Monday, 22 June 2015

ÀGBẸ́KỌYÀ




Ọ̀rọ̀ ǹ bá rò n tó mẹ́fọ̀ọ́ rò
Ẹ̀fọ́ ǹ bá rò n tó fori sẹ́nu
Ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀ níjọ́ọ̀jọ́sí tó dàbí àná
Ọ̀ṣọ́ọ̀sì laya Ògún témìí mọ̀
Ṣangó ló bá wa fỌya ṣaya                5
Ológun ló ń ṣọkọ gbogbo wa
Àwọn ló ń daríi wa nígbà ọ̀rọ̀ ṣẹ̀
Ohun tó dájàngbọ̀n sílẹ̀ kúrò ní bíńtín
Irú ẹ̀ ti ń dájàálẹ̀, òná ti jìn
Ó dájà púpọ̀ sílẹ̀, ọ̀ná na                            10
À bó o gbàgbé ogun àwọn obìnrin ìlú Abá ?
O gbàgbé ìjàngbọ̀n òde Ìṣẹ́yìn?
Ọkàn rẹ fo ti Abẹ́òkúta ni n dan?
Ohun tó dá gbogbo èyí sílẹ̀ náà là ń pè lówóorí
Ṣé àparò ni kìí fún ni láyà tíí gbàna lọ́wọ́ ẹni                            15
Tìjọba ò rí bẹ́ẹ̀
Wọ́n lẹ́ni fẹ́ẹ́ jẹyin awó á ṣawo
Ẹni fẹ́ẹ́ rin títì aláró gbọ́dọ̀ mú ṣílè sílẹ̀
Ẹni fẹ́ẹ́ mumi ẹ̀rọ gbọ́dọ̀ fowó ṣọwọ́
Ẹni ń fóṣùpá àtọwọ́dá láàrin ọ̀gànjọ́  20
Kó yáa fajé ránṣẹ́ sí wọn
Torí a ò lè jèkuru jàkàrà tán
Ká má fohùn eégún bọnu
Èyí sọ̀rọ̀ èèwọ̀
Ẹni fẹ́ẹ́ jẹun dan-indan-in kó yára múra dan-indan-in ni                              25
Èyí náà nìjọba fi sọ pẹ́ni tí yóò gbádùn àwọn nǹkan wọ̀nyí
Gbọ́dọ̀ sanwóo wọn bó ó ṣe tìpátìle
Torí dandan lowó orí
Ọ̀ràn-an-yàn laṣọ ìbora
Ṣùgbọ́n ojú táwọn àgbẹ̀ fi wọ̀rọ̀ yìí ṣèyàtọ̀                      30
À bóò mọ̀ pọ́rọ̀ àgbẹ́kọ̀yà ni mò ń sọ ni?
Àgbẹ́kọ̀yà tó ṣẹ̀ ńlẹ̀ yìí
Tó tàn ká bí iṣuu dàgí
Tó farun iwájú ará ilé mọ́ tará oko
A ti ń gbọ́rọ̀ nípa ìjà tẹ́lẹ̀ ri                           35
Ṣùgbọ́n ìjà èyí yàtọ̀
Kódà, ó yàjọrá
Ní tAbá, gbogbo wọn ni wọ́n ní wọ́n ṣe fẹ́ẹ́ pínwó orí fábo
Ní tAbẹ́òkúta ẹ̀wẹ̀
“N ó ṣe sanwó orí tólúwatrnwgbo wo
n   gbàdá e wà ni   bùn mi, orí tólúwa bùn-ùnyàn”                           40
Ṣùgbọ́n tàgbékọ̀yà yàtọ̀ díẹ̀ séyìí
Torí páwa là ń ṣèjọba araa wa
Yàtọ̀ sÉèbó tí ń ṣèjọba nígbà tàwọn tàkọ́kọ́
Èé wa ti wáá jẹ́?                      
Emi ló fa sábàbí?                      45
Gbàwọ̀sí-n-ò-gbàwọ̀sí ló dá wàhálà sílẹ̀
Ìjọba lówó kéré, ẹ dákun ẹ gbanwọ́ sí i
Àgbẹ̀ léyìí kàmọ̀mọ̀, ẹ dákun ẹ bù ńbẹ̀
Wàràwéré, ọ̀rọ̀ dìjà, ó dìpáǹle
Alápó ń gbápó, ọlọ́fà ń gbọ́fà            50
Ń ṣe lèèyàn tó níyàá jókòó sílé
Ẹni tó ní baba ló ń bá wọn-ọ́n lọ
Igbó yìí kọjá igbó ọ̀dájú, ọ̀rọ́ pọ̀
Àwọn téjìẹ mú lọ́, wọ́n ò níye
Àwọn tálùbúńtù pa ò lóǹkà               55
Ǹjẹ́́ ta là bá rí báwí, ẹ̀yin èèyàn-an wa?
Agbẹ́jọ́ apá kan dá ni wọ́n pè lágbà òṣìkà
Ọ̀rọ̀ ló wà ńlẹ̀ yìí, n gbọ́, kí lo rí sọ?
Ohun témìí rí ńbẹ̀ ò pọ̀, àwọn méjèèjì ló lẹ̀bi
Ǹjẹ́ ẹ̀yin àgbẹ̀ ọ̀rọ̀ kan yín                   60
Tíyín ni mo kọ́ fẹ́ẹ́ gbá mú
Torí ẹ fẹ́ẹ́ jori jata, ẹ̀ẹ́ lówóó san
Ẹ fẹ́ẹ́ dédìí ọ̀pẹ kẹ́ ẹ gbẹ́nu sókè
Ọ̀fẹ́ níí ro?                                
Títì ọlọ́dà tó dókoo yín, ọ̀run ló ti wá?                           65
Iná tí ń ṣẹ́jú wàìwàì lálẹ́, ẹ ṣe bóso ni?
Torí náà, ẹ̀ bá rọ̀rọ̀ wò
Pẹ́ni tí ó jẹ̀fà á ṣe wàhálà ìfà
Ẹní fẹ́ kó dára, á gbọnwọ́ sí i ni
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ìjọba náà ó kù díẹ̀ káàtó      70
Orí bíbẹ́ kọ́ loògùn iná orí
Bọ́rọ̀ bá tún ṣe bí èyí dìjà lọ́jọ́ iwájú
Sùúrù sòkúta jiná tẹ́ ẹ̀ bá mọ̀
Àlàyé ló yẹ ẹ kó sóríi rédíò àti tẹ́lì
Pówó orí ò lọ sápò ẹnì kan
Àǹfààní ará ìlú ló wà fún tẹ́ ẹ̀ bá mọ̀   

No comments:

Post a Comment