Friday, 15 May 2015

A-E: Yoruba Monosyllabic Words (English-Yorùbá)



  
Aa

a: ‘kan’ I gave him a book (Mo fún un ní ìwé kan).
able: ‘lè’ You won’t be able to understand it (Kò níí lè yé ọ).
about: (i) ‘fẹ́’ I am about to become tired (Ó fẹ́ẹ́ rẹ̀ mí) (ii) ‘tó’ He is about my size (Ó tó mi)
absorb: (i) ‘fà’ The cloth absorbed all the water in the bowl (Aṣọ náà fa gbogbo omi inú abọ́ náà) (ii) ‘mọ̀’ I have not absorb all their rules (N kò tíì mọ gbogbo òfin wọn).
abundant: ‘pọ̀’ Maize was abundant last year (Àgbàdo pọ̀ ní ọdún tí ó kọjá).
abuse: ‘bú’ He abused me (Ó bú mi)
accede: ‘gùn’ He acceded to the throne (Ó gun orí ìtẹ́)
accept: (i) ‘dà’ The sacrifice has been accepted (Ẹbọ náà ti dà) (ii) ‘fín’ The sacrifice would be accepted (Ẹbọ náà á fín) (iii) ‘gbọ́’ He accepts what I say (Ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi) (iv) ‘gbà’ He accepted the money (Ó gba owó náà) (v) ‘yàn’ The kolanuts have been accepted by the diety (Obì náà ti yàn).
acceptable: ‘wọ̀’ It is acceptable to me (Ó wọ̀ fún mi).
accommodate: ‘gbà’ Our house can accommodate four people (Ilé wa lè gba ènìyàn mẹ́rin).
accompany: (i) ‘sìn’ He accompanied him there (Ó sìn ín lọ sí ibẹ̀) (ii) ‘bá’ He accompanied Olú to the doctor (Ó bá Olú lọ sọ́dọ̀ dókítà).
accuse: ‘mú’ He accused me of stealing (Ó mú mi lólè)
accurate: ‘pé’ It is accurate (Ó pé).
ache: (i) ‘lọ́’ I have stomach-ache (Inú ń lọ́ mi) (ii) ‘sán’ I have a headache (Ó rí ń sán mi) (iii) ‘fọ́’ I have headache (Ó rí ń fọ́ mi) (iv) ‘run’ I am having stomach-ache (Inú ń run mí).
achieve: ‘gbà’ Do you aknowledge that you are wrong? (Ṣé o gbà pé o jẹ̀bi?).
acquire: ‘ní’ John acquired his knowledge of Yorùbá studying hard (Jọ̀ọ́nù ní ìmọ̀ Yorùbá nípa kíkàwé kárakára).
act: ‘dá’ He acted alone (Ó dá a ṣe).
add: ‘rò’ He added three to four to make seven (Ó ro ẹẹ́ta mọ́ ẹẹ́rin láti di eéje).
address: ‘pè’ We addressed our junior brother as Randa (Ráńdà ni a máa ń pe àbúrò wa ọkùnrin).
adequate: ‘tó’ There is an adequate amount of food at home (Ìwọ̀n oúnjẹ tí ó wà nílé tó).
adjacent: ‘tì’ Our house is adjacent to his (Ilé wa ti tirẹ̀).
admit: ‘gbà’ He admitted that he was lazy (Ó gbà pé óun lẹ).
advance: ‘lọ’ She has advanced in Arithmetic (Ó ti lọ nínú ìṣirò).
affect: ‘kàn’ Those new rules will affect me (Àwọn òfin tuntun yẹn yóò kàn mí).
afflict: (i) ‘tọ’ He is afflicted with trouble (Ìyà tọ lé e) (ii) ‘jẹ’ He is afflicted with suffering (Ìyà jẹ ẹ́).
afford: ‘rà’ I can afford a car (Mo lè ra káà).
afraid: ‘bà’ I was afraid (Ẹ̀rù bà mí).
after: ‘bí’ He was happy after he saw me (Inú rẹ̀ dùn bí ó ti rí mi).
again: ‘tún’ He did it again (Ó tún un ṣe).
against: (i) ‘tì’ The chair is leaning against the wall (Àga náà fi ara ti ògiri) (ii) ‘sán’ He flings him against the ground (Ó gbé e sánlẹ̀) (iii) ‘mọ́’ He hit his head against the wall (Ó lẹ orí rẹ̀ mọ́ ògiri).
age: ‘gbó’ He aged fast (Ó tètè gbó).
agree: ‘gbà’ I agree with your proposal (Mo gba àbá tí o dá wọlé)
aim: ‘sùn’ He aimed at it (Ó sùn ún).
air: ‘sá’ He aired the mat to dry (Ó sá ẹní náà kí ó lè gbẹ).
alight: (i) ‘jó’ The light is alight (Àtùpà náà ń jó) (ii) ‘sọ̀’ I alighted from the train (Mo sọ̀ láti inú ọkọ̀ ojú irin náà) (iii) ‘sun’ He set the dry leaves alight (Ó sun àwọn ewé gbígbẹ náà).
allow: ‘jẹ́’ I allowed him to go (Mo jẹ́ kí ó lọ).
alone: ‘dá’ The house stands alone (Ilé náà dá dúró).
already: (i) ‘ti’ It was already raining (Òjò ti ń rọ̀); He has seen the books already then (Ó ti rí ìwé náà rí nígbà náà).
also: ‘tún’ He plays football, he also swims (Ó ń gbá bọ́ọ̀lù, ó tún ń lúwẹ̀ẹ́).
am: ‘mí’ I am a teacher (Olùkọ́ ni mí).
amount: (i) ‘kú’ It amounted to four (Ó kú sí mẹ́rin) (ii) ‘já’ They amount to the same thing (Déédé ni wọ́n já sí) (iii) ‘tó’ It is three days (It has amounted to three days) since you came (Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tí o ti dé).
an: ‘kan’ I gave him an orange (Mo fún un ní ọsàn kan).
ancient: ‘gbó’ He is holding an-ancient looking hat       (Fìlà tí ó ti gbó ni ó mú dání).
and: ‘sì’ He bought and ate it (Ó rà á, ó sì jẹ ẹ́).
angry: ‘ru’ He is angry (Inú rẹ̀ ń ru).
answer: ‘jẹ́’ He answered my call (Ó jẹ́ ìpè mi).
anymore: ‘mọ́’ He won’t come to school anymore (Kò níí wá sí ilé-ẹ̀kọ́ mọ́).
apart: ‘yà’ Keep the dogs apart or else they will fight (Ya àwọn ajá wọ̀nyẹn bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò jà).
apologize: ‘bẹ̀’ You have offended Olú. Apologize to him (O ti ṣẹ Olú, bẹ̀ ẹ́).
apparent: ‘hàn’ It was apparent that he knew nothing about the case (Ó hàn pé kò mọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà).
appeal: ‘wù’ The book appeals to the student (Ìwé náà wu ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ náà).
appear: (i) ‘yọ’ He appeared from afar (Ó yọ lókèèrè) (ii) ‘ta’ The sun appears (Oòrùn ta).
appeased: ‘rọ̀’ His anger has been appeased (Inú rẹ̀ ti rọ̀).
apply: (i) ‘kùn; He powdered his face (Ó kun àtíkè) (ii) ‘sà’ He applied all his strength to do it and he did it (Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe é, ó sì ṣe é) (iii) The doctor applied some medicine on the cut (Dókítà náà fi oògùn sí egbò náà).
appoint: ‘yàn’ We must appoint a committee (A gbọ́dọ̀ yan ìgbìmọ̀ kan).
appreciate: (i) ‘mọ̀’ He appreciates that he is an elderly person (Ó mọ ara rẹ̀ lágbà) (ii) ‘yọ’ His work is appreciated (Iṣẹ́ rẹ̀ yọ).
appropriate: (i) ‘yẹ’ Choose the book that is appropriate for your class (Yan ìwé tí ó yẹ fún kíláàsì rẹ) (ii) ‘tọ́’ Buy the desk that is appropriate for your class (Ra dẹ́sìkì tí ó tọ́ fún kíláàsì rẹ).
approximately: ‘tó’ I have been to approximately twenty schools (Ilé-ẹ̀kọ́ tí mo ti lọ tó ogún)
are: (i) ‘jẹ́’ Olú and Adé are Dada’s senior brothers (Olú àti Adé jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dàda ọkùnrin) (ii) ‘ni’ Òjó and Ọ̀kẹ́ are Délé’s senior brothers (Òjó àti Ọ̀kẹ́ ni ẹ̀gbọ́n Délé ọkùnrin); Who are you? (ta ni ẹ́?).
arise: ‘jí’ I arose in the morning (Mo jí ní àárọ̀).
around: ‘ká’ They walked around for one hour (Wọ́n rìn ká fún wákàtí kan).
arrange: (i) ‘lé’ He arranged the yams in piles (Ó lé iṣu) (ii) ‘tò’ He arranged them (Ó tò wọ́n).
arrest: ‘mú’ The police arrested the robber (Ọlọ́pàá mú olè náà).
arrive: ‘dé’ He has arrived (Ó ti dé).
as: ‘bí’ Do as I say (Ṣe bí mo ti wí).
ascend: (i) ‘jẹ’ He ascended the throne (Ó je ọba) (ii) ‘gùn’ He ascended the mountain (Ó gun òkè).
ask: (i) ‘bi’ He asked him questions (Ó bi í ní ìbéèrè) (ii) ‘bẹ̀’ He asked me for help (Ó bẹ̀ mí fún ìrànlọ́wọ́).
asleep: ‘sùn’ He is asleep (Ó ti sùn).
assemble: ‘pé’ They assembled (Wọ́n pé).
assume: ‘rò’ I assumed you always woke up by the same time everyday (Mo rò pé àsìkò kan náà lo máa ń jí lójoojúmọ́).
at: (i) ‘ní’ He is at home (Ó wà ní ilé) (ii) ‘sí’ He left the shoe at the market (Ó fi bàtà náà sí ọjà) (iii) ‘fi’ We laughed at the boy (A fi ọmọkùnrin náà rẹ́rìn-ín).
ate: ‘jẹ’ We ate our breakfast (A jẹ oúnjẹ àárọ̀ wa)     
attend: (i) ‘gbọ́’ Attend to your affair (Gbọ́ ti ara rẹ) (ii) ‘lọ’ I attend his birthday party (Mo lọ sí ibi àríyá ọjọ́ ìbí rẹ̀).
attract: ‘wù’ The boy was attracted to this girl (Ọmọkùnrin náà wu ọmọbìnrin yìí).
augment: ‘nú’ He augmented his teaching job with trading (Ó fi iṣẹ́ ọjà títà nú iṣẹ́ tíṣà).
available ‘wà’ Yams are available in August (Iṣu máa ń wà ní oṣù kẹ́jọ ọdún).
await: ‘dè’ He sat waiting for me (Ó jókòó dè mí).
awake: ‘jí’ I awake every morning at 8 o’clock (Mo máa ń jí ní aago mẹ́jọ láràárọ̀).
aware: ‘mọ̀’ I was not aware that it was raining (N kò mọ̀ pé òjò ń rọ̀)
away: ‘nù’ Don’t throw away your book (Má ju ìwé rẹ nù).


Bb

back: ‘dé’ My father is back home (Bàbá mi ti dé sí ilé).
bandage: ‘di’ The doctor bandaged Olú’s cut hand (Dókítà di ọwọ́ Olú tí ó fi pa).
bandy-legged: ‘kẹ̀’ He is bandy-legged (Itan rẹ̀ kẹ̀).
bar: (i) ‘sé’ She barred the door (Ó sé ilẹ̀kùn) (ii) ‘dí’ They barred the way to the school (Wọ́n dí ọ̀nà tí ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ náà).
barbecue: ‘yan’ You’ve made a fire fit to barbecue a goat (O ti dá iná tó tó yan ewúrẹ́).
bargain: ‘ná’ He bargained for the good (Ó ná ọjà náà).
bark: ‘gbó’ The dog barked (Ajá náà gbó).
base: (i) ‘wà’ He is now based at Ibadan (Ìbàdàn ni ó wà báyìí) (ii) ‘gbé’ Base your opinion on facts (Gbé ọ̀rọ̀ rẹ ka orí òtítọ́).
bath: ‘wẹ̀’ She is giving the baby a bath (Ó ń wẹ ọmọ náà).
battle: ‘jà’ They battled for an hour (Wọ́n jà fún wákàtí kan).
beam: ‘ràn’ The sun beamed through the cloud (Oòrùb ràn gba inú kùrukùru kọjá).
bear: (i) ‘gbé’ That small horse cannot bear your weight (Ẹṣin kékeré yẹn kò lè gbé ọ (nítorí pé o ti tóbi jù) (ii) ‘bí’ The woman has borne ten children (Obìnrin yẹn ti bí ọmọ mẹ́wàá).
beat: (i) ‘pa’ The rain was beating him (Òjò ń pa á) (ii) ‘gbọ̀n’ He beats a red-hot cutlass with a hammer so as to reshape it (Ó gbọn àdá) (iii) ‘bọ́’ He beats the earth-floor (Ó bọ́lẹ̀) (iv) ‘lù’ His hearth is beating ̣̣(Ọkàn rẹ̀ ń lù) (v) ‘pò’ She beats eggs in milk (Ó po ẹyin nínú mílíìkì) (vi) ‘nà’ We beat them in football (A nà wọ́n nínú eré bọ́ọ̀lù).
beating: ‘nà’ He was giving a beating (Wọ́n nà án).
beckon: ‘jù’ He beckoned his hand to me (Ó ju ọwọ́ sí mi).
become: (i) ‘mọ́’ To work hard does not mean that the worker will be rich (Gìdìgìdì kò mọ́là) (ii) ‘dì’ It becomes dry (Ó di gbígbẹ) (iv) ‘dà’ What has he become? (Kí ló dà?)
befall: ‘bá’ Misfortune befell them (Ibi bá wọn).
befit: ‘yẹ’ It befits him (Ó yẹ ẹ́).
beg: ‘bẹ̀’ He begged me (Ó bẹ̀ mí).
begin: ‘ṣí’ He began war (Ó ṣígun).
behalf: ‘fún’ I paid the money on your behalf (Mo san owó náà fún ọ).
bellow: ‘ké’ He bellowed like a bull (Ó ké bí akọ mààlúù).
bend: (i) ‘lò’ It bends to the right (Ó lò sí apá ọ̀tún) (ii) ‘tẹ̀’ He bent it (Ó tẹ̀ ẹ́).
beside: ‘tì Sit beside me (Jókòó tì mí).
bet: ‘kọ́’ They bet (Wọ́n kọ́ ọ).
betray: ‘dà’ He betrayed me (Ó dà mí).
better: (i) ‘jẹ́’ You better not go (O jẹ́ má lọ) (ii) ‘tù’ I felt better (Ara tù mí).
bind: (i) ‘dè’ They bind the thief with a rope (Wọ́n fi okùn de olè náà) (ii) ‘dì’ Let me bind the cut on your leg (Jẹ́ kí n bá ọ di egbò ẹsẹ̀ rẹ) (iii) ‘rán’ The book has been well bound (Wọ́n rán ìwé náà dáadáa).
birth: ‘bí’ She gave birth to a baby (Ó bímọ).
bite: (i) ‘yán’ A snake bit him (Ejò yán an) (ii) ‘já’ He bit off some meat (Ó já ẹran) (iii) ‘ṣán’ He was bitten by the snake (Ejò náà ṣán an) (iv) ‘jẹ’ The mosquito bit me (Èfọn jẹ mí) (v) ‘ta’ The insect bit me (Kòkòrò ta mí).
blacken: ‘dú’ He blackened his hands with dye (Ó fi aró dú ọwọ́ rẹ̀)
blameless: ‘mọ́’ He is blameless (Ara rẹ̀ mọ́).
blaze: ‘jó’ The fire was blazing beneath the pot (Iná náà ń jó ní abẹ́ ìkòkò).
bleach: ‘bó’ The woman bleached the clothes when she washed them (Obìnrin náà bó àwọn aṣọ náà nígbà tí ó fọ̀ wọ́n).
bleat: ‘ké’ The goats bleat (Àwọn ewúrẹ́ náà ké).
blind: ‘fọ́’ He is blind in one eye (Ó fọ́ ní ojú kan).
block: (i) ‘sé’ They blocked the window (Wọ́n ṣé fèrèsé náà) (ii) ‘dí’ He blocked the hole (Ó dí ihò).
blow: (i) ‘fín’ He blew the fire to make it burn up (Ó fín iná) (ii) ‘kù’ The dust is blowing about (Eruku ń kù kiri) (iii) ‘fọn’ He blew the whistle (Ó fọn fèrè) (iv) ‘fẹ́’ He blew up the tyre of his bicycle (Ó pọ́ táyá kẹ̀kẹ́ rẹ̀) (vi) ‘wó’ They blew up the bridge (Wọ́n wó bíríìjì náà).
board: (i) ‘wọ̀’ They boarded a taxi (Wọ́n wọ takisí) (ii) ‘gbé’ They are boarding with her (Wọ́n ń gbé pẹ̀lú ẹ̀).
boast: ‘fọ́n’ He is boasting (Ó ń fọ́n ẹnu).
boil: (i) ‘hó’ The water is boiling (Omi náà ń hó) (ii) ‘ru’ The water is boiling (Omi náà ń ru) (iii) ‘sè’ Boil the yam (Se iṣu náà) (iv) ‘bọ̀’ Boil the meat (Bọ ẹran náà).
border: ‘kàn’ Nigeria borders on more than two other countries (Àwọn ilẹ̀ tí ó kan Nàìjíríà ju méjì mìíràn lọ)
bore: ‘sú’ I am bored (Ó sú mi).
born: ‘bí’ She has borne six children (Ó ti bí ọmọ mẹ́fà).
borrow: (i) ‘kó’ He borrowed money (Ó kó owó) (ii) ‘wín’ He borrowed money from me (Ó wín owó lọ́wọ́ mi) (iii) ‘yá’ I borrowed some money from him (Mo yá owó lọ́wọ́ rẹ̀).
bounce: ‘tọ’ The ball bounced off the wall and hit me (Bọ́ọ̀lù náà tọ kúrò lára ògiri, ó sì bà mí).
bound: (i) ‘lọ’ The car is bound for Ifẹ̀ (Ifẹ̀ ni mọ́tò náà ń lọ) (ii) ‘tọ’ The animals were bounding about the street (Àwọn ẹranko náà ń tọ kiri orí títì).
box: ‘gbá’ He boxes my ears (Ó gbá mi létí).
braid: ‘di’ She braids her hair (Ó di irun rẹ̀).
branch: ‘yà’ The road branches off here (Ibí ni ọ̀nà náà ti yà).
brand: ‘jó’ He branded his cows with a hot iron (Ó fi irin jó mààlúù rẹ̀).
break: (i) ‘já’ The goat broke free (Ewúrẹ́ náà já okùn) (ii) ‘ṣẹ̀’ A fire broke out (Iná ṣẹ̀) (iii) ‘ṣẹ́’ He broke the stick (Ó ṣẹ́ igi náà) (iv) ‘só’ He broke wind (Ó só) (v) ‘bù’ He broke off a bit of the loaf of bread (Ó bu búrẹ́dì díẹ̀) (vi) ‘mọ́’ It is day break (Ojú ti mọ́) (vii) ‘là’ He broke it into two (Ó là á sí méjì) (viii) ‘rú’ He broke the law (Ó rú òfin) (ix) ‘fọ́’ The stone broke the window (Òkúta náà fọ́ fèrèsé náà) (x) ‘sọ’ A loud noise broke out (Ariwo ńlá sọ).
breathe: ‘mí’ He is breathing (Ó ń mí).
breed: ‘sin’ They bred goat (Wọ́n ń sin ewúrẹ́).
brew: (i) ‘pọn’ He brewed beer (Ó pọn ọtí) (ii) ‘pò’ He brewed tea (Ó po tíì).
bright: (i) ‘bẹ’ It is bright (Ó bẹ) (ii) ‘ràn’ The sun was bright (Oòrùn ràn) (iii) ‘tàn’ She wore a bright dress (Ó wọ aṣọ tí ó tàn).
bring: (i) ‘ká’ He brought in the washing (Ó ká aṣọ wọlé) (ii) ‘yọ’ He brought out a stick (Ó yọ igi) (iii) ‘tọ́’ He bought her up (Ó tọ́ ọ).
broad: ‘fẹ́’ He has a broad shoulder (Èjìká rẹ̀ fẹ̀).
broken: ‘fọ́’ You have to pay fore the broken window (O gbọ́dọ̀ sanwó fèrèsé tí o fọ́).
bruise: ‘bó’ She bruised her body (Ó fi ara bó).
brush: ‘gbọ̀n’ Brush these clothes for me (Gbọn ẹ̀wù yìí fún mi).
bubble: ‘hó’ The soap bubbles (Ọṣẹ náà ń hó).
budge: ‘tì’ I can’t budge this rock (N kò lè ti òkúta yìí).
build: (i) ‘mọ’ He built a house (Ó mọ ilé) (ii) ‘kọ́’ He built a house (Ó kọ́ ilé) (iii) ‘ṣe’ He built a model house with wood (Ó fi igi ṣe ilé àwòkọ́ṣe).
bulge: ‘wú’ Her bag was bulging of things (Nǹkan tí ó kó sínú báàgì rẹ̀ jẹ́ kí báàgì yìí wú).
bunch: ‘jọ’ We came to school in a bunch (A jọ wá sí ilé-ẹ̀kọ́ ni).
bundle: ‘dì’ Don’t bundle up the clothes like that (Má di àwọn aṣọ yẹn bẹ́yẹn).
burn: (i) ‘jó’ The fire is burning (Iná náà ń jó) (ii) ‘kun’ He burns the bush (Ó kun igbó) (iii) ‘sun’ He burnt it (Ó sun ún).
burst: (i) ‘bẹ́’ It bursts (Ó bẹ̀ pẹ̀ẹ́) (ii) ‘wọ́n’ He burst the door open (Ó wọ́n ilẹ̀kùn náà) (iii) ‘tú’ The boil burst (Eéwo náà tú).
bury: ‘sin’ He was buried (Wọ́n sin ín).
buy: (i) ‘mú’ How much did you buy this cloth? (Èló ni ẹ mú aṣọ yìí?) (ii) ‘ṣí’ He bought pounded yam (Ó ṣíyán) (iii) ‘yàn’ He bought ẹ̀kọ (pap) (Ó yan ẹ̀kọ) (iv) ‘bẹ́’ He bought a little quantity of tobacco (Ó bẹ́ tábà) (v) ‘rà’ He bought it (Ó rà á).
buzz: ‘kùn’ The insects were buzzing around the room (Àwọn kòkòrò náà ń kùn yí yàrá náà po).
by: (i) ‘tì’ Sit by me (Jókòó tì mí) (ii) ‘gbà’ He came in by the door (Ó gba ẹnu ọ̀nà wọlé).


Cc

cackle: ‘gbẹ́’ The hen cackle (Adìyẹ náà gbẹ́).
calculate: ‘ṣí’ He calculated the money (Ó ṣí owó náà).
call: (i) ‘ké’ He called at me/He called on me (Ó ké sí mi) (ii) ‘pè’ They called him (Wọ́n pè é) (iii) ‘sà’ They use his nickname(s) to call him (Wọ́n ń sà á).
can: ‘lè’ I can do it (Mo lè ṣe é).
cane: ‘nà’ The boy was caned for coming late to school (Wọ́n na ọmọ náà  nítorí pé ó pẹ́ dé ilé-ẹ̀kọ́).
capable: ‘lè’ He is capable of doing well in the examination (Ó lè ṣe dáadáa nínú ìdánwò náà).
capture: (i) ‘kó’ He captured slaves (Ó kó ẹrú) (ii) ‘gbà’ They captured their town (Wọ́n gba ìlú wọn).
card: ‘gbọ̀n’ He carded cotton (Ó gbọ òwú)
care: (i) ‘gbé’ He carried the load (Ó gbé ẹrù náà) (ii) ‘rù’ He carried a load (Ó ru ẹrù) (iii) ‘ṣẹ̀’ He carried the load on his head (Ó fi orí ṣẹ ẹrù náà) (iv) ‘ṣe’ I have carried out all my plans (Mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo pa lérò).
carve: (i) ‘kun’ He carved up the carcass of the animal (Ó kun ẹran náà) (ii) ‘gbẹ́’ He carved the tray (Ó gbẹ́ ọpọ́n náà).
cast: (i) ‘jù’ The fisherman casts his net into the river (Apẹja náà ju ìwọ̀n rẹ̀ sí inú omi) (ii) ‘wò’ He cast my horoscope for me (Ó wo bí ọjọ́ iwájú yóò ṣe rí fún mi).
catch: (i) ‘hán’ He caught the money she threw to him (Ó hán owó tí ó jù sí i) (ii) ‘wọ́n’ He caught the ball (Ó wọ́n bọ́ọ̀lù) (iii) ‘tẹ̀’ He has been caught (Ọwọ́ ti tẹ̀ ẹ́) (iv) ‘wọ̀’ I caught the train to Osogbo (Mo wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí Òṣogbo) (v) ‘rí’ I caught sight of the ball on the tree (Mo rí bọ́ọ̀lù náà lórí igi) (vi) ‘bá’ I caught up with him at Ifẹ̀ (Mo bá a ní Ifẹ̀).
cause: (i) ‘fà’ This is what caused it (Èyí ló fà á) (ii) ‘fà’ The rain caused the flood (Òjò náà ni ó fa omíyalé) (iii) ‘mú’ He caused my coming home (Ó mú mi wálé).
cave: ‘ri’ The ground caves in (Ilẹ̀ náà ri).
cease: (i) ‘dá’ The rain has ceased (Òjò ti dá) (ii) ‘yé’ He stopped working (Ó yé iṣẹ́ẹ́ ṣe)
certain: (i) ‘mọ̀’ I am certain he told me to come (Mo mọ̀ (Ó dá mi lójú) pé ó ní kí n wá) (ii) ‘kan’ People who smoke cannot travel in certain trains (Àwọn tí ó ń mu sìgà kò lè wọ àwọn ọkọ̀ ojú irin kan).
change: ‘bì’ The cloth always changes its colour(s) (Aṣọ náà ń bì)
channel: ‘dà’ They channelled all his money into their business (Wọ́n da gbogbo owó rẹ̀ sí orí òwò wọn).
chant: ‘gbà’ He chanted a prayer (Ó gba àdúrà).
charm: ‘wù’ The girl charmed those boys (Ọmọbìnrin náà wu àwọn ọmọkùnrin yẹn).
chase: ‘lé’ Olú chased the chickens (Olú lé àwọn adìyẹ náà).
chat: ‘wẹ́’ Adé is chatting with Olú (Adé ń wẹ́ sí Olú)
cheap: ‘pọ̀’ Yams are cheap in the market (Iṣu pọ̀ lọ́jà)
cheaper: ‘pọ̀’ A bicycle is cheaper than a car (Kẹ̀kẹ́ pọ̀ ju káà lọ).
check: ‘wò’ I will check if all the doors are locked (Màá wò ó bóyá gbogbo ilẹ̀kùn ni wọ́n ti tì).
chew: (i) ‘rùn’ He is chewing a chewing stick (Ó ń run pákò) (ii) ‘rún’ He chewed kolanut (Ó rún obì) (iii) ‘jẹ́’ Chew the meat well (in the mouth) before you swallow it (Jẹ ẹran yẹn dáadáa (lẹ́nu) kí o tó gbé e mì).
chime: ‘lù’ The clock chimed three o’clock (Agogo náà lu agogo mẹ́ta).
chip: ‘bù’ These glasses  chip easily (Àwọn gíláàsì yìí tètè ń bù).
chisel: ‘gbẹ́’ The man chiselled a bowl from a piece of wood (Ọkùnrin náà fi igi gbẹ́ abọ́).
choose: ‘yàn’ He chose me (Ó yàn mí)
claim: ‘ní’ He claimed to have killed a lion (Ó ní òun pa kìnìún).
classify: ‘tò’ He classified the books: all the Yorùbá books are on the top shelf and all the English books on the bottom (Ó to àwọn ìwé náà; gbogbo ìwé Yorùbá wà lókè ṣẹ́ẹ̀fù, gbogbo ìwé Òyìnbó sì wà ní ìsàlẹ̀).
claw: ‘ya’ The cat clawed the paper (Ológbò náà fi èékánná ya ìwé náà).
clean: (i) ‘mọ́’ It is clean (Ó mọ́) (ii) ‘nù’ He cleaned the wall (Ó nu ara ògiri).
clear: (i) ‘fó’ The ground is clear (Ilẹ̀ ti fó) (ii) ‘hàn’ It is clear that he doesn’t like you (Ó hàn pé kò fẹ́ràn rẹ) (iii) ‘ha’ He cleared his throat (Ó ha ọ̀fun) (iv) ‘jù’ He cleared the bush (Ó ju igbó) (v) ‘kó’ They have cleared the books away (Wọ́n ti kó àwọn ìwé náà lọ) (vi) ‘gbẹ́’ He cleared his throat (Ó gbẹ́ ikọ́) (vii) ‘fò’ He cleared six feet (Ó fo ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà).
climb: (i) ‘gùn’ He climbed the tree (Ó gun igi náà) (ii) ‘pọ́n’ He climbed the tree (Ó pọ́n igi náà)
clip: ‘so’ The papers were clipped together with a clip (Wọ́n fi kílíìpù so àwọn ìwé náà pọ̀).
close: (i) ‘ré’ The trap closed (Tàkúté náà ré) (ii) ‘tì’ She closed the door (Ó ti ilẹ̀kùn).
coach: ‘kọ́’ He coaches the school football team (Ó ń kọ́ àwọn tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ilé-ẹ̀kọ́ náà).
cock: ‘kẹ́’ He cocked his gun (Ó kẹ́ ìbọn rẹ̀)
coil: (i) ‘dà’ He coiled up ropes (Ó da okùn) (ii) ‘ká’ They coiled the ropes (Wọ́n ká okùn náà).
collapse: ‘wó’ It collapse (Ó wó).
collect: (i) ‘kó’ He collected his laggage (Ó kó ẹrù rẹ̀) (ii) ‘fọ̀n’ He took burning wood out of the fire so as to ignite another fire (Ó fọn iná) (iii) ‘gbè’ He collected rain water (Ó gbe omi òjò) (iv) ‘tu’ He  collected them bit by bit (Ó tù wọ́n jọ) (v) ‘pé’ A crowd of people had collected to watch the play (Àwọn èrò ti pé láti wo eré náà).
comb: ‘yà’ He combed his hair (Ó ya irun rẹ̀).
come: (i) ‘wá’ Come here (wá níbí) (ii) ‘bọ̀’ My father is coming (Bàbá mi ń bọ̀) (iii) ‘yọ’ My shoes have come off (Bàtà mi ti yọ) (iv) ‘rí’ We came across a snake (A rí ejò) (v) ‘kò’ We came up agaist each other on the way to the school (A ko ara wa lọ́nà ilé-ìwé) (vi) ‘sọ’ A new idea came to my mind (Èrò tuntun sọ sí mi lọ́kàn).
comment: ‘sọ’ He commented on the bad books (Ó sọ nípa àwọn ìwé tí kò dára náà).
commit: ‘ṣẹ̀’ He commits an offence (Ó ṣẹ ẹ̀sẹ̀).
common: ‘pọ̀’ Palm trees are common in Nigeria (Ọ̀pẹ́ pọ̀ ní Nàìjíríà).
compete: ‘dù’ They compete fcor the post (Wọ́n du ipò náà)
complete: ‘jọ’ The year is completed joyfully (Ọdún jọ) (ii) ‘kún’ (iii) ‘pé’ it is complete (Ó pé).
complicate: ‘le’ Multiplying 005 by 500 is very complicated (Fífi 005 sọ 500 di púpọ̀ le púpọ̀).
compliment: ‘yìn’ he compliment Ṣọlá on her cooking (Ó yin Sọlá fún oúnjẹ tí ó ṣè).
compose: ‘kọ’ Musa composes songs in a book every night (Músá máa ń kọ orin sí inú ìwé lálaalẹ́).
concern: ‘kàn’ The letter concerns you. Read it (Lẹ́tà yẹn kàn ọ́. Kà á).
conclude: ‘gbà’ When I had heard his story, I concluded that he had told me the truth (Nígbà tí mo ti gbọ́ ìtàn tí ó sọ, mo gbà pé òtítọ́ ni ó sọ fún mi).
condense: ‘dì’ The steam from the boiling water condensed on the glass and ran down as drops of water (Ooru omi gbígbóná náà dì ní ara gíláàsì ó sì ń kán sílẹ̀ bí omi).
conduct: ‘fà’ They conducted my bride to my house (Wọ́n fa ìyàwó mi fún mi).
confess: ‘kà’ The witch confessed her nefarious deed as a witch (Àjẹ́ náà kà).
congratulate: ‘yọ̀’ He congratulated him (Ó yọ̀ fún un).
conscious: ‘mọ̀’ I was conscious that he was looking at me (Mo mọ̀ pé ó ń wò mí).
consent: ‘gbà’ I asked my father if I could go out, and he consented (Mo bi bàbá mi bí mo lè jáde, ó sì gbà).
consider: ‘rò’ I consider that he is a thief (Mo rò pé olè ni).
construct: (i) ‘kọ́’ I constructed a house (Mo kọ́ ilé) (ii) ‘hun’ I construct a sentence with a noun phrase and a verb phrase (Mo fi àpólà orúkọ àti àpólà ìṣe hun gbólóhùn).
consult: (i) ‘wò’ He consulted Ifá on the matter (Ó wo Ifá sí ọ̀ràn náà) (ii) ‘wò’ He always consults a dictionary if he doesn’t understand a word (Ó máa ń wo ìwé atúmọ̀-èdè bí ọ̀rọ̀ kan kò bá yé e).
consume: (i) ‘lò’ The car consumes a lot of petrol (Káà náà máa ń lo epo púpọ̀) (ii) ‘jẹ’ You must not consume food on the street (O kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ lórí títì).
contact: (i) ‘kó’ He contacted gonorrhea (Ó kó àtọ̀sí) (ii) ‘kọ’ She made contact with me (Ó kọ sí mi).
continue: ‘lọ’ They continue reading (Wọ́n ń kàwé lọ).
contribute: (i) ‘dá’ I contributed money (Mo dá owó) (ii) ‘wí’ He contributed to an èésú (daily, weekly or monthly contribution) (Ó wí èésú).
cook: (i) ‘bọ̀’ The meat is half-cooked (Ẹran náà ti bọ̀) (ii) ‘bu’ He cooked yams in embers (Ó bu iṣu nínú iná) (iii) ‘sè’ He cooked okro soup (Ó se ọbẹ̀ ilá).
copulate: ‘gùn’ He copulated with his wife (Ó gun obìnrin rẹ̀).
correct: ‘tọ́’ What you said is correct (Ọ̀rọ̀ tí o sọ tọ́).
cost: (i) ‘wọ́n’ Do yams cost more than cocoyams? (Ṣé iṣu wọ́n ju kókò lọ?).
costly: ‘wọ́n’ That book was too costly (Ìwé yẹn wọ́n jù).
could: ‘lè’ We could play there yesterday but today, we can’t because it is raining (A lè ṣeré níbẹ̀ lánàá ṣùgbọ́n ní òní, a kò lè ṣeré níbẹ̀ nítorí pé òjò ń rọ̀).
count: ‘kà’ He counted his oranges (Ó ka ọsàn rẹ̀)
cover: (i) ‘bò’ He covered the plate (Ó bo abọ́ náà) (ii) ‘dé’ He covered the pot (Ó dé apẹ náà).
crack: (i) ‘sín’ He cracks nuts (Ó sín ẹ̀kùrọ́) (ii) ‘sán’ The wall cracked (Ògiri náà sán) (iii) ‘bú’ The pot cracked (Ìkòkò náà bù) (ní ìdí) (iv) ‘bẹ́’ The bitter-cola cracked (when it was eating) (Orógbó náà bẹ́) (v) ‘là’ The tea-cup cracked (Kọ́ọ̀bù tíì náà là) (vi) ‘fọ́’ He cracked the coconut shell (Ó fọ́ àgbọn).
crash: ‘fọ́’ The pot crashed to the floor (Ìkòkò náà fọ́ mọ́lẹ̀).
crawl: (i) ‘fà’ The baby is crawling (Ọmọ náà ń fà) (ii) ‘ràn’ The snail crawled (Ìgbín náà ràn) (iii) ‘wọ́’ It crawled into the bush (Ó wọ́ sí inú igbó) (iv) ‘rá’ He is crawling (Ó ń rá).
creak: ‘rọ́’ The chair is creaking (Àga yìí ń rọ́ kẹ́kẹ́).
creap: (i) ‘wọ́’ The dog crept under the table (Ajá náà wọ́ sí abẹ́ tábìlì) (ii) ‘fà’ They crept through the forest (Wọ́n fà kọjá inú igbó).
create: ‘dá’ God created human beings (Ọlọ́run dá ènìyàn).
croak: ‘ké’ The bird croaked loudly (Ẹyẹ náà ké sókè).
crook: (i) ‘gbun’ He has a crooked leg (Ẹsẹ̀ rẹ̀ gbun) (ii) ‘wọ́’ It has a crooked leg (Ẹsẹ̀ rẹ̀ wọ́).
crouch: ‘ká’ He was crouching by the fire (Ó ká sí ìdí iná/Ó ká ti iná).
crow: ‘kọ’ The cock crowed (Àkùkọ kọ).
crowd: ‘kún’ The children crowded the doorway (Àwọn ọmọdé kún ojú ọ̀nà); The market is much too crowded (Ọjà náà ti kún jù)
cruel: ‘le’ That man is cruel (Okùnrin yẹn le)
crumble: (i) ‘rún’ He crumbled the cake for the chicken (Ó rún àkàrà náà fún adìyẹ) (ii) ‘ya’ The river bank crumbled into the river (Bèbè omi náà ya sí inú odò).
crush: (i) ‘fún’ She crushed the orange so she could drink the juice (Ó fún ọsàn náà kí ó bàa lè mu omi inú rẹ̀) (ii) ‘rún’ His dresses were badly crushed (Àwọn aṣọ rẹ̀ rún gan-an ni).
cry: ‘ké’ She started to cry (Ó bẹ̀rẹ̀ síí ké).
cultivate: ‘gbìn’ The farmer cultivated maize (Àgbẹ̀ náà gbin àgbàdo).
cure: ‘rín’ He cured leather (Ó rín awo).
curl: (i) ‘ká’ He curled himself up (Ó ká rúgúdú) (ii) ‘yín’ He curled his lips in disbelief at my statement (Ó yínmú sí mi).
curve: ‘gbun’ The line is curve (Ìlà náà gbun).
cut: (i) ‘bẹ́’ He cut his head off (Ó bẹ́ ẹ ní orí) (ii) ‘bù’ He cut his finger (Ó fi ọwọ́ bù) (iii) ‘fín’ He cut patterns on the calabash (Ó fín igbá) (iv) ‘gán’ He cut off his head (Ó gán an ní orí) (v) ‘gé’ He cut the meat (Ó gé ẹran náà) (vi) ‘gẹ̀’ He cut his hair (Ó gé irun rẹ̀) (vii) ‘jù’ He cut the bush (Ó ju igbó) (viii) ‘kọ’ He cut palm nut (Ó kọ ọ̀pẹ) (ix) ‘pa’ They cut the forest (Wọ́n pa ìgbẹ́) (x) ‘pa’ He cut open the kolanut (Ó pa obì) (xi) ‘rẹ́’ They cut the meat (Wọ́n rẹ́ ẹran) (xii) ‘ro’ He cut the bush in the front of his house (Ó ro oko iwájú ilé rẹ̀) (xiii) ‘ṣán’ I cut the bush (Mo ṣán igbó) (xiv) ‘yin’ He cut the edge of the table with a knife (Ó fi ọ̀bẹ yin etí tábìlì) (xv) ‘yùn’ They cut the animal’s neck with a knife (Wọ́n fi ọ̀bẹ yun ọrùn ẹran náà).


Dd

damage: ‘mu’ The white ants damaged the tree (Ikán ti mu igi náà).
dance: (i) ‘jó’ He danced (Ó jó) (ii) ‘ran’ He is dancing well in the gathering (Ó ń ràn lójú agbo)
dangle: ‘fi’ He is dangling and oscillating to and fro (Ó ń fì dirodiro).
dare: ‘jẹ́
I dare not hit him (N kò jẹ́ nà án).
dark: (i) ‘ṣú’ It has become dark (Ilẹ̀ ti ṣú) (ii) ‘lẹ́’ It is dark (Alẹ́ lẹ́). (iii) ‘ru’ It is dark (Òrú ru).
dart: ‘ta’ He darted forward (Ó ta kéré).
dawn: ‘là’ The day dawned (Ọjọ́ là).
dead: ‘kú’ The cat was dead (Ológbò náà kú).
deal: (i) ‘ṣe’ I can’t deal with this work (N kò lè ṣe iṣẹ́ yìí) (ii) ‘tà/rà’ He deals with bicycle (Ó ń ta kẹ̀kẹ́ tàbí ó ń ra kẹ̀kẹ́)  
          
dear: ‘wọ́n’ Oranges are dear here (Ọsàn wọ́n níbí)
decay: (i) ‘kẹ̀’ The meat has decayed (Ẹran náà ti kẹ̀) (ii) ‘rà’ His teeth has decayed (Eyín rẹ̀ ti rà) (iii) ‘wù’ Wood decays if it is wet (Igi máà ń wù tí ó bá tutù).
deceive: ‘tàn’ He deceived me (Ó tàn mí)
decide: ‘yàn’ I could not decide which is the best of the three dresses (N kò lè yan èyí tí ó dára jù nínú aṣọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta).
decline: (i) ‘kọ̀’ He asked me to his house but I had to decline as I was busy (Ó ní kí n wá sí ilé òun ṣùgbọ́n mo kọ̀ nítorí pé iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ mi) (ii) ‘dín’ There had been a decline in the number of the students here (Iye ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ tí ó wà níbí ti dín).
deep: (i) ‘jìn’ The hole is deep (Ihò náà jìn) (ii) ‘fẹ̀’ He has a deep voice (Ohùn rẹ̀ fẹ̀).
define: ‘kì’ The dictionary defines words (Ìwé-atúmọ̀-èdè máa ń ki ọ̀rọ̀).
definitely: ‘ṣsẹ́’ He will definitely come (Yóò wá sẹ́)
delete: ‘yọ’ Several words have been deleted (Wọ́n ti yọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀).
delicious: ‘dùn’ This soup is delicious (Ọbẹ̀ yìí dùn).
demand: ‘sìn’ He demanded for his money from him (Ó sìn ín lówó).
demolished: ‘wó’ The house are been demolished (Wọ́n ń wó àwọn ilé náà).
dense: ‘há’ It is densely crowded (Ó há gágá).
dent: ‘tẹ̀’ This tin-bowl has being dented (Abọ́ yìí ti tẹ̀).
deny: (i) ‘dù’ He denied me of my post (Ó dù mí ní ipò mi) (iii) ‘ṣẹ́’ He denied me in the presence of everybody (Ó sẹ́ mi lójú gbogbo ayé).
depart: ‘lọ’ They departed fron Ifẹ̀ (Wọ́n lọ láti Ifẹ̀).
descend: ‘sọ̀’ They descended to the tree (Wọ́n sọ̀ sí orí igi).
deserve: ‘tọ́’ Robbers deserved to be punished (Ìyà tọ́ sí olè).
desire: ‘fẹ́’ He desired money (Ó fẹ́ owó).
desolate: ‘kan’ Their house is desolate (Ilé wọn kan (gbínrín)).
despise: (i) ‘gàn’ He despised him (Ó gàn án) (ii) ‘hẹ̀’ He despised me (Ó ṣe  hẹ̀ mi).
destroy: ‘run’ He destroyed the town (Ó run ìlú náà).
develop: ‘wú’ He developed rapidly (Ó wú).
dictate: ‘pè’ The teacher dictated some words for the students to write (Tíṣà náà pe àwọn ọ̀rọ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ).
did: (i) ‘ṣe’ I did my work (Mo ṣe iṣẹ́ mi) (ii) ‘ṣé’ Did you go there? (Ṣé o lọ síbẹ̀).
die: (i) ‘kú’ He died (Ó kú) (ii) ‘wó’ The elephant died (Erin wó)
difficult: (i) ‘rọ’ He took a difficult road (Ọ̀ná tí ó rọ ló gbà) (ii) ‘le’ This task is difficult (Iṣẹ́ yìí le) (iii) ‘ro’ Today is difficult for Ọlá (Òní ro fún Ọlá).
dig; (i) ‘gbẹ́’ He dug the ground (Ó gbẹ́ ilẹ̀) (ii) ‘wà’ He dug up some earth (Ó wa ilẹ̀) (iii) ‘wú’ He dug up the ground (Ó wú ilẹ̀) (iv) ‘hú’ He dug up yams (Ó hú iṣu) (v) ‘sọ’ He dug the ground (Ó sọ ilẹ̀)
digest: ‘dà’ My food has digested (Oúnjẹ mi ti dà)
dilute: ‘là’ He diluted it with water (Ó bu omi là á)
dip: (i) ‘bù’ He dipped water out of the pot (Ó bu omi nínú ìkòkò) (ii) ‘rùn’ I dipped a morsel of food in soup (Mo run ọbẹ̀) (iv) ‘wá’ The bird dipped (down) to the surface of the leaf (Ẹyẹ náà wá (sílẹ̀) sí orí ewé náà).
direct: (i) ‘tọ́’ I told him the most direct way to get to the palace (Mo sọ ọ̀nà tí ó tọ́ jù láti dé ààfin fún un) (ii) ‘kọ’ We direct our steps towards home’ (A kọ ojú sí ọ̀nà ilé).
dirty: ‘pọ́n’ The cloth is dirty (Aṣọ náà pọ́n)
disclose: ‘tú’ He disclosed my secret (Ó tú àṣíírí mi).
discolour: ‘sì’ The clothes have been discoloured (Aṣọ náà ti sì).
disconnect: ‘yọ’ I disconnect the wire from the television (Mo yọ wáyà náà lára tẹlifíṣàn).
discount: ‘dín’ We shall give you a discount of ten naira (A ó dín ọ ní náírà mẹ́wàá).
discover: ‘rí’ Did you discovered your book? (Ṣé o rí ìwé rẹ?).
disgrace: ‘tẹ́’ Don’t disgrace our family (Má tẹ́ ẹbí wa).
disinterested: ‘dì’ He is no more interested in the matter (Ó dì gbọ́ńkú sí ọ̀rọ̀ náà).
dismissed: ‘yọ’ He was dismissed from work (Wọ́n yọ ọ́ níṣẹ́).
dismount: ‘sọ̀’ He dismounted from the bicycle (Ó sọ̀ lórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀).
disobey: ‘kọ̀’ Her mother told her to go to bed, but she disobeyed and went to watch the game (Ìyá rẹ̀ ní kí ó lọ sùn ṣùgbọ́n ó kọ̀ ó sì lọ wo eré).
dispense: ‘fún’ The nurse dispensed some pills to the hiil people (Nọ́ọ̀sì náà fún àwọn aláìsàn náà ní oògùn oníkóró).
dispose: (i) ‘mọ́’ We are well disposed towards him (Inú wa mọ́ sí i) (ii) ‘yọ́’ He felt kindly disposed towards me (Inú rẹ̀ yọ́ sí mi) (iii) ‘fẹ́’ Are you disposed to help me write this letter or shall I ask Olú? (Ṣé o fẹ́ bá mi kọ lẹ́tà yìí àbí kí n bẹ Olú)?.
dispute: ‘jà’ We had a dispute about how much he owed me (A jà lórí iye tí ó jẹ mí).
dissolve: ‘yọ́’ Sugar dissolves in hot tea (Súgà máa ń yọ́ nínú tíì gbígbóná).
distil: ‘pọn’ They distilled alcoholic drinks (Wọ́n pọn ọtí).
distinct: ‘hàn’ Your shadow is quite distinct on that white cardboard (Òjìji rẹ hàn gan-an lára kádíbọ́ọ̀dù funfun yẹn).
divide: (i) ‘là’ He divide the land (Ó la ilẹ̀ náà) (ii) ‘pín’ He divided it into two (Ó pín in sí méjì) (iii) ‘há’ He divided (distributed) the meat among us (Ó há ẹran náà fún wa).
do: (i) ‘ṣe’ I must do it (Mo gbọ́dọ̀ ṣe é) (ii) ‘dè’ Do up your shirt (De ṣáàtì rẹ) (iii) ‘fẹ́’ I could do with cold water (Mo fẹ́ omi tútù).
dodge: ‘yẹ̀’ Olú dodged the book I threw (Olú yẹ ìwé tí mo jù).
does: ‘ṣe’ She does a lot of work at home (Ó máa ń ṣe iṣẹ́ púpọ̀ ní ilé).
dominate: ‘gbà’ The school dominates the street (Ilé-ìwé náà gba gbogbo títì)
donate: ‘dá’ I donated a lot of money to the hospital (Mo dá owó púpọ̀ sí ilé-ìwòsàn náà).
done: ‘ṣe’ He has done it (Ó ti ṣe é).
down: ‘dá’ He has got (He is down with) guinea worm’ (Sòbìà ti dá a).
doze: ‘sùn’ I dozed off for one hour (Mo sùn lọ fún wákàtí kan).
drag: (i) ‘fà’ He dragged him out (Ó fà á jáde) (ii) ‘wọ́’ Drag him out (Wọ́ ọ jáde)
drain: (i) ‘ṣàn’ The water drained away slowly (Omi náà rọra ń ṣàn lọ) (ii) ‘ro’ After I washed the plate, I left them to drain (Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti fọ àwọn abọ́ náà tán, mo fi wọ́n sílẹ̀ láti ro).
drape: ‘ró’ He draped a cloak round his shoulders (Ó ró aṣọ ìlékè náà mọ́ èjìká rẹ̀).
draw: (i) ‘pọn’ He drew water fron a stream (Ó pọn omi láti inú odò) (ii) ‘fà’ He drew a line (Ó fa ìlà) (iii) ‘fà’ He drew water from the well (Ó fa omi láti inú kànga) (iv) ‘yà’ He drew a picture (Ó ya àwòrán).
dress: ‘dì’ I dressed his cut hand (Mo di ọwọ́ tó fi pa)
dribble: ‘gé’ I dribbled him (Mo gé e).
drift: ‘fò’ The feather drifted past in the wind (Ìyẹ́ náà fò kọjá nínú afẹ́fẹ́).
drill: ‘gbẹ́’ He drilled holes in the wall (Ó gbẹ́ ihò sí ara ògiri).
drink: ‘mu’ He drank water (Ó mu omi); ‘mu’ He drank gaàrí (Ó mu gaàrí).
drip: (i) ‘kán’ The water is dripping (Omi náà ń kán) (ii) ‘ro’ This water is dripping into the plate (Omi yìí ń ro sínú abọ́)
drive: (i) ‘dà’ He is driving the cows along (Ó ń da mààlúù lọ) (ii) ‘wà’ He drove a car (Ó wa ọkọ̀) (iii) ‘rú’ (He is driving out animals from the bush (Ó ń rú igbó) (iv) ‘lé’ The chemical can drive away mosquitoes (Oògùn yìí lè lé ẹ̀fọn lọ) (v) ‘kàn’ He used a hammer to drive a nail (Ó fi hámà kan èṣó wọlé) (vi) ‘fẹ́’ The wind was driving the rain against the window-panes (Atẹ́gùn ń fẹ́ òjò lu gíláàsì wínńdò) (vii) ‘tì’ He was driven by hunger to steal (Ebi ló tì í lọ jalè) (viii) ‘ṣe’ What is he driving at? (Kí ni o fẹ́ ṣe)?.
drizzle: (i) ‘fọ́n’ It is drizzling (Òjò ń fọ́n) (ii) ‘wọn’ It is drizzling (Ó ń wọn).
droop: ‘rọ’ The flowers drooped soon after we picked them (Àwọn àdòdó náà rọ ní kété tí a já wọn tán).
drop: ‘bọ́’ It dropped onto the ground (Ó bọ́ sílẹ̀) (ii) ‘ré’ The orange dropped from the tree (Ọsàn náà ré bọ́ láti orí igi) (iii) ‘rẹ̀’ The leaves of the tree have dropped (Igi náà ti rẹ̀) (iv) ‘wá’ I am going to drop in to see you on my way home from school (Mà á wá rí ọ bí mo bá ti ń ti ilé-ẹ̀kọ́ bọ̀ nílé).
drown: ‘rì’ Don’t play by the river in case you fall in and drown (Má ṣeré létí omi kí o má baà subú sínú rẹ̀ kí o sì rì).
drum: (i) ‘lù’ He drummed on the table with his finger (Ó fi ìka ọwọ́ rẹ̀ lu tábìlì) (ii) ‘kì’ He drummed the floor with his feet (Ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ki ilẹ̀).
drunk: (i) ‘pa’ He is drunk (Ọtí ń pa á) (ii) ‘yó’ He is drunk (Ó ti yó).
dry: (i) ‘gbẹ’ The river has dried up (Omi náà ti gbẹ) (ii) ‘sá’ He hung the clothes in the sun to dry (Ó sá àwọn aṣọ náà sí òòrùn láti gbẹ).
due: (i) ‘tọ́’ A great deal of money is due to you (Ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ni ó tọ́ sí ọ) (ii) ‘dé’ The car is due in five minutes (Káà náà yóò dé ní ìṣẹ́jú márùn-ún sí àsìkò yìí) (iii) ‘fà’ His illness was due to bad food (Oúnjẹ burúkú ni ó fa àìsàn rẹ̀).
dull: (i) ‘sì’ He looks dull (Ojú rẹ̀ sì) (ii) ‘fà’ He is dull (Ó fà).
dump: ‘jù’ We dumped our bags on the floor (A ju àwọn báàgì wa sí orí ilẹ̀).
durable: ‘tọ́’ It is durable (Ó tọ́).
during: ‘fún’ I sat for one hour (I sat during the period of an hour (Mo jókòó fún wákàtí kan).





Ee

eager: ‘fẹ́’ He is eager to show me his work (Ó ń fẹ́ láti fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn mí).
early: ‘yá’ I was early (Ó yá mi).
earned: ‘gbà’ He earned a lot of money by working in the morning (Ó gba owó púpọ̀ nítorí pé ó ń ṣiṣẹ́ ní àárọ̀).
ease: ‘rọ̀’ The new medicine eased his pains (Oògùn titun náà mú kí ara ríro rẹ̀ rọ̀).
easy: (i) ‘yá’ This work is easy to do (Iṣẹ́ yìí yá ṣe) (ii) ‘rọ̀’ Those questions are easy (Àwọn ìbéèrè yẹn rọ̀).
eat: (i) ‘gin’ He is eating it in bits (Ó ń yín in jẹ) (ii) ‘wà’ I ate (drank) gaàrí (Mo wa gaàrí) (iii) ‘jẹ’ He ate bread (Ó jẹ búrẹ́dì) (iv) ‘jẹ’ He ate his plantain raw (Ó ṣán ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ).
economically: ‘gán’ He used it economically (Ó gán an lò).
educate: ‘kọ́’ Teachers educates pupils (Àwọn olùkọ́ máa ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́).
effect: (i) ‘mú’ I feel too cold (I feel the effect of cold) (Òtútù mú mi) (ii) ‘gbò’ The sickness had an effect on him (Àìsàn náà gbò ó).
effect: ‘jẹ́’ The medicines is effective (Oògùn náà jẹ́).
elastic: (i) ‘fà’ It  is elastic (Ó ń fà bíi rọ́bà) (ii) ‘lẹ̀’ Rubber is an elastic substance (Nǹkan tí ó lẹ̀ ni rọ́bà).
elect: ‘yàn’ They elected their representative (Wọ́n yan aṣojú wọn).
eliminate: ‘yọ’ She has been eliminated from this year’s athletic race (Wọ́n ti yọ ọ́ nínú eré sísá ọdún yìí).
emerge: ‘yọ’ We went along the river and emerged in the school compound (A tọ ẹ̀bá odò lọ a sì yọ sínú ọgbà ilé-ẹ̀kọ́).
emit: ‘tàn’ The sun emits light (Oòrùn máa ń tan ìmọ́lẹ̀).
empty: (i) ‘dá’ The market is empty (Ọjà dá) (ii) ‘ṣu’ He went to empty his bowel (Ó lọ ṣu).
end: (i) ‘tán’ It has come to an end (Ó ti tán) (ii) ‘pin’ The road ends here (Ọ̀nà pin sí ibí yìí).
endanger: ‘wu’ He is being endangered (Ewu ń wu ú).
engage: (i) ‘gbé’ I engaged a room (Mo ń gbé yàrá kan) (ii) ‘lò’ The telephone number is engaged (Wọ́n ń lo nọ́ḿbà tẹlifóònù náà).
enlarge: ‘fẹ̀’ He enlarged the hole (Ó fẹ ihò náà).
enough: ‘tó’ There is enough paper here (Ìwé ibí yìí tó).
enter: (i) ‘kó’ He entered the forest (Ó kó sí inú igbó (ii) ‘wọ̀’ He entered the house (Ó wọ ilé náà).
entirely: ‘tán’ He has entirely finished the cake (Ó ti parí àkàrà náà tán).
entitled: ‘tọ́’ I am entitled to it (Ó tọ́ sí mi)
envelope: ‘gbà’ The mist enveloped the sky (Ìkùukùu gba ojú ọ̀run)
equal: ‘jẹ́’  Four and two equal six (Ẹẹ́rin àti eéjì jẹ́ ẹẹ́fà).
erect: ‘’kọ́’ He erected a new hut in the village (Ó kọ́ abà titun kan sí abúlé).
escape: (i) ‘yọ’ He escaped from danger (Ó yọ nínú ewu) (ii) ‘bọ́’ The child escaped from his mother (Ọmọ náà bọ́ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀).
escort: ‘sìn’ He escorted his visitors to the motor park (Ó sin àlejò rẹ̀ lọ sí ìdíkọ̀).
evaporate: ‘gbẹ’ Water from their river evaporated (Omi inú odò náà gbẹ).
ever: ‘rí’ Have you ever entered an aeroplane? (Ǹjẹ́ o wọ inú ẹropíléènì rí?).
evident: ‘hàn’ It is evident that he came (Ó hàn pé ó wá).
examine: (i) ‘wò’ He examined it (Ó wò ó wò) (ii) ‘wò’ I examined the insect to see what he was (Mo wo kòkòrò náà kí n lè mọ ohun tí ó jẹ́).
exceed: ‘jù’ Mine exceed yours (Tèmi ju tìrẹ lọ).
except: ‘ju’ I want nothing except but books (N kò fẹ́ nǹkan mìíràn ju ìwé).
excessive: ‘pọ̀’ The price of their chair is excessive, I can’t pay that much (Iye tí ó pe àga wọn pọ̀, n kò lè san owó tí ó tó ìyẹn).
exclude: ‘yọ’ We excluded Ayọ̀ from our club because he was too young (A yọ Ayọ̀ nínú ẹgbẹ́ wa nítorí pé ó kéré jù).
execute: ‘pa’ The man who had killed Olu was executed (Wọ́n pa ọ̀kùnrin tí ó pa Olú).
exhaust: ‘rẹ̀’ The journey has exhausted him (Ìrìnàjò náà ti jẹ́ kí ó rẹ̀ ẹ́).
exist: (i) ‘wà’ It exists (Ó wà) (ii) ‘bẹ’ It exists (Ó ń bẹ) (iii) ‘sí’ It does not exist (Kò sí)
expand: (i) ‘fẹ̀’ It is expanding (Ó ń fẹ̀) (ii) ‘hè’ He expanded it (Ó hè é)
expel: ‘lé’ He was expelled from school (Wọ́n lé e ní ilé-ẹ̀kọ́).
expensive: ‘wọ́n’ It is expensive (Ó wọ́n).
experience: (i) ‘jẹ’ He was whipped (He experienced whipping) Ó jẹ ẹgba (ii) ‘bà’ I experienced a feeling of fear (Ẹ̀rù bá mí).
expose: ‘yá’ He is warming himself by the fire/He exposed himself to the fire (Ó n
       yá iná)
extensive: ‘fẹ̀’ It is extensive (Ó fẹ̀).
extinguish: ‘pa’ They extinguished the fire (Wọ́n pa iná náà).
extract: (i) ‘yọ’ One of his teeth was extracted (Wọ́n yọ ọ̀kan nínú eyín rẹ̀) (ii) ‘wà’ We extracted gold from the earth (A wa góòlù láti inú ilẹ̀).

No comments:

Post a Comment