Adugbò: Ìkénné
Itumò: Kòríkó ìkólé ti a ń pè ní ìken nì èdè Rémo ni ó wópò
púpò ní agbegbe kan
nì ayé ojoún. Nìgbà ti ó wà dì wí pé awoòn ènìyàn ń gbé agbègbè yìí bí ìlú ni
won bá n so wí pé a tun ni ni ikèn néè o. èyí ti a wa se ìsúnkì gbólohùn náà sí
ìkènné.
Adugbò: Sònyìndo
Itumo: Òkunrìn jagunjagun kan ni àdúgbò yìí ni ó ka ení rè kan mo ibi ti ó tí n
kínrin aya re ken leyin nigbati aránbìnrin náà ń wè ní ile iwe. Inu bi okunrin
yìí pàápàá nitori pe erúbinrin náà kò sá nìgbà ti é rí ì. Èyí mu kì ó bínu pa
ìyàwó rè àti erúbìnrin náà Nìgbà ti won sì bì í ìdí ti ó fi se béè o sàlàyé pé
ń se ni erú yìí sànyín-dó. Lati ìgbà náà ni a ti ń pe adugbo ohun ní sànyìndó.
Àdúgbò: Ajíno
Itumò: Nì ayé àtijó, òwúrò kùtùkùtù ni won máa ń ná ojà agbègbè
kan báyìí ni
ìlè Remo. Kèrèkèrè, awon ènìyàn bèrè sí ìlé ní í ko sí ibi ofà yii, wón sì ń
gbé ibe. Bayìí ni won se so ojà náà ní Ajino ti àwon ènìyàn sì so adugbo náà nì
Ajìwo titi di ìsìnsìnyí.
Adúgbo: Ìmóbìdo
Itumò: Agbègbè ti a fi igi Obì pààlà tàbí sàmì sí. Àwon méjì ti
ó ń jà du ààlà ilè ni o fa orúko yìí jáde nítorí awon tì ó nì ìlè salàyé wí pé
ìgi obì ni àwon fì dó: ìlè àwon láti fi se idámo sí ilè elòmìíràn.
Adúgbò: Ìdótun
Itumò: Ní asìko ogun ti awon Yorùbá ń ti ibi kan dé ibì kan ni àwon kan ko ara won jò láti te ìlú tìtun dó.
Léyin ti awon ènìyàn ti n pò níbe ni wòn wa so ìbùdó won yìí ní ‘Ìdótùn’ èyí ti
ó túmò sí ibùdó tìtun.
Àdùgbò: Ìdómolè
Itumò: Nítorí àgbára àti ìwa ìpànle tàbí ìwà jàgídíjàgan okunrin
kan báyìí ti
a pe orùko rè ní Ìdó ni àsìkò Ojoun ni a se so oruko adugbo yìí ní Ìdómolè
léyìn ikù okunrin yìí ni awon ènìyàn bérè sì fi okunrin yìí júwè adúgbò ré. Won
a ní awon n lo sí Ìdó akínkayú nì tàbí
okùnrin imolè nì. Báyìí ni a kuku so adúgbà di Ìdómolè.
Àdùgbó: Ìròlù
Ìtumò: Léyìn ìgbà ti awon Yorùbá ken ti gbà latí parapò máa gbe
pèlu ìrépò ni agbègbè kémo, yìí ni won kùkú wá pè è ní Ìrolù. Èyí túmo sì pé
awon jo kò ó lù ni kí àwón tó ‘péjo síbè.
Àdugbò: Sáàpàdé
Itumò: Àwon ìlu méta ni ó parapò sí ojú kan. Nígbà tí ó wà di wì pé okan kò yònda
oruko tirè oún èkèjì ni wón wà yo nínú oruko awon meteeta; làti yo sàaàpàde
Ìsarà – láti ibi ni wón ti yo
‘sá’
Ìparà
– láti ibi ni wón ti yo oá’
Odè – láti ibi ni wón ti yo dé’
Àpaofò sá- pà-dé ni ó wá di sápadè.
Àdúgbò: Ìsarà
Itúmò: Òde
nì awon tí ó parapò te ìlú ìsara dó. Kaluku awon ènìyàn wònyi ni won sì wá láti
agbègbè òtòòtó. Nígbà ti ó wá dì wí pè ènìkan fé so ara re di olorí ‘àpàpàndodo
ni won bá làá yée pe n se nì awon sa ara awon jo sibe! Ti won sì ‘sun orúkò náà
kì di Isarà.
Àdugbò: Ògèrè
Ìtumò: Áwon
tí ó ń gbé òkèèrè ni won ti kèrèkèrè só dì ògèrè. Láyé àtijó bì ó bà ti dì wí
pé awon ènìyàn Remo bà fé lo sí ibi ti awon are ‘Ògèrè wá won a so wí pè awon
fe ló sí agbègbè awon ara òkèèrè. Awon ènìyàn wònyí búrú púpò jù, won sì taari
won sìwaju. Won á ni Okeere ni ó ye won. Nígbà ti ójú ń là nì wón bà so oruko
ìlú yìí di Ògèrè.
Àdúgbò: Ajítaádùn
Itùmò: Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò
yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn.
Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni
wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn).
No comments:
Post a Comment