Ilé-tààrà: Àdúgbò yìí ni wón ti kókó kó ilé pèlú
búlókù ní ìlú yìí, ilé koríko ni ó pòjù láyé àtijó. Bí àwon ènìyàn bá ti wá ń
sòrò, won yóò máa wí pé àwon ń lo sí ilé tààrà, èyí ni ilé-gidi, tí a ko fi
koríko kó. Bí àdúgbò yìí se gba orúko nìyí.
Ìsawo: Ìtàn fi yé wa wí pé, inú igbó ni àdúgbò yí télè
kí ilé tí dé ibè. Igbó yìí ni wón ti ń se awo tàbí ibo. Wón maa ń pe igbó yìí ni
igbó-ìsawo sùgbón nígbà tí wón kó ilé ibè, wón wá ń pe ibè ní àdúgbò ìsawo.
Bàkókò: Emi tí ó te àdígbò yìí dó ni wón wí
pé, ó wá láàti ilu won tí a ń pè ní òkù légbẹ̀ẹ́ Òmù-àran. Ìtàn wí pé, àdúgbò
yìí ni bàbá yìí pé sí tí ó sì dàgbà kí ó tó kú. Nígbà tí, ó wà láyé, Baboko ni
wón ma ń pè é, Léyìn tí ó kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò yìí ní Babuko.
Ìsàlè-Òbà: Ìdí tí wón fi ń pe àdúgbò yìí béè ni pé
àdúgbò yìí jé ibi tí kòtò wà, ó sì tún jé wí pé ó tèdó sí ibi àbáwo ìlú.
Iwó Road: Àdúgbò yìí tèdó sí òpópó-ònà tí ó lo sí ìlú
iwó-ìsin. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe
àdúgbò yí ní Iwó-road.
Imojì: Gégé bí ìwádìí tí mo se, orí-ilè àdúgbò yí ni
wón ma ń sin òkú sí láyé àtijo. Orí-ilè yìí kò jìnnà púpò sí àárín ìlú kí ó tó
di wí pé ìlú fè dé ibè ni wón bá kúkú ń pè é ní àdúgbò imojì.
Odò-ilé: Ìdí tí àdúgbò yí fi ń jé béè ni pé ó
wà nítòsí Odò kan tí àwon ará ìlú fi ń foso. Odò yìí kò tóbi púpò, kódà, ó ma ń
ya wọ àdúgbò yìí ní ìgbà òjò. Ilé-Odò ni wón máa ń pè é télè kí won tó so ó
di odò-ilé báyìí.
Òkè-Àgbàá: Àdúgbò yìí wà láàárín gbùn-gbùn ìlú. Ìtàn wí
pé, bí òjù bá ti ń rò, àgbàrá òjò yíò kó ìdòtín láti òkè yìí lo sí ìsàlè-òbà,
àwon ará ìsàlè-òbà yóò wá a wí pé, àgbàrá òrè ló kó ìdòtí wá sí àdúgbò àwon. Àgbàrá-òkè yìí ni wón wá fi ń pe àdúgbò yìí kí
ó tú di wí pé, ó ń jé òkè-àgbàrá tàbí òkè-àgbàá.
Gbádéyan Kì í se orúko yìí ni àdúgbò yí ń jé télè.
Ayédùn ni orúko jè télè sùgbón nígbà tí ó di wí pé, enì kan tí ó tip é lénu
isé-oba ní ìpínlè Èkó tí ó jé omo ìlú yìí kú, ni wón bá ń fi orúko rè pe àdúgbò
yí nítorí pé, ó jé omo bíbí àdúgbò yí bákan náà. Wón sì gba ìwé-àse rè láàti
òdò ìjoba ìbílè won.
Òkè-Òbà: Àdúgbò yí wà ní òpópó-ònà tí ó lo sí ilu
owó-kájolà. Ìwádìí kò fi ìdí rè mule. Ìdí tí wón fi ń pè é béè.
Elékùú: Àwon ènìyàn àdúgbò yí wí pé, ní ìgbà
kan, tí àwon ènìyàn ma ń sepo, orí ni wón fi ma ń ru eyìn lo sí ìlú pàmò sùgbón
nígbà tí ó yá, ìjá wà láàárín àwon ará ìlú méjèjì, ni àwon ará-òbà bá sòfin wí pé
enikéni nínú àwon Obìnrin kò gbódù lo se epo ní ìlú-pàmò mó. Àwon ará ìlú Òbà
gba àwon Ègbìrà láàti bá won gbé ekùú ti won náà. Wón wá ilè sí èhìn odi ìlú,
wón sì ń pe ibè ní ilè-ekùú. Sùgbón ní báyìí, wón ti kó ilé yí ni wón wá ń pè
ní elékùú sùgbón èyí kò túmò sí wí pé, àwon àdúgbò yí ló ni èkùú náà. Àwon ekùú
tí wón gbé nígbà náà wà níbè di ìsisìyí.
Òfé-Àrán Ìwádìí kù fi
ìdí rè mule pàtó bí àdúgbò yí se jé sùgbón àrí-gbámú ìtàn kan ni wí pé àwon
àdúgbò yí jé ìbátan kan ní ìlú òmù-Àrán nitorí pé àdúgbò ń jé Òfé-àrán.
Eésabà: Gégé bí
ìtàn, oye ti won n je ní àdúgbò yí ni a ń pè ní Eésabà. Ìdí nì yí tí wón fi ń
pe ibè ní àdúgbò Eésabà .
Agbo Ilé-Òbà: Ọ̀kan nínú àwọ agboolé tí wọ́ ti
ń jọba nìyí..
No comments:
Post a Comment