Àdúgbò: Òkè Àgbìgbò – Òkè
Àgbò
Ìtumò: Ní ayé atijo, àdúgbò yìí wà nínú igbó kìjikìji, àwon eye
àgbìgbò ni o sì pò si ibè. Àwon eye wònyí a máa fò káàkiri orí igi t’osan
t’òru, bákan náà ni òkè pò sí àdúgbò ti a ń so nipa rè yìí. Ní ìgbà tì o se,
àwon ènìyàn bèrè sì tèdó sí àdúgbò yìí, wón ń kó ilé mole síbè àwon eye wònyí
kò fi àdúgbò náà sílè. Obinrin kan lára àwon ti ó kókó te ìlú náà dó ti orúko
rè ń jé “Bèje” akíkanjú obìnrin ni, òun ni ó pa àwon eye àgbìgbò náà run. Wón
sì so àdúgbò náà di Òke Àgbìgbò, ti wón wá ń pè ni “Òkè Àgbò” ni òde
òní. Won sì máa ń ki àwon omo àdúgbò náà báyìí;
“Omo òkè àgbò Bèje” ìdí ni wí pé
Òun (Bèje) ni o pa gbogbo àwon eye àgbìgbò náà run.
2. Àdúgbò: Jàpara
Ìtumò:
Ní ìgbà láyéláyé
ni ìlú Ìjèbú Igbó, ti wón bá ń jagun, ìbi ti ogun ti máa ń le ni won ń pè ni
Jàpara nitorí wí pé ni ibè ni wòn ti máa ń lérí mó ara won pé a o pa ara wa
lónìí ni, won a sì jà titi won ó fi férè pa ara won tán. Ní gbà ti won wa bèrè
síí te ibè dó, àwon àgbà wá so orúko àdúgbò ni “Jàpara” oríkì “Jàpara, a kó
obì se esà, a kérógbó bo ojú ogun. Ìjà ìpara – Jàpara”.
3. Àdúgbò: Itúndosà.
Ìtumò: Àwon
Yorùbá máa ń pe àdúgbò ní Itún nígbà míràn, àdúgbò ti won ń pè ni Itún yìí wà
ni Ìjèbú Igbo. Ṣe ni àwon ara àdúgbò dédé jí ni ojo kan, won rí i ti omi ti di
odò nla sí apá kan Itún won. Káwí káfò, àwon ara Itún bèrè sì ni pa eja nínú
odò náà. Báyìí ni wón so àdúgbò náà di “Itúndòsà”. Won a sì máa pe àwon ti won
wá lati àdúgbò yìí ni “Omo Ìdósà maye”.
4. Àdúgbò: Igbáàìré – Igbáìre
Ìtumò:
Àdúgbò yìí jé ibi ti igi igbá ti máa ń so. Igi igbá pò sí àdúgbò yìí tó
béè gee ti awon eniyan sì máa ń seré lábé rè. Bí enikan bá ni àlejò ti ó wá a
wá, won a ni kì won lo wò ó ni abé igi igbá àìré - igba ti won kò tii ré kúrò
lórí igi. Won wá so àdúgbò náà di Igbáìre.
5. Àdúgbò: Ojówò-Òjóò
Ìtumò: Ibi
ti ojó máa ń wò si ni won ń pè ni Ojó wò ti o wa di Òjóò loni yìí.
6. Àdúgbò: Itún alágbède - Itúnlágbède
Ìtumò:
Itún ni èdè Ìjèbú je “Agbo ilé”. Ó sì jé ibi ti àwon alágbẹ̀dẹ pò sì. Bí
àwon enìyàn bá sì fé júwe àdúgbò yìí láti agbo ilé mìíràn, won a ni e lo
sí Itún alágbède, tí ò sì di Itúnlágbède di oni yìí.
7. Àdúgbò: Asìgìdì
Ìtumò:
Ní ayé àtijú won máa ń mo sìgìdì níni àdúgbò yìí. Nítori ìdí èyí ni won se ń pe àwon ti won tèdó
sí àdúgbò yìí ni
Omo Asìgìdì
mode,
Omo Mode ráàtà
Omo atà je epo
má pòn ón.
8. Àdúgbò: Imò alágbon – Imòàgbon – Imàgbon.
Ìtumò: Ibi ti ìgi àgbon pò sí ni àdúgbò yìí.
Igi àgbon yìí pò to béè ti o fi je wí pe kò si ílé ti e kò ti níí rí i. Béè sì ni imò wà lórí rè lópòlopò.
Àwon eniyan ìgbà náà sì ń pe ibè ni Imò àgbon ti awon enìyan ode òní sì so ó
di “Imàgbon”
9. Àdúgbò: Imòro
Ìtumò: Àdúgbò
yìí je ibi ti ìgi òro pò sí. Àwon ènìyàn a sì máa je òro yìí. Imó ni agbègbè
ibi ti òro yìí ń so sí jìngbìnni. Àwon ènìyàn wá so àdúgbò náà di imó òro. Ìmòro
ni won ń pe ibè lónì yìí.
Oríki! “Imòro àláà, a rérun (enu)
gé òrò bí òbe”
10 Àdúgbò: Òkè
Erefòn
Ìtumò: Ní ìgbà Ìwásè, ẹfòn ńlá kan wa ni
Àdúgbò yìí ti o máa ń dààmú àwon ènìyàn ti won bá fe kojá lo sí oko. Odò nlá
kan sì wà ni orí òkè ibì ti ẹfòn yìí máa ń lúgo sí. Bí àwon eniyàn ba ń darí
bò lati oko won máa ń bu omi mu ninu odò yìí. Tí enikeni bá se ohun míràn yàtó
sí mímu nínú omi náà, ẹfòn yóò fi imú onitòhún fon fèèrè. Sùgbón ti ẹfòn wáà
bá ti rí I wí pé won ń mu omi ni, kì yóò se ohunkóhun fun irú eni béè, won yóò
sì la omi náà kọjá wọn yóò sì dúpé
lówó Olódùmarè wí pé àwon gun òkè Efòn, ati wí pé omi ti àwon mu ninu odò ti re
Efòn té lati má se ìjàmbá titi àwon fi gun òkè. Won wa so àdúgbò náà di òkè Odò
re’fòn teti àgékúrú rè wá di “Òkè-erèfon”
11. Àdúgbò: Ládugbó
Ìtumò: Ládugbó ni èdè Ìjèbú túmò sí ìkokò
ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ìtàn sò wí pé Odò ńlá kan wà ni àdúgbò yìí ti ìkòkò (ládugbó) àbáláyé
kan wà nínú rè. Tí àwon enìyàn bá fé pon omi mímu
nínú Ládugbó yìí ni won ti máa ń pon ón. Sùgbon, bi o ba je ki a fo aso, ìwè
ati ohun miran ni won a lo omi tí ó yí Ládigbó náà ká. Nígbà ti o se, won sọ
àdúgbò náà di “Odò-o-Ládugbó” ti àgékúrú rè wá di Lágugbó.
12. Àdúgbò: Igà
Eran
Ìtumò: Ní ìgbà láyéláyé, Bàbá kan wà ti
wón ń pè ni Òsígbadé Olómo òdo nitori kò mo iye omo ti o bi, sùgbón ó jé onísòwò eran Màlúù. Ó ní
àgbàlá ńlá ti ó máa ń da eran sí lati je papa. Kò si ohun òsìn míràn ti ó ń ba
àwon màlúù náà gbé ni àgbàlá náà. Àgbàlá ńlá yìí ni àwon Ìjèbú máa ń pè ni Ugà
eran ti o wa di “Igà Eran’ lónìí
13. Àdúgbò: Ìdágòlu
Ìtumò: Ní ayé àtijọ́, won a máa sa ìgò jo
sí àdúgbò yìí fún fífo lati tà á. Ìtán so wí pé èyìn odi ìlú ni ibè jé. Wón tún
máa ń da àwon àkúfó ìgò jo síbè. Àwon tí ó bá jé odùndùn, won a fó won sí
wéwé. Ìgbà tí ó se, àwon ènìyàn bèrè sí tè dó sì àdúgbò yìí. won wa ń pe ibè ní
“Abúle Ìdágòlu” ti o wa di “idágòlu” lónìí
14. Àdúgbò: Ìdí
Isin
Ìtumò: Inú Igbó ni àdúgbò yìí jé nígbà
àtijó. Igi ti o máa ń so èso isin ni ó pò nínú igbó yìí jù. Àwon eniyàn a máa
sinmi labe àwon igi náà bí won bá ń ti ònà oko tàbí odò bò. Ìgbà tí ó se, ìgbó
náà bèrè sí súnmó abúlé nìtori àwon ènìyàn ń tè dó sí etí ibè. Tí àwon àgbàlagbà
ní abúlé, pàápàá, àwon Okùnrin bá jeun tan, won a “tàtaré” sí abé igi yìí lati
lo gba atégùn. Ibi ti wón bá ti ń tayò, tí won ń “tàkúrò so”, won a wà níbè fún
ìgbà pípé. Enikéni ti ò ba ni àlejò, won a ni kí ó lo wo eni ní ó ń bèèrè ni
ìdí igi isin tí ó wa di “Ìdí Isin” lónìí.
15. Àdúgbò: Ìdí
scale (síkéèlì)
Ìtumò: Ní àdúgbò yìí, ìwòn tì àwon
alágbède ro ni wón ń lò lati máa fi se òsùwòn kòkó. Gbogbo àwon onísòwò kòkó
pátápátá ni won máa ń pàdé ni àdúgbò ti a ń so yìí lati wa rà ati láti wa ta kòkó won níbè. Ní ìdí èyí, won so ibè dí
ìdí scale ti wón ti ń won kòkó, ti àgékúrú rè sì di “Ìdí scale” lónìí
16. Àdúgbò: Òkè
sópen
Ìtumò: Ní ìgbà atijo, àwon osó ati àjé kò
fi ìse won bò rárá. Isé ibi won kò ni àfìwé, sùgbón àwon Àgbààgbà pinnu lati da
sèríà fún enikeni ti owó won bá tè. Tí won bá mú enikeni ti o ni osó tabi àjé,
ibi tì wón ti yàn sótò, ti won ti ń so òkò pa wón ni wón ń pè ní òkè ti osó
pari emi rè sí, tabí òkè ti emi osó pin sí. Èdè àdúgbò Ìjèbú ni “pen” – olóri
ẹ̀ka-èdèYorùbá ni “pin”. Nígbà ti ojú
ńlà ti àwon enìyàn ń kólé síbè, won wa so àdúgbò náà dí “Orí òkè osópen” ti
àgékúrú rè wá di “ÒKE SÓPEN”
17. Àdúgbò: Odò-Rámúuségun
Ìtumò: Ìtàn so fún wa wí pé àdúgbò kan wà
ti ogun máa ń jà wón lópòlopò. Bí ogun bá sì ti wolé tò wón, won máa kó won lérú
ni. Ní ìgbà ti o se, àwon àgbaàgbà ti won kù ni ìlú náà fi orí kan orí won sì
to “ifá” lo lati bèèrè ohun ti won lè se ti agbègbè àwon kò fi níí parun lowo
àwon ti o ń ko won lérú. Ifá ni kì won bo Odò ti o wà ni ìlú won, kì won sì máa
pon omi Odò náà sí ilé. Gbàrà tì won bá ti gbó wí pé ogun wòlú, ki oníkálukú bu
omi náà mu. Láìpé, Ogun miran wolé tò wón, wón se bi ifá ti wí, wón jagun won
sì ségun. Wón wá ni odò ni awon fí ségun, ti ó wá di “Odò-rámúùségun”
18. Àdúgbò: Itún-Lógun
Ìtumò: Itún ni èdè ìjèbú túmò sí “Agboolé”. Àwon jagunjagun ìlú ni ibi ti wón ti máa ń
pàdé dira ogun ti won ba fe lo sí ojú ogun. Àkókò ti won bá fe lo jagun nikan
ni won máa ń pàdé ni ibè. Tí àwon ènìyàn tì kò mo ohun ti o ń selè télè bá ti ń
ri àwon jagunjagun ti won ń dé sí itún
yìí, won a ni àwon Ológun ti dé sí itún won. Won wa so ibè di “Itún Ológun” ti
àgékúrú rè wa di “itún Lógun”.
19. Àdúgbò: Odò
Asóyìn
Ìtumò: Odò kan wà ni àdúgbò kan, ti èso Òyìn máa ń
so repete ní bèbè rè. Àwon àgbàgbà a máa jókòó ta ayò ni abé àwon igi yìí, won
a si máa fi èso òyìn panu bí ayò bá ń lo lówó. Báyìí ni wón so ibè di “Odò ti o
ń so èso Òyìn” tí ó wá di “Odò asoyìn”.
20. Àdúgbò: Orímolúsì
Ìtumò: Ní Ìgbà Ìwásè, orúko àdúgbò ńlá kan
ni Ìjèbú Igbó ni “Orímolúsì”. Sùgbón, gégé bi a ti mò wí pé àwon Yorùbá máa ń
ye ìpín tabi Àyàmó wò (ori). Àwon ènìyàn àdúgbò náà a da Obì won a wí pé “Orí
ìwo lo mo Olùsìn, Olùserere, je kí ìgbésí ayé mi dára o. Báyìí ni eni ti o kókó je Oba ìlú náà wí pé òun ni Olórí ìlú,
òun ni orí fún àwon ènìyàn ti o wà ni ìlú gbogbo ènìyàn yóò sì ma pe sin òun
ni. Ní ìdí èyí, won so Oba náà di “Orí-mo-Olùsìn” ti ó di “Orímolúsì” lónìí.
21. Àdúgbò: Òkè
Idán
Ìtumò: Àwon eléégún ati àwon abòrìsà ìlú
máa ń se ayeye Odún won ni Odoodún ni ayé atiju. Orí Òkè ńlá kan ni won sì ti
máa ń pa Idán Orísirísi fún àwon ara ìlú. Nígbà tì o se, àwon ènìyàn kólé sí
Orí Òkè yìí, won sí so àdúgbò náà di “Orí Òkè Idán pípa” tó wa di “Òkè Idán”
lónìí.
22. Àdúgbò: Iwáta
Ìtumò: Ní ìgbà ti àwon ènìyàn bá je Oyè
tan ní ìlú, àwon Ìjòyè a sì wá sí Iwájú ìta àafin. Oba pèlú àwon ebí, ara ati
òré won lati wa jó, lati se àjoyò pèlú Olóyè tuntun. Nígbà ti ó se, àwon ènìyàn
féràn lati máa se ayeye orísirìsì ni iwájú ìta àafin Oba nitori pé enikeni ti o
ba fe se ayeye ti Oba ba ti gbó nipa rè ni yóò ri èbùn gbà lówó Oba. Báyìí ni
won bèrè síí lo ìtà Oba fun ayeye. Bí won ba sì fé se àpèjúwe ìbì ti won yóò
ti se ayeye fun àwon ará, òré, ati ojúlùmò, won a ni kí wón wá bá won se ayeyre
ni iwájú ìta Oba. Níbo ni e o ti se ayeye? “Iwáta Oba ni”. Kèrèkèrè wón so
àdúgbò náà di “Iwátá”.
23. Àdúgbò: Òkè
Ererú
Ìtumò: Kí o tó dì wí pé a gba òmìnira,
àdúgbò yìí ni wón ti máa ń ta erú, tì àwon ènìyàn sì ti máa ń ra àwon erú lo sí
“Àgbádárìgì”. Nígbà ti ó se, Ojà erú títà sá féré ni orí òkè yìí, àwon Olùtajà
a sì wá so ibè di Òkè-Ererú
24. Àdúgbò: Òkè
Tákò
Ìtumò: Ní ìgbà àtijó, ti wón ba fe fi Oba
je ni ìlú, àdúgbò yìí ni won ti máa ń gbìmò eni ti Oba kan lati ìdílé ti Oba
kan. Tí ètò fífi Oba je yìí bá ta kókó ti o díjú tan pátá, àwon àgbààgbà
afobaje á kó ara won lo si Ori Òkè kan lati lo tú gbogbo ohun ti o bá dìju
palè. Ní orí òkè yìí, won a dìbò, won a dá ifá, ohun gbogbo yóò sì ni ojútùú kì
won tó padà sí ilé. Nitorí ìdí èyí ni wón se so òkè náà di “Òkè Tákò”. Òkè ti a
ti ń tú ohun lèrò ti ó ta kókó.
25. Àdúgbò: Òkè
Àlààfíà
Ìtumò: Léyìn Ìgbà ti àwon afobaje bá ti ri
ojùtùú enì ti yóò joba, ọkan won a balè, won a wá gun orí òkè kan lo lati lo
gba atégùn sára. Nìbe, wón a mu emu, won a sì máa wí pé àlàáfíà ti dé bá ìlú. Orí òkè yìí ni o di
àdúgbò ńlá lónì, ti won so di “Òkè àlààfíà”.
26. Àdúgbò: Òkè
ìfé
Ìtumò: Orí òkè kan wà ti àwon àlejò ti wón
ba sèsè wo inú ìlú ti máa ń lo búra wí pé àwon kò níí se búburú sí Oba ati
àwon omo onílùú. Orisìrìsi àwon èyà enìyàn ni won máa ń pàdé ni orí oke yìí ni
asìko ìbúra náà, Ègbá, Ibàdàn, Òyó. Hausa, Ìgbò, abbl. Orò ajé ni ó gbe won wá sí ìlú náà (Ìjèbú Igbó). Nígbà tí ó se,
Oba se akiyesi wí pé gbogbo àwon àlejò wònyí ń se bí omo ìyá kan náà, a fi bi
eni pe ile kan ni gbogbo won ti wá. Láì fa òrò gùn, àwon àlejò yìí ń pò sí i,
won ń bí sí i, won ń rè sí i, ìlú sì kún to béè géè tì onílé kò mo àlejò mó. Ní
ojo kan, Oba pe gbogbo àwon àlejò ìlú jo tèbí tàráa won, Ó sì so fún won wí pé
òun rí i pé won ni ìfé ara won. Lati ọjọ́ náà lo, òun (Oba) yọ̀ǹda orí
òkè tì wón tì bura ni ojósí fún won, ki won ko àwon enìyàn won ki wón lo tè dó
sí ibè.
Gbogbo àwon àlejò wònyí sì dupe
lówó oba. Won sì se bi Oba ti wí. Lati Igba náà ni won ti so àdúgbò náà di orí
òkè ìfé ti o di “Òkè Ìfé” loni yìí.
27. Àdúgbò: Atìkòrì
Ìtumò: Ní ayé atijo, ìko tí wón fi ń hun
eni ni ó pò ni àdúgbò yìí. Bàbá kan wà ti o je ògbóǹtagí onísègùn; ìko ni o máa
ń fi ríran sí àwon ènìyàn. Ohun kohun ti ènìyàn bá bá lo si òdò rè, ìko yìí ni
ó máa kó kalè ti yóò sì máa ba sòrò bí ènìyàn; sùgbón ohun nìkan ni o máa ń gbo
èdè tì ìko náà ń so, òun yóò wa túmò ọ̀rọ̀ ìko fún eni tí ó wa se àyèwò. Ní ìdí èyí, won so
“Baba’yìí ni “Ati ìko ri ohun ti o ń sele si ènìyàn” ti o di “Atìkorí” nigba ti
awon ènìyàn tè dó si àdúgbò náà. Lónìí Atìkòrì ni àwon ènìyàn ń pè é.
28. Àdúgbò: Odòdóoróyè
Ìtumò: Ní aye atijo, Okùnrin kan wà ni ìlú.
Ó je alágbára atì alákíkanjú ènìyàn. Orúko rè ń jé “Ọmódóríoyè”. Ó se isé
takun-takun fún ìlú Baba rè, ò sì jè omo Oba. Ní ìgbà tì Oba tó wà lórí Oyè
wàjà, Ìdílé rè ni Oba kàn òun sì ni o ye ki wón mú, nínú ìdílé náà. pàápàá tì o
tún jé alágbára ènìyàn.
Àwon
afobaje gba àbètétè lowo elòmíràn won sì kojú “Omódoríòyè” sóòrùn alé. Kàkà ki
ilè kú, ilè á sá ni Omódérìoyè fi òrò náà se ati bi a se mò wí pé àwon alágbára
kò kò Ikú. Omodorioye se Okunrin, ò sì pinnu wí pé bí won kò tilè fi òun joba won
kò ni gbàgbé òun láyéláyé. Báyìí ni “Ọmódóríoyè tí àwon ènìyàn ti se àgékúrú
orúko rè sí “Dóróyè” télè di odò ńla kan sí odì ìlú náà, ó sì fi ohùn sílè wí
pè, Oba tí ó ba je ti kò bá mu nínú omi náà kò níí pe lori oyè tí wón fi je,
atì wí pé eníkéni tí ó bá ń mu omi náà yóò di alágbára. Bíí àwon ènìyàn se bèrè
sí níí tè dó si eti odò náà ni yìí, ti won sí so àdúgbò náà ti “Odòdóoróyè”
iyan ni pe “Odò Omódórí oyè”.
29. Àdúgbò: Station
(Sitésòn)
Ìtumò: Léyìn Ìgbà ti awon Gèésì dé, ti Okò
ayókélé ati irúfé okò mìran bèrè síí wo orile èdè wa, àwon Okò akérò tì o ba
wo ìlú Ìjèbú Igbó ni ibi kan ti won ti gbódò ja awon èrò won sile, ti won yóò
sì kó àwon èrò miran. Ibè ni won ń pè ni station, Ibikibi ti ènìyàn bá ń lo
lati Ìjèbú Igbó, ibe nikan ni e ti lè ri oko wò.
No comments:
Post a Comment