Friday 3 August 2018

È̩MÍ ÌN MI È̩MÍ ÌN RE̩


LÁTI O̩WÓ̩
ALÀGBÀ O̩LÁTÚBÒ̩SUN O̩LÁDÀPÒ̩ (ODÍDE̩RÉ̩ AYÉKÒÓTÓ̩)[1]
Iwé yì́ jé̩ ìwé ewì àpilè̩ko̩, ò̩kan lára òpó mé̩ta tó gbé lítírés̩ò̩ èdè yòówù ró. Àwo̩n méjì tó kù ni eré onís̩e àti ìtàn àròso̩ o̩ló̩rò̩ geere. Akéwì àti òǹkò̩wé tí ìmò̩ rè̩ pò̩ re̩pe̩te̩ ni olóyè O̩látúbò̩sún O̩ládàpò̩. S̩e àròyé ni is̩é̩ ìbákà, igbe kíké nis̩é̩ e̩ye̩. Ewì kíké ni is̩é̩ ti òǹkò̩wé yìí yàn láàyò. Àgba sò̩rò̩sò̩rò̩ óri rédíò àti te̩lifís̩àn tí ó peregedé ni alàgbà O̩ladapọ. O̩mo̩ ìlú Ìbàdàn ni í s̩e.
     Òpò̩lo̩pò̩ ìwé lóníranǹran ni àgbà òǹko̩wé yìí ti gbé jáde. Lára wo̩n ni Aròyé Akéwì, E̩gbè̩ta Òwe ‘A’, E̩gbè̩ta Òwe ‘B’, E̩gbe̩ta Òwe ‘D’ ati bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩.
NÍPA ÌWÉ EWÌ È̩MÍ-ÌN MI- È̩MÍ-ÌN-RE̩
Ewì ìfé̩ pátápátá ni ìwé náà láti ìbè̩rè̩ dé òpin. Ò̩rò̩ nípa ìfé̩ láko̩lábo àti ló̩ko̩láya sì ni pè̩lú. Ewì mó̩kànlélógún ni ó wà nínú ìwé náà, èyí náà ni ó sì mú kí ó ní orí mó̩kànlélógun ò̩tò̩ọ̀tò̩.
KÓKÓ TÍ EWÌ KÒ̩Ò̩KAN DÁ LÉ
(1)  È̩MÍ-ÌN MI- È̩MÍ-ÌN-RE̩
Akéwì ń fé̩ kí Oyínkánó̩lá fi gbogbo ara re̩ sílè̩ fún un pátápátá ó sì ń fé̩ o̩mo̩bìnrin náà ti s̩e pàtàkì sí i tó. Èyí ni ó fi so̩ ní ìlà ke̩tàlélógún sí iké̩rìndínló̩gbò̩n pé:
                      Bí wó̩n bá je̩yán dùn mí- N ò ní í bèèrè:
                      Bí wo̩n je̩kà dùn mí- N ò ní í bèèrè:
                      E̩ní bá fi ó̩ dùn mí Oyínkánó̩lá,
                      Olúwa rè̩ ní ń wájà e̩le̩ye̩
Akéwì sì tún so̩ fún olólùfé̩ rè̩ yìí pé òun kò déédé máa wá a kiri bíkòs̩e ti àwo̩n àmumye̩ tí ó ní. Ó sì tún so̩ pé bí ó tilè̩ jé̩ pé gbogbo o̩kùnrin ilè̩ yìí ni ó wù kó fé̩ e̩, ó ní ojú ni wó̩n fi rí i, ètè wo̩n ò leè bà a. Ó wá parí ò̩rò̩ rè̩ pé ibi yòówù kí olóbùró òun yìí lo̩, òun yóò bá a lo̩ kódà bó s̩e àjùlé ò̩run.


(2)   ÌPÍNHÙN LA MÙGBÀ ÈJIGBÒ
Kókó pàtàkì tí akéwì ń so̩ nínú ewí yìí ni pé òun fé̩ kí olólùfé̩ òun kúkú fara mó̩ òun nìkan. Ó ní òun kìí ba ènìyàn pín e̩ran je̩. Ìye̩n túmò̩ sí pé òun kò lè bá o̩kùnrin kankan pín obìnrin fé̩. Bé̩è̩ ló sì tún so̩ pé òun kìí s̩e è̩mì tí kìí sunlé àná. Ó wá parí ewì náà pé kí o̩mo̩bìnrin náà jé̩ kí àwo̩n jo̩ s̩e ìpinnu kí àwo̩n tó bè̩rè̩ ìfé̩ àwo̩n.

(3)  À-BÉ̩-WO̩LÉ
Ìbéèrè ni akéwì ń fi ewì yìí bèèrè. Ìbéèrè ò̩hún kò sì rújú rárá. Akéwì ń fé̩ mò̩ bóyá ò̩rò̩ fífé̩ra tó wà láàárín o̩kùnrin àti obìnrin náà yóò jé̩ fífé̩wo̩lé tàbí àfé̩gbéjùsílè̩ gé̩gé̩ bí ò̩pò̩ ò̩dó̩ ti ń s̩e. Ó sì tún fé̩ mò̩ bóyá is̩é̩ ìfé̩ tí ń be̩ láàárín wo̩n yóò já sí às̩ejèrè tàbí às̩edànù.

(4) NÍS̩ULÓ̩KÀ
Àwa ò̩dó̩ òde òní ni Akéwì dojú ewì yìí ko̩ jù ní pàtàkì. Ó ń so̩ fún wa pé kí a wo o̩ko̩ tàbí aya tí a fẹ́ fé̩ dáadáa. Ó s̩àlàyé pé ìyàwó tá a bá s̩e è̩tó̩ lé lórí, tí a fé̩ nís̩uló̩kà kìí sábà ko̩ni ṣsùgbó̩n èyí tí a bá gba ò̩nà è̩bùrú fé̩, yóò padà gba ò̩nà yòówù tó gbà wá padà lo̩. Akéwì wá ń so̩ fún ìyàwó rè̩ pé kó má ko̩ òun, torí pé òun fé̩ e̩ nís̩ulo̩kà ni.

(5)   ÒTÈ̩ LÓRÍ ÌFÉ̩
Akéwì ń so̩ pé òun kò ko̩ ohun tó lè s̩e̩lè̩ nítorí e̩ni tí òun fé̩ fé̩. Ó wá n ́ dojú ò̩rò̩ ko̩ e̩ni yòówù tí yóò dúró gé̩gé̩ bí alátakò tàbí olùbádíje, tí àwo̩n yóò jo̩ wò̩yá ìjà látàrí àtifé̩ e̩ni tí òun yán láàyò. Ó fi kún un pé bí òun bá ríkú tàbí àrùn he nítorí èyí, òun á mo̩ èrèdí ikú tàbí àrùn náà. Ó parí ò̩rò̩ rè̩ pé ‘Bèrùbè̩rù kì í fáre̩wà níyàwó’. Ìye̩n ni pé are̩wà ni e̩ni tí Akéwì ń sò̩rò̩ ìfé̩ nípa rè̩.

(6)  ÀÀYÒ
Kókó ewì yìí ni yíyàn tí o̩ko̩ máa ń yan ìyàwó láàyò. Bí ó ti wù kí àwo̩n ìyàwó pò̩ tó lé̩è̩dè̩ o̩ko̩, ìwà ní í so̩ ìyàwó kan di ààyò o̩ko̩ rè̩. Akéwì so̩ pé O̩ya kìí s̩e ìyàwó àkó̩fé̩ (ìyálé), bé̩è ni kì í s̩e àfé̩gbè̩yìn. S̩ùgbó̩n òun ni ààyò S̩àngó látàrí àwo̩n ìwà tó ń hù tó sì dára. Akéwì fé̩ kí ìyàwó mo̩ bí a s̩e ń tu o̩kó̩ lójú, kí ó sì mo̩ ohun tí o̩ko̩ fé̩ àti èyí tí kò fé̩. Ó ní èyí ni ohun tó fà á tí ò̩pò̩ obìnrin kì í fi gbélé o̩ko̩.

(7)    AYA-O̩DÒ̩
Akéwì ń fi ewì yìí so̩ pàtàkì ìyàwó ní ò̩dè̩dè̩ o̩kùnrin. Ó s̩àlàyé àwo̩n àmúye̩ àti àbùdá ìyàwó. Lóò̩ó̩tó̩ ni wó̩n máa ń dàbí o̩mo̩-ò̩dò̩, òótó̩ ibè̩ ni pé olùrànló̩wó̩ pàtàkì ni wó̩n jé̩ fún o̩kùnrin. Ló̩jó̩ oúnje̩ wíwá, ìtó̩jú o̩ko̩, ìtó̩jú o̩mo̩, àgàgà tó bá tún wá di láàjìn tí o̩ko̩ fe̩ s̩eré oge, aya yìí náà ni. Akéwì wá mo̩ rírì ìyàwó rè̩ pé òun (ìyàwó) náà ni kò jé kí òun (o̩ko̩) di àpó̩n e̩lé̩è̩kejì. Ó parí ò̩rò̩ rè̩ pé aya-ò̩dò̩ ni ìyàwó òun, kìí s̩e o̩mo̩-ò̩dò̩.

(8)   ÒWÒ O̩MO̩
Ìbálòpò̩ tako̩-tabo ni ewì yìí dá lé. Akéwì so̩ pé ìbálòpò̩ ako̩ àti abo kò dá lórí ohun méjì bí kò s̩e ò̩nà láti di o̩ló̩mo̩ láyé. Ó dárúko̩ eku e̩dá, e̩ja, e̩ye̩ àti àfèbàjò tí gbogbo wo̩n ń s̩ere tako̩-tabo. Akéwì so̩ pé eré o̩mo̩ ni wó̩n ń s̩e.

(9)  AYÉE KÍ LO WÁ?
Ní ìbè̩rè̩ ewì yìí, Akéwì ń bá àwo̩n ènìyàn tí wó̩n ń s̩e ohun tí ipá wo̩n kò ká wí. Ó fé̩ kí àwo̩n ìsò̩wó̩ tí wó̩n ń ko̩já àyè wo̩n máa bára wo̩n s̩e pò̩. Ó so̩ pé ó ye̩ kí o̩ko̩ àti aya mo̩ ìwà ara wo̩n, torí ‘Mò̩wà fóníwà ní ń jé̩ ò̩ré̩jò̩ré̩’. Akéwì ní bí ayálégbé ni o̩ko̩ àti aya tí wo̩n kò mo̩ ìwà ara wo̩n. Ní ìparí, Akéwì so̩ pé òun kò fipá wá owó kiri ayé, àmó̩ owó lè wá òun wá.

(10)  ORÒ ÀPÓ̩N
Akéwì ń gbìyànjú láti so̩ fún wa nínú ewì yìí pé ojú àpó̩n máa ń rí tó. Ó mo̩ rírì kí o̩kùnrin ní aya ló̩ò̩dè̩. Ìye̩n náà ló s̩e so̩ pé àwo̩n kan máa ń wí pé bí ìyàwó àwo̩n bá tò̩ sílé, àwo̩n ó le lo̩. Akéwì ní òun kò níí lé irú aya bé̩è̩ lo̩ ní tòun, kàkà bé̩è̩ ìgbèrí rè̩ lòun yóò máa sùn. Ohun tó so̩ ni pé
Torí fòfòròfoforo imú ìyàwó
  Ó sàn fó̩ko̩ ju yàrá òfìfo lo̩ ni:
            Onítò̩ ìyàwó sàn ju yàrá ànìkànsùn.
Akéwì wá s̩e ìkìlò̩ fún àwo̩n aláyo̩nuso̩ pé kí wó̩n jé̩ kó̩ko̩ máa gúnyán, kó máa lo̩ta, kí wó̩n má sì s̩e jé̩ kí o̩ko̩ tún di àpo̩n e̩lé̩è̩kejì.

(11)  ADÉFÚNMIKÉ̩
Akéwì fi ewì yìí perí olólùfé̩ rè̩ tí ó ń jé̩ Adéfúnmiké̩ Fásànyà. Akéwì jé̩ kí a mò̩ pé o̩mo̩ge yìí kìí rí àyè jáde bó s̩e fé̩ débi tí òun yóò fi máa rí i. Akéwì s̩e àpèjúwe Adéfúnmiké̩ yìí gé̩gé̩ bí o̩mo̩lúwàbí tí kì í gbó àwo̩n òbí rè̩ lé̩nu, oníwà tútù, tó tún máań s̩e ò̩yàyà. Bó s̩e níwà gidi tó náà ni e̩wà ara rè̩ pò̩ tó. Akéwì so̩ pé:
 Ó gún régé teyínteyín
       Ó pó̩n ròdòrodo te̩sè̩te̩sè̩
                     Bó wo̩s̩o̩ funfun ló̩jó̩ ò̩sè̩ ìgbàgbó̩
 A rí bí ańgé̩lì látò̩run.
Akéwì, níparí ewì rè̩, dojú ò̩rò̩ ko̩ olólùfé̩ rè̩ pé o̩jó̩ ń bò̩ táwo̩n yóò jo̩ máa gbádùn ara wo̩n, ti àwo̩n aláàbò tó ti ń dé e mó̩lè̩ bí àran àpótí (ìye̩n àwo̩n òbí Adéfúnmiké̩) yóò tu sílè̩ nínú ìdè.

(12)  LÓ̩WÓ̩ E̩ LÓ WÀ
Akéwì fi ewì náà so̩ bí òun s̩e gbára lé aya òun tó. Ó hàn gbangba pé gbogbo ayé Akéwì náà ló ti gbé lé ìyàwó rè̩ ló̩wó̩, kò sì sí ohun kan tí ìyàwó náà kò mò̩ nípa gbogbo ìgbésí ayé o̩ko̩ rè̩ bákan náà. Bí ó tilè̩ jé̩ pé èyí dára ó sì sunwò̩n, ewu ń be̩ níbè̩ púpò̩. Èyí ni Akéwì rò tó fi so̩ pé
             Bóúnje̩ òkè di májèlé
Ìwo̩ lo mò̩ ó̩n
               Bóúnje̩ ìsàlè̩ di májèlé
Ìwo̩ lo mò̩ ó̩n
              E̩ni bá mo̩ni délédélé
   N ní í s̩e ni níbi

(13)  ÌDÀÀMÚ OLÓBÙRÓ
Ewì yìí ń so̩ bí gbogbo o̩kùnrin s̩e máa ń de̩nu ìfé̩ ko̩ ò̩dó̩mo̩bìnrin. Gbogbo o̩kùnrin are̩wà máa ń wù. Èyí sì máa ń sábà kó ìdààmú àti fìtìnátì bá àwo̩n o̩ló̩mo̩ge. Akéwi so̩ bí ò̩gò̩ò̩rò̩ àwo̩n o̩kùnrin ti ń wá. Bí olówó s̩e ń wá ni o̩ló̩rò̩ ń wá, bí e̩ni rere s̩e ń de̩nu ìfé̩ ko̩ ó̩ náà ni ó ń wu àwo̩n ènìyàn búburú náà. S̩ùgbó̩n Akéwì wá ń fi o̩kàn ò̩dó̩mo̩bìnrin balè̩ pé kó máa wò wó̩n lóye, àti pé láìpé̩ jo̩jo̩ ni yóò re̩ àwo̩n tí ó ń wá. Orí o̩ló̩mo̩ge á wá yan o̩ko̩ tirè̩ gangan fún un, torí pé orí ní ó ń yan o̩ko̩ àtàtà fóbìnrin.

(14)  ADÓ
Ò̩nà tí Akéwì gbà gbé ewì yìí kalè̩ s̩e àrà ò̩tò̩ gédéńgbé. Ìdí ni pé gbogbo ìlú tó dárúko̩ nínú ewì náà ló ní ohun kan tàbí òmíràn s̩e nípa bíbá obìnrin sùn. Bí a bá wo Adó tíí s̩e àkó̩lé ewì náà, a mò̩ pé ìlú kan nílè̩ Yorùbáni lóòótó̩. S̩ùgbó̩n ohun tí Akéwì ń so̩ gangan ni ò̩rò̩ ‘dó’ tó túmò̩ sí bíbá obìnrin s̩e eré ló̩ko̩-láya. Ó dárúko̩ Ìsokó àti Ìsòbò gé̩gé̩ bí ìlú, s̩ùgbo̩n è̩yà ara o̩kùnrin àti obìnrin tó ń s̩is̩é̩ ìbálòpò̩ ni Akéwì fi ò̩nà è̩rò̩ gbé kalè̩. Ó ni:
                Ara ohun tá a wáyé wá s̩e yìí náà ni
      E̩ni bá bímo̩ Ìlawè̩: oríire ló s̩e
Ò̩nà Ìgbàrà méjèèjì le̩ gbà.
Láìsí tàbí-s̩ùgbó̩n, ò̩rò̩ ibi àṣírí takọtabo ni Akéwì ń fi ewì yìí so̩. Èyí ló fi gba àwo̩n o̩kùnrin ní ìmò̩ràn ni ìlà mé̩ta tó gbè̩yìn pé:
È̩yin Arìnrìnàjò Àdó
E̩ máa tè̩ é̩ jé̩jé̩ o
Ké̩ e̩ le gúnlè̩ sí Àdó ÀWÁYÈ.

(15)  Ò̩S̩ÙNGBÈ̩GÉ̩
Awe̩lé̩wà obìnrin kan ni Akéwì fi wé ò̩s̩ùn etí omi - irúfé̩ ewéko kan tó dára tó sì máa ń dán láwò̩. Bó tilè̩ jé̩ pé ewé ipín dúdú, àmó̩ kò rí múló̩múló̩ ló̩wó̩. Bé̩è̩ náà sì ni tè̩tè̩rè̩gún fi gbogbo ara s̩e è̩gún. Àwo̩n wò̩nyí ni a lè fi wé àwo̩n o̩ló̩mo̩ge tó buré̩wà. Akéwì sò̩rò̩ nípa e̩wà àto̩wó̩dá àti e̩wà àmútò̩runwá. Dájúdájú, ènìyàn dúdú nini tó sì ń dán ni o̩mo̩ge ti Akéwì ń ya àwòrán rè̩ sí wa ló̩kàn yìí. Ó so̩ ní ìlà mé̩ta tó gbè̩yìn pé:
Ò̩s̩ùngbè̩gé̩ lo̩mo̩ tó wù mí
Dúdú lójúu rè̩ ń jò geregere:
Ikùn rè̩ ni, ààlà funfun gbòò.

(16)  O̩MO̩ S̩Ó̩JÀ (ORIN O̩LÓ̩MO̩GE)
Ewì yìí ni jé̩ orin tí àwo̩n o̩ló̩mo̩ge ayé àtijó̩ máa ń ko̩. Ó dá lórí o̩mo̩ge àti o̩kùnrin S̩ó̩jà kan. Nínú ewì náà ni o̩mo̩ge yìí ti ń so̩ ìrírí rè̩ pè̩lú S̩ó̩jà kan tí ó pàdé òun àti àwo̩n ò̩ré̩ rè̩ tí wó̩n jo̩ jé̩ mé̩ta. S̩ó̩jà yìí bè̩é̩ kó tè̩lé òun kálo̩. Nígbà tí o̩mo̩ge yìí kò̩, S̩ó̩jà forí Ajé àti Yárábì bè̩è̩ títí tí wó̩n fi délé S̩ó̩jà tí wo̩n wo̩ pálò̩, tí wó̩n tún wo̩ yàrá. Lé̩yìn èyí ni S̩ó̩jà sé wíńdò, tí òun wá ń ké yéyèéyèé!!! Áyìí ni ó ṣe lóyún tí ó bímọ fún ṣọ́jà.

(17)  ÀTAN-GBÉ-TAN
Nínú ewì yìí, jo̩ún pé Akéwì náà fé̩ràn o̩mo̩bìnrin kan tó re̩wà, tó dúdú, tó ń dán tó sì pèjí òkè. S̩ùgbó̩n s̩á, àwo̩n òbí àwo̩n o̩mo̩ méjèèjì náà wá fi ìtàn balè̩ pé e̩bí ni wó̩̩n àti pé wo̩n kò lè fé̩ra wo̩n. Ò̩rò̩ yìí jé̩ è̩dùn o̩kàn gidi fún Akéwì yìí. Bí ó tilè̩ jé̩ pé ó dùn ún wo̩nú egungun, síbè̩ ó gba kámú. Ìye̩n náà ló rò tó so̩ pé:
A jé̩ wí pé
Bó̩mo̩ e̩ni bá dára- ká wí lásán ni
Àwòmó̩jú ni só̩yà á wò̩gè̩dè̩!!!

(18)  IKÚ E̩NIAFÉ̩ ÀDÙKÉ̩ ADÉLÉKÉ

Ewì ìdárò pó̩nmńbélé ni ewì yìí. Ikú tí Àdùké̩ yìí kú dun Akéwì gidi. Ó jo̩un pé olólùfé̩ Akéwì nígbà kan ni Àdùké̩ ò̩hún. Akéwì so̩ ti e̩wà tó wàyàmì, ojú tó gún régé, àbàjà lójú olóbùró, àmó̩ tí Àdùké̩ ti gbé gbogbo rè̩ wo̩sà. Àdùké̩ dágbére fún Akéwì nígbà tó ń re àjò láláìmò̩ pé è̩dà ò̩rò̩ ni Àdùké̩ ń so̩ nígbà tó so̩ pé kí ojú má ko̩ àtúnrí. Akéwì wá so̩ pé àsìkò tòun kò tíì pé ló jé̩ kóun pada, àti pàápàá pé kòtò òkú tí wó̩n wà kò gba e̩ni méjì. Ó ní ààyè Àdùké̩ ló wu òun.

(19)  RÁRÀ ÀTI SIN ÌYÀWÓ
Akéwì ń fi ewì yìí s̩e ìkìlò̩ fún ìyàwó tó s̩è̩s̩è̩ ń relé o̩ko̩. Ilé o̩ko̩ ni Akéwì pè ní òkè tí wo̩n kì í ti í jà. Ó so̩ fún ìyàwó às̩è̩s̩è̩gbé pé kó má s̩e s̩ú àwo̩n òbí o̩ko̩ lóhùn. Ìké̩ àti ìgè̩ ni kó je̩ é̩ lógún.

(20)  MO-TÚN-RÁYÒ̩
Akéwì ń fi ewì yìí s̩e àpó̩nle àti ìmo̩rírì Àjo̩ké̩ tó jé̩ olólùfé̩ rè̩. Akéwì jé̩ kí a mò̩ pé Àjo̩ké̩ ló mú ayò̩ tó ti lo̩ nípasè̩ obìnrin àkó̩kó̩ padà wá. Obìnrin àkó̩kó̩ tí a sò̩rò̩ rè̩ yìí fi ojú Akéwì han èèmó̩. Akéwì s̩e àfihàn rè̩ gé̩gé̩ bí obìnrin búrúkú s̩ùgbó̩n ti Ajo̩ké̩ kò rí bé̩è̩. Akéwì so̩ fún Àjo̩ké̩ pé:
                       Ìwo̩ kò délé e̩lé̩bo̩lóògùn rí
                                           Ìwo̩ kìí filé ìjo̩sìn s̩e bojúbojú bíi tiwo̩n
Jésù ló̩sàn-án
               È̩mí ès̩ù tó bá di láàjìn
Ó wá fi to̩kànto̩kàn s̩e àdúrà fún Àjo̩ké̩. Ó sì fi dá a lójú pé àti òkú òun àti ààyè òun, ti Àjo̩ké̩ ni. Akéwì, níparí ò̩rò̩ rè̩ wá ń dunnú pé òun ò mò̩ pé òun tún lè rí ayò̩.

(21)  ORIN OLÓLÙFÉ̩
Orin olólùfé̩ tí Akéwì  fi kádìí ìwé ewì yìí ni ó túbò̩ fi ìdí rè̩ múlè̩ pé ìwé ewì ìfé̩ po̩nḿbélé ni ìwé náà. Akéwì ń fi ewì náà dá olólùfé̩ rè̩ lójú pé ohun yòówù tí ì bá à máa s̩e̩lè̩, àwo̩n jo̩ wà fún ara àwo̩n ni. Ó ní ayé ì bá à paré̩, kódà kí ò̩run tún paré̩, òun àti olólùfé̩ òun yìí yóò jo̩ wà ni.

ÀWO̩N O̩NÀ ÈDÈ YORÙBÁ TÓ SÚ YO̩
Àwo̩n o̩nà èdè Yorùbá ń tawó̩-tasè̩ nínú ìwé ewì yìí. Lára àwo̩n o̩nà èdè náà nìwò̩nyí:
Àfidípò: Ìwo̩ Olóbùró mi; Kó má a bísunkún, kó má a bí àwo̩n ìwàlè̩ o̩mo̩ ni; Bó o bá wáyé àwo̩n jòdìjè̩sò̩; O̩ló̩rò̩ mi jo̩ mí, mo jò̩ré̩è̩ mi àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩.
Gbólóhùn adó̩gba: Bójú bá s̩e méjì: Wo̩n a wòran kedere: E̩sè̩ tó s̩e méjì: Wo̩n a rìnnà pè̩sè̩; Bó lè dogun kó dogun, bó lè dò̩tè̩ kó dò̩tè̩; Bájá bá ń sínwín, ó ye̩ kó mojú iná: Bágùntàn ń s̩iwèrè, ó ye̩ kó meléèrí è̩ yàtò̩; O̩mo̩ge tí kò mè̩tàn, o̩mo̩ge tí kò mèké; Ó gún régérégé teyínteyín, ó pó̩n ròdòròdò te̩sè̩te̩sè̩; Adáké̩ jé̩jé̩ ni yíó lè s̩o̩ko̩ omidan: Awòsùn-ùn ló lè s̩o̩ko̩ àwo̩n are̩wa; Iyan a má-a díkókó, o̩kà a sì má-a díyàyà; Mo wowájú, mo rí o̩ jó, mo wè̩yìn mo sì rí o̩ yò̩.
Àwítúnwí:
a.     Jé̩ á forí korí
     Jé̩ á fe̩nu ke̩nu
     Jé̩ á gbéra léra
b.     Bí wo̩n je̩un dùn mí - N ò ní í bééré;
Bí wo̩n je̩un dùn mí - N ò ní í bèèrè

c.      Òjò ìfé̩ pa mí lóde
N ò délé wí
Iná ìfé̩ jó mi lóde
N ò dó̩ò̩dè̩ so̩
d.     O̩ya kì í s̩e ìyáálé
O̩ya kì í s̩aya àfé̩gbè̩yìn
Àfiwé e̩lé̩lò̩ó̩: Oyin ni ó̩: ma s̩e ta mi, jé̩ kí n lá o̩ ni-i. Èmi kòkòrò rèé tí mo kánjú obì.
Àfiwé tààrà: Fo̩wó̩ mú mi ná, bí ìtì àtìtàkùn ti í fo̩wó̩ kó̩ra wo̩n; Tó ko̩jú sí mi, tó dàbí o̩mo̩ tuntun, tó kè̩yìn sí mi, ó sì dàbí às̩è̩s̩è̩-là oòrùn; Bó bá yo̩ ló̩ò̩kán: A dàbí ère, rúmúrúmú bí ewé òdú ni.
Òwe: A kìí bá yímíyímí dumí; Àpáàdì tó bá sijú dé ògiri, tògiri ní í s̩e
Ìbéèrè pèsìje̩: Taa ní í  bé̩ye̩ agbe dun aró? Taa ní í gba kánbó ló̩wó̩ imú?
Ìfohunpènìyàn: Owó le wá mi wálé
Àso̩dùn: Gbogbo ojú ní n ráns̩é̩ sí o̩; Bó o bá ń ròfó̩ ló̩wó̩, mo le je̩kà ìfé̩ lo̩ bí Igbo̩n bí E̩de̩

IWE ITOKASI

Oladapo Olatubosun (2002), Ẹ̀mí ìn mi Ẹ̀mí ìn rẹ. Ibadan: Olatubosun Records Company.


[1] Ogunde Victor Ogundare ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment