Èmi ò ní í fowó
ọ̀wọ́n rọjà ọ̀wọ́n
N ò ní í fohun
mo ní ṣohun ibi
Kọrọ má wáá
lọ dàbámọ̀ nígbẹ̀yìn
Kó má dihun à á
jeyín-ín sí
Ìbò kan, ìbò kàn
5
Tó wà lọ́wọ́ọ̀
mi yìí
Ojú ológbò ni, ó
ṣòroó kò lọ́jà
Torí náà ni n ó
ṣe fi gbẹ́ni tó dáa wọlé
Kó wọlé wáá ṣehun
rere fún mi
Ẹ̀kọ́ ń wù mí
bẹ́ẹ̀ n ò lówó 10
Mo ń wẹ́ni tí ó
firúu wọn kọ́ wa
Iṣẹ́ ń wù mí kò
sọ́nà
Ẹni tí ó gbọ́
ọ nì ń wá
N ríhun fibòò mi
ṣe lóore
Kórí máa fọ́ni 15
Ká relé aláwo
náwó gọbọi
Ìyẹn ò wù mí
Ọ̀fẹ́ lỌlọ́run
bùn a láfẹ́fẹ́
Ló bùn a lóòrùn
Ọ̀fẹ́ ló yẹ
kíjọbaa wa 20
Máa tọ́júu
gbogbo wa
Oúnjẹ sì tún ń
kọ́ ẹ̀wẹ̀?
Ọ̀gàjà
fọwọ́mẹ́kẹ́
Tó délée tálíkà
tó fàpò rọ̀
Ẹni tí ó sọ
oúnjẹ di gbẹ̀fẹ́ nì ń wá 25
Tí ó sọṣẹ́
àgbẹ̀ dihun iyì
Tí yóò sàn féku,
tí yóò sàn fẹ́yẹ
Àwọn ni n ó
fìbòò mi gbé wọlé
Èmi mẹ̀tọ́ọ̀ mi,
n ò ní í ṣì í lò
Ìwọ ń kọ́, ìwọ
àti ìwọ?
No comments:
Post a Comment