Friday, 12 June 2015

Ẹ WÁLÉ



  

A kì í rebi á má bọ̀.
A kì í regbè á má wálé
Bíkùn bá joko tán
Ikún á lọ
Iwọ yóò kó ire ilẹ̀ yìí lọ ilẹ̀ ibòmíìn lọ̀ ọ́ gbádùn                       5
N kò rò pépè àlejò nù un
Ẹ̀yin èèyàn-an wa
Tí ń bẹ lókè òkun
E dákun ẹ wálé                            10
Ẹni tó rèlú Èèbó
Èyí tó wà lÁmẹ́ríkà
Ti Pàn-àn-yán-àn, ti Potogí
Èyí tó wà ní Jámánì
Ti Rọ́síà
Kí wọ́n fetí ségbèe wa                       15
Ilé oníle kò jọlé ẹni
Bọ́mọdé bá pẹ́ lóko
Yóò gbóhùnkóhùn
Ìbòòsí iléè mi, iléè mi
Leyẹ ń ké
Ẹ dákun ̣ẹ máa bọ̀                             20
Kẹ́ ẹ jẹ́ á wáá
Gbórílẹ̀ èdèe wa yí gẹ̀gẹ̀
Ká agbé e gẹ̀gẹ́
Kó lè dé bi ó yẹ ó dé lágbáláayé
Wọ́n ni àgbájọ ọwọ́ lafi ń sọ̀yà       25
Ẹ dákun ẹ máa bọ
Ọmọ ẹni ò níí ṣèdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀
Ká fi ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíìn
Bílẹ̀ẹ̀ wa yìí ò tílẹ̀ dáa tó
Àwa náà la ó túnlẹ̀ẹ wa ṣe              30
Ọmọ àlè ní í fọwọ́ òsì júweleé bàbá rẹ̀
Ó kì í ṣọmọ àlè
Èmi náà kì í ṣọmọ àlè
Ẹ dákun, ẹ máa bọ̀
Mo gbọ́ pó o ti kàwé bàǹbà              35
O gboyèe dókítà
Dákun wáá bá wa tọ́jú àwọn èèyàn-an wa
Afárá ń bẹ ńlẹ̀ tẹ́-nginíà ó ṣe
Sòfíọ̀ ò kùtà, lọ́ọ́yà ò ní í wáṣẹ́ tì
E jẹ́ kí ilọsíwájú orílẹ̀ èdè yìí jẹ wá lógún    40
Ọlórun jẹ́ á kérè oko délé ni mo gbọ́ rí
Ẹ dákun ẹ fi ṣèwà hù
Pẹ́yin lẹ jìyà
Tẹ́ ẹ ṣíṣẹ̀ẹ́
Tẹ́ ẹ fi ránraa yin nílé ẹ̀kọ́                 45
Ojú ò fẹ́rú ẹ̀ kù rí
Bẹ́ẹ̀ náà níí ṣeé rí fún àwọn òpìlẹ̀sẹ̀ nǹkan-anre
Ẹ dákan ẹ wálé
Nítorí ìkúnlẹ̀ abiyamọ
Nàìjíríà ń pè yín                             
                        
                          

No comments:

Post a Comment