Monday, 27 April 2015

Kémísìrì fún Alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ (Chemistry for Beginners) - Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kìíní (First Lecture)

L.O. Adéwọlé àti A.A. Fábẹkú



Kí ni Kẹ́mísírì? (What is Chemistry?)

Kẹ́mísírì  jẹ́ ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì àrígbéwọ̀n  tí ó ṣe é dán wò . Ó tún jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí ó ń kọ ni nípa èròjà , ìhun  àti ìyídà  ohun-ẹ̀dá (substance) tí ó wà nínú àgbálá ayé .


Kí ni Ẹ̀dá? (What is Matter?)
Ẹ̀dá  ni ohunkóhun ti ó bá ní ìwọ̀n-okun  tí ó sì gba àyè. Ohun tí a ń pè ní ẹ̀dá yìí lè tóbi ó sì lè kéré. A lè fi ojú rí i (tí ó bá tóbi tó nǹkan tí a lè fojú rí) tàbí kí a má lè fi ojú rí i (tí ó bá kéré ju ohun tí a lè fojú wa lásán rí tí ó jẹ́ pé yóò nílò awò amóhuntóbi (magnifying glass) kí á tó lè rí i). Ṣùgbọ́n sá o,  ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé bí ó ti wù kí nǹkan náà kéré tó, ohunkóhun tí ó bá ti ní ìwọ̀n-okun (mass) àti ìwúwo (weight) , ẹ̀dá ni. Ìwọ̀n-okun (matter) àti ìwúwo (weight) bá ara wọn tan, ṣùgbọ́n, síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn gédégédé. Àwọn àpẹẹrẹ ẹ̀dá ni afẹ́fẹ́, omi, òkúta, igi, gbogbo ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ènìyàn, àwọn alùgbinrin àti gbogbo ohun tí ó yí wa ká, yálà èyí tí a lè fi ojú rí tàbí èyí tí a o kò lè fi ojú rí.


Kí ni Ìwọ̀n?
Ìwọn ni iye  ẹ̀dá (matter) tí ó wà nínú ohun-ẹ̀dá (substance). Ìwọ̀n ni àbùdá tí ẹ̀dá ní tí ó fi máa ń fẹ́ wà loju kan láìparadà tàbí kí ó máa lọ láìdúró.

Kí ni Ìwúwo (Weight)?
Ìwúwo (weight) ni ìmọ̀lára ipa tí òǹfà ayé (gravity) ní lórí ìwọ̀n (mass) .


Àbùdá  Ẹ̀dá
A lè dá ẹ̀dá (matter) mọ̀ nípa wíwo oríṣiríṣi àbùdá tí ó ní. Oríṣi àbùdá méjì ni ẹ̀dá ni. Èkíní ni àbùdá òde  tí ẹ̀dá ní. Èkejì ni àbùdá inú  tí ẹ̀dá ní. Àbùdá ẹ̀dá jẹ́ èyí tí a lè rí, tí a lè fi ọwọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n nípa lílo ojú wa, etí wa, ahọ́n wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé a máa nílò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀rọ kí á tó lè lo ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara tí a kà sókè wọ̀nyí kí ó tó lè mọ àbùdá ẹ̀dá .


Àwọn Abùdá Òde tí Ẹ̀dá Ní


Ìtọ́wò: Ìtọ́wò (taste) ni ó ń jẹ́ kí á mọ bí nǹkan kan bá dùn tàbí ó korò tàbí ó kan.


Àwọ̀: Àwọ̀ (colour) ni ó jẹ́ kí á mọ bóyá funfun ni nǹkan kan tàbí gbúre (pink) tàbí pupa (red) tàbí òfeefèé (yellow) tàbí omi ọsàn (orange), tàbí sányán  (brown) tàbí dúdú tàbí aró (blue) tàbí eérú (grey) tàbí ẹsẹ̀ àlùkò (purple).


Òórùn: Òórùn (odour) nǹkan lè jẹ́ òórùn kíkan, òórùn dídùn, òórùn ìdíbàjẹ́, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


Yíyòòrò:Yíyòòrò (solubility) níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan kan lè yòòrò tàbí kí ó yọ́ kí ó di omíyòrò .


Líle: Líle (hardness) níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ le, ṣé ó ṣòro láti tẹ̀, ṣé ó ṣòro láti gé, ṣé ó ṣòro láti kán tàbí pé ṣe ni nǹkan náà dúró ṣinṣin.


Dẹ́ńsítì: Eléyìí ní í ṣe pèlú fífúyẹ́ tàbí wíwúwo nǹkan  tí a bá fi ojú àlàfo tí nǹkan náà gbà  wò ó. A lè rí nǹkan kan tí ó tóbi tí ó sì fúyẹ́ a sì lè rí nǹkan kan tí ó kéré tó sì wúwo. Tí a bá ti ń fi ojú àbùdá fífúyẹ́ tàbí wíwúwo yìí wo nǹkan, ojú dẹ́ńsítì ni a fi ń wo nǹkan náà nìyẹn.


Ìṣeé-fìrọ̀rùn-yí-padà : Àwọn ohun ẹ̀dá  (substance) kan wa tí ìrísí wọn rọrùn láti yí padà. Bí àpẹẹrẹ, alugbinrin  ka tí ó rọrùn láti yí ìrísí rẹ̀ padà sí ìrisí mìíràn ni òjé (lead). Bí irísí òjé bá rí pẹlẹbẹ, a lè yí i pa sí gígùn gbọọrọ bí okùn.  Bí ìrísí rẹ̀ bá sì rí gbọọrọ bí okùn, a lè yí i padà sí pẹlẹbẹ.


Ìrísí Ìdì : Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé bóyá ohun ẹ̀dá kan ti dì tàbí kò dì tí ó sì ní ìwò  kan tàbí òmíràn.


Bí Ìwò Nǹkan Kan Ṣe Rí Nígbà tí Ìgbóná Ojú  Ọjọ́ bá bá ti Inú Ilé Dọ́gba : Ní àsìkò tí ojú ọjọ́ kò gbóná jù tí kò sì tutù jù yìí, ǹjẹ́ a lè sọ pé ẹ̀dá  jẹ́ ohun tí ó dì  tàbí ohun tí ó jẹ́ olómi  tàbí kí ó jẹ́ gáàsì .


Ọ̀gangan Yíyọ́ : Ọ̀gangan yíyọ́ yìí ni ibi tí ìgbóná  yóò dé tí ohun-ẹ̀dá yóò fi yọ́ tàbí kí ó yòòrò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbóná tàbí iná tí yóò mú orí  yọ́ tàbí kí ó yòòrò kò lè tó èyí tí yóò mú irin yọ́. Ìyẹn ni pé iná tí yóò mú irin yọ́ yóò ju ti òrí lọ. Ọ̀gangan yíyọ́ ni ibi tí nǹkan abara líle máa ń gbóná dé kí ó tó di olómi.


Ọ̀gangan Híhó : Ọ̀gangan híhó ni ibi tí iná yóò se nǹkan dé tí nǹkan olómi náà yóò fi máa hó tàbí ibi tí ìgbóná yóò wọ inú nǹkan oĺómi tí ó fi máa hó. Ọ̀gangan híhó yìí ni nǹkan olómi ti máa ń di nǹkan aláfẹ́fẹ́, ìyẹn gáàsì. Bí àpẹẹrẹ, epo tètè máa ń hó ní orí iná ju omi lọ. Èyí fi hàn pé ìgbóná tí yóò mú epo yí padà sí afẹ́fẹ́ kò lè tó ti omi.



A kò lè ṣe ìgbéléwọ̀n  bí ìtọ́wò (taste) àti òórùn ṣe tó. A lè ṣ ìgbéléwọ̀n àwọn àbùdá yòókù.



Endnotes


Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, a ń pe nǹkan kan ní substance. Substance ni a lè pè ní ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀dá (ohun ẹ̀dá, ìyẹn ohun tí a dá) tí ó jẹ pé a lè fi ojú rí tàbí kí a fọwọ́ kàn tàbí kí ó ṣeé wọ̀n. Tí a bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí a ń pè ní substance yìí àti ọ̀nà tí a fi lè tò ó (combine) mọ́ irú rẹ̀ mìíràn tàbí kí ó torí nǹkan  tí ó ṣẹlẹ̀ sí irú rẹ̀ mìíràn ṣe nǹkan kan (react), irú ẹ̀kọ́ yìí ni a ń pè ní Kẹ́mísírì. Ìyẹn ni pé Kẹ́mísírì níí ṣe pẹ̀lú àtòpọ̀ (combination) tàbí ìtakora (reaction) ohun ẹ̀dá (substance).


Àrígbéwọ̀n ni ohun tí a lè fojú rí tàbí tí a lè fọ́wọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n.


Tí a bá dán nǹkan wo, a fẹ́ mọ bí nǹkan náa ti rí ni.


Tí a bá fọ́ nǹkan kan sí wẹ́wẹ́, ohun tí a bá bá nínú rẹ̀ ni èròjà nǹkan náà.


Bí a ṣe to nǹkan pọ̀. Ètò tí nǹkan kan ní ni a ń pè ní ètò nǹkan náà.


Àyídà tàbí ìyídà máa ń yí nǹkan padà ni, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kí nǹkan náà lè dára sí i.
 
Àgbálá ayé (universe) dúró fún  àwọn ìràwọ̀ àti ayé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mìíràn tí ó yí oorùn po.
 
Ẹ̀dá tàbí èròjà ẹ̀dá dúró fún matter. Ẹ̀dá yìí ni ohun-ẹ̀dá (substance) tí a lè fi ojú rí tàbí tí a lè fi ọwọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n.
 
Mass ni a ń pè ní ìwọ̀n-okun nínú Kẹ́mísírì. Tí ó bá jẹ́ inú ẹ̀kọ́ Físíìsì (Physics) ni, ìṣù tàbí títóbi nǹkan ni a ó pè é.
 
Weight yìí ni a ń pè ní ìtẹ̀wọ̀n nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì (Physics). Lára oríkì (definition) tí a lè fún ìtẹ̀wọ̀n (weight) nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì (Physics) ni (i) ipá (force)  tí ó dorí kọlè tí nǹkan kan ní nítorí títóbi (mass) rẹ̀ (ii) ìmúrasáré (acceleration) nítorí ìfàlọsílẹ́ ilẹ̀ ayé (gravitational pull).
 
Ayé ní òǹfà tí ó fi máa ń fa àwọn ohun tí ó wà ní inú rẹ̀ (ìyẹn àwọn ohun tí ó wà ní inú ayé) wá sí orí ilẹ̀ tàbí kí ó fa nǹkan náà mọ́ra. Èyí ni a ń pè ní ipa òǹfà (force of gravity).
 
Àbùdá ni ìrísí tí nǹkan kan ní. Èyí ni ohun tí a máa ń wò mọ́ nǹkan kan lára tí ó fi yàtọ̀ sí nǹkan mìíràn.
 
Physical properties ni àwọn àbùdá òde tí èdá ni.
 
Chemical properties  ni àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ní.
Bí àpẹẹrẹ, bí nǹkn kan bá kéré jù, a lè nílò awò amóhuntóbi (magnifying glass) kí a tó lè rí àbùdá rẹ̀ dáadáa.
 
Solution ni a ń pè ní omíyòrò.
 
Àlàfo tí nǹkan kan gbà ni a ń pè ní volume nǹkan náà.
 
Malleability ni a ń pè ní ìṣeé-fìrọ̀rùn-yí-padà.


Metal ni a ń pè ní alùgbinrin. Alùgbinrin dúró fún ohun tí ó lè dún bí irin bí a bá lù ú.
 
Crystalline form ni a ń pè ní ìrísí ìdì.
 
Shape ni a ń pè ní ìwò.
 
Physical shape at room temperature ni èyí dúró fún. Ní àsìkò yìí ni a máa ń sọ pé nǹkan kan kò gbóná, kò tutù.
 
Matter ni a pè ní ẹ̀dá.
 
Solid ni a pè ní ohun tí ó dì. Èyí ni nǹkan tí ó jẹ́ abara líle tí ó ṣeé gbámú.
 
Liquid ni a pè ní olómi.
 
Nǹkan aláfẹ́fẹ́ ni gáàsì, bí àpẹẹrẹ, isó, afẹ́fẹ́ tàbí ooru. Gaàsì kò seé gbámú bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé mú dání. A lè bu omi dání ṣùgbọ́n kò ṣeé gbámú. A lè gbá nǹkan tí ó bá dì mú bẹ́ẹ̀ ni a lè gbé e dání.
 
Melting point ni a ń pè ní ọ̀gangan yíyọ́.
 
Temperature  ni a pè ní ìgbóná.
 
Shea-butter ni a pè ní òrí.
 
Boiling point ni a ń pè ní ọ̀gangan híhó.
 
Quantitative evaluation ni a pè ní ìgbéléwọ̀n bí wọ́n ṣe tó. Bí wọ́n ṣe tó yìí lè jẹ́ nípa kíkà tàbí wíwọ́n. Bí àpẹẹrẹ, a kò lè ka òórùn tàbí kí á wọ̀n ọ́n bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka ìtọ́wò tàbí kí a wọ̀n ọ́n. Ìyẹn  ni pé a kò lè ka bí kíkan ni nǹkan kan ṣe rí lẹ́nu nígbà tí a tọ́ ọ wò tàbí dídùn.

No comments:

Post a Comment