Bó o ló ò wẹgbẹ́ẹ wa
Àwa náà ò toríì rẹ bọ̀gún
O ò wẹgbẹ́ẹ wa
Àwa náà ò toríì rẹ bọ̀gún
Ìṣ̣ẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀ nísàlẹ̀ ìyín 5
Tó tóhun à á déléé wí
Ẹgbẹ́ẹ wa tá a ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí
náà ni
Ẹgbẹ́ẹ ká ṣòfin láàárọ̀, ká tú u lálẹ́
À bíwọ ò rófin má ta wóróbo lójúu
títì
Nígboro Èkó tí wọ́n ṣe ńjọ́sí
10
Òórọ̀ ni wọ́n ṣe é, ọ̀sán la fìdí ẹ̀
gúnlẹ̀
Ó bùṣe, wọ́n ní á má mu ṣa-n-péè
O ò wálé àwa o wáá gbàkan o fi yọnu
Ti léèsì tí wọ́n sọ ńjọ́sí ló pa mí lẹ́rìn-ín
Èmi ọmọ ọlọ́mọ kí ni mo tíì ṣe 15
Ṣe ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi léèsìí dá pátá
Wọ́n
ní á má ta púùlù, ẹ̀rín pa mí títí
Ṣé téyìí tá à á ṣe bá tán
Èyí tá
a kìí ṣe náà kó má jáàfara
To rọ́gbọ́n è é tán láyé ká wá a lọọ̀run 20
N la ṣe ń gba tẹ́tẹ́ wa látilẹ̀ẹ
Bẹ̀nẹ̀
Tá a ń ta nílẹ̀ẹ tàwa
Má fọ́lé kò kàn wá
Má fipá jalè kèé ṣofin-in tiwa
Àwa là ń sorí ọmọ dorí àá
gbọ́ṣẹẹ́ lé 25
Igbó là wa fi ń sorín-ín rùn lóòórọ̀ ní
kùtù
Ká kówó ilẹ̀ẹ wa relẹ̀ òkèèrè fàà ni.
Ọwọ́ kúdúrú la fi ń gbani síṣẹ́
Mẹ̀kúnù jẹun kò jẹ́un, wàhálàa rẹ̀
Ká wa sá
ti gun pílẹ́sọ̀ 30
Bòrìṣà bá tilẹ̀ ń gbe gbogbo èèyàn
Ta ni yóò ké àgòyà fúnrú àwa
Àwa labínú kání
Wọ́n ní a ò lè bínú kálẹ̀
Ẹ fi wáàlẹ̀
35
Ẹgbẹ́ yìí
Ẹgbẹ́ tó gbayì tó gbẹ̀yẹ ni
N náà ni mo ṣe máa ń sọ
Nígbà gbogbo pé
Bó o ló ò wẹgbẹ́ẹ wa 40
Àwa náà ò toríì rẹ bọ̀gún
O ò wẹgbẹ́ẹ wa
Àwa náà ò toríì rẹ bọ̀gún
No comments:
Post a Comment