Friday, 15 May 2015

T-Y: Yoruba Monosyllabic Words (English-Yorùbá)




Tt

tack: ‘gán’ He tacked the clothes (Ó gán aṣọ náà)
tactful: ‘gbọ́n’ She is very tactful (Ó gbọ́n púpọ̀)
take: (i) ‘fi’ He used knife to cut it (He takes his knife and cut it) (Ó fi ọ̀bẹ gé e) (ii) ‘mú’ He took it (Ó mú un) (iii) ‘kó’ The vehicle took passangers (Ọkọ̀ náà kó èrò) (iv) ‘ré’ He took down the clothes from the peg (Ó ré àwọn aṣọ náà lórí ìkọ́) (v) ‘wà’ I took the cooked rice out of water and left it to drain (Mo wa ìrẹsì kúrò lórí iná mo sì fi sílẹ̀ kí ó gbẹmi) (vi) ‘wọ́n’ I took off my clothes (Mo wọ́n aṣọ kúrò lára mi) (vii) ‘mi’ I took the pill (Mo mi oògùn oníkóró náà) (viii) ‘gbé’ Take the shopping home (Gbé ọjà tí a rà náà sí ilé) (ix) ‘lò’ I took the medicine (Mo lo oògùn náà) (x) ‘gbà’ Will you take N10 for the book? (Ṣé o gba náírà mẹ́wàá fún ìwé náà?) (xi) ‘kọ’ Take down the sentence (Kọ gbólóhùn náà sílẹ̀?) (xi) ‘mu’ Will you take tea or coffee? (Kọfí lo máa mu àbí tíì?) (xiii) ‘bọ́’ Take off youe clothes (Bọ́ ẹ̀wù rẹ) (xiv) ‘sọ’ The dog took guard of the house (Ajá náà ń sọ́ ilé náà).
tall: ‘ga’ Olú is taller than Adé (Olú ga ju Adé).
tame: ‘rọ̀’ The dog is tamed (Ajá yìí rọ̀).
tan: (i) ‘rún’ We tan animal skin to make leather shoes (A rún awọ ẹran láti fi ṣe bàtà aláwọ).
tap: ‘dá’ He tapped the palm tree (Ó da ọ̀pẹ náà).
tardy: (i) ‘fà’ The law is often tardy in reaction to the changing society (Òfin máa ń sáábà fà láti ṣe nǹkan sí àwújọ tí ó ń yí padà) (ii) ‘pẹ́’ He was tardy in offering help to the children (Ó pẹ́ kí ó tó wá ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́).
tasteless: ‘tẹ́’ The food is tasteless (Oúnjẹ yìí ti tẹ́).
taste: ‘tọ́’ He teasted me (Ó tọ́ mi).
tell: (i) ‘sọ’ Tell me what happened today (Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní òní fún mi) (ii) ‘pa’ They listened to the story he told them (Wọ́n fi etí sí àlọ́ tí ó pa fún wọn).
tender: ‘rọ̀’ The meat is tender (Ẹran náà rọ̀).
tenterhook: ‘yán’ I am on tenterhooks with eagerness (Ojú mi yán).
tether: ‘so’ He tethered his goat to the post (Ó so ẹran náà mọ́ òpó).
than: ‘jù’ Olú is older than Adé (Olú dàgbà ju Adé lọ)
that: (i) ‘kí’ He said that I should come (Ó ní kí n wá) (ii) ‘bí’ He says there is nothing but that he will kill him (Ó ní àfi bí òun pa á) (iii) ‘pé’ He thought that he would come (Ó rò pé òun á wá) (iv) ‘yẹn’ That woman is my mother (Ìyá mi ni obìnrin yẹn) (v) ‘tí’ He liked the book that I gave her (Ó fẹ́ràn ìwé tí mo fún un).
thatch: (i) ‘bò’ I thatched my roof (Mo bo ilé mi) (ii) ‘ṣẹ́’ He thatched the house (Ó ṣẹ́ ilé náà).
thaw: ‘yọ́’ Leave frozen food to thaw before cooking it (Jẹ́ kí oúnjẹ tí ó dì yọ́ kí o tó sè é).
their: ‘wọn’ I saw their book (Mo rí ìwé wọn).
them: ‘wọn’ He saw them (Ó rí wọn).
they: ‘wọ́n’ They went (Wọ́n lọ).
thick: ‘ki’ The soup is thick (Ọbẹ̀ náà ki).
thin: (i) ‘fọn’ He is thin/emaciated (Ó fọn) (ii) ‘tín’ His legs are thin (Ó tin lẹ́sẹ̀) (iii) ‘sàn’ The soup is thin (Ọbẹ̀ náà sàn) (iv) ‘rù’ He is thin (Ó rù)
think: ‘rò’ He thought that it is right (Ó rò pé ó dára).
this: ‘yí’ This is what I want you to do (Ohun tí mo fẹ́ kí o ṣe nì yí).
thrash: (i) ‘nà’ He thrashed the child (Ó na ọmọ náà). (ii) ‘lù’ He thrashed the child (Ó lu ọmọ náà).
thread: (i) ‘bọ̀’ He is threading the needle (Ó ń bọ abẹ́rẹ́) (ii) ‘sín’ He threads beads on the cotton (Ó fi òwú sín ìlẹ̀kẹ̀).
thresh: ‘pa’ He threshed the corn (Ó pa ọkà).
through: ‘gbà’ He took it through the house (Ó gbé e gba inú ilé).
throw: (i) ‘jù’ He threw a stone (Ó ju òkúta) (ii) ‘dá’ He threw me on the ground while we were wrestling (Ó dá mi nígbà tí a ń ja ìjàkadì) (iii) ‘sọ’ I threw it inside  the plate (Mo sọ ọ́ sínú abọ́).
thrust: (i) ‘kì’ He thrust his hand into his pocket (Ó ki ọwọ́ rẹ̀ bọ àpò rẹ̀) (ii) ‘tì’ He thrust his hand into his pocket (Ó ti ọwọ́ rẹ̀ bọ àpò rẹ̀) (iii) ‘gún’ He thrust a knife into his enemy’s heart (Ó fi ọ̀bẹ gún ọ̀tá rẹ̀ ní ọkàn).
thunder: ‘sán’ It thundered (Àrá sán).
tickle: ‘rìn’ He tickled my armpit (Ó rìn mí lábíyá).
btidy: ‘mọ́’ I like room to be tidy (Mo máa ń fẹ́ kí yàrá mọ́).
tie: (i) ‘ta’ He tied the cloth round the tree (Ó ta aṣọ náà mọ́ igi) (ii) ‘dè’ He tied it (Ó dè é) (iii) ‘dì’ He tied up the firewood (Ó di igi náà) (iv) ‘so’ They tied it (Wọ́n so ó).
tight: (i) ‘fún’ It is tight (Ó fún) (ii) ‘há’ It is tight (Ó há) (iii) ‘họ́’ It is tight (Ó họ́).
tighten: ‘dè’ Tighten this screw (De súkúrúù yìí).
till: (i) ‘ró’ He tilled the hand (Ó ró ilẹ̀) (ii) ‘dè’ Let’s wait till the rain stops (Jẹ́ kí á dúró de ìgbà tí òjò máa dá).
tilt: ‘tẹ̀’ I tilted the cups to drink out of it (Mo tẹ kọ́ọ̀bù náà kí n lè mu omi láti inú rẹ̀).
time: ‘yá’ It is time for us to go (Ó ti yá kí a lọ).
tiny: ‘wẹ́’ It is tiny (Ó wẹ́).
tip: ‘yí’ When the car hit a bus, it tipped over (Nígbà tí káà náà kọlu bọ́ọ̀sì kan, ó (káà náà) yí dànù).
tire: (i) ‘gá’ I am tired (Ó gá mi) (ii) ‘I am tired (Ó gọ́ mi) (iii) ‘sú’ I am tired (Ó sú mi) (iv) ‘rẹ̀’ I am tired (Ó rẹ mí).
to: (i) ‘fún’ He sold it to me (Ó tà á fún mi) (ii) ‘sí’ He went to the market (Ó lọ sí ọjà) (iii) ‘gbà’ He took it to the house (Ó gbé e gba inú ilé lọ) (iv) ‘dé’ They measured the dog from head to tail (Wọ́n wọn ajá náà láti orí dé ìrù) (v) ‘mọ́’ He fixed the shelf to the wall (Ó de ṣẹ́ẹ̀fù náà mọ́ ògiri) (vi) ‘kù’ It is ten minutes to nine (Aago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá).
together: (i) ‘jọ’ We went together (A jọ lọ) (ii) ‘pọ̀’ I stuck the two pieces of paper together (Mo lẹ àwọn bébà méjèèjì pọ̀).
too: ‘jù’ It is too late (Ó ti pẹ́ jù).
topple: ‘ré’ Olú knocked against the table and the glass toppled onto the floor (Olú kọ lu tábìlì ife sì ré bọ́ sílẹ̀).
toss: ‘jù’ The boys tossed the ball to each other (Àwọn ọmokùnrin náà ju bọ́ọ̀lù náà sí ara wọn).
touch: (i) ‘tọ́’ He touched me lighly (Ó tọ́ mi) (ii) ‘gbún’ He touched me slightly (Ó gbún mi) (iii) ‘kàn’ The branches of the tree touched the water (Àwọn ẹ̀ka igi náà kan omi).
tough: (i) ‘yi’ It is tough (Ó yi) (ii) ‘le’ Soldiers must be tough (Àwọn sójà gbọ́dọ̀ le).
train: ‘tọ́’ He trained me (Ó tọ́ me).
transfer: (i) ‘ré’ Death has been transferred from my head (Ikú ré lórí mi) (ii) ‘fún’ He transferred his property to me (Ó fún mi ní ohun ìní rẹ̀).
translate: ‘yí’ He translated Yorùbá into English (Ó yí èdè Yorùbá padà sí èdè Gẹ̀ẹ́sì).
transplant: ‘lọ́’ He transplanted the vegetable (Ó lọ́ ẹ̀fọ́).
transport: (i) ‘gbé’ The people were transported by train (Ọkọ̀ ojú irin ni wọ́n fi gbé àwọn ènìyàn náà) (ii) ‘kó’ The goods were transported by train (Ọkọ̀ ojú irin ni wọ́n fi kó àwọn ẹrù náà)
travel: ‘rìn’ At what speed is he travelling? (Báwo ló ṣe yára rìn sí?).
tread: ‘tẹ̀’ I trod on his foot by accident (Mo ṣèèṣì tẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀).
treat: ‘mọ́’ He treated the sore on his arm (Ó mọ́ egbò apá rẹ̀)
tremble: (i) ‘wá’ He is trembling (Ó ń wá rìrì) (ii) ‘gbọ̀n’ He trembled with fear (Ẹ̀rù ń jẹ́ kí ó gbọ̀n).
trick: ‘tàn’ He tricked me into taking the medicine (Ó tàn mí mu oògùn náà).
trickle: ‘kán’ Blood trickled from the wound (Ẹ̀jẹ̀ kán láti inú egbò náà).
trim: (i) ‘ré’ I trimmed my fingernails (Mo ré èékánná mi) ‘gé’ He trimmed his hair (Ó gé irun rẹ̀̀) (iii) ‘tọ́’ He trimmed his hair (Ó tọ́ irun rẹ̀).
trip: (i) ‘jìn’ He tripped me from the back (Ó jìn mí lẹ́sẹ̀) (ii)’gbún’ He tripped me (Ó gbún mi lẹ́sẹ̀ láti  ẹ̀yìn).
thrive: ‘gbọ̀’ Vegetables thrive well on humus soil (Ilẹ̀ ọlọ́ràá máa ń gbọ ẹ̀fọ́).
trouble: ‘gbò’ The sickness troubled him (Àìsàn náà gbò ó).
truss: (i) ‘dè’ The policeman trussed up the robber with a rope (Ọlọ́pàá náà fi okùn de olè náà) (ii) ‘dì’ The policeman trussed up the robber with a rope (Ọlọ́pàá náà fi okùn di olè náà).
tuck: ‘ká’ He tucked up his shirt sleeves (Ó ká apá ṣáàtì rẹ̀ sókè).
tug: ‘fà’ The cat was tugging at my shoe-lace (Ológbò náà ń fa okùn bàtà mi).
tune: (i) ‘yín’ He tuned his radio (Ó yín rédíó rẹ̀) (ii) ‘tó’ He was fined up to the tune of N1,000 (Fáìnì tí wọ́n ní kó san tó ẹgbẹ̀rún náírà) (iii) ‘yí’ Tune in (your radio) to Ogun Radio (Yí rédíò rẹ sí Rédíò Ògùn).
turn: (i) ‘kọ’ He tunred his right side to my direction (Ó kọ ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ sí mi) (ii) ‘yà’ He tunred off to the left (Ó yà sí apá òsì) (iii) ‘rún’ He turned (his body) over in bed (Ó rún ara rẹ̀ lórí ẹní) (iv) ‘dì/dà’ He turned traitor (Ó ti di ọlọ̀tẹ̀) (v) ‘tú; Turn the dog loose (Tú ajá náà sílẹ̀) (iv) ‘rìn’ I will take a few turns round the house first (Màá kọ́kọ́ rìn yí ilé po ná) (viii) ‘yí’ The earth turns round the sun (Ayé ń yí oòrùn po) (ix) ‘ṣí’ He was turning the pages of the book (Ó ń ṣí ojú-ìwé náà) (x) ‘dà’ He has turned fifty (Ó ti da ọmọ àádọ́ta ọdún). (xi) ‘tàn’ Turn on the light (Tan iná náà) (xii) ‘pa’ Turn off the light (Pa iná náà) (xiii) ‘nà’ He turned his toes out (Ó na àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ síta) (xiv) ‘ṣe’ The factory is turning out large quantity of plastic pails (Ilé-iṣẹ́ náà ń ṣe péèlì oníke púpọ̀) (xv) ‘gbé’ He has turned over his business to his children (Ó ti gbé ilé-iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀) (xvi) ‘dé’ He hasn’t turned up for work this morning (Kò tíì dé ibi iṣẹ́ ní àárọ̀ yìí) (xvii) ‘wá’ He didn’t turn up for work today (Kò wá sí ibi iṣẹ́ ní òní) (xviii) ‘ká’ Turn up your shirt sleeves (Ká apá ṣáàtì rẹ sókè)
twang: (i) ‘kùn’ The bow twanged and the arrow whistled through the air (Ọrun kùn, ọfà sì súfèé lọ nínú afẹ́fẹ́) (ii) ‘ta’ He was twanging a guitar (Ó ń ta gìtá).
twist: ‘lọ́’ He twisted his neck (Ó lọ́ ọ lọ́rùn)
type: ‘tẹ̀’ Type the letter (Tẹ lẹ́tà náà).
Uu

uncork: ‘ṣí’ Uncork that bottle (Ṣí ìgò yẹn).
under: ‘rì’ The boat went under (Ọkọ̀ náà rì)
understand: (i) ‘gbọ́’ He understood me (Ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi) (ii) ‘yé’ I understand it (Ó yé mi).
undertake: ‘gbà’ He underttok to finish the work by Friday (Ó gbà láti parí iṣẹ́ náà títí ọjọ́ Jímọ̀-ọ̀n).
undone: ‘tú’ My shoe-lace has come undone (Okùn bàtà mi ti tú)
unfasten: ‘tú’ He unfastened hisa belt (Ó tú bẹ́líìtì rẹ̀).
unfold: (i) ‘tẹ́’ He unfolded the carpet (Ó tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì náà) (ii) ‘tú’ He unfolded the cloth (Ó tú aṣọ náà).
ungrateful: ‘ṣú’ He is ungrateful to him (Ó fi ibi ṣú u).
unlock: ‘ṣí’ Unlock that door (Ṣí ilẹ̀kùn yẹn).
unproductive: ‘ṣá’ This land is unproductive (Ilẹ̀ yìí ti ṣá).
unscrew: (i) ‘ṣí’ Unscrew the lid of this bottle (Ṣí ìdérí ìgò yìí) (ii) ‘tú’ Unscrew the mirror from the wall (Tú gíláàsì náà  kúrò lára ògiri)
untie: ‘tú’ He untied the bunch of wood (Ó tú ẹrù igi náà).
unwind: ‘tún’ The thread unwine from the ball (Òwú náà tú lára bọ́ọ̀lù náà).
up: (i) ‘tán’ He ate up his food (Ó jẹ oúnjẹ rẹ̀ tán) (ii) ‘ṣe’ Go and see what the children are up to (Lọ wo ohun tí àwọn ọmọ náà ń ṣe).
upon: ‘lé’ He poured the water upon it (Ó da omi lé e).
uproot: ‘hú/wú’ He uprooted the tree (Ó hú igi náà).
urbane: ‘re’ This girl is too urbane (Ọmọbìnrin yìí ti re jù).
urge: ‘rọ̀’ He urged her to rest (Ó rọ̀ ọ́ kó simi).
urinate: ‘tọ̀’ He urinated (Ó tọ̀).
us: (i) ‘wa’ He saw us (Ó rí wa) (ii) ‘á’ Do you want us to help you? (Ṣé o fẹ́ kí a ràn ọ́ lọ́wọ́?) (v) ‘ni’ He saw us (Ó rí ni).
use: (i) ‘mu’ He uses powdered tobacco (Ó ń mu tábà) (ii) ‘lò’ He used it (Ó lò ó) (iii) ‘sà’ He used charm on him (Ó sa oògùn sí i) (iv) ‘ṣe’ This leather can be made into footwear (Awọ yìí ṣeé ṣe bàtà) (v) ‘fi’ He used a knife to cut bread (Ó fi ọ̀bẹ gé búrẹ́dí).
utter: ‘sọ’ He looked at me without uttering a word (Ó wò mí láìsọ nǹkan kan).    

Vv

value: ‘tó’ He valued the gold at N1,000 (Ó ní góòlù náà tó ẹgbẹ̀rún náírà).
vanish: ‘rá’ It vanished (Ó rá).
vault: ‘fò’ He vaulted the fence and ran away (Ó fo fẹ́ǹsì náà ó sì sá lọ).
venture: ‘jẹ́’ Can he venture to go? (Ó ha jẹ́ lọ?)
vibrate: ‘gbọ̀n’ The vehicle vibrated when the driver started the engine (Ọkọ̀ náà gbọ̀n nígbà tí dẹ́rẹ́bà ṣíná).
vie: ‘dù’ They were vying for the prize (Wọ́n ń du ẹ̀bùn ipò kìnní).
vissible: (i) ‘rí’ The smoke from her fire was visible from the road (A rí èéfín iná rẹ̀ láti ojú títì) (ii) ‘hàn’ It is clearly visible (Ó hàn dáadáa).
vomit: (i) ‘pọ̀’ He vomited on the ground (Ó pọ̀ sílẹ̀) (ii) ‘bì’ He vomited (Ó bì).
vow: ‘jẹ́’ He took a vow (Ó jẹ́ ẹ̀jẹ́).

Ww

wade: (i) ‘wọ́’ He waded through the stream (Ó wọ́ omi kọjá) (ii) ‘là’ He waded across the river (Ó la omi kọjá).
wag: (i) ‘jù’ The dog wagged its tail (Ajá náà ju ìrù rẹ̀) (ii) ‘yán’ The dog wagged its tail (Ajá náà yán ìrù rẹ̀).
wail: ‘ké’ The child was wailing (Ọmọ náà ń ké).
wait: ‘ró’ He waited for me (Ó ró dè mí).
wake: ‘jí’ He woke up from his bed (Ó jí lórí ibùsùn rẹ̀).
walk: ‘rìn’ He walked (Ó rìn).
want: (i) ‘bá’ Anybody who wants to go should go (Ẹni tó bá ń lọ kó lọ) (ii) ‘fẹ́’ He wants money (Ó fẹ́ owó) (iii) ‘wá’ The man was wanted by the police (Ọlọ́pàá ń wá ọkùnrin náà).
warm: ‘lọ́’ The water is warm (Omi náà lọ́).
warp: ‘tẹ̀’ The door won’t shut because the wood has warped (Ilẹ̀kùn náà kò tì nítorí pé igi rẹ̀ ti tẹ̀).
warrant: ‘fà’ What warrants such insolence? (Kí ni ó fa irú àfojúdi bẹ́ẹ̀?).
was: (i) ‘wà’ He was at home (Ó wà ní ilé?) (ii) ‘ni’ He was my teacher (Olùkọ́ mi ni) (iii) ‘jẹ́’ He was a headmaster at Ibadan (Ó jẹ́ olùkọ́-àgbà ní Ìbàdàn) (iv) ‘fẹ́’ I was going to write a letter but I didn’t have the time (Mo fẹ́ láti kọ ìwé ṣùgbọ́n n kò ráyè) (v) ‘lè’ I thought they were going to come but didn’t come (Mo rò pé wọ́n lè wá ṣùgbọ́n wọn kò wá).
wash: (i) ‘bọ́’ He washed his face (Ó bọ́ ojú rẹ̀) (ii) ‘fọ̀’ He washed the cloth (Ó fọ aṣọ náà) (iii) ‘wẹ̀’ He washed himself (Ó wẹ ara rẹ̀) (iv) ‘ṣàn’ He washed his body without soap (Ó ṣan ara) (v) ‘gbé’ The wood was washed up the sore by the waves (Ìrú omi gbé igi náà lọ sí èbúté) (vi) ‘tì’ My lunch was bread and butter washed down with beer (Búrẹ́dì àti bọ́tà tí mo fi bíà tì sí ìsàlẹ̀ ni oúnjẹ ọ̀sán mi).
watch: (i) ‘wò’ We watched television (A wo tẹlifísàn) (ii) ‘sọ́’ Will you watch over my clothes? (Ṣé oó bá mi ṣọ́ aṣọ mi?)
water: ‘wọ́n’ Water the plant (Wọ́n omi sí ewéko náà).
watery: ‘ṣàn’ The soup is watery (Ọbẹ̀ yìí ṣàn).
wave: (i) ‘mì’ The plants wave in the wind (Àwọn ewéko náà ń mì nínú atẹ́gùn) (ii) ‘jù’ He waved his hand to say goodbye (Ó ju ọwọ́ rẹ̀ láti sọ pé ó dìgbà) (iii) ‘fi’ He waved his umbrella (Ó fi agboòrùn rẹ̀).
waver: ‘mì’ His resolution is wavering (Ìpinnu rẹ̀ ń mì).
we: (i) ‘a’ We went (A lọ) (ii) ‘à’ We will go (À á lọ).
weak: (i) ‘rẹ̀’ He was weak after his illness (Ó rẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn àárẹ̀ rẹ̀) (ii) ‘sàn’ This soup is weak (Ọbẹ̀ yìí sàn).
weaken: ‘rẹ̀’ The illness weakened his heart (Àìsàn náà jẹ́ kí ó rẹ ọkàn rẹ̀).
wean: ‘wọ́n’ The child was been weaned (Wọ́n ti  ń wọ́n ọmọ náà lọ́mú).
wear: (i) ‘dì’ She wore string ofbeads round her waist (Ó di bèbè sí ìdí) (ii) ‘wọ̀’ She was wearing her mother’s dress (Ẹ̀wù màmá rẹ̀ ni ó wọ̀) (iii) ‘lò’ Mother always wears ear-rings (Màmá máa ń lo yẹtí nígbà gbogbo) (iv) ‘gbó’ My shoes are worn out (Àwọn bàtà mi ti gbó) (v) ‘dá’ You’ve worn a hole in your shirt (Ó ti dá iho sí ṣáàtì rẹ) (vi) ‘tọ́’  The dress has worn well (Ẹ̀wù náà tọ́) (vii) ‘dé’ He wore a hat (Ó dé fìlà) (viii) ‘fi’ She wore a flower in her button hole (Ó fi àdòdó há ihò bọ́tìnì rẹ̀) (ix) ‘jẹ’ The heels of these shoes are wearing down (Ẹsẹ̀ àwọn bàtà yìí ń jẹ) (x) ‘rẹ̀’ These noisy children do wear me down (Àwọn ọmọ aláriwo yìí jẹ́ kí ó rẹ̀ mí).
weary: (i) ‘rẹ̀’ Olú was feeling very weary after the day’s work (Ó rẹ Olú lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ náà) (ii) ‘sú’ I am weary of his constant grumbling (Kíkùn tí ó ń kùn nígbà gbogbo ti sú mi).
weave: (i) ‘hun’ He weaved cloth (Ó hun aṣọ) (ii) ‘wun’ He weaved cloth (Ó wun aṣọ).
wedge: ‘há’ He wedged a stick in between it (Ó fi igi há a).
weed: ‘tu’ They were weeding the grass (Wọ́n ń tu koríko).
weigh: ‘wọ̀n’ He weighed it (Ó wọ̀n ọ́n).
well: ‘sàn’ I feel well (Ó sàn fún mi).
what: (i) ‘kín’ What is it? (Kín ni?) (ii) ‘kí’ What is it? (Kí ni?).
when: ‘bí’ When he saw me, he was happy (Bí ó ti rí mi, inú rẹ̀ dùn).
whether: ‘bí’ I don’t know whether he will come or not (N ò mọ̀ bí ó máa wá tàbí kò níí wá)
which: (i) ‘tí’ The stick which he took (Igi tí ó mú) (ii) ‘wo’ Which shoe? (Bàtà wo?).
whine: (i) ‘hu’ The dog was whining outside (Ajá náà ń hu ní ìta) (ii) ‘ké’ The child is whinning (Ọmọ náà ń ké).
whip: (i) ‘ná’ He whipped the horse (Ó na ẹṣin náà) (ii) ‘lù’ He whipped the horse (Ó lu ẹṣin náà) (iii) ‘pa’ The rain was whipping the window (Òjò ń pa fèrèsé náà) (iv) ‘fà’ He whipped out a knife (Ó fa ọ̀bẹ kan yọ) (v) ‘bọ́’ He whipped off his dress’ (Ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ sọnù) (vi) ‘já’ He whipped the gold chain off his neck) (Ó já ṣéènì onígóòlù náà kúrò lọ́rùn rẹ̀).
whirl: ‘fi’ I swung my arms (round and round) (Mo fi apá mi)
whisk: ‘gbọ̀n’ He whisked the dirt off (Ó gbọn ìdọ̀tí náà kúrò).
white: ‘fún’ It is as white as a cotton carded ready for spinning (Ó fún bí ẹ̀gbọ̀n òwú).
who: (i) ‘tí’ The child who slept (Ọmọ tí ó sùn) (ii) ‘ta’ Who is it? (Ta ni?).
whom: (i) ‘ta’ Whom did you speak to? (Ta ni o bá sọ̀rọ̀?) (ii) ‘tí’ The boy whom we called Olú is really called Olúwọlé (Olúwọlé gan-an ni orúkọ ọmokùnrin tí à ń pè ní Olú).
whose: (i) ‘tí’ The chair whose arms are broken (Àga tí ọwọ́ rẹ̀ kán) (ii) ‘ta’ Whose shoe is this? (Bàtà ta nì yí?).
why: ‘tí’ I don’t know the reason why you didn’t come (N kò mọ ìdí tí o kò fi wá).
wide: (i) ‘fẹ́’ The road is four feet wide (Títì náà fẹ̀ ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin) (ii) ‘jìn’ Your answer was wide off the mark (Ìdáhùn rẹ̀ jìn sí ohun tí a ń retí).
will: (i) ‘á’ We will go (A á lọ) (ii) ‘ẹ́’ You will go (Ẹ ẹ́ lọ) (iii) ‘ó’ You will go (O ó lọ).
win: ‘jẹ’ He won a lottery (Ó jẹ tẹ́tẹ́).
wind: (i) ‘yí’ He wound the door handle (Ó yí ọwọ́ ilẹ̀kùn náà) (ii) ‘rá’ I wound the rope round it (Mo rá okùn náà wé e) (iii) ‘yín’ He wound the  door handle (Ó yín ọwọ́ ilẹ̀kùn náà).
wipe: ‘nù’ He wiped his face (Ó nu ojú rẹ̀)
wish: ‘fẹ́’ I wish to see your mother (Mo fẹ́ rí màmá rẹ).
with: ‘bá’ No one likes to fight with a friend (Kò sí ẹni tí ó máa ń fẹ́ bá ọ̀rẹ́ jà).
wither: ‘rọ’ The leaves withered (Ewé náà rọ)
work: ‘sìn’ He is working for him (Ó ń sìn ín)
worm-eaten: ‘ju’ The maize is warm-eaten (Àgbàdo náà ju).
worry: ‘mì’ The trouble didn’t bother me (Wàhálà náà kò mì mí)
worship: (i) ‘bọ’ He worshipped the deity (Ó bọ òrìṣà) (ii) ‘sìn’ They worshipped the Lord (Wọ́n sin Olúwa).
worth: ‘tó’ How much is this bicycle worth? (Èló ni kẹ̀kẹ́ yìí tó?).
worthy: (i) ‘yẹ’ The lazy person is not worthy of respect (Ọ̀wọ̀ kò yẹ ọ̀lẹ ẹ̀dá) (ii) ‘tó’ The cloth is worthy of its name (Aṣọ náà tó aṣọ).
wound: ‘pa’ He has been wounded (He has wounded his body) (Ó ti fi ara pa).
wrap: (i) ‘pọ́n’ He used leaves to wrap it (Ó pọ́n ọn léwé) (ii) ‘ṣù’ He is wrapping ẹ̀kọ (a food meal of maize) (Ó ń ṣu ẹ̀kọ).
wrench: (i) ‘rọ́’ He gave his ankle a wrench (Ó fi orúnkún rọ́) (ii) ‘fà’ He gave the tooth a wrench and it came out (Ó fa eyín náà ó sì yọ ọ́ jáde).
wriggle: (i) ‘wọ́’ The snake wriggled along the road (Ejò náà ń wọ́ lọ ní orí títì) (ii) ‘jì’ The worm wriggled as we put it on the fish-hook (Ekòló náà ń jì bí a ṣe fi í bọ ìwọ̀) (iii) ‘pọ́’ He wriggled through the thick hedge (Ó pọ́ kọjá inú ọgbà tí wọ́n fi okùn dì) (iv) ‘yọ’ He wriggled out of the difficulty (Ó yọ kúrò nínú ìṣòro náà).
wring: (i) ‘lọ’ He wrung the chicken’s neck to kill it (Ó lọ́ adìẹ náà lọ́rùn láti pa á) (ii) ‘fún’ He wrung the towel and hung it out to dry (Ó fún tówẹ́ẹ̀lì náà ó sì sá a síta láti gbẹ).
wrinkle: ‘rún’ The front of his dress wrinkles (Iwájú aṣọ rẹ̀ rún).
write: ‘kọ’ He wrote a book (Ó kọ ìwé).
wrong: ‘ṣì’ You’ve spelt the word wrong (Ó ṣi ọ̀rọ̀ náà kọ sílẹ̀).

Yy

yank: ‘fà’ He yanked out a tooth (Ó fa eyín kan tu).
yawn: ‘yán’ He yawned (Ó yán)
yes: (i) ‘hun’ He said yes (Ó ní hun) (ii) ‘hẹn’ I asked him if it is so; he said yes (Mo bi í pé ṣé bẹ́ẹ̀ ni; ó ní hẹn)
yet: ‘ì’ He has yet to come (Kò ì wá)
yield: ‘ta’ The yam yielded very well (Iṣu náà ta).
you: (i) ‘ẹ’ You ate (Ẹ jẹun) (ii) ‘ẹ̀’ You should have gone (Ẹ̀ bá ti lọ) (iii) ‘o’ You ate (O jẹun) (iv) ‘ọ’ I saw you (Mo rí ọ) (v) ‘ẹ́’ I call you (Mo pè Ọ́) (vi) I call you (Mo pè ẹ̀) (vii) ‘ẹ’ I saw you (Mo rí ẹ).
your: (i) ‘ẹ’ Your husband (Ọkọ ẹ) (ii) ‘rẹ’ This is your dog (Ajá rẹ nìyí).`

No comments:

Post a Comment