Monday, 4 May 2015

Kémísìrì fún Alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ (Chemistry for Beginners): Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kejì (Second Lecture)



L.O. Adéwọlé àti A.A. Fábẹkú





 

Ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kìíní, àwọn ohun tí a mẹnu bà ni ẹ̀dá, ìwọ̀n, ìwúwo àti àwo.n àbùdá ẹ̀dá òde. Nínú idànilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ní ni a ó fi bẹ̀rẹ̀.

 

Àwọn Àbùdá Inú tí Ẹ̀dá Ní[1]

 

Àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ní ni ó máa ń kópa nígbà tí ẹ̀dá kan ba ń yí padà di ohun tuntun mìíràn tàbí nígbà tí ẹ̀dá bá gbé ìwà ọtun mìíràn wọ̀. Àbùdá òde[2] kì í fún wa ní ẹ̀dá tuntun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí omi bá dì (tí ó di áísì bulọọ̀kù), omi ni. Nígbà tí omi bá di afẹ́fẹ́ (tí ó di gáàsì), omi náà ni. Bí omi bá dì, bí ó bá dé ọ̀gangan yíyọ́[3], yóò tún di omi padà. Bí omi bá di afẹ́fẹ́ (gáàsì), yóò di omi padà bí ìgbóná[4] bá wá sílẹ̀. Omi tí ó dì àti omi tí ó di afẹ́fẹ́ (gáàsì), abẹ́ àbùdá òde ni gbogbo iṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń ṣẹlẹ̀. Omi yìí kò yí padà di ẹ̀dá tuntun ṣùgbọn ní ti àbùdá inú, ẹ̀dá tuntun mìíràn ni ó máa ń wáyé. Ẹ̀dá tuntun yìí yóò sì yàtọ̀ sí ti  tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí a bá jó igi ní inú iná, ẹ̀dá tuntun tí igi yìí yóò yí padà sí yóò yàtọ̀ sí tit ẹ́lẹ̀. Èjíjó igi yìí yóò yàtọ̀ sí bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ nípa ìrísí, nípa àwọ̀ àti nípa àwo.n ìwà mìíràn. Bákan náà, bí irin bá dípẹtà[5], yóò yàtọ̀ sí bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ nípa àwọ̀, irísí, àti àwo.n ìwà mìíràn. A ó máa ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn àbùdá inú àti àbùdá òde nínú àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí a ó ṣe ní iwájú.

 

Àwọn Àmì[6] Èròjà Ẹ̀dá[7] àti Ìgbékalẹ̀[8] Wọn (Ọmọlẹ̀[9])

 

Nínú Kẹ́mísírì, àwọn àwọn èròjà ẹ̀dá[10] ni a ń pè ní omi ìṣẹ̀dá[11] èyí tí ò lè jẹ́ ọmọlẹ̀ tàbí àdìpọ̀[12]. Àmì (symbol) ni ó máa ń dúró èròjà ẹ̀dá (matter). Ó máa ń rọrùn fún wa láti jẹ́ kí lẹ́tà ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ (initial letter) ọmọlẹ̀ (element) dúró gẹ́gẹ́ bí àmì ọmọlẹ̀ náà. Bí ìkọlura bá fẹ́ wà, a máa ń lo lẹ́tà méjì. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́tà kan náà ni ó bẹ̀rẹ̀ Hydrogen[13] àti Helium[14]Bí wọ́n ṣe yanjú ìkọlura yìí ni pé H  ni ó dúró fún hydrogen nígbà tí He sì dúró fún Helium. Lẹ́tà kejì tí a bá lò yìí gbọ́dọ̀ rọrùn láti ṣe àtapò (association) rẹ̀ dé ara lẹ́tà ọmọlẹ̀ (element) náà. Àwọn àpẹẹrẹ ọmọlẹ̀ (element) oní-lẹ́tà méjì ni:tellurium (Te), technetium (Tc) àti  Terbium (Tb). Púpọ̀ nínú àwọn ọmọlẹ̀ (element) wọ̀nyí ní ó jẹ pé orúkọ Látìnì ni wọ́n fún wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Ara orúkọ Látìnì yìí sì ni àwọn àmì (symbol) wọn ti jẹ yọ. Àwọn àpẹẹrẹ ni Cu, copper (cuprum); Na, sodium (natrium); Fe, iron (ferrum); Ag, silver  (argentums); Sn, tin (stannum); Au, gold (Aurum); K, potassium (Kalimu).

Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí pé nígbà tí a bá lo lẹ́tà méjì fún láti dúró fún ọmọlẹ̀ (element) kan, lẹ́tà àkọ́kọ́ máa ń jẹ́ lẹ́tà ńlá (capital letter.upper case) lẹ́tà kejì sì máa ń jẹ́ létà kékeré (lower case/small letter).

 

Ìtọ́ka[15] Àwọn Ọmọlẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ Jù àti Àwọn Àmi wọn

 

Àwọn ọ̀mọ̀lé tí ó wópọ̀ ju nínú ààtò àtẹ ọ̀mọ̀lé (period table) ni a ṣe ìtóka sí ìsàlẹ̀ yìí. Àwọn mẹ́rìndínlógún tí ó ṣe pàtàkì jù ni a fi ṣáájú.

Ọmọlẹ̀ (Element) 1: Hydrogen [H];    Ọmọlẹ̀ (Element) 2: Helium [He];                  Ọmọlẹ̀ (Element) 3: Lithium [Li]               Ọmọlẹ̀ (Element) 4: Beryllium [Be]   Ọmọlẹ̀ (Element) 5: Boron [B];         Ọmọlẹ̀ (Element) 6: Carbon  [C];              Ọmọlẹ̀ (Element) 7: Nitrogen            [N];    Ọmọlẹ̀ (Element) 8: Oxygen [O];         Ọmọlẹ̀ (Element) 9: Fluorine           [F];         Ọmọlẹ̀ (Element) 10: Neon [Ne];                  (Ọmọlẹ̀ Element) 11: Sodium [Na];    Ọmọlẹ̀ (Element) 12: Magnesium [Mg]; Ọmọlẹ̀ (Element) 13: Aluminum [Al];                     Ọmọlẹ̀ (Element) 14: Silicon  [Si];      Ọmọlẹ̀ (Element) 15: Phosphorus [P];          Ọmọlẹ̀  (Element) 16: Sulfur [S];  Ọmọlẹ̀ (Element) 17: Chlorine [Cl];      Ọmọlẹ̀ (Element) 18: Argon [Ar].

 

Alàyé Sánpọ́n-ná nípa Díẹ̀ lára àwọn Ọ̀mọ̀lé Wọ̀nyí

 

Lithium [Li]: Fàdákà (sílífà) rírọ̀ kan tí ó jẹ́ alùgbinrin (tí ó ń dún bí irin).

 

Carbon [C]: Kẹ́mìka ohun-èdá (substance) kan tí kò díjú tí ó jẹ́ pé ní ògidì rẹ̀, dáyámọ́ǹdì (diamond) ni tàbí gíráfáìtì (graphite)[16].

 

Nitrogen [N]: Gáàsì kan tí kò ní àwọ̀ (clour) tàbí ìtọ́wò (taste). Òun ni ó kó ìdáméjì dín láàádọ̀rin (78%) òfuurufú ó sì wà lára gbogbo ohun tí ó bá wà láàyè.

 

Oxygen [O]: Gáàsì kan tí kò ní àwọ̀ (colour) tí ó jẹ́ pé òun ni ó pọ̀ jù nínú afẹ́fẹ́ inú ayé tí ènìyàn, ẹranko àti ewéko nílò láti wà láàyè.

 

Fluorine [F]: Gáàsì kan tí ó jẹ́ májèlé tí ó ní àwọ̀ òfeefèé tí àwọ̀ òfeefèé náà sì rí fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ (pale yellow).

 

Neon [Neon]: Gáàsì kan tí kò ní àwọ̀ (colour) tàbí ìtọ́wò (taste). Kìí ta ko (react) kẹ́míkà mìíràn. Bí ìṣàn ẹ̀lẹ́ńtíríìkì (electric) bá kọjá lára rẹ̀, ó máa ń mú àwọ̀ pupa tí ó ń dán jáde (it shines red).

 

Sodium [Na]: Kẹ́míkà rírọ̀ kan aláwọ̀ fàdákà tí ó papọ̀ mọ́ funfun (silver-white) tí a máa ń rí nínú iyọ̀.

 

Magnesium [Mg]: Ohun-ẹ̀dá (substance) alùgbinrin (metal) aláwọ̀ fàdákà tí ó papọ̀ mọ́ funfun (silver-white) tí ó máa ń jó dáadáa (it burns very brightly). A máa ń lò ó láti fi ṣe báńgà (fireworks).

 

Aluminium (Bèlẹ̀jẹ́) [Al]: Ohun-ẹ̀dá (substance) kan tí ó jẹ́ alùgbinrin (metal) tí ó ní àwọ̀ fàdákà (silver) tí a maza ń lò, ní pàtàkì, fún nǹkan ìdáná (cooking utensils) tàbí ẹ̀yà ara ẹropíléènì (aircraft).

 

Silicon [Si]: Ohun-ẹ̀dá (substance) aláwọ̀ eérú (grey) tí a máa ń rí ní àdìpọ̀ pẹ̀lú ọọ́síjìn (oxygen) nínú àwọn kùsà (mineral). Silicon wọ́pọ̀. Ó ní àbùdá ẹ̀lẹ́ńtíríìkì tí ó yàtọ̀ lọ́nà tí ó yani lẹ́nu (an unusual electrical characteristics).

 

Phosphorus [P]: Ọ̀mọ̀lé (element) tí ó jẹ́ májèlé (poison) tí ó ní àwọ̀ òfeefèé tí ó papọ̀ mọ́ funfun (yellowish-white) tàbí ní ẹ̀ẹ̀kàndọ́gbọ̀n (rarely), ó máa ń ní àwọ̀ pupa tàbí dúdú ó sì máa ń jó tí ó bá wà nínú afẹ́fẹ́.

 

Silphur Imí ọjọ́ [S]:  Ọ̀mọlẹ̀ (element) aláwọ̀ òfeefèé (yellow) tí ó máa ń wà ní oríṣiríṣi ìrísí àrígbéwọ̀n (physical form). Tí ó bá ń jó, ó máa ń ní àwọ̀ búlúù ó sì máa ń ní òórùn tí ó lágbára. A máa fi ń ṣe oògùn a sì ń lò ó nínú ilé-iṣẹ́ ńláńlá (industry).

 

Chlorine [CL]: Gáàsì aláwọ̀ òfeefèé tí ó papọ̀ mọ́ àwọ̀ ewé (greenish-yellow) tí ó ní òórùn kan tí ó le tí a máa ń fi sí inú omi láti pa  kòkòrò (organism) . Àwọn kòkòrò yìí lè fa àìsàn sí ènìyàn lára.

 

Argon [Ar]: Ọ̀kan nínú àwọn gáàsì tí a máa ń rí nínú afẹ́fẹ́ ni argon. A máa ń lò ó fún ẹ̀lẹ́ńtíríìkì (electric) ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

 

Potassium [K]: Ọmọlẹ̀ (element) aláwọ̀ funfun tí ó papọ̀ mọ́ fàdákà (silvery-white) tí ó jẹ́ pé tí a bá pa á pọ̀ mọ́ ọ̀mọ̀lé (element) mìíràn, a máa ń lò ó láti ṣe ọṣẹ, gíláàsì tàbí ajílẹ̀ (fertilizer = ohun-ẹ̀dá (substance) tí ó ń mú ewéko dàgbà).

 

Calcium [Ca]: Ọ̀mọlẹ̀ (element) kẹ́míkà kan tí ó wà nínú eyín, eegun àti ṣọ́ọ̀kì.

 

Chromium [Cr]: Ọmọlẹ̀ (element) líle aláwọ̀ aró (blue) tí ó dàpọ̀ mọ́ eérú (blue-grey) tí a máa ń papọ̀ mọ́ ohun-ẹ̀dá mìíràn láti fi ṣe ohun ààbò (covering) fún nǹkan (object).

 

Manganese [Mn]:  Ọmọlẹ̀ alùgbinrin (metallic element) aláwọ̀ funfun tí ó papọ mọ́ eérú tí a máa ń lò tí a bá ń ṣe irin (steel).

 

Iron [Fe]: Ọmọlẹ̀  alùgbinrin (metallic element) tí ó wọ́pọ̀. Ó ní àwọ̀ fàdákà (silver). Ó ní òǹfà (it is magnetic). Ó le (it is strong). A máa ń rí i ní ìwọ̀nba (very small amount) nínu ẹ̀jẹ̀. Nínú ẹ̀jẹ̀, ó ti máa ń dàpọ̀ mọ́ kémíkà mìíràn, kìí dá wà.

 

Cobalt [Co]: Alùgbinrin (metal) lílé kan ni cobalt. Àwọ̀ funfun tí ó papọ̀ ṃ́ fàdákà (silvery-whte) ni ó ní. A maza ń dà á pọ̀ (mixture) alùgbinrin (metal) mìíràn láti fi kun nǹkan (material) ní àwọ̀ aró (blue).

 

Copper [Cu]: Oríṣìí alùgbinrin (metal) kan ni copper. Ó ní àwọ̀ pupa tí ó papọ̀ mọ́ àwọ̀ sányán (reddish-brown). A máa ń lò ó láti fi ṣe wáyà tàbí owó.

 

Zinc [Zn] Oríṣìí alùgbinrin (metal) kan ni zinc. Ó ní àwọ̀ aró tí ó papọ̀ mọ́ funfun (bluish-white). A máa fi ń rọ àwọn alùgbinrin (metal) mìíràn tàbi kí a  fi bo àwọn alùgbinrin (metal) mìíràn fún ìdáàbòbò.

 

Ìdánrawò

 

Ìbéèrè

 

Ka àwọn àmì (symbols) wọ̀nyí kí o sì sọ omi ìṣẹ̀dá ọmọlẹ̀ (chemical elements) tí wọ́n dúró fún:

 

(i) K (ii) Cr (iii) Mn (iv) Fe (v) Co (vi) Ni (vii) Cu (viii) Zn (ix) Br (x) Ag.

 

 

Ìdáhùn

 

(i) Potassium (ii) Chromium (iii) Manganese (iv) Iron (v) Cobalt (vi) Nickel (vii) Copper (viii) Zinc (ix) Bromine (x) Silver.

 

 

 



[1] Chemical properties of matter ni a pè ní àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ní.
[2] Physical properties of matter ni a pè ní àbùdá òde tí ẹ̀dá ní.
[3] Melting point ni ọ̀gangan yíyọ́.
[4] Temperature ni a pè ní ìgbóná.
[5] [5] Rust ni a pè ní dípẹtà
[6] Symbol ni a pè ní àmì.
[7] Chemical  ni a pè ní omi ìṣẹ̀dá.
[8] Formula  ni a pè ní ìgbékalẹ̀
[9] Element ni a pè ní ọmọlẹ̀. Element tàbí ọmọlẹ̀ ni àwọn nǹkan bí àazdọ́fà (110) tí ó mọ́, tí ó jẹ́ ògidì, tí ó pé, tí ó ní wóró (atom) irú tirẹ̀ nìkan, tí kò ní àdàlù, tí a kò lè fọ́ sí wẹ́wẹ́ mọ́ tí ó jẹ́ pé ara wọn ni ohun gbogbo tí ó wà láàyè ti wáyé. Bí àpẹẹrẹ, oríṣi ọmọlẹ̀ kan ni bẹ̀lẹ̀jẹ́ (aluminum) jẹ́.
[10] Matter náà ni a pè ní èròjà ẹ̀dá. Èròjà ẹ̀dá ni àwọn ohun-èdá (substance) tí ó wà ní àgbálá ayé (universe).
[11] Chemical ni a ń pè ní omi ìṣẹ̀dá.
[12] Compound ni a maá ń pè ní àdìpọ̀. Ó máa ń ní ju ọmọlẹ̀ kan lọ. Bí àpẹẹrẹ, àdìpọ̀ ni iyọ̀ (salt). Àwọn nǹkan tí ó para pọ̀ di iyọ̀ ni sódíọ̀mù (sodium) àti kilorín-ìn  (chlorine). Sódíọ̀mù ni kẹ́míkà ka tí ó rọ̀ tí ó ní àwọ̀ funfun àti sílífà. Kilorín-ìn ni gáàsì kan aláwọ̀ ewé (green) àti òfeefèé (yellow) tí ó ní òórùn kan tí ó lágbára.
[13] Hydrogen ni gáàsì tí ó fúyẹ́ jù lọ tí kò ní àwọ̀ (clour), tí ó jẹ́ pé bí a tọ́ ọ wò, kò níí jo nǹkan kan lẹ́nu (no taste), tí kò sì ní òórùn (odour) kankan. Hydrogen ni ó máa ń papọ̀ mọ́ oxygen tí ó máa ń di omi.. Gáà sì kan tí kò ní àwọ̀ kankan (colourless) ni oxygen. Òun ni ó pọ̀ jù nínú afẹ́fẹ́ tí ènìyàn ń mí.
[13] Atom ni a ń pè ní wóró. Wóró (atom) ni a lè pè ní kóró (nucleus) oní-ìkókóró (proton) kan àti èrò òjijì (electron) kan.
[14] Helium  ni gáàsì kan tí ó fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ. Kì í jó. Oríṣìí ọmọlẹ̀ (elment) kan ni. A máa ń lò ó nínú bàlúù (balloon) àti oríṣìí àwọn ìmọ́lẹ̀ (light) kan.
[15] List ni a pè ní ìtọ́ka.
[16] Graphite ni oríṣìí kábọ̀ọ̀nu kan tí ó rọ̀ tí ó dúdú tí ó sì ní àwọ̀ eérú (grey) tí a maza ń rí ní àárín pẹ́ńsù (lẹ́ẹ̀dì) tàbí tí a ń lò gẹ́gẹ́ bi nǹkan bí omi (lubricant) tí óń dín ìgbora (ìgbo-ara) kùnínú ẹńjìnnì tí ó sì tún jẹ́ apá kan lára ohun-ẹ̀dá (substance) mìiràn bíi èédú (coal), epo (oil) ó sì tún wà nínú gbogbo ẹranko àti ewéko.

No comments:

Post a Comment