Ìlúgùn: Ni ìgbà
lááláé, ìtàn so fún wa pé omo kan
sonù. Léyìn tí wón ti wá a kiri títí ni wón rí i ni ìlú kan tí ó
jìnà. Nítorí pé ibi tí wón ti rí omo náà jìnà, ni wón se ń pè e ní ìlúgùn.
Àgó Òkò: Òkúta
ni wón ń pè ní òkò nì èka èdè Egbá. Ní ìgbà ogun, awon ará àdúgbò yìí ko ni
ohun elo ìjà kankan
ayàfi òkúta. Òkò ni wón má a ń so fún àwon ota won. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wòn
ní Àgó Òkò
Ojà Àgbò: Eran
àgbò ni wón ń tà níbè kí ó tó di ìbi tí awon ènìyàn ń gbé
Ìtokò: Adágbà
je omo ìrówò ìbàràpá òun ní ó kókó dé Abéòkúta, Ogun lé won dé orí olumo (Àwon
ìbàràpá) wón bá Adágbà tí ó ń se isé ode ní orí olúmo. Adágbà fi àwon Ibàràpá
tí ogun lé dé ori olúmo yìí sí ìdi igi ìto kan. Àwon náà bèrè sí í se ode. Ní ojó kan wón ro oko yí ìdi
igi ìto yìí ká, wón gbá pàntí sí abé igí ìto yìí, wón fi iná sí i. Nígbà tí
Adágbà rí i, ó pariwo lé won lórì pé: Ah! Èyin ènìyàn yìí ìto le kò (Kò túmò sí
kí á pa igi). Bí a se rí ìtokò nì yí.
Ìjemò: Ìjemò
túmò sí Àjumò. Ohun tí a fìjo mò nípa rè
Kémta: Kémta tumo sì kèeta, Àsòjóró, òtè. Wón máa ń
se keèta ara won ìdí èyí ni wón fi ń pe wòn ni Kémta.
Ìjeùn: Ìtumo
re ni “èjì ohùn” áwon olórò méjì héun
Àgó òwu: Àwon
ará àdúgbò yìí jé àwon tí ó ń jowú, owú jíje won ló mú won sokún gba adé àwon
omo ìkijà. Ìdí nìyí tí wón se ń ki won pé “Ara òwu, omo asunkún gbadé
Arégbà: Àdúgbò
tí àwon ìbàràpá tèdó sí. Nígbà tí wón dífá pé kí wón mú Ègbá wá. Wón ní
ati-re-gbà ó. Bí ó se dí arégbà nìyí.
Kúgbà: Ikú-gba-èyí.
Odò ńlá kan
tí ó gbé omo lo ní Arégbà ní àwon ènìyàn ìgbà náà fi ń so pé íkú gba èyí lówó
wa. Kúgbà.
Òkè Èfòn: Àwon ará Efòn Alàyè láti ìpínlè Òndó ni
wón ń gbé àdúgbò yìí. ìdí nìyí tí a fi ń pè àdúgbò náà ní òkè èfòn.
Àdátán: Ogun
àti oko ríro, léyìn tí wón tí ja ogun tán, wón fé roko àyíká àdúgbò náà ní a so
fún òkunrìn kan pé kí ó lo mú Àdá láti fi sisé wá. Òle ènìyàn nì okùnrin yìí, ó
dáhún, ó ní Àdá ti tán. Bayìí ni a se ń pe ibè ní Àdátá.
Sábó: Sábó
wá láti inú Sábánímó. Àdúgbò tí àwon Hausa tèdó si ni. Òrò yìí kì í se òrò
Yorùbá tàbí ti Ègbá.
Odédá: Àdúgbò
tí àwon ode má a ń fàbò sí lèyìn tí wón bá ti sode lo tán ni ibè ní won yóò
péjo sí tí won yóò sì dá àwon eran tí wón bá pa jo sí ibè.
Òkè Agbède: Àdúgbò
yìí ni àwon ìbàdàn tí wón wá sí Abéòkúta tèdó sí ní igbà tí wón wòlú Egbá. Won
kò gba ará ìlú mìíràn móra níbè àfi omo ìbàdàn.
Àgó Ìjèsà: Àdúgbò
àti ìbìdó àwon ará ilésà nínú ìlú ègbá
Ìsàle Jagun: Ìsàlè
(AJAGUN) – Àdúgbò tí wón ti ń ja ogun ní ìlú Ègbá ní ìgbà àtijo. Kòtò wà ní ibè
nì wón fi ń pè é ní ìsàlè jagun.
Àgó Tápà: Ibùdó
àwon Tápà nígbà tí wón dé sí Ègbá
Eléwéran: Ewé iran tí a fi ń
pón èbà tàbí àmàlà ní o hù àyíká yìí ni ìgbà tó tip é láé. Ibè nì àgó olópàá wà
ní Abéòkúta.
Panséké:
Igì
kan wa ti èso rè máa ń dún bì ìgbà ti ènìyàn bá ń mi beere. Ibì tì igi yìí wà
gan-an ní gbogbo ènìyàn si máa n lo lati mú u fún lìlò ni awón ara ìlú fún ni
orúko ti ó jò mo dídún tie so inu rè màa ń dun. – Pasiséké
Mókóla:
Àwon
ará Òkè-Ìdó ni Abéòkúta nìkan ni ó mo awo ti ó wà nínú àgbùdo gbíngbìn. Odò won
sì ni gbogbo awon ènìyàn ti máa n ra àgbàdo. Nítorí ìyànje yìí nì Oba Aláké se
fun Olórí àdúgbò yìí ni Omobìnrin re kan
lati fi se aya. Obinrin yìí ni o ridìí àsiri ìkòkò yìí tì ó sì sàlàyé fún awon
ènìyàn rè. Ibì ti arabinrin yìí wà pàdà nì Oko si ni a fùn ni orunko yìí.
Mókólà – Omo ko olá wá sílé.
Fàjé:
Iyá
kan ni ò ń dààmú awon ara àdùgbò ìbi ti ó n gbé. Nìgba ti idààmú yìí wá pòju tí
awon ènìyàn si mú ejo rè to Oba lo ni ìyá yìí wá sàlàyé wì pé lóòótò ni òún jé
àjé ati wì pé ení ti ó bat ó òun ni òún ń da sèrìyà oún. Kábiyèbi bà so pé
àsàjemátèe ni obìnrin yìí o. Bi wòn se ń fi ìyá yìí fúwe àdùgbò tì ó ń gbé
nìyèn. Won a ní àwón ń lo sí sàje:
Quarry:
Àdugbò yìí ni awon òyìnbó tédò sí làtí máa fo òkútà si wéwé oún ilé kíko
tàbi òná sise. Awon Òyìnbó yìí ni wón n pè ni Òyìnbó Quarry nítori Orúko òyìnbo
ti ó koko gbé àdùgbò yen. Won ní àwon ń lo sí agbègbè Qùarry.
Àgo Òwu:
Ní àsìkò
Ogun nígbà ti ogun tú awon ènìyàn Owu ti onìkàlùkù won sì fónká. Awon ti ó tédó
sí àdúgbò yìí ni o kúkú fé se ìdámò ara won si awon Ègbà yookù. Ìdí nìyìí ti won
fí so Ibùdó won nì Àgó Òwù Àgò ti a tì ilè rí awon ara Owù
Ita-Eko:
Ní àtijó
àdúgbò kookan ni ó ní ise ìdamo won. ‘Sùgbón nì tí awon ara àdúgbò yìí eko nì
gbogbo awaon obìnrin won màá ń tà. Bí ó bà sì dì ale gbogbo won a pate eko won
sì ojú kan.
Bì a bá wà rí ení ti o bá fe lo sí ojúde yìí onítòhùn yòó sò pé òun lo si
Ìtà-eko. Orúko yìí nì ò sì mo àdúgbò náà lòrí dì onì yìí ni pàtàkí fún ìdamò
ìta-eko ojóun.
Ita
Ìyálòde:
Akínkanjú
obinrin kan
wa ni Ègbá ni ayé ojóun. Efúnróyè Tínubú nì orúko rè. ‘Nítorí ibe ìdàgbàsòkè re
sù ìlú Ègbá ni oba Àláké se fí jè Ìjatóde ìlù. Oún ni ìyálódè Ègbá àkòkó. Ibì
ti Ìyá yìí wá kólé sí ní àdúgbò rè ni won so di ‘Ita ìyálódè.
Kútò:
Nì
àyé àtíjó àbikú ń da bàbá kan
láàmu. Nigbà ti ó dáfá, won ni ki ó fe síwáju bì ó bà ń fé kì àbìkú dúró. Bàbá
yìí wá dó sí ìbi ti a mo sí Kútò lónìí. Sùgbon léyìn odún díè omo ti ó bà tún
kú nì o bá bérè ariwo pé ikú tun to òun léyìn dé ibí yìí. Báyìí ni awon elégbe
rè se ge orúko kéré di`kútò tí ó sì wà dòní yìí
Ìdí
àbà:
Nígbà tì kò tíì sí ònà móto bí àwon ti a ní lònìí yìí àwon ènìyàn ti wón
jè yálà ode tàbí àgbè a máa fi adúgbò Ìdí Àbà se ìpàdé won. Igi àbà po ni
àdúgbò yìí nìgbà náà. Awon ènìyàn wonyi a sì maa sinmi ni àbe àwon Ìgi yìí yàlà
ní àlo tabì ní àbò. Báyìí nì won se kúkú so agbégbè yìí ni Idí àbà. Bì ó file
jè pé olàjú ti dé báyìí èyí kò yí oruko adugbo náà páde dì báyìí.
Ajítaádùn:
Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò
yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn.
Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni
wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn).
No comments:
Post a Comment