Friday, 20 January 2017

SHORT



Kúkurú[1]: A máa ń lò ó láti fi ṣe àpèjúwe ènìyàn (kúkúrú)

i.               Ènìyàn kúkúrú ni Adégbọlá

Adegbola is a short man

ii.             Ọmọkùnrin kúkurú náà wà níbẹ̀ ní àná

The short man was there yesterday.

iii.           Arábìnrin kúkurú náà kò sọ nǹkankan

The short woman said nothing

Kúrú: A fí ń s̩e àpèjúwe ènìyàn tí kò ga

i.               Ọkọ obìnrin náà kúrú

The woman’s husband is short

ii.             Àbúrò mi kúrú.

My younger brother is short.

Àáyá̩: A máa ń lò ó fún ǹǹkan ti ko gba àkókò púpọ̀.

i.               Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ parí iṣẹ́ náà láàárìń ìṣẹ́jú àáyá.

The student finished the work within a short period of time.


SHOP:

Ilé-o̩jà: Ibi tí a ń kó ẹru ọja wá sí.

i.               Arákunrin náà tọ́jú gbogbo ọja rẹ sínú ilé-o̩jà lánàá.

The man kept all his goods in the shop yesterday.

Ilé-ìtajà: Ibi tí a ti ń tajà

i.               Ilé ìtaja To̩la kò jìnà sí ilé ìfowópamọ́ àgbáyé.

Tola’s shop is not far from the world bank.


SHOOT:

Ya: S̩íṣe àfihàn sinimá

i.               Àwọn eléré ìtàgé wa ya eré orí-ìtàgé ládùúgbò wa

The actor/actress shot a play in our area/community

Yìn: Títa o̩ta láti inú ìbo̩n

i.               Bọla fé̩ yin ìbo̩n fún ọmọbinrin náà

Bola wants to shoot the girl with a gun

Hù: A maa ń lò ó fún ohun tí ó bá ń so láti inú ilè̩

i.               Ẹwá náà ma hù jáde láti inú ilẹ.

The beans will shoot out of the ground.

Gba: Gbígbá bọ́ọ̀lù lo si oke

i.               Sala gbọ́dọ̀ gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọ̀n.

Sala must shoot the ball into the net




SHOE:

Bàtà: Nǹkan tí a má ń wò̩ sí e̩sè̩

i.               Tádé ji bàtà Kikẹ.

Tade stole Kike’s shoe

ii.             Adé ra bàtà tó wuyì fún Jo̩ké̩.

Ade bought a nice shoe for Joke.


SHIP:

Ọkọ̀ Ojú omi: Ó jé̩ ohun tí à ń fi kó ẹrù lórí omi.

                                       i.              Wọ́n f ọkọ̀ ojú omi kó ẹrù náà wá

They brought all the goods with the ship

ii.             Ọkọ̀ ojú omi ti gúnlẹ̀ sí èbúté.

The ship has arrived at the port


SHINE:

Ràn: Tan ìmó̩lè̩

                                       i.              Ó ye̩ kí òorùn ràn ní ò̩la

The sun ought to shine tomorrow

Dán:

i.               Ìpara  ye̩n á mú ara re̩ dán

That cream will make your body shine


SHELF:

 Pẹpẹ: Àte̩ igi tí a máa ń kó ǹǹkan sí

i.               Àwọn ìwé náà wa lóri pẹpe̩

The books are on the shelf

ii.             Dayọ̀ fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ sí ori pẹpẹ

Dayọ put the phone on the shelf


SHEET:

Abala: Ojú ìwé

i.               Fún mi ní ìwé abala méjì

Give me two sheets of paper

ii.             Ó gba abala ìwé kan sí i nígbà ìdánwò

He requested for an extra sheet during the exam

SHEEP

Àgùntàn: Orísi e̩ranko kan

i.               Bàbá mi ní àgùntàn tó pọ̀

My father has many sheep

ii.             Arákùnrin Haúsá tí ó wà ní è̩yìn ilé wa ní àgùntàn méje

The Hausa man at the back of our house has seven sheep

SHADOW:

Òjijí: Àwòrán nǹkan

i.               Nígbà tí ̀òor̀un lọ sílẹ̀ , a rí Òjìjí ní pápá ìṣeré náà.

As the sun went down we saw long shadows on the field.

Ìpasè:

i.               Bàbá náà wí fún ọmọkùnrin náà pé “O̩mọkùnrin! máa tọ ìpasẹ̀ mi”

The man said to the boy, “Oh boy! Walk in my shadow”


SHAKE:

Bò̩:

i.               Ṣọlá fé̩ bọ Jídé lọ́wọ́

Sola wants to shake Jide’s hnad

Gbò̩n:

i.               Bọ́sẹ̀ ń gbò̩n ní ìgbà náà

Bose was shaking (shivering) at that time


SHADE:

Àtùpà:

i.               Àtùpà náà mọ́lẹ̀ kedere

The shade is clear and bright

Ibòji:

ii.             Àwọn ọmọdé náà ń ṣeré ní abẹ́ Ibòji igi oróǹbó.

The children are playing under the shade of the orange tree.


SHE:

A ń lò ó fún obìnrin:

i.               Obìnrin náà re̩wà

She is beautiful

ii.             Obìnrin náà ń jà bíi kìnìún

She fights like a lion


SEX:

Ìbálòpò̩:

i.               T’o̩ko̩, t’aya ni ìbálòpò̩ wá fún

Sex is meant for husband and wife

È̩yà abo àti ako̩/ È̩yà obìnrin àti o̩kùnrin:

i.                    Ìbejì tí Ìyá Fúnmi bí jé̩ o̩kùnrin àti obìnrin

The sexes of the twins delivered of Funmi’s mother were male and female


SEVEN:

Méje:

i.               O̩jó̩ méje ló wà nínú ò̩sè̩

There are seven days in a week

ii.             Igi méje ló wà nínú o̩gbà ilé-ẹ̀kọ́ mi

There are seven trees in my school compound


SEVERAL

Àìmo̩ye: ̀o̩p̀o̩lo̩p̀o̩

i.               Ó s̩e àpétúnpè ìbéèrè náà ní àìmo̩ye ìgbà

He repeated the question several times

Onírúuru:

i.               Onírúuru as̩o̩ ló wà ní ọjà Gbági

Several kinds of clothes are in Gbagi market


SHARP:

Mú:

i.               Bàbá Bó̩lá fi àdá tí ó mú gé igi.

Bola’s father used a sharp cutlass to cut the tree

ii.             Ìya S̩o̩lá fi ̀o̩be̩ tí ó mú pa àkùkọ adìe náà.

Sola’s mother killed the cock with a sharp knife.

Yára:

i.               Ọmọbìnrin náà máa ń yára rìn

The girl walks fast.

Jáfáfá:

i.               Ọmọkùnrin náà jáfáfá ní gbogbo ọ̀nà.

The boy is sharp in all aspects.


SHAPE:

Àwòrán: Bí ǹǹkan tàbí ènìyàn s̩e rí

                                       i.              Àwòrán ìwé náà kò dára.

The shape of the book is not good.

Ìrisí:

i.               Ìrisí ilé tuntun náà rí rogodo.

The shape of the new house is round.        







SHARE:

Ìpín: Ohun tí ó wà fún ènìyàn tàbí àwo̩n ènìyàn

i.               Fún mi ní ìpin tèmi.

Give me my own share

ii.             Ípín tí wọ̩́n fúnnínú ogún baba mi kéré

My share f my father’s inheritance was small

Pí́n: Fún àwo̩n ènìyàn ní nǹkan káàkiri

i.               Ó máa pín ò̩gè̩dè̩ ye̩n fún gbogbo wa

He will share the plaintain among us all

SHIRT:

 È̩wù àwò̩sókè: È̩wù Òyìnbó tí àwo̩n o̩kùnrin máa ń wò̩ sí okè sòkòtò

i.               O̩kùnrin náà ń wo̩ è̩wù àwò̩sókè aláwò̩ ewé

The boy is wearing a green shirt

ii.             È̩wù àwò̩sókè yìí gùn jù fún e̩

This shirt is too long for you.

           






[1] These items were translated by Omowunmi Omosola Iyawe.


           


No comments:

Post a Comment