Wednesday, 10 June 2015

Ipò Àwọn Ọ̀mọ̀wé nínú Ìtàn Àròsọ Yorùbá




Ohun tí ó kọ́kọ́ máa ń jẹ́ kàyéfi fún ẹni tí ó bá fẹ́ yẹ ipò Ọ̀mọ̀wé wò nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá ni àwọn gan-an tí a lè pè ní Ọmọ̀wé. ìyẹn ni pé ìbéèrè tí ó máa ń kọ́kọ́ wá sí ènìyàn lọ́kàn ni pé àwọn wo ni Ọ̀mọ̀wé? Ìbéèrè yìí ṣòròo dáhùn ṣùgbọ́n ohun tí a ó ṣe ni pé kí á yẹ oríkì tí ẹnì kan fún Ọ̀mọ̀wé wò. Ẹni náà ni Gutkind (1975: 22)13, ó ní:
the Ọmọwe (the educated and wise)... are treated as honourable and fair people whether they are poor or not. The Ọmọwe may be part of the mẹkunnu but in almost every respect are ‘above’ the ordinary people. Many of the latter treat the Ọmọwe as keepers of the human consicience, of what is good and eternally valuable. To be an Ọmọwe one must not necessarily have received a higher education. There are illiterate been honourable, who help others, who give carefully reasoned and helpful advice. Ọmọwe do not oppress or exploit others, they want all people to succeed. The socials status of the Ọmọwe is not associated with cars, large houses, big parties, or well dressed women and children – a set of features associated with the Olówo.

Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo oríkì tí Gutkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé yìí ni àwa fi ara mọ́, síbẹ̀, a lè sọ pé ó gbìyànjú. Fún àpẹẹrẹ àwa ò fi ara mọ́ ibi tí ó ti sọ pé Ọ̀mọ̀wé máa ń fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.
A sọ èyí nítorí òwe Yorùbá tí ó sọ pé kò sí ẹni tí ó fẹ́ kí á dà bí òun, àfi adẹ́tẹ̀. Èyí tí àwa kò tún fi ara mọ́ ni ibi tí ó tún ti mẹ́nu ba pé a kì í fi ojú òǹle mọ́tò wo Ọ̀mọ̀wé. Lóòótọ́, a gbà pé kì í ṣe gbogbo Ọ̀mọ̀wé ni ó ń lo mọ́tò ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó ń lo mọ́tò ní ayé òde òní. Yàtọ̀ sí àkíyèsí méjì tí a tọ́ka sí ní òkè yìí, ó fẹ́rẹ̀ dà bí ìgbà pé gbogbo oríkì yòókù tí Gutkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé ni a fi ara mọ́ nítorí pé ó da bí ìgbà pé ó ṣe àkíyèsí àwọn Ọ̀mọ̀wé ayé àtijọ́ àti ti òde òní nígbà tí ó ń ṣe oríkì yìí. Ohun tí a ń sọ ni pé a lè fi oríkì tí Gutkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé yìí ṣe ọ̀pá ìdiwọ̀n ohun tí Ọ̀mọ̀wé jẹ́ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ wa.
Tí a bá wá gba oríkì tí Gutkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé yìí wọlé, a jẹ́ pé yóò nira fún wa láti gba pẹ̀lú àwọn lámèyítọ́ ìtàn àròsọ Yorùbá kan tí wọn pe àwọn olú-ẹ̀dá-ìtàn kan ní ‘ordinary people’. Àwọn lámèyítọ́ yìí ni Ìṣọ̀lá (1976: 495)14 àti Barber (1973: 37)15. Nígbà tí Ìṣọ̀lá (1976) ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa pé àwọn tí ó pè ní ‘ordinary people’ ni Òkédìjí kọ ìwé rẹ̀ fún, ó ní:
Okediji’s criminals are ordinary people... the hero, Lapade, is part of the ordianry people. He lives among them, operates among them... His tastes in food are simple and his clothes ordinary.

Barber (1973) náà tún kín in lẹ́yìn nípa sísọ pé:
                        (Lapade) has no pretensions to the life of an alákọ̀wé
Lóòótọ́, a gbà pé àwọn tí a lè pè ní ‘ordinary people’ ni àwọn ọ̀daràn àti àwọn tí Lápàdé ń ràn lọ́wọ́ ṣùgbọ́n ojú yòówù tí a lè fi wò ó, a ò lè ka Lápàdé kun àwọn tí a lè pè ní ‘ordinary people’. A ó ṣe àkíyèsí pé tí a bá ní kí fi ojú oríkì Guitkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé wo Lápàdé, a ó rí i pé ara àwọn Ọ̀mọ̀wé ni a ó kà á mọ́. Gẹ́gẹ́ bí oríkì tí Gutkind (1975) fún Ọ̀mọ̀wé yìí, Lápàdé fẹ́ràn ọmọnìkejì, kò yan ẹnì kankan jẹ, tẹrútọmọ ló fẹ́ràn rẹ̀, ìdí kí ó lè dára ló wà, ó sì mọ ìwé dé àyè kan nítorí wọ́n fi yé wa pé ó ń ka ìwé ìròyìn. Pẹ̀lú èyí, a lè ka Lápàdé kún àwọn tí Gutkind (1975) sọ nípa wọn pé:
In almost all respect, they are ‘above’ the ordinary people.
Ọ̀rọ̀ ẹni ti Òkédìjí kọ ìwé rẹ̀ fún kọ́ ni ó jẹ wá lógún níyìín. Ohun tí ó fa atótónu tí a ti ń ṣe láti òní ni láti fi oríkì tí a lè fún Ọ̀mọ̀wé lélẹ̀. Lójú ti wa, àwọn tí a lè pè ní ‘ordianry people’ ni àwọn tálákà tí Gutkind (1975: 12) tún sọ nípa wọn pé:
the talaka... are ... characterized ... as those who push carts and “carry loads on their heads” ... The talaka come closest to what can be called the dispossessed.

Tí a bá gba oríkì yìí, a jẹ́ pé irú àwọn Salami Kemberu ni a lè gbà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí àwọn lameyitọ tí a mẹ́nu bà lókè yìí ń pè ní ordinary people’ tí àwa túmọ̀ sí tálákà. Nígbà tí ọwọ́ Lápàdé ba Sàlámì yìí tí ó sì sọ ìdí tí ó fi ń jalè, ó sọ pé:
Mo rìn rìn rìn, mo pààrà pààrà, mo rin gbogbo ilẹ̀ yí, ng ko ri ẹni gba mi ṣíṣẹ́ kankan. Ẹ beere lọ́wọ́ àwọn kọ̀ráà ní Gbági. Ẹ lọ bèèrè ní Sekiteria lórítamẹ́fà. (Àjà Ló Lẹrù Pg. 51)
Irú àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí ó wáṣẹ́ tí kò rí iṣẹ́ yìí ni àwa lè ka kún ‘ordinary people’ tí àwa túmọ̀ sí tálákà. kéré tán, a ó ka irú Lápàdé yẹn kún ara àwọn kòlà-kòṣagbe. Tí ìwé Òkédìjí bá fẹ́ tẹ̀lẹ́ ohun tí Barber (1979: 37)16 sọ wí pé:
His two novels show a profound sympathy with the ordinary people who hae not made it into the elite.

ń ṣe ni ó yẹ kí ó wá ọ̀nà tí irú àwọn Sàlámì yìí yóò fi rí iṣẹ́ ṣe tí ọ̀rọ̀ à-ń-ja-olè kò fi ní í jẹ wọ́n lógún. A sì ti rí àpẹẹrẹ irú ẹni tí ó kọ irú ìwé báyìí. Àpẹẹrẹ irú ìwé báyìí ni ti Treassel (1965)17 tí Nazareth (1967: 35)18 sọ nípa rẹ̀ pé:
(He) designed to show the conditions resulting from poverty and unemployment to expose the futility of the measures taken to deal with them and to indicate what (He) beleives to be the only real remedy, namely socialism ... he presents ... a faithful picture of working class life... more especially of those engaged in the Building trades... we see and feel for ourselves the injustice, oppression, inhumanity, brutality and degradation suffered by those people.... Tressell is angry – he is angry ... with the employers .... who inflicts injustice on their workers out of self interest ... people always take great care of their horses. If they were to work their horses to death, they would have to buy another, if they work a man to death, they can get another for nothing at the corner.

Ohun tí a kàn ń fi gbogbo ohun tí a ń sọ láti òní ṣe àlàyé ni pé ògo àwọn Ọ̀mọ̀wé ni Òkédìjí ń fi Lápàdé gbé ga nínú àwọn ìwé rẹ̀ méjèèjì. Báyìí náà ni Akínlàdé ṣe lo Akin Olúṣínà náà nínú àwọn ìwé ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tirẹ̀. Lóòótọ́, àwọn ènìyàn máa ń ṣe àpèjúwe Olúṣínà gẹ́gẹ́ bí:
ọkùnrin onitubomu to (máa ń) di tayi mọrun pọn-pọn-pọn
síbẹ̀, lójú ti wa, kò sí ìyàtọ̀ kan dan-in dan-in láàrin òun àti Lápàdé. Ipò Ọ̀mọ̀wé kan náà ni a lè kà wọ́n sí. Ohun tí ó kàn ń ṣẹlẹ̀ kò ju ohun tí Mercier (1966: 379)19 ṣe àkíyèsí wí pé:
... between the elites themselves the relationship fluctuates
ìyẹn ni pé ẹni tí ó bá ka Lápàdé àti Olúṣínà sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gba kò jayò pa.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ohun tí a kàn ti ń gbìyànjú láti ṣe ni láti fi ìdí àwọn tí a lè pè ní Ọ̀mọ̀wé lélẹ̀ kí á sì sọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin wọn àti ohun tí àwọn kan pè ní “ordinary people” tí àwa túmọ̀ sí tálákà èyí tí a kò ka àwọn Ọ̀mọ̀wé mọ́ ní ti wa.
Lẹ́yìn ìgbà tí a ti mọ àwọn tí a lè pè ní Ọ̀mọ̀wé yìí, a lè wá bèèrè pé irú ìhà wo ni àwọn òǹkọ̀wé wa kọ sí àwọn Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn? Ṣé tí a bá wo àwọn tí ó ń kọ ìtàn àròsọ ní èdè míiràn, ohun tí a ó ṣe àkíyèsí ni pé bákan méjì ní èrò wọn nípa Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn. Wọ́n lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé jẹ wọ́n lógún. Bó wù wọ́n, wọ́n lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ bí àwọn Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn yóò ṣe gbé e kalẹ̀, bó sì wù wọ́n, wọ́n lè máà ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá wo The Interpreter, ìwé tí Ṣóyínká kọ lórí àwọn Ọ̀mọ̀wé gan-an, ibi tí ó ti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ó ń lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn Ọ̀mọ̀wé yóò ṣe sọ ọ́ kò pọ̀ rárá. Àkíyèsí èyí ni Ogundipẹ-Lesilie (1981: 3)20 ṣe lẹ́yìn ìgbà tí ó ti yẹ ìwé náà wò tí ó fi sọ pé
hold an intellectual discussion of important issues and this they do in a rather disjointed and distracted manner... It may be argued that four times is not inconsiderable in a novel whose time-span is so brief but this is a novel about intellectuals.

Ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ń kọ ìtàn àròsọ Yorùbá kò rí báyìí. Ó dàbí ìgbà pé ìtàn àròsọ wọn tí kò dá lórí Ọ̀mọ̀wé pàápàá, yàtọ̀ sí ti pé wọn yóò gbé ìrírí wọn hàn wá gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn yóò ṣe gbé e hàn wá, ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé ni ó máa ń jẹ wọ́n lógún. Nǹkan tí èyí ń fi hàn ni pé ìhà tí àwọn òǹkọ̀wé ìtàn àròsọ Yorùbá kọ sí àwọn Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n kọ sí ipò ọba. Ṣé ní ti ọba, a lè rí àwọn òǹkọ̀wé kan tí ó jẹ́ pé ipò tí àwọn ọba yìí wa ní ayé àtijọ́ sì ń wù wọ́n, wọ́n ń fẹ́ kí ayé padà sí ibi àárọ̀. Àwọn míràn sì wà tí ó jẹ́ pé wọ́n ń fẹ́ kí àyípadà dé bá àwọn ọba yìí. Lójú àwọn òǹkọ̀wé tí ó ní irú èrò yìí, bí a ṣe bí ẹrú ni a bí ọmọ. Nípa ti ọ̀rọ̀ ipò ọba yìí kan náà, àwọn òǹkọ̀wé kan wà tí a kò mọ ibi tí ó yẹ kí á to wọ́n sí. A sì ti sọ ohun tí a rò pé ó fà á tí àwọn ohun tí a ṣe àkíyèsí yìí ṣe rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n tí a bá wo ipò Ọ̀mọ̀wé nínú àwọn ìtàn tí ó ń kọ ìtàn àròsọ wa, ọ̀kan náà ni wọ́n. Ìyẹn ni pé omi ẹ̀kọ, ẹ̀kọ ni. Bóyá èyí ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé ń ṣe ni gbogbo àwọn òǹkọ̀wé wa sùn tí wọ́n kọ orí sí ibi kan náà nípa ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé. Ṣé àkéké tó kégi nígbó ni ọ̀rọ̀ yìí, orí ara rẹ̀ ni ó ń ké. Mo rò pé èyí ní ó fà á tí àwọn òǹkọ̀wé wa kò fi ń fẹ́ sọ̀rọ̀ òdì púpọ̀ sí àwọn Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn.
Yàtọ̀ sí ti pé ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà kan náà ni òǹkọ̀wé àti Ọ̀mọ̀wé yìí jọ wà, a ó tún ṣe àkíyèsí pé àwọn Ọ̀mọ̀wé yìí gan-an ni àwọn òǹkọ̀wé ní lọ́kàn nígbà ti wọ́n ń kọ ìwé wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó jẹ́ pé eléyìí kì í ṣe ìfẹ́ inú wọn. Àwọn tí ó máa ń bá wọn tẹ ìwé wọn jáde ló máa ń fà á ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ṣé a mọ̀ pé nítorí kí wọn lè jèrè ni àwọn òǹtẹ̀wé ṣe ń tẹ ìwé jáde. Ohun tí ó sì máa ń jáde ni ẹnu àwọn òǹtẹ̀wé  yìí ni pé ṣe wọn yóò ra a? Nítorí ìdí èyí, àwọn ìwé tí Ọ̀mọ̀wé àárín wa yóò rà ni wọ́n máa ń fẹ́ tẹ̀ jáde. Tí a bá sì fi ìwé pẹ̀gàn ènìyàn, bóyá ni yóò ṣe rà á.
rí ìwé Fágúnwà ni a ó ti bẹ̀rẹ̀ sí níí yẹ ohun tí àwọn òǹkọ̀wé sọ nípa àwọn Ọ̀mọ̀wé wò. Nígbà tí Fágúnwà ń kọ̀wé rẹ̀, àwọn Ọ̀mọ̀wé ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde ni. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ pé wọn ò pọ̀, ọwọ́ wọn ni gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní ìgbà náà gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, akọ̀wé kóòtù, lééridà àti àwọn irú iṣẹ́ báwọ̀nyí máa ń bọ́ sí. Irú àwọn Fágùnwà yìí ni ó fi ara wọn sí ipò agbẹnusọ fún àwọn ènìyàn wọn. Fágúnwà ní tirẹ̀ tilẹ̀ sá sọ ọ́ di iṣẹ́ gidi gan-an ni. Tí a bá wo àdúrà tí ó ṣe ní ìparí Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irunmalẹ̀ tí ó fi sọ pé
Orilẹ ede yin yio tubọ ma pọ si ni ọgbọn ati ni agbara, awa enia dudu ko ni ire ẹhin mọ lailai. (Pg. 95).
a ó rí i pé àdúrà yìí wá láti ẹnu ẹni tí ó gbà pé orílẹ̀ èdè yìí kò gbọ́n tẹ́lẹ̀ àti pé ni ẹ̀yìn ni orílẹ̀ èdè yìí wa. Ohun tí ó yẹ kí á bí ara wa ni pé kí ni Fágúnwà fi ṣe ọ̀pá ìdiwọ̀n wí pé orílẹ̀ èdè yìí kò gbọ́n àti pé ó wà ní ẹ̀yìn? Ohun tí ó fi ṣe ọ̀pá ìdiwọ̀n kò ju àṣà àwọn ará òkè òkun lọ. Ìyẹn ni pé ni ojú Fágúnwà, ọ̀nà kan tí orílẹ̀ èdè yìí fi lè máa ga sí i ni nípa kíka ìwé èyí tí òùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti ṣe. Bẹ́ẹ̀, ohun tí Yorùbá máa ń sọ ni pé ìwé kò kan ọgbọ́n. Èyí tilẹ̀ fi hàn pé Yáì (1977: 6)21 ṣe àkíyèsí Fágùnwà gan-an ni kí ó tó sọ pé lóòótọ́, ìdílé mẹ̀kúnnù ni Fágúnwà ti wá ṣùgbọ́n ohun tí ó ń gbìyànjú láti ṣe ni pé kí ó fi ipò yìí sílẹ̀ kí ó sì da ara pọ̀ mọ́ àwọn tí a lè pè ní Ọ̀mọ̀wé, àwọn tí ó jẹ́ pé àwọn ni a ń fi ojú iyì àti ẹ̀yẹ wò ní ayé àtijọ́. Yáì (1977: 6)
his “source class” so to speak is the Yoruba poor peasantry, his “target class” was undoubtedly the urban petty bourgeoisie

Ọ̀nà kan tí Fágúnwà sì fi lè ṣe èyí ni pé kí ó ka ìwé nítorí lójú tirẹ̀ bí wọn kò bá ní ọlá ní òní,
Oni, nwọn mbọ wa ni lọla
Abájọ tí Fágùnwà fi sọ ọ̀kan nínú àwọn òbí olú-ẹ̀dá-ìtàn rẹ̀ kan ní Akọ̀wédìran. Mo rò pé èyí kan náà ni Yáì (1977: 10)22 rí tí ó ṣe pé olú-ẹ̀dá-ìtàn yìí ní
... conformist, reactionary and egoist who is completely deaf to the problem of the Nigerian masses

Tí a bá tilẹ̀ fi ojú inú wo ìwé Fágúnwà, a ó rí i pé bí ẹni ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́ gan-an ni ó ka iṣẹ́ tí ó ń ṣe sí. Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fi ẹ̀sìn àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì han àwọn tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dára pọ̀ mọ́ àwọn Ọ̀mọ̀wé. Kò dà bí ìgbà pé gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ wa jẹ ẹ́ lógún rárá. Fún àpẹẹrẹ, nínú Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmalẹ̀, nígbà tí àwọn ọdẹ ń lọ sí Òkè Láńgbòdó tí wọ́n kọjá Igbó Irúnmalẹ̀ tán, ohun abàmì kan ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ṣe ni wọ́n dédé rí i tí igbó bẹ̀rẹ̀ sí níí yí wọn po tí wọn kò sì rí ojú ọ̀nà mọ́. Wọn kò lè yá sí ọ̀tún bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè yà sí òsì. Iwájú ò ṣeé lọ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yìn ò ṣeé padà sí. Wọ́n tilẹ̀ ní igbó náà dí débi tí ó fi jẹ́ pé èkúté pàápàá kò lè rí ibi gbà kọjá. Ó ṣe ni ẹyẹ kan sọ pé àfi tí wọ́n bá pa oùn tí wọ́n sì fi òun rúbọ ni inú Ọlọ́run yóò fi lè dùn sí wọn. Wọ́n pa ẹyẹ yìí lóòótọ́, wọ́n sì fi i rúbọ. Fágúnwà ní
Gẹ́gẹ́ bí àṣà ilẹ wa, a mu ẹiyẹ yi a la inu rẹ̀ a bu epo si i a si gbe e sinu apadi kekere kan bayi a gbe e lọ si idi igi nla kan ti mbẹ lẹba ọdọ wa. Inu Ọlọrun dun pe a ronupiwada – ki ise nitori ẹbọọ ti a ru – ṣugbọn nitori o mọ̀ pe ibaṣepe a ni oye jubẹ lọ ni, a ba sin on ni ọna ti o dara ju eyini lọ
A ó ṣe àkíyèsí pé bí àwọn ènìyàn yìí ṣe sin Ọlọ́run ni ọ̀nà ìbílẹ̀ wa yìí kò tẹ́ Fágúnwà lọ́rùn rárá. Àwọn tí ó lóye lójú tirẹ̀ ni àwọn Ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ń sin Ọlọ́run ní ìlànà tí àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì.
Ọ̀rọ̀ ti pé a ń gbé ọ̀rọ̀ eẹni tí ó mọ̀wé lárugẹ yìí tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ máà jẹ́ kí á lè gba ìtàn Fágúnwà gbọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ní inú Igbó Olódùmarè, ohùn ẹni tí ó ń sọ ìtàn yìí fún wa ni a kọ́kọ́ gbọ́ tí ẹnì kan pè pé kí ó wá máa kọ ìtàn kan sílẹ̀. Ìtàn tí wọ́n ń kọ sílẹ̀ yìí kì í ṣe ti ẹni tí ó ń sọ ọ́, ti baba rẹ̀ ni. Nígbà tí ó ṣe, kò kúkú sọ ìtàn yìí mọ́, ń ṣe ni ó bẹ̀rẹ̀ sí níí kà á níbi tí baba rẹ̀ kọ ọ́ sí. Èyí fi hàn pé ẹni tí ó ń sọ ìtàn yìí mọ ìwé. Bẹ́ẹ̀ rè é, ọdẹ sì ni. Ohun tí a rí ṣe ní àlàyé ni pé ó ní láti ti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọdẹ. Kàyééfì gbáà ni eléyìí. Tí a bá fi ojú inú wo àsìkò tí Fágúnwà ń kọ ìwé rẹ̀, a ó rí i pé yàtọ̀ sí ti pé ọdẹ kò lè mọ-ìwé-kọ-mọ̀-ọ́n-kà, kò ṣeé ṣe kí baba ẹni tí ó jẹ́ ọdẹ yìí tún mọ ìwé kọ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Fágúnwà kò ro èyí jinlẹ̀ nígbà tí ó ń kọ ìwé rẹ̀ nítorí ohun tí ó jẹ ẹ́ lógún, ìyẹn ìgbéga àwọn Ọ̀mọ̀wé. Ní òde òní pàápàá tí àwọn Ọ̀mọ̀wé kò rí iṣẹ́ ṣe tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ mọ́ yìí, a ò tí ì rí Ọ̀mọ̀wé tí ó finúfẹ̀dọ̀ sọ pé iṣẹ́ ọdẹ ni ó wu òun.
Tí a bá tilẹ̀ wo ohun tí Barber (1979: 25)23 pè ní àléébù nínú ìwé Fágúnwà, a ó rí i pé ọ̀nà àtigbé ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé lárugẹ ni ó fa àléébù yìí. Barber (1979) ní a kì í mọ ohùn ẹnì kan yàtọ̀ sí ti èkejì. Irú gbólóhùn kan náà ni Fágúnwà máa ń lò léra léra. Ibáà ṣe pé ó ń wàásù ni tàbí pé ó ń sọ ọ̀rọ̀ ìjà. Bí àgbàlagbà ń sọ̀rọ̀, bákan náà ni yóò rí sí ti ọmọdé. Bí ó ṣe òǹkọ̀wé pàápàá ni ó ń ṣe àyàbá tí ó ń dá sí ohun tí àwọn ẹ̀dá-ìtàn ń sọ, a kì í ṣe àkìyèsí ìyàtọ̀ kankan. Ní ìparí, Barber (1979) ní ẹnikẹ́ni yòówù tí ó ń sọ̀rọ̀, ibikíbi yòówù tí ó ti ń sọ ọ́, bí ẹni ń gba ohùn Fágúnwà sọ ni ó máa ń rí.
A gbà pẹ̀lú gbogbo ohun tí Barber (1979) ṣe àlàyé yìí ṣùgbọ́n kò fi ìdí tí Fágúnwà ṣe ṣe èyí yé wa. Ohun tí ó fà á tí Fágúnwà fi ṣe èyí ni pé ó fẹ́ kọ ìwé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe tọ́ kí Ọ̀mọ̀wé kọ ọ́ sílẹ̀. Ó fẹ́ kọ ọ́ ni ọ̀nà tí ó tọ̀nà fún kíkọsílẹ̀ èdè Yorùbá. Ohun tí ó fà á gan-an nì yí tí kò fi fẹ́ kí èdè tí ẹnì kan bá sọ nínú ìwé òun yàtọ̀ í ti ẹlòmíràn. Tí ó bá ṣe èyí, lójú tirẹ̀, àgbékalẹ̀ rẹ̀ kò ní í bá èyí tí àwọn Ọ̀mọ̀wé mu.
Tí a bá tilẹ̀ kúrò lórí ìwé Fágúnwà tí a yẹ àwọn ìwé tí a kọ jáde láìpẹ́ wò, lékèe wí pé Yáì (1977: 7) sọ pé
Nowadays, people attach more importance to being an alhaji,  a major, (a businessman) than to being a professor

Ìyẹn ni pé àwọn alhaji, àwọn ológun àti àwọn oníṣòwò ni ó gbajúmọ̀ jù ní àwùjọ wa lónìí tí ó sì jẹ́ pé àwọn Ọ̀mọ̀wé kò rí ipò kan tí ó dára kó, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ó n kọ ìtàn àròsọ wa ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa à ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ni ó jẹ wọ́n lógún. Kì í ṣe pé a sọ pé ohun tí wọ́n ṣe yìí kò dára, ṣùgbọ́n ohun tí a ṣe àkíyèsí ni pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ yìí ni ó jẹ́ pé awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ báyìí ni wọ́n fi bojú ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ tí ó jẹ́ pé ìgbésí ayé wọn gan-an ni wọ́n kọ sí ìta fún wa kà. Tí a bá wo Kékeré Ẹkùn àti Àyànmọ́, díẹ̀ ni gbogbo ohun tí a mẹ́nu bà nínú ìwé méjèèjì yìí fi yàtọ̀ sí ìgbésí ayé Ọlábímtán fúnra rẹ̀. Bákan náà ni ó ṣe jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Akínwùmí Ìṣọ̀lá ní Yunifásítì Ìbàdàn ni ó kún inú Ó Le Kú tẹ́tẹ́.
Ní ìgbà míràn, tí àwọn òǹkọ̀wé yìí kò bá sọ ìtàn ìgbésí ayé wọn, wọn yóò sáà wá ọ̀nà láti fi hàn wá pé ọ̀rọ̀ ìwé kò ṣeé mú yẹpẹrẹ. Nínú Aiyekootọ, ọ̀rọ̀ nípa bí Ọpẹ́yẹmí ṣe lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ni ó fẹ́rẹ̀ gba ìlàjì ìwé ọ̀hún tán. Bí àwọn onígbàgbọ́ ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ àgbà àti bí ìwé kíkà ṣe gbé Déòtí gòkè àgbà ni ohun tí ó kan Ládélé gbọ̀ngbọ̀n nínú Jẹ́ N Logba Temi. A tilẹ̀ fi dandan lé e pé ẹni tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ẹ̀sìn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ àgbà bí Bánkọ́lé ṣe ń kọ́
bi-à-ba, bí-e-bè, bí-ẹ̀bẹ
bí-ì-bi ... bí-ọ̀-bọ (Jẹ N Logba Temi, Pg. 16).
Kí á tilẹ̀ ní a kúrò lórí àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n ti sọ ìwé wọn di agbátẹrù bí a ṣe ń kọ́ ọmọ ní ìwé, ọ̀pọ̀ nínú ìwé tí wọ́n ṣe bí ẹni pé àwọn kò polongo ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ pàápàá, ohun tí wọn mẹ́nu bà nípa Ọ̀mọ̀wé kúrò ní díẹ̀. Ohun tí a ṣe àkíyèsí pé ó pọ̀ jù nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ yìí ni pé àwọn tí ó kọ wọ́n gbà pé nǹkan Gẹ̀ẹ́sì sunwọ̀n ju ti wa lọ. Àwọn nǹkan Gẹ̀ẹ́sì yìí ni wọ́n fi ṣe àwòrán ojú inú tí ó dúró fún Ọ̀mọ̀wé, ìyẹn ni pé a lè pe àwọn nǹkan Gẹ̀ẹ́sì tí a mẹ́nu bà yìí ní àwọn ohun tí wọ́n fi pàrokò fún Ọ̀mọ̀wé. Nínú ìwé Délànọ̀, àwọn onígbàgbọ́ ni ó jẹ́ kí ó dúró fún àwọn nǹkan Gẹ̀ẹ́sì yìí, ó ní
Gbogbo obi igbana a ma ṣofu ọmọ pupọ nitori iwa ope àti aigbọn... Tani jẹ ko iyan onigbagbọ kere ... eto iwosan àti ilera wa ni sakani wọn. bi wọn ti kere to ọga ni nwọn jẹ fun awọn keferi ti nwọn jijọ nbe ladugbo (Aiye Daiye Oyinbo, Pg. 61)
A ó ṣe àkíyèsí nínú àyọlò òkè yìí wí pé kì í ṣe pé wọ́n ka ẹ̀sìn àjèjì yìí sí nìkan ni, wọ́n tún fẹnu tẹ́ńbẹ́lú èyí tí ó jẹ́ ti wa. Èyí tí Délànọ̀ ìbá fi pè é ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀, kèfèrí ni ó pè é. Lójú Délànọ̀, kò sí ìdí méjì tí àwọn òbí yìí fi ń ṣòfu ọmọ bí kò ṣe ti pé wọn kò kọ́ ẹ̀kọ́ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì yìí gbé dé lọ.
Ọ̀rọ̀ àìní ìfẹ́ ohun ìbílẹ̀ wa kan náà ni a ṣe àkíyèsí nínú Kékeré Ẹkùn. Ọlábímtán gbìyànjú láti rí i pé àṣà Òyìnbó borí ti Yorùbá. Bí a ṣe yí Bádéjọ padà sí ìgbàgbọ́ jẹ́ kàyééfì gbáà. Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀jẹ̀ kò tilẹ̀ janpata. Ó tilẹ̀ ṣe wá jẹ́ pé àlùfáà gan-an ni ó wá ṣe kòńgẹ́ igi tí a jù lu Àlàbí? A ó tún ṣe àkíyèsí pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Bádéjọ náà ló ṣẹlẹ̀ sí Bánkọ́lé nínú Jẹ́ N Logba Temi. Yàtọ̀ sí èyí, a ó tún ṣe àkíyèsí pé ọṣẹ́ tí egbòogi ìbílẹ̀ ṣe fún ọmọ kan ló jẹ́ kí Àlàbí fẹ́ kọ́ iṣẹ́ ìṣègùn nínú Àyànmọ́ nítorí oníṣègùn òyìnbó ló gba ọmọ tí àìsàn yìí ń ṣe là. Ǹjẹ́ a lè wá torí èyí gba ohun tí Lamming (1973: 61)25 sọ gbọ́ pé “the colonial system taught us much more about the mother country than about ourselves”. Ìyẹn ni pé ìjẹgàba lẹ́ni lórí tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì jẹ gàba lé wa lórí, ń ṣe ni wọ́n fi ń kọ́ wa ní ohun tí ó jẹ mọ́ ilẹ̀ wọn tí wọ́n sì ń tẹ ti ilẹ̀ wa rì. Lójú ti wa, a rò pé a lè gbà pẹ̀lú rẹ̀ mọ̀nà. A sáà rí i tí àìmọ̀wé Ọláńrewájú ń dún ìyá rẹ̀ sùn-ùn-ùn nínú Aiye Dáiye Oyinbo. Bẹ́ẹ̀ a sì mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ohun tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì yìí fi sílẹ̀ fún wa ni ẹ̀kọ́ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà. Ọ̀rọ̀ tí pé ọmọ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà yìí tilẹ̀ ká ìyá Ọláńrewájú tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lára débi tí ó fi sọ pé ìyá jẹ òun. Ó ní ọmọ òun ìbá mọ̀wé ìbá di ènìyàn ńlá lójijì. Ìyẹn ni pé ìwé mímọ̀ nìkan ni ó ń sọ ni di ènìyàn ńlá. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lójú àwọn òǹkọ̀wé wa nì yí. Àìmọ ìwé wá di ohun àbùkù bẹ́ẹ̀ rè é nǹkan kan ni adìyẹ ń jẹ kí àgbàdo tó dé ilé ayé. Àṣà Òyìnbó wọ Bámidélé lẹ́wù tán nínú Gbọ́baníyì débi pé bí ó bá ń jẹun lọ́wọ́ tí àlejò bá dé, kì í pè é wá jẹun, kò tilẹ̀ ní í jẹ́ kí irú ẹni bẹ́ yẹn mọ̀ pé ń ṣe ni òun ń jẹun lọ́wọ́. Lójú Yemitan, àṣà tó dára ni, “ajẹ̀rù ni” irú ẹni tí ó bá bá ni ní orí oúnjẹ tí ó ti ọwọ́ bọ̀ ọ́. Irú ohun tí kì í ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ wa tẹ́lẹ̀ nì yí tí ó jẹ́ pé ṣe la máa ń ro àlejò mọ́ oúnjẹ wa. Jọkẹ́ tilẹ̀ bínú pé àbúrò Àlàbí tí ó wá kí òun kò kọ́ kọ ìwé ṣáájú nínú Àyànmọ́. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí, àwọn òǹkọ̀wé wa kò kọ wọ́n ní ìtẹ́ńbẹ́lu tàbí ní ìbu ẹnu àtẹ́ lù, ń ṣe ni wọ́n ń kọ wọ́n ní ọ̀nà tí yóò fi gbe ògo àwọn Ọ̀mọ̀wé ga.
Ní ayé àtijọ́, nígbà tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gòkè ni Awóníyì tún gbé wa lọ nínú ìwé rẹ̀ Aiyekootọ. Ní ìgbà yẹn, gbogbo iṣẹ́ tí ó bá ti gbajúmọ̀ ni ó máa ń jẹ́ ti àwọn Ọ̀mọ̀wé. Àwọn ni kò-sí-ní-àjọ-àjọ-ò-kún. “Hẹẹ́dì” tí Awóníyì lò bí aṣojú àwọn Ọ̀mọ̀wé níyìín ni
Oníwàásù ijọ, òun kan náà ni atẹduuru... ọga àwọn akọrin... ogbifọ... Bí ọ̀rọ̀ kan ṣe pàtàkì ni abule, lẹhin Baalẹ oun naa ni o kan... omiran tilẹ ro pe Dokita ni gbogbo ẹni tí o bá ti mọ iwe, nitorina bi ọ̀rọ̀ kan ba ti de nipa aisan, o di ọdọ Hẹẹdi (Aiyekootọ, Pg. 28).
Àwọn nìkan ni ó mọ ohun tí ó tọ́ tí ó mọ ohun tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí Fílíbì ṣe fi ọgbọ́n sọ̀rọ̀ sí Baba Bámidélé nínú Gbọ́baníyì nítorí tí ó tutọ́ sí ilẹ̀ ilé lásan. Ó ní
Bí Fílíbì ti jokòó tan, baba Bamidele sana si ikoko, ... o tutọ silẹ... Ara Filibi ṣọgbọn kọ ọ, ó sì rọra ki ọgbọn alakọwe bọ ọ. Baba ẹ jẹ ka bọ si ẹgbẹ ita jokòó ki ẹ le raye maa tutọ. Awọn ọga wa nile-iwe lo maa nsọ fun wa pe ka maa tutọ sinu ile (Gbọ́baníyì, Pg. 20).
Bẹ́ẹ̀ sì rè é, Fílíbì tí ó ń pẹ̀gàn ẹni tí ó ń mu ìkòkò tí ó ń tutọ́ sílẹ̀ yìí ni a fi yé ni pé sìgá mímú ti di bárakú fún ṣùgbọ́n nítorí pé Fílíbì jẹ́ ọ̀mọ̀wé tí òǹkọ̀wé fẹ́ gbé ní arugẹ, kò bu ẹnu àtẹ́ lu sìgá mímu Fílíbì yìí dàbí alára.
A ó ṣe àkíyèsí wí pé tí a bá rí Ọ̀mọ̀wé kan tí ó ń ṣi ìwà hù, àwọn òǹkọ̀wé wa kò ní í fẹ́ kí á fi ojú Ọ̀mọ̀wé lásán wò wọ́n. Wọn yóò ti ọ̀rọ̀ wọn mọ́ nǹkan míràn lọ́rùn. Wọ́n lè sọ wọ́n di olóṣèlú tàbí oníṣòwò pàtàkì. Tí wọ́n bá ti lè sọ wọ́n di irú nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lè wá sọ ohun tí ó bá wù wọ́n nípa wọn. Irú àwọn ẹni tí àwọn òǹkọ̀wé wa ṣe báyìí ṣe ni Délé nínú Gbọ́baníyì àti Dúró nínú Baba Rere. Délé tí kò kọ ibi ara sí ọ̀rọ̀ ìwé ní ìlú òkèèrè dé wá ń du ipò ìlú ṣíṣe. Àìtó owó tí ìbá rí ná láti fi gba iyì gba ẹ̀yẹ ni ó mú Délé gba rìbá. Bákan náà ni Dúró tí a gbé hàn wá gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò bẹ̀rẹ̀ sí máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìbàjẹ́ láti fi lè ní owó lọ́wọ́. Ó n gé ẹfun mọ́ òògùn. Ó ń kó ẹrù fàyàwọ́. Ó tilẹ̀ pa ènìyàn nítorí owó. Àìfi wọ́n sí ipò Ọ̀mọ̀wé ni ó jẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé wa ṣe báyìí gbé wọn hàn wá.
Ni ti wa, a rò pé àwọn òǹkọ̀wé wa kò fi ayé Ọ̀mọ̀wé wa hàn wá tó bí ó ṣe tọ́ àti bí ó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe fún àwọn ọba. Tí a bá wo àwùjọ wa, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, a ó ṣe àkíyèsí pé àwọn oníṣòwò àti àwọn olóṣèlú ni ayé tún wà ní ọwọ́ wọn báyìí. Ó dàbí ìgbà pé àwọn òǹkọ̀wé wa ti tẹnpẹlẹ mọ́ ipa ti Ọ̀mọ̀wé jù. Bẹ́ẹ̀ rè é, Ògungbẹ̀san (1971: 61)26 ti sọ̀rọ̀ tán, ó ní
If literature is relevant at all it is because we obtain some pciture of society and of life from it

Ìyẹn ni pé tí lítíréṣọ̀ yóò bá wúlò rárá, ó yẹ kí á rí àwòrán ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nínú rẹ̀. Àwọn tí ó ń kọ ìtàn àròsọ wa kò ṣe èyí nígbà tí ọ̀rọ̀ kan àwọn Ọ̀mọ̀wé ẹgbẹ́ wọn. Wọn kò bá ayé yí. Bí nǹkan ṣe ń rí ni ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni wọ́n sì ń gbé hàn wá. Lóòótọ́, àwọn oníṣòwò, olóṣèlú àti àwọn ọ̀gá ṣọ́jà ló gbayì láwùjọ wa ṣùgbọ́n àìkọ ìtàn àròsọ jáde àwọn wọ̀nyí kò jẹ́ kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ ara wọn ga kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ fi ọwọ́ ara wọn tún ìwà ara wọn ṣe bíi ti àwọn Ọ̀mọ̀wé. Láìsì kọ ìtàn àròsọ tí a sọ yìí fúnra wọn nípa ara wọn, n kò rò pé àwọn òǹkọ ìtàn àròsọ tí a ní báyìí yoò gba ọ̀rọ̀ wọn wí gẹ́gẹ́ bí Smythe and Smythe (1967: 81)27 ṣe sọ wí pé
the educated Nigerians are usually aloof from the masses
Ìyẹn ni pé ń ṣe ni àwọn Ọ̀mọ̀wé ọmọ Nàìjíríà máa ń ta kété sí ọ̀rọ̀ tí ó bá kan gbogbo ènìyàn. Èyí gan-an ni àwa ro pé ó bá àwọn tí ó ń kọ ìtàn àròsọ Yorùbá mu. Lójú tiwa, ọ̀rọ̀ ara won jẹ wọ́n lógún ju àwọn míràn lọ.

Ìtọ́ka
1.      Ọba O. O. Oyesọsin Keji (1977: 3), “Ipa àti Ipò tí Àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní”, Yorùbá Gbòde, Vol., 3, No. 4.
2.      Benedict M. Ibitokun (n.d.: 1 1), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar paper delivered at the Department of African Languages and Literatures, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
3.      Karin Barber (1979: 22), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fágùnwà and Okèdíji”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ Universiyt, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
4.      Tony Bennett (1979: 115), New Accents: Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
5.      O.B. Yai (1977: 4), “Ideas for a Political Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at Orisha Tradition held at the Unviersity of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
6.      Karin Barber (1979: 4), Op. cit.
7.      Ibid., pg. 22.
8.      Ibid., pg. 5
9.      Op. cit.
10. Op. cit.
11. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (n.d.: 27), “Images of the Ọba in Yorùbá Novels”, a Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
12. Op. cit
13. Peter C.W. Gutkind (1975: 22), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Developing Area Studies, McGill Univeristy.
14. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (1976: 395), “The Detective Novel in Yorùbá”, Department of African Languages and Literatures Seminar Series, No. 1, 1976-77, Part II.
15. Karin Barber (1979: 39), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fagunwa and Okediji”, An unpublished Seminar Paper delivered at Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the 9th April, 1979.
16. Op. cit.
17. Robert Tressel (1965), The Ragged Trouserred Philanthropists, with an introduction by Allan Sillitoe, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
18. Peter Nazareth (1967: 35), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol, 6 (iv), Feb./March 1967.
19. P. Mercier (1966: 379), in P.C. Lloyed (ed.), The New Elites of Tropical Africa, OUP, London.
20. Ọmọlara Ogundipe-Lesilie (1981: 3), “A Marxist Reading of The Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English and Department of Philosophy Joint Seminar, University of Ibadan, Nigeria, 25th March, 1981.
21. O.B. Yai (1977: 10), Op. cit.
22. Ibid.
23. Op. cit.
24. Op. cit.
25. George Lamming (1973: 61), In The Castle of my Skin, quoted from S. Wayak “V.S. Naipaul and the West Indian Situation” Busara, Vol. 5, No. 1, 1973.
26. Kọ́lá Ògúngbẹ̀san (1971: 61), “Literature and Society in West Africa” African Quarterly, xi, 3.
27. Quoted from F.O. Okediji and Opeyemi Ọla (1967: 81) “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, vol. 4, No. 1.
28. Ayọ̀ Bamgboṣe (1974: 61). The Novels of D.O. Fágúnwà, Ethiope Publishing Corporation, Benin City.
29. O.R. Dathorne (1965: 63), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulleting of the Assocaition for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
30. Ibid.
31. Movement for Progressive Nigerians (1978: 23), “Nigerian Women and the Revolution of the Nigerian People” Positive Review, No. 1, 1978.
32. Walter Norman May (1965: 44), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
33. Rev. Samuel Johnson (1921: 201), The History of the Yorubas, (ed.) O. Johnson, C.M.S. Bookshop, Lagos.
34. Walter Benjamin (1977: 34), ‘Understanding Brecht’ New Left Books, London.
35. Op. cit
36. Hilary Seymour (1983: 49), “Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood. A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English, University of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
37. Ibid.
38. Ibid., pg. 20
39. Ibid.
40. Walter Norman May (1965: 26), Op. cit.
41. Ibid.
42. Quoted from Hilary Seymour (1983: 21), Op. cit.
43. Kamene Okonjo (1976: 46), “Igbo Women and Community Politics”, in Women in Africa (eds.) N.J. Hafkin and E.G. Bay. Stanford: Stanford University Press.
44. R. George Horner (1971: 3), “Folklore as a Psychological Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
45. Op. cit.
46. Op. cit.
Àkọ́jo Orúkọ Ìwé
Ìwé Ìtàn Àròsọ
Adeoye, C.L. (1966), Ẹ̀dá Ọmọ Oòduà, Onílé Owó Press, Ìbàdàn (later by OUP, Ibadan, 1971).
Akinlade, K. (1971), Ta Ló Pa Ọmọ Ọba?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1971), Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnṣìkà, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Aṣenibánidárò, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Ta Lolè Ajọ́mọgbé?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, (1974), Alosi Ọlọ́gọ, Longman, Lagos.
Akinlade, (1976), Owó Ẹ̀jẹ̀, Oníbọn-òjé, Ìbàdàn.

Àkọ́jo Orúkọ Ìwé
Ìwé Ìtàn Àròsọ
Adeoye, C.L. (1966), Ẹ̀dá Ọmọ Oòduà, Onílé Owó Press, Ìbàdàn (later by OUP, Ibadan, 1971).
Akinlade, K. (1971), Ta Ló Pa Ọmọ Ọba?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1971), Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnṣìkà, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Aṣenibánidárò, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Ta Lolè Ajọ́mọgbé?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, (1974), Alosi Ọlọ́gọ, Longman, Lagos.
Akinlade, (1976), Owó Ẹ̀jẹ̀, Oníbọn-òjé, Ìbàdàn.
Akinlade, (1976), Àgbákò Nílé Tẹ́tẹ́, Evans, Lagos.
Akintan, E.A. (1931), Ìgbẹ̀hìn Á Dùn, The Anchor.
Awoniyi, T.A. (1973). Ayékòótọ́, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Delanọ, I.O. (1955). Aiye Daiye Oyinbo, Thomas Nelson and Sons, London.
Delanọ, I.O. (1963), Lọ́jọ́ Ọjọ́ Un, Thomas Nelson and Sons, London.
Fadeṣere, P.I. (1978), Ajítòní, OUP, Ìbàdàn.
Fagunwa, D.O. (1938), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀, C.M.S. Nigeria Bookshops, Lagos (Later, by Thomas Nelson and Sons, London 1950).
Fagunwa, (1949), Igbó Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1949), Ìrèké Oníbùdó, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1594), Ìrìnkèrìndò Nínú Igbó Elégbèje, Thoams Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1961), Àdììtú Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Faleti, A. (1969), Ọmọ Olókùn Ẹṣin, U.LP., Port Harcourt.
Fatanmi, D.A. (1967), Kórímálẹ Nínú Igbó Àdìmúlà, Thomas Nelson and Sons, London.
Ilara, Tunde (1977), Ẹ̀san Á Ké, Ladson International, Ilé-Ifẹ̀.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ó Le Kú, OUP, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ìgbà Èwe, UPL, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ogún Ọmọdé, UPL, Ìbàdàn.
Jẹbọda, Fẹ́mi (1964), Olówólaiyemọ, Longman, Lagos.
Ladele, T.A. (1971). Jẹ Ń Lògbà Tèmi, Macmillan, Lagos.
Ladele, T.A. (1978), Ìgbì Ayé Ń Yí, Longman, Lagos.
Ogundele, J.O., (1956), Èjigbẹ̀dẹ́ Lọ́nà Ìsánlú Ọ̀run, Longman, Lagos.
Ogundele, (1956), Ibú Olókun, University of London Press, London.
Ogunniran, L. (1972), Eégún Aláré, Macmillan, Lagos.
Okediji, O. (1969). Àjà Ló Lẹrù, Longman, Lagos.
Okediji, O. (1971), Àgbàlagbà Akàn, Longman, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1969), Kékeré Ẹkùn, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1973), Àyànmọ́, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1978), Baba Rere, Macmillan, Lagos.
Owólabí, O. (1974), Orí Adé Kì í Sunta, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1947), Aiye Ree, Gaskiya Corporation, Zaria.
Oyedele, A. (1970), Ìwọ Ni, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1970), Kini Mo Ṣe? Macmillan, Lagos.
Ọdunjọ, J.F. (1964), Kúyẹ̀, AUP, Lagos.
Ọdunjọ, JLF. (1964), Ọmọ Òkú Ọ̀run, AUP, Lagos.
Ọdunjọ J.F. àti Ọladipupọ, A.B. (1967), Kádàrá àti Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Ọmọyajowo, J.A. (1957), Ìtàn Ọdẹ́níyà, Adégbàmí and Sons Press, Agbor.
Ọmọyajowo, J.A. (1961), Báyọ̀ Ajọ́mọgbé, Longman, Lagos.
Ṣobande, O.A. (1959), Rìgímọ̀ Obìnrin Kò e é Tú, Tìkà Toore Press, Lagos.
Yemitan, O. (1972), Gbọ́baníyì, O.U.P., Ìbàdàn.
Yemitan, O. (1980), Orúkọ Ló Yàtọ̀, UPL., Ìbàdàn.

Ìwé Àpilẹ̀kọ àti Ìwé Àtẹ̀jáde
Bamgboṣe, Ayọ̀ (1974), The Novels of D.O. Fagunwa, Ethiope Publishing Corporation, Benin City, Nigeria.
Barber, Karin (1979), “Sociology of Written Literature: Fagunwa and Okediji”, A Semianr Paper delviered at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the March 9th, 1979.
Benjamin, Walter (1977), “Understanding Brecht”, New Left Books, London.
Bennet Tpny (1977), New Accents, Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
Boa, E. and J.H. Reaid (1972), Critical Strategies, Edward Arnold Publishers Ltd., London.
Cabral, Amilcar (1969). Revolution in Guinea, Stage One, London.
Coker, Cheyney Syl (1973), Concerto for Exile, Heinemann, London.
Dada, P.O. (1980), “Marxist Criticism and African Literature”, Ganga, Vol. 2, No. 4.
Dathorne, O.R. (1965), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulletin of the Association for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
Eagleton, Terry (1977), Marxims and Literary Criticism, Methuen and Co. Ltd., London.
Echeruo, Michael J.C. (1967), “Robinson Crusoe, Purchase his Pilgrim and his Novel”, English Studies in Africa, Vol. 10, No. 2.
Goldman, Lucien (1975), “Dialectical Materialism and Literary History”, Toward a Sociology of The Novel, London, Tavistock.
Gutkind, Peter C.W. (1975), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Devleoping-Area, McGill University.
Horner, George R. (1971), “Folklore as a Psycholgocial Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
Ibitokun, Benedict M. (n.d.), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar Paper Delviered at the Department of African Languages and Literarues, University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Irele, Abiola (1977), “Study African Literature”. Nigerian Journal of Humanities, Vol. 1,. No. 1.
Ìṣọ̀lá, A. (1979), “Presenting Revolution in Ọmọ Olókùn Ẹsin”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Univeristy of Ifẹ, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria on 26th February, 1979.
Jackson, I.F. (1956), Advance in Africa, OUP, London.
Johnson, Rev. Samuel (1921), The History of the Yorubas, (ed.) Johnson, O., CMS Bookshop, Lagos.
Lowenthal, Leo (1957), Literature and the Image of Man, Boston, Mass.
Lukacs, George (1963), The Meaning of Contemporary Realism, Merlin Press, London.
My, Walter Norman (1965), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
Nazareth, Peter (1967), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol. 26(iv), Feb./March 1967.
Nkrumah, Kwame (1970), Class Struggle in Africa, International Publishers, New York.
Ogundipe-Leslie, Ọmọlara (1981), “A Marxist Reading of The  Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature-in-English and Department of Philosophy Joint Seminar, Unviersity of Ibadan, Nigeria on March 25th, 1981.
Ogungbẹsan, Kọ́lá (1971), “Literature and Society in West Africa”, African Quarterly, xi, 3.
Okediji, F.O. and Ọla Ọpẹyẹmi (1967), “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, Vol 4, No. 1.
Okonjo, Kamene (1976, “Igbo Women and Community Poltiics”, in Women in Africa (eds) Hafkin, N.J. and E.G. Bay, Stanford University Press, Stanford.
Oyesọsin, Ọba O.O. (1977), “Ipa àti Ipò tí àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé tijọ́ àti lóde ní”, Yorùbá Gbòde, Vol. 3, No. 4.
Seymour, Hlary (1983), Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood”, A Seminar Paper Presented at the Deparment of Literature-in-English, Univeristy of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
Shuking, L. (1944), The Sociology of Literary Taste, London.
Tressel, Robert (1965), The Ragged Trousered Philanthropists, with an introduction by Silitoe, Allan, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
Yai, O.B. (1977), “Ideas for a poltiical Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at the Orisha traditon, held at the University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Zhdnov, Vladimir (1956), “Some Recent Soviet Studies in Literature”, Soviet Literature, No. 8, Moscow.

No comments:

Post a Comment