Friday, 15 May 2015

P-S: Yoruba Monosyllabic Words (English-Yorùbá)


Pp

pack: ‘kún’ People packed the classroom (Èrò kún inú kíláàsì náà).
paddle: ‘tù’ Paddle your canoe (Tu ọkọ̀ rẹ).
pain: (i) ‘dùn’ He has a pain in his back (Ẹ̀yìn ń dùn ún) (ii) ‘ro’ He has a pain in his back (Ẹ̀yìn ń ro ó) (iii) ‘ta’ He has a pain in his head (Orí ń ta á).
paint: ‘kùn’ He painted the house (Ó kun ilé náà).
palpitate: ‘já’ His heart is palpitating (Àyà rẹ̀ ń já)
pare: ‘ré’ He pared off its surface (Ó ré e lórí)
paste: (i) ‘lẹ̀’ Paste up the notice (Lẹ àkíyèsí náà).
patch: ‘lẹ̀’ Patch the tyre with a rubber (Fi rọ́bà lẹ táyà náà).
patter: ‘rọ̀’ Rain was pattering onto the iron roof (Òjò  ń rọ̀ sí orí páànù náà).
pay: (i) ‘san’ He paid his money (Ó san owó rẹ̀) (ii) ‘pé’ Sheep farming pays (Ọ̀sìn àgùntàn pé) (iii) ‘gbè’ Teaching profession pays some people (Iṣẹ́ olùkọ́ gbe àwọn kan) (iv) ‘bù’ He has called to pay him his respect (Ó ti wá láti bu ọ̀wọ̀ fún un) (v) ‘wá’ He paid him a visit (Ó wá rí i)
peal: ‘lù’ The church bells were pealing (Àwọn agogo ṣọ́ọ̀ṣì náà ń lù).
peck: ‘sọ’ The bird pecks the tree (Ẹyẹ náà fi ẹnu sọ igi).
pedal: ‘wà’ The boy pedalled away on his bicycle (Ọmọkùnrin náà wa kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lọ).
peel: (i) ‘bó’ He peeled off the back of the orange (Ó bó ọsàn náà) (iii) ‘bẹ’ He peeled the yam (Ó bẹ iṣu náà) (iii) ‘hó’ He peeled oranges (Ó hó  ọsàn).
penetrate: ‘gún’ The needle penetrated the skin of her finger (Abẹ́rẹ́ gún un ní ìka).
people: ‘a’ People don’t grow old without getting married  (A kì í dàgbà má láya).
per: ‘ní’ They used to work one hour per day (Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí kan ní ojúmọ́).
perceive: ‘gbọ́’ He perceived a smell (Ó gbọ́ òórùn)
perch: ‘bà’ The birds perched on the branch (Àwọn ẹyẹ bà lé ẹ̀ka náà).
perforate: ‘lu’ The paper was perforated (Wọ́n lu bébà náà).
perform: ‘ṣe’ The children performed a play (Àwọn ọmọdé náà ṣe eré kan).
perish: (i) ‘gbé’ He perished on the water (Ó gbé sí ojú omi náà) (ii) ‘run’ The whole family has perished (Gbogbo ìdílé náà ti run) (iii) ‘kú’ The corn plants all perished (Gbogbo igi àgbàdo náà kú).
person: ‘ni’ He saw us (Ó ríni).
persuade: ‘rọ̀’ He persuaded him from doing the job (Ó rọ̀ ọ́ kó má ṣe iṣẹ́ náà).
pet: (i) ‘gẹ̀’ He petted me (Ó gẹ̀ mí) (ii) ‘kẹ́’ He pets me (Ó kẹ́ mi).
pick: (i) ‘ṣà’ I picked them from the ground (Mo ṣà wọ́n nílẹ̀) (ii) ‘já’ He picked vegetable leaves (Ó já ẹ̀fọ́) (iii) ‘re’ He picked pepper (Ó re ata) (iv) ‘tọ́’ He picked out leaves from the vegetable one by one (Ó tọ́ ẹ̀fọ́) (vi) ‘he’ He picked it (Ó he é) (vii) ‘te’ They collected (picked) them in ones and twos (Wọ́n te é jọ) (viii) ‘rọ̀’ He is picking the ones he likes (Ó ń ṣà, ó ń rọ̀) (ix) ‘mú’ Pick your hat (Mú fìlà rẹ) (x) ‘gbé’ He stopped his car and picked a boy (Ó dá káà rẹ̀ dúró ó sì gbé ọmọkùnrin kan).
pierce: (i) ‘lu’ She has her ear pierced (Wọ́n lu etí rẹ̀) (ii) ‘gún’ The arrow pierced his arm (Ọfà náà gún un lápá) (iii) ‘gbà’ Her shriek pierced the air (Ariwo rẹ̀ gba inú afẹ́fẹ́) (iv) ‘wọ̀’ A ray of light pierced the darkness (Ìtànṣán iná kan wọ inú òkùnkùn).
pinch: (i) ‘fún’ These shoes pinch me (Àwọn bàtà yìí fún mi) (ii) ‘mú’ He is pinched with cold (òtútù mú un) (iii) ‘ta’ He is pinched with poverty (Òṣì ń ta á) (iv) ‘jí’ (colloq.) Who pinched my pen? (Ta ló jí pẹ́ẹ̀nì mi?) (v) ‘mú’ You will be pinched (by police) if you are not careful (Àwọn ọlọ́pàá yóò mú ọ tí o kò bá sọ́ra).
pipe: (i) ‘mú’ He piped water into his house (Ó mú omi (ẹ̀rọ) wọ ilé rẹ̀) (ii) He piped water into his house (Ó fa omi (ẹ̀rọ) wọ ilé rẹ̀).
pique: ‘yìn’ He piqued himself by being punctual (Ó yin ara rẹ̀ fún ṣíṣe nǹkan lásìkò).
pitch: (i) ‘kọ́’ The  boy pitched a tent (Àwọn ọmọkùnrin náà kọ́ tẹ́ǹtì) (ii) ‘dà’ The man pitched his old clothes into the river (Ọkùnrin náà da àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó gbó sínú omi).
pity: ‘dùn’ It is a pity that you have to go so soon (Ó dùn wá pé o ti yára tètè ń lọ).
place: (i) ‘fi’ He placed a book in front of her (Ó fi ìwé kan sí iwájú rẹ̀).
plait: ‘dì’ He plaited her hair (Ó di irun rẹ̀).
plant: ‘gbìn’ He planted beans (Ó gbin erèé).
plaster: ‘ṣán’ He plastered the wall with cement where it was dilapidated (Ó sán ògiri ní ibi tí ó ti ya).
play: (i) ‘jẹ̀’ The goat is playing around (Ewúrẹ́ náà ń jẹ̀ kiri) (ii) ‘tẹ̀’ He is playing in the harmonium (Ó ń tẹ dùùrù) (iii) ‘ta’ They played the ayò game (Wọ́n ta ayò) (iv) ‘fọn’ They played a woodwind (Wọ́n fọn fèrè) (v) ‘ṣe’ They played hide and seek game (Wọ́n ń ṣe bojúbojú) (vi) ‘fun’ They played a wood wind (Wọ́n fun fèrè) (vii) ‘lò’ They play a violin (Wọ́n lo faolíìnì) (viii) ‘gbá’ They played football (Wọ́n gbá bọ́ọ̀lù) (ix) ‘lù’ They played the drum (Wọ́n lu ìlù).
pleasant: ‘dùn’ The food was pleasant to the taste (Oúnjẹ náà dùn lẹ́nu (Oúnjẹ náà dùn ní títọ́wò).
please: (i) ‘wù’ It pleases me (Ó wù mí) (ii) ‘yé’ Please, do it for me (Yé, bá mi ṣé) (iii) ‘wùn’ It pleases me (Ó wùn mí).
plentiful: ‘pọ̀’ The grass is plentiful in our town (Koríko náà pọ̀ ní ìlú wa).
plenty: ‘bò’ Leaves are plenty on the ìrókò tree (Igi ìrókò náà bò).
pluck: (i) ‘ká’ He plucked the orange (Ó ká ọsàn náà) (ii) ‘já’ He plucked the orange (Ó já ọsàn náà).
point: ‘nà’ He pointed his finger at me (Ó nàka sí mi)
poke: (i) ‘kò’ He (poked the fire) arranged the burning stcik so as to get a good temperature (Ó ko iná) (ii) ‘rú’ He poked the fire (Ó rú iná).
polish: ‘kùn’ He polished the shoes (Ó kun àwọn bàtà náà).
pose: ‘ṣe’ He posed as a policeman (Ó ṣe bí ọlọ́pàá).
possess: ‘ní’ He lost all his possessed (Gbogbo nǹkan tí ó ní ni ó ti sọnù).
pound: (i) ‘wẹ́’ He pounded the beans (Ó wẹ́ erèé náà) (ii) ‘gún’ He pounded yams (Ó gún iyán) (iii) ‘tẹ̀’ He bent over while pounding yams (Ó tẹ iyán) (iv) ‘rọ́’ The pounded yam is well pounded (Iyán náà rọ́).
pour: (i) ‘rọ’ He poured water into the bottle (Ó rọ omi sínú ìgò) (ii) ‘tú’ He poured water into it (Ó tú omi sí i) (iii) ‘dà’ He poured water outside (Ó da omi sí ìta) (iv) ‘dà’ The baby poured out some of the food he took (Ọmọ náà dà) (v) ‘rọ̀’ The rain poured down (Òjò rọ̀ sílẹ̀).
praise: (i) ‘yìn’ He praised him (Ó yìn ín) (ii) ‘kì’ He praised the man (Ó ki ọkùnrin náà).
prefix: (i) ‘a’ To cut (bẹ)--->razor (abẹ) (ii) ‘à’ To arrive (bọ̀)---> arrival (àbọ̀) (iii) ‘ẹ’ To carry (rù) ---> a load (ẹrù) (iv) ‘ẹ̀’ religion (ẹ̀sìn) (vi) ‘ì’ To be angry (bínú)     ---> anger (ìbínú), to bundle (dì) a bundle (ìdì) (vii) ‘i’ To die (kú) ---> death (ikú) (viii) ‘o’ To be old (gbó)     --->old age (ogbó) (ix) ‘ò’ to play (ṣeré) ---> actor (òṣèré) (x) ‘ọ̀’ To be lazy (lẹ) --->a lazy person (ọ̀lẹ) (xi) ‘ọ’ To be wise (gbọ́n) ---> wisdom (ọgbọ́n) (xii) ‘e’ To carry (gbé)--->a charm that carries one (egbé).
pregnant: (i) ‘gùn’ That goat is pregnant (Ewúrẹ́ náà ti gùn) (ii) ‘yún’ This woman is pregnant ‘Obìnrin yìí ti yún).
prepare: (i) ‘wá’ He is preparing food (Ó ń wá oúnjẹ) (ii) ‘tẹ̀’ He prepared cassava flour (ẹ̀bà) (Ó tẹ ẹ̀bà) (iii) ‘ṣú’ It is preparing (going) to rain (Òjò ti ṣú) (iv) ‘rò’ He prepared vegetables (Ó ro ẹ̀fọ́).
present: (i) ‘wá’ There were only ten boys present (Ọmọkùnrin mẹ́wàá péré ló wá).
preserve: ‘wò’ God preserves the child (Ọlọ́run wo ọmọ náà).
press: (i) ‘kán’ He is pressed for time (Ojú ń kán an) (ii) ‘rìn’ He pressed it down (Ó rìn ín mọ́lẹ̀) (iii) ‘tẹ̀’ He pressed the door bell (Ó tẹ aago tó wà lẹ́nu ọ̀nà) (iv) ‘tì’ The children are pressing each other as they tried to get out quickly (Àwọn ọmọdé náà ń ti ara wọn bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú àtitètè jáde).
previously: ‘rí’ He was there before (previously) (Ó lọ sí ibẹ̀ rí).
prick: (i) ‘gún’ A thorn pricked him in the leg (Ẹ̀gún gún un lẹ́sẹ̀) (ii) ‘sún’ A thorn pricked my hand (Ẹ̀gún sún mi lọ́wọ́) (iii) ‘ta’ I pricked my pimples (Mo ta ifọ̀n ojú mi).
print: ‘tẹ̀’ He printed the book (Ó tẹ ìwé náà).
proceed: (i) ‘pọ̀n’ They continue (proceed) on their journey (Wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n) (ii) ‘lọ’ They proceeded slowly (Wọ́n rọra ń lọ).
produce: (i) ‘yọ’ The maize produces very well (Àgbàdo náà yọ ọmọ dáadáa) (ii) ‘ṣe’ The factory produces cars (Ilé-iṣẹ́ náà ń ṣe  ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́) (iii) ‘yọ’ Trees produce leaves (Igi máa ń yọ ewé).
proficient: ‘mọ̀’ She is proficient at taking photographs (Ó mọ fọ́tò yà).
profitable: ‘gbè’ The business was profitable to all of us (Òwò náà gbe gbogbo wa).
progressive marker: (i) ‘ń’ I am going there (Mò ń lọ síbẹ̀) (ii) ‘ḿ’ I am going with him (Mo ń bá a lọ)
pronounce: ‘pè’ He pronounced my name wrongly (Ó ṣi orúkọ mi pè).
propel: ‘tù’ He propelled the boat (Ó tu ọkọ̀ náà).
proper: (i) ‘yẹ’ You aren’t wearing proper clothes for walking on mountains (O kò wọ aṣọ tí ó yẹ fún rírìn lórí òkè) (ii) ‘tọ́’ You aren’t wearing proper clothes for walking in the rain (O kò wọ aṣọ tí ó yẹ fún rírìn nínú òjò).
protrude: ‘ta’ His teeth protrude (Eyín rẹ̀ ta).
provide: (i) ‘fún’ We provided them with food (A fún wọn ní oúnjẹ) (ii) ‘tí’ You can go provided that you come here before dark (O lè lọ tí o bá ti máa dé kí ilẹ̀ tó ṣú).
provoke: ‘tọ́’ He provoked me (Ó tọ́ mi)
prudent: ‘gbọ́n’ The teacher is very prudent (Olùkọ́ náà gbọ́n gabnan).
puff: ‘fà’ He puffed at his cigarette (Ó ń fa sìgá rẹ̀)
pull: (i) ‘já’ He pulled it off (Ó já a kúrò) (ii) ‘yọ’ He pulled it out (Ó yọ ọ́ síta) (iii) ‘fà’ He pulled it (Ó fà á) (iv) ‘wọ́’ He pulled him (Ó wọ́ ọ) (v) ‘wó’ He pulled off his shirt (Ó bọ́ ṣáàtì rẹ̀) (vii) ‘wọ̀’ He pulled on his new shirt (Ó wọ ṣáàtì rẹ̀ titun).
pump: ‘pọn; She pumped water into the drum (Ó pọn omi sínú dúrọ́ọ̀mù náà) (ii) ‘pọ́’ Pump up the tyre (Pọ́ táyà náà).
punch: ‘lu’ He punched two holes in the tin of oil (Ó lu ihò méjì sí ara agolo epo náà).
puncture: ‘gún’ The needle punctured her skin (Abẹ́rẹ́ náà gún un lára).
puny: ‘rán’ This child is puny (Ọmọ yìí rán).
purchase: ‘rà’ The victory was purchased with the people’s blood (Ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn ni a fi ra ìṣẹ́gùn náà).
pure: ‘mọ́’ The water is pure (Omi náà mọ́).
pursue: ‘lé’ They pursued him to the river (Wọ́n lé e dé ìdí odò).
push: (i) ‘tì’ He pushed me (Ó tì mí) (ii) ‘bì’ He pushed me (Ó bì mí) (iii) ‘rọ́’ He pushed the vehicle on to the road (Ó rọ́ mọ́tò náà sí ojú ọ̀nà) (iv) They pushed the fire together (Wọ́n ko iná).
put: (i) ‘dé’ He put a lid on the plate (Ó dé abọ́ náà) (ii) ‘gẹ̀’ She put on her head-kerchief in a jaunty way (Ó gẹ gèlè rẹ̀ gẹngẹ) (iii) ‘fi’ Put it there (Fi í síbẹ̀) (iv) ‘pa’ They put out a light (Wọ́n pa iná náà) (v) ‘wọ̀’ He puts on his clothes (Ó wọ ẹ̀wù rẹ̀) (vii) ‘tàn’ The light has been put on (Wọ́n ti tan iná náà) (viii) ‘dé’ He puts on his cap (Ó dé fìlà rẹ̀) (xi) ‘ró’ She puts on her wrapper (Ó ró aṣọ rẹ̀) (xii) ‘yí’ Put the sentence into Yorùbá (Yí gbólóhùn yìí sí Yorùbá) (xiv) ‘kó’ He puts the books collectively on the table (Ó kó àwọn ìwé náà lé orí tábìlì) (xv) ‘wé’ She puts on her headkerchief (Ó wé gèlè rẹ̀).

Qq

quake: ‘gbọ̀n’ He was quaking with fear (Ìbẹ̀rù ń jẹ́ kí ó gbọ̀n).
quarrel: ‘jà’ They are quarrelling (Wọ́n ń jà).
quench: ‘pa’ It  was the cold water that quenched his thirst (Omi tútù náà ni ó pa òǹgbẹ rẹ̀).
question marker: (i) ‘ha’ Did you do it? (Ìwọ ha ṣe é?) (ii) ‘ti’ What’s your concern about this? (Tìrẹ ti jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí?) (iii) ‘ṣé’ Did you go? (Ṣé o lọ?) (iv) ‘dà’ Where is the book? (Ìwé náà dà?) (v) ‘bí’ Did he go? (Ó lọ bí?) (vi) ‘kí’ What is your name? (Kí ni orúkọ rẹ?) (vii) ‘ta’ Who is that? (Ta nìyẹn?)(viii) ‘dan’ Has he gone? (Ó ti lọ dan?) (ix) ‘kẹ̀’ Has he gone? (Ó ti lọ kẹ̀?).
queue: ‘tò’ They queue for food (Wọ́n tò fún oúnjẹ).
quick: ‘yá’ I was quick at my work (Iṣẹ́ mi yá mi).





Rr

race: ‘kùn’ He raced a long (Ó kùn lọ).
rain: ‘rọ̀’ It rained (Òjó rọ̀).
raise: ‘nà’ He raised his fingers up (Ó na ìka rẹ̀ sí òkè).
ram: ‘kì’ They ram down the soil (Wọ́n ki ilẹ̀).
rank: ‘kà’ I rank footballing as the most important game (Mo ka bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá sí eré tí ó ṣe pàtàkì jù).
ransack: ‘wá’ They ransacked the shop for the ball (Wọ́n wá (inú) ṣọ́ọ̀bù náà fún bọ́ọ̀lù (tí wọ́n sọnù)).
rapid: ‘yá’ The most rapid way of getting to our village is by lorry (Ọ̀nà tí ó yá jù láti dé oko wa ni nípa wíwọ ọkọ̀).
rattle: ‘jì’ She rattled the coins in the tin (Ó ji àwọn owó inú agolo náà).
reach: (i) ‘dé’ I have reached the place (Mo ti dé ibẹ̀) (ii) ‘tó’ My hands reaches the top of the table (Ọwọ́ mi tó orí tábìlì náà) (iii) ‘nà’ He reached his hand out for the bottle (Ó na ọwọ́ láti mú ìgò náà).
read: ‘kà’ He read his book (Ó ka ìwé rẹ̀).
ready: ‘yá’ I am ready to go (Ó yá mi láti lọ).
rear: ‘wò’ She reared her child until the child grew up (Ó wo ọmọ rẹ̀ dàgbà).
receive: ‘gbà’ When did you receive the letter? (Nígbà wo ni o gba lẹ́tà náà?).
recite: (i) ‘kì’ He recited his descriptive names (Ó kì í) (ii) ‘rán’ He recited the Ifa verse (Ó rán Ifá).
reckon: ‘kà’ Do you still reckon him as one of your friends? (Ṣé o sì kà á sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ?).
recognize: ‘mọ̀’ Everybody recognizes that Olú is the oldest boy in the class (Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ pé Olú ni ọmọkùnrin tí ó dàgbà jù nínú kíláàsì náà).
record: ‘ká’ We made a (tape) recording of the song (A ká orin náà sí téèpù).
recover: ‘sàn’ He is gradually recovering his health (Ó ń sàn án bọ̀)
recur: ‘rán’ The pain I had last year has recurred (Ẹsẹ̀ tí ó ń dùn mí ní ọdún tó kọjá ń rán mi).
red: (i) ‘pọ́n’ It is red (Ó pọ́n) (ii) ‘rẹ̀’ The flower is bright red (Òdòdó náà rẹ̀ dòdò).
reduce: (i) ‘dín’ He reduced the price of the good (Ó dín owó ọjà náà) (ii) ‘dẹ̀’ My cough has become reduced (Ikọ́ mi ti dẹ̀) (iii) ‘fà’ The boil on his body has reduced (Oówo ara rẹ̀ ti fà) (iv) ‘rún’ The plate is reduced to pieces (Wọ́n rún àwọn àwo náà wómúwómú).
refuse: ‘kọ̀’ He refused  to go (Ó kọ̀ láti lọ)
regard: ‘kà’ We regard him as one of our cleverest students (A kà á sí ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa tí ó mọ̀wé jù).
reject: ‘kọ̀’ We rejected his proposals (A kọ àwọn àbá rẹ̀).
rejoice: ‘yọ̀’ They rejoiced when they won a lottery (Wọ́n ń yọ̀ nígbà tí wọ́n jẹ tẹ́tẹ́).
relate: (i) ‘pa’ He told me a riddle (Ó pàlọ́ fún mi) (ii) ‘rò’ He related everything to him (Ó ro gbogbo rẹ̀ fún un) (iii) ‘tan’ They are related (Wọ́n tan).
relay: ‘jẹ́’ He relayed a message for him (Ó jẹ́ iṣẹ́ fún un).
release: (i) ‘gọ̀’ He released the hammer of his gun (Ó gọ ìbọn rẹ̀) (ii) ‘tú’ He was released from captivity (Wọ́n tú u nínú ìgbèkùn).
remain: ‘kù’ It remains three (Ó ku mẹ́ta).
remark: ‘ní’ ‘That is where Olú lived’, she remarked (Ó ní, ‘ibẹ̀ yẹn ni Olú ń gbé’).
remove: (i) ‘hu’ He removed hair from the hide (Ó hu awọ) (ii) ‘tú’ He removed cooked yam from the pot (Ó tú iṣu lórí iná)
replete: ‘yó’ My appetite is satisfied (I am replete with food) (Mo ti yó).
reply: ‘jẹ́’ I called him, he did not reply at all (Mo pè é, kò tilẹ̀ jẹ́ mi rárá).
reproduce: ‘bí’ Cats reproduce twice a year (Ológbò máa ń bímọ ní ẹ̀ẹ̀méjì lọ́dún).
require: ‘gbà’ Four months are required for completing it (Ó gba oṣù mẹ́rin láti parí rẹ̀).
rescue: ‘yọ’ We rescued the boy who fell into the river (A yọ ọmọkùnrin tí ó kó sínú odò).
resemble: ‘jọ’ He resembles me (Ó jọ mí).
return: (i) ‘dé’ My son returned yesterday (Ọmọ mi dé lánàá) (iii) ‘bọ̀’ I was returning from school when I saw him (Mo ń bọ̀ nílé láti ilé-ẹ̀kọ́ ni mo rí i) (iii) ‘fún’ I returned him all the money I owed him (Mo fún un ní gbogbo owó tí mo jẹ ẹ́).
revive: ‘jí’ They revived the girl (Wọ́n jí ọmọbìnrin náà).
revolt: ‘rú’ He stirred up revolt in the town (Ó rú ìlú).
revolve: ‘yí’ The  car wheels revolve (Ẹsẹ̀ káà náà ń yí).
rewarding: ‘pé’ My work is rewarding (Iṣẹ́ mi pé).
rich: ‘là’ He is rich (Ó là).
ride: ‘gùn’ He rode a bicycle (Ó gun kẹ̀kẹ́).
rig: ‘kọ́’ We rigged up a small hut in our garden (A kọ́ abà kékeré kan sínú ọgbà wa).
right: (i) ‘tọ́’ This is the right way to write a letter (Ọ̀nà tí ó yẹ láti kọ lẹ́tà nìyí).
ring: (i) ‘lù’ The bell rang (Agogo lù) (ii) ‘pè’ I rang Olú (Mo pe Olú (lórí fóònù) (iii) ‘dún’ The telephone is ringing (Fóònù ń dún).

rinse: ‘ṣàn’ He rinsed the clothes (Ó ṣan aṣọ).
rip: ‘ya’ He ripped his shirt on a nail (Ìṣó ya aṣọ rẹ̀).
ripe: (i) ‘gbó’ The maize has ripen (Àgbàdo náà ti gbó) (ii) ‘pọ́n’ The mangoes were ripening (Àwọn máńgò náà ti ń pọ́n).
rise: (i) ‘rú’ The smoke is rising up (Èéfín náà ń rú sókè) (ii) ‘yọ’ The sun rose at seven o’clock (Oòrùn yọ ní aago méje) (iii) ‘jí’ I don’t rise early (N kì í tètè jí) (iii) ‘fò’ The bird rose high above the sky (Ẹyẹ náà fò sókè lójú òfúrufú).
roam: ‘yí ́We roamed around the town (A yí ìgboro ká).
roar: ‘bú’ The lion roared (Kìnìún náà bú).
roast: (i) ‘yan’ He roasted the meat (Ó yan ẹran náà) (ii) ‘sun’ He roasted the meat (Ó sun ẹran náà).
rob: ‘jí’ The  man robbed me of fifty naira (Ọkùnrin náà jí mi ní àádọ́ta náírà).
roll: (i) ‘yí’ Tha ball rolled away (Bọ́ọ̀lù náà yí lọ) (ii) ‘ká’ He rolled the paper up (Ó ká bébà náà sókè).
roof: ‘bò’ We roofed our house (A bo ilé wa).
roost: ‘wọ̀’  The chicken went to roost (Adìẹ náà wọ̀)
root: ‘fà’ What is the root of the trouble between you and Olú? (Kí ni ó fa wàhálà tí ó wà láàárín ìwọ àti Olú?).
rot: ‘wù’ The fruit had been left to rot (Wọ́n ti fie ̀so yẹn sílẹ̀ láti wù)
rotate: ‘yí’ The earth rotates round the sun (Ayé ń yí oòrùn po).
rotten: (i) ‘rà’ This meat is rotten/putrid (Ẹran yìí rà) (ii) ‘kẹ̀’ The dead body of the dog is rotten (Ara òkú ajá náà ti kẹ̀)
rough: (i) ‘ru’ The river is rough (Odò yìí ru sókè) (ii) ‘le’ The child was very rough (Ọmọ náà le gan-an).
round: (i) ‘ṣù’ It is round (Ó ṣù) (rìbìtì) (ii) ‘po’ The earth turns round (Ayé ń yí po) (iii) ‘ká’ They walked round for one hour (Wọ́n rìn ká fún wákàtí kan).
row: ‘tù’ They rowed a boat (Wọ́n tu ọkọ̀).
rub: (i) ‘ra’ He rubbed his leg with oil (Ó fi epo ra ẹsẹ̀ rẹ̀) (ii) ‘pa’ I rubbed my hands with oil (Mo fi epo pa ọwọ́ mi) (iii) ‘wọ́’ He rubbed it with some medicine (Ó fi oògùn wọ́ ọ) (iv) ‘nù’ She rubbed his shoes with a cloth (Ó fi aṣọ nu bàtà rẹ̀) (v) ‘yún’/hún’ He rubbed the mosquito bite (Ó yún ibi tí ẹ̀fọn ti jẹ ẹ́).
rule: ‘fà’ He ruled a line under his name (Ó fa ìlà sí abẹ́ orúkọ rẹ̀).
rumble: (i) ‘kù’ The sky is rumbling (showing that it may rain) (Òjò ń kù) (ii) ‘kùn’ His stomach is rumbling (Inú rẹ̀ ń kùn)
run: (i) ‘fọ̀n’ He took to his heels (Ó fọ̀n ọ́n) (ii) ‘du’ He rushed away (Ó du lọ) (iii) ‘gbá’ He ran after me (Ó gbá tì mí) (iv) ‘tu’ He ran off (Ó tu lọ) (v) ‘sá’ He ran away (Ó sá lọ) (vi) ‘di’ The river has run dry (Omi náà ti di gbígbẹ/Omi náà  ti gbẹ) (vii) ‘yí’ The wall runs round the village (Ògiri náà yí abúlé náà po) (viii) ‘bó’ The colour in my new dress ran (Àwọ̀ aṣọ mi titun bó/Aṣọ mi titun bó) (ix) ‘tán’ We have ran out of sugar (Súgà wa ti tán) (x) ‘sọ’ The lorry ran into a wall (Ọkọ̀ náà sọ mọ́ ògiri).
rush: ‘rọ́’ They rushed out (Wọ́n rọ́ lọ).


Ss

sad: ‘dùn’ I am very sad to hear that your father has died (Ó dùn mí láti  gbọ́ pé bàbá rẹ ti kú).
sadden: ‘dùn’ I was saddened by the news of his death (Ìròyìn ikú rẹ̀ dùn mí).
sag: ‘jìn’ The bed sag down in the middle (Bẹ́ẹ̀dì náà jìn sínú láàárín).
sail: ‘ṣí’ He sailed the boat (Ó ṣí ọkọ̀ náà).
satisfy: (i) ‘tó’ The meat satisfied me (Ẹran náà tó mi) (ii) ‘yó’ The food satisfied me (Oúnjẹ náà yó mi).
save: (i) ‘là’ God saved him (Ọlọ́run là á) (ii) ‘gbà’ Save me (Gbà mí).
saw: ‘yùn’ They saw the plank with a saw (Wọ́n fi ayùn yun pákó náà).
says: (i) ‘ní’ He said he was coming (Ó ní òun ń bọ̀) (ii) ‘pé’ He said he was coming (Ó pé òun ń bọ̀) (iii) ‘wí’ What do you say? (Kí lo wí
?) (iv) ‘ṣe’ He  said hello to him (Ó ṣe é ní pẹ̀lẹ́) (v) ‘sọ’ What is he saying? (Kí ni ó ń sọ?).
scarce: ‘wọ́n’ It is scarce (Ó wọ́n).
scatter: ‘fọ́n’ He scaterred the beans on the ground (Ó fọ́n erèé náà sí orí ilẹ̀).
scoop: (i) ‘gbọ́n’ He scooped water out of the pot (Ó gbọ́n omi kúrò nínú ìkòkò náà) (ii) ‘wọ̀’ I scooped the pawpaw (Mo wọ ìbẹ́pẹ náà).
scorch: ‘jó’ This food has become scorched (Oúnjẹ yìí ti jó).
scramble: (i) ‘dù’ We scrambled for the money (A du owó náà) (ii) ‘fà’ The child scrambled up the hill (Ọmọ náà fà gun òkè náà).
scrape: ‘fá’ He scrapped out the remaining of the soup and threw it away (Ó fá ọbẹ̀ tí ó kù náà dànù) (ii) ‘bó’ He fell and scraped his leg (Ó ṣubú ó sì bó ní ẹsẹ̀) (iii) ‘gbẹ́’ He scraped out a hole (Ó gbẹ́ ihò) (iv) ‘ha’ Scrape the mud off your shoes with a knife (Fi ọ̀bẹ ha àbàtà ara bàtà rẹ kúrò).
scratch: (i) ‘họ’ I scratched where it itched me (Mo họ ibi tí ó ń dùn mi) (ii) ‘ti’ He scratched it with his nails and ate it (Ó fi èékánná ti í jẹ) (iii) ‘hún’ He scratched the mosquito bite (Ó yún ibi tí ẹ̀fọn ti jẹ ẹ́ lẹ́sẹ̀).
scream: (i) ‘han’ He screamed (Ó han) (ii) ‘ké’ He screamed (Ó ké).
scrub: (i) ‘kín’ He scrubbed my back (Ó kín mi lẹ́yìn) (ii) ‘fọ̀’ Scrub the floor (Fọ ilẹ̀).
seal: ‘lẹ̀’ Seal the envelope (Lẹ àpò ìwé náà).
search: ‘wá’ I searched everywhere for my book but I could not find it (Mo wá gbogbo ibi fún ìwé mi ṣùgbọ́n n kò rí i).
see: (i) ‘rí’ He saw me (Ó rí mi) (ii) ‘yé’ I don’t see what you mean (Ohun tí o ń sọ kò yé mi) (iii) ‘wò’ See who is at the door (Wo ẹni tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà) (iv) ‘kà’ I see that the governor  is coming to our town (Mo (rí i) kà pé gómìnà ń bọ̀ ní ìlú wa) (v) ‘bá’ See me home (Bá mi dé ilé) (vi) ‘sìn’ I was seen off by my friend (Ọ̀rẹ́ mi sìn mí sọ́nà) (vii) ‘já’ We saw through his pack of lies (A já àwọn irọ́ rẹ̀).
seek: ‘wá’ He sought answers to the questions (Ó wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà).
seem: ‘jọ’ It seems to be the case (Ó jọ bẹ́ẹ̀).
seep: ‘kán’ Water seeped out of the bowl (Omi kán jáde láti inú abọ́ náà).
segment: ‘gé’ He segmented the word into segments (Ó gé ọ̀rọ̀ náà sí ègé).
select: ‘yàn’ I was selected for the school football team (Wọ́n yàn mí mọ́ àwọn tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ilé-ẹ̀kọ́ náà).
sell: ‘tà’ He sold her wares (Ó ta ọjà rẹ̀).
send: (i) ‘rán’ He sent him on an errand (Ó rán an ní iṣẹ́)  (ii) ‘tẹ̀’ He sent a telegram (Ó tẹ wáyà).
separate: ‘yà’ They have separated them (Wọ́n ti yà wọ́n).
serve: ‘sìn’ She was serving the man (Ó ń sin ọ̀kùnrin náà).
set: (i) ‘wọ̀’ The sun has set (Oòrùn ti wọ̀) (ii) ‘kun’ He set fire on the bush (Ó kun ìgbẹ́) (iii) ‘ṣí’ He set out for Lagos (Ó ṣí lọ sí Èkó) (iv) ‘ṣá’ Set a match to the piece of paper (Ṣá iná sí bébà yẹn) (vi) ‘ṣọ’ Set a match to the piece of paper (Sọ iná sí bébà yẹn) (vii) ‘tò’ Set the papers in order (To àwọn ìwé yẹn lọ́wọ̀ọ̀wọ́) (viii) ‘fà’ What has set the dog barking? (Kí ni ó fà á tí ajá náà fi ń gbò?) (ix) ‘jẹ́’ The news set me thinking (Ìròyìn náà jẹ́ kí n máa ronú) (x) ‘tẹ́’ They set the food before me (Wọ́n tẹ́ oúnjẹ náà sí iwájú mi) (xi) ‘fún’ He set the labourers to cut wood (Ó fún àwọn lébìrà náà ní igi gé) (xii) ‘jó’ Don’t set the house on fire (máà jó ilé náà) (xiii) ‘dẹ’ He set the trap for the rat (Ó dẹ tàkúté fún eku náà) (xiv) ‘yàn’ What books have been set for the examination? (Àwọn ìwé wo ni wọ́n ti yàn fún ìdánwò náà?) (xv) ‘lọ̀’ The carpenter sets his saw (Káfín-ńtà náà lọ ayùn rẹ̀) (xvi) ‘pa’ He sets up a yell (Ó pa ariwo) (xvi) ‘dé’ The  rainy season has set in (Àsìkò òjò ti dé) (xviii) ‘lọ́’ Set the young flowers at one foot apart (Lọ́ àwọn àdòdó wẹ́wẹ́ náà ní ẹsẹ̀ bàtà kọ̀ọ̀kan sí ara wọn) (xviii) ‘jìn’ The house is well set back from the road (Ilé náà jìn sí títì) (xix) ‘ná’ The book set me back N20 (Ìwé náà ná mi ní ogún náírà).
settle: (i) ‘dó’ He settled at Ìbàdàn (Ó dó sí Ìbàdàn) (ii) ‘bà’ The bird settled on a branch (Ẹyẹ náà bà sórí ẹ̀ka igi) (iii) ‘wọ́’ The cold has settled on his chest (Òtútù ti wọ́ sí i láyà) (iv) ‘fẹ́’ What have you settled to do about it? (Kí ni o fẹ́ láti ṣe nípa rẹ̀?) (v) ‘san’ Settle your bill (San owó tí o jẹ) (vi) ‘gbà’ I had opened to get N100 for the book but I had settle for N80 (Ọgọ́rùn-ún náírà ni mo fẹ́ ta ìwé náà ṣùgbọ́n mo wá gba ọgọ́rin náírà).
sever: (i) ‘gé’ He severed the head of the goat from its body (Ó gé orí ẹwúrẹ́ náà kúrò ní ara rẹ̀) (ii) ‘já’ The rope severed (Okùn náà já).
sew: (i) ‘rán’ He sewed the cloth (Ó rán aṣọ náà) (ii) ‘ṣọ’ He sewed together the broken calabash (Ó sọ igbá náà) (iii) ‘ta’ He sewed the button of his shirt on (Ó ta bọ́tìnì ṣáàtì rẹ̀).
sex: (i) ‘dó’ (colloquial) He has sexual intercourse with her (Ó dó o) (ii) ‘mọ’ He had sexual intercourse with her wife (Ó mọ ìyàwó rẹ̀) (iii) ‘lò’ (slang) He had sexual intercourse with her (Ó lò ó)
shake: (i) ‘bọ̀’ He shook hand together with him (Ó bọ̀ ọ́ lọ́wọ́) (ii) ‘gbọ̀n’ He shook his head (Ó gbọn orí) (iii) ‘jì’ He shook it (Ó jì í) (iv) ‘mì’ He is shaking the tree (Ó ń mi igi náà) (v) ‘gbò’ He shook the tree (Ó gbo igi náà) (vi) ‘gbọ̀n’ He shook his head to say ‘No’ (Ó gbọn orí rẹ̀ láti sọ pé ‘Rárá’).
shall: (i) ‘á’ We shall go (A á lọ) (ii) ‘ó’ I shall go (N ó lọ) (iii) ‘lè’ You shall not have it, it is mine (Kò lè di tìrẹ, tèmi ni) .
shame: (i) ‘họ̀’ He said shame on me (Ó ṣe họ̀ mi) (ii) ‘tẹ́’ He has been put to shame (Ó ti tẹ́).
shape: ‘ṣù’ He shaped the clay into a ball (Ó ṣu amọ̀ náà rìbìtì).
share: (i) ‘san’ Let me share with you in the bus fare (Jẹ́ kí n bá ọ san nínú owó bọ́ọ̀sì náà) (ii) ‘pín’ Share out N100 among five people (Pín ọgọ́rùn-ún náìrà fún ènìyàn márùn-ún).
sharp: ‘mú’ The knife is sharp (Ọ̀bẹ náà mú)
sharpen: (i) ‘pọ́n’ He sharpened it (Ó pọ́n ọn) (ii) ‘gbẹ́’ He sharpened the pencil (Ó gbẹ́ lẹ́ẹ̀dì náà).
shave: ‘fá’ He shaved his hair (Ó fá irun rẹ̀).
she: ‘ó’ She went there (Ó lọ síbẹ̀).
shed: ‘bọ́’ The people shed their clothes (Àwọn ènìyàn náà bọ́ aṣọ wọn).
shell: ‘pa’ They shelled palmnuts (Wọ́n pa ẹ̀kùrọ́)
shift: ‘sún’ He shifted for him (Ó sún fún un)
shine: (i) ‘ràn’ The sun is shining (Oòrùn ń ràn) (ii) ‘kọ’ The shoes are shining (Àwọn bàtà náà ń kọ)
shiver: ‘gbọ̀n’ He is shevering (Ó ń gbọ̀n)
shoot: (i) ‘jù’ As the car hit the tree, the occupants were shot out (Bí káà náà ti forí sọ igi, ó ju àwọn tí ó wà nínú rẹ̀ síta) (ii) ‘sọ’ As the car hit the tree, the occupants were shot out (Bí káà náà ti forí sọ igi, ó sọ àwọn tí ó wà nínú rẹ̀ síta) (iii) ‘lọ’ Rents have shot up (Owó ilé ti lọ sókè) (iv) ‘ga’ Olú is shooting up fast (Olú tètè ń ga sí i) (v) ‘wù’ Rose bushes shot again after being cut (Igbó àdòdó róòsì tún wù lẹ́yìn tí wọ́n ti gé e) (vi) ‘hù’ Rose bushes shot again after being cut (Igbó àdòdó róòsì tún hù lẹ́yìn tí wọ́n ti gé e) (vii) ‘ta’ He shot the arrow (Ó ta ọfà) (viii) ‘yìn’ He shot the gun (Ó yan ìbọn) (x) ‘pa’ The soldier was shot for desertion (Wọ́n pa sójà náà fún sísá tí ó sá).
shout: (i) ‘fọ́’ He is shouting out boastingly (Ó ń fọ́ táá) (ii) ‘ké’ He is shouting with all his power (Ó ń ké tagbára tagbára)
show: ‘hàn’ She had torn her dress under the arm, but it didn’t show (Ó ya ẹ̀wù rẹ̀ ní abíyá ṣùgbọ́n kò hàn).
show off: ‘rọ́’ The boy is showing off (Ọmọkùnrin náà ń rọ́).
shred: ‘ya’ The dog shredded the piece of paper (Ajá náà ya bébà náà).
shrewd: ‘bẹ’ The boy is too shrewd (Ọmọkùnrin yẹn bẹ)
shriek: ‘ké’ He shrieked as the snake came towards her (Ó ké nígbà tí ejò náà ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀).
shrug: (i) ‘sọ’ She shrugged her shoulder (Ó sọ èjìká) (ii) ‘gún’ She shrugged her shoulder (Ó gún èjìká).
shudder: ‘gbọ̀n’ He shudders when he sees the snake (Ó ń gbọ̀n nígbà tí ó rí ejò náà).
shut: ‘tì’ He shut the door (Ó ti ilẹ̀kùn náà).
sick: (i) ‘bì’ Olú was sick when he ate too much pounded yam (Olú bì nígbà tí ó jẹ iyàn ní àjẹjù) (ii) ‘rẹ̀’ his father was sick (Ó rẹ bàbá rẹ̀).
sieve: (i) ‘kù’ He sieved the yam flour (Ó ku ẹ̀lùbọ́ náà).
sift: (i) ‘jọ̀’ He sifted the yam flour (Ó jọ èlùbọ́ náà).
sight: ‘rí’ I caught sight of an empty seat (Mo rí ìjókòó tí kò sí ènìyàn lórí rẹ̀).
silent: ‘wọ̀’ He kept silent (Ó wọ̀ ṣin).
sing: (i) ‘kọ’ He sang a song (Ó kọ orin) (ii) ‘wì’ He singed it (Ó wì í)
sink: (i) ‘rì’ The ship sank into the river (Ọkọ̀ náà rì sínú odò) (ii) ‘wọ̀’ The water sank into the ground (Omi náà wọ inú ilẹ̀).
sir: ‘sà’ I thank you sir (Mo dúpẹ́ sà).
situate: (i) ‘wà’ The house is situated on a hill (Orí òkè ni ilé náà wà) (ii) ‘kọ́’ They situated the factory near the town (Wọ́n kọ́ ilé-iṣẹ́ náà sí ẹ̀gbẹ́ ìlú).
sketch: ‘yà’ He sketched a diagram (Ó ya àwòrán kan).
skid: (i) ‘yọ́’ The car skilledded on a pool of oil (Káà náà yọ́ lórí adágún epo) (ii) ‘yọ̀’ The car skidded on a pool of oil (Káà náà yọ̀ lórí adágún epo)
skim: ‘ré’ He skimmed the water of its surface (Ó ré omi orí rẹ̀).
skin: ‘bó’ I skinned the snake (Mo bó awọ ejò).
skinny: ‘tin’ The man has a skinny arm (Ọkùnrin náà tin lápá).
slack: (i) ‘rẹ̀’ She feels slack this morning (Ó rẹ̀ ẹ́ láàárọ̀ yìí) (ii) ‘tẹ̀’ The rope is not stretched tightly, it hung slack in the water (Wọn kò fa okùn náà ro, ó tẹ̀ sí inú omi).
slant: ‘tì’ The ladder was slanted against the wall (Wọ́n fi àbà náà ti ògiri).
slap: ‘gbá’ He slapped my ears (Ó gbá mi létí).
slaughter: ‘dú’ He slaughtered it (Ó dú u) ‘pa’ He slaughtered it (Ó pa á).
sleep: ‘sùn’ He slept (Ó sùn).
slender: ‘tin’ He has a slender arm (Apá rẹ̀ tin).
slew: ‘dà’ They slew the babies on their backs round the front (Wọ́n da àwọn ọmọ náà).
slice: (i) ‘rẹ́’ He sliced the vegetable (Ó rẹ́ ẹ̀fọ́ náà) (ii) ‘gé’ He sliced the meat thin (Ó gé ẹran náà kéékèèkéé).
slide: (i) ‘yọ̀’ He slid down the shining floor (Ó yọ́ lọ lórí ilẹ̀ tó ń dán).
slimy: (i) ‘yọ̀’ A worm feels slimy when you touch it (Ara ekòló máa ń yọ̀ tí o bá fọwọ́ kàn án) (ii) ‘yọ́’ A worm feels slimy when you touch it (Ara ekòló máa ń yọ́ tí o bá fọwọ́ kàn án).
sling: ‘jù’ He slung his book on the table (Ó ju ìwé rẹ̀ sí orí tábìlì).
slip: (i) ‘yọ̀’ He slipped and fell (Ó yọ̀ ṣubú) (ii) ‘yọ́’ He slipped and fell (Ó yọ́ ṣubú) (iii) ‘bọ́’ The fish slipped out of his hand (Ẹja náà bọ́ ní ọwọ́ rẹ̀) (iv) ‘wọ̀’ He slipped into a dress (Ó wọ ẹ̀wù kan) (v) ‘bọ́’ He slipped out a dress (Ó bọ́ ẹ̀wù kan) (vi) ‘fi’ He slipped ten naira into his hand (Ó fi náírà mẹ́wàá bọ̀ ọ́ lọ́wọ́).
slippery: (i) ‘yọ̀’ The floor is slippery (Ilẹ̀ náà ń yọ̀) (ii) ‘yọ́’ The floor is slippery (Ilẹ̀ náà ń yọ́).
slit: ‘já’ I slit opened the letter with a knife (Mo fi ọ̀bẹ já lẹ́tà náà).
slop: ‘ṣẹ́’ The tea slopped into the saucer (Tíì náà ṣẹ́ sí inú sọ́sà).
slough: ‘bọ́’ The snake slaughed its skin (Ejò náà bọ́họ)
slow: ‘fà’ He is a bit slow (Ó fà díẹ̀). (Ẹnìkan tí ó máa ń fà ni)
sluggish: ‘fà’ He is a sluggish person (Ó ń fà gọ̀lọ̀)
slumber: (i) ‘wo’ Adé neither sleep nor slumbered (Adé kò sùn kò wo) (ii) ‘sùn’ They slumbered away that afternoon (Wọ́n sùn lọ ní ọ̀sán ọjọ́ náà).
smack: (i) ‘lù’ He smacked him (Ó lù ú) (ii) ‘nà’ He smacked him (Ó nà án).
smart: ‘ta’ Iodine smarts when it is put on a cut (Ayodáìn máa ń ta tí a bá fi sí egbò).
smash: ‘fọ́’ He smashed the plate (Ó fọ́ àwo náà).
smear: (i) ‘fọ́n’ They smeared the child’s face with chocolate (Wọ́n fọ́n ṣokoléètì sí ọmọ náà lójú) (ii) ‘wọn’ They smeared the child’s face with chocolate (Wọ́n wọ́n sṣokoléètì sí ọmọ náà lójú) (iii) ‘bá’ His hand were smeared with blood (Ẹ̀jẹ̀ bá a lọ́wọ́).
smell: (i) ‘ta’ It smells nice (Ó ń ta sánsán) (ii) ‘rùn’ It is smelling (Ó ń rùn).
smile: ‘rín’ He smiled at the children (Ó rín sí àwọn ọmọ náà).
smite: ‘gbá’ His knees smote together (Àwọn orúnkún rẹ̀ ń gbá ara wọn).
smith: ‘rọ’ He smithed a hoe (Ó rọ ọkọ́).
smoke: ‘mu’ He smoked cigarettes (Ó mu sìgá).
smooth: ‘dán’ It is smooth (Ó dán).
smoother: ‘bò’ I was smothened in dust (Eruku bò mí).
snap: (i) ‘kán’ He snapped my stick (Ó kán igi mi) (ii) ‘dá’ He snapped the stick into two (Ó dá igi náà sí méjì) (iii) ‘já’ The rope snapped (Okùn náà já) (iv) ‘yà’ He snapped me (Ó yà mí) (ní fọ́tò) (v) ‘yán’ The dog snapped at him but did not bite him (Ajá náà yán an ṣùgbọ́n kò bù ú jẹ) (vi) ‘kó’ The cheap shoes were quickly snapped up (Wọ́n tètè kó àwọn bàtà tí kò wọ́n náà) (vii) ‘ta’ He snapped his finger at him (Ó ta ìka sí i).
sneak: ‘yọ́’ Where are you sneaking up to? (Níbo ni ò ń yọ́ lọ?).
sneer: ‘gàn’ He sneered at me (Ó gàn mí).
sneeze: ‘sín’ He sneezed (Ó sín).
sniff: ‘fà’ He sniffed up the snuff through the nostrils (Ó fa aáṣáà náà síhò imú).
soak: ‘rẹ’ He soaked the clothes in water (Ó rẹ aṣọ náà sínú omi).
soar: ‘ga’ The price of grain has soared because of war (Iye tí wọ́n ń ta àgbàdo ti ga sí i nítorí ogun).
sober: ‘dá’ He has recorvered from his drunkness (He is sober) (Ojú rẹ̀ ti dá).
soft: (i) ‘dẹ̀’ The orange is soft (Ọsàn náà dẹ̀) (ii) ‘rọ̀’ The orange is soft (Ọsàn náà rọ̀).
soften: ‘rọ̀’ The earth softened (Ilẹ̀ rọ̀).
soggy: ‘rin’ The rain has made the ground soggy (Òjò náà rin ilẹ̀)
solder: ‘jó’ He soldered them together (Ó jó wọn pọ̀).
solidify: ‘le’ Gold is usually solid (Góòlù máa ń sáábà le ni).
solid: ‘dì’ The water has solidified (Omi náà ti dì)
some: ‘kan’ Some girls are dancing (Àwọn ọmọbìnrin kan ń jó).
soothe: (i) ‘rọ̀’ I soothed my son when he was crying (Mo rọ ọmọ mi nígbà tí ó ń sunkún) (ii) ‘tù’ I soothed the man when he was angry (Mo tu ọkùnrin náà nígbà tí ó ń bínú).
sore: ‘kan’ My arm is sore when I was bitten by the mosquito (Apá  tí ẹ̀fọn ti jẹ mí ń kan mí)
sorry: ‘dùn’ I am very sorry, I can’t come to your party (Ó dùn mí, n kò lè wá sí patí rẹ).
sound: (i) ‘ró’ The clock is making a tick-tock sound (Aago náà ń ró kẹ kẹ kẹ) (ii) ‘dún’ It sounds like a gun (Ó ń dún bí ìbọn).
sour: ‘kan’ The soup is sour (Ọbẹ̀ náà kan)
sow: (i) ‘sú’ He sowed the seeds (Ó sú àwọn èso náà) (ii) ‘gbìn’ He sowed rice (Ó gbin ráìsì).
spare: ‘yá’ Spare me your money (Yá mi lówó rẹ).
sparkle: (i) ‘tàn’ Drops of water sparkles in the sun (Èkíkán omi máa ń tàn nínú oòrùn) (iii) ‘dán’ The diamond sparkled in the bright light (Dáyámọ́ǹdì náà ń dán bí iná tí ó mọ́lẹ̀ náà ṣe tàn sí i).
speak: (i) ‘fọ̀’ He spoke to me (Ó fọ̀ sí mi) (ii) ‘bẹ’ He spoke cheekly to me (Ó bẹ sí mi) (iii) ‘sọ’ He can speak Yorùbá (Ó lè sọ Yorùbá).
spend: (i) ‘ná’ He spent his money (Ó ná owó rẹ̀) (ii) ‘lò’ I spent one hour at home (Mo lo wákàtí kan nínú ilé) (iii) ‘fi’ He spent all his time reading (Ó fi gbogbo àkókò rẹ̀ kàwé).
spicy: ‘ta’ I like spicy food (Mo fẹ́ràn oúnjẹ tí ó bá ta).
spilt: ‘dà’ The water spilt over my book (Omi dà sí ìwé mi)
spin: (i) ‘gbọ̀n’ He is spinning his top (Ó ń gbọn òògo) (ii) ‘yí’ The tyres of the car were spinning (round) (Àwọn táyà káà náà ń yí (po)) (iii) ‘ran’ Spiders spin thread (Aláǹtakùn ń ran òwú).
spit: (i) ‘tu’ He spit out a fly which has flown into his mouth (Ó tu eṣinṣin tó kó sí i lẹ́nu jáde) (ii) ‘bẹ́’ They spit out saliva (Wọ́n bẹ́ itọ́) (iii) ‘pọ̀’ The baby spat his food all over the table (Ọmọ náà pọ gbogbo oúnjẹ rẹ̀ sí orí tábìlì).
splash: (i) ‘ta’ Water splashes over my leg (Omi ta sí mi lẹ́sẹ̀) (ii) ‘kán’ The tap splashes (Omi ẹ̀rọ ń kán) (iii) ‘yán’ Splash water on the floor (Yán omi sílẹ̀).
split: (i) ‘là’ We split the wood (A la igi náà) (ii) ‘pín’ We split up the work between us (A pín iṣẹ́ náà láàárín ara wa) (iii) ‘sán’ There is a split in the wood of this table (Igi tábìlì yìí sán).
spot: (i) ‘so’ He has spot on his body (Ara rẹ̀ so) (ii) ‘sú’ He has spot on his body (Ara rẹ̀ sú) (iii) ‘mú’ He spotted the winner in the race (Ó mú ẹni tí ó borí nínú eré ìje náà) (iv) ‘rí’ He spotted his friend in a crowd (Ó rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ láàárín èrò).
sprain: (i) ‘sẹ́’ He sprained my leg (Ó sẹ́ mi ní ẹsẹ̀) (ii) ‘wọ́n’ I sprained my leg ( Ẹsẹ̀ mi wọ́n) (iii) ‘rọ́’ He sprained his leg (Ó fi ẹsẹ̀ rọ́)
spray: ‘fín’ He sprayed the room with sheltox (Ó fi ‘sheltox’ fín yàrá náà).
spread: (i) ‘kẹ̀’ The fire is spreading (Iná náà ń kẹ̀) (ii) ‘fà’ The beans have spread out (Ẹ̀wà náà ti fà kálẹ̀) (iii) ‘ràn’ This disease has started spreading (Àìsàn yíí ti ń ràn) (iv) ‘tẹ́’ He spread out the mat (Ó tẹ́ ẹní náà) (v) ‘nà’ The bird speads its wing (Ẹyẹ náà na ìyẹ́ rẹ̀).
spring: (i) ‘rú’ The leaves are springing up (Àwọn ewé náà ti ń rú bọ̀) (ii) ‘fò’ He sprang up (Ó fò sókè) (iii) ‘ta’ The branch sprang back and hit me (Ẹ̀ka igi náà ta padà ó sì bá mi) (iv) ‘wù’ Weeds are spinning up everywhere (Igbó ń wù káàkiri gbogbo ibi).
sprinkle: (i) ‘fọ́n’ I sprinkled water on it (Mo fọ́n omi sí i) (ii) ‘wọ́n’ He sprinkled water on the ground (Ó wọ́n omi sí ilẹ̀).
sprout: (i) ‘yọ’ This yam has sprouted (Iṣu yìí ti yọ) (ii) ‘sú’ The plants sprouted abundantly (Àwọn ewé okó sú) (iii) ‘hù’ The grasses sprouted (Àwọn koríko náà hù) (iv) ‘sọ’ The tree sprouted leaves at the side (Igi náà sọ ewé lẹ́gbẹ̀ẹ́).
squash: (i) ‘fọ́’ He squashed them together (to form a solid mass) (Ó fọ́ wọn pọ̀) (ii) ‘fún’ These news shoes squash my feet up (Àwọn bàtà titun yìí fún mi lẹ́sẹ̀) (iii) ‘fọ́’ The ripe tomatoes at the buttom of the box had been squashed (Àwọn tòmátò pípọ́n tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àpótí náà ti fọ́).
squeak: (i) ‘ké’ The rat squeaked and ran away (Eku náà ké ó sì sá lọ) (ii) ‘dún’ The door squeaked when I opened it (Ilẹ̀kùn náà dún nígbà tí mo fí i).
squeeze: (i) ‘pọ́’ He squeezed himself into the house (Ó pọ́ wọlé) (ii) ‘fún’ He squeezed my hand (Ó fún mi lọ́wọ́) (iii) ‘gbo’ I squeezed the leaves in the water (Mo gbo ewé náà nínú omi).
stab: ‘gún’ He stabbed him with a knife (Ó gún un lọ́bẹ)
stale: ‘gan’ The bread has gone stale (Búrẹ́dì náà ti gan).
stamp: ‘pa’ He stamped out the fire (Ó pa iná náà).
stand: (i) ‘ró’ He stood in the front of his master (Ó ró síwájú ọ̀gá rẹ̀) (ii) ‘so’ The scar on his leg stands out (Àpá ẹṣẹ̀ rẹ̀ so) (iii) ‘wà’ The house stands at the top of the hill (Ilé náà wà ní orí òkè) (iv) ‘ṣe’ Will you stand as god mother for the child who is being baptized? (Ṣé o ó ṣe ìyá ìsàmì fún ọmọ tí ó fẹ́ gba ìbatisí?).
start: (i) ‘dé’ It has started raining (Òjò ti dé) (ii) ‘bẹ́’ Trouble has started (Ọ̀ràn ti bẹ́) (iii) ‘ṣí’ He started up a motor car (Ó ṣí ọkọ̀).
state: (i) ‘sọ’ He stated that he had bought the book (Ó sọ pé òun ti ra ìwé náà) (ii) ‘ní’ He stated that he had bought the book (Ó ní òun ti ra ìwé náà) (iii) ‘pé’ He stated that he had bought the book (Ó pé òun ti ra ìwé náà) (iv) ‘wí’ He stated that he had bought the book (Ó wí pé òun ti ra ìwé náà).
steal: (i) ‘kó’ He stole their money (Ó kó owó wọn) (ii) ‘jí’ He stole my money (Ó jí mi lówó) (iii) ‘yọ́’ He stole into the room (Ó yọ́ wọ yàrá náà).
stealth: (i) ‘yọ́’ He did good by stealth (Ó yọ́ rere ṣe) (ii) ‘jí’ He did good by stealth (Ó jí rere ṣe).
steathily: ‘yọ́’ He walked steathily/fortively on tiptoe (Ó ń yọ́ rìn).
step: ‘tẹ̀’ He is stepping on the ground gently (Ó ń tẹ ilẹ̀ jẹ́jẹ́).
stern: ‘le’ His father is too stern (Bàbá rẹ̀ ti le jù).
stew: (i) ‘sè’ She stewed the meat (Ó se ẹran náà) (ii) ‘bọ̀’ She stewed the meat (Ó bọ ẹran náà).
stick: (i) ‘lẹ̀’ I stuck a stamp on the letter (Mo lẹ sítá
ǹbù mọ́ lẹ́tà náà) (ii) ‘gún’ He stuck the needle through his finger (Ó fi abẹ́rẹ́ gún ìka rẹ̀) (iii) ‘rì’ The tyre of the car stuck in the mud (Táyà káà náà rì sínú àbàtà).
sticky: ‘yọ̀’ The gum is thick and sticky (Gọ́ọ̀mù náà ń yọ̀)
stiff: ‘le’ The board is stiff (Pákó náà le).
stiffen: ‘wo’ The small animal stiffened with fear as it saw the lion coming (Ẹ̀rù mú ẹranko kékeré náà wo nígbà tí ó rí kìnìún tí ó ń bọ̀).
stiffer: ‘le’ The examination was stiffer than I had expected (Ìdánwò náà le ju bí mo ti lérò tẹ́lẹ̀).
still: ‘ṣì’ I still remember my first day at school (Mo ṣì rántí ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́).
sting: (i) ‘jó’ The insect called ‘ìpín’ stung him (Ìpín jó o) (ii) ‘ta’ The bees sting him (Oyin ta á).
stink: ‘rùn’ The dead fish stinks (Òkú ẹja náà ń rùn).
stir: (i) ‘ru’ He stirred sediments in the water (Ó rú omi náà) (ii) ‘rò’ He stirred the soup on the fire (Ó ro ọbẹ̀ ní orí iná) (iii) ‘mi’ Not a leaf was stirring (Ewé kankan kò mì) (iv) ‘pò’ He stirred his tea (Ó po tíì rẹ̀) (v) ‘kò’ He stirred the fire (Ó ko iná náà).
stitch: ‘ta’ Have you stitched your button on your shirt? (Ṣé o ti ta bọ́tìnì rẹ mọ́ ṣáàtì rẹ?)
stock: ‘tà’ They do not stock yams, only rice (Wọn kì í ta iṣu, ráìsì nìkan ni wọ́n ń tà).
stop: ‘pa’ They stopped drumming (Wọ́n pa ìlù).
straight: (i) ‘gún’ It was straight (Ó gún) (ii) ‘tọ́’ It was straight (Ó tọ́).
strain: (i) ‘rọ́’ He strained his leg (Ó rọ́ lẹ́sẹ̀) (ii) ‘yọ̀’ He has strained the tea – There are no tea leaves in the cup (Ó ti yọ́ tíì náà – kò sí ewé tíì nínú kọ́ọ̀bù náà).
strand: ‘tàn’ He was stranded in a foreign country (Ó tàn sí ilẹ̀ àjèjì).
stretch: (i) ‘nà’ He stretch it out (Ó nà án) (ii) ‘ta’ He stretched out a rope (Ó ta okùn) (iii) ‘fà’ Rubber stretches (Rọ́bà máa ń fà).
strict: ‘le’ The teacher is very strict (Tíṣà náà le).
strike: (i) ‘ṣá’ He strikes a match (Ó ṣá ìṣáná) (ii) ‘lù’ I struck him with my stick (Mo fi igi mi lù ú) (iii) ‘nà’ I struck him with my stick (Mo fi igi mi nà án) (iv) ‘gbá’ He struck me on the chin (Ó gbá mi lágbọ̀n).
strip: ‘bọ́’ Olú stripped his shirt (Olú bọ́ ṣáàtì rẹ̀).
stroll: ‘rìn’ We stroll round the village (A rìn yí abúlé náà ká).
strong: (i) ‘le’ The liquor is strong (Ọtí náà le) (ii) ‘rọ́’ The rope is strong (Okùn náà rọ́)
stuck: (i) ‘há’ A bone got stuck in his throat (Eegun há a  lọ́fun) (ii) ‘rì’ The car got stuck in the mud (Káà náà rì sínú ẹrẹ̀).
study: ‘kọ́’ I am studying art (Mò ń kọ́ àwòrán yíyà).
stuff: (i) ‘kún’ The bed was stuffed with the cotton (Bẹ́ẹ̀dì náà kún fún òwú) (ii) ‘dí’ My nose is stuffed up (Imú mi dí); I stuffed up a hole (Mo dí ihò kan).
stupid: (i) ‘dẹ̀’  He has a stupid character (Ó dẹ̀) (ii) ‘gọ̀’ He is stupid (Ó gọ̀) (iii) ‘fà’ He is very stupid (Ó fà púpọ̀).
submit: ‘fún’ I submitted my paper to the teacher (Mo fún olùkọ́ náà ní ìwé mi).
subside: ‘rọ̀’ The storm began to subside (Ìjì náà bẹ̀rẹ̀ síí rọ̀).
subtract: ‘yọ’ I have subtracted five for your bad spelling (Mo ti yọ aárùn-ún fún àwọn ọ̀rọ̀ tí o sì kọ).
such: ‘bí’ They want some juicy fruits such as orange (Wọ́n ń fẹ́ èso tí ó kún fún omi bíi ọsàn).
suck: ‘mu’ The baby is sucking her mother’s breast (Ọmọ náà ń mu ọyàn ìyá rẹ̀).
suddenly: ‘ku’ It befell me suddenly (Ó kàn mí ku).
suffer: (i) ‘ṣẹ̀’ He suffered a bereavement (Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ẹ́) (ii) ‘jó’ He suffered a bereavement (Iná jó o).
sufficient: ‘tó’ It is sufficient (Ó tó)
summon: ‘pè’ He summoned his minister (Ó pe mínísítà rẹ̀).
supply: ‘kó’ The company supplied paper to the printer (Ilé-iṣẹ́ náà kó bébà fún atẹ̀wé náà).
support: ‘gbè’ He took my part (Ó gbè mí).
suppose: (i) ‘rò’ I supposed that he had left (Mo rò pé ó ti lọ) (ii) ‘yẹ’ What are you supposed to be doing? (Kí ni ó yẹ kí o máa ṣe?)
sure: (i) ‘á’ It is sure to rain tomorrow (Òjò á rọ̀ lọ́la) (ii) ‘ó’ It is sure to rain tommorrow (Òjò ó rọ̀ lọ́la).
surpass: ‘jù’ Adé surpass Òjó in strength (Adé lágbára ju Òjó lọ).
survive: ‘yè’ He survived (Ó yè).
suspect: ‘rò’ He seems poor, but I suspect that he has quite a lot of money (Ó jọ òtòsì ṣùgbọ́n mo rò pé ó lówó lọ́wọ́ gan-an ni).
swagger: ‘yan’ He is swaggering along slowly (Ó ń yan lọ).
swallow: ‘mì’ He swallowed the pill (Ó mi oògùn oníkóró náà).
swarm: (i) ‘ṣù’ The bees swarmmed round him (Àwọm oyin ṣù bò ó) (ii) ‘rọ́’ The children swarmmed into the classroom (Àwọn ọmọ náà rọ́ wọ inú kíláàsì náà).
sway: ‘mì’ The dancers swayed as they stood (Àwọn oníjó náà ń mì bí wọ́n ṣe dúró (Àwọn oníjó náà ń mì lójú kan)).
sweep: (i) ‘gbá’ He swept the floor (Ó gbá ilẹ̀) (ii) ‘rọ́’ The crowd swept down the hill (Àwọn èrò náà dà wálẹ̀ láti òkè).
sweet: ‘dùn’ It is sweet (Ó dùn).
swell: (i) ‘lé’ My arm is swollen (Apá mi lé) (ii) ‘wú’ His body is swollen (Ara rẹ̀ wú).
swim: ‘wẹ̀’ He knows how to swim (Ó mọ̀ ọ́n wẹ̀).
swing: (i) ‘fi’ He swung the rope (Ó fi okùn náà) (ii) ‘ṣán’ He swung arm to and from (Ó ṣán apá rẹ̀).
switch: (i) ‘pa’ Switch off the light (Pa iná náà) (ii) ‘yí’ Switch on the radio (Yí rẹ́díò yẹn) (iii) ‘yín’ Switch on the radio (Yín rẹ́díò yẹn)
swirl: ‘hó’ The river is swirling along (Odò yìí ń hó)

No comments:

Post a Comment