Èyí èé ṣètàn, ohun ojú rí la ń wí
Mo ní kèé ṣètàn,
ohun a rí tó la ń sọ
Èmi kiní yìí náà
ni kiní ọ̀ún ṣẹ̀ sí láìp̣ẹ́
Èmi ló ṣẹ̀ sí
ni kò pẹ́ kò jìnà
Ṣé Yoòbá pẹ̀gàn
ẹni tí ò lóbìn-in 5
Torí bí wọ́n rí
ẹ lóde
Aya ni wọn ó
kọ́ beerè ó tóó kan tọmọ
Òhun náà ni baba
wa Sóbọ̀ ṣe sọ ọ̀rọ̀ kàn
Tó ní “Páàdì o
tó yìí oò nóbìnrin, ó tàbùkù”
N ló dífá
fọ́mọ Yoòbá 10
Tí wọn è é fi í
fi gbogbo ara
Pọ̀ rẹpẹtẹ
níbi iṣẹ́ olúsọ́ Àgùdà
Wọ́ lỌ́lọ́run
jẹ́ o torí obìn-in kú, o ò ṣàmín
Bó ò torí abo kú
torí emi oó ṣe kú o jèe?
Bó o lówó tó
dàbíi gbìngbìn-nì kìn 15
Emi ló o fowó
ọ̀ún wá bí ò ṣọmọ?
Ibo lo ó ha ti
rọ́mọ rà láìfẹ́bìin?
Béèyàn ò sì
tilẹ̀ lówó lọ́ọ́
Yóò fẹ́bìn-in
dandan ni bí owó orí àtaṣọ ìbora
Èmi sì ni yí, n
ò lówó lọ́ọ́, kọ́bọ̀ ṣàgbàà mi 20
Ọjọ́ sì ti ń lọ
lórí, ọdún ṣẹ̀ ń kọjá ọgbọ̀n
Ẹ ni dákẹ́ tara
rẹ̀ á ba dákẹ́
Ló jẹ́ n jí
níjọ́ kan tí mo gbọ̀nà òde
Mo múlé onísogún
dogójì pọ̀n
Mo dé ọ̀ún mo
yírà sọ́tùn-ún, mo yírà sósì 25
Mo ní baba rere
bàbá kẹ̀
Ẹ ẹ̀ sì yá mi
lọ́gọ́rùn-ún owó
Kí n fi gbáya
wálé ní rọ̀ǹgbà
Babá wò mí
tìkàtẹ̀gbin, n ò mọ̀ pá a níjà tì
Ó ní n gbéra
ńlẹ̀ n dìde, mo sì gbà 30
Olúwa má fi wá
lọ́táa wa lọ́wọ́, ẹ ṣàmín ẹ̀
Torí awọ
fẹ́lẹ́ tó bonú ò jẹ́ á dáṣeni mọ̀
Ó ní n gbowó, mo
ní èló lèlé bàbá?
Ṣégba ló dà
àbọ́ọ̀dúnrún?
Ó ní ká má rí i
òun ò ní í gbèlée kọ́bọ̀ lọ́wọ́ọ tèmi 35
Ó ní ká fọ̀rọ̀
ṣèfẹ̀ ká fi ṣàwàdà
Ó ní n ó ti rówó
kó tó dèyí àmọ́dún
Inú mí dùn,
ìfẹ́ n mo ṣe bí, n ò mọ̀
Pé ìfẹ́ a fẹ́
adìẹ ò dénú
Ó ní ṣùgbọ́n,
tó bá dàmọ́dún, tí n kò bá rówó ọ̀hún gbé jù sílẹ̀ 40
N bòun mú báásí
ẹran kan láraà mi
Èyí ò tilẹ̀ kò
kọ mi lóminú, kò ṣe mí ní háà!
Mo rò pé kó tó
dèyí àmọ́dún, ma rówó
Nítorí oko baba
ń bẹ nílé, mọ́tò baba ń bẹ lọ́nà
Lásán ni n ò lóó
lọ́ọ́, kè é ṣe pé bàámi ò là
Kò fẹ́ẹ́ fún
mi ni 45
Ó ló yẹ kọ́mọ
náà ó f̣ọwó ṣiṣẹ́ ajé, mo sì gbà
Ọkàn mi tilẹ̀
sì balẹ̀ ní ṣáà yí
Ṣé wọ́n ní bá à
ń jà, bíi ká kú kọ́
Bàámi ò ní í fi
mí sílẹ̀ pé wọn ó fìyà jẹ mí láìgbà mí
N ni mo bá gbowó
ni mo múlé aya lọ 50
Mo ṣèyí ó tọ́
tán, mo tún ṣèyí ó yẹ pẹ̀lú
Mo gbówó orí, mo
gbóbì ní gìdìgbà
Mo máya bọ̀
wálé
Ọ̀̀rọ̀ ìyàwó
rọlẹ̀ tán kí nǹkan tóó ṣe
Ìṣẹ̀lẹ̀ yí
ṣẹ̀, ó kọjá ti Jóòbù ní Bíbéélì 55
Ilée babá jó,
okó run, ọkọ̀ ṣègbé
Ọ̀rọ̀ ọ̀ún
dun ni, ó dùnìyàn jù
Torí kò sówó
lọ́wọ́ kò sí kọ́bọ̀ lápò
Ọdún sì ti bù
pé tán
Egbò ọ̀ún ṣajá
lọ́ṣẹ́, orí ló ti mú un 60
Kò pẹ́ náà kò
jìnà, baba olówó dé
“Owó tó o jẹ
mi, o ò ní í san án ni, àbí mo jẹ ìran rẹ lówó tì?
Baba yarí
pátá, ó tún fara ya
Wàràwéré ọ̀rọ̀
dọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀
Mo ránṣẹ́
abẹ́lẹ̀ sí bàbá 65
Pé kó dákun
dábọ̀ fiyèdénú
Kó fọjọ́
sọ́jọ́ owóo a jẹ
Bàbá kọ̀ jálẹ̀,
ó fàáké kọ́rí
“Owóò mi ni tàbí
báásí ẹran tí mo sọ”
Òrọ̀ yìí
ṣẹ̀ wá ń kọjáa bá a ṣe pè é, ó ń dihun míìn 70
Ṣáyé Òyìnbó sì lèyí, kè é ṣe tàwọn baba wa
Kò pẹ́ náà là wa
méjèèjì múra ó di kóòtù
A déwájú adájọ́
tó dì gágá dì gogo
Oníwá rojọ́
ẹlẹ́yìn rò, ẹlẹ́rìí ò kúkú sí
Ìwé a jọ tọwọ́
bọ̀ náà ló ṣẹlẹ́rìíi wa 75
Adájọ́ rọ̀rọ̀
síwá, ó rò ó sẹ́yìn
Ó bagbejọrò
lẹ́jọ́, ó bagbẹjọ́rò léèrè ọ̀rọ̀
Ó ní kò sí ṣíṣe
kò sáìṣe, báásí ẹran ni n ó san bá a ṣe sọ
Gbogbo aráyé ti
wá owó wá, gbogbo aráyé ti wá owó jọ, ̣n
bàbá ò gbà
Ó ní àdéhùn tá a
ṣe ti kọjá, ọjọ́ sì ti yẹ̀ 80
Mo woke, mo
wolẹ̀, omí dà pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀ lójúù mi
Ẹní gbọ́jọ́ ikú
rẹ̀ á sìwà hù
Bó sìwà hù tán,
á á sì ṣe pẹ̀lú
Níbi èrò dúró
sí, ariwo sọ lọ kùù
Gbogbo wọn ń ṣèrántí
ọjọ́ ìkúnlẹ̀ abiyamọ 85
A kì í kúkú
bẹ̀bẹ̀ ní kóòtù, ohun adájọ́ sọ labẹ́ gé
Èyí náà ló
máyáni lówó tó fi lọ yọdà, tó yọ̀bẹ
Tó fẹ́ẹ́ gba
báásí ẹran tá a jọ sọ
Kò sì mọ́bẹ
rebi méjì bí ò ṣoókan àyà mi
Ǹjé bá a bu
báásí ẹran kan láyà èyàn
Ikú ò níí dé? 90
Mo kúkú gba kámú
dé, mo fọ̀rọ̀ molúwa
Díẹ̀ ló kù, àní,
ó kù bín-ńtín
Kí oókan àyà mi
àtọ̀̀bẹ ṣ kòńgẹ́
Kí wọn dira mú
kí wọn fara kora
Gbígbọ̀n tí mò ń
gbọ̀n kọjáa torí omi 95
Iye àìsàn tó ti
kọ lù mí kọjá ogóje
Ẹní gbọ́jọ́ ikú
rẹ̀ á sìwà hù
Láàárín
ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ladájọ́ figbe ta
Ó ní, “Dúró
ayáni lówó
Báasí ẹran lẹ
ṣèwé, ẹ kò ṣèwé ẹ̀jẹ̀ 100
Ohun ìwé sọ lo
ó gbà láìláfikún
Ohun ìwé sọ lo
ó gbà láìlábùlà”
Kó o wà ńbẹ̀
níjọ́ ọ̀hún kó o wá wòran, ọ̀rẹ́ẹ wa
Kó wo bọ́wọ́ọ
baba ṣe ń gbọ̀n tọ́bẹ ń jáábọ́
Àbí a ti ṣ é ya
ni lọ́bẹ láyà kí pọ́n ó má ṣe 105
N ò mọ bá a ti
ṣeé ya ni lọ́ebẹ láyà kó má dọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀
Ò̀rọ̀ dòdì ẹni
à ń bẹ̀ ló wá tún ń bẹ ni
Ẹní a ń bẹ̀
ló wá ń ṣèpẹ̀
Torí òfin ti wà
ńlẹ̀ látayérayé
Pé ẹni tó bá
tàjẹ̀ sílẹ̀ á ṣòfùn ọ̀pọ̀ 110
Tọrọ̀, tilé
ẹni náà á á di tẹlẹ́jẹ̀
Bídájọ́ ṣe rí
nígbẹ̀yìngbẹ́yín rèé, ọ̀rẹ́ẹ wa
Owó, owó, n ò
san
Ọrọ̀ ayánilówó
tún di tẹni
N lo ṣe bá mi
níjọ́wo níhìn-ín tí mò ń mì nínú ọrọ̀ 115
N ò digun jalè,
bẹ́ẹ̀ ni, n ò fọ́lé
Owó ayánilówó ni
mo fi ń gbádùn araà mi
Èyí nìkan kọ́
ni wọ́n ṣe fáyáni lówó
Wọ́n tún lé e
kúrò ní ìlú fún àbá ìpànìyàn
Ìgbà mo délé
lọ̀rọ̀ yìí tóó wáá yé mi 120
N ò mọ̀ páya mo
fẹ́ sílé ló dì gágá di gogo lórí àga ìdájọ́
Ń ṣe ló
lọọ gbaṣọọ adájọ́ kan tó fi ṣe
tiẹ
Tó fi gbọkọ tó
ní kalẹ̀ láìròtì
N náà lèmi ṣe
máa fi ń ṣorin kọ
Pé
tá ń péyàwó ò dáa 125
Ta
ń péyàwó ò sunwọ̀n
Kó
wáá waya mo fẹ́ sílé
Tó
fẹ́ni fúnre
N lèmi ṣe
gbàwọn ọ̀dọ́ níyànjú
Pé wọn ó faya
níní ṣe ti wọn 130
Aya nìyá ọkọ
tó ò bá mọ̀
No comments:
Post a Comment