṣe.
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nì yi pẹ̀lú Ẹẹ́sítà. Ń ṣe ni Ládélé n jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa wo Ẹẹ́sítà tìkàtẹ̀gbin. Bẹ́ẹ̀ kì í ṣe bí ó ṣe yẹ kí nǹkan rí nì yí. Ènìyàn méjì sáà lọ́ ń jẹ̀bi sún-mọ́-mi n-ò-sún-mọ́-ọ. Ká ni Ẹẹ́sítà lóyún, ǹjẹ́ òun ni ó fún ara rẹ̀ lóyún? Wọn ò ṣe lọ mú ẹni tí ó fún un lóyún kí wọn ṣe é sìbásìbo? Tí a bá ní kí á fi ìwé yìí wé ìwé Sembene, a ó rí i pé ìwé Sembene dáńgájíá jù ú lọ. A sọ èyí nítorí pé nínú ìwé rẹ̀, God’s Bits of Wood, bíbú lásán ni ọkùnrin kan bú ìyàwó rẹ̀ tí gbogbo àwọn obìnrin kó ara wọn jọ, ohun tí ojú ọkùnrin yìí rí kúrò ní kékeré. Ní ìgbà tí ọwọ́ àwọn obìnrin yìí tẹ̀ ẹ́, wọ́n dè é mọ́ igi, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí níí máa kọ orin burúkú fún un, wọ́n ń jó yi i ká, wọ́n tilẹ̀ tọ̀ lé e lorí dánwò. Ẹnu Seymour (1983: 49)36 ni ọ̀rọ̀ yìí ti dùn, ó ní:
After seizing their victim, they tied him to the tree. The women began to sing a song which said very bad things – a very bad song. This is a standard song they sing: ‘You abuse your wife. You call her names...’ They said that he was merely an old man whose penis always pointed down, and they laughed and laughed... While they were abusing him they danced around him and put their naked vulvas in his face. He was terribly ashamed and the smell was bad too. Some of the women also urinated on him. Thereafter, we are told he was made to endure further humiliations!

  Yàtọ̀ sí ti pé obìnrin nìkan ni wọ́n máa ń dá ẹ̀bi tí ó yẹ kí ó jẹ́ ti ọkùnrintobìnrin fún, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó jẹ́ pé nǹkan lè má wu àwọn obìnrin yìí nínú ọkàn wọn ṣùgbọ́n lójú àwọn òǹkọ̀wé wa, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà á bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀. Àṣàbí sọ nínú Aiye Daiye Oyinbo wí pé:
Niti emi, bi mo jẹ ọkunrin ng ko ni fẹ ju iyawo kan lọ nitori ohun ti oju mi ri ni ile baba mi... ko kere (Pg. 5)

Síbẹ̀, ìyàwó tí ọkọ rẹ̀ fẹ́ lé e kì í ṣe ẹyọ kan mọ, kò sì sí ohun tí ó lè ṣe. Ọ̀rọ̀ ti pé ìyàwó púpọ̀ dára tàbí kò dára kó ni ó yẹ kí àwọn òǹkọ̀wé wa máa tẹnpẹlẹ mọ́. Ohun tí àwọn obìnrin yìí ìbà ṣe láti dín ìyà wọn kù ló yẹ kí ó jẹ òǹkọ̀wé lógún.
Tó bá jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé wa fẹ́ ṣe nǹkan bí ó ṣe tọ́ ni, ń ṣe ló yẹ kí takọtabo máa jọ gbayì tàbí kí wọn jọ máa tẹ́ fún ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe. Bí ọkùnrin bá ṣe nǹkan kan tí ó dàbí àṣejù, kò sẹ́ni tí yóò bá a wí, wọ́n tilẹ̀ lè kà á kún akọni. A sáà rí ohun tí àwọn ọmọ Ọba Òkò àti Tóngẹ́ẹ́ ṣe nínú Ọmọ Olókùn Ẹṣin àti Ìgbì Ayé Ń Yí. Kò sẹ́ni tí ó yọ sùtì ètè sí ìwà wọn. Tí ó bá jẹ́ obìnrin ni, wéré ni wọn yóò ti sọ ẹ̀bi di tìyá-tọmọ bí ìyá kò tilẹ̀ mọwọ́-mẹsẹ̀ ọ̀rọ̀. A rí àpẹẹrẹ ìda ẹ̀bí tí kì í ṣe tẹni léni lórí yìí nínú Aiye Daiye Oyinbo nígbà tí baba Àlàbí fi ọ̀rọ̀ ọkọ lọ Àṣàbí tí Àṣàbí kọ̀ sí i lẹ́nu, wéré ó ti yára sọ ọ̀rọ̀ di ọ̀rọ̀ iyá rẹ̀ ó ní:
Iwọ, irọ lo pa, Ṣe iyẹn ọ̀rọ̀ iwọ ati iya rẹ irọ lo pa (Pg. 6)

Abájọ tí Àṣàbí fi sọ fúnra rẹ̀ lẹ́yìn eléyìí pé:
Ohun gbogbo ti ọmọ ba ṣe iya li ẹlẹbi rẹ... ati pe iya mi li oludamọran mi, o ti fi mi lọ́kọ, o ti kọ mi nikọkukọ (Pg. 6)
Gbogbo ohun tí èyí ń fi hàn ni pé baba ni aláṣẹ nínú ẹbí. Lójú Délànọ̀, bí ọkùnrin tilẹ̀ ṣẹ obìnrin, wọn kò gbọdọ̀ tọrọ àforíjì. Bẹ́ẹ̀ rè é, obìnrin kò sì gbọdọ̀ bínú, ó ní:
... Ewọ ni, a ko gbọdọ gbọ ọ ni, mba tọrọ aforiji lọwọ rẹ fun iwa mi na. Ki Balogun ma bẹ obinrin? Ẹwọ! (Ibid., Pg. 16)

Obìnrin yìí kan náà ni Délànọ̀ fi yé wa wí pé wọn kò lẹnu dan-in-dan-in nínú ọ̀rọ̀ ọmọ wọn láyé ìgbàanì. Èyí ta ko ohun tí Johnson (1921) ti fi yé wa ṣáájú. Ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa kàn ń fẹ́ ṣe ni láti sọ obìnrin di ohun tí Seymour (1983: 8)37 sọ nípa wọn pé:
they are pasisve pawns where their male counterpats are active agents.


ìyẹn ni pé àwọn obìnrin máa ń dákẹ́ bí olúńdù ni ti àwọn ọkùnrin wọn yóò máa mú wọn lò bí ó ṣe wù wọ́n. Tí àwọn òǹkọ̀wé yìí bá rí obìnrin tí tirẹ̀ fẹ́ yọyẹ́ díẹ̀, yálà nípa ìwé tí ó kà ni o tàbí  ohun míràn, kí ó torí èyí fẹ́ gba ara rẹ̀ sílẹ̀, bí wọn yóò ṣe gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ hàn wá kò ní í sunwọ̀n. Irú nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jọkẹ́ nì yí nínú Àyànmọ́. Nítorí pé Jọkẹ́ ti gba oyè Lọ́ọ́yà bọ̀ láti òkè òkun tí ó sì ti mọ ẹ̀tọ́ rẹ̀ dé ojú àmì ni ó jẹ́ kí Ọlábímtán gbé e hàn wá bí ẹni tí ó ń pe ọkọ rẹ̀ lórúkọ, tí ó ń wọ pátá gbigbóná, tí ó sì ń mu sìgá èyí tí Àlàkẹ́ ẹni tí ó tẹ̀ sí ibi tí wọ́n ń fẹ́ kì í ṣe. Ṣé sisí sohin ni òun ní tirẹ̀.
Bí ó ti wù kí ọkùnrin lè wu obìnrin tó, obìnrin yìí kò lè kù gìrì sọ pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ ṣùgbọ́n ọkùnrin, lójú àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí, ló lè máa wọn obìnrin wò bí ẹni ń wọn ọjà tí ó fẹ́ rà. Nínú Ó Le Kú, Àjàní ní:
Àṣàkẹ́ lẹ́wà ṣùgbọ́n kò mọ̀wé kí oun ma lọ bímọ jọ ọ́, ìyẹn nípa ọpọlọ nínú. Ọpọlọ Lọlá pé ṣùgbọ́n kò rẹwà tó Àṣàkẹ́. Ohun tó rẹwà kì ítètè é tí. (Pg. 8)

Ṣé ti Àjàní tilẹ̀ sì dára díẹ̀, ṣebí ń ṣe ni ó ṣẹlẹ̀ nínú Orúkọ Ló Yàtọ̀ pé Mọrẹ́nikẹ́ tí ó jẹ́ aya àfẹ́sọ́nà Fálọlá ń kọjá lójúde Ọba Ọ̀dàn lọ sí ọjà alẹ́, Ọlọ́dàn rí i, ó sì ní kí àwọn Ìlàrí òun lọ gbé e wá tí ó ní òun gbé ẹsẹ̀ lé e. Báyìí ni Mọrẹ́nikẹ́ ṣe di aya ọba. Ọ̀rọ̀ ti pe ọba gbẹ́sẹ̀ lé e kò dùn wá tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. A ṣá mọ̀ pé òun ni aláṣẹ, èkejì òrìṣà, ikú bàbá yèyé ní pàtàkì kí àwọn yìnbó tó gòkè. Ṣùgbọ́n ìbéèrè tí ó yẹ kí ó jẹ òǹkọ̀wé lógún ni pé ǹjẹ́ ó yẹ kí á sọ ọmọ ènìyàn di ẹran tí a kàn lè mú nígbà tí ó bá wù wá bí ẹni mú ewúrẹ́? Ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ nínú Ìgbì Aye N Yí nígbà tí Deegbe
... rí obìnrin arẹwà kan ti nsa gíjógíjó. O ni ki wọn pe e wá... Deegbe ni ki ọkọ obinrin yii maa mu un ni so ní Òtólú ki oun ba a ni ọ̀dẹ̀dẹ̀ òun. (Pg. 11)

Ọ̀rọ̀ bí a ṣe ń ṣe obìnrin nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ wa yìí wá bá ohun tí lámèyítọ́ kan sọ mu wí pé:
We are denied into (their) mind and emotion. We are left with an image of woman as sex object and exchange commodity... a submissive subordiante38


Ìyẹn ni pé àwọn òǹkọ̀wé wa kì í jẹ́ kí á rí èrò ìkọ̀kọ̀ ọkàn àwọn obìnrin. Wọ́n kàn sọ wọ́n di ohun èlò lásán tí a lè ṣe bí ó ṣe wù wá tí wọn kò gbọdọ̀ gbin.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé olùwòran lásán ni ipò tí obìnrin yóò wà tàbí kí ó jẹ́ “arọ́kin” irú èyí tí Àṣàbí ń ṣe nínú Aiye Daiye Oyinbo. Wọn kì í mú èdè lò lọ títí bí ọkùnrin. Àsìkò wo ni wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún náà o jàre. Mo rò pé irú èyí ni Seymour (1983: 16) 39 rí tí ó fi sọ pé:
Linguistic competence and dexterity is a mark of being human. The women in quesiton are relegated to a sub-species characterised by restrcitions, confinement and overall underdevelopment ... and this is amply illustrated in the novels.


Ìyẹn ni pé bí mímọ èdèé lò bá jẹ́ àmì kan pàtàkì láti fi bí a ṣe jẹ́ ènìyàn sí hàn, a ó ṣe àkíyèsí wí pé a kò fi àwọn obìnrin hàn bí ènìyàn gidi nítorí a kì í jẹ́ kí wọ́n gbé ìmọ̀ èdè wọn yọ ní pàtàkì nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ wa.
Púpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé yìí ló jẹ́ pé wọn kò fi ọ̀nà kankan hàn wá tí àwọn obìnrin yìí fi lè gba ara wọn sílẹ̀. Ohun tí ọkọ wọn bá sọ ni abẹ gé. Pé ọkọ bínú lásán báyìí, ìyẹn ti tó kí ìyàwó bú sí ẹkún bí ọmọ àná. A kò tilẹ̀ rí ọ̀kankan nínú wọn tí a lè sọ pé ó là ó lu. Jùmọ̀kẹ́ tí a lè sọ pé ó là díẹ̀ nínú Baba Rere, ọkọ rẹ̀ Dúró ni ó ń ṣiṣẹ́ sìn. Gbogbo nǹkan tí ó bá ti jẹ́ ti agbára tí ó sì jọni lójú ló jẹ́ ti ọkùnrin tí gbogbo ohun tí a bá tí ń fi ojú tẹ́mbẹ́lú máa ń jẹ́ ti obìnrin. Èyí kò sì dara tó lójú ti wa.
Òǹkọ̀wé kan tí a rò pé ó fẹ́ yàtọ̀ ní ojú ti wa nínú àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí ni Fálétí, ìyẹn nípa bí ó ṣe gbe Ìbíwùmí hàn wá. Èyí kò sì dédé rí bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kìíní ná, bóyá ni a fi lè gbọ́ apá kan ìtàn yìí láìjẹ́ pé a ṣe Ìbíwùmí bí a ṣe ṣe é yẹn. Yàtọ̀ sí èyí, bóyá ni ìjàgbara inú ìwé yìí ìbá fi yọrí sí rere láìsí Ìbíwùmí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé ní àsìkò tí nǹkan bá le koko, lásìkò ọ̀tẹ̀, lásìkò làásìgbò ni àwọn ohun tí a lè ṣe ṣùgbọ́n tí ó ti sá pamọ́ nínú wa máa ń jẹ jáde. Òyìnbó kan ti ṣe àkíyèsí èyí, ó ní:
It takes an emergency to bring out the best in us and unmask our dormant talent40


Ohun gan-an tí ó ṣẹlẹ̀ nì yí nínú ìwé Fálétí tí ó fi lo Ìbíwùmí bí ó ṣe lò ó. Ṣé ó fẹ́rẹ̀ máà sí òǹkọ̀wé míràn tí ó kọ ìtàn àròsọ lórí ìjàgbara ní èdè Yorùbá. Fálétí mú Ìbíwùmí lò bí ó ṣe mú un lò nítorí pé ó nílò rẹ̀ gan-an ni kí ìwé rẹ̀ baà lè yọrí sí rere. Àìmú un lò báyìí, bóyá ni ìwé yìí ìbá fi gbe igba orókè.
Lékèé wí pé ó ní ìdí tí Fálétí fi mú Ìbíwùmí lò bí ó ṣe mú un lò yìí, síbẹ̀, ipa tí Ìbíwùmí kó nínú ìwé yìí wù wá gan-an ni. Ó fi hàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn obìnrin wa lè ṣe tí àwọn òǹkọ̀wé wa ń bò mọ́lẹ̀. Kì í kúkú ṣe pé kò ni Fálétí lára díẹ̀. Ó ni ín lára, ọgbọ́n ni ó dá sí i. Irú ọgbọ́n tí àwọn òǹkọ̀wé máa ń dá ní àwùjọ àwọn a-fẹ́-á-jẹ-má-fẹ́-á-yó náà ló dá sí i. Ṣé gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ ìwé tí a kọ ní àwùjọ yìí ni ó jẹ́ pé wọn kì í jẹ́ kí obìnrin kó ipa tí ó jọnilójú tàbi èyí tí yóò ta ìlànà pé kí ọkùnrin jẹ gàba láyà. Ṣùgbọ́n tí ó bá wá jẹ́ pé òǹkọ̀wé wá rí obìnrin kan tí ó fẹ́ mú lò lọ́nà tí a kì í ti í ṣe bẹ́ẹ̀ mú obìnrin lò tẹ́lẹ̀, ohun tí yóò ṣe ni pé kí ó kọ́kọ́ fa irú obìnrin bẹ́ẹ̀ yọ kúrò nínú gbogbo ohun tí a mọ̀ mọ́ obìnrin, wọn yóò gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àrà ọ̀tọ̀. Seymour (1983: 21)41 ní:
In a great deal of bourgeois and petty bourgeois art only the men receive multidimensional treatment. Within the confines of this ideological framework, a female character exhibiting independent thought or initiative which directly challenges patriarchal assumptions and priorities is semantically re-classified and disassociated from the fremale category. In other words, the exception proves the rule.

Gẹ́gẹ́ bí Seymour (1983) ṣe sọ yìí tí àwa náà sì ti ṣe àlàyé sí òkè, jẹ́ kí a wo bí Fálétí ṣe mú Ìbíwùmí lò. Ohun tí Fálétí kọ́kọ́ ṣe ni pé kí ó mú Ìbíwùmí ṣe ohun tí kò tọ́ sí obìnrin láti ṣe. Ó ran Àjàyí lọ́wọ́ láti jáde ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Èyí kì í ṣe eegun tí ó rọ̀ tí obìnrin lè ṣe bẹ́ẹ̀ fọ́. Yàtọ̀ sí èyí, lékèe wí pé Àjàyí jẹ ọ̀tá baba rẹ̀, ó dara pọ̀ mọ́ ọn láti ja ìjà òmìnira. A mọ̀ pé ó gba Àjàyí gan-an ní àsìkò kí ó tó lè ṣe àlàyé tó tó láti yí Ìbíwùmí lọ́kàn padà ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ó ti yí i ní ọkàn padà tán yìí, Ìbíwùmí wá di ènìyàn tuntun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ọ̀rọ̀ ìyàwó Macbeth tí ó sọ pé:
... Come, you spirits
that tend on mortal thoughts,
unsex me here,
And fill me from the crown to
The toe, top-full
Of direct cruelty!...42

Ohun tí ìyàwó Macbeth ń ṣe ní ibi ni pé ó ń gbàdúrà sí gbogbo àwọn ẹ̀mí wí pé kí wọ́n sọ òun di ọkùnrin. Ṣé ọkùnrin ni ó rò pé ó lè ṣe ohun líle tí ó fẹ́ ṣe. Lóòótọ́ Ìbíwùmí kò gbàdúrà irú èyí sí ìta àti pé ohun tí òun fẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ti ìyàwó Macbeth, ìyẹn ni pé iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe ní tirẹ̀ kì í ṣe iṣẹ́ ibi. Tí a bá sì torí àwọn ohun tí ìyàwó Macbeth ṣe pè é ní obìnrin alágbára, a ò rí ìdí tí a kò fi ní í pe Ìbíwùmí náà ní alágbára ní pàtàkì nípa iṣẹ́ ìṣèlú ìjàgbara tí ó ti ara bọ. Èyí wá jẹ́ kí á gbà pẹ̀lú ohun tí Okonjo (1976: 46)43 sọ wí pé: “Nigerian women in traditional times were active politcial animals”, ìyẹn ni pé ní ìṣẹ̀ṣe, àwọn obìnrin wa ń kó ipa tí ó jọjú nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. A ó ṣe àkíyèsí pé wéré tí Ìbíwùmí ti gba ohun tí Àjàyí wí wọlé ni ó ti bèèrè fún ogún tirẹ̀ lọ́dọ̀ baba rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ pé ṣàṣà ni nínú àwọn òǹkọ̀wé wa ni ó lè jẹ́ kí obìnrin tí ó bá jẹ́ ẹ̀dá-inú-ìtàn ìwé òun ṣe irú èyí. Ogún tí Ìbíwùmí gba yìí ni ó fi ra àwọn ẹrú padà. Àwọn ẹrú yìí náà sì ṣe iṣẹ́, wọ́n ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú míràn. Àwọn ẹrú yìí ló wá ja ìjà ìdí Àràbà. Baba ‘re àti Ọbákáyéjá. Ara àwọn ẹrú tí Ìbíwùmí kọ́kọ́ rà ni wọ́n sì ṣe olórí wọn. Ìgbà tí Ìbíwùmí pàápàá fi ojú àwùjọ wa wo ara rẹ̀, ó yà á lẹ́nu gan-an gidi ni tí òun fúnrarẹ̀ fi sọ pé:
Idi nu ti mo fi dabi ọmọ buruku (Ọmọ Olokun Ẹsin, pg. 86)
Kì í kúkú ṣe ọmọ burúkú ṣùgbọ́n lójú àwọn ènìyàn wa, yóò jọ ọmọ burúkú nítorí wọn yóò rò pé ọmọ burúkú ló lè ṣe irú ohun tí ó ṣe yìí.
Ìgbà tí Àjàyí tilẹ̀ sì bá a lẹ́wọ̀n, lékèè wí pé wọ́n jọ bẹ̀rẹ̀ ìjà yìí ni, ó yà á lẹ́nu nítorí kò mọ̀ pé ó lè fi orí tì í dópin ó ní:
Nígbàti mo fi ipa kọ oju obinrin na si ọdọ mi ti ngo wo oju rẹ – igi da ni: Mo ni “Ibiwumi! Tabi tanu? Kini o wa de inu tubu nihin... Ẹnu ya mi (Ọmọ Olókùn Ẹsin, Pg. 77)

Lójú tiwa, irú àowọn bí i Ìbíwùmí ni Ṣòyínka ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí ó ní:
They ride on the crest of the wave... make the human problem theirs and sacrifice themselves voluntarily for the common man (Soyinka: The Strong Breed)

Ìyẹn ni pé irú wọn ni ọ̀gbìgbà tí ń gba ará àdúgbò. Àwọn ni ojú wọn ti rí nǹkan bí okùn bí okùn tí wọ́n ti fi imú dán irin nítorí àtigba ọmọ ènìyàn ẹgbẹ́ wọn là.
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n nípa tí pé òǹkọ̀wé tó dáńgájíá ni Fálétí. Irú Fálétí ni Horner (1971: 3)44 ní ní ọkàn nígbà tí ó sọ pé:
The great writer is... precisely that exceptional individual who succeeds in creating within a specific domain, ... an imaginary universe ... the structure of which corresponds to that towards which the social groups is directed.

Ìyẹn ni pé lójú Horner (1971), òǹkọ̀wé tí ó dáńgájíá ni òǹkọ̀wé tó bá gbé èrò ọkàn rẹ̀ kalẹ̀ tí ó jẹ́ pé ètò rẹ̀ bá ibi tí ọkàn àwọn ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ń fẹ́ lọ. Àwọn kan lè sọ pé ìyà jẹ Ìbíwùmí. Hẹn, a ò sọ pé ìyà kò jẹ ẹ́. Ìyà ìfẹ́ ìlú tí ó ní ni ó jẹ ẹ́. Ṣoyinka ti sọ àsọtẹ́lẹ irú ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí irú àwọn tí ó bá ní ìfẹ́ ìlú báyìí. Ó ní:
It is not the mouth of the boaster that says he belongs to the strong breed. It is the tongue that is red with pain and black with sorrow.
                                    (Soyinka: The Strong Breed)

 Ìyẹn ni pé kì í ṣe àwọn tí ó jókòó sí ibì kan tí wọn yóò máa dánnu ni a lè kà mọ́ àwọn alágbára bí kò ṣe àwọn tí ó jìyà gan-an. Ojú bọ̀rọ̀ kọ́ ni a fi ń gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́. Ìkòkò tí yóò sì jẹ ata ni, ìdí rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbóná. Tí àwọn kan bá wà ní àwùjọ kan tí a sì fẹ́ kí wọn ní ìlọsíwájú, kí wọn ní ìfẹ́ ìlú wọn ju bí wọ́n ṣe ní in tẹ́lẹ̀ lọ tí a sì fẹ́ ètò jẹ-kí-n-jẹ ní ìlú yìí, ohun tí a lè ṣe ni Fálétí ti ṣe yìí. May (1965: 28)45 ṣe àlàyé kíkún lórí èyí, ó ní:
if we wish to civilize the behaviour of individuals, groups or nation, we must civilize their desires and ambitions and inspire them to human service... We must show them by example that the desire to make some contribution, however humble, to the world we live in is the mostt stimulating and lasting desire which anyone can possibly harbour... the noblest aspiration of humanity, the desire of freedom, the love of justice, the sense of pity (should be enhanced).


A ó rí i pé gbogbo ohun tí May (1965) sọ yìí ni Fálétí ṣe. Ó dàbí ìgbà pé ó fẹ́ gbé ògo àwọn obìnrin ga. Ó mú ọ̀kan nínú wọn, ó fún un ní iṣẹ́ tí ó gbayì ṣe, ó sì jẹ́ kí ó ṣe é ní àṣeyọrí rere.
 Ní ìparí, àwa fi ara mọ́ ohun tí Seymour (1983: 35)46 sọ nípa ìwé Sembene tí a rò pé ó bá Ìbíwùmí mu nínú ìwé Fálétí, ó ní:
In Sembene’s work, not only are the women central to the plot and narrative structure, they are shown as being capable of change and capable of intiating change in others, and they are frequently portrayed in dynamic and dialectical opposiiton to authority figures, usually male.

Irú èyí ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé yòókù kò ṣe tí a kò fi ara mọ́.


Ìtọ́ka
1.      Ọba O. O. Oyesọsin Keji (1977: 3), “Ipa àti Ipò tí Àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní”, Yorùbá Gbòde, Vol., 3, No. 4.
2.      Benedict M. Ibitokun (n.d.: 1 1), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar paper delivered at the Department of African Languages and Literatures, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
3.      Karin Barber (1979: 22), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fágùnwà and Okèdíji”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ Universiyt, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
4.      Tony Bennett (1979: 115), New Accents: Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
5.      O.B. Yai (1977: 4), “Ideas for a Political Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at Orisha Tradition held at the Unviersity of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
6.      Karin Barber (1979: 4), Op. cit.
7.      Ibid., pg. 22.
8.      Ibid., pg. 5
9.      Op. cit.
10. Op. cit.
11. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (n.d.: 27), “Images of the Ọba in Yorùbá Novels”, a Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
12. Op. cit
13. Peter C.W. Gutkind (1975: 22), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Developing Area Studies, McGill Univeristy.
14. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (1976: 395), “The Detective Novel in Yorùbá”, Department of African Languages and Literatures Seminar Series, No. 1, 1976-77, Part II.
15. Karin Barber (1979: 39), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fagunwa and Okediji”, An unpublished Seminar Paper delivered at Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the 9th April, 1979.
16. Op. cit.
17. Robert Tressel (1965), The Ragged Trouserred Philanthropists, with an introduction by Allan Sillitoe, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
18. Peter Nazareth (1967: 35), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol, 6 (iv), Feb./March 1967.
19. P. Mercier (1966: 379), in P.C. Lloyed (ed.), The New Elites of Tropical Africa, OUP, London.
20. Ọmọlara Ogundipe-Lesilie (1981: 3), “A Marxist Reading of The Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English and Department of Philosophy Joint Seminar, University of Ibadan, Nigeria, 25th March, 1981.
21. O.B. Yai (1977: 10), Op. cit.
22. Ibid.
23. Op. cit.
24. Op. cit.
25. George Lamming (1973: 61), In The Castle of my Skin, quoted from S. Wayak “V.S. Naipaul and the West Indian Situation” Busara, Vol. 5, No. 1, 1973.
26. Kọ́lá Ògúngbẹ̀san (1971: 61), “Literature and Society in West Africa” African Quarterly, xi, 3.
27. Quoted from F.O. Okediji and Opeyemi Ọla (1967: 81) “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, vol. 4, No. 1.
28. Ayọ̀ Bamgboṣe (1974: 61). The Novels of D.O. Fágúnwà, Ethiope Publishing Corporation, Benin City.
29. O.R. Dathorne (1965: 63), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulleting of the Assocaition for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
30. Ibid.
31. Movement for Progressive Nigerians (1978: 23), “Nigerian Women and the Revolution of the Nigerian People” Positive Review, No. 1, 1978.
32. Walter Norman May (1965: 44), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
33. Rev. Samuel Johnson (1921: 201), The History of the Yorubas, (ed.) O. Johnson, C.M.S. Bookshop, Lagos.
34. Walter Benjamin (1977: 34), ‘Understanding Brecht’ New Left Books, London.
35. Op. cit
36. Hilary Seymour (1983: 49), “Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood. A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English, University of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
37. Ibid.
38. Ibid., pg. 20
39. Ibid.
40. Walter Norman May (1965: 26), Op. cit.
41. Ibid.
42. Quoted from Hilary Seymour (1983: 21), Op. cit.
43. Kamene Okonjo (1976: 46), “Igbo Women and Community Politics”, in Women in Africa (eds.) N.J. Hafkin and E.G. Bay. Stanford: Stanford University Press.
44. R. George Horner (1971: 3), “Folklore as a Psychological Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
45. Op. cit.
46. Op. cit.
Àkọ́jo Orúkọ Ìwé
Ìwé Ìtàn Àròsọ
Adeoye, C.L. (1966), Ẹ̀dá Ọmọ Oòduà, Onílé Owó Press, Ìbàdàn (later by OUP, Ibadan, 1971).
Akinlade, K. (1971), Ta Ló Pa Ọmọ Ọba?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1971), Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnṣìkà, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Aṣenibánidárò, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Ta Lolè Ajọ́mọgbé?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, (1974), Alosi Ọlọ́gọ, Longman, Lagos.
Akinlade, (1976), Owó Ẹ̀jẹ̀, Oníbọn-òjé, Ìbàdàn.

Àkọ́jo Orúkọ Ìwé
Ìwé Ìtàn Àròsọ
Adeoye, C.L. (1966), Ẹ̀dá Ọmọ Oòduà, Onílé Owó Press, Ìbàdàn (later by OUP, Ibadan, 1971).
Akinlade, K. (1971), Ta Ló Pa Ọmọ Ọba?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1971), Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnṣìkà, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Aṣenibánidárò, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Ta Lolè Ajọ́mọgbé?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, (1974), Alosi Ọlọ́gọ, Longman, Lagos.
Akinlade, (1976), Owó Ẹ̀jẹ̀, Oníbọn-òjé, Ìbàdàn.
Akinlade, (1976), Àgbákò Nílé Tẹ́tẹ́, Evans, Lagos.
Akintan, E.A. (1931), Ìgbẹ̀hìn Á Dùn, The Anchor.
Awoniyi, T.A. (1973). Ayékòótọ́, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Delanọ, I.O. (1955). Aiye Daiye Oyinbo, Thomas Nelson and Sons, London.
Delanọ, I.O. (1963), Lọ́jọ́ Ọjọ́ Un, Thomas Nelson and Sons, London.
Fadeṣere, P.I. (1978), Ajítòní, OUP, Ìbàdàn.
Fagunwa, D.O. (1938), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀, C.M.S. Nigeria Bookshops, Lagos (Later, by Thomas Nelson and Sons, London 1950).
Fagunwa, (1949), Igbó Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1949), Ìrèké Oníbùdó, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1594), Ìrìnkèrìndò Nínú Igbó Elégbèje, Thoams Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1961), Àdììtú Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Faleti, A. (1969), Ọmọ Olókùn Ẹṣin, U.LP., Port Harcourt.
Fatanmi, D.A. (1967), Kórímálẹ Nínú Igbó Àdìmúlà, Thomas Nelson and Sons, London.
Ilara, Tunde (1977), Ẹ̀san Á Ké, Ladson International, Ilé-Ifẹ̀.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ó Le Kú, OUP, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ìgbà Èwe, UPL, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ogún Ọmọdé, UPL, Ìbàdàn.
Jẹbọda, Fẹ́mi (1964), Olówólaiyemọ, Longman, Lagos.
Ladele, T.A. (1971). Jẹ Ń Lògbà Tèmi, Macmillan, Lagos.
Ladele, T.A. (1978), Ìgbì Ayé Ń Yí, Longman, Lagos.
Ogundele, J.O., (1956), Èjigbẹ̀dẹ́ Lọ́nà Ìsánlú Ọ̀run, Longman, Lagos.
Ogundele, (1956), Ibú Olókun, University of London Press, London.
Ogunniran, L. (1972), Eégún Aláré, Macmillan, Lagos.
Okediji, O. (1969). Àjà Ló Lẹrù, Longman, Lagos.
Okediji, O. (1971), Àgbàlagbà Akàn, Longman, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1969), Kékeré Ẹkùn, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1973), Àyànmọ́, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1978), Baba Rere, Macmillan, Lagos.
Owólabí, O. (1974), Orí Adé Kì í Sunta, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1947), Aiye Ree, Gaskiya Corporation, Zaria.
Oyedele, A. (1970), Ìwọ Ni, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1970), Kini Mo Ṣe? Macmillan, Lagos.
Ọdunjọ, J.F. (1964), Kúyẹ̀, AUP, Lagos.
Ọdunjọ, JLF. (1964), Ọmọ Òkú Ọ̀run, AUP, Lagos.
Ọdunjọ J.F. àti Ọladipupọ, A.B. (1967), Kádàrá àti Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Ọmọyajowo, J.A. (1957), Ìtàn Ọdẹ́níyà, Adégbàmí and Sons Press, Agbor.
Ọmọyajowo, J.A. (1961), Báyọ̀ Ajọ́mọgbé, Longman, Lagos.
Ṣobande, O.A. (1959), Rìgímọ̀ Obìnrin Kò e é Tú, Tìkà Toore Press, Lagos.
Yemitan, O. (1972), Gbọ́baníyì, O.U.P., Ìbàdàn.
Yemitan, O. (1980), Orúkọ Ló Yàtọ̀, UPL., Ìbàdàn.

Ìwé Àpilẹ̀kọ àti Ìwé Àtẹ̀jáde
Bamgboṣe, Ayọ̀ (1974), The Novels of D.O. Fagunwa, Ethiope Publishing Corporation, Benin City, Nigeria.
Barber, Karin (1979), “Sociology of Written Literature: Fagunwa and Okediji”, A Semianr Paper delviered at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the March 9th, 1979.
Benjamin, Walter (1977), “Understanding Brecht”, New Left Books, London.
Bennet Tpny (1977), New Accents, Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
Boa, E. and J.H. Reaid (1972), Critical Strategies, Edward Arnold Publishers Ltd., London.
Cabral, Amilcar (1969). Revolution in Guinea, Stage One, London.
Coker, Cheyney Syl (1973), Concerto for Exile, Heinemann, London.
Dada, P.O. (1980), “Marxist Criticism and African Literature”, Ganga, Vol. 2, No. 4.
Dathorne, O.R. (1965), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulletin of the Association for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
Eagleton, Terry (1977), Marxims and Literary Criticism, Methuen and Co. Ltd., London.
Echeruo, Michael J.C. (1967), “Robinson Crusoe, Purchase his Pilgrim and his Novel”, English Studies in Africa, Vol. 10, No. 2.
Goldman, Lucien (1975), “Dialectical Materialism and Literary History”, Toward a Sociology of The Novel, London, Tavistock.
Gutkind, Peter C.W. (1975), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Devleoping-Area, McGill University.
Horner, George R. (1971), “Folklore as a Psycholgocial Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
Ibitokun, Benedict M. (n.d.), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar Paper Delviered at the Department of African Languages and Literarues, University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Irele, Abiola (1977), “Study African Literature”. Nigerian Journal of Humanities, Vol. 1,. No. 1.
Ìṣọ̀lá, A. (1979), “Presenting Revolution in Ọmọ Olókùn Ẹsin”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Univeristy of Ifẹ, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria on 26th February, 1979.
Jackson, I.F. (1956), Advance in Africa, OUP, London.
Johnson, Rev. Samuel (1921), The History of the Yorubas, (ed.) Johnson, O., CMS Bookshop, Lagos.
Lowenthal, Leo (1957), Literature and the Image of Man, Boston, Mass.
Lukacs, George (1963), The Meaning of Contemporary Realism, Merlin Press, London.
My, Walter Norman (1965), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
Nazareth, Peter (1967), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol. 26(iv), Feb./March 1967.
Nkrumah, Kwame (1970), Class Struggle in Africa, International Publishers, New York.
Ogundipe-Leslie, Ọmọlara (1981), “A Marxist Reading of The  Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature-in-English and Department of Philosophy Joint Seminar, Unviersity of Ibadan, Nigeria on March 25th, 1981.
Ogungbẹsan, Kọ́lá (1971), “Literature and Society in West Africa”, African Quarterly, xi, 3.
Okediji, F.O. and Ọla Ọpẹyẹmi (1967), “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, Vol 4, No. 1.
Okonjo, Kamene (1976, “Igbo Women and Community Poltiics”, in Women in Africa (eds) Hafkin, N.J. and E.G. Bay, Stanford University Press, Stanford.
Oyesọsin, Ọba O.O. (1977), “Ipa àti Ipò tí àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé tijọ́ àti lóde ní”, Yorùbá Gbòde, Vol. 3, No. 4.
Seymour, Hlary (1983), Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood”, A Seminar Paper Presented at the Deparment of Literature-in-English, Univeristy of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
Shuking, L. (1944), The Sociology of Literary Taste, London.
Tressel, Robert (1965), The Ragged Trousered Philanthropists, with an introduction by Silitoe, Allan, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
Yai, O.B. (1977), “Ideas for a poltiical Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at the Orisha traditon, held at the University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Zhdnov, Vladimir (1956), “Some Recent Soviet Studies in Literature”, Soviet Literature, No. 8, Moscow.

No comments:

Post a Comment