Ilé-Àwòrò-òsé: ìtàn
ti a gbo nipa adugbo tabi agbo-ile yì so fun wa pe ilé Àwòrò-òsé je ibi pàtàkì
ti won ti ma n se orò, ò sì tun je ile-Olorisa.
Ìlé-Olúóde: A gbó pe ode ni ìran àwon
wònyí n se láti ìgbà ìwásà. Ibe sì nì Olórí àwon ode n gbe.
Ile-Olutojokun: Àwon ìdílé yi ni o ma ń joba ni
ìlú-ìlá-òràngún.
Ile-Olorirawo: Adugbo
ati Agbo-ile ni eyi je. Ìtan ti a si gbo nipa won ni pé ìbè ni Olori awon awo
tedo sì.
Ìjímògòdò: Akoni èdá kan ni o je, jagunjagun si ni pelu, oun lo
te àdúgbò yì dó.
Ìgbonnìbí: jé
òkan nínú àwon oba akíkanjú ti o wolè ni Ilá. Níbi ti o wolè sin i a n pe ni
Ìgbonnìbí loni yìí.
Ajagúnlá: Ode
ni ajagunle nigba aye re, o si je jagunjagun O si bínú wolè lo ni.
Ògbon Ìperin: Nibi ti a pa Erin sin i a n pe ni ìperin
Òkè-Èdè: túmò
si ibi ti a pa elédè si
Ògbún ìsèdó: Eyi tumò
si ibi ti isé sodo si. Agbègbè yi ni ìlú ma n lo gégé bi ojúbo isé.
Ilé- Olóòsà: A gbo
pe wón ma n ko òrìsà pamó sì adugbó yií.
Òkè-Alóyin: Odò kan ti o n san ni àdúgbò
yì, wón ma n lo omi yì láti fi se ìmúláradá àwon omo wéwé.
Ilé-Alápìnni:
Ìtàn so pe idile Oloje tabi eleegun ni won je. Àwon si ni Olórí gbogbo
àwon eégún.
Ilé-Ìyálóde: Obìnrin
ni o te idile yi do, O gbé fáàrí O si tun je akikanju obinrin láàrin ìlú.
Ilé-Akogun: Jagunjagun
naa ni o te adugbo yi do. Akogun si tun je Oloye pàtàkì ni ìlú
Ilé-Òjá-bèbè: Isé
abèbè ni wón yàn láàyò ni àdúgbò yì.
Ìlé-Agbèdègbede: Àwon
ìdílé Alágbède ni àwon wonyi n se.
Ilé-Òdú: Èfó
òdú ni won ma ngbin ni akoko ti won so orúko ile yii.
Ilé-Ajengbe: Isé Ìsègùn ni won ma n se ni ìdílé yi. Won si tun je akoni èdá kan.
Ilé-Obajisun: Ìdílé
oba ni won jé won sì tun je Olóyè ìlú. Èfó òsùn pò púpò nì àdúgbò yìí
Ilé-Onílù: Àwon
àyàn ni o te ile yìí do, ìdílé onilu ni àwon wonyi je
Ilé-Awúgbo: àwon
ìdílé yi saba ma n gbìn erè kan
ti a n pe ni awúje, èyí tí o ti gbilè ti won fi n pe won lórúko loni.
Ile-Èelemukan : Èkan po ni àdúgbò yìí
Ìle-Obajoko: Idile yin i won ti ma n sábà fi Oba je,
eyìti a mo si kugmaker.
Òkè-Ògbún:
Nígbà tí ìlú ko ti làjú àdúgbò yi ni wón ma sábà ko gbogbo àwon òhun
ìdòtí pamó si, o si je ògbun eyì ti wòn so di oke-ògbún lòni yì.
No comments:
Post a Comment