He has athlete’s foot – Ó ní kán-ànyán.
He has small feet – Ẹsẹ̀ rẹ̀ kéré.
He is a footballer – Agbá-bọ́ọ̀lù
àfẹ̀sẹ̀gbá ni.
He is a foot-man – Òun ni ó máa ń ṣí
ilẹ̀kùn ọkọ̀ fún àlejò tàbí kí ó gbé oúnjẹ sí orí tábìlì.
He is blessed with footballing skills –
Ó ní ẹ̀bùn bí a ṣe ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.
He is club-footed – Ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ ti bàjé
láti ìgbà tí w’ọn ti bí i.
He is coming on foot – Ó ń rìn bọ̀.
He is flat-footed – Kò ní ibi apá ẹsẹ̀
tí ó máa ń wọnú yẹn/Kò ní òbò ẹ̀sẹ̀.
He is seven-feet tall – Ó ga ní ìwọn
ẹsẹ̀ bàtà méje.
He is walking around the house in bare
foot – Ó ń rìn yípo ilé láìwọ bàtà.
He lost his footing – Ó ṣi ẹsẹ̀ gbé.
He pressed the foot brake – Ó tẹ
bíréèkì ti ẹlẹ́sẹ̀.
He saved a left-footed shot at the dying
minutes of the match- Nígbà tí bọ́ọ̀lù fẹ́ parí, ó mú bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n fi
ẹsẹ̀ òsì gbá.
He stood at the foot hills of the
Himalayas – Ó dúró sí ibi àwọn òkè Himalaya.
He was a footloose, unemployed man –
Ọ̀kùnrin tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tí ó lè lọ sí ibi tí ó bá wù ú ni.
He was nearly trampled under-foot by the
crowd rushing to get out – Àwọn èrò tí wọ́n fẹ́ sáre jade fẹ́rẹ̀ẹ́ rẹ́ ẹ
mọ́lẹ̀.
He watched an old film footage of moon
landing – Ó wo fíìmù tí ó fi ìṣẹ̀lẹ̀ bí wọ́n ṣe balẹ sí orí
He went through this footpath – Ọ̀nà
ẹsè yìí ni ó gbà kọjá.
He won on the football pools – Ó jẹ
tẹ́tẹ́ ti oní-bọ́ọ̀lù àfẹ̀sẹ̀gbá.
He wore a football boot – Ó wọ bàtà tí
wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.
His boat is an eight-footer – Ẹsẹ̀ bàtà
mẹ́jọ ni ọkọ̀ ojú omi rẹ̀.
His business sense helped set the
society on its feet again – Ọgbọ́n òwò ṣíṣe tí ó ní ti jẹ́ kí ó ran ẹgbẹ́
náà lọ́wọ́ láti máa jèrè.
I don’t want your children under my feet
when I am working – N ò fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ máa dí mi lọ́wọ́ bí mo bá ń
ṣiṣẹ́.
I have been on my feet since yesterday –
N kò tíì jókòó láti àná.
I have been on my feet since yesterday –
Orí ìdúró ni mo wà láti àná.
I heard his foot-fall – Mo gbọ́ ìró
ẹsẹ̀ rẹ̀.
I saw his foot print in the sand – Mo rí
ibi tí ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ní orí yanrì.
I vowed not to set foot in the place –
Mo búra pé n kò níí fi ẹsẹ̀ mi kan ibẹ̀.
In the game, he has hardly put a foot
wrong – Ninú eré ìdárayá náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ṣe àṣiṣe kankan.
It is at the foot of the bed – Ó wà ní
ìsàlẹ̀ ibùsùn náà.
It is at the foot of the hill – Ó wà ní
ẹsẹ̀ òkè náà.
It is at the foot of the page – Ó wà ní
ìsàlẹ̀ ojú-ìwé náà.
òṣùpá hàn.
Read the third footnote – Ka
ìtọ́sè-ọ̀rọ̀ kẹ́ta.
Rise to your feet – Dìde dúró.
That is a foot bridge – Bíríìjì tí àwọn
ẹlẹ́sẹ̀ máa ń gbà nìyẹn.
That is his footprint – Òjú ẹsẹ̀ rẹ̀
nìyẹn.
The company gained a foothold in Nigeria
– Ilé-iṣẹ́ náà fi ẹsẹ̀ mulẹ ní Nàìjíríà.
The company is now on a sound financial
footing – N’I ti owó, ilé-iṣẹ́ náà ti wáa rọ́wọ́ mú.
The ground was dry and firm under-foot –
Ilẹ́ náà gbẹ ó sì le ní abẹ́ ẹsẹ̀.
The tax payers will foot the bill –
Àwọn tí ó ń san owó-orí ni yóò san owó náà.
The want to be treated on the same
footing as the rest of us – Wọ́n fẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn náà bí wọ́n ṣe ṣe àwa
yòókù.
They are playing football – Wọ́n ń gbá
bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.
They rose to their feet – Wọ́n dìde.
They were caught flat-footed by the
attack – Ìpèníjà náà bá wọn lójijì.
We came on foot – A rìn wá.
We saw many people going barefoot on the
street – A rí ọ̀pòlọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń rìn lórí títì láìwọ bàtà.
Wear the correct foot-wear on your feet
– Wọ ohun tí yóò dáàbò bo ẹsẹ rẹ.
When his parents died, he had to learn
to stand on his own two feet – Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ kú, ó ní láti kọ́ bí yóò
ṣe dá dúró.
When you are tired, put your feet up –
Tí ó bá rẹ̀ ọ́, simi.
You will need a
deft political footwork to save the situation – Ó nílò ọgbọ́n òṣèlú tí ó ga
kí nǹkan máà bàa dàrù.
You’ve got to put your foot down and
make him stop seeing her – O ní láti fi dandan lé e pé kò gbọdọ̀ rí i mọ́.
Reference
Hornby, A.S. (2001), Oxford Advanced Learner’s Dictionary of
Current English, edited by Sally Wehmeier. Oxford: Oxford University Press.
No comments:
Post a Comment