Sunday, 7 June 2015

ÈDÈ ABÍNIBÍ




N ò rẹ́ni tó fèdè elédè ronú rí
Àfi ti wa
Ẹ wo gbogbo àwọn ìlú ńlá
Àwọn ìlú kàǹkà-kàǹkà
Ní gbogbo ayé yíká kódà tée délẹ̀ẹ Kùsà                                            5
Irú èdè wo ni wọ́n fi ń kọ́mọ o jèe?
Èdèè-bílẹ̀ẹ wọn ni wọ́n ń lo
Wọ́n sì ti digi osè, wọ́n ti dàràbà
Ẹ wÀmẹ́ríka, ẹ wo Rọ́síà, kẹ́ẹ wáá wòlú Èèbó
Ẹ ó ri pédèe wọn ni wọ́n fi ń ronú    10
Ni wọ́n fi tóbi
Ṣùgbọ́n bíi tèmi tìrẹ kọ́
Ká tóó pèrò ní Yoòbá
Ká tóó yí i sÉèbó
Gbogbo tepotiyọ̀ inú ọ̀rọ̀                   15
Ti gbákúla
Bóo la ṣe lé fèdè elédè ronú jinlẹ̀
Wọ́n fọmọ ọdún mẹ́ta sílé ẹ̀kọ́
Pé ó máa kọ́ Faransé, ó máa kÉèbó
Ó ṣe, ọmọ gbọ́ Faransé díẹ̀, ó gbÉèbó díẹ̀                                           20
Torí pó jọ́mọ-ọn Yoòbà
Ó fi Yoòbá sàbùlàa wọn
Ọ̀rọ̀ di ṣákálá ṣokolo ṣòkòlò ṣákálá
Ó ń relé kò délé
Ó ń roko kò dóko                             25
Àfọ́o.̀fọ́tán ojú a sì dásọ̀ọ́lẹ̀
Àdàlú èdè a fa họ́wùhọ́wù dání
Ọmọ ò níí lè dánú olóódoó rò
Ohun a bá sọ fún un náà ní ó sọ padà bí ayékòótọ́
Ọmọ a délé                                30
A ní ‘Dádì, Yọ̀ bíládù fuù’
Kò kúkú gbọ́, kò yé e páà
Wọ́n ti ní bí wọ́n ṣe ń sọ
Sẹ́ni tó ṣe un tí ò dáa nù un
Ọmọ o sì mọ̀ péyìí yọ bàbá òun sílẹ̀  35
Bákan náà ni gbogbo èèyàn sorí lójúu wọn
Wọn a kẹ́yẹlé mádìyẹ bó ṣe wu wọ́n
Wọ́n a kó tẹrú tọmọ tìwọ̀fà pọ̀
Ṣé kò kúkú ságbà lọ́mọ ajá
Àkọbí ajá, abíkẹ́yìn nazà bẹ́ẹ̀                                               40
N náà ni awọn ọmọ naa yoo ṣe
Ajísebí Èkó, Èkó ní í kúú sí
Èyí tí ò yé wọn
Pọ̀ jèyí tó yé wọn lọ
N ò kúkú ráwọn ọmọ bá wí ńtiwọn  45
Ohun a fi kọ́ wọn ni wọ́n gbà
Wọ́n ní amúkùn-ún, ẹrù rẹ wọ́
Ó ni ẹẹ̀ wòsàlẹ̀
Mo ń bá ọ̀ ilé ìwé pàtàkì kan
Fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ ńjọ kan                  50
Ọ̀gá yìí kàwé a ò rírú ẹ̀ rì
Ìwé tó kà tó bàm̀bà bamba
Mo ní ‘Ọ̀gá, ẹ bá n parí òwe yìí
Ẹ dákun e fiyè dénú’
Mo ní                                                  55
‘Òní, àgbẹ̀ pọkọ́ mọ́
Ọla àgbẹ̀ pọkọ́ mọ́’
Wéré, ọ̀gá ti kó sí mi lẹ́nu
Ó lóun ti mọ̀yóókù
Kí n máà déènà pẹnu                         60
Ó ní 
‘Lọ́tùn-ún-ùn-la, àgbẹ̀ á gbọ́kọ́ ńbi ó fi pamọ́ sí
À bẹ́ ẹ̀ réèmọ̀, ẹyin èèyàn-àn mi
Èèmọ̀ lu kutu pẹ́bẹ́ tan
Ó tún lu pẹ̀bẹ́ pẹ̀lú ẹ                          65
Àgbàlagbà ló ṣe báun parí  òwe
Ta ni ò mọ̀ péparí òwe ùn ni pé
Ọjọ́ to.́kọ́ ó pàgbẹ̀ mọ́ ń bọ̀
Táriwó á sọ
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má fojú òpè wọ̀gá         70
Ọ̀pọ̀ ló ń pòwè Láwúwo
Tó ṣe bí gidi làwọn ń ṣe
Ẹní jìn sí kòtò
Ló dá lẹ́sẹ̀
Ẹní forí tì í dópìn-in                         75
Àfàìmọ̀ kó má daláàrúù
Nǹkan àrà gbáà
Ọmọ Yoòbá ò fálà fédèe rẹ̣̀ mọ́
Èdè tó ládùn tó yìí
Lẹ fọ́wọ́ òsì tì dànù                          80
Níbi orirí ti ń sunkún ilé
Tówìwí ń sunkún àtibọ̀ oko
Ibẹ̀ lẹ tit a wọn-n-le
Tèdè elédè
A wí tán                                    85
Wọ́n lédèe wa ò kún tó
Wọ́n lọ́sàn tó wọ̀ tí ò dùn
Bí ò kúkú wọ̀, ó tọ́
Kí làǹfààni olówó tí kò níyì?
Ẹ ṣé, a dúpẹ́                                     90
Ó tán n bó kù?
Ẹ máa pọ́nrọ́ ńbíbà
Ẹ máa pọ́n èdè elédè lé
Ẹ máa sọ tiyín di sáré-pẹgbẹ́
Ilé ẹni lèmí mọ̀ pọ́nà pẹ̀kun sí           95
Wọ́n ní sòkòtòo Yoòbà ò balẹ̀       
Wọ́n ní bá a gbá a létí
Tá a kàn án ńkòó
Tinú ẹ̀ ni yóò ṣe
Ẹ kú iṣẹ́                                             100
Ẹ̀̀yin lọlọ́gbọ́n, eẹyin lọmọ̀ràn          
‘Ọ̀mọ̀ràn tíi mọ tinú ìgbín nínú ìkarahun’
Wọ́n ní bá a bá ń fi Yoòbá kẹ́kọ̀ọ́
A ó ti ṣe pogo ọ̀rọ̀ tí ń bẹ ní sáyẹ́ǹsì?
A ó ti ṣe pọjíbírà àti jọmẹńtìrì?                   105
A ó ti ṣe pọọ́sínjìn?                          
A ó ti pe kábọńdaosàìdì?
Ti pai-áárú-sukuàdì ń kọ?
Ṣùgbọ́n gẹ̀gẹ̀ bí mo ṣ sọ ṣáájú
Èyí tí ò yée yín                        110
Pọ̀ jèyí tó yée yín lọ                        
Ó jọun pẹ́ ò mohun tédè jẹ
Ló jẹ́ ẹ mọ́ ọn sọ̀ yún-ùn
Àìmọ̀kan, àìmọ̀kàn                         
Ló kúkú n báayín-ín jà, o jàre 115
Ẹ ò mọ̀ pé
Bí gbogbo ọmọ káàárọ̀ o ò jíbí?
Bá pé báyìí la ó máa pé nǹkan-an wa
Òyìyẹ̀ tí ń yẹ̀ ẹ́ ò sí                        
Báyìí là ń ṣe ńlé wa                 120
Èèwọ̀ ibòmín-ìn
Bá a bá sọ pé
Báyìí la ó máa pọọ́síjìn
Tá a sì fún kábọ́ǹdàosàìdì
Tá ni yóò ya sùtì ètè                125
Tí ó sọ pé Ṣàngo wa ò pọnmọ-ọnre?
Ẹ tilẹ̀ sọ pé Yoòbá ò kún tó
Ǹjẹ́ èyín mọ̀ pé
Ṣe lèdè máa ń dàgbàá sí i                 
Ó dàbí aṣọ                               130
Tọ́kan gbó tá a mú mí-ìn
Ẹyin ti lọ sápótí ìṣúra
Kẹ́ ẹ wá à wọn èdè tẹ́ ẹ ti pa tì
Kẹ́ ẹ mú nínú-un wọn                     
Kẹ́ ẹ fi fáwọn nǹkan wọ̀nyí lóókọ tuntun             135
Bá a tilẹ̀ sì ta á bó tì
Kì ló sọ pé kí á má lọ sédè mí-ìn
Lọọ yá oókọ tá a ó máa pohun tuntun
Ká fara wọn mọlé
Púpọ̀ nínú Èèbó tí ẹ̀ ń wò un         140
Ara èdèe wọn kúkú kọ́ níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀
Mímú ni wọ́n mú láti ara èdèe Látín-ìn-nì, Gíríìkì àti Hébéérù
Kò sọ́rọ̀ Matimátíìkì kankan ni Èèbó
Tí kì í ṣèdèe Lárúbáwá ló ti wa     
Tá ni Lárúbáwá wáá sun mó jù nínú àwa àti Èèbó?      145
Bóo ni tèmi tìrẹ ti wáá jẹ́
Ọmọ ìyáà mi?
Ohun tí ò sì yée yín ni pé              
Ọ̀pọ̀ èdè ló sáà ti wọ tiwa
Tí kò sì ṣe wá ni háà!                        150
Bóyá o ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀
Bí ‘àlàáfíà’, ‘àlùbáríkà’ àti ‘dàńsíkí’
Tí wọ́n tinú Haúsá di ti wa             
N ò ṣẹ̀ṣẹ̀ lè sọ tÈèbó
Ìyún-ùn pọ̀ bíi kàasínǹkan                155
Kí ló dé tá a tẹpelẹ mọ́yìí
Ká fóhun gbogbo lórúkọ
Kó di ti wa?
Bóya ọ̀gọ̀rọ̀ èdè
Tó wà ńlẹ̀ẹ wa                160
Ló ń kọ yín lóminú
Pé bí Haúsá bá ń fi ti ẹ̀ kọ́mọ
Tí Íbò ń ṣe bákan náà                     
Ìgbà wo lọ̀rọ̀ọ wa
Ò ní í dàbí ilé gígaa Bábéélì?             165
Ìdáhùn síyún-ùn-ùn ò le, ọ̀rẹ́ẹ wa
Bóko ò jìnà, ilá kó tì
Orin tí kò ṣòro í dá                        
Kì í ṣòro í gbè
Bá a bá sọ pé ìsáǹsalùbọ́                  170
Pẹẹrẹpẹ sì lègbèe rẹ̀
Ìjà ò sí ńṣọ́ọ̀ṣì
Ṣàdúrà n ṣàmín ni                        
Bí Íbò bá ń fèdè abínibí kọ́mọ
A ó tún rọ̀ ọ́ kó dákun fiyè dénú                 175
Kó fọ̀kan nínú Haúsá tàbí Yoòbá
Kọ́mo náà pẹ̀lú
Bí Yoòbá bá ń lo tirẹ̀                      
A óò ní kó fi ọ̀kan
Nínú Haúsá tàbí Íbò kún un              180
Bá Haúsá náà sì ni
Yóò fi ọ̀kan nínúun
Yoòbá tàbí Íbò tì í                           
Kò ní í pẹ́, kò ní í jìnà
Tá a ó fi máa gbọ́raa wa                   185
Lágbòóyé
Ìyún-un ni pé
A fewé àdúgbò kàgbo ọmọ             
Gbogbo rẹ̀ a sì kú mùn-ún-ùn
Bí ojú tó ti kékeé fọ́                 190
Ṣé tójú bá ti kékeé fọ́
Ṣe ní í kú mọ̀ràn-ìn mọran-in
Ò̀rò wa a sìdayọ̀                  
À sì fọpẹ́  fÓlúwa
A kúkú mọ̀ pédèe wa è é jẹ́ bẹ́ẹ̀ 195
Àwa la tajà eèpẹ̀
Tá a ń gbowó òkúta
A kọ fìlà fún wèrè                         
Wèrè sì fẹ́ẹ́ lo fìlà gbó
N ò kúkú bá wọ́n wí                200
Àbí ta ni a ó gbọ́kọ́ fún
Tí ò ní í roko sọ́dọ̀ ara rẹ̀
Àṣá ló sì ń mádìyẹ waá sọ̀lẹ        
Òjò ló sì ń pàyèrèpè lọ́wọ́
Tó fi dẹni àkọlù             205
Kì í sì í rẹ̀gà títí
Kọ́mọ inú rẹ̀ má gbọ̀n lebelebe
Yóò balẹ̀ yóò balẹ̀                         
Ni labalaba fi ń wọgbóó lọ
Bí wọ́n ṣe ń dìrọ̀ mápáá tó                210
Apáa wọn ò kúkú ní í kápá
Bí wọ́n dìrọ̀ mọ́gi osè
Apáa wọn ò ní í kósè                   
Òjò iwájú ì í pahun
Tẹ̀yìn kìí pàgbín                                215
Gbogbo epe tí a bá ṣé lu Onítibí
Ara ní í fi í san
Ológbò o ní í fìgbà kan kúkú ìwọ̀sílẹ̀
Ìjímèrè ò ní í bá wọn kúkú ọ̀wọọwọ̀ọ́                                 
Èdèe Yorùbá ò ní í kú mó wa lójú              220
Ẹ dákun, ẹ ṣàmín ẹ̀.

No comments:

Post a Comment