Òkè-Àgó: Gégé bí
ìwádìí tí mo se, àdúgbò yìí ni àwon tí ó kókó tèdó sí ìlú yìí dé sí. Láyé ìgbà
náà, kò ì tí ì sí ilé-búlókù, àgó ni wón
ma ń pa, ibi tí wón rook pàgó sí ni wón wó ń pè ní òkè-àgó ní oorí pé, ó bó sí
ibi tí òké wà.
Ilé-Ita: Gégé bí ìtàn se so, ní orí ilè yí nì àwon
ará ìlú pàápàá jùlo àwon àgbàgbà lókìnrin
ti ma ń ta ayò bí wón bá ti took dé láyé ìgbà náà. Ilè-ìtayò nì wón ń
kókó pè é kó tó di wí pé, wón kó ilé síbè gan-gan. Ilè-ìtayò ni ó wá yí padà sí
ilé-ìtayò, ìgbà tí ó yá, wón so ó di ilé-ita. Eyí ni, ibi tí a ti ń ta ayò.
Ilé-Okógbà: Àdúgbò
yìí gba orúko rè nípa sè Baba kan
tí ó fé ràn isé oko púpò. wón ní Bàbá yìí ma ń fi àyíká ilé e rè gbin orisirisi
nnkan lódodún sùgbón wón wí pé, àwon eran òsìn bíi ewúré ma ń yo ó lénu púpò.
Nígbà tí ó yá, ó wá bèrè sí ní pa àwon erúré tó bá ti won ú ogbà a rè. Eléyìí
ló wá fà á tí ìjà fi wà láàárín òun àti àwon ènìyàn, ni wón bá fim ni orúko wí
pé, Baba ológbà. Léhùn tí bàbá yìí kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò ibè ní
ilé-Ológbà.
Ìdí-Isin : Gégé
bí ìwádìí, won ni igi ńlá kan
wa níbè nígbà náà tí a ń pè ní igi-isin. wón wí pé, lábé rè ni wón ti ma ń gba
aféfé nítorí pé igi-ńlá ni, wón sì tún ma ń je èso ara rè. Bí ó tilè jé pé,
èyìn ìlú ni igi-isin yìí wà, sùgbón ní gbà tí wón kó ilé de ibè, ni wón bá ń pè
é ní ìdí-isin
Ilé-Lódò: wón
ní àdúgbò yìí jé ibi ilè àkèrò nígbà náà. Odò kékeré kan sì wà níbè nígbà náà tí wón ń pon mu.
Orúko Odò yìí ni a ń pè ní Odò-àwéré, Ibí yìí ni àdúgbò yìí tí gba orúko rè.
Ilé-
ńlá: Wón wí pé láàti
àdúgbò kan tí
a ń pè ní ilé-ńlá nilu ilé-ifè ni àwon àdúgbò yìí ti sè wá nípa sè ogun Ìdí
nìyìí tí wón fi ń pè é ni ilé-ńlá.
Òkè-Ganmo: Àdúgbò yìí
gba oríko jè láà ti ìlú kan
tí ó wà ní tòsí ìlorin tí a ń pè ní Gunmo. Lati ìlú yìí ni wón ní àwon ènìyàn
tó kókó tèdó sí sórí ilè náà o wá. Ìdí nìyìí tí wón fi ń pè é ní àdúgbò ara
ganmo títí ó fid i wí pé, wón ń pè rí òkè-Ganmo.
Òkè-Abà: Àdúgbò
yìí náà jé òkan lára àwon àdúgbò tó tí pé jù nilu yìí. wón wí pé, nígbà tí ìlú
kò ì tíì pò rárá, bí ènìyàn dúrói ní àdúgbò yìí, yóó máa wo gbogbo ìlú tókù ketekete,
ìdí nìyìí tí wón kúkú fi ń pe ibè ní òkè-abà.
Ìsàlè-ojà: Àdúgbò
yìí ni àdúgbò tí ó wa ní ojúde-ojà gan-an tí wón ti ń ná jà di òní-olónú.
Àdúgbò yìí kò jìnnà sí ilé-Oba.
Oníbàtá: Láyé
ojóun, wón ní, Olórí àdúgbò yìí ni wón fi je olórí àwon alubàbá àti igangan ní
ìlú yìí. Láàti ìgbà tí wón ti fi je é, ni wón ti ń pè é ní baba-oníbàbá, tí wón
sì ń pe ilé e jè ní ilé Baba-oníbàtá. Lati ibí yìí ni wón ti so àdúgbò ibè ní àdúgbò
oníbàtá èyí ni àdúgbò ilé Baba oníbàtá.
Olú-ìpo: Orúko
oyè kan
pàtàkì ni orúko àdúgbò yìí. Ìwádìí fihàn wí pé, eni tí ó je oyè yìí nígbà ìkéjì
jé akíkanjú ènìyàn tí ó lágbára tí ó sì tún jé ode. Oyè yìí ti di àsómodómo.
Ìlálè: Wón wí pé,
nígbà kan tí àwon ará ìlú-òbà wá sígun bá àwon ìlú pàmò wón wí pé nígbà tí wón
dé lojiji, ni enìkan nínú àwon asájú tàbí olóyè ìlú pàmò bá fowó fa ìlà tàbí
fowó la ilè wí pé àwon ará ìlú-òbà kò gbodò kojá ilà yen kí won tó pa dà séhìn
sùgbón wón dá ilà náà kojá tí ó sì fa ìjà ńlá. Ibi tí wón ti ja ìjà tí ó wá di
ìlálè lónìí.
Aráròmí: Ìtàn
fi yé wa wí pé, ogun ló lé àwon tí ó tèdó sí àdúgbò yí wá. Nígbà tí wón dé, ìlú
pàmò gbà wón láàyè láàti dúró tì wón. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe ibè ní aráròmí.
No comments:
Post a Comment