Monday 27 April 2015

Gírámà Gẹ̀ẹ́sì fún Àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (English Grammar for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kejì (Second Lecture)



L.O. Adéwọlé


Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kìíní, a sọ ohun tí gírámà (grammar) jẹ́ a sì tún sọ̀rọ̀ nípa gbólóhùn (sentence), olùwà (subject) àti kókó-gbólóhùn (predicate). Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, ọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀-ìṣe ni a ó fi ṣíde.


Oriṣìí Ọ̀rọ̀-ìṣe (Verb Types)
Oríṣìí ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) mẹ́ta ni ó wà. Àwọn  náà ni aláìgbàbọ̀ (intransitive), asopọ̀ (linking) àti agbàbọ̀ (transitive).


Ọ̀rọ̀-ìṣe Aláìgbàbọ̀ (Intransitive Verb)
Gbogbo gbólóhùn tí ó wà ní (23) ni ó fi ọ̀rọ̀-ìṣe aláìgbàbọ̀ hàn.


(23) (a) Olú laughed (Olú rẹ́rìn-ín)    (b) He wouldn’t come     (Kò níí wá)
(c) The boy appeared (Ọmọkùnrin náà yọ jáde)


Ọkọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn (sentence) tí ó wà ní (23) ni ó ní olùwà (subject) àti ọ̀rọ̀-ìṣe (verb). Eléyìí fi hàn pé bátànì (pattern) tí wọ́n ní ni SV (olùwà (subject) àti ọ̀rọ̀-iṣe (verb)). Bátànì (23a) ni a kọ sílé ní


(24) Bátànì Gbólóhùn Kìíní (Sentence Pattern One)
    S          V                                                                                                                                                
    Olú      laughed (Olú rẹ́rìn-ín)


SV dúró fún olùwà (subject) àti ọ̀rọ̀-ìṣe (verb).


Ọ̀rọ̀-ìṣe Asopọ̀ (Linking Verb)
Púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe ni ó máa ń sọ ohun tí olùwà ṣe. Tí a bá sọ pé Olú laughed (Olú rẹ́rìn-ín), ohun tí olùwà (subject) Olú ṣe ni laughed (rẹ́rìn-ín) ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe asopọ̀ (linking verb) kìí hùwà báyìí. Àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe asopọ̀ (linking verb) kìí sọ ohun tí olùwà (subject) ṣe. Dípò èyí, wọ́n máa ń so olùwà pọ̀ mọ́ fọ́nrán (element) mìíràn tí ó bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) ní. Bí àpẹẹrẹ, tí a bá sọ pé ‘Adé is three’ (Adé di ọmọ ọdún mẹ́ta), a kò sọ pé Adé ṣe nǹkan kan. Ohun tí ó ṣẹlẹ ni pé ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) inú gbólóhùn yìí, ìyẹn is, kàn so olùwà (subject), ìyẹn  Adé, mọ́ three ni. Ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) tí a ń pè ní be (bí àpẹẹrẹ, is, was, are. were, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) ni ó máa ń sábàá ṣe irú iṣẹ́ yìí ṣùgbọ́n o, àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) mìíràn tí ó tún ń ṣe irú iṣẹ́ yìí tún wà. Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀-ìṣe asopọ̀ (linking verb) míìràn ni wọ́n wà ní (25).


(25) (a) It seems so (Ó jọ bẹ́ẹ̀) (b) He appeared calm (Ó jọ ẹni tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀)       
(c) You look well (Ojú rẹ jọ ojú ẹni tí ó ń gbádùn)          
(d) I became suspicious (Ara ń fu mí)
(e) It went unreported (Wọn kò ròyìn rẹ̀)


Àmúpé olùwà (subject complement tí àgékúrú rẹ̀ jẹ́ SC) ni a ń pe fọ́nrán (element) tó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀-ìṣe asopọ̀ (linking verb) yìí. Eléyìí ni bátànì gbólóhùn kejì (sentence pattern 2).
   
Bátànì Gbólóhùn Kejì (Sentence Pattern 2)
    S         V    SC
    Adé     is    three (Adé di ọmọ ọdún mẹ́ta)


S dúró fún subject (olùwà), V dúró fún verb (ọ̀rọ̀-ìṣe), SC sì dúró fún subject complement (amúpé olùwà).


Ọ̀rọ̀-ìṣe Agbàbọ̀ (Transitive Verb)
Àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe agbàbọ̀ (transitive verb) ni àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) tí kò lè dá dúró nínú kókó-gbólóhùn (predicate) láìjẹ́ wí pé fọ́nrán inú gbólóhùn (sentence element) mìíràn tẹ̀ lé wọn. Bí fọ́nrán inú gbólóhùn (sentence element) mìíràn kò bá tẹ̀ lé wọn, ìtùmọ wọn kò níí pé.


Tí a bá wo ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) destroy (bàjẹ́) fún àpẹẹrẹ, a kò lè dá a lò. Ó nílò kí fọ́nrán (element) mìíràn tẹ̀ lé e nínú kókó-gbólóhùn. A kò lè sọ pé *The bomb destroyed ṣùgbọ́n a lè sọ pé The bomb destroyed the town (Bọ́ǹbù náà ba ilù náà jẹ́). Irú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) bíi destroy tí kò lè dá dúró nínú kókó-gbólóhùn ni a ń pè ní ọ̀rọ̀-ìṣe agbàbọ̀ (transitive verb). Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni (27).


(27) (a) The factory produces many cars (Ilé-iṣẹ́ náà ṣe káà tí ó pọ̀)
(b) I bought a new book (Mo ra ìwé tuntun kan)    (c) I enjoyed  the film (Mo gbádùn fíìmu náà)


Àwọn fọ́nrán (element) tí ó jẹ́ kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe agbàbọ̀ (transitive verb) kún bíi many cars (káà tí ó pọ̀), a new book (ìwé tuntun) àti the film (fíìmù náà) ni a ń pè ní àbọ̀ tààrà (direct object). Gbólóhùn Gẹ̀ẹ́sì tí ó bá ní àbọ̀ tààrà (direct object) ni a pín sí ìpín gbólóhùn bátànì kẹ́ta (sentence pattern 3).
   
(28) Bátàní gbólóhùn Kẹ́ta (Sentence Pattern 3)
    S    V            DO
    I    enjoyed        the film (Mo gbádùn fíìmù náà)


S dúró fún subject, V dúró fún verb, DO sì dúró fún direct object. Ọpọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) ni ó ní ìlò ìgbàbọ̀ (transitive) àti àìgbàbọ̀ (intransitive) ṣùgbọ́n o, ìtumọ̀ wọn lè yàtọ̀ sí ara nígbà tí wọ́n bá gba àbọ̀ àti ìgbà tí wọn kò bá gba abọ̀. Àpẹẹrẹ irú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) tí ó ń hùwà báyìí ni ó wà ní (29).


(29) (ai) Aìgbàbọ̀ (Intransitive): The plant grew (Koríko náà hù) (S+V (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))
 (aii) Ìgbàbọ̀ (Transitive): The man grew maize (Ọkùnrin náà gbin àgbàdo) (S+V+DO (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))


(bi) Àìgbàbọ̀ (Intransitive): The man shook (Ọkùnrin náà gbọn) (S+V (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))
(bii) Ìgbàbọ̀ (Transitive): The bomb shook the building (Bọ́ǹbù náà mú kí ilé náà gbọ̀n) (S+V+DO (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))


(ci) Àìgbàbọ̀ (Intransitive): He sang (Ó kọrin) (S+V (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))
(cii) Ìgbàbọ̀ (Transitive): He sang two songs (Ó kọ orin méjì) (S+V+DO (Olùwà àti ọ̀rọ̀-iṣe))


Ní èdè Yorùbá, a lè sọ pé kọrin (kọ orin) jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ yìí, sang kò ní àbọ̀ nínú. Àbọ̀ tààrà (direct object (DO)) ni ohun tí ọ̀rọ̀-ìṣe ń ṣe (‘action’ of the verb) nínú gbólóhùn máa ń kàn gbọ̀ngbọ̀n. A máa ń sábàá dá àbọ̀ tààrà (DO) mọ̀ nínú gbólóhùn nípa lílo what tàbí whom/who láti bèèrè ìbéèrè, nípa rẹ̀, bí apẹẹrẹ:
(30) (i) The bomb destroyed the town (Bọ́ǹbù náà ba ilù náà jẹ́)
Q: What did the bomb destroy? (Kí ni bọ́ǹbù náà bàjẹ́?)
A: The town (Ilú náà) (DO (àbọ̀ tààrà))
   
(ii) The policeman arrested the woman (Ọlọ́pàá náà mú obìnrin náà)
 Q: Whom/Who did the policeman arrest? (Ta ni ọlọ́pàá náà mú?)
 A: The man (Obìnrin náà) (DO (ábọ̀ tààrà))


Àbọ̀ Ẹbùrú (Indirect Object)
Àwọn gbólóhùn kan máa ń ní àbọ̀ (object) méjì, bí àpẹẹrẹ,
   
(31) We gave Òjó the prize (A fún Òjó ní ẹ̀bùn náà)


Àwọn àbọ̀ méjèèjì inú gbólóhùn yìí ni Òjó àti the prize. Wúnrẹn (element) the prize ni àbọ̀ tààrà (direct object). Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, àbọ́ tààrà ni a fi máa ń dáhùn ìbéèrè what (bí apẹẹrẹ, What did we give Òjó? (Kí ni a fún Òjó?)); The prize (Ẹbùn)). Àbọ̀ (object) kejì, Òjó, ni a ń pè ní àbọ̀ ẹ̀bùrú (Indirect Object (IO)). Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni (32).


(32) (a) I asked Olú a question (Mo bèèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ Olú)
(b) He told his son a story (Ó sọ ìtàn kan fún ọmọ rẹ̀)
(c) She bought us a book (Ó ra ìwé kan fún wa)
(d) They awarded Adé a salary increase (Wọ́n fi kún owó oṣù Adé)


Àwọn àbọ̀ tààrà (direct object) inú gbólóhùn wọ̀nyí ni question, a story, a book àti a salary increase. Àwọn àbọ̀ ẹ̀bùrú ni Olú, his son, us àti Adé.
Tí àbọ̀ mejì bá wà nínú gbólóhùn, àbọ̀ ẹ̀bùrú (indirect object) ni ó máa ń ṣaájú; àbọ̀ tààrà (direct object) ni ó máa ń tẹ̀ lé e. Bí bátànì (pattern) gbólóhùn tí ó ní àbọ̀ ẹ̀bùrú nínú ṣe máa ń rí nì yí:
  
 (33) Bátànì Gbólóhùn Kẹ́rin (Sentence Pattern 4)
    S     V              IO    DO
    I    asked        Olú    a question (Mo bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Olú)


S dúró fún subject (olùwa); V dúró fún verb (ọ̀rọ̀-ìṣe); IO dúró fún indirect object (àbọ̀ ẹ̀bùrú) nígbà ti DO dúró fú́n direct object (àbọ̀ tààrà). Ìgbà mìíràn wà tí a lè tún gbólóhùn bátànì kẹ́rin tò, bí àpẹẹrẹ,


(34) (a) We gave Olú the prize (A fún Olú ní ẹ̀bùn náà)
(b) We gave the prize to Olú (A fún Olú ní ẹbùn náà).

No comments:

Post a Comment