Kí ni Àtamọ́?
Nínú iṣẹ́ yìí, ọ̀rọ̀ nípa
àtamọ́ ni a fẹ́ mẹ́nu bà. Klavan (1980: 65) sọ pé àtamọ́ ni àwọn
fọ́nrán kan tí ó jẹ́ pé nínú ẹ̀ka fonọ́lọ́jì, wọ́n máa ń bá
àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣe pọ̀ ṣùgbọ́n wọn lè máà bá wọn ṣe pọ̀ nínú
ẹ̀ka mọfọ́lọ́jì. Bí wọ́n bá sì bá àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe pọ̀
nínú ẹ̀ka mọfọ́lọ́jì, wọ́n lè máà bá wọn ṣe pọ̀ nínú ẹ̀ka
fonọ́lọ́jì. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn fọ́nrán yìí kìí ṣe àfòmọ́
ìṣẹ̀dá tàbí ti ìlò. Èyí fi hàn pé wọ́n ní àbùdá ọ̀rọ̀ wọ́n
sì tún ni àbùdá àfòmọ́.
Arọ́pò-Orúkọ
Oyelaran (1987) àti Pulleyblank (1986)
gbà pé oríṣi àtamọ́ kan ni arọ́pò-orúkọ[1].
Tí a bá wo gbólóhùn (1), bí àpẹẹrẹ,
(1a)
Olú rí i
(1b)
Olú rí mi, Ó pè mí
tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó,
AR inú rẹ̀ ní nǹkan-an ṣe pèlú fáwẹ́lì ọ̀rò-ìṣe[2]
tí ó tẹ̀ lé. Èyi fi hàn pé a kò lè fi gbogbo ara pè é ní ọ̀rọ̀.
Tí a bá fi ojú mọfọ́lọ́jì wò ó, a ó rí i pé kì í ṣe àfòmọ́,
yálà ti ìlò tàbí ti ìṣẹ̀dá[3]
nítorí pé a kò lò ó láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun lára IṢ tí ó tẹ̀
lé.
Kì í ṣe pé torí pé AR yìí tẹ̀
lé IṢ ni ó jẹ́ kí ohun tí ó ṣẹ̀lẹ̀ sí i ṣẹ̀lẹ̀ o. Gẹ́gẹ́ bí
Oyelaran (1987) ti ṣe àkíyèsí, nínú àwọn ẹ̀ka-èdè kan, IṢ ni o
máa ń sọ irú fáwẹ́lì tí AR tí ó jẹ́ olùwà rẹ̀ máa ní. Ẹ wo
gbólóhùn (2-5):
(2) Mo mí
jó
(3) Mọ mí lọ
(4) Mo
ṣé
(5) Mọ
gbà
Nínú ẹ́ka-èdè yìí, a ó ṣe
àkíyèsí pé ìbáṣepọ̀ wa láàrin fáwẹ́lì IṢ àti AR tí a bá fi
ojú fonọ́lọ́jì wò ó. Nínú gbólóhùn (2-5), àjọṣepọ̀ àǹkóò
fáwélì wà láàrin fáwẹ́lì AR àti IṢ[4].
Pẹ̀lú àlàyé wọ̀nyí, ó tọ̀nà láti pe AR ní àtamọ́.
Sílébù
Olóhùn Òkè
Sílébù olóhùn òkè[5] ni
wúnrẹn mìíràn tí a ó tùn yẹ̀ wò. Àbá méjì ni a ó yẹ̀ wò lórí
SOO yìí. Bamgboṣe (1980) sọ pé SOO kò ní nǹkan kan-an ṣe pẹ̀lú
àpólà ìṣe[6]
nínú gbólóhùn. Ó ní òpin àpólà orúkọ[7] ni
ó máa ń fi hàn. Iyẹn ni pé, ní (6-7), ohun tí SOO ń ṣe ni pé ó ya
ibi tí APOR ti parí sọ́tọ̀ sí ibi tí APIṢ ti bẹ̀rẹ̀.
(6) Òjò ó rọ̀
(7) Àwọn
túlẹ̀ ẹ́ gba ìsinmi
Tí a bá wo (6) àti (7) dáadáa, a ó
rí i pé ohun tí alàyé Bamgboṣe (1980) ń fi yé wa ni pé, lóòótọ́,
SOO kò ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun láti ara òjò
tàbí àwọn túlẹ̀, síbẹ̀, APOR wọ̀nyí ni SOO ń bá ṣiṣẹ́ ó sì tún
ní nǹkan-an ṣe pẹ̀lu fáwẹ́lì tí
ó gbẹ̀yìn APOR yìí tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó. Lójú
Awobuluyi (1975), atọ́ka afànámónìí ni SOO. Tí a bá fi ojú eléyìí
wò ó, APIṢ tàbí gbólóhùn ni SOO ń bá ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tí a bá fi
ojú fonọ́lọ́jì wò ó, fáwẹ́lì tí ó gbẹ̀yìn APOR ni ó máa ń ràn
mọ́.
Aṣáájú
Ọ̀rọ̀-ìṣe Ọbọ̀rọ́
Nínú Bámgbóṣé (1990: 145), díẹ̀
nínú àwọn gbólóhùn tí ó sọ pé ó ní atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe
ọ̀bọ̀rọ́ nínú ni:
(8a) Ó fẹ́ẹ́ lọ
(b) Ó bẹ̀rẹ̀
sí í máa kọrin
(d) Omi náà
tóó mu
Nínú àwọn àpẹẹrẹ (8a-d), àwọn
atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ ni ẹ́,
í àti ó tí a kọ yàtọ̀ yẹn.
Bámgbóṣé (1990: 144) sọ pé í
ni ìpìlẹ̀ atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́. Àrànmọ́ ni ó sọ í yì di ẹ́ àti ó ní (8a àti
d).
Atọ́ka
Àpólà Orúkọ Oníbáàtan
Lójú Bamgbose (1990: 119), atọ́ka
yìí ni ó máa ń wà láàrin OR tí ó bá ń yán OR. Ó pè é ní ẹ̀hun
oníbàátan. Ó máa ń wáyé, ní pàtàkì, tí kọ́ńsónáǹtì bá
bẹ̀rẹ̀ ẹ̀yán ajórúkọ, bí àpẹẹrẹ, ‘tiwa’ nínú
(9) Owóo tiwa
A ó ṣe àkíyèsí pé o tí ó dúdú jù lara ‘Owóo tiwa’ kò sí lára ‘owó’ tàbí
‘tiwa’ ní ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ rèé, ó ràn mọ́ ‘owó’ láìjẹ́ pé ó
ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun lára rẹ̀. Gbogbo àkíyèsí yìí ni ó bá oríkì
àtamọ́ tí Klavan (1980: 65) fi lélẹ̀ mu.
Alàyé
Atàmọ́
Tí a bá fẹ́ ṣe àláyé àtamọ́,
àwọn ohun márùn-ún ọ̀tọ̀tọ̀ ni a gbọ́dọ̀ ṣe àkíyèsí[8].
Lọ́nà kìíní, a gbọ́dọ̀ lè ṣe àlàyé orúkọ tí irú àtamọ́
bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ (clitic identity). A ó máa pe èyí ní P1. Èkejì ni
ẹ̀wọ́n tí ó gàba lé irú àtamọ́
bẹ́ẹ̀ lórí (domain of cliticization). A o má ape èyí ni P2. Ẹkẹ́ta ni
àpólà tàbí ọ̀rọ̀ tí o gba irú àtamọ́ bẹ́ẹ̀ lálejò bóyá ìró
ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀[9]
bẹ́ẹ̀ ni o tàbí ìró tí ó wà ní ìparí (initial/final). A ó máa pe
eléyìí ni P3. Ẹ̀kẹ́rin ni pé ọ̀rọ̀ tàbí àpólà tí ó gba àtamọ́
yìí ní àlejò, ṣé iwájú àtamọ́ yìí ni ó wà ni tàbí ẹ̀yìn rẹ̀
(before/after)? A ó pe eléyìí ni P4. Ẹkarùn-ún, tí ó jẹ́ ìparí, ni
pé ṣé àtamọ́wájú ni àtamọ́ yìí ni tàbí àtamẹ́yìn
(proclitic/enclitic). Eléyìí ni a pè ní P5.
Tí a bá fi ojú àlàyé tí a ṣe
yìí wo AR, àláyé wa yóò lọ báyìí:
(10) Àtamọ́ Arọ́pò orúkọ
P1: AR
P2: AṢ[10].
P3: ìparí[11]/-
P4: iwájú àti
ẹ̀yìn[12]
P5:
àtamọ́wájú àti àtamẹ́yìn[13]
Ni (3), AR ni ‘mọ’(P1), oríṣi
aṣàfihàn (P2) kan ni. Òpin (P3) ni àtamọ́ tí ó ṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹ̀ sí i
nínú ‘mọ mí lọ’. Ẹ̀yìn (P4)
ni fọ́nrán tí ó fa àtamọ́ wa ní (3) nítorí ìdí èyí, àtamọwájú
(P5) ni. Tí a bá wá wo (1a) níbi tí a ti
rí ‘Olú rí i’, àlàyé tí
rí ṣe ni pé AR ni ‘i’ (P1)
oríṣi aṣàfihàn (P2) kan ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ bóyá
ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí i nítorí
ọ̀rọ̀ oníròó kan ni i ṣùgbọ́n tí a bá wo (1b), a ó
rí i pé òpin ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí mi/mí nítorí pé ohùn orí IṢ
onísílébù kan ni ó máa ń sọ irú ohùn tí AR tí ó jẹ́ àbọ̀ fún
un máa ní. Òpin AR (1b) yìí sì ni àyípadà ohùn yìí ti ṣẹlẹ̀ tí
a fi rí mi tí ó ní ohùn àárin
àti mí tí ó ní ohùn òkè
nítorí IṢ tí ó ṣaájú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ni (P4), iwájú ni ohùn tí
ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àtamẹ́yìn ni àrànmọ́
tí ó ṣẹlẹ̀.
(11) Atamọ́ Oníbàátan
P1: atọ́ka
oníbàátan
P2:
AṢ
P3: -
P4: iwáju
P5: àtamẹ́yìn[14]
Ohun tí (11) ń ṣe àlàyé ni pé P1
sọ pé àtamọ́ oníbàátan ni
àtamọ́ yìí. P2 sọ pé aṣàfihàn ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ bóyá
ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí àtamọ́ yìí ti
ṣẹlẹ̀ sí i nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni atọ́ka rẹ̀, ọ[15].
Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní
(P5), àranmẹ́yìn ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀.
(12) Àtamọ́ SOO
P1: SOO
P2: WỌ
P3: -
P4: iwájú
P5:
àr̀anmẹ́yìn
Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní (12) fara
jọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni (11). P1 sọ pé àtamọ́ SOO ni àtamọ́ yìí. P2 sọ pé aṣèrànwọ́
ìṣe[16]
ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ bóyá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àrànmọ́
tí ó ṣẹlẹ̀ sí àtamọ́ yìí ti ṣẹlẹ̀ sí i nítorí ọ̀rọ̀ oníròó
kan ni atọ́ka rẹ̀, bí àpẹẹrẹ ó tí
ó dúdú jù nínú ‘Òjò ó rọ̀. Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa
àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àranmẹ́yìn ni àrànmọ́ tí
ó ṣẹlẹ̀.
(13) Atamọ́ àpólà ìṣe ọ̀bọ̀rọ́
P1: atọ́ka
àpólà ìṣe ọ̀bọ́rọ́
P2: AF[17]
P3: -
P4: iwájú
P5: àtamẹ́yìn[18]
P1 sọ pé àtamọ́ àpólà ìṣe
ọ̀bọ́rọ́ ni àtamọ́ yìí. P2 sọ
pé oríṣìí àfòmọ́ kan ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ bóyá
ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí àtamọ́ yìí ti
ṣẹlẹ̀ sí i nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni atọ́ka rẹ̀. Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa
àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àranmẹ́yìn ni àrànmọ́ tí
ó ṣẹlẹ̀[19].
Àbùdá
Ọ̀rọ̀ àti Àpínpẹ̀kun
Kí àlàyé wa lórí àtamọ́ lè kún tó bí ó
tri yẹ, a nílò láti wo àbá tí Cann (1984) dá lórí abùdá ọ̀rọ̀
àti àpínpẹ̀kun[20].
Lójú Cann (1984), a lè pín ìsọ̀ri sí oríṣi mẹ́rin. Èkíní ni
ìsọrí tí ó jẹ àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́ àpólà. A ó má ape
eléyìí ní APX[21].
Èkejì ni ìsọ̀rí tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kì í sì i ṣe àpólà;
ìyẹn ni pé ó ju ọ̀rọ̀ lọ kò sì tó àpólà. Ìsọrí yìí kìí ṣe
àpínpẹ̀kun, kìí ṣe ọ̀rọ̀ kì í sì i ṣe àpólà. A ó má a pe
eléyìí ní XB. Ìkẹ́ta ni ìsọ̀rí tí kìí ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì
jẹ́ ọ̀rọ̀. A ó pe èyí ní XD. Ìkẹ́rin ni ìsọ̀rí tí ó jẹ́
àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́ ọ̀rọ̀. Eléyìí ni XC. Bí àwọn ìpín
mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe rí nì yí:
(14) (i) {<APÍNPẸ̀KUN, +> <WÚNRẸN,
->} APX (ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun ṣùgbọ́n tí kìí ṣe
wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘bàtà Olú’).
(ii) {<APÍNPẸ̀KUN, -> < WÚNRẸN, ->}
XB (ìsọ̀rí tí kì i ṣe
àpínpẹ̀kun tí kìí ṣe wúnrẹ̀n
kan soso, b.a. ‘e Déle’ nínú ‘Ilée Délé’).
(iii) {<APÍNPẸ̀KUN, -> < WÚNRẸN, +>}
XD (ìsọ̀rí tí kì i ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ wúnrẹ̀n kan soso,
b.a. ‘Dele’ nínú ‘Ilée Délé’).
(iv) {<APÍNPẸ̀KUN, +> < WÚNRẸN, +>}
XC (ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘Olú’ nínú ‘Olú
lọ’).
Yàtọ̀ sí òfin ìsọ̀rí, Cann (1984) tún dábàá òfin fún àwọn ọ̀rọ̀. Òfin
yìí ni ó wà ní (15):
(15) (i) [+Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni ọ̀rọ̀
tí a kò ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘lọ’) [+Ọ, +I][22]
(ii) [-Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni àfòmọ́, bí
àpẹẹrẹ, ‘i’ nínú ‘ijó’) [-Ọ, -I]
[+Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni ọ̀rọ̀ tí a
ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘ijó’) [+Ọ, -I]
[-Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni àtamọ́, bí
àpẹẹre, SOO) [-Ọ, +I]
Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àlàyé oríkì
ìsọrí àti òfin ọ̀rọ̀ tán, a lè wá wo bí wọn ṣe ń jẹ yọ lórí
àkámọ́ aṣàmìsí.
(16) Olú fẹ́ẹ́
lọ (Olu wants to go)
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] fẹ́ =[23] [IṢB[IṢD[-Ọ,
+I] ẹ́ [IṢD[+Ọ, +I] lọ]]]]]
Àwọn onígírámà kan gbà pé fẹ́
í lọ ni ìpìlẹ̀ àpólà yìí ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí
àrànmọ́ ti lè wáyé láàrin fáwẹ̀lì fẹ́ àti í láti fún
wa ní fẹ́ẹ́ lọ, a kò jayò pa
tí a bá sọ pé í yìí
rọ̀gbọ̀kú lé fẹ́ lórí. Lójú
àwọn onígírámà mìíràn, ìtumọ̀ kan náà ni Olú fẹ́ẹ́ lọ àti Olú
fẹ́ ní àtilọ ní. Ohun tí a rí sọ sí èyí ni pé ìtùmọ̀ wọn ni
ó bára mu, ìhun wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Ọ̀rọ̀-atọ́kùn ni ní tí ó wà nínú ní àtilọ nígbà ti àtilọ jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Bí àkámọ́ aṣàmìsí
fún fẹ́ láti lọ (fẹ́ ní àtilọ)
yóò ṣe rí ni[24]
(17). Àwọn àkámọ́ aṣàmìsí tẹ̀lé àwọn gbólóhùn yòókù.
(17) Olú fẹ́
ní àtilọ (Olú wants to go)
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] fẹ́][ATX[ATD[+Ọ,
+I] ní][ASC[+Ọ, -I] àtilọ]]]
(18) Mo rí
Olú (I saw Olú)
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] rí[AṢC[+Ọ,
+I] Olú]]]
(19) Mo rí i (I saw him)
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I]rí = [AṢC[-Ọ,
+I] i]]]
(20) Aṣọọ
Délé (Délé’s clothes)
[AṢD[AṢD[+Ọ, +I] Aṣọ = [ASB[AṢD[+Ọ,
+I] ọ[AṢD[+O, +I]]]]]
Àwọn onígírámà kan gbà pé Aṣọ Idélé ni ìpìlẹ̀ àpólà
yìí yàtọ̀ sí Aṣọ i Délé tí
àwọn tí ó gba i yìí gẹ́gẹ́
bí atọ́ka oníbàátan ṣe máa ń sọ. Lójú àwọn onígírámà tí o gba
Aṣọ Idélé ní ìpìlẹ̀ Aṣọọ Délé, gbogbo OR Yorùbá ni
fáwẹ̀lì bèrẹ̀ àti pé orúkọ tí a ń pè ni Délé nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, Idélé ni wọ́n máa ń pè é nínú àwọn èka-èdè Èkìtì
kan. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àkámọ́ aṣàmìsí tí ó wà
fún Aṣọọ Délé(Aṣọ Idélé) ni
(21):
(21) Aṣọ
Idélé (Délé’s clothes)
[AṢX[AṢD[+Ọ, +I] Aṣọ
[AṢC[+Ọ, +I] Idélé]]]]
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, nínú gbólóhùn Òjòó rọ̀, lójú àwọn
onígírámà kan, iṣẹ́ sílébù olóhùn òkè yìí ni láti jẹ́ atọ́ka
fún oríṣìí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Àwọn kan sọ pé oríṣìí àsìkò
kan ni ó jẹ́ atọ́ka fún nígbà tí àwọn kan sọ pé iṣẹ́ atọ́ka
ìbámu ni ó ń ṣe. Iṣẹ́ yòówù tí ó ń ṣe, ó yìí rọ̀gbọ̀kú lé Òjò
tí ó ṣaájú rẹ̀ púpọ̀. Bí wọn kò tilẹ̀ jọ sí nínú ìsọ̀rí kan náà, bí ìpìlẹ̀ SOO
yìí bá jẹ́ í, gẹ́gẹ́ bí
àwọn onígírámà kan ti sọ, láàrin í
yìí àti ò tí ó gbẹ̀yìn òjò ni àrànmọ́ ti ṣẹlẹ̀.
Nítorí ìdí èyí, àkámọ́ aṣ̀mìsí tí a ó lò fún Òjòó rọ̀ ni (22):
(22) Òjòó
rọ̀ (It rained)
[AFX[AṢD[+ọ, +I] Òjò] = [AFB[AFD[-Ọ,
+I] ó]][IṢD[+Ọ +I] rọ̀]]
Ìgúnlẹ̀
Nínú iṣẹ́ yìi láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà
láàrin àpólà, ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀, ọ̀rọ tí a ṣẹ̀dá,
fọ́nrán tí ó ju ọ̀rọ̀ lọ ṣùgbọ́n tí kò tó àpólà, àfòmọ́
ìṣẹ́dá àti atamọ́ hàn kedere. Yàtọ̀ sí èyí, àtúpalẹ̀ tí a ṣe
nínú iṣẹ́ yìí kò fi àyè gba pele bíi ti inú síńtáàsì onípele.
Pele nínú síńtáàsì onípele máa ń dá wàhálà sílẹ̀ nígbà
mìíràn nítorí àyọtúnyọ pele. Ohun tí a ní lọ́kàn ni pé, lẹ́yìn
pele méjì (XII) tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun, a lè rí àyọtúnyọ
pele kan (XI) kí ó tó wá kan pele òfo (X0). Kò sí
àyọtúnyọ yìí nínú ìlànà aláìnípele tí a mú lò nínú iṣẹ́
yìí.
Àkójọpọ̀
Orúkọ Ìwé
Adewole (1986), ‘the Yoruba High Tone Revisited’, Work in Progress 19: 81-94. Edinburgh:
Departmenent of Linguistics, University of Edinburgh.
Adewole, L.O. (1988), ‘the categorical Status and the
Functions of the Yoruba Auxiliary Verbs with Some Structural Analyses in
GPSG.’, PhD Dissertation, University of Edinburgh.
Adewole, L.O. (1998), ‘Another Visit to the Yoruba
High Tone Syllable’, AAP 53: 91-106.
Awobuluyi, O. (1975), ‘On “the Subject Concord
Prefix” in Yoruba’, Studies in African
Linguistics 6, 1: 215-238.
Awobuluyi, O. (2013), Ẹ̀kọ́ Gírámá Èdè Yorùbá. Osogbo: Atman Limited.
Bamgbose, A. (1966), A Grammar of Yoruba. Ibadan: OUP.
Bamgbose, A. (1980), ‘Pronouns, Concord,
Pronominalization’, Afrika und Ubersee
LXIII: 189-198.
Bamgbose, A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: UPL
Cann, R. (1984), ‘Heads without Bars: A Theory of
Phrase Structure’, An Unpublished Paper.
Cann, R. (1986), ‘The Structure of Words’, Work in Progress 19: 107-121.
Eddinburgh: Department of Linguistics, University of Edinburgh.
Klavan, Judith L. (1980), ‘Approaches to a Universal
Theory of Clitics.’, PhD Dissertation, University of London.
Owolabi, D.K.O. (1976), ‘Noun-Noun Construction in
Yoruba: A Syntactic and semantic Analysis.’, PhD Dissertation, University of Ibadan,
Ibadan, Nigeria.
Oyelaran, O.O. (1987) ‘Ọ̀nà Kan Ò Wọjà:
Mọfọ́lọ́jì Yorùbá’, Yoruba 1:
25-44.
Oyelaran, O.O. (1992), ‘The Category AUX in the
Yoruba Phrase Structure’, research in
Yoruba Language and Literature 3: 59-86.
Pulleyblank, D. (1986), ‘Clitics in Yoruba’, Syntax and Semantics9: 43-64. New York:
Academic Press.
[1] Wo Awobuluyi
(2008:206) fún ìdí tí a fi lo arọ́pò-orúkọ dípò ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ.
AR ni a ó máa lò fún arọ́pò-orúkọ láti ìsìnyí lọ.
[2] IṢ láti
ìsìnyi lọ.
[3] Afòmọ́
ìṣẹ̀dá ni ‘i’ nínú ‘ijó’ nítorí pé a lò ó láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀
tuntun láti ara ‘jó’ ni. Àfòmọ́ ìlò ni ‘s’ ara ‘books’ nítorí pé
‘book’ tí a ṣẹ̀dá rẹ̀ lára rẹ̀ fi ìlò yàtọ̀ sí i.
[4] Wo Adewole
(1996 àti 2011) fún àlayé kíkún lórí àǹkóò fáwẹ́lì yìí.
[5] SOO láti
ìsìnyí lọ.
[6] APIṢ láti
ìsìnyí lọ.
[7] APOR láti
ìsìnyí lọ.
[8] Wo Klavan
(1980: 126) fún ẹ̀kúnṛẹ́rẹ́ àlàyé.
[9] tàbí àpólà
[10] Nínú
gírámà ‘Minimalist’, oríṣìí aṣàfihàn (determiner) kan ni wọ́n ka AR
si. Aṣàfihàn ni a gé kúrú sí AṢ.
[11] Tí a bá wo Mo lọ olóri ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí ó
di Mọ lọ nínú àwọn èka-èdè
kan, a ó rí i pé òpin mo tí ó
di mo ni àyípadà ti wáyé. Èyí
ni a lo ìparí fùn. Ṣùgbọ́n tí a bá AR inú Mo rí I, ìró kan ni AR yìí. A kò
lè sọ̀rọ̀ nípa iwájú tàbi ẹ̀yìn. Èyí ni a lo ‘-‘ fún. Àkíyèsí
kejì yìí ni a ó lò fún àwọn àtamọ́ yòókù nítorí ìró kọ̀ọ̀kan
ni wọ́n.
[12]
Àrànmọ́wájú ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mọ lọ. Àrànmẹ́yìn ni ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mo rí i.
[13] Atamọ́wájú
ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mọ
lọ. Àtamẹ́yìn ni ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mo rí i.
[14] Àtamọ́
oníbàátan ni ọ tí ó dúdú jù
nínú ‘Aṣọ ọ Délé’
[15] Wo ìtọsẹ
ọ̀rọ̀ (14).
[16] Aṣèrànwọ́
ìṣe ni a ń pè ní àfòmọ́ nínú gírámà ‘GB’ àti ‘Minimalist’.
Àfòmọ́ yìí ni orí fún àpólà àfòmọ́.
[17] Nínú
gírámà ‘GB’ àti ‘Minimalist’, oríṣìí àfòmọ́ kan ni atọ́ka
ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ tí àwọn onígíràmà kan máa ń pè ní atọ́ka
ìn-ìnfínítíìfù (infinitive).
[18] Atọ́ka
àpólà ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ ni ẹ́
àti ọ́ tí ó dúdú jù nínú
gbólóhùn wọ̀nyí: ‘Ó fẹ́ẹ́
lọ’ àti ‘Ó mọ ọkọ̀ọ́ wà’.
[19] Àlàyé lórí
àtamọ́ ju eléyìí tí a ṣ yìí lọ o ṣùgbọ́ ìwọ̀nba àlàyé tí
yóò jẹ wá lógún nípa àtamọ́ nínú iṣẹ́ yìí nì yí. Fún
ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa àtamọ́ inú èdè Yorùbá, wo Adewle (1998).
[20] Can 91984) pe
eléyìí ní ‘lexical and maximal features’.
[21] ‘X’ dúró fún
ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, bí àpẹẹrẹ, OR, IṢ, àbbl.
[22] ‘I’ ni ó
dúró fún ‘ìpìlẹ̀’, ‘Ọ’ sì dúró
fún ‘ọ̀rọ̀’.
[23] Àmì yìí,
‘=’, duzró fún pé ọ̀rọ̀ tí ó ṣáájú, bí àpẹẹrẹ, ‘fẹ́’ nínú
àpẹẹrẹ yìí, ni àtamọ́ yìí gbára lé. Irú iṣ́ yìí ni ‘=’ ń ṣe
nínú àwọn àpẹẹrẹ yòó kù.
[24] Ẹ fi (i) Olú fẹ́ láti lọ/Olúfẹ́ẹ́ lọ wé
(ii) Olú gbọ́dò lọ/Ópọn dandan kí Olú lọ. Bí ìhun gbólóhùn tí ó
wà ní (i) ṣe yàtọ̀ sí ara wọn tí ìtumọ̀ wọn sì bára mu ni ìhun
àwọn gbólóhùn tí ó wà ní (ii) náà ṣe yàtọ̀ sí ara wọn tí
ìtumọ̀ wọn sì jọra. Èyí fi hàn wí pé ìhun gbóllohùn lè yàtọ̀
sí ara kí ìtumọ̀ wọn bára mu.
No comments:
Post a Comment