Tuesday, 5 May 2015

Gírámà Gẹ̀ẹ́sì fún Àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (English Grammar for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Karùn-ún (Fifth Lecture)


L.O. Adéwọlé

Nínú idánilẹ́kọ̀ọ́ kẹ́rin, a mẹ́nu ba àrótì (adjunct), ((ọ̀rọ̀-orúkọ) àkésí (vocative), gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) àti gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence). Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, gbólóhùn aṣẹ (imperative sentence) ni a ó fi bẹ̀rẹ̀ àláyé wa.

Imperative Sentence (Gbólóhùn Àṣẹ)

A máa ń lo gbólóhùn àṣẹ láti fi pàṣẹ (to issue orders) tàbí láti fi tọ́ ni sọ́nà (to instruct). Àwọn àpẹẹrẹ ni:

(61) (a) Dìde dúro (Stand up).

(b) Take a train to Ìbàdàn (Wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí Ìbàdan).

(c) Leave him (Fi i sílẹ̀).

Gbólóhùn àṣẹ (imperative sentence) kì í sábàá ní olùwà (subject) bí àwọn àpẹẹrẹ (61) ṣe fi hàn ṣùgbọ́n, a lè lo olùwà (subject) you nígbà mìíràn fún ìtẹnumọ́ (emphasis). Bí àpẹẹrẹ, dípò (62a), a lè sọ (62b).

(62) (a) Sit down (Jókòó sílẹ̀)

(b) You sit down (Ìwọ jókòó sílẹ̀)

Exclamative Sentence (Gbólóhùn Ìyanu)

Nǹkan tí ó yani lẹ́nu (exclamation) ni gbólóhùn ìyanu (exclamative sentence) máa ń fi hàn. What tàbí how ni ó máa ń bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ ni:

(63) (a) What a fool I’ve been! (Mo ma hu ìwà agọ o!)

(b) How big you’ve grown! (O mà ti dàgbà sí i!)

Nínú gbólóhùn ìyanu (exclamative sentence), what ni ó máa ń ṣaájú ọ̀rọ̀-orúkọ (noun); how ni ó máa ń ṣaájú àwọn oríṣìí mìíràn (other types).

Àwọn oríṣìí gbólóhùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin (the four sentence types) – declarative (àlàyé), interrogative (ìbéèrè), imperative (àṣẹ) àti exlamative (ìyanu) – ní ìrísí gírámà (grammatical form) tí ó ya ọkan sọ́tọ̀ sí èkejì. Ṣùgbọ́n sá o, ìgbà míìràn, a lè lo gbólóhùn oní-ìrísi gírámà kan (a sentence with a grammatical form) láti fi jẹ́ iṣẹ́ gbólóhùn oní-ìrísí gírámà mìíràn tí a bá ń sọ̀rọ̀ (performs the role of a sentence with another form in communication). Bí àpẹẹrẹ, ìrísí gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) ni  (64a) ní ṣùgbọn tí a bá gbé ohùn sókè nígbà tí a ń sọ ọ́, yóò di gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní (64b).

(64) (a) You need more money (O nílò owó sí i)

(b) You need more money? (O nílò owó sí i?)

Tí a bá sì wá wo ìbéèrè pèsìjẹ (rhetorical question), lóòótọ́, ìrísí gbólóhùn ìbéèrè ni ó ni, bẹ́ẹ̀ rèé, àlàyé ni a máa ń lò ó fún. Bí àpẹẹrẹ:

(65) Who knows? (= Nobody knows.) (Ta ló mọ̀? (= Kò sí ẹni tí ó mọ̀))

Fragments and Non-sentences (Àwọn Ẹ̀hun tí kò Tó Gbólóhùn)

Gbogbo àwọn gbólóhùn (sentence) tí a ti ń yẹ̀ wò ni ó pé tí wọ́n sì bá òfin gírámà mu (grammatically complete). Gbólóhùn tí ó bá pé tí ó sì bá òfin gírámà mu gbọ́dọ̀ ní olùwà (subject) àti ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) àyàfi tí gbólóhùn náà bá jẹ́ gbólóhùn àṣẹ (imperative sentence) níbi tí olùwà rẹ̀ kì í t ií hànde (the subject is understood). Ṣùgbọ́n sá, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, tí a bá ń bá ara wa sọ̀rọ̀, a kì í lo gbólóhùn tí ó kún. Fún àpẹẹrẹ, a máa ń sábàá pa I jẹ tí ó bá wà ní ipò olùwà (subject). A máa ń gbọ́ irú àwọn ìpèdè wọ̀nyí:

(66) (a) Can’t see anything (N kò rí nǹkan kan).

(b) Must sleep early tonight (Mo gbọ́dọ̀ tètè sùn lálẹ́ òní).

Nínú irú àwọn ìpèdè báwọ̀nyí, a ti mọ̀ ọ́n sínú pé I ni olùwà (subject).

Tí a bá tún ń dáhùn ìbéèrè, gbólóhùn tí kò kún ni a tún sábà máa ń lò:

(67) (a) Olú: What did buy for me? (Kí ni o rà fún mi?).

(b) Adé: A book (Ìwé kan).

Gbólóhùn tí kò kún ni ìsọ (utterance) tí ó ti ẹnu Adé jáde. Tí Adé bá fẹ́ kí ìsọ rẹ̀ jẹ́ gbólóhùn tí ó kún, ohun tí yóò sọ ni pé I bought a book for you (Mo ra ìwé kan fún ọ).
Tí a bá wo inú ìwé ìròyìn, àwọn gbólóhùn tí kò kún máa ń pọ̀ nínú wọn. Bí apẹẹrẹ, a lè rí:

(68) Adé in pensions scandal (Ìwà ìbàjẹ́ tí ó jẹ mọ́ owó àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì kan Adé).

Ìsọ èdè Gẹ̀ẹ́sì (68) yìí kò ní ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) ṣùgbọ́n ìtumọ̀ tí ó máa ní ní ọkàn wa ni Ade is involved in a pensions scandal (Ìwà ìbàjẹ́ tí ó jẹ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì kan Adé).

A mẹ́nu ba àwọn èhun tí kò tó gbólóhùn wọ̀nyí nítorí pé a lè túmọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè túmọ̀ gbólóhùn tí ó kún tí ó sì bá òfin gírámà mu (grammatically complete sentence). Àwọn ìsọ (utterance) kan tilẹ̀ wà tí wọn kò tilẹ̀ ní èhun gbólóhùn rárá tí kò sì sí nǹkan kan ní sàkáni wọn. A máa ń sábàá rí irú àwọn wọ̀nyí lára pátákó ìtọ́ka tàbí pátákó ìṣàmìsí (public signs and notices). Àwọn àpẹẹrẹ ni:

(68) (a) Exit (Àbájáde ).

(b) No Standing (Máà dúró níbí)

(c) Pothole Ahead (Kòtò kótokòto wà níwájú)

(d) Ìbàdàn, 2 miles (Ó ku mẹ́ẹ̀lì méjì kí a dé Ìbàdàn)

(e) 10% Off (A fi ìdámẹ́wàá dín in kù)

(f) Ticket Office (Ọọ́fíìsì ìgba tíkẹ́ẹ̀tì)

(g) Closing Down Sale (Ọjà tí a ó tà tí a ó fi kógbá wọle)

Àwọn irú ìsọ yìí tí a máa ń rí tí a bá ń sọ̀rọ̀ ni bye, goodbye, hello, yes, no, ok, right, sure, thanks, thanks very much, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìsọ tí kò tó gbólóhùn wọ̀nyí máa ń wáyé púpọ̀ nígbà tí a bá ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní àkókò gbẹ̀fẹ́ (informal situation). Tí a bá wo gbogbo ìsọ (utterance) tí a máa ń sọ jáde, nǹkan bí ìdá mẹ́ta rẹ̀, ẹ̀hun tí kò tó gbólóhùn ni ó máa ń jẹ́.

Ọ̀rọ̀

Ìdá (unit) tí ó ṣe patàkì ni ọ̀rọ̀ (word) jẹ́ nínú gbólóhùn (sentence). Tí a bá sọ pé My father bought a big car (Bàbá mi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ńlá kan), òye àhunmọ́ (instinct)  wa yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ lè fi yé wa pé ẹ̀yà (type) kan náà ni father àti car àti pé irú ẹ̀ya kan náà kọ́ ni father àti bought. Bí irú èyí bá ṣẹlẹ̀, ohun tí òye àhunmọ́ wa ń fi yé wa ni pé ìsọ́rí ọ̀rọ̀ (word class) kan náà ni father àti car àti pé father àti bought kìí ṣe ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan náà. A lè pín àwọn ọ̀rọ̀ inú èdè kan sí inú àwọn ìsọ̀rí (major word classes) wọ̀nyí:

Ìsọ̀rí (Word Classes)            Àpẹẹrẹ (Examples)

Nouns (Ọ̀rọ̀-orúkọ)            brother, children, England, biology, John, wood

Main verbs (Ọ̀rọ̀-ìṣe kíkún)        break, dance, come, repair, drink, sing, talk

Adjectives (Ọ̀rọ̀-àpèjúwe)        happy, hot, foolish, dirty, old, angry

Adverbs (Ọ̀rọ̀-àpọ́nlé)            sluggishly, carelessly, happily, slowly

Pronouns (Ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ)        I, me, my, you, he, his, her, we, our

Auxiliary verbs (Aṣèrànwọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe)    can, could, may, do, might, will, would

Conjunctions (Ọ̀rọ̀ asopọ̀)        and, but, or, although, because, when

Articles (Átíkù)                a, an, the

Numerals (Òǹkà)            four, five, thirty, sixth, seventh

Orísi méjì ni isòrí ọ̀rọ̀ tí o wà. Àwọn kan wà tí wọn kò níye. Ìdí ni pé wọn lè gba ọmọ ẹgbẹ́ tuntun. Irú àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí kò níye yìí ni ọ̀rọ̀-orúkọ (nouns) àti ọ̀rọ̀-iṣe (verb). Iye ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó wà kò tilẹ̀ dàbí ìgbà pé ó lóǹkà nítorí pé ń ṣe ni ó tún ń fẹ jú sí i bí nǹkan tuntun ṣe ń yọjú.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tí ó tún ti wọ inú ọ̀rọ̀-orúkọ lẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni: bitmap, internet, website, CD-ROM, e-commerce, e-mail, URL, laptop, modem, dotcom, multimedia, newsgroup àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tuntun náà tún ti ń wáyé. Ara wọn ni: download, upload, reboot, right-click, double-click.

No comments:

Post a Comment