Sunday, 7 June 2015

Ìlòbùú: Adúgbò Díẹ̀


Agbo-ilé Gbọ́bamú:  Gẹ́gẹ́ bí itàn ṣe sọ, wọ́n ní àwọn ìdílé yìí jé igbákejì ọba wọ́n sì tún lè jọba. Ìdí nìyí yí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ilé Gbọ́bamú.

Agbo-ilé Akéyán:        Wọ́n ní àwọn ìdílé yìí fẹ́rán láti máa jẹ iyán púpọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ilé akéyán.

Agbo-ilé Jagun:           Àwon ìdílè jagunjagun ní àwọn ara ilé yìí. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fí ń pè wọ́n ní jagun olórò.

Agbo-ilé Baara  Olókúta:         Itan sọ pé òkúta ló wà ní àdúgbò yìí tẹ́lẹ̀ kí ó tó dí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kọ́lé síbeẹ̀. Kódà, àwọn okuta kọ̀ọ̀kàn sì wà yíkà agbo-ilé yìí títí di àsìkò yìí.

Agbo-ilé Akín-in-nú: Akín-in-nú gbangba ló ṣeé yan. Igbákeji ọba ni àwọn ìdílé yìí, Àyè púpọ̀ wà ní ojúde wọn tí ó fi àyè sílẹ̀ fún ènìyàn láti rìn bó ṣe wù ú pẹ̀lú ìròrùn. Ìdí nìyẹn tí wón fi ń pè wọ́n ní Akín-in nú gba  ṣeé yan.

Agbo-ilé Alápata:        Ìtàn sọ pé wọ́n ní egúngún kan ní ilé yìí tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí ó bá jáde ni ó máa ń gbé apata dání. Ìdí nìyẹn tí wón fi ń pè é ní ilé alápata.

Agbo-ilé Ajítàpèé:       Orúko eégún ìdílé yìí tí ó mọ̀-ọ́n jó gan-an ni wón fi sọ orúkọ ilé yií. Ìyen ni pé tí egúngún yìí bá ti ń jó a máa tàpá sókè, á sì máa jó bíi òkòtó. O ní òsó bíi ìpépé lára.

Agbo-ilé Òjáwúro:      Ìtàn sọ pé wón fẹ́ran láti máa gbin ewúro ní ilé yìí tí ó fi jẹ́ pé ibẹ̀ ni gbogbo àwọn ará ìlú ti máa ń já ewúro fi se ẹ̀gúsí.


Agbo-ilé Afolú:           Àwon ìdílé yìí fẹ̀ran láti máa fi olú jẹ iyán.

Agbo-ilé Ewé:             Wọ́n a máa gbin ewé èko ní ilé yìí ní ayé àtijọ́. Ìdí nìyen tí wón fi ń pè wọ́n ní ilé onílé Ewé.

No comments:

Post a Comment