Láti ìbẹ̀rè pẹ̀pẹ̀ ni àwon onímò èdè ti gba ti
inú ‘ìwé ti Òjó’ sí ‘possessive
marker’ àfi ìgbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan wò ó dáadáa tí ó sọ pé OR ni. Ó ní nínú
‘iwé ti Òjó’, ‘ti’ jẹ OR nínú APOR, ‘ti Òjó’ àti pé APOR, ‘ti Òjó’, dúró ní
àdàpè (apposition) fún ‘ìwé’. Èyí fi han
pé nínú ‘ìwé ti Òjó’, ‘ìwé’ ń yán ‘ti’.
A wá ní OR méta nínú ‘ìwé ti Òjó’. Ìbásepọ̀ ‘ìwé’àti ‘ti Òjó’ wá dàbí ìbáṣepọ̀
tí ó wà láàrin ‘Òjó’ àti ‘àdẹ́mu’ nínú ‘Òjó adẹ́mu ń bò’. Ọ̀jọ̀gbọ́n kejì ni ọ̀rọ̀
kò ri báyìí. Ó ní iṣẹ́ jẹ́nítíìfù (tàbí possessive) ni ‘ti’ ń se nínú ‘ìwé ti
Òjó’. Ó ní tí a bá sọ pé ‘tèmi’, nǹkan tí a ní lọ́kàn ni ‘nǹkan kan tèmi’. Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kẹ́ta, òrò kò rí bí ọ̀jọ̀gbọ́n
kejì ti là á sílẹ̀ yẹn. Lójú tirẹ̀, a lè fi ‘ti’ wé ‘oní’ nínú ‘ti aró/ti aṣọ’
àti ‘aláró/aláṣọ’, iṣé kan náà ni wón ń ṣe. ‘Ti aró’ ń tọ́ka sí ohun kan tí
a mọ aró mọ́. Ohun yòówù tó lè jẹ, kìí ṣe aró fúnra rẹ̀. Aró wá dàbí ọlọ́kọ̀ọ́
ohun tí a ní lọ́kàn. Ní ti ‘aláró’, ohun
tí a mọ̀ mọ aró ni a ní lọ́kàn. Ohun tí a ní lọ́kàn yìí sì ni ọlọ́kọ̀ọ́ aró. Lọ́rọ̀
kan, gbogbo APOR (ti + OR) jẹ́ òdì APOR (oní + OR). Ó ní a ó rí i pé kò sí ohun
tí a lè ṣe sí ikíní tí a kò lè se sí èkejì. (i) Wón lè se olùwà GBOL, ba: Onílé
kò lè gbé e lọ sí ọ̀run/Tilé kò lè gbé e lọ sí ọ̀run. (ii) Wọ́n lè
ṣe àbọ̀ GBOL, ba: Mo ránṣẹ́ só onílé/Mo ránṣẹ́ sí tilé (iii) A
lè yán wọn, ba: onílé gogoro/tilé gogoro (iv) a lè ṣèdá òrò mìíràn lára wọn,
ba: olónigbaojúlé/onítilé. (v) a lè fi wón yán ọ̀rọ̀ mìíràn ba: owó onílé/owó
tilé. Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kẹta yìí, ìgbà tí a bá lo ‘ti + OR’ ní àkànlò ni ó máa ń
dàbí ẹ̀yánrọ̀ lásán. Èyí ni ọ̀jọ̀gbọ́n kejì pè ní ‘marked genitive
construction’ (owó ti onílé) tí ó fa àtenumọ́ lọ́wọ́ yàtọ̀ sí ‘unmarked
genitive construction’ (owo onílé). Ìdí nì yí tí ọ̀jọ̀gbọ́n kejì fi lè túmọ́
‘owó tilé’ sí ‘owó kan tí a mọ̀ mọ́ ilé’. Ọ̀jọ̀gbọ́n kẹ́ta túmọ̀ ‘owó tilé’ sí
‘owó tí a mọ̀ mọ́ ohun kan tí a mọ ilé mọ́’ Ojú yòówù kí a fi wò ó, lójú ọ̀jọ̀gbọ́n
kẹ́ta, ìsọ̀rí gírámà tí a bá to ‘oní’ sí ló ye kí á to ‘ti’ sí. Níwòn ìgbà tí
‘oní’ ti jé mọ́fíímù àfòmọ́ tí a lè lò láti ṣèdá OR láti ara OR, ‘ti’ náà ní
láti jẹ́ àfòmọ́ tí a fi ń ṣèdá OR láti ara OR.
No comments:
Post a Comment