A fẹsẹ̀ ba orí ilẹ̀ – We set foot on
land/We disembarked.
A fẹsẹ̀ gbá bọ́ọ̀lù – We played
football.
A nasẹ̀ lọ sí ọjà – He was strolling
to the market.
Àṣà yìí fẹsẹ̀
mule – This custom is firmly established.
Ẹ jẹ́ kí a péjú pésẹ̀ sí ìpàdé náà –
Let us all be present at the meeting.
Ẹsẹ̀ dá wáí – There are no visitors
here.
Ẹsẹ̀ gììrì nílé àńjọ̀fẹ́, ańjọ̀fé kú, a
ò rí ẹni kan – Feet rush to a house where people can get things for nothing,
when things can no longer be got for mere asking, such visitors cut short their
visits (rats deserts a sinking ship).
Ẹsẹ̀ kò gbèjì ni ibẹ̀ yẹn – That is a
narrow track.
Ẹsẹ̀ kò pọ̀ lọ́nà yìí – This is an
unfrequented road.
Ẹsẹ̀ kún mi – I am tired of standing.
Ẹsẹ̀ ni ó lò tí ó fi rí iṣẹ́ – He used
his influence to secure the job.
Ẹsin náà tasẹ̀
wáíwáí – The horse kicked backward.
Gbogbo wa ni a pésẹ̀ sí ìpàdé náà – we
were all present at the meeting.
Gìrì-gìrì ni ẹsẹ̀ ń wọ́ọ́ lọ sílé rẹ̀
– People are flocking to his home.
Ijó ń bẹ nínú arọ, ẹsẹ̀ ni kò sí –
The lame wants to dance but there are no legs/Barkis is willing/Opportunity
makes the thief.
Ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì
náà ṣẹlẹ̀ ní ṣísè-n-tẹ̀lé – The two events are inseparable.
Ìyàwó á
fẹsẹ̀ẹre tẹlé o – Goodluck on your marriage, bridegroom.
Kò jẹ́ kí o ya
òun lẹ́sẹ̀ kan – He won’t let him out of his sight for a moment.
Kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ – He has no supporters.
Kò mẹsẹ̀ kó
yẹjú – He who has come uninvited should withdraw.
Máà yẹsẹ̀ –
Don’t move.
Máà yinsẹ̀ –
Don’t move.
Mo fẹsẹ̀ bù – I hurt my leg so that it
bled.
Mo fẹsẹ̀ ra ijó
– I took part in the dance.
Mo fi ẹsẹ̀ pa – I hurt my leg.
Mo rí ojú ẹsẹ̀ lórí yanrìn – I saw his
footprints on the sand.
N kò gbọ́ iró ẹsẹ̀ rẹ̀ – I didn’t hear
his footfalls.
N ò mọ ibi tí orí ń bá ẹsẹ̀ẹ́ rè – I
don’t know what is in store for me.
N ó mú un wá
lẹ́sẹ̀ kan náà tí mo bá ti lò ó tán – I shall bring it as soon as I finished
using it.
N ó mú un wá
lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ tí mo bá ti lò ó tán – I shall bring it as soon as I finished
using it.
Ní ìrọwọ́rọsẹ̀
ni ó rí owó yií – He got this money easily.
Ó bá ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ̀ – He took a
hurried leave.
Ó bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ – He took to his
heels.
Ó dásẹ̀ dúró – He halted.
Ó dásẹ̀ níbẹ̀ – He ceased going there.
Ó di irun kòlẹ́sẹ̀ – She made a style of
hairdressing where the hair is plaited from the front to the back of head; the
plaits descending to the nape of the neck.
Ó dide lójú ẹsẹ̀ – He stood up
immediately.
Ó dúró ní ẹsẹ̀ ọ̀nà – He stood by the
roadside.
Ó dúró síbi ẹsẹ̀ mi – He stood near my
feet.
Ó fẹsẹ̣̀ bale – He put down his foot.
Ó fẹsẹ̀ iṣẹ́
yìí lélẹ̀ – He started work on this.
Ó fẹsẹ̀ kan
délé mi – He paid me a flying visit.
Ó fẹsẹ̀ kọ –
He knocked his foot on something.
Ó fẹsẹ̀ kọ́lẹ̀ lọ – He walked away
slowly and dejectedly.
Ó fẹsẹ̀ lé ọ̀nà
Èkó – He set out for Lagos.
Ó fẹsẹ̀ lulẹ̀ –
He stamped on the ground.
Ó fẹsẹ̀ rọ́ –
He sprained his foot/He dislocated his foot.
Ó fẹsẹ̀ ṣẹ́ –
He broke his leg.
Ó fẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́
– He trod on it.
Ó fẹsẹ̀ wọ́ odò
náà – He waded through the river.
Ó fi orí ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn kọjá lọ sí ojú
fèrèsé – He is tiptoed over to the window.
Ó fi ọwọ́ kan àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ – He
touched the sole of his feet.
Ó gbé mi lẹ́sẹ̀ – He took me on his
knee.
Ó gùn ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà – It is six
feet long.
Ó ka ẹ̀sẹ̀ apààyàn sí i lẹ́sẹ̀ – He
accused him of murder.
Ó ka ẹsẹ̀ wọn
– He counted their legs.
Ó kasẹ̀ – He
paced along/He stepped out.
Ó kásẹ̀ – It
came to an end.
Ó kasẹ̀ ìyàwó –
He walked slowly/She walked with measured tread.
Ó kó ẹsẹ̀ tile
– He raced along.
Ọ́ kọ́ mi lẹ́sẹ̀
– He impeded me.
Ó kọsẹ̀ bá mi –
He happened to meet me.
Ó lẹ́sẹ̀ – He is sociable.
Ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ – He has supporters.
Ó lọ gbọnsẹ̀ –
He went to relieve himself/He went to the lavatory.
Ó lọ nasẹ̀ ní ọjà – He went for a
stroll in the market.
Ó mẹ́sẹ̀ dúró –
He persevered/He is dogged.
Ó mọ àtẹsẹ̀wáyé ọmọ rẹ̀ – He knows
his child’s destiny.
Ó nasẹ̀ – He
stretched out his leg.
Ó nasẹ̀ lọ – He
went for a walk.
Ó ní ẹ̀lasẹ̀ –
He has a splitting of the skin under his toes.
Ó ní ẹ̀làsẹ̀ – He
has a splitting of the skin under his toes.
Ó ní ẹsẹ̀ – He is influential.
Ó ní ẹ̀yasẹ̀ –
He has a splitting of the skin under his toes.
Ó ní ìbẹ́sẹ̀ –
He has a splitting of the skin under his toes.
Ó ní ìlasẹ̀ – He
has a splitting of the skin under his toes.
Ó pasẹ̀ fún
ọmọ – She jingled herself about to soothe the baby carried on her back.
Ó ra ẹsẹ̀ bàbá ń Kánò – he bought a
cooked cow’s leg.
Ó rin ẹsẹ̀/Ó fi ẹsẹ̀ rìn – He
travelled on foot.
Ó rosẹ̀ fún mi –
He waited some time for me.
Ó rọwọ́rọsẹ̀
ṣe é – He had no difficulty in doing it.
Ó sáré, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò bale – He ran at
full speed.
Ó ṣe ẹsẹ̀ kan ilé, ẹsẹ̀ kan òde – He
sat on the fence (he waited to see which way the cat jumped).
Ó sẹsẹ̀ kan gbé
– He committed an error of judgment.
Ó sésẹ̀ níbí –
He has ceased coming here.
Ó ṣísẹ̀ – He
departed/He moved off.
Ó tẹ̀ mí lẹ́sẹ̀
– He trod on my foot.
Ó tẹsẹ̀ dúró – He halted.
Ó ti ipàsẹ̀ èyí
ya àgàn – She has for this reason become barren.
Ó tọ ìṣísẹ̀ mi
– he guided my footsteps.
Ó topasẹ̀ mi –
He pursued me/He dogged my footsteps.
Ó tọsẹ̀ ẹjẹ̀
náà – He spoored the track of the blood.
Ó tọsẹ̀ ọ̀rọ̀
náà – He delved into the matter.
Ó yásẹ̀ – He is
fast.
Ó yẹsẹ̀ – He
moved away a short distance.
Ọba náà gbésẹ̀ – The king died.
Ọjà yìí kò
gbẹsẹ̀ – This market is overcrowded/This market is parked with people.
Òjò náà ti kásẹ̀ – The rain has stopped.
Ọrùn ẹsẹ̀ mi ti wú – My ankles have
swollen.
Òtá wa forí sábẹ́ ẹsẹ̀ wa – Our enemies
submitted to us.
Ọwọ́ ti wọwọ́, ẹsẹ̀ ti wọ ẹsẹ̀ –
Harmony has prevailed between them.
Pasẹ dà kúrò
níbí – Move your leg away from here.
Rí mi lẹ́sẹ̀ kan
– See me for a moment.
Wò mí lẹ́sẹ̀ kan
– Please, excuse me for a moment.
Wọ́n kẹ́sẹ̀ lọ
– They went together.
Wọ́n pésẹ̀/Ẹsẹ̀
wọn pé – They assembled.
Wọn yasẹ̀ –
They dissolved their partnership.
Reference
Abraham, R.C.
(1958), Dictionary of Modern Yoruba.
London: Hodder and Stoughton.
No comments:
Post a Comment