Ọjà-Ọba: Ojúde ààfin ọba ni ọjà yìí wà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ná ọja alaalẹ́.
Ìyan ńlá: Orúkọ òkè kan ní èyí ní ìlú Tedé, Orúkọ òkè yìí ni wọ́n
sì fi ń pè àdúgbò yìí.
Agb- ilé Gbẹ́nàgbẹ́nà: Irúfẹ́
iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n fi sọ ilé yìí lórúkọ. Igi gbígbẹ́ ni a mọ
àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà mmọ̀. Wọn a sì máa gbẹ́ odó iyan, àti ere
oríṣìíríṣìí. Ìdí nìyẹn tí wón fi ń pè ọ́ón ní gbẹ́gilére.
Ilé Ẹlẹ́gùn: Orúkọ Olóyè Ṣàngó ni wọ́n fi sọ ilé
yìí. Enì tí òòṣà bá gùn ní wọ́n ń sọ pé ̣̀ègùn gùn. Ìdí nìyí tí wọ́n fi
ń pè é ní ilé oní ẹ̀gùn Ṣàngó.
Òkè-Òdò: Odò kan tí ó n san láàrin ìlú ní àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ fi ń
pé ẹ̀gbẹ́ kejì ní òkè-Òdò.
Ná-Ján-n-ríre: Orúko ọjà kan ni wón fì sọ adùgbó yìí lórúkọ..
Agbo-ilé Ayángun: Orúko olóyè kan ní ìlú Tedé ni wón fì sọ
ilé yìí lórúọo
Agbo-ilé-Olóólà: Irúfẹ́ isé àwọn yìí ni wọ́n fi sọ
ilé yìí lórúkọ. Àwọn wọ̀nyìí ló máa ń kọlà ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti ilà abẹ́ fún àwọn
ènìyàn.
Ilé Àgòrò: Orúọo olóyè kan ni wón fi so ilé yìí lórúkọ. Òun ni ó sún
móọoba jù. Tí ọba bá ti wàjà, òun ni yóò máa múlé lọ́wọ́ títí wọn yóò fi
yan ọba mìíràn.
Ilé Ọ̀tún: Orúkọ olóyè kan náà ni wọ́n fi so
orúkọ ilé yìí.
Awùjà: Orúkọ odò kan tí ó tóbi tí ó sì dárogún ní ayé àtijọ ni
wọ́n fi sọ orúkọ àdúgbò yìí.
Ilé Babamogbà: Orúkọ olórí àwon oníṣàngó ni wọ́n
fi sọ ilé yìí. Mọgbà jẹ́ ọ̀kan nínú orúkọ oyè tí àwon oníṣàngó máa ń fí àwoọn
olóyè won je.
Agbo-ilé Gbélékalè: Agbo ilé yìí tóbi púọ̀ọ̀ ó sì ní ilé tí ó
pọ̀ tí ó sì lẹ́wà gidì. Ìdí nìyen tí wón fi ń pè é ní ilé gbélékalè
No comments:
Post a Comment