Friday, 26 June 2015

ÀKỌỌ́LẸ̀Ẹ YOÒBÁ



À bó ò gbọ́, àwé
Mo níre tó wà ńnú-unbi pọ̀
Ó kúrò ní wín- ńwín
Lóòótọ́ la mọ̀
Póyìnbó kó wa lẹ́rú, wọ́n kó wa singbà                         5
Ṣùgbọ́n tá a bá ń bá wọn wí náà
Ó yẹ á yìn wọ́n díẹ̀ o jàre
Fóhun ribiribi tí wọ́n ṣe fún wa
Àwọn ló fèdè kíkọ sílẹ̀ jí-nkíi wa
À bẹ́ ẹ̀ mọ̀ tẹ́lẹ̀?                         10
Tóri náà, ẹ má jẹ́ á pa gbogbo ẹyẹ
Tó ní hùruhùru lápá pọ̀ mádìyẹ
Adìyẹ kí i gbogbo wọn
Bóòrùn ti ń mú hanhan
Tó ń ní sánmọ̀ dúdú díẹ̀             15
Bẹ́ẹ̀ la réyìí tó ṣe wá lóore
Ńnú àwọn Èèbó
Èdè sì pọ̀ láyé rẹ rẹ rẹ
Tí è è tí ì di kíkọọ́lẹ̀
Ṣúgbọ́n a dúpẹ́, Yoòbá ti ń dàgbà nínú-un kíkọ               20
Ó ti ń digi àràbà nínú-un kíkà
Àwọn Èèbó ló sì ṣe ribiribi méje
Yàhàyà mẹfà
Láti rí i pé èyí kò forí sánpọ́n
Ó yẹ ká fọpẹ́ fúnjọ Sẹ́mẹẹ̀sì                          25
Tó ṣalábojútó ìkosílẹ̀ èdè yí
Ká dúpẹ́ lówọ́ọ Gómà
Ká fòòṣù bàǹbà fún Kíráódà
Ẹrú dúdú tó di Bíṣọ́ọ̀bù
Wọ́n ṣe é, a ò ní í gbàgbée wọn         30
Lóòótọ́, ó yéni, a sì mọ̀
Pé torí ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá
Ni wọ́n ṣe sèdèe wa di kíkọ sílẹ̀
Torí ẹ̀ ni mo ṣe sọ ṣáájú
Pé ire pọ̀ ńnú-unbi                            35
Ẹran tí a ó tà
Bíbọ́ là á bọ́ ọ                           
Nnú ìkòkò dúdú
Lẹ̀kọ funfun ringindin tií jáde
Wọ́n da ọ̀pọ̀ ohun ilẹ̀ wa láàmú                  40
A ò jiyàn
Ṣùgbón láìsí wọn, èdèe wa ha lè di kíkọ sílẹ̀ bí?                               
Èyí lohun à ń wí
Bí yóò sì di kíkọ sílẹ̀
Ńnú-un ká ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbìyànjú           45
Kò tí ì lè gbégi osè rù
Kò fàràbà dání                         
Èyí sì jẹ́ nǹkan pàtàkì
Tá a rí lóore tí wọ́n ṣe
N la ṣe ń kí wọn                                50
Pé wọ́n ṣé èyí ná

Òmíìn la à mọ̀
                                 
 

No comments:

Post a Comment