Tuesday, 9 June 2015

Ipò Ọba nínú Ìwé Ìtàn Àrosọ Yorùbá





Ọ̀nà mẹ́ta ni a lè pín àwọn òkọ̀wé ìtàn àròsọ Yorùbá sí nípa ohun tí wọ́n mẹ́nu bà nípa ipò àwọn ọba. Àwọn kan tẹnpẹlẹ mọ́ ohun tí ó dára nípa ipò ọba, àwọn mìíràn tẹnu mọ́ ohun tí kò dára, àwọn kan sì nì yí, wọ́n dàbí ìgbà pé wọ́n wà ní ààrin méjì tí a kò mọ ibi tí a lè tò wọ́n sí.
Irú àwọn tí a lè pín sí ipò kìíní ni Fágùnwà, irú àwọn wọ̀nyí máa ń sọ gbogbo ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó dára nípa Ọba. Wọn kò fẹ́ kí nǹkan yí padà sí bí ó ṣe wà ìyẹn ni pé kí àwọn ẹni tí ó ń jẹ gàba wà ní ipò wọn kí àwọn mẹ̀kúnnù sì fi ara mọ́ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn. Ohun tí a ó kọ́kọ́ bèèrè ni pé kí ni ó fà á tí ó fi ṣe èyí? Ohun tí ó fà á ni pé, ipò tí alákọ̀wé wà nígbà tí Fágúnwà ń kọ ìwé rẹ̀ bí ipò àwọn Ọba náà ni ó rí. Ọ̀wọ́ àwọn alákọ̀wé táṣẹ́rẹ́ tí ó wà ní ìgbà náà ni ó wà ní ipò tí ó jọjú jù lọ bẹ́ẹ̀ rèé “àwọn ajẹ́lẹ̀ tí a mọ̀ sí (Resident tàbí District Officers)... mọ ipò àti ipa àwọn ọba alayé”1, èyí ni pé ipò gíga kan náà ni irú Fágúnwà àti àwọn ọba wà nígbà tí ó ń kọ ìwé rẹ̀. Tí a bá fi ojú ti pé kí ọba ní agbára tí ó pọ̀ gan-an dúró fún ohun àtijọ́ kí díndínkù agbára ọba sì dúró fún ohun òde òní àti ọjọ́ ìwájú wò ó, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ti Ìbitòkun sọ nípa àwọn kan yóò bá èrò Fágúnwà mu, ó ní:
Of all the three concepts of time, past, present and future, the past, because of its greatness and therefore of its completeness, is irreducible. The present is present only in its realtion to the past. It could dispense with the future but not with the past2.

 Àìfẹ́ kí ohun àtijọ́ tí a sọ pé ipò ọba dúró fún bàjẹ́ yìí gan-an ni ó mú Fágùnwà kọ ìwé rẹ̀ bí ó ṣe kọ ọ́. Ṣé àwọn Gẹ̀ẹ́sì ni ó sọ pé kí ó kọ àwọn ìwé yìí. Ohun tí Fágúnwà wá fẹ́ẹ́ ̣e ni pé kí ó fi ara rẹ̀ sí ipò ẹni tí ó jẹ́ aṣojú fún àwọn nǹkan ìbílẹ̀ lójú àwọn Gẹ̀ẹ́sí gẹ́gẹ́ bí Barber ṣe ṣe àkíyèsí nípa Fágùnwà.
... (Fágúnwà) regard(s) himself as the representative of Yorùbá culture and tradition to the colonial authority...3

A sì ti mọ̀ pé nínú àwọn ọ̀nà pàtàkì tí a fi lè fi èrò inú wa kọ́ ènìyàn, ọ̀kan nínú rẹ̀ ni nípa ìwé kíkọ. Bennett sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa èyí, ó ní:
the ideological state apparatuses (are): the education system, the media, the family, the church... Ideology might thus be said to consist of those myths through which idnviiduals are reconciled to their given social positions by falsely representing to them those position and the relationships between them as if they formed a part of some inherently signficant, intrinsically coherent plan or process4.

Nínú àwọn ìwé tí Fágúnwà kọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn òǹkọ̀wé ṣe máa ń ṣe, ni ó ti gbé èrò rẹ̀ jáde. Ṣé ó ti mọ̀ pé ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá kò wọ́pọ̀ ní àkókò náà. Ó sì tilẹ̀ di dandan kí wọ́n ka ìwé rẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó ni ilé-ẹ̀kọ́ ní ìgbà náà yóò ṣe fi àṣẹ sí i. Tí a bá wo Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmalẹ̀, ìwé tí Fágúnwà kọ́kọ́ kọ, a ó rí i pé ń ṣe ni ọba rán àwọn ọdẹ ní iṣẹ́ tí yóò ṣe ìlú ní àǹfààní. Níyìín, Òkò Láńgbòdó ni ọba rán àwọn ọdẹ yìí láti lọ mù ohun tí yóò jẹ́ kí ìlú ní òkìkì tí ìlú yóò sì wà ní àlàáfíà wá. Àkàràoògùn ti ṣe ìlérí tán fún ọba kí ó tó mọ bí iṣẹ́ tí a bẹ òun ọ̀hún ṣe léwu tó ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó lè ṣe nítorí
ibiti o wu ẹfufu lẹlẹ ni ida ori igbẹẹ si, ibiti o wu olowo ẹni ni iran ni lọ, ibikibi ti ẹ ba fẹ, ẹ rán mi ng o lọ.(Pg. 49)

 Níyìín, a ó rí i pé ń ṣe ni Fágúnwà gbé àwọn ọba kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rí ní àwùjọ wa ní ayé àtijọ́. Ẹni tí ó bá fi ojú di ọba ní ìgbà náà, ń ṣe ni àwóowó máa ń wó o. Èyí kò sì ya ẹni tí ó bá ti ka ìwé sílẹ̀. Yáì (1977: 4)5 tí Barber (1979: 4)6 tọ́ka sí nípa ìhà tí Fágùnwà kọ sí òṣèlú wí pé ó gbàgbọ́ nínú ohun tí ó pè ní “social immobilism”, ìyẹn ni pé kí oníkálukú mọ àyè rẹ̀ ní àwújọ kí ó má sì là kàkà tàbí kí ó fẹ ojú sí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ kò tó. Ó ní:
it is a sin to question the existing social order or try to change it
Tí a bá wo ohun tí a mẹ́nu bà yìí, a ó ṣe àkíyèsí wí pé Fágúnwà fi ọwọ́ sí pé kí ọba wà ní ipò ọlá kí mẹ̀kúnnù sì máa gbàdúrà pé yóò sì dára. Ọ̀nà àlọ́ tàbí ohun tí àwọn kan pè ní mérìíìiírí ni Fágúnwà gbé ìtàn àròsọ rẹ̀ gbà láti fi ipò àwọn ọba hàn wá. Èyí kò sì dédé rí bẹ́ẹ̀. Ìdí pàtàkì tí ó jẹ́ kí FÁgúnwà lo irú ìlànà yìí ni pé kò sí bí ó ṣe lè ṣe é tí ìtàn rẹ̀ fi lè jẹ òótọ́ tí ó bá gbé e ka ojú ayé gidi. A sọ èyí nítorí pé ní àsìkò tí ó ń kọ ìwé rẹ̀ pàápàá, àyípadà tí ń dé bá ipò ọba. Ohun tí ó wá ṣe ni pé kí ó mú wa lọ sí inú ìgbẹ́, kí ó sọ ìtàn rẹ̀ di àlọ́, kí ó máa fi kọ́ ni lọ́gbọ́n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí níí sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn tí ó dá dúró fúnra wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn. Tí a bá wo Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmalẹ̀, a ó rí i pé ìrìnàjò mẹ́ta ni àwọn ọdẹ inú ìwé yìí lọ. Gbogbo ìrìnàjò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, kò sí ohun tí ó so wọn pọ̀.
Yàtọ̀ sí ti pé ìtàn yìí kò sọ pọ̀, a ò tún lè sọ pé ìtàn yìí lọ tààrà. Ojú kì í kán ẹni tí ó ń sọ ìtàn yìí. Tí ó bá lo títí, á tún dúró tí ó bá dé ibi kan. Ó tún lè pẹ́ pẹ́ pẹ́ ní ibẹ̀. Àfi tí nǹkan kan bá ta á ní ìdí páá kí ó tó tún máa lọ. Kì í ṣe pé ibi tí ó ń lọ kì í kán an lójú ṣùgbọ́n ohun tí a ṣe àkíyèsí ni pé ó máa ń fẹ́ dúró ṣe àlàyé láti kọ́ ni lọ́gbọ́n ní ibi tí kò yẹ. Ohun tí ó máa ń so ìtàn rẹ̀ pọ̀ kò ju ọgbọ́n tí ó sọ pé òun ń kọ́ ni yìí lọ. Bí ó ń ṣọ ìtàn tí ó jẹ mọ́ ohun tí ìwé dálé lórí lọ, ó lè yà bàrá kí ó tún mẹ́nu ba ọgbọ́n tí ó fẹ́ kọ́ ni. Ó ní:
Nko ni sọ itan igbesi aiye mi fun ọ loni, nitori ilẹ ti ṣu, nígbà tí o ba di owurọ ọọla ng o ma sọ eyini fun ọ. Ṣùgbọ́n ki a to lọ sun lalẹ yi ng o sọ ian kan fun ọ ng o si kọ ọ ni ọgbọn pataki kan. (Ireke Onibudo Pg. 21)
A ó rí i pé ohun tí ó fẹ́ ṣe gan-an ni ó fi sílẹ̀ tí ó mú ohun tí kò ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ ṣe. Ìbá ṣòro fún un láti ṣe irú èyí tí ó bá jẹ́ pé kì í ṣe ìlànà mérìíirí ni ó lò. Ọ̀rọ̀ ti pé a ń kọ́ ni lọ́gbọ́n yìí jẹ́ àléébù kan tí ó bá èrò ọkàn rẹ̀ mu tí ó sì ba ìwé rẹ̀ jẹ́. Tí a bá tilẹ̀ wo ọgbọ́n tí ó sọ pé òun ń kọ́ ni yìí gan-an, a ó rí i pé kì í ṣe nǹkan tí ó yọrí sí rere nitorí a ò le sọ pé ó ní ojútùú. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kàn dàbí ti pé a kì í mú olè kí a máa yán an ni. Gbogbo ibi tí ó bá dé ni ó ti máa ń mẹ́nu ba irú ìtàn ìkọ́nilọ́gbọ́n yìí. Kò sì ya àwọn ìtàn yìí sí ọ̀tọ̀ sí ara wọn. Bí olè jíjà ṣe tóbi tó ní ojú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni pé kí á pàdé ẹni ní ọ̀nà kí á máà kíni ṣe tóbi tó. Kò sí àgbà nínú ọmọ ajá tirẹ̀. Abájọ tí ó fi dojú ìwé rẹ̀ kọ àwọn ọmọ ilé-èkọ́.
Tí a bá tún ní kí á wo ìlò èdè rẹ̀, a ó rí i pé kò kó ògo já náà ní ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé àwọn náà kò so mọ́ ara tó. A sáà rí i pé àwọn tí ó sọ ìtàn nínú ìwé rẹ̀ pọ̀ díẹ̀, síbẹ̀ tí a bá wò ó dáradára, a ó rí i pé kò sí ìyípadà nínú ohun tí a gbọ́. Bí Ìtànforítì ṣe sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni Baba Onírùngbọ̀nyẹukẹ ṣe sọ̀rọ̀ bákan náà ni Olówó-ayé ṣe sọ. Ní ti èdè ẹ jẹ́ kí a wo àyọlò yìí.
Ṣùgbọ́n bi mo fẹ bi mo kọ ọkùnrin na yọ si mi dandan inu bi mi gidigidi, mo fa oju ro bi ẹniti ebi npa, mo npoṣe bi ẹniti iya njẹ, mo di ẹnu dudu bi ọmọ ọdọ ti o fọ́ awo onjẹ, ti ko le sọ fun ni, ti o nrin kakiri ẹgbẹ ogiri, ti inu ọmọ na si daru bi igẹdẹgẹdẹ idi ẹmu inu ṣago7.
Gẹ́gẹ́ bí Barber ṣe ṣe àkíyèsí, a ó rí i pé ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó kọ́kọ́ fọ́ awo ni ó fi bẹ̀rẹ̀ àfiwé tààrà yìí. Ó tún wá kúrò ní orí ohun tí ó fi ọmọ ọ̀dọ̀ wé, ó bẹ́ sí orí ọmọ ọ̀dọ̀ gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí fi ohun mìíràn wé e. Ohun tí ó tún fi ń wé ọmọ ọ̀dọ̀ yìí ni ó wá tún tẹnpẹlẹ mọ́, ó ti kúrò ní orí ọ̀rọ̀ tí o ń sọ tẹ́lẹ̀. A kò sọ pé àfiwé kò ní ìwúlò tirẹ̀ ṣùgbọ́n ó dàbí ìgbà pé ojú kì í kán Fágúnwà. Irú àwọn nǹkan báwọ̀nyí tí a ṣe àkíyèsí ni Barber (1979: 22)8 ṣe sọ pé:
This type of displacement of attention occurs cosntantly in Fagunwa’s prose and it suggests that the writer is in no hurry to nail down any particular idea or image; instead he is content to elaborate whatever idea happens to be before him. This kind of writing is decorative more than purposive. Like the plots of his books, his prose seems to be filling in a given space as attractively as possilbe, rather than aiming at any goal.

A ó ṣe àkíyèsí wí pé èrò tí Fágúnwà fẹ́ fi ìwé rẹ̀ gbé jáde, ìyẹn ìjẹgàba àwọn alágbára lórí àwọn mẹ̀kúnnù, tí kò fi agbára wu ni, ni kò jẹ́ kí ọ̀nà tí ó fi gbé ìtàn náà kalẹ̀ àti èdè tí ó lò wuni. Ṣùgbọ́n a lè wá bèèrè lọ́wọ́ ara wa pé lékèe pé iṣẹ́ Fágúnwà rí báyìí, kí ni ó dé tí àwọn ènìyàn ń gbádùn à ń ka ìwé rẹ̀? Ohun tí ó fa èyí kò le.
Ohun tí a ó ṣe àkíyèsí ni pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé Fágúnwà ni ó kọ́kọ́ kọ ìwé ìtàn àròsọ jáde ní èdè Yorùbá. Tí wí pé èdè àwọn ti di ohun tí a fi ń kọ ìtàn àròsọ dùn mọ́ àwọn ènìyàn wa nínú débi pé wọn kò lè ṣe kí wọn máà kà á. Ṣé èdè òyìnbó ni gbogbo ìtàn àròsọ tí ó wà ní ìgbà náà àfi Sẹ̀gilọlá Ẹlẹ́yin Ẹgẹ Ẹlẹgbẹrun Ọkọ Laiye; irú àwọn wọ̀nyí kò sì pọ̀. Ti pé wọ́n rí ìw tí a kọ ní èdè wọn yìí ni ó jẹ́ kí kíkà rẹ̀ jẹ wọ́n lógún láiwo ohun tí ó dá lé lórí tí kò ti ìgbéga wọn lẹ́yìn. Yáì (1977: 9)9
Thus Fagunwa’s novels were – and are still to a great extent – blessed with double reading. The masses enjoyed the language, or rather the mere fact taht their language was written and given such large publicity, while they neglected the reactionary content.

Àwọn tí a lè sọ pé kò ṣeku kò ṣẹyẹ tí wọ́n fi ara wé àdán ni irú àwọn òǹkọ̀wé bíi Délànọ̀ àti Fálétí. Ó tún dàbí ìgbà pé a tún lè tún àwọn yìí pín sí méjì ní àárin ara wọn. Ó jọ bí ẹni pé Délànọ̀ fẹ́ fi ara mọ́ ti pé kí ipò ọba máà ga ju bí ó ti yẹ lọ, Fálétí náà ń fẹ́ kí ọba wà ṣùgbọ́n kí ó máà láṣẹ tó ti àtijọ́. A rò pé nínú àwọn ohun tí ó fa èyí ni ohun tí Ìbítókun (n.d.: 1)10 sọ nípa Achebe tí a lè fi ojú rẹ̀ wo àwọn méjèèjì yìí, ó ní:
Ọmọtọṣọ is one of our angry young men, Achebe, on the other hand, belongs to a different tradition and society, so do his fictional characters. Theirs is the culture contact or culture conflict tradition that brings about societal disintegration.

Olóyè Délànọ̀ ni àyọlò yìí bá mu jù nítorí nígbà tí òun ń sọ̀rọ̀ nípa ọba nígbà tí yìnbó gòkè àti kí wọn tó gòkè, ọba ayé àtijọ gan-an ni Fálétí ń sọ nípa wọn ní tirẹ̀. Tí a bá wo àwọn méjèèjì yìí, a lè sọ pé ó ní ìdí tí èrò wọn fi fẹ́rẹ̀ bára mu. (A kò sọọ pé ó bá ara mu tán o ṣùgbọ́n tí ó bá ara mu dé ibi tí a ti lè tò wọ́n sí abẹ́ ìsọ̀rí kan náà). Olóyè ni Délànọ̀ ọmọ ọba sì ni Fálétí. Nítorí ìdí èyí, wọ́n ní ìfẹ́ láti dáàbò bo ipò ọba síbẹ̀ nítorí ìwé tí wọ́n kà, wọ́n tún ní ìfẹ́ pé kí ó dára fún mẹ̀kúnnù.
Tí a bá wo Fálétí, a o rí i pé àsìkò tí ó kọ ìwé rẹ̀ wa lára ohun tí ó jẹ́ kí ó kọ ìwé yìí bí ó ṣe kọ ọ́ yìí. Ṣé ètò òmìnira fún ilẹ̀ Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ní sáà yìí. Òun gan-an ni ó ní láti jẹ́ kí ó fi ojú tí ó fi wo ipò ọba wò ó. Ṣé tí a bá ní kí á wò ó jinlẹ̀jinlẹ̀, a ó rí i pé kì í kúkú ṣe pé ipò rẹ̀ ní àwújọ yàtọ̀ sí ti Fágùnwà. Lóòótọ́, ó kàwé ju Fágúnwà lọ àti pé irú iṣẹ́ tí ó sì ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń bá ilé Rédíò ṣiṣẹ́, lè jẹ́ kí ó mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí ju Fágúnwà lọ. Irú èyí ni ó hàn nínú ìwé Fálétí tí ó fi yàtọ̀ sí Fágúnwà tí wọ́n jọ kọ ìtàn ṣùgbọ́n ohun tí a ṣe àkíyèsí ni pé àwọn tí ó wà ní ọ̀wọ́ (class) kan a máa fi ojú tí ó yàtọ̀ síra wo nǹkan.  Lóòótọ́, Ọba Fágúnwà jẹ ọba mérìírírí ju ti Fálétí lọ síbẹ̀ náà a lè fi wọ́n wé ara. Kì í kúkú ṣe pé Fálétí fi gbogbo ara sọ pé kí a máà ka ipò ọba sí náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ, nǹkan tí ó ń fẹ́ ni pé kí àwọn ènìyàn máa fi ẹnu ara wọn sọ bí wọ́n ó ṣe máa sin ọba wọn. Ó mọ̀ lóòótọ́ pé láìsí ọba kò lè sí àjọṣepọ̀ láàrin gbogbo ìlú tí ó wà ní abẹ́ ìgbèkùn Òkò; òun ló dàbí ẹni tí ó so àwọn ìlú yìí pọ̀. Tí a bá sì wo ìtàn tí ó sọ, ara ìdí tí a kò fi mọ ibi ti ó yẹ kí a to Fálétí si ni pé, ní ojú ayé, lóòótọ́, àwọn ará Òkè Ògùn ṣígun sí Ọ̀yọ́ ṣùgbọ́n wọn kò ṣẹ́gun11. Ní inú ìwé rẹ̀, àwọn ará Òkè Ògùn ṣẹ́gun ṣùgbọ́n èyí tí ìbá fi fún àwọn ènìyàn láyè láti gbádùn òmìnria wọn, ń ṣe ni wọ́n gbà láti máa ṣe nǹkan fún ọba. Àjàyí ni ó sọ ètò náà báyìí, ó ní
Lọdọdun a o ma fi adọta ọkẹ ranṣẹ si Olumoko Ọba Oko, a o si ma fi adọta ọkẹ ransẹ si awọn ijoye rẹ̀. Ao ma fi maalu meji ranṣẹ akọ kan abo kan – lọdọdun fun ọdun mẹwa. Ọba ko gbọdọ ni ju ogun ẹru lọ. Ao si ma fi ogun ọkẹ ranṣẹ sí Arẹmọ-ọba lọdọdun. (Pg. 168-169)

A mọ̀ pé Fálétí gbé ìwé rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀nà tí ó dára gan-an ni; ó sì ṣe ètò rẹ̀ tí nǹkan fi ń lọ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé tí ó sì wuni. Ṣùgbọ́n ohun tí ó yani lẹ́nu ni bí Àjàyíó ṣe tún sọ pé kí àwọn ènìyàn máa san nǹkan fún ọba lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti ṣẹ́gun tán. Àlàyé kan tí a rí ṣe kò ju pé nítorí pé òǹkọ̀wé jẹ́ ọmọ ọba lọ. Síbẹ̀, ó yẹ kí á kí Fálétí kí á yin ín ní pàtàkì tí a bá wo àwọn ọba tí ó ń kọ ìwé nípa wọn. Tí a ba rí onkowe tí ó lè ṣe báyìí kọ̀wé nípa àwọn ọba àtijọ́ bí ipò wọn ṣe ga tó, a ò jayò pa tí a bá sọ pé ó ní ìfẹ́ mẹ̀kúnnù lọ́kàn.
Ní ti Délànọ̀, ó dàbí ìgb pé ó fẹ́ fi sí ọ̀dọ̀ àwọn yìnbó. Tí a bá wo ìwé Délànọ̀ ní ẹ̀yìn ìdájọ́ ajẹ́lẹ̀ tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí máa hu ìwà tí ó wù wọ́n, a ó rí i pé Délànọ̀ kò fi agbára gba ti ọba lọ títí. Ó ṣe ó kúkú mú Babalọlá fi ọwọ́ wọ́nú, ó sì gba ohun tí ìyàwó rẹ̀ wí pé:
kí a ma ṣe mẹlọmẹlọ pẹlu oyinbo. Igba ti o de li a a ṣe ... Ba oyinbo rẹ, jẹ ọmọloju oyinbo diẹ niyoku... oyinbo li Ọlọun fi ṣe ọkọ enia dudu. (Pg 62)
Àsìkò wá tó wàyí kí Babalọlá mọ èyí tí yóò ṣe gan-an. Bákan méjì ní Délànọ̀ ni àyè àtigbé Babalọlá hàn wá níyìín. Yálà kí ó jẹ́ kí Baálẹ̀ fi orí oyè sílẹ̀ tàbí kí ó tilẹ̀ gba ẹ̀mí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n Délànọ̀ kò ṣe èyí; ọ̀tọ̀ ni ohun tí ó mú Babalọlá ṣe gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn rẹ̀, Babalọlá ní
Irú anọ yẹn sisun ni ng bá sùn ng ba sun bi baba nla mi iba ti ṣe ni iru ọran bayi. Ṣugbọn Aṣabi, ki nsun, ki ng pa ara mi... nitori oro Adanọja lẹhinti Ọlọrun ti yọ mi ninu ewu iku papa? Ki ng pa ara mi, ki ng da gbogbo yin silẹ ni oriyo, ki ng ma gbadun gbogbo ohun meremere ti oyinbo wa gunlẹ si oke yi? Sisun na gbero Aṣabi. Orun ko tilẹ kun mi ni. (Pg 61)
Kò sí tàbí ṣùgbọ́n, Délànọ̀ ti fi ibi tí ó fi sí hàn wá. Ó fẹ́ kí ìfẹ́ àti àjọṣepọ̀ tí ó wà ní ààrin àwọn ọba àti ajẹ́lẹ̀ jẹ gàba lórí àṣà. Bi ọba tilẹ̀ ń pa irọ́, kò jọ ọ́ lójú, kí ó máà sáà ti tẹ́ ní ọwọ́ àwọn yinbo. Gbogbo ohun tí a rí yìí fi hàn pé Délànọ̀ kò fẹ́ kí ọba jẹ gàba nítòótọ́ ṣùgbọ́n síbẹ̀ ó fẹ́ kí àwọn yìnbó máa ṣe ohun tí àwọn ọba ń ṣe tẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí ìfẹ́ àwọn ará ìlú nítorí yẹ̀yẹ́ ni àwọn ará ìlú n fi baálẹ̀ ṣe káàkiri wí pé:
Babalọlá ni ọba ti a niyi njẹ o,
O dẹru oyinbo, o ta ara rẹ lọpọ,
A ko ni roju ṣe oku ọdalẹ l’ọjọ ti o ba k (Pg. 64
)
Ohun tí ó tilẹ̀ tún fi ìdí ìgbàgbọ́ wa múlẹ̀ nípa ti pé Délànọ̀ fẹ́ràn ìjẹgàba àwọn Gẹ̀ẹ́sì ni pé ìgbà tí wọ́n wà lórí àlèéfà ni ó kọ ìwé rẹ̀ yìí. Yàtọ̀ sí èyí, ó tún bá àwọn Gẹ̀ẹ́sì yìí kan náà ṣiṣẹ́ ní “School of Oriental and african Studies, London”. Tí kò bá jẹ́ ìfẹ́ wọn tí ó ní, kò yẹ kí ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ tó báyìí. A ó ṣe àkíyèsí wí pé Délànọ̀ kò fi ìgbà kan sọ pé báyìí ni yóò ṣe rí fún àwọn mẹ̀kúnnù. Tí a bá wá wo Fálétí, lóòótọ́, ibi tí ó fi s fi ara sin díẹ̀, síbẹ̀, a mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ mẹ̀kúnnù nítorí pe àwọn ni ó sọ pé kí ó máa yan ohun tí wọn yóò máa kó fún ọba. A ó sì ṣe àkíyèsí wí pé bí èrò rẹ̀ ṣe rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀nà tí ó fi gbé ìwé rẹ̀ kalẹ̀ náà ṣe wuyì. Òun ni Ìṣọ̀lá (1979: 26)12 rí tí ó fi sọ pé
secondary matter of style and technique. It is inseparable from the subject matter.
Ọ̀rọ̀ ti Délànọ̀ kò rí báyìí. Èdè rẹ̀ kò wuni, ètò ìwé rẹ̀ kò fi agbára sunwọ̀n. Nínú Lọ́jọ́ Ọjọ́un, ẹ̀kọ́ kẹfà àti èkeje rẹ̀ kò wúlò fún ìtàn tí ó ń sọ nípe Fífákẹ́. Ohun tí ó ń mẹ́nu bà ní ìyín kò ju ìwádìí ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ ọtí lọ. Ọ̀rọ̀ nípa èdè Yorùbá, àṣà àti ọ̀nà ìwòsàn ìbílẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀kọ́ kẹsàán náà kò wúlò fún ìtàn tí ó ń sọ. Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ kò ju pé òǹkọ̀wé yìí ní ọ̀pọ̀ ìtàn gidi sí ọwọ́ tí ó sì fẹ́ kí ó jáde nínú ìwé òun ní ọ̀nà kọnà. Gbogbo èyí ń fa ìtàn sẹ́yìn ni kò mú un lọ sí ìwájú. Bẹ́ẹ̀ ni ìwé ọ̀hún tilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ di ìtàn gidi tán. A rí àwòrán gidi ní inú rẹ̀ a sì rí àwọn ọjọ́ tí nǹkan ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀ tí ó bá ti ojú ayé mu. Èyí kò ya mi lẹ́nu nítorí yàtọ̀ sí ìwé nípa èdè tí a mọ̀ mọ́ Délànọ̀, ohun tí a tún mọ̀ mọ́ ọn ni pé kí ó máa kọ ìtàn gidi nípa ìlú tàbí ènìyàn. Gbogbo àwọn àléébù yìí kò fi nǹkan méjì hàn bí kò ṣe èrò ọkàn òun pàápàá tí ó ní àléébù díẹ́.
Tí a bá wá wo Yemitan, Ọlábímtán àti Ládélé, a ò ní í ṣe wàhálà jìnnà tí a ó fi mọ ibi tí wọ́n fi sí nípa ipò ọba ní àwùjọ wa. Wọ́n ṣe èyí nípa mímú kí ọba hu àwọn ìwà kan tí kò sunwọ̀n, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ gbajúmọ̀ sí ọba lẹ́nu láti fi irú ipò tí wọ́n fẹ́ kí ọba wà hàn. Nítorí pé ọba gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó ará ìlú, Yemitan ní
Ọlọ́dàn dọ̀ọ̀bálẹ̀ níwájú ajẹ́lẹ̀ nítòótọ́, ojú ṣọgbọ́n ti ọ̀gbẹ́ni Alọ́ní pé ajẹ́lẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.



Ọ̀rọ̀ ti pé Ọlọ́dàn fẹ́ Morẹ́nikẹ́ gbé kó ni ó jẹ wá lógún, ohun tí ojú ọba rí ní ọ̀dọ̀ ajẹ́lẹ̀ yìí fi bí ipò ọba ṣe rí lójú Yemitan hàn. Nígbà tí Fálọlá sọ fún un pé ọmọ ọba ń gbẹ́sẹ̀ lé obìnrin ní ìlú Ọ̀yọ́ kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọba, ó yára dá a lóhùn pé:
Ọ̀yọ́ kọ́ la wa yí sá o...
Ọdàn ni ibi yìí ń jẹ́... (Orúkọ Ló Yàtọ̀,  Pg. 3)
Bẹ́ẹ̀ òdodo ni lójú Yemitan. Irú ayé tí àwọn ọba Òkò n jẹ ti kọjá. Àwòrán ojú inú fún bíi ayé òde òní ṣe rí gan-an tí iyì ọba ti ń dín ín kù ni Yemitan fi Ọ̀dàn dúró fún tí Ọ̀yọ́ tí Fálọlá dárúkọ sí dúró fún ìgbà ti àtijọ́ tí ọba máa ń jẹ́ “ikú bàbá yèyé, aláṣẹ, èkejì òrìṣà’. Irú èrò yìí kan náà ni Yemitan gbé hàn wá nínú Gbọ́baníyì ní ibi tí a ti rí odidi ọba tí ó ń tan iná wa iyì kiri.
Ládélé náà kò ṣàìfi èrò rẹ̀ hàn nípa bí ó ṣe fẹ́ kí ipò ọba rí nínú ìwé rẹ̀ Ìgbì Ayé ń. Ẹni tí Ládélé fi ṣe èṣù-lẹ́yìn-ìbejì fún Olú Òtólú àti ọmọ rẹ̀ ni Bàkó. Bàkó yìí tí ó ti ṣe ọmọlójú lọ sí Èkó fún ìgbà pípẹ́ ni ó kọ́kọ́ ta ko ayé ìjẹkújẹ tí àwọn ìdílé ọba ń jẹ. Ó bá Déegbé, ọmọ ọba, fa ìjàngbọ̀n débi tí ọ̀rọ̀ fi di ọ̀ràn tí ó fi di ti àwọn ọlọ́pàá tí ó wá láti Èkó. (Ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí). Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá yìí dé ààfin, ìgbátí, ìgbámú bíi kẹrikẹrì; àwọn ará ààfin kó ìbóǹbó bò wọ́n.
... Nígbà tí Gómìnà gbọ́ àbọ̀ wọn, ó gbaná jẹ pé irú ilu wo ni ilu ọhun? O gbe ibọn le awọn sọja mẹfa lọwọ ki wọn lọ mú Olu Òtólú náà pẹ̀lú àwọn ẹru rẹ̀ àti Déegbé... Àwọn sọ́jà wọ ààfin, wọ́n ní kí Olú Òtólú máa múra toun ti àwọn ẹru rẹ̀, Gómìnà npe wọn l’Eko, tí o bá sì jáfara àwọn yo fi ibọn forí oun àti àwọn ẹru rẹ̀ danu. (Pg. 44-45).
Ládélé wá sọ Olú Òtólú di Olú àńperí. Ó mú kí á sọ Olú tólú sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan kí á sì sọ Déegbé sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta. Irú ìfi ọba wọ́lẹ̀ wo lèyí? Ẹkún ni Ládélé mú ọba bú sí èyí tí ìbá fi gba kádàrá kí ó ṣe bí ọkùnrin ó ní:
Háà, ọba mà ni mi (pg. 58)
Ọba tí ó jẹ lẹ́yìn èyí, ìyẹn Lábándé, ń ṣe ni Ládélé jẹ́ kí ó yára ti ọwọ́ ọmọ tirẹ̀ bọ aṣọ. Ní òpin ìwé, Ládélé wá fi ìfẹ́ rẹ̀ sí mẹ̀kúnnù han. Ó mú ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mú kí Gómìnà fẹ́ kí àwọn mẹ̀kúnnù kó ipa nínú ìjọba ṣẹlẹ̀. Gómìnà wá fi Bàkó tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ̀kúnnù jẹ oyè abọ́bajírò tí yóò máa ṣòfin ìlú tí ó jẹ́ pé kí ọba kàn máa fi ọwọ́ sí i lásán ni. Báńkàrere àti Májèétí-Ọba-ó-di, tí ó jẹ́ ẹrú lásán wá di ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀.
Ọlábímtán náà fì sí ibi tí Yemitan fì sí. Èyí kò sì yà wá lẹ́nu tí a bá wo àsìkò tí òun náà kọ ìwé rẹ̀ àti àsìkò tí ó fi orí ìwé rẹ̀ sọ. Lójú tirẹ̀, Ọba gbọ́dọ̀ máa fa àwọn tí ó bá gbé pẹ́ẹ́ díẹ̀ mọ́ra ní àárín ìlú láti máa bá ọba dáàbò bo ipò rẹ̀ tí ó ń lọ sílẹ̀ yìí. Ọba ní:
Dúró, ó ńjìnnà si mi. Iru rẹ nilẹ̀ yìí ti o ti rókun ti o ti rọ́sà, ṣe irú rẹ ni o yẹ ki o ma jina si mi? Bi o ò bá máa rin mọ mi, ki ẹ máa fún mi ní ìmọ̀ran, bí Soho yii o ti dara, ẹyin ni àwọn ọrẹ yin yio ma a bu o (Baba Rere Pg. 32)
Ọba wá di ẹni tí ó wá ń ṣìpẹ̀ fún àwọn ará ìlú pé kí wọn wá fún òun ní ìmọ̀ràn! Ọba tí ó jẹ́ pé ń ṣe ni àwọn ènìyàn yẹ kí ó máa du ọ̀dọ̀ rẹ̀ wa. Ṣùgbọ́n irú ọba tí a lè máa du ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá báyìí kò tẹ́ Ọlábímtán lọ́rùn. Ìgbà tí ó kúkú ṣe ni ó bá fi irú ipò tí òun fẹ kí ọba wà gan-an hàn wá. Ọba tí ó jẹ́ pé ohunkóhun tí ó bá wù ú ni ó yẹ kí ó táwọ́ sí ní ààrin ìlú tí kò yẹ kí ó sí ẹlẹ́ẹ̀mú rẹ̀ wá di ẹni tí ó ń tọrọ owó, ó ní:
Wò ó, Ijẹẹbu lásán-lásán, o dabira. Ọjọ́ wo ni ng ba to r’owo kọle bi o ba si tirẹ. Ki iru Duro wa nílùú kò ma loore kan lara? (Pg. 32)
Ibi tí Ọlabimtan n lọ gan-an ló dé yìí.
Lóòótọ́, a ó rí i pé ipò ọba ti fẹ́ di yẹpẹrẹ ní ọwọ́ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a yẹ̀wò gbẹ̀yìn yìí ṣùgbọ́n ọ̀nà tí oníkálukú gbà gbé tirẹ̀ hàn wá yàtọ̀ sí ara. Tí a bá wo Ọlabimtán àti Yemitan, àwọn ka ìwé gan-an. Ìwádìí tilẹ̀ fi hàn pé ìlú Òyínbó ni Yemitan ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ Gbọbaniyi bẹ́ẹ̀ rèé olùkọ́ ni Ọlabimtan ní Yunifásiti Èkó. Lójú àwọn méjèèjì yìí, àwọn oníṣòwò tàbí àwọn tí ó wà ní ipò ọlá bí i Bamidele àti Dúró ni ó máa ń ṣe alágbàwí ọba, ìyẹn ni pé àwọn ló wá di ẹni tí ó ń ran ọba lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan kò dán fún un mọ́. Ohun tí èyí ń fi hàn àn ni pé lóòótọ́, ipò ọba kò jọ bí ti àtijọ́ mọ́ síbẹ̀ àwọn òńkọ̀wé méjì yìí kò tí ì ṣe tán láti gbé mẹ̀kúnnù sí òkè. Wọn kò kó ọ̀rọ̀ mẹ̀kúnnù sí ọkàn tó Ládélé. Ládélé kó ọ̀rọ̀ mẹ̀kúnnù lékàn gan-an ni. Bí ó ti ń rẹ ipò ọba sílẹ̀ ni ó ń gbé ti mẹ̀kúnnù ga. Ohun tí a rò ni pé sísúnmọ́ tí Ládélé súnmọ́ àwọn mẹ̀kúnnù yìí ni ó fà á. Ṣé ó ka ìwé. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ títí tí ó fi simi lẹ́nu iṣẹ́. Sísúnmọ́ tí ó súnmọ́ àwọn mẹ̀kúnnù yìí ni ó jẹ́ kó fi wọ́n hàn wá bí ó ṣe tọ́ àti bí ó ṣe yẹ.

Ìtọ́ka
1.      Ọba O. O. Oyesọsin Keji (1977: 3), “Ipa àti Ipò tí Àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní”, Yorùbá Gbòde, Vol., 3, No. 4.
2.      Benedict M. Ibitokun (n.d.: 1 1), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar paper delivered at the Department of African Languages and Literatures, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
3.      Karin Barber (1979: 22), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fágùnwà and Okèdíji”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ Universiyt, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
4.      Tony Bennett (1979: 115), New Accents: Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
5.      O.B. Yai (1977: 4), “Ideas for a Political Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at Orisha Tradition held at the Unviersity of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
6.      Karin Barber (1979: 4), Op. cit.
7.      Ibid., pg. 22.
8.      Ibid., pg. 5
9.      Op. cit.
10. Op. cit.
11. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (n.d.: 27), “Images of the Ọba in Yorùbá Novels”, a Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
12. Op. cit
13. Peter C.W. Gutkind (1975: 22), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Developing Area Studies, McGill Univeristy.
14. Akínwùmí Ìṣọ̀lá (1976: 395), “The Detective Novel in Yorùbá”, Department of African Languages and Literatures Seminar Series, No. 1, 1976-77, Part II.
15. Karin Barber (1979: 39), “Sociology of Yorùbá Written Literature: Fagunwa and Okediji”, An unpublished Seminar Paper delivered at Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the 9th April, 1979.
16. Op. cit.
17. Robert Tressel (1965), The Ragged Trouserred Philanthropists, with an introduction by Allan Sillitoe, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
18. Peter Nazareth (1967: 35), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol, 6 (iv), Feb./March 1967.
19. P. Mercier (1966: 379), in P.C. Lloyed (ed.), The New Elites of Tropical Africa, OUP, London.
20. Ọmọlara Ogundipe-Lesilie (1981: 3), “A Marxist Reading of The Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English and Department of Philosophy Joint Seminar, University of Ibadan, Nigeria, 25th March, 1981.
21. O.B. Yai (1977: 10), Op. cit.
22. Ibid.
23. Op. cit.
24. Op. cit.
25. George Lamming (1973: 61), In The Castle of my Skin, quoted from S. Wayak “V.S. Naipaul and the West Indian Situation” Busara, Vol. 5, No. 1, 1973.
26. Kọ́lá Ògúngbẹ̀san (1971: 61), “Literature and Society in West Africa” African Quarterly, xi, 3.
27. Quoted from F.O. Okediji and Opeyemi Ọla (1967: 81) “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, vol. 4, No. 1.
28. Ayọ̀ Bamgboṣe (1974: 61). The Novels of D.O. Fágúnwà, Ethiope Publishing Corporation, Benin City.
29. O.R. Dathorne (1965: 63), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulleting of the Assocaition for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
30. Ibid.
31. Movement for Progressive Nigerians (1978: 23), “Nigerian Women and the Revolution of the Nigerian People” Positive Review, No. 1, 1978.
32. Walter Norman May (1965: 44), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
33. Rev. Samuel Johnson (1921: 201), The History of the Yorubas, (ed.) O. Johnson, C.M.S. Bookshop, Lagos.
34. Walter Benjamin (1977: 34), ‘Understanding Brecht’ New Left Books, London.
35. Op. cit
36. Hilary Seymour (1983: 49), “Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood. A Seminar Paper Presented at the Department of Literature in English, University of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
37. Ibid.
38. Ibid., pg. 20
39. Ibid.
40. Walter Norman May (1965: 26), Op. cit.
41. Ibid.
42. Quoted from Hilary Seymour (1983: 21), Op. cit.
43. Kamene Okonjo (1976: 46), “Igbo Women and Community Politics”, in Women in Africa (eds.) N.J. Hafkin and E.G. Bay. Stanford: Stanford University Press.
44. R. George Horner (1971: 3), “Folklore as a Psychological Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
45. Op. cit.
46. Op. cit.
Àkọ́jo Orúkọ Ìwé
Ìwé Ìtàn Àròsọ
Adeoye, C.L. (1966), Ẹ̀dá Ọmọ Oòduà, Onílé Owó Press, Ìbàdàn (later by OUP, Ibadan, 1971).
Akinlade, K. (1971), Ta Ló Pa Ọmọ Ọba?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1971), Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnṣìkà, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Aṣenibánidárò, Macmillan, Lagos.
Akinlade, K. (1973), Ta Lolè Ajọ́mọgbé?, Macmillan, Lagos.
Akinlade, (1974), Alosi Ọlọ́gọ, Longman, Lagos.
Akinlade, (1976), Owó Ẹ̀jẹ̀, Oníbọn-òjé, Ìbàdàn.
Akinlade, (1976), Àgbákò Nílé Tẹ́tẹ́, Evans, Lagos.
Akintan, E.A. (1931), Ìgbẹ̀hìn Á Dùn, The Anchor.
Awoniyi, T.A. (1973). Ayékòótọ́, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Delanọ, I.O. (1955). Aiye Daiye Oyinbo, Thomas Nelson and Sons, London.
Delanọ, I.O. (1963), Lọ́jọ́ Ọjọ́ Un, Thomas Nelson and Sons, London.
Fadeṣere, P.I. (1978), Ajítòní, OUP, Ìbàdàn.
Fagunwa, D.O. (1938), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀, C.M.S. Nigeria Bookshops, Lagos (Later, by Thomas Nelson and Sons, London 1950).
Fagunwa, (1949), Igbó Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1949), Ìrèké Oníbùdó, Thomas Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1594), Ìrìnkèrìndò Nínú Igbó Elégbèje, Thoams Nelson and Sons, London.
Fagunwa, (1961), Àdììtú Olódùmarè, Thomas Nelson and Sons, London.
Faleti, A. (1969), Ọmọ Olókùn Ẹṣin, U.LP., Port Harcourt.
Fatanmi, D.A. (1967), Kórímálẹ Nínú Igbó Àdìmúlà, Thomas Nelson and Sons, London.
Ilara, Tunde (1977), Ẹ̀san Á Ké, Ladson International, Ilé-Ifẹ̀.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ó Le Kú, OUP, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ìgbà Èwe, UPL, Ìbàdàn.
Ìṣọ̀lá, A. (1974), Ogún Ọmọdé, UPL, Ìbàdàn.
Jẹbọda, Fẹ́mi (1964), Olówólaiyemọ, Longman, Lagos.
Ladele, T.A. (1971). Jẹ Ń Lògbà Tèmi, Macmillan, Lagos.
Ladele, T.A. (1978), Ìgbì Ayé Ń Yí, Longman, Lagos.
Ogundele, J.O., (1956), Èjigbẹ̀dẹ́ Lọ́nà Ìsánlú Ọ̀run, Longman, Lagos.
Ogundele, (1956), Ibú Olókun, University of London Press, London.
Ogunniran, L. (1972), Eégún Aláré, Macmillan, Lagos.
Okediji, O. (1969). Àjà Ló Lẹrù, Longman, Lagos.
Okediji, O. (1971), Àgbàlagbà Akàn, Longman, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1969), Kékeré Ẹkùn, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1973), Àyànmọ́, Macmillan, Lagos.
Ọlabimtan, A. (1978), Baba Rere, Macmillan, Lagos.
Owólabí, O. (1974), Orí Adé Kì í Sunta, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1947), Aiye Ree, Gaskiya Corporation, Zaria.
Oyedele, A. (1970), Ìwọ Ni, Macmillan, Lagos.
Oyedele, A. (1970), Kini Mo Ṣe? Macmillan, Lagos.
Ọdunjọ, J.F. (1964), Kúyẹ̀, AUP, Lagos.
Ọdunjọ, JLF. (1964), Ọmọ Òkú Ọ̀run, AUP, Lagos.
Ọdunjọ J.F. àti Ọladipupọ, A.B. (1967), Kádàrá àti Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀, Oníbọnòjé, Ìbàdàn.
Ọmọyajowo, J.A. (1957), Ìtàn Ọdẹ́níyà, Adégbàmí and Sons Press, Agbor.
Ọmọyajowo, J.A. (1961), Báyọ̀ Ajọ́mọgbé, Longman, Lagos.
Ṣobande, O.A. (1959), Rìgímọ̀ Obìnrin Kò e é Tú, Tìkà Toore Press, Lagos.
Yemitan, O. (1972), Gbọ́baníyì, O.U.P., Ìbàdàn.
Yemitan, O. (1980), Orúkọ Ló Yàtọ̀, UPL., Ìbàdàn.

Ìwé Àpilẹ̀kọ àti Ìwé Àtẹ̀jáde
Bamgboṣe, Ayọ̀ (1974), The Novels of D.O. Fagunwa, Ethiope Publishing Corporation, Benin City, Nigeria.
Barber, Karin (1979), “Sociology of Written Literature: Fagunwa and Okediji”, A Semianr Paper delviered at the Department of African Languages and Literatures, University of Ife, Nigeria on the March 9th, 1979.
Benjamin, Walter (1977), “Understanding Brecht”, New Left Books, London.
Bennet Tpny (1977), New Accents, Formalism and Marxism, Methuen and Co. Ltd., London.
Boa, E. and J.H. Reaid (1972), Critical Strategies, Edward Arnold Publishers Ltd., London.
Cabral, Amilcar (1969). Revolution in Guinea, Stage One, London.
Coker, Cheyney Syl (1973), Concerto for Exile, Heinemann, London.
Dada, P.O. (1980), “Marxist Criticism and African Literature”, Ganga, Vol. 2, No. 4.
Dathorne, O.R. (1965), “The African Novel – Document to Experiment”, Bulletin of the Association for African Literature in English, No. 3, November, 1965.
Eagleton, Terry (1977), Marxims and Literary Criticism, Methuen and Co. Ltd., London.
Echeruo, Michael J.C. (1967), “Robinson Crusoe, Purchase his Pilgrim and his Novel”, English Studies in Africa, Vol. 10, No. 2.
Goldman, Lucien (1975), “Dialectical Materialism and Literary History”, Toward a Sociology of The Novel, London, Tavistock.
Gutkind, Peter C.W. (1975), The View from Below: Political Consciousness of the Urban Poor in Ibadan, Centre for Devleoping-Area, McGill University.
Horner, George R. (1971), “Folklore as a Psycholgocial Projective System”, The Conch, Vol. 3, No. 1.
Ibitokun, Benedict M. (n.d.), “Revolt in Nigerian Novel: Kole Ọmọtọṣọ’s The Edifice, Sacrifice and The Scales. A Seminar Paper Delviered at the Department of African Languages and Literarues, University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Irele, Abiola (1977), “Study African Literature”. Nigerian Journal of Humanities, Vol. 1,. No. 1.
Ìṣọ̀lá, A. (1979), “Presenting Revolution in Ọmọ Olókùn Ẹsin”, A Seminar Paper Presented at the Department of African Languages and Literatures, Univeristy of Ifẹ, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria on 26th February, 1979.
Jackson, I.F. (1956), Advance in Africa, OUP, London.
Johnson, Rev. Samuel (1921), The History of the Yorubas, (ed.) Johnson, O., CMS Bookshop, Lagos.
Lowenthal, Leo (1957), Literature and the Image of Man, Boston, Mass.
Lukacs, George (1963), The Meaning of Contemporary Realism, Merlin Press, London.
My, Walter Norman (1965), Gem of Thought: Wisdom and Inspiration, Gift Edition Books Incorporation, Chicago.
Nazareth, Peter (1967), “A Committed Novel”, Transition, No. 29, Vol. 26(iv), Feb./March 1967.
Nkrumah, Kwame (1970), Class Struggle in Africa, International Publishers, New York.
Ogundipe-Leslie, Ọmọlara (1981), “A Marxist Reading of The  Interpreters”, A Seminar Paper Presented at the Department of Literature-in-English and Department of Philosophy Joint Seminar, Unviersity of Ibadan, Nigeria on March 25th, 1981.
Ogungbẹsan, Kọ́lá (1971), “Literature and Society in West Africa”, African Quarterly, xi, 3.
Okediji, F.O. and Ọla Ọpẹyẹmi (1967), “The Formation of New Elites in Tropical Africa: A Review Article”, ODU, Vol 4, No. 1.
Okonjo, Kamene (1976, “Igbo Women and Community Poltiics”, in Women in Africa (eds) Hafkin, N.J. and E.G. Bay, Stanford University Press, Stanford.
Oyesọsin, Ọba O.O. (1977), “Ipa àti Ipò tí àwọn Ọba Kó ní Ilẹ̀ Yorùbá: Láyé tijọ́ àti lóde ní”, Yorùbá Gbòde, Vol. 3, No. 4.
Seymour, Hlary (1983), Textual Silence: An Exploration of Patriarchy in Things Fall Apart and God’s Bits of Wood”, A Seminar Paper Presented at the Deparment of Literature-in-English, Univeristy of Ife, Nigeria on the 5th of May, 1983.
Shuking, L. (1944), The Sociology of Literary Taste, London.
Tressel, Robert (1965), The Ragged Trousered Philanthropists, with an introduction by Silitoe, Allan, Panther Paperback, Lawrence and Wishart Ltd., London.
Yai, O.B. (1977), “Ideas for a poltiical Reading of Fagunwa”, A Conference Paper Presented at the Orisha traditon, held at the University of Ife, Ile-Ife, Nigeria.
Zhdnov, Vladimir (1956), “Some Recent Soviet Studies in Literature”, Soviet Literature, No. 8, Moscow.

No comments:

Post a Comment