Friday, 17 March 2017

LAND


 (1) Land[1]

N/or: (i) Ilẹ̀: We made the journey by land, though flying would have been cheaper: Ọnà orí ilẹ̀ la gbà láti rin ìrìnàjò náà bí o ti lẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ ojú òfurufú rọjú jù ú lọ.

(ii) Adj/Aj: The Elephant is the largest living land animal. Erin ni ẹranko tó tóbi jù lọ tó ń gbé ní orí ilẹ̀.

 (iii) Landlord - onílé: A person or company from who you rent a room: Ẹni tàbí ilé-isẹ́ tí a lè gbá ilé lọ́wọ́ rẹ̀.


(2) Key: N/OR: Kọ́kọ́rọ́

(i) The spare of key: kọ́kọ́rọ́ kejì

(ii) N/OR: The key to success is preparation

                   Ìgbáradì ni kọ́kọ́rọ́ àṣeyọrí

(iii) N/OR: The driver of the car probably have the key to solve the matter. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ọwọ́ awakọ̀ náà ni a ti lè rí kọ́kọ́rọ́ tí a máa fi yanjú ọ̀rọ̀ yìí.

(iv) Adj/Aj: The girl played a key role in the dispute: Ọmọbìnrin náà kópa tó jọjú nínú aáwọ̀ náà.

 (v) Keyhole (N/OR) ojú kọ́kọ́rọ́ tí à ń ti kọ́kọ́rọ́ bọ̀ láti ti ilẹ̀kùn tàbí láti sí í.


(3) Kettle

Àgé (N/OR) (i) The woman is using an electrical kettle – Arábìnrin náà ń lo àgé ìdáná tí ó ń lo iná ẹ̀lẹ́ńtíríìkì

(ii) I will put the kettle on and make some tea: Máa tan àgé ìdáná náà láti po tíì kékeré.


(4) Kick (v/iṣ)

Tàpá.

(i) The child was dragged away, kicking and screaming - Wọn wọ ọmọ náà ni tìpá tì kùkù, bẹ́ẹ̀ lo ń han gan-an-ran

(ii) Stop kicking; it hurts: Má tàpá mọ́; ó ń dùn ni

(iii) The dancers kicked their leg in the air. Àwon oníjó náà tàpá ijó ninu afẹ́fẹ́

(iv) IDIOM (àkànlò): He kicks the bucket: Ó ta téru nípàá

(v) Kicker (N/OR): A person who kicks, especially the player in a sports team who kicks the ball to score points: Olùgbá - ẹni tí ó ń gbá bọ́ọ́lù kí ó lè baà gba àmì-ayò.

(5) Knife - ọ̀bẹ (N/OR)

 N/OR: (i)  The man was murdered in a frenzied knife attack. Ọ̀bẹ ni wọ́n fi gún arákùnrin náà pa

(ii) V/IṢ: The man knifes someone. Ọkùnrin náà gún ẹnikan ní ọ̀bẹ pa.


(6) Kiss: fífi ẹnu kora lẹ́nu V/IṢ

(i)      They stood in a door way kissing

          Wọ́n fẹnu kora lẹ́nu ọnà

(ii)     Come here and give me a kiss

          Sún mọ́ mi kó o fẹnu kòmí lẹ́nu

(iii)    We were greeted with hugs and kisses

          Wọ́n kí wa tẹ̀rín tọ̀yàyà

(iv)    Kisser: Olùfẹnukoralẹ́nu (N/OR)

(v)     Kiss off: Ìdádúró – N/OR

          The man got the kiss-off from his job!

          Wọ́n dá ọkùnrin náà dúró níbí iṣẹ́ rẹ̀.


(7)     Knee:  Orókún – (N/OR) I grazed my knee when I fell

Mo fi orókún bọ́lẹ̀ nígbà tí mo subú

(ii)     These jeans are torn at the knee:

          Sòkòtò jìn-ínsì wọ̀nyí ya lórókún

(iii)    v/iṣS: He kneed his attacker in the groin

          Ó kúnlẹ̀ le ọ̀tá rẹ̀ lórí kòtò itan

(iv)    Knee jark (adj/aj) without any serious thought: ìṣesí àironúlélórí: It was a knee jark on her part. Ìṣesí rẹ̀ jẹ́ èyi ti kò ronú lé lórí.


(8) Knot: ta kókó (N/OR)

(i)      To tie a knot: Láti tata kókó

(ii)     Tie the two ropes together with a knot?

          Fi kókó okùn kan ta okùn méjéèjì papọ̀

(iii)    He carefully knotted his tie: Ó fara balẹ̀ di táì rẹ̀ ni kókó

(iv)    Knotty: pakasọ: (Adj/Aj.): A knotty problem -  wahálà tó pakasọ


(9) Kind. Irú (N/OR)

(i)      She insulted him and he responded in kind.

          Obìnrin náà kàn án lábùkù, òun náà sí dà àbùkù náàpadà fún un.

(ii)     Kind dára/ìwà pẹ̀lẹ́ (Adj/Aj)

          The man is so kind to everybody – Ìwà ọkùnrin náà dára sí gbo ènìyàn

(iii)    Kindness – ìwà ọmọlúwàbí (N/OR)

          Her kindness saved her

          Ìwà ọmọlúwàbí obìnrin náa kó o yọ

(iv)    Kindly:  Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ (adv/Ap)

          She approached her kindly

          Ó sún mọ́ ọn pẹ̀lú ọ̀wọ̀


(10) Knowledge- ìmọ̀ (N/OR)

(i)      The boy sent the letter without my knowledge

          Ọmọkùnrin náà fi lẹ́tà náà ránsẹ́ láìjẹ́ pé mọ nímọ̀ nípa rẹ̀

(ii)     The lady denied all knowledge of the affairs

          Ọ̀dọ́mọbìnrin náà fárígá pe òhun kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà.

(iii)    Knowledgeable – O ni ìmọ̀ (Adj/aj)

          The man is very knowledgeable about plant

          Ọkùnrin náà jẹ́ ní ìmọ̀ nípa ewéko







[1] Okunade Mutiyat Adeola Translated these words

No comments:

Post a Comment