Friday, 27 April 2018

ÌGBÈ̩YÌN


Alàgbà Adékúnlé Adédire jé̩ o̩mo̩ bíbí ìlú Ilé-Ifè̩ ní ìpínlè̩ Ò̩sun. Ǹǹkan bí i àadó̩ta o̩dún ó lé díè̩ ni O̩ló̩run fi òǹkò̩wé yìí ta ìdílé Adékúnlé ló̩re̩. Ilé-è̩kó̩ L . A. primary school, Ilode ni ìlú Ilé-Ifè̩ ni alàgbà Adékúnlé ti bè̩rè̩ ìwé alákò̩ó̩bè̩rè̩, kí wó̩n tó ko̩já sí Saint Agnes Primary School, Ipo̩nri- Fárótadé ní ìlú Ilé-Ifè̩. Yéké̩mi High School àti Odùduwà College ní Ilé-Ifè̩ náà ni wó̩n ti lo̩ ilé è̩kó̩ girama.
   Lé̩yin èyí ni wó̩n ta àtaré sí ilé è̩kó̩ gíga Adéye̩mi College of Education, ìlú Òǹdó láti gba oyè ìmò̩ ìjìnlè̩ àko̩gbà B. A (Ed.) ní o̩dún 1992. Ilé è̩kó̩ gíga fásitì Ìló̩rin ni wó̩n  sì ti gba oyè ìmò̩ ìjìnlè̩ èkejì ní o̩dún 1997. Alàgbà Adékúnle ni akò̩wé E̩gbé̩ Aké̩kò̩ó̩ Ìjìnle̩ Yorùbá ní ilé-è̩kó̩ gíga Adéye̩mí ní o̩dún 1989/90, kí wó̩n tó di Ààre̩ e̩gbé̩ náà ní odun 1990/91. Àwo̩n náà sì tún ni alukoro e̩gbé̩ àwo̩n aké̩kò̩ó̩ agboyèkóyè ní ilé-è̩kó̩ gíga Ìlo̩rin ní o̩dún 1995/96.Ilé è̩kó̩ gíga fásitì O̩lábísí O̩nàbánjo̩ ti ìpínlè̩ Ògùn ni òǹkò̩wé àtàtà yìí ti ń s̩e is̩é̩ olùkó̩ni báyìí. Lára ìwe tí òǹkò̩wé yìí tún ti ko̩ ni Fòné̩tíìkì Èdè Yorùbá àti Mè̩kúnnù ń Ṣèlú.
ÌTÀN INÚ ÌWÉ ÌGBÈ̩YÌN NÍ S̩ÓKÍ
Ìwé Ìgbè̩yìn jé̩ ìwé eré onís̩e Yorùbá tí ó jé̩ ò̩kan lára àwo̩n òpó mé̩ta tí ó gbé lítírés̩ò̩ èdè yòówù tí ì bá à jé̩ dúró. Ìẃe eré onís̩e àpilè̩ko̩ náà dá lórí àwo̩n aké̩kò̩ó̩ ilé-è̩kó̩ girama ti Ifè̩ City College, èyí tó fìdí kalè̩ sí ìlú Ilé-Ifè̩. Àwo̩n akópa tí ò̩pò̩ ìs̩è̩lè̩ inú eré náà dá lé lórí jù ni Wálé, Òjó, Àjàyí, Bìmpé àti Ké̩mi. Bákan náà ni a rí Ògúntólú, bàbá O̩lá, ò̩gbé̩ni Kó̩lá, ìyá Bó̩lá, bàbá onímó̩ngòrò, àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩.
  Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ inú ìwé yìí yan ìrégbè láàyò nígbà tí wó̩n wà ní ilé-è̩kó̩ àyàfi Ògúntólú tí ó jé̩ as̩áájú àti as̩ojú kíláàsì wo̩n tí òun jé̩ onílàákàyè  àti àwo̩n díè̩. Ó kù de̩dè̩ kí wó̩n jáde ìwé mé̩wàá ni Ké̩mi lóyún fún ò̩gá ilées̩é̩ kan tí ó ń jé̩ bàbá O̩lá. S̩ùgbó̩n bàbá O̩lá kò̩ jálè̩, kò gba oyún náà. Báyìí ni Ké̩mi s̩e bí o̩mo̩ tí kò ní bàbá. Bóyá èyí ni ó mú kí Ké̩mi pinnu láti yí padà kúrò láàárín e̩gbé̩ oníranù, tí ó sì yan rere.
  Lé̩yìn tí Ké̩mi ti jáde ilé-è̩kó̩ olùkó̩ni kìn-ín-ní, ó ń s̩e is̩é̩ olùkó̩ ní ilé è̩kó̩ kan ní ìlú Ilés̩a. Ó ní àfé̩só̩nà kan tí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Bím̀bó̩. Àkókò ìgbéyàwó wo̩n kù dè̩dè̩ ni awo ya sí Bím̀bó̩ ló̩wó̩ pé Ké̩mi ti bímo̩ kan rí, èyí tí kò jé̩ kí òun mò̩. Bím̀bó̩ ko̩ Ké̩mi sílè̩. Nínú ìrònú yìí ni Ké̩mi sì wà nígbà tí ìjàǹbá ńlá s̩e̩lè̩ sí bàbá O̩lá tí i  s̩e bàbá o̩mo̩ Ké̩mi. È̩san ìwà tí ó hù sí Ké̩mi ni ó so̩ ó̩ di aláìtíìló̩mo̩ láyé. Èyí ni ó sì mú kí ó padà wá be̩ Ké̩mi láti gba o̩mo̩ rè̩, Táyò̩.
   Níwò̩n ìgbà tí Bímbò̩ ti fi àáké kó̩rí pé òun kò níí fé̩ Ké̩mi mó ni ìyá Bó̩lá tíí s̩e ò̩ré̩minú Ké̩mi gbà a ní ìmò̩ràn láti fi ara mó̩ Kó̩lá tí ó nífè̩é̩ rè̩ gidigidi. Olùkó̩ni ní ilé-è̩kó̩ gbogbonìs̩e póli (poly-technic) ni Kó̩lá.
     Kò sí e̩ni tí kò ní ìgbè̩yìn nínú gbogbo àwo̩n aké̩kò̩ó̩ náà pátá; ìgbè̩yìn oníkálukú ló kàn yàtò̩ síra wo̩n. Àtubò̩tan ìwà àgbèrè àti ò̩pò̩ oyún tí Bímpé ti yo̩ dànù nígbà tí ó wà ní o̩mo̩ge ni ó lé e kúrò nílé o̩ko̩ lé̩yìn tí ó dúró fún o̩dún mé̩wàá gbáko láìrí o̩mo̩ gbé jó. Akin tí í s̩e o̩ko̩ rè̩ ìgbà náà lé e jáde. Èyí mú kí Bímpé padà lo̩ máa gbé ní ilé àlàpà tí àwo̩n òbí rè̩ kó̩ ní Omitótó, Ilode ní ìlú Ilé-Ifè̩. O̩jó̩ tí Bímpé lo̩ ra gbe̩re̩ tí yóò tún tà ló̩jà ni ó s̩e alábàápàdé Ògúntólú tí ó ti di ò̩gá àgbà ilé is̩é̩. Àtubò̩tán tàbí ìgbè̩yìn rere ni fún Tolú tí ó fi ojú sí è̩kó̩ rè̩. Tolú pinnu láti ran Bímpé ló̩wó̩.
    Ké̩mi pinnu láti fé̩ Kó̩lá. Àwo̩n méjèèjì sì fi o̩jó̩ ìgbéyàwó wo̩n sí os̩ù kéjìlá o̩dún náà. Àkókò tí Ké̩mi mú ìwé ìpè síbi aye̩ye̩ ì́gbeyàwó rè̩ lo̩ sí ò̩dò̩ Tolú ni ó gbó̩ pé o̩wó̩ s̩ìnkún àwo̩n agbófinró ti te̩ Wálé, Àjàyí àti àwo̩n méjì mìíràn, èyí tí wo̩n yóò fi è̩yìn wo̩n ti àgbá ní o̩jó̩ náà gan-an. Ìgbè̩yìn ti àwo̩n nìyí. S̩ugbó̩n Òjó ní tirè̩ tètè pinnu láti yan dáadáa. Òun tilè̩ máa ń kàwé ní òròòru ní àsìkò tí wó̩n wà ní sé̩kó̩ńdírì s̩ùgbó̩n àwo̩n ò̩ré̩ rè̩ kò mo̩ èyí. Èyí mú kí ó lè tè̩ síwájú nínú è̩kó̩ rè̩. Yunifásitì Ìbàdàn gan-an ni ó ti ké̩kò̩ó̩ gboyè ó sì ń s̩is̩é̩ olùkó̩ ní Ìbàdàn Grammar School.
    Gé̩gé̩ bí òwe tí òǹkò̩wé pa, òs̩é níí s̩áájú e̩kún, àbámò̩ ní í gbè̩yìn ò̩̩̀rò̩, gbogbo ò̩tò̩tò̩ ìlú pé jo̩, wo̩n kò rí e̩bo̩ àbámò̩ s̩e. Níbi tí e̩lé̩kún ti ń sunkún ni aláyò̩ ti ń yò̩ ni ò̩rò̩ ò̩hún. Àmó̩ ní ti Ké̩mi tí a gbà gé̩gé̩ bí olú-è̩dá ìtàn inú ìwé yìí, àbámò̩ kò s̩e bé̩è̩ gbè̩yìn ò̩rò̩ rè̩ tán pátápátá. Bé̩è̩ náà sì ni ti Òjó
ÀWO̩N O̩NÀ ÈDÈ YORÙBÁ TÍ Ó JE̩ YO̩ NÍNÚ ÌWÉ ÌGBÈ̩YÌN
O̩kan-ò-jò̩kan àkànlò èdè ayàwòrán ni ó ń tawó̩-tasè̩ nínú ìwé àpilè̩ko̩ Igbeyin. Òǹkò̩tàn sì s̩e àmúlò àwo̩n o̩nà èdè náà dáadáa. Ò̩gangan ibi tí òwe bá ye̩ kí ó ti wáyé ni a ti ń rí i. Òǹkò̩wé yìí kò gbé o̩mo̩ O̩bà fún Ò̩s̩un rárá. Èyí kò lè s̩àìmáà rì í bé̩è̩. Ohun tí ó s̩e okùnfà èyí kò fara sin rárá. Ògúnná gbòǹgbò tí ń dátó̩ lé̩nu ìgbín ni alàgbà Adékúnlé Adédire; ìmò̩ è̩dá-èdè tó yanranntí ni ó papò̩ mó̩ ìmò̩ lítírés̩ò̩. Èyí ni ó sì mú ìwé náà dùn mó̩ ni láti kà ní àkàgbádùn. Díè̩ lára àwo̩n o̩nà èdè Yorùbá tí ó hànde nínú ìwé náà ni òwe, àkànlò èdè, àdàpè/àfidípò, àfiwé tààrà, fìrósínròóje̩, ìbéèrè pèsìje̩, ìfò̩rò̩dárà, ìyánrò̩ fé̩é̩ré̩, àwítúnwí àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩.
ÒWE
Láìsí tàbí-s̩ùgbó̩n, òwe ni ó pò̩ju nínú àwo̩n o̩nà èdè Yorùbá tí ó je̩ jáde nínú ìwé náà. Ìwò̩nyí ni díè̩ lára àwo̩n òwe Yorùbá tí ó je̩ yo̩:
i.                    Òs̩é ní í s̩áájú e̩kún, àbámò̩ ní í gbè̩yìn ò̩rò̩. Gbogbo ò̩tò̩tò̩ ìlú pé jo̩, wo̩n kò rí e̩bo̩ àbámò s̩e.
ii.                  Ìwà o̩mo̩ níí mú o̩mo̩ je̩ òkígbé̩.
iii.                Ìdá ni ìkó.
iv.                Idà ń wólé ara rè, ó ní òun ń ba àkò̩ jé̩.
v.                  Àtijó̩ tí alákàn ti ń s̩epo, epo rè̩ kò kún ahá.
vi.                Àìfinipeni, àìfèèyàn pèèyàn tíí mú ará oko sán ibàǹté̩ wò̩lú.
vii.              O̩jó̩ ní í pé̩, ìpàdé kìí jìnnà.
viii.            Ikún ń jò̩gè̩dè̩, ikún ń rèdí mó̩lè̩, ikún ò mò̩ póhun tó dùn ní ń s̩ekú pani.
ix.                Apèèpo lé̩yìn àgbà, àgbà yóò kan è̩yin náà bó pé̩ bó yá.
x.                  Ojú tí kò rí pípó̩n iná, tí kò rí rè̩rè̩  òòrùn, kò lè rí ohun tó jo̩ bí ide̩.

ÀKÀNLÒ ÈDÈ
i.                    Ó dìgbà tí a bá fi e̩nìkan jófin…
ii.                  E̩ jé̩ kí a má fi òjò tiwo̩n gbinkà…
iii.                E̩ran àgbà ni o.
iv.                Ìye̩n ìtì ò̩gè̩dè̩.
v.                  Ó ti fé̩rè̩ jáwé dímú.
vi.                Wó̩n wí wí wí, mo ko̩tí ikún.
vii.              Ko ye ki a tun maa fi eko tanna funra wa.
viii.            À ní mo ti fé̩ra kù.
ix.                O̩wó̩ pálábá àwo̩n aké̩kò̩ó̩ bé̩è̩ yóò ségi.
ÀFIWÉ TÀÀRÀ
i.                    Ké̩mi, o ò rójú bàbá ye̩n bó s̩e wú gúdugùdu bíi kúlíkúlí Àjàs̩é̩-Ìpo.
ii.                  Wó̩n ń fi ó̩ ré̩rìn-ín fún àbùkù tó wà lára rè̩ bí owó páńda ni.
iii.                Tí ojú re̩ ń wami bí e̩kún eléji.
iv.                Tó wú tútú bí olóòwu òtùtú.
v.                  Gúdugùdu lojú rè̩ rí bí ojú e̩ni forí gbé ilé agbó̩n.
vi.                S̩e kò sí ǹǹkan tí o fi ń dá kùn bí òkú àgàn?
vii.              … tí è̩ ń bó eyín bí e̩ni je̩ púùlù.
ÌFÒ̩RÒ̩DÁRÀ
i.                    O̩mo̩nígèlègélé rè̩ ti s̩eré géle lónìí.
ii.                  Bàbá O̩lá ò wá, bàbá o̩là ló wá, kò sì mó̩là ló̩wó̩.
iii.                Ibi tí Ifá ti tà, wo̩n ò gbó̩fá, bé̩è̩ ni ìfà sì tún ń be̩ l’Ó̩fà níbi tí àwo̩n ènìyàn ti ń dífá tó ń fa ìfà á wá.
ÀFIDÍPÒ/ÀDÀPÈ
i.                    S̩è bí o mò̩ pé e̩ran àgbà ni
ii.                  Bàbá ti gbé̩mìí mì.
iii.                … títí tí mò̩mó̩ fi jé̩pè Olúwa.
iv.                Ké̩mi, bàbá Wálé ti jáwé dímú.
v.                   
ÀWO̩N È̩KÓ̩ TÍ A RÍ KÓ̩ NÍNÚ ÌWÉ ÌGBÈ̩YÌN
Àwo̩n àgbà bò̩, wó̩n ní bómi bá balè̩, a nípa, òjò balè̩ ta s̩àràs̩àrà. Ìdí òwe yìí ni pé kò sí òǹkò̩wé onís̩é̩ o̩nà alátinúdá tàbí òǹkò̩tàn tí kìí ní is̩é̩ kan tàbí òmíràn tí ó ń fi is̩é̩ rè̩ rán sí àwùjo̩. Bákan náà ni ti ìwé Igbeyin s̩e rí. Àwo̩n è̩kó̩ pò̩ lo̩ bí ilè̩ bí e̩ní fún tó̩mó̩dé-tàgbà láti s̩àmúlò nínú ìwé eré onís̩e abójú-ayé-mu yìí. Òtító̩ ni pé eré tó dá lórí àwo̩n ò̩dó̩ ni, àmó̩ kò sí e̩ni tí kò níí rí omi o̩gbó̩n bù mu nínú rè̩. Díè̩ nínú àwón è̩kó̩ tí ìwé yìí ń kó̩ wa nìyí:
Ní àkó̩kó̩, bí a bá ti ibi ìs̩áná kíyèsí òògùn, a ó rí i dájú pé eré yìí ń so̩ fún àwa aké̩kò̩ó̩ pé kò sí ohun tí a s̩e lónìí tí kò ní èrè lé̩yìnwá ò̩la. Àti pàápàá pé às̩egbé kan kò sí láyé, às̩epamó̩ ló wà.
A tún rí i kó̩ pé è̩san rere ń be̩ fún o̩mo̩ tí ó ko̩jú mó̩ è̩kó̩ rè̩, àti pé irú o̩mo̩ bé̩è̩ kò níí s̩e e̩rú e̩gbé̩ rè̩ ló̩jó̩ ò̩la. Bé̩è̩ náà ló sì jé̩ pé ìdàkejì ni fún irúfé̩ aké̩kò̩ó̩ tó bá ń sá kiri. Gbogbo àwo̩n aké̩kò̩ó̩ tí ó ń sá kiri ni ìgbè̩yin wo̩n polúkúrúmus̩u, àyàfi Òjó tí ó tètè s̩e àtúns̩e sí ò̩nà rè̩.
 È̩wè̩, a rí i kó̩ pé kí a má fi gbogbo ara máa tè̩lé àwo̩n e̩lé̩gbé̩ wa nípa ohun kan tàbí òmíràn tí wó̩n bá ń s̩e. Èyí ni ohun tí ó s̩e̩lè̩ láàárín Òjó àti àwo̩n e̩lé̩gbé̩ rè̩. S̩e àwo̩n ò kúkú mò̩ pé Òjo̩ a máa kàwé ní ò̩gànjó̩ òru nínú ilé rè̩, bé̩è̩ ni wó̩n sì ń s̩e àfarawé e rè̩, títí tí òun fí s̩e às̩eyege nínú ìdánwò às̩ekágbá.
   Bé̩è̩ náà ni ìwé yìí tún bá àwo̩n òbí wí pé o̩mo̩ ti̩ a ò bá kó̩ ni yóò gbé ilé tí a kó̩ tà. Èyí ni ti Wálé àti àwo̩n òbí i rè̩. Àwo̩n òbí i rè̩ ni wó̩n bà á jé̩ débi pé wó̩n gbà á láyè láti máa lo̩ sí òde àlo̩sùn.
  A kò s̩àìrí i dájú pé àtubò̩tán ìs̩ekús̩e àti oyún s̩ís̩é̩ kò dára. Bí i kó ránni ló̩run àìpé o̩jó̩, ó le ba ilé o̩mo̩ je̩ débi pé onítò̩hún le máà rí oyún ní débi tí yóò ní o̩mo̩ láyé. Èyí ni ó mú kí o̩ko̩ Bímpé kò̩ ó̩ sílè̩ lé̩yìn o̩dún mé̩wàá tí wó̩n ti jo̩ ń gbé.
  Ní àkótán, mo wòye pé òwe àwo̩n Yorùbá tó so̩ pé ‘ Ìgbè̩yìn ní í yé olókùú àdá’, àti pé ‘ Ìgbè̩yìn laláyò ń ta’ ni òǹkò̩wé yìí s̩e àgékúrú fún. Bí a bá sì yiri è̩ wò dáadáa, a ó rí i gbangba pé àwo̩n òwe náà bá àwo̩n ìs̩è̩lè̩ inú eré náà mu dáadáa.
Reference
M.A. Adekunle (1997), Ìgbẹ̀yìn. Ifẹ: Amat Publishers.

No comments:

Post a Comment