Àlàyé tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan se lórí èyí
ni a ó kọ́kọ́ yẹ̀ wò. Ó ní àwon ìlànà tí a fi lè mọ IṢ ní èdè Yorùbá nìwònyí:
(i) Ọ̀rọ̀ tí ó bá ti wọ férémù yìí - //OR ---- (OR)// - IṢ ni. Gbogbo ọ̀rọ̀
tí a fa igi sí nídìí yìí ló wo férémù náà, ‘Ò lọ, Ó ra iṣu.
(ii) Òrò tí a bá ti lè sọ dorúkọ nípa àpètunpè ẹlẹ́bẹ. IṢ ni, ba: ‘lílọ
ni ó lọ’. (iii) IṢ ni ó máa ń yan olùwà nínú GBOL, ba: ‘Olu gbin isu’,
‘*Igi gbin isu’. (iv) IṢ ní ó máa ń yan àbọ̀ nínú GBOL, ba: ‘Olú gbin iṣu’,
‘*Olú gbin Adé’. (v) Ọ̀rọ̀ tí a bá ti lè fi ṣe se ìbéèrè nípa rè, IṢ
ni, ba: ‘Kí ni Olú ṣe?’, ‘Ó lọ’. (vi) Ọ̀rọ̀ tí a bá ti lè sọ dorúko nípa àpètúnpè
ẹlẹ́bẹ tí a sì fi kó yí sódì, IṢ ni, ba: ‘Lílọ ko ni ó lọ’,
(vii) Ọ̀rọ̀ tí a bá lè fi GBOL aṣàpèjúwe yán léyìn ìgbà tí a bá ti se àpètúnpè
ẹlẹ́bẹ sí i, IṢ ni, ba: ‘Lílọ tí ó lọ’. Ọ̀jọ̀gbọ́n kejì dá a
lohùn, ó ní merin ni òun yóò yewò nínú àbá méje tí ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ dá nítorí
pé méjì jé àwítúnwí, òkan kò sì kápá gbogbo IṢ. Ó ní a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ sọ IṢ
di OR pẹ̀lú àpètúnpè ẹlẹ́bẹ kí á tó lè ṣe àbá (i), (vi) àti (vii), nítorí
náà, àbá kan ni mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Yàtọ̀ sí èyí, kì í se gbogbo IṢ ni a lè fi ṣe bèèrè ìbéèrè nípa rè, ba: tí a bá ní ‘Olú ga’,
a kò níi sọ pé ‘Kí ni Olú se?’. ‘Báwo ni Olú ti rí?’ ni a ó sọ. Èyí fi hàn pé
àbá mérin péré ni ó kù, ìyẹn (i), (ii), (iii), àti (iv), àwon yìí ni ọ̀jọ̀gbọ́n
kejì yìí yẹ̀ wò. Ó ní nípa àbà mérin yìí, kí á kọ́kọ́ mú ọ̀rọ̀ kan tí gbogbo onímọ̀ ẹ̀dá-èdè Yorùbá mọ̀ sí IṢ,
ìyẹn ‘ṣaájú’. Ó ní àbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni ó ṣiṣẹ́ fún un, ba: (i) ọmọ náà ṣaájú.
(ii) ṣíṣaájú ni ọmọ náà ṣaájú (iii) kò lè gba ‘igi’ ní olùwà, *igi náà ṣaájú
(iv) kò lè gba igi ní àbọ̀, * ó ṣaájú igi náà. Ó ní sùgbón tí a bá wo GBOL
àsínpò-ìṣe ‘igi náà ṣaájú ilé yìí wó/igi náà wó ṣaájú ilé yìí’, a ó rí i pé
gbogbo ìlànà yìí kò ṣiṣẹ́ mó, ba: a kò lè se àpètúnpè elébe sí ‘ṣaájú’ mọ́,
ba: *ṣíṣaájú ni igi náà wó ṣaájú ilé yìí’.
Kò lè yan olùwà bẹ́ẹ̀ ni kò lè yan àbọ̀ mó. Nítorí ìdí èyí ni ‘igi’ àti
‘ilé’ fi lè jé olùwà àti àbọ̀ fún un, èyí tí kò ṣeé ṣe nínú GBOL abọ́dé. Pèlú
gbogbo eléyìí, a ó rí i pé ìlànà (ii), (iii) àti (iv) náà kò wúlò fún dídá IṢ
mọ̀. Ó wá sé ku àbá (i).
No comments:
Post a Comment