1. Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ[1]
Ariwo
tí a ń gbọ́ káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lónìí ni
ìpè fún ìtanijí gbogbo olùgbé àṣùwàdà ènìyàn yìí sí ojúṣe ẹni kọ̀ọ̀kan fún
ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀. Láti lè jẹ́ ìpè náà bó ṣe
tọ́ àti bó ṣe yẹ, ó yẹ kí kálukú wa kọ́kọ́ ṣe àyèwò ara rẹ̀ bí òun gan-an
alára bá mọ ojúṣe rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó dìgbà tí a bá lè yangàn fúnra wa
pé àwa gan-an lápapò àti ní ẹni kọ̀ọ̀kan mọ ojúṣe wa sí orílẹ̀-èdè wa ká tó
lè fọwọ́ sọ̀yà pé a tó ìpè ìjọba í jẹ́, fún ìtanijí gbogbo ènìyàn yòókù sí
ojúṣe wọn fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè wa.
Ẹni tí kò
mọ àṣà fún ìbágbépọ̀ ìrọ̀rùn pẹ̀lú àwọn ènìyàn àyíká rẹ̀, kò lè yangàn pé
òun mọ ojúṣe òun fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú àwùjọ gan-an tó ń gbé, débi
tí yóò mọ ojúṣe rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ lápapọ̀ (Awóníyì, 1975:363). Nítorí
ìmọrírì òdodo ọ̀rọ̀ pé “ilé la ti í kẹ́sọ̀ọ́ rode”, ló fi yẹ pé kí gbogbo
ọmọ Yorùbá kọ́kọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ojúṣe wọn bó bá tọ̀nà, kí wọn tó lè kópa
tó gúnmọ láwùjọ gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè yìí nínú jíjẹ́ ìpè ìjọba.
Nírorí pé a
nígbàgbọ́ pé ó ṣeé ṣe pé kí ọ̀pọ̀ nínú àwọn àgbà Yorùbá tí dáńgájíá nínú
ìmọ̀ àti ìlò àṣà ọmọlúwàbí láwùjọ la ṣe dojú iṣẹ́ yìí kọ àwọn ògo
wẹẹrẹ ní pàtàkì jù lọ, tó ṣe ṣe pé kí wọn má mọwọ́ ọ̀tún dá yatọ̀ sí
tòṣì nípa ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọmọlúwàbí tí í gbé orílẹ̀-èdè dé èbúté rere.
2. Oríkì Àṣà[2]
Àṣà ènìyàn
kan pàtó ni ìṣesí tàbí ìhùwàsí tí a mọ̀ mọ olúwarẹ̀, tó yà á sọ́tò sí ẹ̀dá
ènìyàn mìíràn. Yorùbá a máa lo ọ̀rọ̀ ìṣe ‘dá’ fún ìṣesí tàbí ìhùwàsí tí a kà
kún àṣà. Wọn a ní ènìyàn ‘dá’ àṣà tó rí ṣà fúnra rẹ̀ ní àyíká rẹ̀. Ènìyàn
sì lè ‘kọ́’ àṣà lọ́dọ̀ ẹni tó rìn pàdé tàbí tó bá gbé pò láyìíká, bẹ́ẹ̀ sì ni
ènìyàn lè jogún àṣà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Wọn a ní ènìyàn káṣà (kọ́ àṣà)[3]
aláṣà.,
Bí àṣà rere
ti wà náà ni àṣà burúkú wà. Ṣé tibitire la dálé ayé. Gbogbo ìṣesí àti
ìhùwàsí tó yẹ ọmọlúwàbí ènìyàn tó sì lè ṣeé bá ẹ̀dá ènìyàn tí a ń bá gbé
pọ̀ láwùjọ lára mu débi pé ó lè ṣe àwa àtàwọn láǹfààní ni a kà kún àṣà
rere (Awóníyì, 1975:357). Nídà kejì
ẹ̀wẹ̀, ìṣesí àti ìhùwàsí yòówù tí kò lè ṣe ẹ̀dá ènìyàn, yálà, ẹni tó ṣèṣe
tàbí tí ó hùwà náà fúnra rẹ̀, àwọn alájọgbó tàbí alábàágbé rè láwùjọ
láǹfààní, tó tilẹ̀ lè pa òun fúnra rẹ̀ tàbí àwọn ẹlòmíràn lára tàbí tí ó lè
ṣe wọ́n níjàmbá ni a kà kún àṣà tàbí ìwà burúkú (Abímbọ́lá, 1975:389). Fún
àpẹẹrẹ, àwọn ìhùwàsí bí olè jíjà, ìmẹ́lẹ́ tàbí ọ̀lẹ síṣe, ìpànìyàn,
ìdigunjalè, ìṣàgbèrè, ahun síṣe, òfófó síṣe, ìdìtẹ̀, ìjáfara, ìgbéraga àti
àwọn ìhùwàsí búburú mìíràn tó lòdì sí ìfẹ́ àwùjọ ènìyàn ni a kà kún àṣà
burúkù.
Nígbà tí
ìṣesí tàbí ìhùwàsí kàn bá di bárakú fún ẹ̀dá ènìyàn kan ni a máa ń kà á kún
àṣà rẹ̀, ì báà ṣe àṣà rere tàbí àṣà burúkù. Bí Yorùbá bá ṣàkíyèsí pé ẹ̀dá
ènìyàn kan ní àṣà rere kan tó ń ṣe é ní àǹfààní tó hànde, wọn a máa là kaka láti
kọ́ irú àṣà bẹ́ẹ̀ tí wọn kò bá tíì ní in tẹ́lẹ̀. Nídà kejì ẹ̀wẹ̀, tí Yorùbá
bá mọ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́ àṣà burúkú kan, wọn a máa sára fúnrú ẹni
bẹ́ẹ̀ kó má baà kó àṣà burúkú ọwọ́ rẹ̀ ràn wọ́n. Wọn a tilẹ̀ máa ki ẹni
wọn nílọ̀ pé kó má ṣe bá aláṣà burúkú náà rìn kó má baà kó àṣà burúkú tí a
ti mọ̀ ọ́n mọ́ ran onítọ̀hún.
3. Àlọ́ àti Àṣà
3.1 Ìfáárà
Ipò
pàtàkì ni Yorùbá to àlọ́ sí lágbo ńlá lítíréṣọ́ nípa kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àṣà.
Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ‘lílò’ tí Bascom dábàá gẹ́gẹ́ bíi tíọ́rì tó tọ̀nà jù lọ
láti máa fi ṣe àtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ àti àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ gbogbo, bí ìtàn
ìwáṣẹ̀ àti fókìlọọ̀ (Dorson, 1972:21). Ẹ̀dá inú àlọ́ ni apàlọ́ hun àṣà tó
fẹ́ fi kọ́ àwùjọ̀ lọ́gbọ́n mọ́ lára. Lára ohun tí apàlọ́ ń kíyè sí kó tó gbé
ìṣẹ́ fún ẹ̀dá yòówù ó jẹ́ nínú àlọ́ ni bí àbùdá, ìrísí, ìṣesí àti ìhùwàsí tí
apàlọ́ ti mọ̀ mọ irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ṣe lẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ irú iṣẹ́ tí a
fẹ́ gbé fún un náà (Finnegan, 1967:344-346). Fún àpẹẹrẹ, iṣẹ́ tí í fi èrè
ìwà ọ̀dàlẹ̀, tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun, ọgbọ́n àrékérekè, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ọgbọ́n ìjàǹbá
hàn ni apàlọ sáábà ń rán alábahun Ìjàpá nínú àlọ́ (Babalọlá, 1973).
Nígbà tí
àpàlọ́ bá fẹ́ rán ahun nírú iṣẹ́ báwọ̀nyí, ó sáábà ń fi ẹ̀dá mìíràn tí ìhùwàsí
àti àbùdá rẹ̀ lòdì sí ti alábahun ta ko Ìjàpá. Dípò pé kí apálọ́ (olùsẹ̀dá
àlọ́) jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó fẹ́ fi ìtàn inú àlọ́ náà kọ́ àwùjọ hàn ní kíákíá, ó máa
ń fún àwọn ẹ̀dá inú àlọ́ náà láyè láti tayò àmúlò àṣà tàbí ọgbọ́n rere àti
búburú, bó tílẹ̀ jẹ́ pé àṣà tàbí ọgbọ́n tí apàlọ́ gbàgbọ́ pé ó wúlò, tó sì
fẹ́ fi kọ́ àwùjọ ni yóò pàpà jẹ́ kó borí ọgbọ́n tí àwùjọ lòdì sí, ṣùgbọ́n
tó ti fún ẹ̀dá inú àlọ́ náà lò ní àlòtẹ́rùn. Níbi tí àwọn ẹ̀dà inú àlọ́ ti ń
tàkòtó àmúlò ọgbọ́n ni ẹ̀kọ́ inú àlọ́ ti í hàn sí olóye ènìyàn kí apàlọ́ wá tó
fa ọgbọ́n yọ ní ìkádìí àlọ́, pàápàá fún ọmọdé.
Fún àpẹẹrẹ,
nínú àlọ́ ‘Ìjàpá Rí Ilẹ̀ tí ó lójú’ (Babalọlá, 1973b:70) ni apàlọ́ ti fi ìwà
sùúrù, ìwà pẹ̀lẹ́ àti làákàyè ẹyẹlé ta ko ìwà ojúkòkòrò, ànìkànjopọ́n àti
àrékérekè alábahun Ìjàpá. Nígbà tí apàlọ́ náà ń hun ìtàn inú àlọ́ nàá pọ̀ mọ́
àwọn olú ẹ̀dá tó lò, ìjàpá, ẹyẹlé, àna ẹyẹlé, abbl., ó mú kí àwọn olú ẹ̀dá
ìtàn méjèèjì, ìjàpá àti ẹyẹlé, máa yí ara wọn sébè àti sí poro nípa àmúlò
ọgbọ́n. Bí alábahun ti ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí a mọ̀ ọ́n mọ́ jẹ ẹyẹlé níyà,
náà ni ẹyẹlé ń fi ìwà sùúrù àti làákàyè jàjàgbara. Nítorí ẹ̀kọ́ tí apàlọ́ fẹ́
fi kọ́ àwùjọ nínú àlọ́ náà, pé ‘àkọ́dá oró kò dà bí oró àdágbẹ̀yìn’, ó fi àyè
gba alábahun Ìjàpá láti kọ́kọ́ fi ọgbọ́n àrékérekè jẹ ẹyẹlẹ́ níyà kí apàlọ́
ọ̀hún tó wá fún ẹyẹlé láyè láti fi hàn pé bẹbẹ ọgbọ́n kò pin sọ́dọ̀ ẹni
kan ṣoṣo.
Lára àwọn
ìwà burúkù tí a ti mọ̀ mọ alábahun Ìjàpá, tí a sì fún un láyè láti hù tẹ́rùn
nínú àlọ́ òkè yẹn ni ìwà àìsòótọ́, àìṣeégbẹ́kẹ̀lẹ́, àrékérekè, wọ̀bìà,
ojúkòkòrò, ahun, àṣerínikójẹ, àjẹkì, ọ̀kánjúà, àgàbàgebè, òfófó,
ìfèrúgbàbùkún àti ẹnu-àìmẹ́nu. Gbogbo ìhùwàsí wọ̀nyí àti irú wọn mìíràn ni
àwùjọ Yorùbá lòdì sí. Lára àwọn ìwà tó bá àwùjọ lára mu tí apàlọ́ mú kí
ẹyẹlé hù nínú àlọ́ náà ni ìwà ìfẹ́ tòótọ́, ìpamọ́ra, sùúrù, ìtẹ́lọ́rùn, ìwà
tútù àti ọgbọ́n inú.
Nínú àlọ́
‘Ìjàpá jí iṣu Ìgbín àná rẹ̀’ (Babalọlá, 1973a:107) apàlọ́ hun onírúurú èrè
àṣà tó jẹ mọ́ olè jíjà mọ́ Ìjàpá àti Ìgbín àna rẹ̀ lára. Ìjàpá jèrè ìtìjú
nígbà tí Ìgbín àna rẹ̀ jèrè ìwà àṣejù. Nínú àlọ́ mìíràn, ‘Òjòlá ṣahun sí
Ìjàpá’ (Babalọlá, 1973b:132). ni apàlọ́
ti hun èrè àṣà ahun síṣe pọ̀ mọ́ Ìjàpá àti Òjòlá lára ṣùgbọ́n Ìjàpá ṣe àmúlò ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti
jẹ Òjòlá lójèé; èyí tó fa òwe ‘ènìyàn ní í kọ́ni pé ká gùn, ènìyàn ní sì í
kọ́ni pé ká kúrú.’ Nínú àlọ́ mìíràn ni apàlọ́ ti hun ẹ̀kọ́ àṣà àmúlò ọgbọ́n
pọ̀ mọ́ Ìjàpá (kòtòǹkan ẹranko) àti erinmi (tó tóbi jù lọ láwùjọ ẹran inú
omi). Nínú àlọ́ yìí, ‘Ìjàpá, Erin Òkè àti Erinmi’ (Babalọlá, 1973a:56), ni
Ìjàpá ti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ jẹ àwọn ‘atóbanti má lọ́gbọ́n nínú’ ẹranko wọ̀nyí
lójèé, èyí tó bí àkànlò èdè ‘ọgbọ́n ju agbára’. Yàtọ̀ sí àwọn àpẹẹrẹ àlọ́ òkè
wọ̀nyẹn, onírúurú àlọ́ mìíràn tó fi ìbáṣepọ̀ ènìyàn sí ènìyàn àti ènìyàn sí
ẹranko hàn lò wà, tó sì wúlò fún ìtanijí sí àṣà tó wúlò fún ìbágbépọ̀ ènìyàn
ní àwùjọ. Fún àpẹẹrẹ, nínú àlọ́ ‘Ọmọ́yọ àti Erè: (Abọ́dúndé: tó ń bọ̀
lọ́nà) ni apàlọ́ ti hua ọ̀kan-ò-jọ̀kan àpẹẹrẹ àṣà àwùjọ pọ̀ mọ́ra wọn sí.
Nígbà tí alóyinlétè apàlọ́ yóò bá fi kádìí àlọ́ náà ni onírúurú ẹ̀kọ́ yóò ti
hànde.
Nínú àṣà
àsùwàdà ènìyàn tó para pọ̀ sínú àlọ́ náà la ti rí
3.2 Àwọn Ohun tí a máa ń Rí nínú Àṣà Asùwàdà Ènìyàn
3.2. 1. Àṣà Ẹbí Síṣe
Ìpìlẹ̀
ẹbí nílẹ̀ Yorùbá ni ọkọ (baba Ọmọ́yọ), ìyàwó (ìyá Ọmọ́yọ) ọmọ (Ọmọ́yọ).
Ọmọ́yọ, ọ̀dọ́mọbìnrin awẹ́lẹ́wà tó ń wá ọkọ ni àpẹẹrẹ ète ìfẹ̀lójú
mọ̀lẹ́bí. Nígbà tí Ọmọ́yọ bá lọ́kọ, òun àti ọkọ tirẹ̀ ni yóò bẹ̀rẹ̀ ẹbí
tuntun, nípa bẹ́ẹ̀, igi ẹbí tí baba Ọmọ́yọ gbìn bẹ̀rẹ̀ sí í pẹka nìyẹn.
3.2.2. Ìgbàgbọ́ Yorùbá
Èyí
ni apàlọ́ ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbáṣepọ̀ tó wáyé láàrin Ọmọyọ (ẹ̀dá ènìyàn)
àti ẹbọra (erò tó gbáwọ̀ ẹ̀dá ènìyàn wọ̀) pẹ̀lú ète àtinájà aráyè. Àṣífẹ́
wáyé láàrin Ọmọ́yọ (ènìyàn) àti erè (àdàmọ̀dènìyàn). Agbára ẹbọra ta ti ènìyàn
yọ nípa àyípadà sí ẹ̀dá ènìyàn tó máa ń rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti ṣe gẹ́gẹ́
ìgbàgbọ́ ènìyàn.
3.2.3. Àfìhàn Àṣà Iṣẹ́ Ọdẹ Ṣíṣe
Ọdẹ
ni olùgbàlà Ọmọ́yọ nínú àlọ́ yìí. Agbára tí ẹlẹ́dàá fún ẹ̀dá ènìyàn lórí
ẹranko ló jẹ́ kí ọdẹ kápá erè nígbà tó ń ṣèṣe ẹranko lọ́wọ́. Èyí tún fi
pàtàkì iṣẹ́ ọdẹ hàn; èyí tí í ṣe ààbò ìlú àti olùgbé rẹ̀.
3.2.4. Àṣà Ọjà Níná
Jákèjádò
ilẹ̀ Yorùbá la ti í nájà òòjọ́ (ojoojúmọ́), ọrọọrún, isiisán, ìtàdógún,
abbl. Ìgbàgbọ́ Yorùbá sí ni pé àtènìyàn àtẹbọra pẹ̀lú ẹ̀mí àìrí mìíràn gbogbo
ní í ṣe àkọlùkọgbà nínú ọjà lásìkò tí ọjà níná bá ń lọ lọ́wọ́.
3.2.5. Èrè Ìwà Ìgbéraga
Ọmọ́yọ fi
ìwà ìgbéraga lòdì sí àṣà rere tí í ṣe ìgbọràn. Tó bá jẹ́ pé Ọmọyọ gbọ́ràn
sí àwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu nípa pé kó gbà láti fẹ́ ọkọ láàrin ènìyàn ẹlẹgbẹ́
rẹ̀, kì bá tí fojú kòkòrò kàgbákò ẹbọra tó ṣì fẹ́ ẹ lọ́kọ. Ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀
Ọmọ́yọ ló ń dúró de ọmọdé tí kò bọ̀wọ̀ fún òbí rẹ̀ nípa gbígbọ́ràn sí wọn
lẹ́nu.
3.2.6. Ohun Èlò Iṣẹ́ Ọdẹ
Ọ̀bẹ
aṣóró tí ọdẹ fi pa ẹbọra erè jẹ́ ọ̀kan lára ohun èlò iṣẹ́ ọdẹ.
3..2.7. Orin Kíkọ
Ipò
iyọ̀ amọ́bẹ̀dùn ni apàlọ́ to orin kíkọ́ sí nínú àlọ́ àpagbè. Orin kíkọ kì í
jẹ́ kí òǹwòran àlọ́ sùn lọ títí tí wọn yóò fi rí ẹ̀kọ́ fà yọ nínú ìtàn
àlọ́. Orin àlọ́, lọ́pọ̀ ìgb, a máa jẹ́ ìsọníṣókí ìtàn inú àlọ́. Àtúnkọtúnkọ
rẹ̀ sì máa ń gbin ẹ̀kọ́/kókó inú àlọ́ sọ́kàn olùgbọ́ àti èrò ìwòran.
3.2.8. Ọnà Àlọ́ Àpagbè
Ìtàkúrọ̀sọ
tó ń wáyé láàrin apàlọ́ àti elègbè àlọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ àlọ́ òkè yìí wà ní ìbámu
pẹ̀lú àṣà. Ọ̀nà àtimáaṣe àkójọ àwọn elègbè orin àlọ́ ni ó jẹ́ ìdí pàtàkì
kan tó fi í wáyé. Nígbà mìíràn, apàlọ́ a máa fi àlọ́ àpamọ̀ bíi mélòó kan, àrọ̀
jíjá tàbí ìmọ́ bíbú kún bátànì ìtàkúrọ̀sọ bẹ́ẹ̀.
3.2.9. Ìkádìí Àló
Ìdí
àlọ́ mi rèé gbáńgbáláká
Ìdí àlọ́ mi
rèé gbàǹgbàlàkà …’
Kò ní ìtumọ̀ kan pàtó ju ète ìfọ̀rọ̀dárà, tó tún jẹ́ ìpèdè
tó ya àlọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ mìíràn. Ọgbọ́n àtimú ìtàn dùn náà ni.
Onírúurú ọnà
èdè ni apàlọ́ máa ń mú lò láti hun ìtàn inú àlọ́ pọ̀, tó ń mú kí àlọ́ dùn kó sì
lárinrin. Irú ọnà èdè bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ aṣàpèjúwe (àpèjúwe ẹwà ọmọkùnrin tí
wọ Ọmọ́yọ lójú), àwítúnwí, àfiwé (dára bí egbin).
3..2.9. Àló gẹ́gẹ́ bíi díńgí
Nígbà mìíràn,
Yorùbá a máa lo àlọ́ gẹ́gẹ́ bíi díńgí láti fi wo ohun tí wọn ì bá fẹ́ lọ́kàn
wọn pé kó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n bí ó tilè jẹ́ pé ìtàn, àwígbọ́ tàbí ìrírí kò fi
hàn pé ó ṣẹlẹ̀ rí tàbí pé ó lè ṣẹlẹ́ ní ìgbésí ayé ènìyàn. Alábahun Ìjàpá
jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú èròjà àyíká tí àwọn apàlọ́ sáábà ń hun irúfẹ́ àlọ́ bẹ́ẹ̀
mọ́ lára. Ète ìkìlọ̀ ìwà ‘àlá ọ̀sán’ tí
í ṣokùnfà ìwà ojúkòkòrò, tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìwà bí ìdigunjalè la bá débi irú àlọ́
bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àlọ́ ‘Ìjàpá àti
àbọ̀n ẹyìn’ (Babalọlá, 1973a:29) lọ báyìí:
Nígbà tí ìyàn mú ní ìlú Ìjàpá, Ìjàpá lọ ko àbọ̀n ẹyìn kan
tó bọ́ sínú òkun. Ìjàpá kán lu omi òkun pẹ̀lú ìlàkàkà àtitọ̀pa àbọ̀n ẹyin náà
délé olókun, ọba omi. Olókun ṣàánú Ìjàpá nípa pé ó fún un ní àràmọ̀ǹdà
ìgbakọ kan
tó lè pèsè gbogbo ohun tí ẹnu ń jẹ tí Ìjàpá bá ti lè sọ pé ‘Ìgbakọǹkọyán,
ìgbakọǹkọkà, ìgbakọǹkọ gbogboǹkan fẹ́lẹ́fẹ̀lẹ’. Ìjàpà lo ìgbakọ yìí
làti rọ̀yàn òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀, kó tó fi ayọ̀ fọ́ ọ, tó sì pàdánu ìgbakọ̀
náà pẹ̀lú ìjìyà tó dógbin…
Apàlọ́ jẹ́ kí Ìjàpá pàdánù
àràmọ̀ǹdà ìgbákọ pẹ̀lú ìjìyà tó dógbin láti kó ‘àlá ọ̀sán’ náà kúrò lọ́kàn
olùgbọ́ tó lè máa rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lójú ayé
kó sì máa lépa rẹ̀ lọ́kàn ara rẹ̀.
Nígbà tí a rí àpẹẹrẹ àṣà Yorùbá
tó pọ̀ tó tòkè yẹn fà yọ nínú àpẹẹrẹ àlọ́ tí a lò lókè yẹn, a kò ṣàìmọ̀
pé ẹni tó pe àlọ́ ní ibú àṣà Yorùbá kò jayò pa, pàápàá, bí a bá fojú inú wo
ọ̀kẹ́-àìmọ̀ye àpẹẹrẹ àṣà tí a lè bá pàdé nínú ogunlọ́gọ̀ àlọ́ tó wà.
4. Àgbálọgbábọ̀
Yorùbá
bọ̀, wọ́n ní ‘Ó rọrùn láti mú igi gùn látìsàlẹ̀ ju ká múgi gùn látòkè lọ̀’.
Àìtìdí-múgi ẹ̀kọ́ àṣà gùn nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ wa bó ṣe tọ́
àti bó ṣe yẹ láti ìbẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ ayé wọn ló fa ìpè àpàpàǹdodo fún ìtanijí
tó gbòde kan
báyìí.
Ọ̀kan pàtàkì
nínú èròjà àjogúnbá tí a ní ṣùgbọ́n tí a kò kọbi-ara sí lílò rẹ̀ ni àlọ́ jẹ́.
Àlọ́ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí àtìrandíran Yorùbá fi í kọ́mọ lẹ́kọ̀ọ́ àṣà látìgbà
ìwáṣẹ̀. Àìkọbi-ara sí ìlò àlọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ ká ṣe kún ohun tó
jẹ́ kí ìwà búburú gbogbo gbòde kan nílẹ̀ wa lónìí, tó sì fa ariwo ìtanjijí
àwùjọ wa sí ojúṣe ẹni kọ̀ọ̀kàn tí à ń pa báyìí. Ṣùgbọ́n ó sì bà ni, kòì
bàjẹ́. Kó má baà bàjẹ́ tán ló fi yẹ kí á tètè ṣán ṣòkòtò wa kó le, nípa
àmúlò àlọ́ àti ẹ̀ka lítíréṣọ̀ wa yòókù tí àwọn baba-ńlá Yorùbá ti hun àṣà
rere àti ọgbọ́n-àmúlò-ṣelé-ayé-ẹni mọ́ lára, fún kíkọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ wa
lẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere. Èyí ló lè mú kí ìdàrúdàpọ̀ tó ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wa
lórílẹ̀-èdè yìí lọ́wọ́lọ́wọ́ dáwọ́ dúró.
Ìwé Ìtọ́kasí
Abímbọ́lá, Wándé (1975), “Ìwàpẹ̀lẹ́: The Concept of Good
Character in Ifá Literary Corpus.” in Yorùbá Oral
Tradition:
Poetry in Music, Dance and Drama, edited
by Wándé Abímbọ́lá, pp. 389-420.
Ile-Ife, Nigeria: Department of African
Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University..
Abọ́dúndé, Abíọ́dún (forthcoming), Àlọ́ Pípa Nílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: New Horn Press Ltd.
Awóníyì, T.A. (1975), “Ọmọlúwàbí: The Fundamental Basis of
Yorùbá Traditional Education”. in Yorùbá
Oral Treadition: Poetry in Music Dance and Drama, edited by Wándé Abímbọ́lá, pp. 358-388. Ile-Ife,
Nigeria: Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo
University.
Babalọlá, Adébóyè (1973), Àkójọpọ̀ Àlọ́ Ìjàpá (2 Vols.). Ìbàdàn: University Press
Ltd.
Dorson, Richard, M. (1972), Folklore and Folklife: An Interoduction. Chicago : The University of Chicago
Press.
Finnegan, Ruth (1967), Oral
Literature in Africa. Clarendon: Oxford
University Press.
[1] This work was published as
Abodunde, Abiodun (1989), ‘Ipò Àlọ́ nínú Akitiyan Ìtanijí Àṣà Àwùjọ’, Seminar Series 2, edited by T.M.
Ilesanmi, L.O. Adewole and B.A. Oyetade, pp. 108-121. Ile-Ife, Nigeria:
Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University.
[2] Nínú
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí àwọn òǹkọ̀wé ti kọ tó sì wà lórí àtẹ ni wọ́n ti mẹ́nu ba
ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àṣà, pàápàá, ìtumọ̀ tí a lè fún ọ̀rọ̀ náà ‘àṣà’.
[3] Bí
kó + àṣà ṣe lè fún wa ní káṣà náà ni kó + àṣà ṣe lè fún wa ní kásà. Ohun
tí a bá kọ lọ́dọ̀ ẹlòmíràn tó bá jẹ mọ́ àṣà, kíkọ́ náà la kọ́ ọ.
No comments:
Post a Comment