Wọ́n ń tàpá lókùn-un, wọ́n ń tàkìtì lọ́sà
Ìbẹ̀mbẹ́ ń ró, ìlù ń dún kìì, ọlọ́mọlé
ò dáwọ́ ró
Bàtá ń ṣe bátabàta, mo ń gbọ́ dùndún,
mo ń gbọ́yáàlù
Níbii wọ́n ń ṣàjoyọ̀ nílée wọn
Olóòlù gbápóló orí méjì rù sẹ́yìn 5
Ẹ̀jẹ́ wẹrí, ẹ̀jẹ́ wẹrùn, ojú pọ́n koko,
kò fọ́
Àwọn ọdẹ kò ṣàìkó tapó mọ́ tapò
Tó wọnú agbọ̀n tó dìpà ọdẹ
Wọ́n ń ṣèrántí araa wọn
Ẹni tó rí i pẹ́ran tà lọ́run, tó wẹ́ran
lọ 10
Ìsàlẹ̀ tí mo wò, ọ̀tọ̀ nihun mo rí
Àwọn ọmọ ìmàrò kan nàró
Àwọ́n kan jókòó sídìí dùùrù
Àwọn kan ń ta gìtá
Àwọn kan ń funpè 15
Orin-in kiriyó ní ń bẹ lẹ́nu-un wọn
Ijó kọ́ làwọn tó nàró ń jó, iṣẹ́ ni
wọ́n ń pè
Tí wọ́n ń peṣẹ́ bí ẹni ń rogun
Ìrònú di méjì n ò mèyí mà ṣe
Ìbẹ̀mbẹ́ ń kù bí òjò, dùùrú ń kọrin 20
O ò sì wáá là mí lọ́yẹ̀, ọ̀rẹ́ẹ wa
Èyí mà ga!
No comments:
Post a Comment