Friday, 15 May 2015

F-O: Yoruba Monosyllabic Words (English-Yorùbá)



Ff

fade: (i) ‘tí’ It has faded (Ó ti tí) (ii) ‘ṣá’ This cloth has faded (Aṣọ yìí ti ṣá) (iii) ‘sì’ The clothes have faded (Aṣọ náà ti sì).
fair: ‘tọ́’ It is not fair that he has five mangoes and I have three (Kò tọ́ kí ó ní máńgòrò márùn-ún kí èmi ní mẹ́ta).
fall: (i) ‘jìn’ He fell into a deep pit (Ó jìn sí kòtò) (ii) ‘ká’ His tooth fell out (Ẹyín rẹ̀ ká) (iii) ‘já’ He fell from the tree (Ó já láti orí igi); ‘já’ The fruit fell off the tree (Èso náà já ní orí igi) (iv) ‘wọ̀’ The fruit fell off the tree (Èso náà wọ̀ (sílẹ̀) (láti orí igi)) (v) ‘rọ̀’ Rain was falling steadily (Òjò ń rọ̀ láìmọ́wọ́ró).
fancy: ‘rò’ I fancied I heard someone entering the house (Mo rò pé mo gbọ́ tí ẹnìkan ń wọ inú ilé náà).
far: (i) ‘jìn’ The place is far (Ibẹ̀ jìn) (ii) ‘lọ’ He is far better than me in drawing (Ó dára jù mí lọ nínú àwòrán yíyà).
fascinate: ‘wù’ The town fascinates him (Ìlú náà wù ú).
fast: ‘yá’ My watch was 20 minutes fast (Aago mi fi ogún ìṣẹ́jú yá).
fasten: (i) ‘tì’ She has fastened the door (Ó ti ti ilẹ̀kùn) (ii) ‘dè’ He has fastened his coat (Ó ti de kóòtù rẹ̀).
feed: (i) ‘nù’ He is feeding the baby (Ó ń nu ọmọ náà) (ii) ‘bọ̀’ He fed the child (Ó bọ́ ọmọ náà) (iii) ‘rọ̀’ She fed her baby (Ó rọ ọmọ rẹ̀).
feel: (i) ‘bà’ I feel afraid (Ẹ̀rù ń bà mí) (ii) ‘mú’ I feel cold (Òtútù mú mi) (iii) ‘rò’ He felt he could have done a better work (Ó rò pé òun ìbá ti ṣe iṣẹ́ tí ó dára ju ìyẹn lọ).
ferment: ‘bà’ The cocoa has fermented (Kòkó náà ti bà)
fester: ‘kẹ̀’ His sore has festered (Egbò rẹ̀ ti kẹ̀)
fetch: ‘pọn’ He fetched a bucket of water from the river (Ó pọn péèlì omi kan láti inú odò).
fierce: (i) ‘le’ Tigers are fierce (Àwọn ẹkùn máa ń le) (ii) ‘mú’ In the afternoon, sun is fierce (Oòrùn máa ń mú ní ọ̀sán).
fight: ‘jà’ They fought (Wọ́n jà).
file: (i) ‘ha’ He is filing his nail (Ó ń ha èékánná rẹ̀) (ii) ‘pọ́n’ He is filing the cutlass (Ó ń pọ́n àdá rẹ̀).
fill: (i) ‘kún’ He filled the bucket with water (Ó pọn omi kún inú péèlì náà) (ii) filter: ‘sẹ́’ They filter water before they drink it (Wọ́n sẹ́ omi náà kí wọn tó mu uń)
find: (i) ‘bá’ He found himself in my presence (Ó bá ara rẹ̀ níwájú mi) (ii) ‘já’ He found out my lie (Irọ́ mi já) (iii) ‘já’ He found out my lie (Ó já irọ́ mi) (iv) ‘rí’ You can find your country in an atlas (O lè rí ìlú rẹ nínú atíláàsì) (v) ‘mọ̀’ We found our way here without difficulty (A mọ ọ̀nà débí láìníṣòro) (vi) ‘kọ́’ They found out something about leaves (Wọ́n kọ́ nǹkan nípa ewé) (vii) ‘já’ After a long walk in the forest, he found out the way to the school (Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìrìn nínú igbó, ó já ọnà ilé-ẹ̀kọ́).
first: (i) ‘kọ́’ I am the first to complete it (Èmi ni ó kọ́ ṣe é tán) (ii) ‘ná’ I must finish this work first (Mo gbọ́dọ̀ parí iṣẹ́ yìí ná).
fit: ‘yá’ He is feeling fit again after his illness (Lẹ́yìn àìsàn tí ó ṣe é, ara rẹ̀ ti ń yá) (ii) ‘yẹ’ This food is not fit for me (Oúnjẹ yìí kò yẹ mí) (iii) ‘so’ He fitted a telephone in my house (Ó so tẹlifóònù sí inú ilé mi).
fix: (i) ‘kàn’ He fixed a picture to the wall (Ó kan àwòrán mọ́ ara ògiri) (ii) ‘mú’ We have fixed a date for our harvest (A ti mú ọjọ́ ìkórè wa).
flake: ‘ṣí’ That paint flake off the wall (Ọ̀dà náà ṣí kúrò lára ògiri).
flame: ‘jó’ The house was in flame (Ilé náà ń jó).
flash: ‘kọ’ The lightning flashed (Mọ̀nọ̀mọ́ná kọ) (ii) ‘tàn’ She flashed a light in my eyes (Ó tan iná sí mi lójú) (iii) ‘sá’ The car flashed past (Káà náà sá kọjá).
flat: (i) ‘tẹ́’ The land is flat (Ilẹ̀ náà tẹ́) (ii) ‘jò’ The car’s tyre is flat (Táyà káà náà jò).
flatter: ‘pọ́n’ He flattered him (Ó pọ́n ọn).
flee: (i) ‘họ’ He fled (from fear) (Ó họ) (ii) ‘sá’ The dog flee from us (Ajá náà sá fún wa).
flexible: ‘lẹ̀’ This stick is flexible (Igi yìí lẹ̀)
flick: ‘yán’ He flicked me with a stick (Ó yán mi lọ́pàá).
float: ‘fó’ It floated on the river (Ó fó lórí omi).
flock: ‘dà’ They flocked past (Wọ́n dà yọyọ lọ).
flood: ‘ya’ The river rose and flooded the field (Odò náà kún ó sì ya wọ orí pápá).
flop: ‘wó’ I flopped onto the bed (Mo wó sí orí bẹ́ẹ̀dì/Mo wó lu bẹ́ẹ̀dì).
flourish: ‘gbọ̀’ Vegetable flourishes in this earth (Ilẹ̀ yìí gbọ ẹ̀fọ́).
flow: (i) ‘ṣàn’ The water flows (Omi náà ń ṣàn) (ii) ‘fẹ́’ Air flowed into the room when he opened the window (Atẹ́gùn fẹ́ wọ inú yàrá náà nígbà tí ó ṣí fèrèsé) (ii) ‘wọ́’ The crowd of people flow into the building (Àwọn èrò wọ́ wọ inú ilé).
fluent: ‘yọ̀’ He is very fluent (Ẹnu rẹ̀ yọ̀).
fly: (i) ‘fò’ The bird flew (Ẹyẹ náà fò) (ii) ‘sá’ She flew out of the house (Ó sá jáde nínú ilé náà).
fold: (i) ‘ká’ He folded his umbrella (Ó ká agboòrùn rẹ̀) (ii) ‘ṣẹ́’ I folded the cloth into two equal parts (Mo ṣẹ́ aṣọ náà sí méjì ọgbọọgba).
follow: (i) ‘tọ̀’ He followed this road (Ó tọ ọ̀nà yìí) (ii) ‘gbà’ I followed the left path (Mo gba apá òsì) (iii) ‘yé’ He didn’t follow what the teacher was saying (Ohun tí olùkọ́ ń sọ kò yé e).
fond: (i) ‘wù’ That boy is fond of this girl (Ọmọbìnrin yìí wu ọmọkùnrin yẹn) (ii) ‘fẹ́’ I am fond of eating meat (Mo máa ń fẹ́ jẹ ẹran).
fool: (i) ‘gọ̀’ He is a fool. He left his meat with the cat (Ó gọ̀. Ó fi ẹran rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ológbò) (ii) ‘tàn’ I fooled him into thinking that I will give him the money (Mo tàn án láti jẹ́ kí ó rò pé n ó fún un ní owó náà).
foot: (i) ‘rìn’ We decided to go on foot (A gbà láti rìn) (ii) ‘san’ My parents footed the bill for the wedding (Àwọn òbí mi ni ó san owó gbogbo ohun tí a fi ṣe ìgbéyàwó) (iii) ‘gbọ́’ My parents footed the bill for the wedding (Àwọn òbí mi ni ó gbọ́  gbogbo ohun tí a fi ṣe ìgbéyàwó).
for: (i) ‘dì’ He made himself ready for the day (Ó múra sílẹ̀ di ọjọ́ náà) (ii) ‘fún’ I put on his cap for him/I put on a cap (on my head) for him (Mo dé fìlà fún un) (iii) ‘dè’ He made himself ready for the day (Ó múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà).
forge: ‘rọ’ He forged a hoe (Ó rọ ọkọ́).
fork: ‘yà’ Fork left after the river (Yà sí apá òsì tí o bá ti kọjá odò).
form: ‘dì’ A table is formed of a flat piece of wood and four legs (Igi pẹrẹsẹ tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ló máa ń di tábìlì).
forment: ‘bà’ I formented his ulcer (Mo ba egbò rẹ̀)
formerly: ‘rí’  Ghana was formerly called Gold Coast (Gold Coast ni Ghana ń jẹ́ rí)    
forward: ‘bẹ’ That boy is too forward (Ọmọkùnrin yẹn bẹ)
fossick: ‘fọ́’ He is fossicking about in the bush (Ó ń fọ́ igbó kiri).
fracture: ‘dá’ His leg was fractured in an accident (Ẹsẹ̀ rẹ̀ dá nínú ìjàǹbá tí ó ṣẹlẹ̀ sí i).
fray: (i) ‘já’ It frayed at the edge (Ó já létí) (ii) ‘ju’ This garment is frayed (Aṣọ yìí ju)
freeze: ‘dì’ The water has frozen (Omi náà ti dì).
friendly: ‘rẹ́’ They are friendly (Wọ́n rẹ́).
from: ‘ti’ He went to Ìbàdàn from Lagos (Ó ti Èkó lọ sí Ìbàdàn).
frothed: ‘ru’ The saliva frothed (Itọ́ náà ń ru).
fruit: ‘so’ This oranged tree has fruited (Igi ọsàn yìí  ti so).
fry: (i) ‘dín’ He fried meat (Ó dín ẹran) (ii) ‘gbá’ He fried red palm oil (Ó gbá epo)
full: (i) ‘kún’ It is full  (Ó kún) (ii) ‘yó’ I felt full after eating the pounded yam (Mo yó nígbà tí mo jẹ iyán náà tán).
Gg

gather: (i) ‘gbọ́’ I gather that you are interested in football (Mo gbọ́ pé o nífẹ̀ẹ́ sí bọ́ọ̀lù) (ii) ‘kó’ She gathered her books (Ó kó àwọn ìwé rẹ̀).
guage: (i) ‘rò’ I gauged that there will be five books on that table (Mo rò pé ìwé márùn-ún ni yóò wà lórí tábìlì yẹn) (ii) ‘wọn’ He gauged the amount of petrol in the car (Ó wọn iye epo pẹtiróò tí ó wà nínú káà náà).
gaze: ‘wò’ I was gazing in surprise at the people (Mo ń wo àwọn ènìyàn náà  pẹ̀lú ìyanu).
germinate: (i) ‘wù’ The bean seed germinates (Irúgbìn ẹ̀wà náà wù) (ii) ‘hù’ The bean seed germinates (Irúgbìn ẹ̀wà náà hù).
germination: (i) ‘wù’ Seeds need water for germination (Irúgbìn nílò omi láti wù) (ii) ‘hù’ Seeds need water for germination(Irúgbìn nílò omi láti hù).
get: (i) ‘lù’ He got into trouble (Ó lu ìjàngbọ̀n) (ii) ‘rí’ He got profit on his wares (Ó rí èrè lórí ọjà rẹ̀) (iii) ‘jẹ’ He got profit on his wares (Ó jẹ èrè lórí ọjà rẹ̀) (iv) ‘ní’ I have got a dog (Mo ti ní ajá) (v) ‘gbà’ I got a letter from Mary (Mo gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ Màríà) (vi) ‘rà’ I must get a book from the bookshop (Mo gbọ́dọ̀ ra ìwé kan ní ilé ìtàwé) (vii) ‘mú’ I got out my book (Mo mú ìwé mi jáde) (viii) ‘gbé Get these books to Olú (Gbé àwọn ìwé yìí fún Olú) (ix) ‘kó’ Get these stones to the house (Kó àwọn òkúta yìí lọ sí inú ilé) (x) ‘jẹ́’ He got the shirt clean (Ó jẹ́ kí ṣáàtì náà mọ́)(xi) ‘sọ̀’ Get down (Sọ̀ kalẹ̀) (xii) ‘já’ He got to the road (Ó já ọ̀nà) (xiii) ‘dé’ I must get to Ibadan tomorrow (Mo gbọ́dọ̀ dé Ìbàdàn lọ́la) (xiv) ‘wọ̀’ He got on the train (Ó wọ ọkọ̀ ojú irin náà).
give: (i) ‘bùn’ He gives me money (Ó bùn mí lówó) (ii) ‘dá’ He gave thanks (Ó dá ọpẹ́) (iii) ‘fún’ He gave me money (Ó fún mi lówó) (iv) ‘pa’ He gave an order (Ó pa àṣẹ) (v) ‘sìn’ He gave his daughter in marriage (Ó sin ọmọ rẹ̀ ní ìyàwó) (vi) ‘san’ How much did you give for that book? (Èló ni o san fún ìwé yẹn?).
give birth to: ‘bí’ She gave birth to a baby (Ó bí ọmọ).
glance: ‘wò’ He glanced along the road to see if he was there (Ó wo ojú títì láti rí i bóyá ó wà níbẹ̀).
glare: ‘wò’ He glared at me (Ó wò mí).
glean: ‘tàn’ The moon gleaned to the river (Òṣùpá tàn sí omi náà).
glide: ‘yọ̀’ The boat glides away on the river (Ọkọ̀ náà ń yọ̀ lọ lórí omi).
glammer: ‘kọ’ The light from the house glimmered in the distance (Iná inú ilé náà ń kọ ní ọ̀kánkán).
glitter: ‘dán’ The ring glittered on her hand (Òrùka náà ń dán ní ìka rẹ̀).
gloat: ‘yọ̀’ The enemies gloated over his misfortune (Ọ̀tá yọ̀ ọ́).
glow: ‘kọ’ The dying fire glows in the dark forest (Iná tí ó ń kú lọ náà sì ń kọ nínú igbó dúdú náà).
glue: ‘lẹ̀’ She glued the handle to the cup (Ó lẹ ọwọ́ kọ́ọ̀bù náà mọ́ ara kọ́ọ̀bù náà).
gnaw: (i) ‘họ’ He gnawed a bone with his teeth (Ó fi eyín họ eegun) (ii) ‘gbẹ́’ The rat gnawed a hole in the tree (Eku náà gbẹ́ ihò sí ara igi náà).
go: (i) ‘rè’ Where did you go? (Níbo lo rè̀?) (ii) ‘lọ’ He went home (Ó lọ sílé) (iii) ‘tàn’ The light went on (Iná náà tàn) (iv) ‘kú’ The light went out (Iná náà kú) (v) ‘wò’ Go through this work (Wo iṣẹ́ yìí) (vi) ‘bọ́’ Go out (Bọ́ síta).
govern: ‘dè’ The preposition governs a noun in a sentence (Ọ̀rọ̀-Atọ́kùn máa ń de ọ̀rọ̀-orúkọ nínú gbólóhùn).
grab: ‘mú’ He grabbed the book (Ó mú ìwé náà).
grade: ‘tò’ We have graded those eggs into several sizes (A ti to Àwọn ẹyin yẹn sí oríṣìíríṣìí ìwọ̀n).
grant: ‘fún’ The children were granted a holiday (Wọ́n fún àwọn ọmọ náà ní ìsinmi).
grasp: (i) ‘yé’ I could not grasp what the teacher taught me (Ohun tí olùkọ́ kọ́ mi kò yé mi) (ii) ‘mú’ I grasped the cat’s tail (Mo mú ìrù ológbò náà).
grate: ‘rin’ She grated cassava (Ó rin ẹ̀gẹ́).
graze: ‘bó’ My skin is grazed (Ara mi bó).
great: ‘ga’ That party was great (Patí yẹn ga).
greet: (i) ‘kí’ He greets me (Ó kí mi)
grind: ‘lọ̀’ We grind grain to make flour (A lọ ọkà láti fi ṣe èlùbọ́).
group: ‘pín’ They grouped them round their teacher (Wọ́n pín wọn yí olùkọ́ wọn ká).
grow: (i) ‘hù’ Your orange is growing fast (Ọsàn rẹ ń tètè hù) (ii) ‘wù’ Your orange is growing fast (Ọsàn rẹ ń tètè wù).
growl: ‘kùn’ The dog growls at the visitors (Ajá náà ń kùn sí àwọn àlejò náà).
grunt: ‘kùn’ The pigs are grunting (Àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà ń kùn).
guard: ‘sọ́’ The dog guards the house (Ajá náà ń ṣọ́ ilé náà).

Hh

habitual marker: ‘(i) ‘ń’ I got to school everyday (Mò ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ lójoojúmọ́) (ii) ‘ḿ’ I go with him everyday (Mò ḿ bá a lọ lójoojúmọ́) (iii) ‘í’ We always see it from home (Ilé la ti í rí i).
had: ‘ti’ He had gone before his friend arrived (Ó ti lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dé).
haft: ‘rú’ He hafted the hoe (Ó rú ọkọ́).
hammer: ‘kàn’ He hammered the nail (Ó kan ìsó náà).
hand: ‘(i) ‘gbé’ I handed it over to him (Mo gbé e fún un) (ii) ‘fún’ Hand me that book (Fún mi ní ìwé yẹn).
handle: ‘lò’ He learnt how to handle a knife (Ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀bẹ).
hang: (i) ‘kọ́’ Hang your cloth here (Fi aṣọ rẹ kọ́ síhìn-ín) (ii) ‘rọ̀’ He is hanging on a tree (Ó ń rọ̀ lórí igi) (iii) ‘yọ’ A dog’s tongue angs out when it runs fast (Ahọ́n ajá máa ń yọ jáde tí ó bá ń sáré gan-an) (iv) ‘lẹ̀’ Hang the wallpaper (Lẹ bébà náà mọ́ ara ògiri) (v) ‘gbé’ Where are you hanging out now? (Níbo lò ń gbé báyìí?) (vi) ‘sá’ He is hanging out the washing? (Ó ń sá aṣọ) (viii) ‘ta’ They hanged out flags for the queen (Wọ́n ta àwọn àsíá fun Ọbabìnrin).
happen: (i) ‘bá’ Anybody who (happens to go) goes will be punished (Ẹni tí ó bá lọ, á jìyà) (ii) ‘gbé’ Do you notice where we have made a mistake? (Do you happened to know where we have made a mistake?) (Ṣé o rí ibi tí a gbé ṣe àṣìṣe?) (iv) ‘ṣẹ̀’ A sterling event happened (Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀)
happy: (i) ‘yọ̀’ They are happy (Wọ́n ń yọ̀) (ii) ‘yá’ He is extremely happy (Ara rẹ̀ yá gágá).
hard: ‘le’ This tree is hard (Igi yìí le).
harden: ‘gan’ The loaf of bread has become hardened (Búrẹ́dì náà ti gan)
harsh: ‘le’ The teacher is very harsh (Olùkọ́ náà le jù).
harvest: ‘ká’ He harvested is guinea corn (Ó ká ọkà bàbà rẹ̀)
has: (i) ‘ti’ He has gone (Ó ti lọ) (ii) ‘ní’ He has that type of book (Ó ní irú ìwé yẹn) (iii) ‘fà’ He has dried saliva on his mouth (Ó fa lala).
hatch: ‘pa’ The hen has hatched the chicken (Adìẹ náà ti pa ọmọ)
haul: ‘tì’ They hauled the boat into the river (Wọ́n ti ọkọ̀ náà sí inú omi).
have: (i) ‘ti’ They have gone (Wọ́n ti lọ) (ii) ‘ní’ They have money (Wọ́n ní owó) (iii) ‘fà’ They have dried saliva on their mouths (Wọ́n fa lala).
he: ‘ó’ He picked up the bag (Ó gbé báàgì náà)
head: ‘lọ’ The bus is heading towards the centre of the town (Bọ́ọ̀sì náà ń lọ sí àárín ìlú).
heal: (i) ‘sàn’ The sore on his leg has healed (Egbò ẹsẹ̀ rẹ̀ ti san) (ii) ‘pa’ They healed the wound (Wọ́n pa ọgbẹ́ náà) (iii) ‘sàn’ He has now been healed (Ó ti sàn fún un báyìí).
hear ‘gbọ’ He heard my call (Ó gbọ́ ìpè mi).
heavy: ‘pọ̀’ The rain was very heavy (Òjò náà pọ̀ púpọ̀).
help: (i) ‘bá’ He helped me to do it (Ó bá mi ṣe é) (ii) ‘ràn’ He helped me with the load (Ó ràn mí lẹ́rù) (iii) ‘gbà’ Help me (Gbà mí) (iv) ‘fún’ He helped me to some rice (Ó fún mi ní ráìsì díẹ̀).
her: (i) ‘í’ I held her (Mo dì í mú) (ii) ‘i’ I saw her (Mo rí i) (iii) ‘á’ I draw her nearer (Mo fà á mọ́ra) (iv) ‘a’ I am looking for her (Mò ń wá a) (v) ‘ẹ̀’ Her clothes (Aṣọ ẹ̀/Aṣọ ẹ̀) (vi) ‘é’ I called her (Mo pè é) (vii) ‘ún’ It pained her (Ó dùn ún) (viii) ‘un’ he gave her (Ó fún un) (ix) ‘ú’ He beats her (Ó lù ú) (x) ‘u’ He abused her (Ó bú u) (xi) ‘ẹ’ I love her (Mọ fẹ́ ẹ) (xii) ‘ẹ́’ I begged her (Mo bẹ̀ ẹ́) (xiii) ‘e’ I overtook her (Mo lé e bá) (xiv) ‘ẹ’ Your cloth (Aṣọ ẹ) (xv) ‘ín’ I tripped her from the back (Mo jìn ín lẹ́sẹ̀ láti ẹ̀yìn (xvi) ‘in’ I scrubb her back (Mo kín in lẹ́yìn).
here: ‘é’ Here is the money (Owó rèé).
hide: (i) ‘ba’ I hid under the tree (Mo ba sí abẹ́ igi) (ii) ‘bo’ He hid under the tree (Ó bo sí abẹ́ igi) (iii) ‘mù’ He hid under the bush (Ó mù sí abẹ́ igbó)
high: ‘ga’ He is tall (Ó ga)
him: (i) ‘í’ I held him (Mo dì í mú) (ii) ‘i’ I saw him (Mo rí i) (iii) ‘ẹ́’ I begged him (iv) ‘ú’ He beats him (Ó lù ú) (v) ‘u’ He slaughtered him (Ó dú u) (vi) ‘á’ I drew him nearer (Mo fà á mọ́ra) (vii) ‘a’ I am looking for him (Mò ń wá a) (xiii) ‘e’ I overtook him (Mo lé e bá) (ix) ‘é’ I called him (Mo pè é) (x) ‘ún’ It pained him (Ó dùn ún) (xi) ‘un’ He gave him (Ó fún un) (xii) ‘ẹ’ I loved him (Mo fẹ́ ẹ) (xiii) ‘ín’ I tripped him from back (Mo jìn ín lẹ́sẹ̀).
hire: ‘yá’ He hired a car (Ó yá káà kan).
his: (i) ‘rẹ̀’ His clothes (Aṣọ rẹ̀) (ii) ‘in’ I scrubbed his back (Mo kín in lẹ́yìn).
hit: (i) ‘bà’ The stone he threw hit me (Òkúta tí ó sọ bà mí) (ii) ‘gán’ He hit him on the palm with ‘òkòtó’ (small snail-shell) (Ó fi òkòtó gán an) (iii) ‘nà’ He hit me (Ó nà mí) (iv) ‘dá’ He hit me with a stick (Ó dá mí ní igi) (v) ‘lù’ He hit him (Ó lù ú) (vi) ‘jàn’ He hit me with a stick (Ó jàn mí ní igi) (vii) ‘jàn’ He threw me down in a wrestling contest (Ó jàn mí mọ́lẹ̀) (viii) ‘kán’ He hit me with a stick (Ó kán mi ní igi) (ix) ‘tí’ He hit me with a stick (Ó tí mi ní igi) (x) ‘gbá’ He hit me with his hand (Ó gbá mi lábàrá) (xi) ‘tà’ That song was a hit last year (Orin yẹn tà ní èṣí) (xii) ‘bá’ The stone hit me (Òkúta náà bà mí).
hoe: ‘tu’ The man was hoeing the ground where he planted the beans (Ọkùnrin náà ń tu ilẹ̀ ibi tí ó gbin ẹ̀wà sí).
hoist: (i) ‘gbé’ He hoisted the bag onto his shoulder (Ó gbé àpò náà kọ́ apá) (ii) ‘ta’ He hoisted the flag to the top of the pole (Ó ta àsíá náà sí orí òpó).
hold: (i) ‘fà’ He held my hand (Ó fà mí lọ́wọ́) (ii) ‘mú’ He was holding a book in his hand (Ó mú ìwé kan dání (iii) ‘gbà’ The bottle holds a litre of water (Ìgò náà gba lítà omi kan) (iv) ‘ṣe’ They are holding a party next week (Wọn yóò ṣe patí lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀).
honour: (i) ‘bu ọlá’ He honoured him (Ó bu ọlá fún un) (ii) ‘yẹ́ sí’ He was honouered
hook: (i) ‘kọ́’ His cloth got hooked on a tree (Aṣọ rẹ̀ kọ́ igi) (ii) ‘dè’ She hooked up her dress (Ó de aṣọ rẹ̀) 
hot ‘ta’ The pepper tastes hot in my mouth (Ata náà ta mí lẹ́nu)
how: ‘bí’ He taught me how to do it (Ó kọ́ mi bí mo ti máa ṣe é)
howl: ‘(i) ‘han’ He howled (Ó han) (ii) ‘hu’ He howled out (Ó hu)
hum: ‘kùn’ The bees are humming (Àwọn oyin náà ń kùn).
hungry: ‘pa’ He is hungry (Hunger is killing him) (Ebi ń pa á)
hunt: (i) ‘dẹ’ He hunted for animals in the bush (Ó dẹ ìgbẹ́) (ii) ‘wá’ I hunted for my book in the classroom (Mo wá ìwé mi nínú kíláàsì).
hurl: ‘jù’ He hurled the book at the wall (Ó ju ìwé náà lu ògiri).
hurt: ‘dùn’ My leg hurts (Ẹsẹ̀ mi ń dùn mí).
husky: ‘kẹ̀’ He has a husky voice (Ohùn-un rẹ̀ kẹ̀).

Ii

i: ‘n’ I didn’t go (N kò lọ).
identical: ‘jọ’ This book is identical to that one (Ìwé yìí jọ ìyẹn).
identify: ‘mọ̀’ I have identified the man who wrote the letter – It is Olú (Mo ti mọ ọkùnrin tí ó kọ ìwé náà – Olú ni).
if: ‘bí’ If you hit me I will hit you (Bí o lù mí n ó lù ọ́).
ignite: ‘ràn’ The wood has ignited (Igi náà ti ràn).
ill: ‘rẹ̀’ He is ill (Ó rẹ̀ ẹ́).
imagine: ‘rò’ Do you imagine I am going to stop your game? (Ṣé o rò pé mo máa dá eré yín dúró ni?).
implore: ‘bẹ̀’ He implored the robber not to take all their money  (Ó bẹ olè náà kí ó má kó gbogbo owó wọn lọ).
in: (i) ‘ní’ He is in the market (Ó wà ní ọjà) (ii) ‘sí’ Don’t stand in his way (Má dùúró sí ojú ọ̀nà tí ó ń gbà) (iii) ‘fi’ The words were written in pencil (Pẹ́ńsù ni wọ́n fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà) (iv) ‘wọ̀’ She was in a black skirt (Síkẹ́ẹ̀tì dúdú ni ó wọ̀).
incite: ‘dẹ’ I incited them against him (Mo dẹ wọ́n sí i)
increase: (i) ‘gbé’ It increased slightly (Ó gbé pẹ́ẹ́ díẹ̀ sí i) (ii) ‘lé’ My clothes have increased by one (Aṣọ mi ti lé ọ̀kan sí i) (iii) ‘rẹ̀’ They gave birth to more children, they increased in number (Wọ́n bí sí i, wọ́n rẹ̀ sí i).
indulgent: ‘gbà’ He was indulgent to me (Ó gbà fún mi).
infect: ‘ràn’ His feve illness infected three other children (Àìsàn rẹ̀ ran àwọn ọmọ mẹ́ta mìíràn).
inflate: ‘pọ́’ He inflated the bicycle’s tyre (Ó pọ́ táyà kẹ̀kẹ́).
inhabit: ‘gbé’ They used to inhabit the street (Wọ́n máa ń gbé títì náà tẹ́lẹ̀).
inhale: ‘fà’ He inhaled it (into his nose) (Ó fà á símú).
initially: ‘kọ́’ He initially wanted to work to town but changed his mind (Ó kọ́ fẹ́ rìn lọ sí ìgboro ṣùgbọ́n ó yí ọkàn rẹ̀ padà).
inscribe: ‘gbẹ́’ They inscribed me with the spirit to take it (Ó kì mí láyà láti mù un).
install: ‘gùn’ He was installed a chief (Ó gun orí oyè )
instruct: ‘kọ́’ He instructed me how to use a telephone (Ó kọ́ mi bí a ti ń lo fóònù).
intelligent: ‘gbọ́n’ The boy is intelligent (Ọmọkùnrin náà gbọ́n)
intend: (i) ‘fẹ́’ Today, I intend to write my letter (Ní òní, mo fẹ́ kọ lẹ́tà mi) (ii) ‘wà’ This book is intended for children (Ìwé yìí wà fún ọmọdé).
interrogate: ‘yin’ He interrogated him in order to hear the facts from him (Ó yin ọ̀rọ̀ gbọ́ lẹ́nu rẹ̀).
intoxicate: ‘yó’ The man was intoxicated (Ọkùnrin náà ti yó).
invite: ‘pè’ He invited us to the meeting (Ó pè wá sí ìpàdé náà).
involve: ‘kàn’ We were all involved in the play (Gbogbo wa ni eré náà kàn).
iron: ‘lọ̀’ I ironed two shirts (Mo lọ ṣáàtì méjì).
irritate: ‘jó’ The cow-itch irritated his body (Wèrèpè jó o lára).
is: (i) ‘ni’ He is Peter’s friend (Ọ̀rẹ́ Pítà ni) (ii) ‘wà’ He is in the market (Ó wà ní ọjà) (iii) ‘jẹ́’ One of them is a student (Ọ̀kan nínú wọn jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́).
issue: (i) ‘já’ I have issued from a path to highway (Mo ti já ojú ọ̀nà) (ii) ‘fún’ He issued pens to the children (Ó fún àwọn ọmọ náà ní pẹ́ẹ̀nì).
it: (i) ‘á’ I bought it (Mo rà á) (ii) ‘a’ I swept it (Mo gbá a) (iii) ‘ẹ́’ I ate it (Mo jẹ ẹ́) (iv) ‘e’ I cut it (Mo gé e) (v) ‘é’ I did it (Mo ṣe é) (vi) ‘í’ I tied it (Mo dì í) (vii) ‘i’ I opened it (Mo ṣí i) (viii) ‘ẹ’ I cut it (Mo bẹ́ ẹ) (ix) ‘ú’ He carried it (Ó rù ú) (x) ‘u’ He untied it (Ó tú u) (xi) ‘ùn’ He wipped it (Ó nù ún) (xii) ‘un’ He squeezed it (Ó rún un) (xiii) ‘in’ I fried it (Mo dín in) (xiv) ‘gbé’ Where did you see him? (Where is it that you see him?) (Níbo lo gbé rí i?) (xv) ‘ó’ It is in my room (Ó wà ní yàrá mi) (xvi) ‘ín’ I planted it (Mo gbìn ín).
itch: ‘yún’ His ear itched all night (Gbogbo alẹ́ ni etí rẹ̀ fi ń yún un).

Jj

jab: (i) ‘gún’ When I was sewing, I jabbed my finger with a needle (Nígbà tí mò ń rán aṣọ, mo fi abẹ́rẹ́ gún ara mi níka).
jam: (i) ‘fún’ I jammed all my clothes into the small box (Mo fún gbogbo aṣọ mi mọ́ inú àpótí kékeré náà) (ii) ‘kì’ I jammed all my clothes into the small box (Mo ki àwọn aṣọ mi mọ́ inú àpótí kékeré náà) (iii) ‘kún’ The hall was jammed full of people (Èrò kún inú gbọ̀ngàn náà) (iv) ‘há’ I can’t open the window, it is jammed (N kò lè ṣí fèrèsé náà, ó ti há) (v) ‘họ́’ So many people came to the seminar that the place was jammed (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ó wá sí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà tí ó fi jẹ́ pé ibẹ̀ họ́).
jeer: ‘yọ̀’ They jeered him (Wọ́n yọ̀ ọ́)
joggle: ‘lò’ The tree is joggling up and down (Igi náà ń lò)
join: ‘bá’ He went with me (He joined me to go (there) (Ó bá mi lọ).
joint: ‘jọ’ Olú and Adé are the joint owners of the business (Olú àti Adé ni wọ́n jọ ni ilé-iṣẹ́ náà).
jointly: ‘jọ’ They owned the business jointly (Wọ́n jọ ni ilé-iṣẹ́ náà ni).
jump: (i) ‘fò’ He jumped over it (Ó fò ó) (ii) ‘bẹ́’ The child jumped (Ọmọ náà bẹ́) (iii) ‘tọ’ He jumped (Ó tọ).
just: (i) ‘kàn’ Òjó entered just to say good morning (Òjó wọlé láti kàn sọ pé ẹ káàárọ̀) (ii) ‘bí’ Adé entered just as I left (Adé wọlé bí mo ṣe jáde).

Kk

keen: (i) ‘wù’ Are you keen on swimming? (Ṣé ó wù ọ́ láti wẹ̀?) (ii) ‘fẹ́’ Are you keen on swimming (Ṣé o fẹ́ wẹ̀?).
keep: (i) ‘sìn’ He is keeping poultry (Ó ń sin adìẹ) (ii) ‘mú’ I don’t want that book, keep it (N kò fẹ́ ìwé yẹn, máa mú un) (iii) ‘ṣọ’ Olú kept eyes on the children (Olú ń ṣọ́ àwọn ọmọ náà) (iv) ‘fi’ He kept it in mind (Ó fi sọ́kàn) (v) ‘jẹ́’ Keep the fire burning (Jẹ́ kí iná yẹn máa jó) (vi) ‘jó’ The fire will keep on for one hour (Iná náà yóò jó fún wákàtí kan) (vii) ‘dé’ Keep your hat on (Dé fìlà rẹ) (viii) ‘kà’ Do you still keep up your Greek? (Ṣé o sì ń ka Gíríkì rẹ?) (ix) ‘kó’ He keeps bad company (Ó ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́).
kick: (i) ‘gbá’ He kicked the ball (Ó gbá bọ́ọ̀lù) (ii) ‘ta’ The horse kicked him (Ẹṣin náà ta á ní ìpá).
kill: ‘pa’ He killed the snake (Ó pa ejò náà).
kindle: ‘dá’ It is difficult to kindle the fire if the wood is wet (Iná igi tí ó bá tutù ṣòroó dá).
knit: (i) ‘hun’ My mother knits me some socks (Màmá mi hun ìbọ̀sẹ̀ mélòó kan fún mi) (ii) ‘wun’ My mother knits me some socks (Màmá mi wun ìbọ̀sẹ̀ mélòó kan fún mi).
knock: (i) ‘sẹ̀’ He knocked his head against Adé (Ó sẹ orí mọ́ Adé) (ii) ‘kàn’ Knock on the door before you enter (Kan ilẹ̀kùn kí o tó wọlé) (iii) ‘lù’ He knocked the snake on the head with a stick (Ó fi igi lu ejò náà lórí) (iv) ‘wó’ The house was knocked down (Wọ́n wó ilé náà lulẹ̀).

know: (i) ‘mọ̀’ He knows it (Ó mọ̀ ọ́n) (ii) ‘gbọ́’ He knows how to do divination (Ó gbọ́ Ifá).

Ll

labour: ‘tẹ̀’ She is labouring to have a baby (Òbí tẹ̀ ẹ́)
lack: ‘dá’ He has no money (Ọ̀dá owó dá a)
laden: ‘kún’ The lorry was laden with boxes (Àpótí kún inú ọkọ̀ náà).
ladle: (i) ‘kọ’ She ladled ‘àmàlà’ (Ó kọ àmàlà) (ii) ‘tọ́’ She ladled out some soup (Ó tọ́ ọbẹ̀).
lap: ‘lá’ The dog laps its water (Ajá náà lá omi rẹ̀).
lash: (i) ‘nà’ The man lashed the cow (Ọkùnrin náà na mààlúù náà) (ii) ‘lù’ The man lashed the cow (Ọkùnrin náà lu mààlúù náà) (iii) ‘pa’ The rain lashes our faces (Òjò pa wá lójú) (iv) ‘so’ We lashed the boat to the tree (A so ọkọ ojú omi náà mọ́ igi).
last: (i) ‘ká’ This food will last for a year (Oúnjẹ yìí yóò ká ọdún) (ii) ‘pẹ́’ It cannot last (Kò le pẹ́) (iii) ‘gbà’ Our holiday lasted ten days (Ìsinmi wa gba ọjọ́ mẹ́wàá) (iv) ‘tó’ Buy loaves of bread that will last us for ten days (Ra búrẹ́dì tí yóò tó wa fún ọjọ́ mẹ́wàá).
late: ‘pẹ́’ He was late (Ó pẹ́)
laugh: ‘rín’ He laughed (Ó rín (ẹ̀rín))
lay: (i) ‘yé’ The hen laid eggs (Adìẹ náà yé ẹyin) (ii) ‘fi’ Lay the book on the table (Fi ìwé náà sí orí tábìlì).
lazy: ‘lẹ’ He is lazy (Ó lẹ)
lead: ‘mú’ The road led us to Ayọ’s house (Títì náà mú wa dé ilé Ayọ̀).
leading: ‘lé’ The teacher was leading the song (Olùkọ́ náà ń lé orin náà).
leak: (i) ‘jò’ The plate leaks (Abọ́ náà ń jò) (ii) ‘lu’ The plate leaks (Abọ́ náà lu).
leaky: (i) ‘jò’ The roof is leaky (Páànù tí wọ́n fi bo ilé náà ń jò) (ii) ‘lu’ The roof is leaky (Páànù tí wọ́n fi bo ilé náà lu) 
lean: (i) ‘rù’ He is lean (Ó rù) (ii) ‘gbé’ Lean your elbow on the table (Gbé ìgbọ̀nwọ́ rẹ lé tábìlì).
leap: ‘fò’ The dog leapt over the table (Ajá náà fo tábìlì náà kọjá).
learn: ‘kọ́’ He  learns arithmetic (Ó kọ́ ìṣirò)
leave: (i) ‘bọ́’ He left for the backyard (Ó bọ́ sí ẹ̀yìnkùnlé) (ii) ‘tú’ Everybody left the market hurriedly (Ọjà tú lójijì)
lend: (i) ‘yá’ He lend me some money (Ó yá mi lówó) (ii) ‘wín’ I lent him some money (Mo wín in lówó).
level: ‘tẹ́’ We need a level piece of ground to play football on (A nílò ilẹ̀ tí ó tẹ́ níbi tí a ti lè máa gbá bọ́ọ̀lù).
lick: ‘lá’ He licked the soup (Ó lá ọbẹ̀ náà).
lie: (i) ‘wà’ The plate lay on the table (Àwọn àwo náà wà lórí tábìlì) (ii) ‘sùn’ Lie down (Sùn sílẹ̀).
lift: ‘gbé’ He lifted it up (Ó gbé e sókè).
light: (i) ‘tàn’ Light the fire (Tan iná náà) (ii) ‘ràn’ I lit the cigarette with a match (Mo fi iná ìṣáná ran sìgá náà) (iii) ‘ṣá’ I lit the tobacco with a match (Mo ṣá ìṣáná sí tábà náà).
like: (i) ‘fẹ́’ He likes me (Ó fẹ́ mi) (ii) ‘jọ’ He is like his father (Ó jọ bàbá rẹ̀) (iii) ‘bí’ Ayọ’s shoes are black, like mine (Bàtà Ayọ̀ dúdú, bí i tèmi).
limit: ‘mọ’ This is my limitation (Bí mo ti mọ nìyí).
limp: ‘rọ’ When plants are dying their leaves become limp (Bí koríko bá fẹ́ kú, ewé wọn yóò rọ).
line: ‘tò’ They are in a line (Wọ́n tò).
listen: ‘gbà’ He does not listen to our advice (Kò gba ìpẹ̀ tí a ṣe fún un).
live: ‘gbé’ He lives at Ìbàdàn (Ó ń gbé ní Ìbàdàn)
load: ‘kì’ He loaded the gun (Ó ki ìbọn náà).
loan: ‘yá’ They loaned me some money  (Wọ́n yá mi lówó díẹ̀).
locate: (i) ‘wà’ The house was located in the market (Ilé náà wà ní ọjà) (ii) ‘kọ́’ The house was located in the market. (Wọ́n kọ́ ilé náà sí ọjà) (iii) ‘rí’ I cannot locate the pen (N kò rí pẹ́ẹ̀nì náà).
lock: ‘tì’ You used a key to lock the door (Kọ́kọ́rọ́ ni a fi ń ti ilẹ̀kùn).
lodge: (i) ‘wọ̀’ He lodge in my house (Ó wọ̀ sí ilé mi) (ii) ‘gbé’ He lodged in a room in our house (Ó ń gbé yàrá kan nínú ilé wa).
loft: ‘gbá’ He lofts the ball over his head (Ó gbá bọ́ọ̀lù náà kọjá orí rẹ̀).
lofty: ‘ga’ That is a lofty mountain (Òkè yẹn ga).
long: (i) ‘gbò’ My absence from home made him long for me (Àìsí nílé mi gbò ó) (ii) ‘gùn’ It is long (Ó gùn) (iii) ‘pẹ́’ Will you be long? (Ṣé o máa pẹ́?) (iv) ‘bí’ You can go out as long as you promise to be back soon (O lè jáde bí o kò bá ti níí pẹ́) (v) ‘fẹ́’ I longed to see my mother, she has been away for a long time (Mo fẹ́ rí màmá mi, ó ti pẹ́ tí ó ti lọ).
look: (i) ‘wò’ He looked at it (Ó wò ó) (ii) ‘wá’ He looked for it (Ó wá a) (iii) ‘rí’ How does it look like? It is round (Báwo ló ṣe rí? Ó rí kiribiti).
loose: (i) ‘dẹ̀’ I must loosen this belt, it is too tight (Bẹ́líìtì yìí ti fún mi jù, mo gbọ́dọ̀ dẹ̀ ẹ́) (ii) ‘mì’ Ayọ̀ has a loose tooth (Eyín Ayọ̀ ń mì) (iii) ‘sọ̀’ A loose belt is better than a tight one (Bẹ́líìtì tí ó sọ̀ dára ju èyí tí ó fún mi lọ).
loosely: ‘sọ̀’ My trousers fit me loosely (Ṣòkòtò mi sọ̀ mí).
lose: (i) ‘nù’ He is looking for his lost sheep (Ó ń wá àgùntàn rẹ̀ tí ó nù) (ii) ‘re’ The tree losts its leaves (Igi náà re ewé)
love: ‘fẹ́’ He loves me (Ó fẹ́ mi).
lukewarm: ‘lọ́’ The water was only lukewarm (Omi náà lọ́ lásán ni).
lurk: ‘gọ’ He lurked in hiding (Ó gọ).

Mm

make: (i) ‘mọ’ He  made pottery (Ó mọ ìkòkò) (ii) ‘kọ’ He made yam heaps (Ó kọ ebè) (iii) ‘pa’ She makes a little sales today (Ó pa owó díẹ̀ lónìí) (iv) ‘pa’ They are making noise (Wọ́n ń pariwo) (v) ‘ta’ There was a great noise (They make a great noise) (Òkìkí ta) (vi) ‘ṣe’ He made it into law (Ó ṣe é ní òfin) (vii) ‘rí’ He makes a lot of money every week (Ó ń rí owó púpọ̀ lọ́sẹ̀) (viii) ‘mú’ He made me drink water (Ó mú mi mu omi) (ix) ‘yé’ I can’t make out what he is saying (Ohun tí ó ń sọ kò yé mi) (x) ‘jẹ’ He makes a lot of money in the lottery (Ó jẹ owó púpọ̀ nínú tẹ́tẹ́) (xi) ‘ṣá’ He made kẹ́kẹ́ marks on it (Ó ṣá kẹ́kẹ́ sí i lẹ́rẹ̀kẹ́) (xii) ‘sà’ I made a mark on it (Mo sà á lámì) (xiii) ‘ní’ I make friends easily (Mo tètè máa ń ní ọ̀rẹ́) (xiv) ‘jẹ́’ What made him so angry? (Kí ni ó jẹ́ kí ó bínú?).
manage: (i) ‘gbà’ That is how I can manage to do it (Ọ̀nà tí mo lè gbà ṣe é nìyẹn) (ii) ‘gbé’ Where did you manage to get it? (Níbo lo gbé rí i?)
manufacture: ‘ṣe’ Cars are manufactured in this factory (À ń ṣe mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ nínú ilé-iṣẹ́ yìí).
many: ‘pọ̀’ Bananas are not very many in the basket (Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ kò pọ̀ nínú agbọ̀n  náà).
march: ‘yan’ The soldiers are marching along the street (Àwọn sọ́jà ń yan lórí títì).
marry: ‘fẹ́’ He married her (Ó fẹ́ ẹ)
massacre: ‘pa’ They massacred the women and children of the town (Wọ́n pa àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé inú ìlú náà).
may: (i) ‘lè’ I may go (Mo lè lọ) (ii) ‘jẹ́’ Perharps he may come (Bóyá a jẹ́ wá) (iii) ‘kí’ May our class win (Kí kíláàsì wa borí).
me: (i) ‘mi’ He saw me (Ó rí mi) (ii) ‘mi’ He calls me (Ó pè mí).
measure: ‘wọ̀n’ He measured it (Ó wọ̀n ọ́n)
mediate: ‘là’ He mediated between them (Ó là wọ́n ní ìjà)
meet: (i) ‘bá’ He found himself in my presence (Ó bá ara rẹ̀ níwájú mi) (ii) ‘kò’ He met me on the way (Ó kò mí lọ́nà) (iii) ‘mọ̀’ I would like to meet your teacher (Màá fẹ́ mọ olùkọ́ rẹ) (iii) ‘rí’ I would like to meet your friend (Mà á fẹ́ rí ọ̀rẹ́ rẹ).
melt: ‘yọ́’ It  melted (Ó yọ́).
might: ‘lè’ He said he might come (Ó ní òun lè wá).
mill: ‘lọ̀’ The new machine mills flour very quickly (Ẹ̀rọ titun náà tètè máa ń lọ fúláwà).
miss: ‘sé’ The stone he threw missed the hole (Òkúta tí ó jù sé ojú ihò náà).
mistake: ‘ṣì’ He  made a mistake (Ó ṣì  í)
mix: (i) ‘lú’ He mixed them together (Ó lú wọn mọ́ra) (ii) ‘pò’ He poured milk into the tea and mixed the two together (Ó bu mílíìkì sínú tíì, ó po méjèèjì pọ̀).
modify: ‘pọ́n’ He  modified a verb with an adverb (Ó fi ọ̀rọ̀-àpọ́nlé pọ́n ọ̀rọ̀-ìṣe).
moist: (i) ‘dùn’ Rain has moisten the groud (Òjò dun ilẹ̀) (ii) ‘rin’ It is moist (Ó rin).
more: (i) ‘jù’ I have more bread than they have (Búrẹ́dì mi ju tiwọn/Mo ní búrẹ́dì tí ó ju èyí tí wọ́n ní) (ii) ‘sí’ We need more books (A nílò ìwé sí i) (iii) ‘mọ́’ He won’t come to school anymore (Kò níí wá sí ilé-ẹ̀kọ́ mọ́) (iv) ‘bí’ There were thirty people in the house, more or less (Ènìyàn bí ọgbọ̀n ló wà nílé rẹ̀)
most: (i) ‘jù’ That is the most beautiful flower (Àdòdó tí ó dára jù nìyẹn) (ii) ‘pẹ́’ At the very most, it will take you an hour  to get to Ìbàdàn from Ifẹ̀ (Ó pẹ́ tán, yóò gbà ọ́ ní wákàtí kan láti dé Ìbàdàn láti Ifẹ̀).
motion: ‘lọ’ You must not get out of the lorry when it is in motion (O kò gbọ́dọ̀ sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ tí ó bá sì ń lọ).
mould: ‘mọ’ They mould a head out of the clay (Wọ́n fi amọ̀ náà mọ orí kan).
mouldy: ‘bu’ It is mouldy (Ó bu)
mount: ‘pọ̀n’ He mounted on his back (Ó pọ̀n sí i lẹ́yìn) (ii) ‘gùn’ He mounted his horse (Ó gun ẹṣin rẹ̀) (iii) ‘pọ̀’ Our expenses are mounting up (Ìnáwó wa ń pọ̀ sí i).
move: ‘ṣí’ He moved house (Ó ṣí ilé) (ii) ‘sún’ He moved near me (Ó sún mọ́ mi) (iii) ‘kó’ Lorries were used to move the soldiers (Wọ́n fi ọkọ̀ elérò kó àwọn jagunjagun náà) (iv) ‘lọ’ Time moves on (Àkókò ń lọ) (v) ‘bọ́’ He moved to the front of the class (Ó bọ́ sí iwájú kíláàsì).
mow: (i) ‘gé’ The men are mowing the grass (ọkùnrin náà ń gé oko) (ii) ‘ro’ The men are mowing the grass (À wọn ọkùnrin náà ń ro oko).
much: ‘fì’ Even a naira is irksome (is much) to him to spend (Náírà kan fì í lọ́wọ́ láti ná).
murder: ‘pa’ The man murdered his wife (Ọkùnrin náà pa ìyàwó rẹ̀).
my: (i) ‘mi’ My book (Ìwé mi).
myself: ‘dá’ My friend were out, so I played by myself (Àwọn ọ̀rẹ́ mi ti jáde, nítorí náà, ṣe ni mo ń dá ṣeré).


Nn

nail: ‘kàn’ Nail the plank to the wall (Kan pákó náà mọ́ ògiri).
name: ‘sọ’ They named the baby Olú (Wọ́n sọ ọmọ náà  ní Olú).
narrate: (i) ‘sọ’ He narrated his adventures in the town (Ó sọ nípa ìrìnàjò rẹ̀ ní ìlú náà) (ii) ‘rọ́’ He narrated his dream (Ó rọ́ àlá rẹ̀).
narrow: (i) ‘há’ It is narrow (Ó há) (ii) ‘họ́’ It is narrow (Ó họ́).
navigate: ‘wà’ In spite of the cloud, he navigated the plane down onto the ground (Lékèe wí pé kùrukùru gba ojú ọjọ́, ó wa ọkọ̀ òfúrufú náà gúnlẹ̀).
near: ‘kín’ He is very near to me (Ó kín mi).
neat: ‘mọ́’ Our classroom is neat (Kíláàsì wa mọ́).
next: (i) ‘tì’ My father’s house is next to his (Ilé bàbá mi ni ó ti tirẹ̀). (ii) ‘kàn’ It was Saturday, so the next day was Sunday (Ọjọ́ Sátide ni, nítorí náà ọjọ́ tí ó kàn ni Sọ́n-ńdè).
nibble: ‘yín’ He his nibbling the food (Ó ń yín oúnjẹ náà jẹ).
no: ‘tì’ No (Ó ti).
not: ‘kọ́’ (i) ‘not’ It is not you (Ìwọ kọ́) (ii) ‘kò’ Olú didn’t go (Olú kò lọ) (iii) ‘má’ Don’t go (Má lọ) (iv) ‘yé’ Do not go (Yé lọ).
now: ‘wá’ I now understand (Ó wá yé mi)
numerous: ‘pọ̀’ The people are many (numerous) (Àwọn ènìyàn náà pọ̀).


Oo

obey: ‘gbọ́’ I obeyed him (Mo gbọ́ tirẹ̀).
observe: (i) ‘wò’ He observed the sky (Ó wo ìràwọ̀) (ii) ‘ní’ ‘This class is dirty’, the teacher observed (Tísà náà ní, ‘kíláàsì yìí dọ̀tí’).
obtain: (i) ‘gbà’ I have obtained the book (Mo ti gba ìwé náà) (ii) ‘rí’ Do you know where it can be obtained? (Ǹjẹ́ o mọ ibi tí a ti lè rí i?).
obvious: ‘hàn’ It is obvious that he is alive (Ó hàn pé ó wà láàyè).
occupy: ‘gbà’ The table occupied half of the room (Tábìlì náà gba ìlàjì yàrá náà).
of: ‘ti’ I gave my friend some books. One of his father was there. (Mo fún ọ̀rẹ́ ní àwọn ìwé kan. Ọ̀kan ti bàbá rẹ̀ wà níbẹ̀).
off: ‘lọ’ He is off to London (Ó ti lọ sí Lóńdọ́ọ̀nù).
offend: ‘ṣẹ̀’ I have offended you (Mo ti ṣẹ̀ ẹ́).
offer: (i) ‘fún’ He offered me an orange (Ó fún mi ní ọsàn kan) (ii) ‘gbà’ He offered to carry the pail for me (Ó gbà láti bá mi gbé péèlì náà) (iii) ‘rú’ He offered a sacrifice (Ó rú ẹbọ).
old: ‘gbó’ He is old (Ó ti gbó).
omit: ‘fò’ You have omitted my name (O ti fo orúkọ mi)
on: (i) ‘ní’ I shall arrived on Monday (Mà á dé ní Mọ́ńdè) (ii) ‘bí’ On her arrival, she sat down (Bí ó ti dé, ó jókòó sílẹ̀) (iii) ‘lé’ I placed my leg on it (Mo gbé ẹsẹ̀ mi lé e) (iv) ‘kà’ He placed it on the table (Ó gbé e ka orí tábìlì).
onto: ‘mọ́’ They jumped onto the train (Wọ́n fò mọ́ ọkọ̀ ojú irin náà).
one: (i) ‘a’ One should try to help other people (A gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú láti ran àwọn ènìyàn mìíràn lọ́wọ́) (ii) ‘kan’ I bought one chair (Mo ra àga kan).
only: ‘kàn’ I am only looking at the shoes (Mo kàn ń wo àwọn bàtà náà ni).
onwards: ‘lọ’ They hurried onward without stopping  to rest (Wọ́n ń kánjú lọ láìdúró sinmi).
ooze: ‘sun’ Water oozes out (Omi ń sun jáde).
open: (i) ‘là’ He opened his hand (Ó la ọwọ́ rẹ̀) (ii) ‘gà’ He opened his umbrella (Ó ga agboòrùn-un rẹ̀) ‘ṣí’ He opened the door (Ó ṣí ilẹ̀kùn náà) (iv) ‘yà’ He opened his eyes (Ó ya ojú rẹ) (v) ‘ṣí’ They opened fire on them (Wọ́n ṣí iná bò wọ́n).
operate: ‘lò’ Do you know how to operate this machine? (Ǹjẹ́ o mọ̀ bí a ṣe ń lo ẹ̀rọ yìí?)
order: (i) ‘tò’ Keep those papers in order (To àwọn bébà yẹn) (ii) ‘kí’ They left early in order that they might catch the bus (Wọ́n tètè lọ kí wọ́n lè rí bọ́ọ̀sì wọ̀) (iii) ‘dà’ Don’t order me about (Má dà mí kiri).
orderly: ‘tọ́’ Behave in an orderly manner (Hùwà ní ọ̀nà tí ó tọ́).
originate: ‘ṣẹ̀’ The people of Ẹ̀fọ̀n originated from Ifẹ̀ (Ifẹ̀ ni àwọn ènìyàn Ẹ̀fọ̀n ti ṣẹ̀).
ought: ‘yẹ’ He ought to take care of this children (Ó yẹ kí ó tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀).
our: ‘wa’ We put the books in our bags (A kó àwọn ìwé náà sínú báàgì wa).
out: ‘kú’ The lights were out (Àwọn iná náà kú).
outlying: ‘jìn’ It took us a long time to get to the centre of the town because we live on an outlying farm (Ó pẹ́ wa kí a tó dé àárín ìlú nítorí pé oko tí ó jìn ni a ń gbé).
outstanding: ‘kù’ Are there any outstanding jobs at all to be finished? (Ṣé àwọn iṣẹ́ kù tí a sì máa parí?).
over: (i) ‘wá’ Ask him over (Ní kí ó wá) (ii) ‘kù’ If there is any meat (left) over, give it to the dog (Bí ẹran bá kù, fún ajá).
overcome: ‘gbé’ He had an epilepsy (Epilepsy overcomes him) (Wárápá gbé e).
overflow: ‘ya’ The stream overflows its bank (Odò náà ya).
overgrown: ‘kún’ Your garden will become overgrown (Oko rẹ yóò kún).
overpower: ‘ràn’ I can overpower him (Ọwọ́ mi lè ràn án)
overripe: ‘kó’ The okro has overripen (Ilá náà ti kó)
overtake: (i) ‘bá’ I overtook him (Mo bá a) (ii) ‘yà’ He overtook me (Ó yà mí).
owe: ‘jẹ’ He owed me some money (Ó jẹ mí lówó).
own: (i) ‘ni’ He is the one who owns the money (Òun ni ó ni owó náà). (ii) ‘ti; The book is not his own (Ìwé náà kì í ṣe tirẹ̀).

No comments:

Post a Comment