Wednesday, 10 June 2015

Àtúnyẹ̀wò Arọ́pò-orúkọ nínú Ẹka-èdè Ifẹ̀






1.         Arọ́pò-orúkọ

Ohun tí a ó kọ́kọ́ ṣe àkíyèsí ni pé dípò ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ (Bamgbóṣé 1992: 36), arọ́pò-orúkọ ni a lò fún orí-ọ̀rọ̀ iṣẹ́ yìí. Ìdí tí a fi ṣe èyí ni pé a gba ohun tí Awóbùlúyì (2008: 206) sọ wí pé ìfọ̀rọ̀ṣòfò lásán ni ìlò ọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ nítorí pé kò sí ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó tún ní ìtumọ̀ rọ́pò-orúkọ nínú èdè Yorùbá. Nítorí ìdí èyí, tí a bá lo arọ́pò-orúkọ fún ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ nínú èdè Yorùbá, kò lè ní pọ́nna kankan[1].
A ó ṣe àkíyèsí pé a kò lè ṣe ohun tí a ṣe sí ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ lókè yìí sí ọ̀rọ̀-ìṣe, ọ̀rọ̀-orúkọ àti àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan mìíràn nínú èdè Yorùbá. Ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀-ìṣe ṣe àpẹẹrẹ. Tí a bá yọ ọ̀rọ̀ kúrò lára ọ̀rọ̀-ìṣe, yàtọ̀ sí pé ìṣe tí yóò kù kò níí ní ìtùmọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ìṣe, yóò tún ní ìtumọ̀ mìíràn nínú èdè Yorùbá.

2.         Arọ́pò afarajorúkọ
Nínú pépà yìí, a kò níí mẹ́nu ba arọ́pò afarajorúkọ[2] tí Awóbùlúyì (2008: 80) pè ní arọ́pò-orúkọ gígùn. Ìdí tí àwa fi lo arọ́pò-orúkọ àti arọ́pò afarajorúkọ nínú iṣẹ́ yìí ni pé nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, ó rọrùn láti fi arọ́pò-orúkọ gígùn àti kúkurú ya oríṣìí arọ́pò-orúkọ méjèèjì yìí sọ́tọ̀. Èyí kò ṣeé ṣe nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, sílébù kan ni arọ́pò-orúkọ kúkurú máa ń ní tí gígùn sì máa ń ní sílébù méjì. Ọ̀rọ̀ kò rí báyìí nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Nínú ẹ̀ka-èdè yìí, ọ̀kan nínú àwọn arọ́pò-orúkọ tí à bá pè ní arọ́pò-orúkọ kúkurú ní ju sílebù kan lọ. Ẹ wo àpẹẹrẹ (1).
(1)       a.         Ó ghí ìghán rà á
                        Ó ní àwọ́n rà á
            b.         O ghí ighán rà á
                        Ó ní wọ́n rà á
A ó ṣe àkíyèsí pé sílébù méjì méjì ni ìghan ‘àwọn’ àti ighán ‘wọ́n’ ní. Arọ́pò afarajorúkọ ni ìgbhan[3], arọ́pò-orúkọ sì ni ighán.
Yàtọ̀ sí àlàyé tí a ṣe lókè nípa ọ̀rọ̀-arọ́pò kúkurú àti gígùn yìí, àbá tí Awóbùlúyì (2008: 80) tún dá pé láti ara arọ́pò-orúkọ kúkurú ni a ti ṣẹ̀dá arọ́pò-orúkọ gígùn kò tẹ́ wa lọ́rùn tó. Àbá tí àwá fẹ́ẹ́ dá ni pé láti ara arọ́pò afarajorúkọ ni a ti ṣẹ̀dá arọ́pò-orúkọ. Àlàyé Awóbùlúyì ni pé àfòmọ́wájú aṣe-fáwẹ̀lì {ì} tí àwọn ẹ̀dà rẹ̀ jẹ́ /à-, è-, ẹ̀-, ì-, ò-/ ni a lò gẹ́gẹ́ bíi mọ́fíìmù àsọdorúkọ láti ṣẹ̀dá arọ́pò afarajorúkọ láti ara arọ́pò-orúkọ. Wàhálà tí irú àbá yìí yóò ní ni pé báwo ni a ó ṣe mọ ìgbà tí ó yẹ kí á lo ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí? Ìyẹn ni pé báwo ni a ó ṣe mọ̀ pé è- ni ó yẹ kí á fi mọ́ mi tí yóò fi di èmi àti pé à- ni a ó fi mọ́ wọn tí yóò fi di àwọn.
Tí a bá wo Awóbùlúyì (2008: 22), alàyé tí mó ń ṣe yìí yóò yé wa yékéyéké. Ní ojú ìwé yìí, Awóbùlúyì gbà pé ẹ̀dà {è-} ni é- àti ẹ̀-. Tí a bá lo è-, a lè ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ bíi ègé, èjó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tí a bá lo ẹ̀-, a lè ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ bíi ẹ̀kọ́, ẹ̀gbẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó rọrùn fún wa láti fi àrànmọ́ ṣàlàyé ohun tí ó ń wáyé nípa ìṣẹ̀dá ègé kí á sì fi àǹkóò fáwẹ̀lì ṣe àlàyé tí èjó. Irú àlàyé yìí kò ṣeé ṣe fún ọ̀nà tí Awóbùlúyì (2008: 80) sọ pé a ń gbà ṣẹ̀dá arọ́pò-orúkọ láti ara arọ́pò afarajorúkọ. Àlàyè àrànmọ́ ko seé ṣe bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rò pé àlàyé àǹkóò fáwẹ̀lì náà yóò ṣeé ṣe. Ní tiwa, ohun tí a rò ni pé arọ́pò afarajorúkọ gan-an ni ìpìlẹ̀ fún ìṣẹ̀dá arọ́pò-orúkọ. Ohun tí a kàn ṣe kí ìṣẹ̀dá yìí tó wáyé ni pé ń ṣe ni a pa àwọn fáwẹ̀lì tó bẹ̀rẹ̀ àwọn arọ́pò afarajorúkọ wọ̀nyí jẹ. Ìyẹn ni pé ìpajẹ à láti ara àwọn ni ó fún wa ní wọn.
Irú ìlànà tí a mẹ́nu bà yí ni àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń lò láti ṣẹdá baby-sit láti ara baby-sitter[4]àti edit láti ara editor[5]. Bamgbóṣé (1990: 126) ti ṣe àkíyèsí pé ìlànà yìí náà ni a lò láti ṣẹdá yìí láti ara èyí àti yẹn láti ara ìyẹn. Irú àbá yìí kan náà pàápàá ni Awóbùlúyì (1992: 27) fi ara mọ́ fún ìṣẹ̀dá arọ́pò-orúkọ láti ara ará arọ́pò afarajorúkọ.

3.         Arọ́pò-Orúkọ ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
Ara àwọn nǹkan tí mo sọ nínú Adéwọlé (1996: 57-58) ni wí pé:

(2)[6] the Ifẹ̀ singular pronoun has forms, the use of which depends on the tenseness or laxness of the vowel of the first full verb in the predicate which the pronoun immediately precedes. The lax vowels of the verbs which take mọ ‘I’ ọ ‘you’ and ọ́ ‘it/she/he’ are a, ẹ, ọ, an and ọn (as in mọ gbà ‘I accepted’, mọ ṣẹ̀ ‘I sinned’, mọ lọ ‘I went’, mọ yán ‘I yawned’, mọ pọn omi ‘I drew water’[7]) and the tense vowels which take mo ‘I’, o ‘you’ and ó it/she/he are e, i, o, u, in un (as in mo ṣé ‘I did it’, mo ri i saw him’ mo fò ‘I jumped’ mo bu ‘I abused him’ mo rín ‘I laughed’, mo sùn ‘I slept’[8]) (tiwa ni àmì àkámọ́).
Ẹ jẹ́ kí á wo àwọn gbólóhùn tó wà ní (3) àti (4)[9]:
(3)       a.         Mọ wẹ̀
                        Mo wẹ̀
            b.         Mọ lọ
                        Mo lọ
            d.         Mọ gbà
                        Mo gbà
(4)       a.         Mo ri
                        Mo rí i
            b.         Mo rù ú
                        Mo rù ú
            d.         Mo pè é
                        Mo pè é
            e.         Mo jo
                        Mo jó o[10]
Àkíyèsí tí mo wá ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí ni pé ọ̀rọ̀ kò rí báyìí. Lóòótọ́, gbogbo fáwẹ̀lì àìrámúpè ni kò ní àpẹẹrẹ-àfi sí àbá (2), àpẹẹrẹ-àfi àwọn fáwẹ̀lì àránmúpè pọ̀ díẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á wo àwọn àpẹẹrẹ (5)-(7):
(5)       a.         Ọ́ gbìn ín
                        Ọ́ gbìn ín
            b.         Ó gbin
                        Ó gbin
            d.         Mọ sín
                        Mo sín
            e.         Mo sín
                        Mo sin ín
            ẹ.         Ọ din
                        O dín in
(6)       Mọ[11] mọ̀
            Mo mọ̀
(7)       a.         Ó mu
                        Ó mú un
            b.         Ọ́ mú
                        Ó mu ún
            d.         Ọ́ kún
                        Ó kún
            e.         Ó kún
                        Ó kun ún[12]
Tí a bá wo àwọn àpẹẹrẹ (5) àti (7), a ó rí i pé fáwẹ̀lì àránmúpè in àti un ni àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe inú wọn ní. Tí a bá wo àbá tí ó wà ní (2), mo, ó tàbí ó ni arọ́pò-orúkọ tí ó yẹ kí ó ṣaájú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí. A tún wọn kọ sí ìsàlẹ̀ yìí ní (8a), (8b), (8d), (9a) àti (9b) ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé níbi tí (8) ti dúró fún àwọn àpẹẹrẹ (5) tí (9) sì dúró fún àwọn àpẹẹrẹ (7).
(8)       a.         Ọ́ gbìn ín
                        Ó gbìn ín
            b.         Mọ sín
                        Mo sín
            d.         Ọ din
                        O dín in
(9)       a.         Ọ́ mú
                        Ó mu ún
            b.         Ọ́ kún
                        Ó kún
A lè fẹ́ kọ́kọ́ rò pé ẹ̀ka-èdè yìí ń fagi lé àǹkóò fáwẹ̀lì nínú àwọn ìsọ kan nítorí àtiyẹ pọ́nna. Àlàyé yìí yóò fẹ́rẹ̀ lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí a bá wo (5d) àti (5e) tí a sì tún wo (7d) àti (7e) tí a tún kọ sí ìsàlẹ̀ yìí ní (10a), (10b), (11b) ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé níbi tí (10) ti dúró fún (7).
(10)     a.         Mọ sín
            Mo sín
b.         Mo sín
            Mo sin ín
(11)     a.         Ọ́ kún
            Ó kún
b.         Ó kún
            Ó kun ún
Tí a kò bá lo mọ ní (10a) kí á lo mo ni (10b), pọ́nna ìbá wà nínú àwọn gbólóhùn wọ̀nyí nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ohun tí à bá rí ni mo sín tàbí mọ sín fún àwọn méjèèjì nínú ẹ̀ka-èdè yìí. Bí a kò bá sì lo ọ́ ní (11a) kí á lo ó ní (11b), pọ́nna ìbá wà bákan náà. Ohun tí à bá rí náà ni ọ́ kún tàbí ó kún fún àwọn méjèèjì.
Láti lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé báyìí kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí, ẹ wo (12).
(12)     a.         Ọ́ dín dòdò, ọ́ din
                        Ó dín dòdò, ó dín in
            b.         Ọ́ dín owó ọjà, ọ́ din
                        Ó dín owó ọjà, ó dín in.
Tí a bá wo (12), a ó rí i pé ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ kò torí pọ́nna kí ó lo ọ́ níbì kan kí ó lo ó níbì kejì. A kò tún lè sọ pé torí pé àbọ̀ wà nínú gbólóhùn (10b) àti (11b) (bí a tilẹ̀ ti pa àbọ̀ yìí jẹ ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀) tí kò sì sí àbọ́ nínú gbólóhùn (10a) àti (11a) ni ó jẹ́ kí á lo mo àti ó ní (10b) àti (11b) ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé tí a sì lo mọ àti ọ́ ní (10a) àti (11a) ní síṣẹ̀-n-tẹ̀lé bákan náà. Àpẹẹrẹ (12) ta ko èyí nítorí pé àbọ̀ wà nínú gbólóhùn (10b) àti (11b), a lo mo àti ó, àbọ̀ sì wà nínú gbólóhùn méjèèjì tí ó wà ní (12), a sì lo ọ́.
Ọ̀nà mìíràn tí a tún lè gbà wo àwọn ìsọ tí a ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni pé kí a sọ pé kòbẹ́gbẹ́mu ni àwọn arọ́pò-orúkọ tí kò tẹ̀ lé àbá (2). Ohun tí kò jẹ́ kí a sọ eléyìí ni pé àpẹẹrẹ irú àwọn arọ́pò-orúkọ tí ó wùwà ṣégeṣege báyìí pọ̀ nínú ẹ̀ka-èdè yìí[13].
Àlàyé mìíràn tí a tún lè ṣe ni pé fáwẹ̀lì àránmúpè nìkan ni àbá (2) ń ṣiṣẹ́ fún wí pé kò ṣiṣẹ́ fún fáwẹ̀lì àránmúpè. Ìdí tí àlàyé yìí kò fi wúlò ni pé kìí ṣe gbogbo fáwẹ̀lì àránmúpè ló ń ṣe báyìí hùwà nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀[14]. Gbogbo ibi tí an àti ọn bá ti jẹ yọ ni àbá (2) dè.
Èmí rò pé àlàyé tí ó wúlò jù ni èyí tí Bámgbóṣé (1990: 29) ṣe pé àǹkóò fáwẹ̀lì ti ń kógbá sílé nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ohun tí a lè fi kún èyí ni pé kìí ṣe inú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá nìkan ni ìkógbásílé àǹkóò fáwẹ̀lì yìí tí ń ṣẹlẹ̀. Ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ bákan náà. Èyí ni ó fà á tí ìhùwàsí àǹkóò fáwẹ̀lì àwọn fáwẹ̀lì àránmú pè yìí ṣe ń ṣe ṣégeṣège.

4.         Ìgúnlẹ̀
Tí a bá gba ohun tí Crystal (1996: 7) sọ pé ‘each dialect - regional or standard – has its rules of grammar and meaning and children learn them at home, in the street, or in the school’ wọlé, a ó gbà pé ẹ̀ka-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá àti ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Inú àwọn méjèèjì ni àǹkóò fáwẹ̀lì ti ń kógbá sílé. Ohun tí ó wá ń ṣẹlẹ̀ ni pé ìkógbásílé àǹkóò fáwẹ̀lì ti inú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí kọjá ti ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá àti ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ yìí ni a ń pè ní àyípadà tí ó máa ń dé bá ẹ̀ka-èdè tí a ń kọ́ nínú lingúísíìkì ajẹmọ́tàn (historical linguistics). Lingúísíìkì ajẹmọ́tàn yìí ń fi yé wa pé àyípadà tí ó dé bá ẹ̀ka-èdè kan ti lè ré kọjá ti èkejì. Ní ti àǹkóò fáwẹ̀lì, àyípadà tó dé bá olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ti kọjà ti ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
 Ìlò àǹkóò fáwẹ̀lì nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá kò tó nǹkan. Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ tì ń lo àǹkóò fáwẹ̀lì nínú arọ́pò-orúkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n eléyìí náa ti ń ṣe ṣégeṣège. A kò sọ pé nínú gbogbo gírámà rẹ̀ ni àyípadà ti dé bá olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ju ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ lọ o. Tí a bá wo abala gírámà mìíràn, àyípadà tí ó ti dé bá ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ti lè kọjá ti olórí èka-èdè Yorùbá[15]. Ọ̀rọ̀ Doipohyne (1976: 15) ni a ó fi kádìí iṣẹ́ yìí, ó ní ‘differences... often reflect some of the changes that have taken place in the language over a period of time. In other words, dialect differences often provide us with the most direct evidence of the history of the language’.

Àkójọ Orúkọ Ìwé
Abraham, R.C. (1958), Dictionary of Modern Yorùbá. London: University of London.

Adéwọlé, L.O. (1996), ‘Ifẹ̀ Pronouns in Polylectal Grammar’, Journal of Nigerian Languages and Literatures 2: 56-63.

Adéwọlé, L.O. (1998), ‘Another Visit to the Yorùbá High Tone Syllable’, AAP53: 91-106.

Adéwọlé, L.O. (2005), A Bilingualized Dictionary of the Yorùbá Monosyllabic Words. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.

Awóbùlúyì, O. (1978), Essentials of Yorùbá Grammar. Ìbàdàn: UPL.
Awóbùlúyì, O. (1992), ‘Aspects of Contemporary Standard Yorùbá in Dialectological Perspective’, in New Findings in Yorùbá Studies, o.i. 1-79. Ibadan: Ọdúnjọ Memorial Lectures.

Awóbùlúyì, O. (2008), Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ Yorùbá. Ìbàdàn: UPL.
Crystal, D. (1996), ‘Slip of the Mother Tongue’, The Independent on Sunday (London), o.i. 7.

Diopohyne, F. (1976), ‘Dialect Differences and Historical Records in Akan’, Journal of Humanities 2: 15-27.

http://www.thefreedomdictionary.com/babysit. (Accessed on 22nd of June, 2011).
http://www.thefreedomdictionary.com/editing. (Accessed on 22nd of June, 2011).
Klavan, Judith L. (1980), ‘Approach to the Universal Theory of Clitics.’, PhD Dissertation, University of London.

Pulleyblank, D. (1986), ‘Clitics in Yorùbá, Syntax and Semantics 9: 43-64. New York: Academic Press.

Àsomọ́
An:
Ọ́ dán ‘It is smooth’, ọ́ gan lórí ‘He cuts off his head’, ọ́ gan ‘It becomes hardened (i.e. as of a loaf of bread)’, ọ́ gàn án ‘He despised him’, ọ́ han ‘He screamed’, ọ́ hàn ‘It is clear’, ọ́ han ‘He catches it’, ọ́ jàn mí nígi ‘He hit me with a stick’, ọ́ kángi mi ‘He snapped my sick’, ọ́ kan mi ‘It pained me’, ọ́ kàn án ‘He hammered it’, ọ́ nà án ‘He hit him’, ọ́ ran ‘He sew it’, ọ́ rànwú ‘He did spinning’, ọ́ ràn mi (lẹ́rù) ‘He helped me (with the load)’, ọ́ sán ‘It cracked’, ọ́ sanwó’ ‘He paid some money’, ọ́ sàn kò ó ‘He is well’, ọ́ sángbó ‘He cleared the bush’, ọ́ ṣàn ‘It flows (as of water)’, ọ́ tan m ‘He is related to him’, ọ́ tán ‘It is finished’, ọ́ tàn ‘He is stranded’, ọ́ yán ‘He yawned’, ọ́ yan ‘He swaggered along slowly’ ọ́ yàn mí ‘He chose me’.

In:
Àwọn tí ó ńjẹ yọ pọ̀
Ọ́ din ‘He fried it’, ọ́ fin ‘He sprayed it’, ọ́ gbinṣu ‘He planted yams’, ọ́ jìn ‘it is deep/it is far’, ọ́ kin lẹ́yìn ‘He scrubbed his back’, ọ́ ní owó ‘He has money’, ọ́ pin ‘He divided it’, ọ́ rìn ‘He walked’, ọ́ rin ‘It is moist’, ọ́ sín ‘He sneezes’, ọ́ sìn ín ‘He worshipped it’, ọ́ tin lẹ́sẹ̀ ‘His legs are thin’, ọ́ yin jẹ ‘He eats it in bits’, ọ yìn ín’ ‘He praised him’.
Àwọn tí ó ba o jẹ yọ
Ó gbin ‘He grunted’, ó mí ‘He breathed’, ó mì n ‘He swallowed it’, ó pin ‘It comes to an end’, ò rín ‘He smiled’.

ọn
ọ́ bọn (as of clothes) ‘It is no more new’, ọ́ fọn ká (ó fọ́n ọn ká) ‘He scattered them’, ọ́ fọ́n (ó fọn ọ́n) ‘He blew it’, ọ́ fọ̀n ọ́n ‘He took to his heels’, ọ́ gbọ́n ‘He is wise’, ọ́ ń gbọ̀n ‘He is shivering’, ọ́ mọ́ (ó mọ̀ ọn) ‘He built it’, ọ́ mọ́ ‘It is clean’, ọ́ mọ̀ ‘He knows’, ọ́ pọ́n ‘It is red’, ọ́ pọ́n (ó pọn ọ́n) ‘He drew it (as of water from a well), ọ́ pọ̀n ‘She mounted on her back’, ọ́ wọ́n ‘It is expensive’, ọ́ ń wọn ‘It is drizzling’, ọ wọ̀n ọ́n ‘He weighed it’.

un
Àwọn tí ó ba ọ jẹ yọ
ọ́ dùn mí ‘It pained me’, ọ́ dún ‘It sounds’, ọ́ fún mi ‘He gives it to me’, ọ́ fún ‘He blew it (as of a whistle)’, ọ́ gbun ‘It is curve’, ọ́ gbún mi ‘He triped me’, ọ́ kún ‘It is full’, ọ́ mú ‘He drinks it’, ọ́ n ún ‘He cleaned it’.
Àwọn tí ó o jẹ yọ
ó kún ‘He carved up its carcass’, ó m ‘He hid’, ó mu ‘He takes it’.



[1] Oríṣìí oro-orúkọ kan ni arọ́pò-orúkọ àti arọ́pò afarajorúkọ nínú Awóbùlúyì (1978: 12 àti 21).
[2] Tí a bá wo àlàyé tí a ṣe lókè nípa pé arọ́pò-orúkọ ni a ó lò dípò oro-arọ́pò-orúkọ, kò níí yà wá lẹ́nu láti rí i pé arọ́pò afarajorúkọ ni a lò dípò oro-arọ́pò afarajorúkọ nínú iṣẹ́ yìí. Àlàyé kan náà ni ó bá àwọn méjèèjì mu.
[3] Ìghan gan-an ni wọ́n ń lò fún àwọn ni ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Sílébù olóhùn òkè tí ó máa ń ṣaájú àpólà ìṣe lẹ́yìn àpólà orúkọ olùwà nínú gbólóhùn ni ó sọ ọ́ di ghán. Fún àlàyé lórí sílébù yìí, wo Bamgbóṣé (1990: 179-180).
[4] In th second type of back-formation, as seen in the case of baby-sit, first recorded in 1937, no misunderstanding is invovled. The agent noun baby-sitter with its – er suffix could have been derived from the verb baby-sit as diver  was from dive but evidence shows that the pattern was reversed and the agent noun (baby-sitter) precedes the v erb (baby-sit) from which it would normally have been derived (http://www.the freeictionary.com) (accessed on the 22nd of June, 2011).
[5] Edit is not the source of editor, as dive is of diver, the expected derivational pattern, rather, the reverse is the case. Edit in the sense ‘to prepare for publishig’, first recorded in 1793, comes from editor, first recorded in 1712 in the sense of ‘one who edits’ (http://www.the freedictionary.com) (accessed on the 22nd of June, 2011).
[6] Lóòótọ́, kò yẹ kí á fún àyọlò bí irú èyí ni nọ́ńbà ṣùgbọ́n nítorí pé a ó máa tọ́ka sí i lemọ́lemọ́ nínú iṣẹ́ yìí ni o jẹ́ kí á ṣe èyí.
[7] Mọ́ nìkan ni a lò fún àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí. A lè lo àwọn arọ́pò-orúkọ ẹyọ yòókù bákan náà, bí àpẹẹrẹ: gbà ‘you accepted’, ọ ṣẹ̀ ‘ you sinned’ ọ lọ ‘you went’ ọ yán ‘you yawned’, ọ pọn omi ‘you drew water’ and ọ́ gbà ‘he accepted’, ọ́ ṣẹ̀ ‘he sinned’, ọ́ lọ ‘he went’, ọ́ yán ‘he yawned’, ọ́ pọn omi he drew water’.
[8] ‘Mo’ nìkan ni a lò fún àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí. A lè lo àwọn arọ́pò-orúkọ ẹyọ yòókù bákan náà, bí àpẹẹrẹ: o ṣé ‘you did it’, o ri ‘you saw it’ o fò ‘you jumped’ o bu ‘you abused him’, o rín ‘you laughed’, o sùn ‘you slept’ and ó ṣe ‘he did it’, ó rí ‘he saw it’, ó fò ‘he jumped’, ó rín  ‘he laughed’, ó sùn ‘he slept.
[9] Ní (3) àti (4), gbólóhùn ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni ó wà ní òkè níwájú nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan gan-an. Gbólóhùn olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni ó wà nísalẹ̀ rẹ̀.
[10] Nínú gbólóhùn olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, a lè sọ pé Mo jó o tàbí Mo jo ṣùgbọ́n, nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, Mo jo  nìkan ni wọ́n máa ń sọ bí wọ́n tilẹ̀ ń rọra sọ̀rọ̀.
[11] Àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé ìbáṣepọ̀ wà láàrin arọ́pò-orúkọ bíi mo àti àwọn ẹ̀dà rẹ̀ bíi mọ. A ó rí i pé ara mọ kìí ṣe àránmúpè (nítorí ẹ̀dà mo ni ó sì fi àbùdá yìí jọ ọ́) bíi ti ara mọ̀ (tí kìí ṣe ẹ̀dà mo tí kò sì fi àbùdá jọ ọ́). A ó rántí pé àránmúpè ni ó yẹ kí àwọn fáwẹ̀lì tí ó bá tẹ̀lé kọ́ńsónáǹtì àránmúpè jẹ́, bí àpẹẹrẹ, mi, mu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdí tí ara arọ́pò-orúkọ mọ kò fi jẹ́ àránmúpè ni pé àtamọ́ ni arọ́pò-orúkọ nínú èdè Yorùbá. Wo Adéwọlé (1998), Klavan (1980) àti Pulleyblank (1986) fún àlàyé kíkún lórí àtamọ́.
[12] Èdè Gẹ̀ẹ́sì fún àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ni (5a) He planted it (5b) He grunted (5d) I sneezed (5e) I buried it (5ẹ) He fried it (6) I  know (7a) He took it (7b) He drank it (7d) It is full (7e) He carved up its carcass.
[13] N kò sọ pé kòbẹ́gbẹ́mu kò lè sí o. Ó máa ń wà nínú èdè dáadáa. Àpẹẹrẹ kòbẹ́gbẹ́mu kkan ni èyí tí Bamgbóṣé (1990: 124) fi hàn nípa kan àti àwọn òǹkà yòókù. Ní ti àwọn òǹkà yòókù, a lè rí oríṣìí wọn bíi méjì, méjèèjì, méjì méjì àti kejì; mẹ́ta, mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, mẹ́ta mẹ́ta àti kẹ́ta, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ti kan, ohun tí wà ni kan, kọ̀ọ̀kan àti kìíní. Kò sí ohun tí ó lè dúró ní ipò méjèèjì àti mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ìdí nì yí tí kan fi jẹ́ kọ̀bẹ́gbẹ́mu láàrin ẹgbẹ́ rẹ̀. 
[14] Wo àsomọ́ iṣẹ́ yìí fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpẹẹrẹ.
[15] Wo Adéwọlé (1996: 60-62) fún àwọn àpẹẹrẹ kan. Ó tún lè wo Adéwọlé (1999).

No comments:

Post a Comment