Tuesday, 5 May 2015
Gírámà Gẹ̀ẹ́sì fún Àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (English Grammar for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kẹ́rin (Fourth Lecture)
L.O. Adéwọlé
Nínú idánilẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ta, a mẹ́nu ba àmúpé àbọ̀ (object complement), a ṣe àpẹẹrẹ àwọn bátànì (pattern) àwọn gbólóhùn márààrún a sì ṣe àlàyé gbólóhùn ákítíìfù (active sentence) àti gbólóhùn pásíìfù (passive sentence). Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àrótì (adjuct) ni a ó fi bẹ̀rẹ̀ àláyé wa.
Adjunct (Àrótì)
Gbogbo bátànì (pattern) máràárún tí a ti mẹ́nu bá ṣáájú ni a lè ṣe àfikún sí nípa lílo àrótì (adjunct) mọ́ wọn. Wọfún (optional) ni ìlò àrótì (adjunct (A)) nínú gbólóhùn. Àrótì (adjunct) máa ń ṣe àlàyé síwájú si i nípa gbólóhùn. Bí àpẹẹrẹ, tí a bá mú gbólóhùn S+V (olùwà + ọ̀rọ̀-ìṣe) yìí: Olú laughed (Olú rẹ́rìn-ín), a lè lo àrótì (adjunct) láti ṣe àfikún sí i báyìí:
(48) (a) Olú laughed loudly (Olú rẹ́rìn-ín sókè) (S+V+A) (olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àrótì)
(b) Olú laughed before noon (Olú rẹ́rìn-ín kí aago méjìlà ọ̀sán tóó lù) (S+V+A) (olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àrótì)
(c) Olú laughed at about 11 o’ clock (Olú rẹ́rìn-ín ní nǹkan bí aago mọ́kànlá) (S+V+A) (olùwà+ọ̀rọ̀- ìṣe+àrótì)
Àwọn onímọ̀ gírámà kan lè sọ pé ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ rẹ̀ ni rẹ́rìn-ín (rín ẹ̀rín) (laughed) nínú èdè Yorùbá. A kò jiyàn. Ṣùgbọ́n ohun tí a fẹ́ kí a mọ̀ ni pé ohun tí ó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ yìí ni èdè Gẹ̀ẹ́sì kìí ṣe èdè Yorùbá. Ìyẹn ní pé laugh gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-ìṣe ni ó jẹ́ wá lógún nínú gbólóhùn òkè yìí . Kìí ṣe rẹ́rìn-ín (rín ẹ̀rin) (laugh) gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn bátànì gbólóhùn (sentence pattern) máràárún ni a lè fi àrótì kún. Àwọn àpẹẹrẹ ni ìwọ̀nyí:
(49) (a) Bátànì Kìíní (Pattern 1): S+V+O (Oluwà+Ọ̀rọ̀-ìṣe+Àrótì)
Olú laughed at about 9 a.m. (Olú rẹ́rìn-ín ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án)
(b) Bátànì Kejì (Pattern 2): S+V+SC+A (Oluwà+Ọ̀rọ̀-ìṣe+Àmúpé olùwá+Àrótì)
Òjó is fighting as usual (Òjó (tún) ń jà bí ó ṣe má a ń ṣe)
(c) Bátànì Kẹ́ta (Pattern 3): S+V+DO+A (Oluwà+Ọ̀rọ̀-ìṣe+Àbọ̀ tààrà+Àrótì)
The soldiers destroyed the village yesterday (Àwọn sójà ba abúlé náà jẹ́ ní àná)
(d) Bátànì Kẹ́rin (Pattern 4): S+V+IO+DO+A (Oluwà+Ọ̀rọ̀-ìṣe+Àbọ̀ ẹ̀bùrú+Àbọ̀ tààrà+Àrótì)
We gave Olú the prize yesterday (A fún Olú ní ẹ̀bùn náà ní àná)
(e) Bátànì Kárùn-ún (Pattern 5): S+V+DO+OC+A (Oluwà+Ọ̀rọ̀-ìṣe+Àbọ̀ tààrà+Àmúpé àbọ̀+Àrótì)
The dye turned the water black in three minutes (Dáì náà sọ omi náà di pupa ní ìsẹ́jú méta)
Àrótì (adjunct) tún lè wáyé ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ gbólóhùn ṣáájú olùwà:
(50) Suddenly, the sky darkened (Lojijì, ojú ọjọ́ dúdú) (A+S+V (àrótì+olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe))
A tilẹ̀ lè rí ju àrótì kan lọ nínú gbólóhùn abọ́dé (simple sentence) kan.
(51) (a) At about 9 o’clock, the sky darkened suddenly (Ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án,ojú ọjọ́ dúdú lójijì) (A+S+V+A (àrótì+olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àrótì))
(b) On Sunday, at about 9o’clock, we met Olú outside the school (Ní ọjọ́ ìsinmi, ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án, a pàdé Olú ní iwájú ilé-ẹ̀kọ́ (A+A+S+V+DO+A (àrótì+àrótì+olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àbọ̀ tààrà+àrótì))
Olùwà (subject), ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) àti àbọ̀ (object) kò gbọdọ̀ ju ẹyọ kọ̀ọ̀kan lọ nínú gbólóhùn abọ́dé (simple sentence) kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn ni pé gbólóhùn abọ́dé (simple sentence) kan kò gbọdọ̀ ní ju olùwà (subject) kan, kò gbọdọ̀ ní ju ọ̀rọ̀-ìsẹ (verb) kan bẹ́ẹ́ ni, kò sì gbọdọ̀ ní ju àbọ̀ (object) kan lọ.
The Meanings of Adjuncts (Àwọn Ìtumọ̀ tí Àrótì máa ń Ní)
Oríṣiríṣi ìtumọ̀ ni àrótì (adjunct) máa ń fi kún gbólóhùn (sentence). Díẹ̀ nínú wọn ni:
Time (when something happens) (Ìgbà (àkókò tí nǹkan ṣẹlẹ̀))
(52) (a) They danced yesterday (Wọ́n jó ní àná)
(b) They arrives at seven o’clock (Wọ́n dé ní aago méje)
(c) We visit Ìbàdàn every year (A máa ń lọ sí Ìbàdàn ní ọdọọdún)
Place (where something happens) (Ibìkan (ibi tí nǹkan ti ṣẹlẹ̀))
(53) (a) Olú attended university in Ilé-Ifẹ̀ (Olú lọ sí yunifásítì ní ilé-Ifẹ̀)
(b) We met outside the school (A pàdé ní iwájú ilé-ẹ̀kọ́ náà)
(c) I saw Òjó at the market (Mo rí Òjó ní ọjà)
Manner (how something happens) (Ọ̀nà (bí nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀))
(54) (a) Gradually, the room filled with smoke (Díẹ̀díẹ̀, èéfín kún inú ilé náà)
(b) The children behaved very well (Àwọn ọmọ náà hùwà dáadáa)
(c) He walks sluggishly (O ń rìn tìkọ̀tị̀kọ̀)
Vocatives ((Ọ̀rọ̀-orúkọ) Àkésí)
(Ọ̀rọ̀-orúkọ) àkésí (vocative) ni a fi ń ṣe ìdámọ̀ ẹni tí gbólóhùn ń sọ̀rọ̀ sí.
(55) (a) Olú, your food is ready (Olú, oúnjẹ rẹ ti ṣe tán (Oúnjẹ náà ti wà nílẹ́))
(b) Come inside, children (Ẹ wọlé, ẹ̀yin ọmọdé)
(c) Doctor, this boy is ill (Dókítà, ara ọmọ yìí kò yá)
(d) The book was on the table, my Honour (Orí tábìlì ni ìwé náà wà, Olúwa mi)
(e) Goodbye, everyone – I‘ll see you tomorrow (Ó dìgbà, gbogbo ènìyàn – màá ríi yín lọ́la)
(f) Ladies and gentlemen, thank you for the gift (Lọ́kùnrin lóbìnrin, ẹ ṣé fún ẹ̀bùn tí ẹ fún mi)
Nínú ìhun gbólóhùn (sentence structure), (ọ̀rọ̀-orúkọ) àkésí kò pọn dandan (it is optional). Ó fi èyí jọ àrótì (adjunct).
Sentence Types (Ẹ̀yà Gbólóhùn)
Oríṣìí ẹ̀yà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbólóhùn ní tí a bá fi ojú ìlò (function/use) wò ó. Gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) wa. Gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence)wà. Gbólóhùn àṣẹ (imperative sentence) wa gbólóhùn ìyanu (exclamative sentence) náà sì wa.
Declarative Sentence (Gbólóhùn Àlàyé)
Gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) ni a fi maa ń ṣe ìròyìn. Òhun ni a fi máa ń ṣe àwíyé. Àwọn àpẹẹrẹ ni:
(56) (a) Òjó is playing football (Òjó ń gbá bọ́ọ̀lù)
(b) I went to the market (Mo lọ sí ọjà)
(c) Olú bought a new car (Olú ra ọkọ̀ tuntun)
(d) Délé retired last year (Délé fẹ̀yìn tì ní ọdún tí ó kọjá)
Nínú gbólóhùn àlàyé (declarative sentence), olùwa (subject) ni ó máa ń kọ́kọ́ ṣaájú, ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) ni ó sì máa ń tẹ̀ lé e. Gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) ni a máa ń lò jù, nínú gbogbo awọn oríṣìí gbólóhùn, tí a bá ń sọ̀rọ̀ (iyẹn tí a bá fi ojú ìlò (function/use) wò àwọn gbólóhùn wọ̀nyí).
Interrogative Sentence (Gbólóhùn Ìbéèrè)
Gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence) ni a máa ń lò tí a bá fẹ́ bèèrè ìbéèrè tàbí tí a bá fẹ́ kí ẹni kan ṣàlàyé nǹkan kan fún wa. Àwọn àpẹẹrẹ ni:
(57) (a) Is this the market? (Ṣé ọjà nì yí?)
(b) Have you eaten? (Ǹjẹ́ o ti jẹun?)
(c) Did you receive the money? (Ǹjẹ́ o rí owó náà gbà?)
(d) Do you play football? (Ṣé o máa ń gbá bọ́ọ̀lù?)
Àwọn ìbéèrè tí ó wà ní (57) ni a ń pè ni yes-no question (ìbéèrè oní-bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́). Ìdí tí a fi ń pè é báyìí ni pé èsì tí a ń retí ni yes or no (bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́).
Alternative interrogative (ìbéèrè apààrọ) máa ń fún wa láyè láti mú ọ̀kan lára ìdáhùn tí ó ju ẹyọ kan lọ. Àwọn àpẹẹrẹ ni:
(58) (a) Do you want tea or coffee? (Ṣé kọfí ni ó ń fẹ́ tàbí tíì?)
(a) Is he a driver or a tailor (Ṣé awakọ̀ ni tàbí aránṣọ?)
Wh-interrrogatives (Ìbéèrè oní-ni): Àwọn ìbéèrè oní-ni (wh-interrogative) ni àwọn ìbéèrè tí ó máa ń ní wh nínú ṣùgbọ́n tí a bá túmọ̀ wọn sí èdè Yorùbá, ni máa ń wà nínú irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ ni:
(59) (a) What happened (Ki ni ó ṣẹlẹ̀?)
(b) Where do you work? (Níbo ni o ti ń ṣiṣẹ́?)
(c) Who bought that book? (Ta ni ó ra ìwé yẹn?)
Dípò what, where àti who, a tún máa ń lo how nínú ìbéèrè oní-ni (wh-interrogative):
(60) (a) How do I get to Ibàdàn from here (Báwo ni a ṣe lè dé Ìbàdàn láti ibí?)
(b) How do you plan to spend your holiday? (Báwo ni mo ṣe fẹ́ lo ìsinmi rẹ?)
(c) How old is Olú? (Ọmọ ọdún mélòó ni Olú?)
No comments:
Post a Comment