Monday 27 April 2015

Gírámà Gẹ̀ẹ́sì fún Àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (English Grammar for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kìíní (First Lecture)



L.O. Adéwọlé



Gírámà

Nínú iṣẹ́ yìí, gírámà ni a ó gbà sí ọ̀nà tí a ń gbà to ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn tí wọ́n fi ń di gbólóhùn. Nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì, Òjó has been dancing (Òjó ti ń jó) jẹ gbólóhùn tí ó ní ààtò (well-formed sentence) tí ó sì bá òfin gírámà mu (grammatical sentence). Gbogbo ẹni tí ó bá ti lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni yóò lè sọ irú gbólóhùn yìí tí yóò sì mọ ìtumọ̀ rẹ̀ láìtilẹ̀ mọ ohun tí a ń pè ní gírámà. Bí àwọn ènìyàn kan náà bá rí irú ẹ̀hun (construction) yìí: *dancing Òjó been has, wọn yóò sọ pé ààtò rẹ̀ kò dára (not well-formed); wọ́n á ní kò bófin gírámà mu (ungrammatical).


Ẹ̀kọ́ nípa gírámà ni ó máa ń jẹ́ kí à lè mọ ọ̀rọ̀-ìperí (terminology) tí a lè lò tí a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa èdè kan. Ó ń jẹ́ kí á lè ṣe ìtúpalẹ̀ (analysis) kí á sì lè ṣe àpèjúwe (description) èdè wa àti èdè àwọn ẹlòmíràn. Tí a bá ń kọ̀wé, ìmọ̀ wa nípa gírámà máa ń jẹ́ kí á lè ṣe ìgbéléwọ̀n (evaluation) oríṣiríṣi àṣàyàn (choices) tí ó wà fún wa nígbà tí a bá ń kọ àròkọ (composition).


Tí a bá ní kí á tò ó ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, nínú gírámà, gbólóhùn(sentence) ni o máa ń ṣaájú tí awẹ́-gbólóhùn (clause) yóò tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn èyí ni yóò kan àpólà (phrase) àti ọ̀rọ̀ (word). Gbólóhùn (sentence) máa ń ní awẹ́-gbólóhùn (clause) kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú.  Awẹ́-gbólóhùn (clause) máa ń ní àpólà (phrase) kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú. Àpólà (phrase) máa ń ní ọ̀rọ̀ (word) kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú.


Lára àwọn nǹkan tí a ó yẹ̀ wò nínú iṣẹ́ yìí ni gbólóhùn (sentence), awẹ́-gbólóhùn (clause), àpólà (phrase), ọ̀rọ̀-orúkọ (noun), ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ (pronoun), ọ̀rọ̀-ìṣe (verb), ọ̀rọ̀-àpọ́nlé (adverb), ọ̀rọ̀-àpèjúwe (adjective), ọ̀rọ̀-atọ́kùn (preposition), ọ̀rọ̀-asopọ̀ (conjuction), aṣèrànwọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe (auxiliary verb), àsìkò (tense), ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ (aspect), ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ (word formation),  àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.



Àwọn Fọ́rán Gbólóhùn Abọ́dé (The Elements of a Simple Sentence)

Gbólóhùn Abọ́dé (Simple Sentence): Tí a bá ń kọ nǹkan sílẹ̀, gbólóhùn (sentence) ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a tò pọ̀ tí a fi lẹ́tà ńlá (capital letter) bẹ̀rẹ̀ tí a si fi àmì ìdánudúró (full stop or period), àmì ìbéèrè (question mark) tàbí àmì ìyanu (exlamation mark) parí. Bí a bá wo oríkì (definition) yìí, àpẹẹrẹ gbólóhùn (sentence) ní èdè Gẹ̀ẹ́sì (English) ni:
(1) Olú played football (Olú gbá bọ́ọ̀lù) (2) Who played football? (Ta ni ó gbá bọ́òlù?)
 (3) How big you have grown! (O mà ti tóbi sí i gan-an!)
Gbólóhùn abọ́dé (simple sentence) ni ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn (1), (2) àti (3).



Gbólóhùn Alákànpọ̀ (Compound Sentence): A lè so gbólóhùn abọ́dé (simple sentence)  méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀ nípa lílo ọ̀rọ̀-asopọ̀ (conjunction) bíi but tàbí and. Ẹ jẹ́ kí á wo (4) àti (5):
(4) Òjó played football (Òjó gbá bọ́ọ̀lù)   
(5) Adé preferred ayò game (Ayò tìta ni ó wu Adé)
A lè so gbólóhùn tí ó wà ní (4) àti (5) pọ̀ di (6):
(6) Òjó played football but Adé preferred ayò game (Òjó gbá bọ́ọ̀lù ṣùgbọ́n ayò títa ni ó wu Adé)
Gbólóhùn tí a bá so pọ̀ bíi (6) tí o jẹ́ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè dá dúró bíi (4) àti (5) ni a ń pè ní gbólóhùn alákànpọ̀ (compound sentence). Àpẹẹrẹ gbólóhùn alákànpọ̀ mìíràn ni (9) tí ó jẹ́ àpapọ̀ (7) àti (8):
(7) I went to the market (Mo lọ sí ọjà)    (8) I bought a football (Mo ra bọ́ọ̀lu kan)
(9) I went to the market and bought a football (Mo lọ sí ọjà mo sì ra bọ́ọ̀lu kan)



Gbólóhùn Oníbọ̀ (Complex Sentence): Gbólóhùn oníbọ̀ (complex sentence) máa ń jẹ́ àpapọ̀ awẹ́-gbólóhùn tí ó lè dá dúró (independent clause) àti awẹ́-gbólóhùn tí kò lè dá dúró (dependent clause). Bí àpẹẹrẹ:
(10) When I got home, I bought a football (Nígbà ti mo délé, mo ra bọ́ọ̀lù kan)
Gbólóhùn tí ó lè dá dúró fúnrarẹ̀ (tí a ń pè ní independent clause) ni ‘I bought a football (Mo ra bọ́ọ̀lù kan)’. Gbólóhùn  tí kò lè dá dúró fúnrarẹ̀ (tí a ń pè ní dependent clause) ni ‘When I got home (Nígbà tí mo délé)’. Orúkọ mìíràn tí a máa ń pe gbólóhùn tí ó lè dá dúró fúnrarẹ̀ ni ‘main clause (olóri awẹ́-gbólóhùn)’. Orúkọ mìíràn tí a ń pe ‘dependent clause’ ni ‘subordinate clause (gbólóhùn àfibọ̀ tàbí gbólóhùn àfarahẹ)’. Àpẹẹrẹ gbólóhùn oníbọ̀ (complex sentence) mìíràn ni (11):
 (11)When I saw him, I greeted him (Nígbà tí mo rí i, mo kí i)
Ní (11), olórí awẹ́-gbólóhùn (main clause) ni ‘I greeted him (Mo kí i)’ nígbà ti ‘When I saw him (Nígbà tí mo rí i)’ jẹ́ awẹ́-gbólóhùn àfarahẹ (dependent clause).


Olùwà (Subject) àti Kókó-gbólóhùn (Predicate): Gbólohùn abọ́dé (simple sentence) máa ń ní olùwà (subject) àti kókó-gbolóhùn (predicate). Ìyẹn  ni pé a lè pín gbólóhùn abọ́dé (simple sentence) sí olùwà (subject) àti kókó-gbólóhùn (predicate). Olùwà (subject) ni ó máa ń sábàá ṣáájú ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) nínú gbólóhùn (sentence). Lẹ́yìn olùwà (subject) yìí, gbogbo àwọn fọ́nrán (element) tí ó bá ṣẹ́kù nínú gbólóhùn (sentence) tí ó fi kan ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) ni a ń pè ní kókó-gbólóhùn (predicate). Àwọn àpẹẹrẹ olùwà (subject) àti kókó-gbólóhùn (predicate) ni ó wà ní (12):
    (12) Olùwà (Subject)                Kókó-gbólóhùn (Predicate)
    Òjó (Òjó)                                   laughed (rẹ́rìn-ín)
    Adé (Adé)                                  played football (gbá bọ́ọ̀lù)
The girl (Ọmọdébìnrin náà)            is very beautiful (lẹ́wà gan-an)
The police (Ọlọ́pàá (náà))            arrested the man (mú ọmọkùnrin náà)

Kókó-gbólóhùn (predicate) gbọ́dọ̀ ni ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) kan nínú, ó kéré tán.



Dídá Olùwà Mọ̀ (Identifying the Subject): A máa ń sábàá dá olùwà (subject) mọ̀ nípa bíbèèrè ìbéèrè tí who (ta) tàbí what (kí) bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Ẹ wo (13) àti (14):
    (13) (a) Olú laughed (Olú rẹ́rìn-ín)
    (b) Who laughed? (Ta ni ó rẹ́rìn-ín?)
    (c) Olú (Olú)
    (14) (a) The house is very beautiful (Ilé náà lẹ́wà gan-an)
    (b) What is very beautiful? (Kí ni ó lẹ́wà gan-an?)
    (c) The house (Ilé náà)
Tí  a bá wo gbólóhùn (sentence) tí ó wá ní (13a) tí a fi (13b) ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀, a ó rí i pé ọ̀rọ̀ tí a fi dáhùn ìbéèrè yìí ní (13c) ni Olú. Èyí fihàn pé Olú ni olùwà (subject) gbólóhùn (sentence) yìí. Bákan náà ni ní (14). Gbólóhùn  (sentence) tí ó wà ní (14a) ni a fi (14b) ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀ tí a sì fi the house (ilé náà) ní (14c) ṣe ìdáhùn rẹ̀. The house (ilé náà) tí a  fi ṣe ìdáhùn fún ìbéèrè what (kí) yìí ni olùwà (subject) fún gbólóhùn (14a).


Ní afikún, a tún lè dá olùwà (subject) mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà wọ̀nyí:
(15) Pípa àyè olùwà (subject) àti aṣèrànwọ́-iṣe (auxiliary verb) dà sí ara wọn nígbà tí a bá sọ gbólóhùn àlàyé di ìbéèrè (Subject-Auxiliary Inversion)
        (a) Gblólóhùn àlayé (Declarative Sentence): Ojo will dance (Òjó yóò jó)
        (b) Gbólóhùn Ìbéèrè (Interrogative Sentence): Will Ojo dance? (Ṣé Òjó yóò jó?)
Nínú gbólóhùn àlayé (declarative sentence) tí ó wà ní (15a), Òjó tí ó jẹ́ olùwà (subject) ni ó ṣaájú will (yóò) tí ó jẹ́ aṣèrànwọ́-ìṣe (auxiliary verb) ṣùgbọ́n ní (15b), a ti pa ipò àwọn méjèèjì dà sí ara wọn nínú gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence). Òjó tí ó jẹ́ olùwà (subject) ní (15a) tí ó ṣaájú tẹ́lẹ̀ ni ó wá tẹ̀ lé will (yóò) tí ó jẹ́ aṣèrànwọ́-ìṣe (auxiliary verb) ní (15b) ní ibi tí a ti yí gbólóhùn àlàyé (declarative sentence) padà sí gbólóhùn ìbéèrè (interrogative sentence).
  
 (16) Ìbámu olùwà (subject) àti ọ̀rọ̀-ìṣe (subject-verb agreement)
Olùwà (subject) gbọ́dọ̀ bá ọ̀rọ̀-iṣe (verb) tí ó tẹ̀ lé e mu ní iye (number), ìyẹn ní ẹyọ (singular) tàbí ọ̀pọ̀ (plural). Ẹ wo gbólóhùn (sentence) (17) àti (18).
    (17) Olùwà tí ó jẹ́ ẹyọ (singular subject): The man cries (Ọkùnrin náà pariwo)
    (18) Olùwà tí ó jẹ́ ọ̀pọ̀ (plural subject): The men cry (Àwọn ọkùnrin náà pariwo)
Nígbà tí olùwà (subject) jẹ́ ẹyọ (singular), ìyẹn the man (ọkùnrin náà), ọrọ-ìṣe náà jẹ́ ẹyọ (singular), ìyẹn cries (pariwo). Èyí ni a rí nínú gbólóhùn (17). Nínú gbólóhùn (sentence) (18), olùwà, the men (àwọn ọkùnrin náà), jẹ́ ọ̀pọ̀; ọ̀rọ̀-iṣe náà, cry (pariwo), sì jẹ́ ọ̀pọ̀.


Àkíyèsí kan tí  ó yẹ kí á ṣe ni pé nígbà tí ọ̀rọ̀-iṣe bá wà ni àsìkò (tense) ìsìnyí (present) nìkan ni ìbámu (agreement) yìí máa ń wáyé. Ní àsìkò ọjọ́un (past), ìbámu (agreement) yìí kìí wáyé. Àwọn gbólóhùn (19) àti (20) fi eléyìí hàn
    (19) Olùwà tí ó jẹ́ ẹyọ (singular subject): The man cried (Ọkùnrin náà pariwo)
    (20) Olùwà tí ó jẹ́ ọ̀pọ̀ (plural subject): The men cried (Àwọn ọkùunrin náà pariwo)
Nígbà tí olùwà (subject) jẹ́ ẹyọ ní (19), ọ̀rọ̀-ìṣe cried (pariwo) ni a lò. Nígbà tí ó sì tún jẹ́ ọ̀pọ̀ (plural) ní (20), ọ̀rọ̀-ìṣe cried (pariwo) náà ni a lò. Èyí fi hàn pé òfin ìbámu tí ó ṣiṣẹ́ ní (17) àti (18), nígbà ti àwọn gbólóhùn náà wà ní àsìkò ìsìnyí (present tense), kò ṣiṣẹ́ ní (19) àti (20) nígbà tí àwọn gbólóhùn náà wà ní àsìkò ọjọ́un (past tense).


Yàtọ̀ sí èyí, nígbà tí olùwà (subject) bá jẹ ẹni kẹ́ta ẹyọ (third person singular subject) nìkan ni òfin Ìbámu yìí máa ń ṣiṣẹ́. Òfin yìí kìí ṣiṣẹ́ nígbà tí olùwà (subject) bá jẹ́ ẹni kìíní ẹyọ àti ọ̀pọ̀ (first person singular and plural), ẹni kejì ẹyọ àti ọ̀pọ̀ (second person singular and plural) àti ẹni kẹ́ta ọ̀pọ̀ (third person plural). Àwọn gbólóhùn (sentence) (21) àti (22) fi eléyìí hàn.
    (21) Olùwà tí ó jẹ ẹyọ (singular subject)
        (a) I cry (Mo pariwo)    (b) You cry (O pariwo)
    (22) Olùwà tí ó jẹ́ ọ̀pọ̀ (plural subject)
        (a) We cry (A pariwo)    (b) You (pl.) cry (Ẹ pariwo)    (c) They cry (Wọ́n pariwo)
A ó rí i wí pé cry (pariwo) ni a lò nínú gbólóhùn (sentence) (21) àti (22). A kò lo cries (pariwo) fún ọ̀kankan nínú wọn.

No comments:

Post a Comment