Monday, 30 April 2018

EÉGÚN ALÁRÉ


NÍPA ÒǸKỌ̀WÉ[1]
            wuyì Ògúnníran jẹ́ ọmọ agbo ilé Arógunmásàá ní ìlú Ìbàdàn. Wọ́n bí Alàgbà yìí ní ọjọ kìíní, oṣù kọkànlá ọdún 1935. Ó fẹ́ràn àlọ́ àti ìtàn sísọ. Ó sì ti kọ àwọn ìwé tí ó ṣe àǹfààní fún wa ní àwùjọ.
Àwọn ìwé náà ni: Òjòwú ‘Bìrin, Àdùkẹ́ Aláròká, Àjànàkú, Ọmọ Alálẹ̀ Ìlẹ̀kẹ̀, Ọlọ́run ò màwàdà, Ọ̀nà kan ò wọjà, Eégún Aláré àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nípa Ìwé Eégún Aláré
            Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká àti Dáṣọfúnjó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní ìlú Òkehò ní ilẹ̀ Ìjọ̀ba Aláàfin Ọ̀yọ́. Eégún Aláré ni wọ́n ń ṣe ṣùgbọ́n Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká pinnu láti lọ sí ìlú mìíràn fún láti lọ máa ṣisẹ́ iṣẹ́. Ó sọ fún Dásọfúnjó kí wọ́n jọ lọ ṣùgbọ́n ìyẹn kọ̀. Oyún wà nínú ìyàwó Ọ̀jẹ̀, Ìyádùnní, ní àsìkò yìí, kò sì jẹ́ kí Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká lè mú un lọ. Ó pinnu láti padà wá mu un tí ó bá ti ráyè ìjókòó. Ṣé Dásọfúnjó kò tẹ̀lé e lọ sí ìrìn àjò yìí, òun àti ìyàwó rẹ̀ jọ ń wo Ìyádùnní títí tí ó fi bímọ.
            Dásọfúnjó gbìyànjú, ó ṣe ìtọ́jú ìyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣé ti owó ni tàbí oògùn aláboyún tàbí dídúró tini ni, Dásọfúnjó sa ipá tirẹ̀. Àmọ́ títí tí Ìyádùnní fi bímọ, wọn kò gbúròó Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká rárá. Kódà, Dásọfúnjó ni ó ṣọ ọmọ ti Ìyádùnní bí ní orúkọ. Ọmọ náà ń jẹ́ ‘Ọ̀jẹ́dé’. Lẹ́yìn ìkómọ, babaláwo ríran pé irú iṣẹ́ bàbá ọmọ náà ni Ọ̀jẹ́làdé yóò ṣe, yóò sì lókìkí ju bàbá rẹ̀ lọ.
            Babaláwo ka ẹbọ fún wọn ‘Ẹyẹlé mẹ́rin, àgbébọ̀ adìẹ mẹ́rin, obì gidi mẹ́rin àti ọ̀pá aṣọ funfun mẹ́rin.
            Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Ọ̀jẹ̀ ti lọ sí àjò, Ọ̀jẹ́làdé ti di ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, Ìyádùnní pinnu láti wá ọkọ rẹ̀ lọ. Ó sì sọ fún Dásọfúnjó àti ìyàwó rẹ̀. Àwọn méjèèjì kò fara mọ́ ọn nítorí pé kò sí ẹni tó mọ ibi tí Ọ̀jẹ̀ wà tàbí tí ó gbúròó rẹ̀ gan-an, ṣùgbọ́n ọkàn Ìyádùnní le, kò sì gbà, Wọ́n tún gbà á níyànjú pé kí ó fi Ọ̀jẹ́làdé, ọmọ rẹ̀, sílẹ̀ ṣùgbọ́n Ìyádùnní ní ibi tí ìgbín bá lọ, ìkaraun ẹ̀ á tẹ̀lé e. Ó ní ‘Ajá a ha máa lọ ki koko rẹ̀ gbélé?’ Ó sì kọrí sí àjò àtiwá ọkọ rẹ̀ lọ nígbà tí Dásọfúnjó ti fún wọn ní owó.
            Ní àjò tí Ìyádùnní àti ọmọ rẹ̀, Ọ̀jẹ́làdé, kó sí, ìyà púpọ̀ jẹ wọn. Níṣe ni wọ́n ń lọ láti ìletò kan sí ìletò mìíràn láìgbúròó ọkọ rẹ̀. Owó tán lẹ́yìn ọdún kan. Wọ́n ṣíṣẹ àárù kiri. Nígbà tí ìyà náà pọ̀jù, wọ́n padà sílé láìgbúròó Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká
            Nígbà tí wọ́n délé padà, àwọn ẹbí Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ní kí Ọ̀jẹ́làdé máa kọ́ṣẹ́ idán pípa. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, Ọ̀jẹ́làdé gba àdúrà lẹ́nu ọ̀gá àti ẹbí rẹ̀. Òun náà sì pinnu làti lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láti máa pidán. Lóòótọ́, nígbà tí ó kọ́kọ́ sọ fún Dásọfúnjó, ìyẹn kò gbà ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀, Dásọfúnjó gbà fún un. Dásọfúnjó fún un ní àwọn àṣírí díẹ̀, ó sì tun fi ọmọ rẹ̀ obìnrin, Àńséétì, fún Ọ̀jẹ́làdé kí ó fẹ́ ní ìyàwó.
            Lọ́jọ́ kejì, Ọ̀jẹ́làdé àti ìyàwó rẹ̀ tuntun fi ìlú sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ìlú kan, wọ́n fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó; òkìkì Ọ̀jẹ́làdé bẹ̀rẹ̀ síí tàn kàákiri. Kò pẹ́, àwọn Baálẹ̀ ìlú ńláńlá ti ń ráńṣẹ́ pè é.
            Ìlú àkọ́kọ́ tí ó lọ, Ọ̀jẹ́làdé lọ rí Eégún Aláré kan tí ó ń gbé ìlú náà láti kí i. Ọ̀jẹ́làdé sọ fún un pé òun wá ṣeré ni, ó fún bàbá yìí ní ẹ̀bùn. Bí wọ́n ti ń lọ ni bàbá yìí tẹjú mọ́ ìyàwó Ọ̀jẹ́làdé, ó sì wù ú. Wọ́n padà pàdé ní ọjà alẹ́, ìyẹn ìyàwó Ọ̀jẹ́làdé àti bàbá yìí, wọ́n sì lérí sí ara wọn.
            Ní ọjọ́ aré, Baálẹ̀ gúnwà, àwọn ìjòyè pésẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èrò pitì. Ọ̀jẹ́làdé bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣe eré tirẹ̀ lọ, ó ń pidán; ó di òjòlá ni kò bá padà di ènìyàn mọ́. Àwọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ bínú, wọ́n sì ti fa àṣẹ yọ pé ẹni bá ṣe irú èyí, kó jẹ́wọ́. Ọ̀jẹ́làdé ní tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sà júwe ara rẹ̀. Ó júwe bàbá àti ìyá rẹ̀.
            Bí bàbá yìí ṣe gbọ́ orúkọ ‘Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ni ó bẹ́ sójú agbo jìàjìà, tó ń ké kí wọ́n gba òhun, pé òun ti fi ọwọ́ ara òun ṣe ara òun. Kíá ló lọ́ mú ẹ̀rọ̀ wá. Ọ̀jẹ́làdé para dà, ó sì di ènìyàn padà. Òun àti bàbá rẹ̀ sì dì mọ́ra wọn. Àwọn tó wà ní ojú agbo náà sì kọ́ ẹ̀kọ́ àti ọgbọ́n lára ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
            Kò pẹ́ púpọ̀ tí Ọ̀jẹ́làdé àti bàbá rẹ̀ pàdé ara wọn ni ó tún múra àjò mìíràn. Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká kò lè lọ sóde idán mọ́. Ó sì fún ọmọ rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn kí ó fi máa ṣe ọkùnrin. Kò pẹ́ púpọ̀ tí Ọ̀jẹ́làdé sì ń palẹ̀mọ́ ni bàbá rẹ̀ kú. Bí ó ti ṣọ̀fọ̀ bàbá rẹ̀, Ọ̀jẹ́ Lárìnnàká, tán, ó kọjú mọ́ eré ṣíṣe rẹ̀.
            eré mìíràn tí ó lọ lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, ó kọ̀, kò júbà ẹnìkọ̀ọ̀kan. Bóyá nítorí oògùn tí bàbá rẹ̀ kó fún un kó tóó ni ó ń gùn ún. Níṣe ni ó ń pidán lọ. Ó di màálù, abá-òwú, eégún àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn àgbà tún pè é, wọ́n kò jùbá kí ó tó wọlé. Ọ̀jẹ́làdé kò dáhùn, orin ló ń kọ. Àwọn àgbà sì jẹ́wọ́ ara wọn hàn án. Bí Ọ̀jẹ́làdé ti di ọ̀nì ńlá, kò lè yí padà di ènìyàn mọ́.
            Ọ̀jẹ́làdé ti mọ ohun tó ṣe é, ó sì ké sí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan, kí ó lọ mú oògùn ẹ̀rọ̀ kan wá fún òun ní ilé. Àmọ́ kí ọmọ náà, Ọ̀jẹ́kúnlé, tó dé, òjò ti ṣú, bẹ́ẹ̀ òjò kò gbọdọ̀ kán lé ọ̀nì lórí. Òjò bẹ̀rẹ̀ sí níí rọ̀. Ọ̀jẹ́làdé wá ń fi ẹ̀ṣà dágbére fún àwọn olùwòran.
            Àgbàrá òjò wọ́ ọ̀nì yìí lọ sí inú odò ńlá kan tó ní ojú ibù sí ìlú kan tó súnmọ́ ìlú náà. Ọ̀nì yìí ń yọjú ní bèbè odò. Ó rí obìnrin dúdú kan tí ó gbé agbọ̀n èèrí ògì wá sí orí àkìtàn láti dànù. Ló bá fi ẹ̀ṣà bá obìnrin náà sọ̀rọ̀. Bí obìnrin yìí ṣe rí ọ̀nì tẹ́nu rẹ̀ rí hànhà, ó ju àgbọn èèrí nù, ó fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Bí èèrí ti kan ọ̀nì ní ara ni ó yí padà di ènìyàn nínú ẹ̀kú eégún. Ó sáré tẹ̀lé obìnrin yìí  wọ ilé rẹ̀ ó sì ṣàlàyé fún òun àti ọkọ rẹ̀ nǹkan tó ṣẹlẹ̀. Ọkọ obìnrin yìí ló fún un ní ẹ̀wù àti ṣòkòtò tí ó wọ̀ padà sí ìlú rẹ̀. Kódà, Ọ̀jẹ́làdé ṣaájú àwọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ dé ilé.
            Bí Ọ̀jẹ́làdé ti ń ko àgbákò kiri níbi aré náà ló ń borí tí òkìkì rẹ̀ sì ń kàn sí i. Kò pẹ́ ni ó jẹ oyè ‘Baálẹ̀ Arẹ̀kú-Eegún’ lẹ́yìn tí ó borí Ìfagagbága pẹ̀lú Dúdúyẹmi, ó mú inú ọba ìlú rẹ̀ dùn fún gbígbé orúkọ ìlú rẹ̀ ga.
            Ọ̀jẹ́làdé wá di àgbà ọ̀jẹ̀. Ó sì di oníṣòwò ńlá.

Àwọn ọnà èdè inú Eegún Aláré
1.      Àyálò ọ̀rọ̀ – Ìwọ̀nyìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a yá láti inú èdè mìíràn wọ èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ
‘Àálà’ àti ‘Yárábì’ – èdè lárúbáwá fún Ọlọ́run
2.      Àfiwé Tààrà – Àpẹẹrẹ
i.                    A! Obìnrin ló pupa bí edé báyìí
ii.                  Nígbà tí bàbá náà ri pé ọkàn obìnrin náà le bí òkúta, ó dẹ́rù bà á
iii.                Àwọn oníbàtá tí wọ̀ sin-in bí ọbẹ̀ pàánù
iv.                Bàbá náà ń gbọ̀n jìàjìà kiri ojú agbo bí òtòṣì bánáláwo
3.      Ìfohunpènìyàn – Èyí ni fífi ohùn ènìyàn tàbí abẹ̀mí pe ohun tí kò ní ẹẹ̀mí nínú. Àpẹẹrẹ
i)                    Etí làwòko fi í gbéyàwó ọ̀rọ̀
ii)                  Ọ̀rọ̀ kúkú ni ọmọlétí í jẹ.
4.      Àwítúnwí – Nínú ìwé yìí, a rí Àwítúnwí odidi gbólóhùn, àwítúnwí awẹ́-gbólóhùn, àwítúnwí èrò tàbí ìtumọ̀ àti àwítúnwí ẹyọ ọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ:
i)                    Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká dákun má gbàgbé mi
ii)                  Kí ló ṣe tóbìnrin ò mawo-ó-ṣe
iii)                Bí kò sí onìrè, a kò yẹ̀nà
iv)                Bó ò fáná, ara ìlágbẹ̀dẹ a ló o ṣeun
v)                  Bá a rebi, à dáni lógún ọdún
vi)                Àwọn ọmọ ẹni tí kò gbọ́n
vii)              Ẹ la ẹran òjòlá
viii)            Ẹ bì í àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
5.      Ìfọ̀rọ̀dárà àti Ìfọ̀rọ̀ṣeré – Àwọn àpẹẹrẹ:
i)                    Àwọn ló gbé orí ìrókò ni wọ́n ro ko ko ko
ii)                  Ìyàn mú, mú, ó pa olómù
iii)                Fíná fíná fíná ḿbẹ lẹ́nu alágbẹ̀dẹ
6.      Àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ – Àpẹẹrẹ:
i)                    Orí ni í ṣeni táà á dádé owó
ii)                  Orí ni í ṣeni táà á tẹ̀pá ìlẹ̀kẹ̀
7.       Òwe – Ìlò òwe wà làra ohun tí ìwé náà fi dùn ún kà. Ó sì pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ẹ̀. Díẹ̀ nínú wọn ni:
i)                    Erin kì í fọn, kí ọmọ rẹ̀ fọn
ii)                  Ìdí iṣẹ́ ẹni là á mọni lọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹsin dáni kìí a má tún un gùn.
8.      Ìbéèrè pèsìjẹ - Èyí ni àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní ‘Rhetorical Question’. Ìbéèrè pèsìjẹ pọ̀ nínú ìwé yìí, àwọn díẹ̀ nínú wọn ni:-
i)                    Ajá ha máa lọ kí kókó rẹ̀ gbélé?
ii)                  Òyìnbó a ha máa ràjò kó má mú Ajá rẹ̀ lọ?
iii)                O rójú ayé, à bí o ò rí i?
iv)                Kí lọmọ ewúrẹ́ ń ṣe níṣọ̀ adìẹ?

Kókó mìíràn ti ó yẹ kí á yin Alàgbà Láwuyì Ògúnníran fún ni ọgbọ́n ìṣọ̀tàn. Ó lo aríhìn-iń-rọ́hùn-ún nígbà tí ó ń sọ ìṣẹ̀lẹ̀ ìrìnàjò Ọ̀jẹ́làdé àkọ́kọ́ àti ìkéjì bí ẹni tí ó ń tẹ̀lé e kiri.
A rí:- Ọgbọ́n ìsọ̀tàn pípadàsẹ́yìn, ìtàn nínú ìtàn, ìsọ̀rọ̀gbèsì, ìdánilọ́kànró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìwé Eegún Aláré.

Díẹ̀ nínú wọn ẹ̀dá inú ìtàn :
1.      Ọ̀jẹ́làdé
2.      Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká
3.      Dásọfúnjó
4.      Ìyádùnní
5.      Àńséétù

1.      Ọ̀jẹ́làdé
Òun ni olú ẹ̀dá-ìtàn inú ìwé yìí. Ó jẹ́ ọmọ Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká àti Ìyádùnní. Kò fojú kan bàbá rẹ̀ ní gbà tí a bí i nítorí inú ìyá rẹ̀ ni ó wà tí bàbá rẹ̀ lọ sí ìrìnàjò. Kódà Dásọfúnjó àti àwọn ẹbí bàbá rẹ̀ ni wọ́n sọ ọ́ ní orúkọ. Dásọfúnjó ni ó sì kọ́ ọ ní iṣẹ́ idán pípa.
Ó jẹ́ ọkọ Àńsíétù, ọmọ Dásọfúnjó, ó sì jẹ́ akọni eégún. Ó padà sí ìlú rẹ̀ tòun tọrọ̀ rẹpẹtẹ lẹ́yìn tó di Arẹ̀kú Eégún. Ó di onísòwò pàtàkì, ó sì ń gbádùn ayé rẹ̀.

2.      Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká
Onídán ni òun náà. Ó jẹ́ bàbá Ọ̀jẹ̀làdé, ọkọ Ìyádùnní. Nígbà tí ó ṣàkíyèsí pé nǹkan kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ déédé mọ́ ni ó pinnu láti rìnrìnàjò lọ ìlú mìíràn. Ó fi oyún sí ìyàwó rè nínú, kò sì wẹ̀yìn wò mọ́. Ó fẹ́ràn obìnrin, èyí ló fà á tí ó fi fẹ́ẹ́ fẹ́ ìyàwó Ọ̀jẹ́làdé. Ó ṣe oògùn sí Ọ̀jẹ́làdé, tí kò mọ̀ pé ọmọòhun ni nígbà tí ìyẹn ń pidan lọ́wọ́. Àṣírí tú nígbà tí Ọ̀jẹ̀làdé ń pẹ̀sà nípa bí òun ti jẹ́. Ó kábàámọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Kí ó tó kú, ó gbé agbára oògùn fún ọmọ rẹ̀.

3.      Dásọfúnjó
Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àti ọ̀rẹ́ gidi sí Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká, ó ṣojú-ṣẹ̀yìn nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ sí àjò. Òun ló tọ́jú ọmọ àti ìyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó fún ọmọ náà lórúkọ, ó kọ́ ọ ní iṣẹ́ eégún aláré, ó sì tún fún un ni ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí aya.

4.      Ìyádùnní
Òun ni ìyàwó Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká, Ìyá Ọ̀jẹ́làdé. Ó nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ dénú-dénú. Ìgbà tó pé ọdún mẹ́wàá tí kò gbúròó ọkọ rẹ̀, ó wá a lọ. Ó sì mọ oore. A máa dúpẹ́ gidi lọ́wọ́ Dásọfúnjó fún ìtọ́jú òhun àti ọmọ rẹ̀, Ọ̀jẹ́làdé tí ó ṣe.
5.      Àńṣéétù
Òun ni ìyàwó, Ọ̀jẹ́làdé. Ó jẹ́ ọmọ Dásọfúnjó. Ó jẹ́ ìyàwó tó fọwọ́ sí ohun tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe nítorí ó mọ̀ nípa ẹ̀sà pípè àti idán pípa gẹ́gẹ́ bíi bàbá rẹ̀, Dásọfúnjó. Ó dúró ti ọkọ rẹ̀ nígbà ìṣòro. Ìyàwó rere ni.


[1] Adenle Iyanuoluwa Deborah lọ́ ló kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment