Monday 27 April 2015

Gírámà Gẹ̀ẹ́sì fún Àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (English Grammar for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kẹ́ta (Third Lecture)



L.O. Adéwọlé


Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kejì, a sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀-ìṣe (verb), àbọ̀ tààrà (direct object) àti àbọ̀ ẹ̀bùrú (indirect object). Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, orí àmúpé àbọ̀ (object complement) ni a ó ti bẹ̀rẹ̀.


Àmúpé Àbọ̀ (Object Complement)
Àwòmọ́ (Atrribute) tí àbọ̀ ní ni àmúpé àbọ̀ (object complement) máa ń ṣe àlàyé. Bí àpẹẹrẹ, bí a bá sọ pé
  
(35) The dye turned the water red (Dáì náà sọ omi náà di pupa)


Red ni àmúpé àbọ̀ (object complement). Àwòmọ́ (attribute) tí water (omi) náà ní, ìyẹn àwọ̀ (colour) ni ó ń ṣe àlàyé. Water (omi) yìí ni àbọ̀ nínú gbólóhùn (sentence) yìí. Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni:
  
(36) (a) His gift made me happy (Ẹ̀bùn rẹ mú kí inú mi dùn)
(b) They elected him chairman (Wọ́n yàn án ní alága)
(c) He called him a fool (Ó pè é ni ọ̀dẹ̀)


Nínú gbólóhùn wọ̀nyí, me àti him ni àbọ̀ (object) nígbà tí happy, chairman àti a fool jẹ́ àmúpé àbọ̀ (object complement). Amúpé àbọ̀ (object complement) máa ń tẹ̀ lé àbọ̀ tí ó ń ṣe àlàyé àwòmọ́ rẹ ni.


(37) Bátànì Gbólóhùn Karùn-ún (Sentence Pattern 5)
         S            V                    DO         OC
The dye        turned        the water    blue (Dáì náà sọ omi náà di pupa)


S dúró fún  subject (olùwà), V dúró fún verb (ọ̀rọ̀-ìṣe), DO dúró direct object (àbọ̀ tààrà) nígbà tí OC dúró fún object complement (àmúpé àbọ̀). Bí a bá kọ́kọ́ wò ó, yóò dà bí ìgbà pé bátànì gbólóhùn kérin àti ẹkárùn-ún fẹ́ẹ́ jọra. Ẹ fi (38) wé (39).


(38) Bátànì Gbólóhùn Karùn-ún
           S        V        DO    OC
     They    made     him    chairman (Wọ́n yàn án ní alága)


(39) Bátànì Gbólóhùn Kẹ́rin
       S    V    IO    DO
    Olú    made     John     coffee (Olú po kọfí fú Jọ̀ọ́nú)


Ìyàtọ̀ láàrin (38) àti (39) yóò hàndé tí a bá yí ìhun wọn padà. Bí apẹẹrẹ, fún (39), a lè sọ pé


(40) Olú made coffee for John (Olú po kọ́fí fún Jọ̀ọ́nú)


Fún (38), a kò lè sọ pé


(41)*They made chairman for him


Bí a bá tilẹ̀ lè sọ bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ (41) yóò yàtọ̀ si (38). Bẹ́ẹ̀ rèé, ìtumọ̀ kan náà ni (39) àti (40) ní. Ohún tí wúnrẹ̀n (element) chairman ń ṣe ni pé ó ń sọ àwòmọ́ (attribute) tí him ní. Ìyẹn ni pé He is chairman (Òun ni alága). Chairman (alága) jẹ́ àmúpé àbọ̀ (object complement) fún him ní (38). Ẹ wo àwọn
wọ̀nyí náà:   


(42) (a) He called him a fool (Ó pè é ní ọ̀dẹ̀)
(b) He is a fool (Ọ̀dẹ̀ ni)


(43) (a) He called him a taxi (Ó pe takisí fún un/Ó bá a pe takisí)
(b) He called a taxi for him (Ó pe takisí fún un/Ó bá a pe takisí)


Bátànì gbólóhùn kárùn-ún ni (42) ní nígbà tí (43) ní bátànì gbólóhùn kẹ́rin.


The Five Sentence Patterns (Àwọn Bátànì Gbólóhùn Márààrún)


Bàtànì Kìíní: Olú laughed (Olú rẹ́rìn-ín) (S and V (Olùwà àti ọ̀rọ̀-ìṣe))


Bátànì Kejì: Adé is three (Adé di ọmọ ọdún mẹ́ta) (S, V and SC (Olùwà, ọ̀rọ̀-ìṣe àti àmúpé olùwà))


Bátànì Kẹ́ta: I enjoyed the film (Mo gbádùn fíìmù náà) (S, V and DO (Olùwà, ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ tààrà))


Bátànì Kẹ́rin: I asked Olú a question (Mo bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Olú/Mo bi Olú ní ìbéèrè) (S, V, IO àti DO (Olùwà, ọ̀rọ̀-ìṣe, àbọ̀ ẹ̀bùrú àti àbọ̀ tààrà))


Bátànì Kárùn-ún: The dye turned the water red (Dáì náà sọ omi náà di pupa) (S, V, DO and OC (Olùwà, ọ̀rọ̀-ìṣe, àbọ̀ tààrà àti àmúpé àbọ̀).


Ohun tí a ó ṣe àkíyèsí ni pé gbogbo gbólóhùn wọ̀nyí ni ó ní subject (olùwà) àti ọ̀rọ̀-ìṣe nínú. Bí gbogbo gbólóhùn ṣe máa ń ní àwọn méjèèjì yìí nì yí àyàfi imperative sentence (gbólóhùn àṣẹ) tí subject (olùwà) rẹ̀ máa ń jẹ́ mọ̀-ọ́n-nú tàbí tí a ti pa olùwà rẹ̀ jẹ. Nítorí ìdí èyí ni a fi lè sọ pé Stand up (Dìde dúró). Tí a bá sọ èyí, ohun tí a ń sọ ni pé (You) stand up ((Ìwọ) dìde  dúró).


Active and Passive Sentences (Àwọn Gbólóhùn Ákítíìfù àti Pásíìfù)
Nínú gbólóhùn tí o bá jẹ́ ákítíìfù (active), olùwà (subject) ni ó máa ń ṣe ohun tí ọ̀rọ̀-ìṣe ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gbólóhùn tí ó bá jẹ́ ákítíìfù ni ìdàkejì gbólóhùn tí ó bá jẹ́ pásíìfù (passive). Ohun tí eléyìí ń sọ ni pé bí gbólóhùn kan kò bá jẹ́ ákítíìfù yóò jẹ pásíìfù. Àwọn àpẹẹrẹ ni ó wà ní (45).


(45) (a) Active (Ákítíìfù): Olú wrote a book (Olú kọ ìwé kan)


(b) Passive (Pásíìfù): A book was written by Olú (Olú ni ó kọ ìwé kan)


Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé èdè Yorùbá kò ní gbólóhùn tí a lè pè ní pásíìfù. Gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ (focus construction) ni a fi túmọ̀ gbólóhùn pásíìfù sí èdè Yorùbá. Bátànì (pattern) gbólóhùn ákítíìfù (active) ni S+V+D (olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àbọ̀), ìyẹn bátànì kẹ́ta tí a ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀. A book (ìwé kan) tí ó jẹ́ àbọ̀ tààra (direct object) nínú gbólóhùn ákítíìfù (active sentence) ni ó di subject (olùwà) nínú gbólóhùn pásíìfù (passive sentence).Olú tí ó jẹ́ subject (olùwà) nínú gbólóhùn ákítíìfù (active sentence) ni ó lọ sí òpin gbólóhùn pásíìfù (passive sentence). Gbólóhùn ákítíìfù ni gbólóhùn ìpìlẹ̀ (underlying sentence) fún gbólóhùn pásíìfù. A máa ń ṣẹ̀dá gbólóhùn pásíìfù láti ara ákítíìfù nípa fífi aṣèrànwọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe pásíìfù (passive auxiliary) tí a ń pè ní be (àwọn aṣèrànwọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe tí a ń pè ní be ni is, was, are, were àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) bọ inú gbólóhùn ìpìlẹ̀ tí a ó sì lo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-iṣe (different form of the verb) inú gbólóhùn ìpìlẹ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, nínú gbólóhùn (45a) tí ó jẹ́ gbólóhùn ìpìlẹ̀, a lo ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) wrote ṣùgbọ́n nínú gbólóhùn pásíìfù, written ni a lò.
Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn ákítíìfù àti pásíìfù mìíràn ni ìwọ̀nyí:


(46) (a) (i) Active: Adé broke the stick (Adé dá igi náà)
(a) (ii) Passive: The stick was broken by Adé (Adé ni ó dá igi náà)


(b) (i) Active: Òjó shows the book to the visitor (Òjó fi ìwé náà han àlejò náà)
(b) (ii) Passive: The book is shown to the visitor by Òjó (Òjó ni ó fi ìwé náà han àlejò náà)


Tí a bá wo gbólóhùn akítíìfù Olú ate the biscuit (Olú jé bisikíìtì náà), Olú tí ó jẹ́ olùwà ni ó ṣe nǹkan ṣùgbọ́n tí a bá wo gbólóhùn pásíìfù The biscuit was eaten by Olú (Olú ni ó jẹ bisikíìtì náà), a ó rí i pé bisikíìtì ni olùwà, òun ni a si ṣe nǹkan sí.


Nígbà mìíràn, a kìí lo àpólà (phrase) tí ó ní by nínú tí gbólóhùn (sentence) náà kò wá níí ní olùṣe (agent). A máa ń pe irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ní pásíìfù aláìní olùṣe (agentless passive). Àpẹẹrẹ ni ìwọnyí:


(46) (c) Akítíìfù (Active): Olú broke a cup (Olú fọ́ kọ́ọ̀bù kan)
(d) Pásíìfù (Passive): A cup was broke by Olú (Olú ni ó fọ́ kọ́ọ̀bù kan)
(e) Pásíìfù tí kò ní olùṣe (Agentless Passive): A cup was broken (Kọ́ọ̀bù kan fọ́)


Àwọn kan máa ń túmọ̀ irú gbólóhùn bíi A cup was broken by Olú sí 'A fọ́ kọ́ọ̀bù náà láti ọwọ́ Olú'. Ohun tí ó yẹ kí a mọ̀ ni pe ọmọ Yorùbá tí kò bá gbọ́ èdè Gẹ́ẹ̀sì kankan kò níí sọ̀rọ̀ báyìí. Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé ọ̀rọ̀-ìṣe agbàbọ̀ (transitive verb) nìkan ni a lè yí gbólóhùn rẹ̀ padà sí pásíìfù (passive). Àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe agbàbọ̀ (transitive verb) kan tilẹ̀ wà tí a kò lè yí gbólóhùn wọn sí pásíìfù (passive). Lára wọn ni have, resemble àti  suit.


(47) (ai) Ákítíìfù (Active): Òjó has a new house (Òjó ní ilé tuntun)
(aii) Pásíìfù (Passive): *A new house is had by Òjó


(bi)  Ákítìfù (Active): Òjó resembles Àìná (Òjó jọ Àìná)
(bii) Pasíìfù (Passive): *Àìná is resembled by Òjó


(ci) Akítíìfù (Active): That colour suits Olú (Àwọ̀ náà bá Olú lára mu)
(cii) Paíìfù (Passive): *Olú is suited by that colour


A máa ń lo àmì ásítẹ́ríìkì (*) fún àpẹẹrẹ tí kò bófin gírámà mu (ungrammatical) tàbí èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà (incorrect). Ìyàtọ̀ láàrin gbólóhùn ákítíìfù (active sentence) àti gbólóhùn  pásíìfù (passive sentence) ni a ń pè ní fọ́ìsì (voice). Ìyẹn  ni pé a máa ń pe àwọn gbólóhùn kan ní gbólóhùn ákítíìfù (active sentence) a sì ń pe àwọn kan ní gbólóhùn pásíìfù (passive sentence).

No comments:

Post a Comment