ÌRAN KÌN-ÍN-NÍ
(NÍ
ÌDÍ MÒGÚN NÍ ÌLÚ ÒGÙDÙ)
(Iná tàn, a sì ri Òrìṣà Mògún. Wọ́n ti tẹ́
gbogbo ohun èlò ìbọ sí ìdi
òrìṣà náà. A
bẹ̀rẹ̀ sí níí gbọ́ orin àwọn olùsìn Mògún láti ẹ̀yin ìtàgé)
Orin: Mògún
o ṣé o, onílé orókè, a dúpẹ́ dúpẹ́. A kò jẹ́ fọ̀gẹ̀dẹ̀ n mọ́yán
rẹ, a kò jẹ́ fiṣu lásán bọ ẹ́ mọ́.
Bá wa gbékú lọ, kó o gbárùn lọ. Mògún onírè, baba, ìwọ la ó máa sìn o. (Igbà tí wọn yóò fi kọ orin dé ibí yìí,
àwọn olùsin Mògún ti ń yọ sí orí ìtàgé. Síbẹ̀ wọn kò dákẹ́ orin àti ijó)
Orin: Ajá
ńlá lo ń wá, a ó wá a, a ó fi ṣàwárí. Lákọlábo, ajá ńlá, lo ń fẹ́ tá a ó fi
ṣètùtù o, ètùtù owó, a ó ṣe ètùtù ọmọ. Wá, wá, wá, Mògún o, wá bá wa ṣaṣe
yọ́rí. Lónílé lálejò, ká má ṣe kábàmọ̀, gbọpẹ́ wa. Ìwọ la ó máa sìn o.(Ó jọún pé Mògún ti ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí
lóore gidi ni. Bí wọ́n ṣe ń tọ ni wọ́n ń fò bí olè tí ó gbé ọ̀kẹ́ ìyere
tí ó ṣe bí owó ni. Ó ṣe sá, Olùbọ dé, ó sì dá wọn ní mẹ́nu).
Olùbọ: Ó
tó (gbogbo won dákẹ́).A dúpẹ́
lọ́wọ́ Mògún pé a ṣe ọdún yìí, á ó ṣé ẹ̀ẹ̀míìn. Àbí, bá a bá ṣe ní
lóore ọpẹ́ káà á dá bí? Wọ́n ní ẹni tí a ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí a ṣe
elèyún-ùn níkà ni kò léèwọ̀. Ṣé òhun náà ni Yorúba rò pọ̀ tó fi sọ pé
ènìyàn yin-ni-yin-ni, kẹ́ni ṣèmíìn.
Àwọn Olùsìn: Ọpẹ́ náà la wá fi fún Mògún lónìí.
Olùbọ: Èmi
á dúpẹ́ tèmi, èmi á dúpẹ́ tèmi, tá a bá ṣeni lóore, ọpẹ́ là á dá o (ìlú sọ)
Àwọn
Olùsìn: Èmi á dúpẹ́ tèmi
Olùbọ:
Tá a bá ṣeni lóore, ọpẹ́ là á dá
o
Àwọn
Olùsìn: Èmi á dúpẹ́ tèmi
Olùbọ: Ò
tó. (Àwọn olùsin dákẹ́) Ọ̀rọ̀ mì ò
ní í pọ̀ lọ́jọ́ òní, àròyé mí dọjọ́ mìín, ọjọ́ ire, tórí ọpẹ́ ni mo
wá fi ọjọ́ òní dá bí mo ṣe sọ. Àdúà ni mo wá fọjọ́ òní gbà. Ṣe ni a kúkú
n kọbè sílẹ̀, Mògún ló mẹni tí yóò jẹṣu. A ti jẹ tọdún tó kọjá, a
dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá. A kì í da fíríì
ká má wàkè, méjèèjì la ti ṣe lọ́dún èsí, kò ṣe wá níhun páà, a fọpẹ́ fún
Mògún. Àmọ́, báwo lọdún tuntun yìí yóò ṣe rí? N náà la wá bèèrè. Bí ìṣẹ́gun
yóò tilẹ̀ wà, kì í ṣe láti ọwọ́ idà fúnra rẹ̀ bí kò ṣe láti ọwọ́ ẹni
tó mú un dání. Àwa sì nidà, Mògún ni jagunjagun tó mú wa dání, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Àwọn
Olùsìn: Bẹ́ẹ̀ ni
Olùbọ: Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, kí á tó bẹ̀̀rẹ̀ ìbọ tòní, Mògún náà la ó bi
léèrè bí
nǹkan yóò ṣe rí.
Àwọn
Olùsìn: Bẹ́ẹ̀ ni, o wíire
Olùbọ: (Ó kọjá sí ìdi Mògún. Ó mú obì ajóòópá
lọ́wọ́. Ó da obì ọwọ́ rẹ̀, obì fọre, ó fi ariwo bọnu) Mògún yè.
Àwọn
Olùsìn: Yèèè.
Olùbọ:
Mògún yèèèè.
Àwọn Olùsìn: Yèèèè (Ọkùnrin kan yọ
sí orí ìtàgé. Ó wọ aṣọ Òyìnbó ó sì dàpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tó dúró, ṣùgbọ́n
wọ́n ti rí i. Kíá, ìlú ti sọ, orin ti bẹ̀ṛẹ̀, ó jọun pé wón mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀
ni)
Orin:
Ẹni tá à ń wí, ó dé
Olówu Ògùdù, ó dé
Ẹni tá à ń wí, ó dé
Olùgbàlà wa, ó dé (Ní
wéréwéré, ijó ti bẹ̀rẹ̀, erukutu ń sọ làù. Ó ṣé, wọ́n tún yí ìlù àti orin
padà. Wọ́n ń sáré lu ìlú bí i wí pé ìdúrò kò sí, ìbẹ̀rẹ̀ kò sí)
Olówu ló wọ̀lú, ẹ fara balẹ̀
Olówu ló wọ̀lú, ẹ fara balẹ̀
(Ẹni tí wọ́n
ń kọ orin fún náà sọ̀rọ̀)
Olówu:
Olùbọ ò ò ò ò
Olùbọ: Olówu ò ò ò ò
(Àwọn méjèèjì gba ọwọ́ ológun kí Olówu tó mórin sẹ́nu)
Olówu: Iná Mògún jó rire ò
Àrìṣikà
Ìná Mògún jó rire ò
(Lóòótọ́, ọ̀sán ni wọ́n ń ṣe ìbọ Mògún yìí, síbẹ̀, wọ́n fi iná sí
ògùsọ̀)
Àwọn
Olùsìn: Iná Mògún jó rire ò
Àrìṣìkà
Ínà Mògún jó rire ò
Àrìṣìkà
Olówu: Ká jà ká bọ́ lọ́wọ́ ọlọ̀tẹ̀
Ká jà ká gbara wa lọ́wọ́ amẹ̀yà
Àwọn
Olùsìn: Iná Mògún jó rire ò
Àrìṣìkà
Iná Mògún jó rire o
(Olówu tún pa orin dà )
Olówu: Yẹ yẹ yẹ, màrìwò yẹ mọlẹ̀
Mo mẹ́yẹ rúbọ
Àwọn
Olùsìn: Yẹ yẹ yẹ, màrìwò yẹ mọlẹ̀,
yẹ yẹ
Olùbọ: (Ó tún yí orin padà)
Àwá dé, àwá dé, àwá dé
Onímògún o,
Àwá dé ò e e.
Àwọn
Olùsìn: Àwá dé, àwá dé, àwá dé
Onímògún ò, àwá dé ò e e.
Olùbọ: (Ó
dáwọ́ ijó dúró) Ó tó. Mògún yèè.
Àwọn
Olùsìn: Yèè
Olùbọ: Yèé a wí, Mògún mọ̀ gbọ́ ò,
Akin-ọ̀run
Àwọn Olùsìn: Yèé a wí, Mògún mọ̀ gbọ́ o, Akin-ọ̀run (Ayọ̀ abara tín-ń-tín. Ibi tí àwọn ènìyàn ti ń jó tí wọ́n ń yọ̀ yìí ni
àwọn ọlọ́pàá ti ya wọ inú agbo tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní í da agbo wọ́n rú. Ìgbà
tí wọ́n rí Olówu ni wọ́n mú ọ̀dọ̀ rẹ̀ pọ̀n)
Àwọn Olùsìn: (Wọ́n ń pariwo nígbà tí ọḷ̣pàá
ń nà wọ́n) Mo gbé o, ẹ gbà mí o, ìhà mí dá o, àyà mí fò lọ ò, èjìká mi ti
yẹ o, mo fọ́ lórí o. (Wéré, gbogbo wọ́n
ti fi aré bẹ́ ẹ. Ọmọdé kì í sáà rí ẹ̀rù kí ẹ̀rù má bà á. O wá ku Olówu àti
àwọn ọlọ́pàá nìkan).
Ọ̀gá
Ọlọ́pàá: Wọ́n ń wá ọ lágọ̀ọ́ wa
Olówu: Àwọn taa ni?
Ọlọ́pàá
kan: Nígbà tó o bá dé ọ̀hún.
Olówu:
Kí ni wọ́n ní mo ṣe?
Ọlọ́pàá
kan: Ṣé ìwọ yóò tilẹ sì dé ọ̀hún
ná
Olówu: Ìwé tí ẹ fi wá mú mi dà?
Ọ̀gá
Ọlọ́pàá: Òun nì yí (Ó fi ìwé hàn án)
(Olówu jọ̀wọ́
ara rẹ̀ fún wọn láti mú lọ. Bí wọ́n ṣe ń lọ ni iná ń kú díẹ̀díẹ̀ títí tí wọ́n
fi fi orí ìtàgé sílẹ́, iná sì kú tán pátá).
No comments:
Post a Comment