1.
Attraction – Ìfàmọ́ra[1]
(Adjective)
(a)
Fífèràn èyàn dé ibi pé
kí nǹkan pa wọ́n pọ̀
e.g. Olú fë fa Ṣadé mọ́ra
(Olu wants to attract Sade)
(b)
Ibi tí àwọn èyàn
fëràn láti lọ
e.g Èkó jẹ́ ibi tí ó
fani mọ́ra (Lagos is an attractive place)
(c)
Nǹkan tí ó jẹ́ kí
ènìyàn ní ìfẹ́ sí nǹkan kan
e.g. Ìwà ìrẹ̀lẹ rè
fani mọ́ra (His gentle manners attracts one)
2.
Authority – Ipò àṣẹ
(Adverb)
(a)
Ní àṣẹ láti darí àwọn
ènìyàn
e.g. Àwọn ọba ní àṣẹ
láti darí àwọn ènìyàn wọn (Kings have the authority to order their people)
(b)
Fífún láyè láti ṣe nǹkan
e.g. Bàbá mí fún mi láyè
láti darí ẹgbẹ́ náà fún òun (My father gave me the authority to lead the group
on his behalf)
3.
Awake – Ṣe àìsùn
(Verb)
(a)
Àìsùn
e.g. N kò sùn (I am
awake)
(b)
Kí ìmọ̀lára èèyàn ta jí
e.g. Nígbàkúùgbà tí mobá
ti rí i, ìfẹ́kúfẹ̀é ara mi máa ń jí pépé (Whenever I see her, my lust is
awakened)
4.
Drain – Ìmúgbẹ
(Noun/Verb)
(a)
Láti jẹ́ kí nǹkan gbẹ
nípa jíjẹ́ ki gbogbo omi ara rẹ̀ kúrò
e.g. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ kí
gbogbo omi ara ìrẹsì náà ro tán ni (I have just drained the water from the
rice)
(b)
Láti jë kí omi sàn kúrò
lára nǹkan
e.g. Omi inú síǹkì náà
ṣẹ̀ṣẹ̀ sàn kọjá tán ni (The water just got drained from the sink)
5.
Dress – Aṣọ (Noun)
Aṣọ Títí ti kéré jù
fún un (Titi’s dress is too short)
e.Dókítà náà wẹ egbò
rẹ̀ (The doctor dressed his wound)
(a)
Láti ṣètò nǹkan
e.g. Ó dára láti ṣètò
ilé rẹ ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan (It is good to dress your house once in a while)
6.
Drink – mu (verb)
(a)
Mu nǹkan
e.g. Mo máa n mu omi jù
(I drink water a lot)
7.
Driving – wakọ̀ (Verb)
(a)
Bí èyàn ṣe ń wa ọkọ̀
e.g. Ẹ̀gbọ́n mi máa ń
sáré tó bá ti ń wa ọkọ̀ (My brother likes driving really fast)
(b)
Dídarí nǹkan
e.g. Òun ni ó ń darí àpérò
ìpàdé náà (He is driving the discussion of the meeting)
8.
Drop – já bọ́ (Verb)
(a)
Kí nǹkan já bọ́
e.g. Ife náà ṣèèsì já
bọ́ ní ọwọ́ mi (I dropped the cup by mistake)
(b)
Subú lójijì
e.g. Ó subú lójijì tori
pé ó ti rẹ̀ ẹ́ jù (She dropped suddenly due to stress)
(c)
Tutù, wálẹ̀
e.g. Ojú ọjọ́ déédé tutu
ní ìtà (The weather just dropped outside)
(d)
Bọ́ sílẹ̀
e.g. Ọkọ̀ náà dúró láti
jẹ́ kí ó bọ́ sílẹ̀ ní iwájú ilé rẹ̀ (The vehicle stopped to drop him in front of
his house)
No comments:
Post a Comment