Friday, 26 August 2016

ÌPÌN-SÍ-ÌSỌ́RI ÓRIǸ ÌBÍLẸ̀ ÈKÌTÌ


 

 

          Bọ̀dé Agbájé[1]

1.      Ìfáárà

          Àwọn èwì ìṣẹ̀nbáyé pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Èkìtì gẹ́gẹ́ bí àwọn agbègbè ìyókù nílẹ̀ Yorùbá ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìwádìí kò tíì jinlẹ̀ tó ní agbègbè Èkìtì tí a bá fi wé agbègbè Ọ̀yó àti Ẹ̀gbá. Oríṣiríṣi lítírésọ̀ alohùn tó wà nílẹ̀ Èkìtì ni ìsọ̀rọ̀kéwì, ìsàrè àti orin. Díẹ̀ nínú àwọn lítíréṣọ̀ alohùn wọ̀nyìí ló jẹ́ pé ó kárí gbogbo ilẹ̀ Èkìtì ṣùgbọ́n àwọn kan tún wà tó jẹ́ pé agbègbè kan ni wọn ti gbajúmọ̀.

          Àwọn ẹ̀yà ewì alohùn kan náà wà tó jẹ́ pé ilẹ̀ Èkìtì   ni wọ́n rìn mọ. Lára irúfẹ́ àwọn ewì bẹ́ẹ̀ ni alámọ̀, àsamọ̀, urèrè, ìpèsì, jóórójóórójo, olúgbe, òwè àga, àràpólẹ́bẹ̀, òrìṣà-òsì, Ùjàmẹsẹ̀, alákútù, òdùdù/eré ejió, àgbé aláàlúyì àti gbóhùngbóko. Àwọn ẹ̀yà ewì alohùn mìíràn tún wà tó jẹ́ pé kì í ṣe ilẹ̀ Èkìtì nìkan ní wọn pẹ̀kun sí. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ àwọn bẹ́ẹ̀ ni, orin, ẹsẹ-Ifá, Ìjálá, ọfọ̀, olele, ẹ̀sà, oríkì-orílẹ̀, Ṣàngó-pípè, Ọ̀sanyìn pípè,  etíyẹrí/wonwẹ́, àlọ́, ìmọ́, àrọ̀, ègè, asíkò àti òwe.

          Nínú gbogbo ẹ̀yà ewì alohùn tí a sọ pé ó jẹ mọ́ ilẹ̀ Èkìtì nìkan, iṣẹ́ tí Olútóye (1976) ṣe lórí àsamọ̀, (1981) lorí Ùjàmẹsẹ̀ àti Afẹnífọ́rọ̀ (1982) lórí ìsàré ní ìlú Òsi-Èkìtì ni a le rí tọka sí. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó jẹ́ pé Orin nìkan ló jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ yìí, a ó fi ìsàré àti ìsọ̀rọ̀kẹ́wì sílẹ̀ fún àwọn tó bá máa ṣe iṣẹ́ ìwádìí lọ́jọ́ iwájú. Orin kíkọ yìí ló sì jẹ́ Èkìkì lógún jù nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà ewì alohùn yòókù ní ilẹ̀ Yorùbá.

 

2.      Orin Ìbílẹ̀ Èkìtì

          Onírúurú ẹ̀yà ènìyàn ló wà ní ilẹ̀ Yorùbạ́ Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló sì ní ẹ̀yà ewì alohùn tirẹ̀ tó jẹ ẹ́ lógún.  Bí àwọn ẹ̀yà ewì alohùn wọ̀nyí ṣe pò. Yanturu tó, ìyàtọ̀ díẹ̀ díẹ̀ wà láàrin wọn láti ibi kan sí èkejì. Àwọn onímọ̀ kan ti gbìyànjú láti pín lítíréṣọ̀ alohùn wọ̀nyí sí ìsọ̀rí tó bójú mu láti le jẹ́ kí ó rọrùn láti dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ́.

          Beier àti Gbàdàmọ́sí (1959) ni àwọn onímọ̀ àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìpín-sí-ìsọ̀rí lítírésọ̀ alohùn Yorùbá. Ohun tí wọ́n sọ́ nìyí

 

Yorùbá poetry is classified not so much by the contents or the structure but by the group of people to which the reciter belongs and the techniques of recitation which he employs.

 

Babalọ́lá (1966:23) fara mọ́ ìlànà Beier àti Gbàdàmọ́sí. Àfikún tí Babalọ́lá ṣe ni ọfọ̀ tàbí ògèdè tí ó pín mọ́ ara lítíréṣọ̀ Yorùbá. Olúkòjú (1978:60) pín lítíréṣọ̀ Yorùbá sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Ó sọ pé:

                            

The first is the speech mode or recitation mode which comprises oríkì, Ifá, etc. The second category is the chant mode, whose vocalising tone falls between the spoken and the sung forms. The third category deals with the song mode which encapsulates all types of songs. All the three categories have their basis in music.

 

          Ó hàn gbangba pé Olúkòjú (1978) ni ó kọ́kọ́ lo ìlànà tìlùtìfọn láti pín ewì  Yorùbá sí ìsọ̀rí mẹ́ta. A ó rí i pé ọ̀nà ìṣẹ̀ré yìí wúlò púpọ̀ láti pààlà láàrin ìsàré kan sí èkejì. Ó tún ń ṣe àfihàn àbùdá tìlùtìfọn àwọn ewì láàrin ìsọ̀rí orin. Ìlànà ìsèré yìí kan náà kò ṣeé mú lò láti pín àwọn àwọn ẹ̀yà ewì tó jẹ mọ́ ìṣọ̀rọ̀kéwì, nítorí náà ìbá dára láti wá ọ̀nà tó péye mìíràn láti pín àwọn ewì àlohun Yorùbá sí ìsọ̀rí. Àkíyèsí wa ni pé nìlànà ìpín-sí-sọ̀rí tí Olúkòjú (1978) mú lò yìí yàtọ̀ sí tí Beier àti Gbàdàmọ́sí (1959) àti Babalọ́lá (1966).

 

          Ọlátúnjí (1984:7-8) sọ pé:

         

Those poetic forms which are recognized solely by the musical manner in which they are chanted I have called chanting modes… there those which are not recognized by the musical mode of chanting, but by certain characteristic, linguistic and semantic features which set them apart …. I have labeled this class or poetic forms the feature types…

 

          Lóòótọ́, Ọlátúnjí   js class or poetic forms the feature types...uistic and semantic features which set them apart ...ich the reciter belongs and fara mọ́ Beier àti Gbàdàmọ́sí (1959) àti Babalọ́lá (1966) sùbgọ́n ó fi ìka tọ́ ọ pé kì í ṣe gbogbo lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá ni a lè fi òǹṣèré dá mọ̀. Ó tún sọ pé àwọn kan wà tó jẹ mọ ohun tí lítírésọ̀ náà dá lé àti ìhun rẹ̀. A tún ṣàkíyèsí pé ìjọra wà nínú ìsọ̀rí kìíní àti ẹ̀kẹ́ta Ọlátúnjí (1084) àti ìsọ̀rí kejì àti ẹ̀kẹ́ta Olúkòjú (1978). Ìlànà ìpín-sí-ìsọ̀rí Ọlátúnjí (1984) yìí múná dóko ṣùgbọ́n ohun tí a kíyè sí ni pé a tún lè ṣe à-tún-pín-sí-ìsòrí orin.

 

                   Ilésanmí (1985:49-50) sọ pé:

         

I have chosen the functional factor in preference to others because Ìjẹ̀ṣà artists often use it to distinguish their genres. They often talk of genres related to religious ritual (Orin Òrìṣà) and those that are secular.

 

Ó dàbí ìlànà ọ̀tọ̀ ni Ilésáànmí (1985) mú lò láti pín lítíréṣọ̀ alohùn ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà sí ìsọ̀rí. A fara mọ́ ìlànà tó kẹ́yìn yìí nítorí pé ó wúlò púpọ̀ láti pín lítíréṣọ̀ alóhùn Yorùbá sí àwọn ìsọ̀rí tó bójú mu. Yàtọ̀ sí ìwúlò ìlànà yìí, ó sì tún jẹ́ kí ó rọrùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá àti àwọn tó jọra wọn tí a lè tó sábẹ́ ìsọ̀rí kan náà.

          Nínú àwọn onímọ̀ òkè wọ̀nyí, Olúkòjú (1978), Ọlátúnjí (1984) àti Ilésanmí (1985) ló gbà pé orin jẹ́ ìsọ̀rí kan pàtàkì nínú lítíréṣọ̀ Yorùbá. Àwọn onímọ̀ wọ̀nyí fẹnu kò pé. “gbogbo orin ni ewì ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ewì ni orin”. Orin kíkọ máa ń mú ìlù lílù àti ìjó jíjó lọ́wọ́.

          Gbogbo àkíyèsí àwọn onímọ̀ wọ̀nyí nípa àbùdá orin ni ó wúlò fún iṣẹ́ yìí ṣùgbọ́n a tún lé fẹ́ orin lójú ju bí wọn ti lérò lọ. A tún fẹ kí ó yé wa pé orin ìbìlẹ̀ ni kókó nǹkan tí Èkìtì Yorùbá fi kún ìlànà ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ fókìlọọ̀ Yorùbá. Ohun tí àkójọpọ̀ ìsàlẹ̀ yìí dúró fún ní láti jẹ́ kí ó dá wa lójú pé orin  ni ó wọ́pọ̀ jù ní ilẹ̀ Èkìtì.

          Ìlànà ti a mú lò láti ṣẹ àsàyàn àwọn ewì alohùn ìsàlẹ̀ yìí lára èyí tí a mẹ́nu bà lójú ewé kìíní ni pé gbogbo wọn ló tán káàkiri igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ Èkìtì. Àtẹ àwọn ewì alohùn náà nìwọ̀nyí:

 

Àṣàyàn Àwọn Ewì Alohùn Ilẹ̀ Èkìtì

 

Èyà Orin                      Orin Pọ́nńbélé             Wọ́núwọ̀de Orin àti Ìsàré   

Alámọ̀                                                                                     **[2]

Asamọ̀                                                                                    **

Urèrè                                                                                       **

Olele                                                                                       **

Ujàmẹsẹ̀                                                                                  **

Ujùnù-Ògún (Ìjálá)                                                               **

Orin Egungun                        *[3]

Orin Àjàgbó                           *

Orin Ojìja                               *

Orin Ọbuntun                        *

Orin Ogun                              *

Orin Olorì                              *

Orin Òkú                                *

Orin Oluà                               *

Orin Ìṣílé                                *

Orin Ìwọgbẹ́                           *

Orin Obìnrin Ilé                    *

Orin Arẹmọ                            *

Orin Ọgbẹ̀lẹ̀                           *

Orin Ìgbéyàwó                       *

                                                14                                            6

                                                         

Ti a bá wo àkójọpọ̀ àwọn ẹ̀yà ewì alohùn tó wà lókà yìí, a ó rí i pé ìdámẹ́fà nínú ogún 6/20[3/10] tàbí ìdá-ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùún (30%) ló jẹ́ wọnúwọ̀de orin àti ìsàré. Bákan náà, ìdá mẹ́rìnlá nínú ogún 14/20 [7/10] tàbí ìdá-àádọ́rin nínú ọgọ́rùún (70%) ló jẹ́ orin pọ́nbélé. Nítorí náà, pẹ̀lú ẹ̀rí tó wà lókè yìí, a le gbà pé orin kíkọ ló múmú láyà àwọn Yorùbá Èkìtì ju ìsàré lọ.

          Adékọ̀gbà (1983:47-49) sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn orin ìbílẹ̀ Èkìtì ní ìlú Ìkẹ́rẹ́-Èkìtì àti Ìlawẹ̀-Èkìtì nínú iṣẹ́ àpilẹ̀kọ rẹ̀ fún oyè àkọkọ́. Nínú iṣẹ́ yìí, ó sọ fún wa pé ipò tí ọ̀kọrin bá wà ló máa ń ṣe okùnfà irúfẹ́ orin tó máa ti ẹnu rẹ̀ jáde. Iṣẹ́ rẹ̀ yìí ṣe pàtàkì, ó sì wúlò púpọ̀ ṣùgbọ̀n ó wá yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwádìí yìí nítorí pé ìpín-sí-ìsọ̀rí gbogbo àwọn ẹ̀yà orin ìbílẹ̀ Èkìtì gan-an ló jẹ wa lógún.

          Àwọn ìlànà kan wà nílẹ̀ tí a le mú lò láti pín orin ìbílẹ̀ sí ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí. Àwọn ílànà wọ̀nyí ni àkóónú, agbègbè tí orin yẹn jẹ mọ́, ọ̀nà ìṣèrè àti ìwúlò ẹ̀yà orin kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Ẹ̀kìtì. Àwọn ìlànà òkè wọ̀nyí lè sàìbójú mu tó nítorí àwọn ìṣòro tí a lè bá pàdé tí a bá ń mú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lò bíi ọ̀pá òdiwọ̀n láti pín orin ìbílẹ̀ Èkìtì sí ìsọ̀rí.

          Wọnúwọ̀de ni àkóónú orin ìbílẹ̀ Èkìtì. Nítorí náà, tí a bá mú ìlànà yìí lò láti pín àwọn orin Èkìtì sí ìsọ̀rí a kò níí ṣàìbá àwọn ìṣòro kan pàdé tí yóò ṣe ìdènà láti pààlà tó yè kooro láàrin ẹ̀yá orin kan sì èkejì.

          Àwọn orin kan wà tó jẹ́ agbègbè kan pàtó ni a mọ̀ wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ Èkìtì; àwọn orin kan náà sì wà tó jẹ́ pé káríayé ni wọ́n ní ilẹ̀ Èkìtì. A lérò pé tí a bá mú ìlànà àgbègbè tí orin kọ̀ọ̀kan jẹ mọ́ lò láti pín orin ilẹ̀ Èkìtì sí ìsọ̀rí, yóò mú ìrújú wá.

          Kò rọrùn láti dágbá lé ọ̀nà ìṣèré orin kan tó múná doko nítorí ìbásépọ̀ tó wà láàrin àwọn ọ̀nà ìṣèré inú orísìríṣi ẹ̀yà àwọn orin. Síbẹ̀, ìlànà ìpín-sí-ìsọ̀rí kò gbọ́dọ́ mú ìdàrúdápọ̀ lọ́wọ́. Nítorí náà, ìṣòrò yóò wà tí a bá mú ìlànà ọ̀nà ìṣèré lò láti pín orin sí ìsọ̀rí tó bójú mu.

          A gbìyànjú láti pín àwọn orin ìbílẹ̀ Èkìtì sí ìsọ̀rí mẹ́jọ nípa mímú ìlànà ohun tí a ń lo orin fún lò (Functional Mode). Ilésanmí 1985:50) tọ́ka sí àǹfààní tó rọ̀ mọ́ mímú ìlànà yìí lò. Ìlànà yìí ni Ilésanmí (1985) lò láti pin orin ìbílẹ̀ Ìjẹ̀ṣà sí ìsọ̀rí méjì. Ìlànà yìí kan náà ni a gbìyànjú láti mú lò nínú iṣẹ́ àpilẹkọ yìí nítorí ìbáṣepọ̀ tó wà nínú àṣà ìbílẹ̀ Ìjẹ̀ṣà àti Èkìtì. Àwọn ọ̀kọrin ìbílẹ̀ Èkìtì ń lo ìlànà yìí láti fún orin kọ̀ọ̀kan lórúkọ bí ó ṣe hàn nínú àtẹ (diagram) tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí. Wọ́n ń tọ́ka sí àjọṣe tó wà láàrin orin kọ̀ọ̀kan àti ìwúlò wọn láwùjọ́ Èkìtì; eléyìí sì mú àwọn ìrújú díẹ̀ tíì bá wà nínú ìlànà yìí kúrò. Ìlànà yìí bá àṣà Èkìtì mu, ó sì tún fi kún ìmọ̀ iṣẹ́ akadá.

          Ẹ̀wẹ̀, ìlànà yìí lọ́ wúlò jù láti pín àwọn orin ìbílẹ̀ Èkìtì sí ìsọ̀rí nítorí pé ó pààlà láàrin orin kan sí òmíràn lọ́nà tí kò fi lè mú ìrújú wa.

 

          A ó bẹ̀rẹ̀ sí i máa gbé ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan yẹ̀wò báyìí.

(1)     Orin Ètùtù

          Òrìṣà kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Èkìtì ni ó ní ẹ̀yà orin tí a mọ̀ ọ́n mọ́. A ń pé àwọn orin wọ̀nyí ní “Orin Ètùtù” nítorí pé ojúbọ àwọn Òrìṣà wọ̀nyí ní a ti ń kọ wọ́n ní àkókò kan pàtó ní ìgbà ọdún ìbílẹ̀ tàbí nígbà ayẹyẹ ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Àwọn orin wọ̀nyí máa ń fi ìgbàgbọ́ nínú àwọn òrìṣà hàn, ó ń fi ẹ̀mí ìmoorè hàn, ó wà fún ìjúbà, ó tún wà fún ìbọ̀wọ̀ fún àti àpọ́nlé wọn. A máa sábàá ṣe àwọn ètùtù kan kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin wọ̀nyí. Enikẹ́ni tó bá kọrin ètùtù ṣeré yóò rí ìbínú àwọn òrìṣà àti pé ẹni náà yóò sì kan ìdin nínú iyọ̀. Ọ̀kan nínú àwọn orin tí àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ wọ̀nyí máa ń kọ tọ́ka sí èyí. Fún àpẹẹrẹ:

                                      Òdẹ́lẹ́sìnrìn lá pẹyẹ ugbó umọlẹ̀

                                      Oni pẹyẹ ugbó umọlẹ̀

                                      È dẹ̀ yọ́wá Ọ̀rín ra ò

                                      Ọ̀délẹ́sìnrìn lá pẹyẹ ugbó umọlẹ̀.

          Ọ̀nà ẹ̀rọ́ ni a gbà mú orin yìí lò láti túmọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tọ́ lè fa ìbínú àwọn òrìṣà. Enikẹ́ni tó bá sì tẹ èèwọ̀ yìí lójú kò níí ní àǹfààní láti bá wọn wọ igbó àwọn òrìṣà wọ̀nyí mọ́ láéláé ní ilẹ̀ Èkìtì.

          Gbogbo àwọn orin ọdún (orò) ìbílẹ̀ tọ́ jẹ mọ́ àwọn òrìṣà, orin egúngún àti orin ìwọgbẹ́ jẹ́ ara àwọn àpẹẹrẹ orin ètùtù nílẹ̀ Èkìtì.

 

(2)     Orin Ẹ̀fẹ̀

          Orin yìí wà láàrin orin ètùtù àti orin ayẹyẹ nítorí pé àsìkò ayẹyẹ ni orin ẹ̀fẹ̀ sábàá máa ń wáyé. Ààbò tó nípọn máa ń wà fún àwọn ọkọrin ẹ̀fẹ̀ wọ̀nyí nítorí àsìkò kan wà pàtó tí a máa ń kọ orin yìí. Ìdí nìyí tí àwọn Yorùbá fi máa ń sọ pé:

 

                   Máa wí,

                   Máa wí,

                   Ọba kì í p’ọ̀kọrin

                   Kọ̀ǹkọ̀ ń kọ tirẹ̀ lódò.

          Òpin wà fún ààbò tí ọ̀kọrin ní, nítorí pé èèwọ̀ ni pé a kò gbọ́dọ̀ kọrin ẹ̀fẹ̀ sáájú tàbí lẹ́yìn àkókò ọdún ìbílẹ̀ tó bá jẹ́ mọ́. Àkókò tí ọdún ìbílẹ̀ yìí máa ń wáyé le jẹ́ ọjọ́ kan, ọjọ́ mẹ́ta, ọjọ́ márùn-ún tàbí ọjọ́ méje. Ọ̀kọrin ẹ̀fẹ̀ tó bá kọ orin tìrẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn àkókò tí a tọ́ka sí yìí le bá ìbínú ẹni ti ọ̀rọ̀ kàn pàdé tàbí kí gbogbo àwùjọ fi ìyà tó nípọ̀n jẹ irúfẹ́ ọ̀kọrin bẹ́ẹ̀.

          Orin ẹ̀fẹ̀ wúlò fún ìdárayá àti ìkìlọ̀ ìwà. A le tọ́ka sí díẹ̀ nínú àwọn onímọ̀ tó tí ṣàlàyé nípa irúfẹ́ iṣẹ́ ti orin ẹ̀fẹ̀ àwàdà ń ṣe ní àsùwàdà ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, Cupy (1963:19) sọ pé, “Humor is meant to blow up evil and make fun of the follies on life.” Bákan náà, Chesterton (1963:20) gbà pé ohun tí ẹ̀fẹ̀ wà fún ni láti yí ọ̀daràn tàbí ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn lọ́kàn padè sí rere. Ó sọ pé, “.  .  .  the purpose of satire is to make the victim improve his behaviour .  .  .”

 

Yàtọ̀ sí pé orin ẹ̀fẹ̀ máa ń ta ẹni tí ọ̀rọ̀ bá kángun sí lólobó láti tún ìwà rẹ̀ ṣe, Ọbáfẹmi (1984:4) tún kíyè sí i pé ẹ̀fẹ̀ tàbí àwàdà ṣíṣe máa ń tú àsírí gbogbo àwọn ìwà ibi tó bá wà ní orílẹ̀-èdè kan. Ẹ jẹ́ kí a gbọ́ ohun tó sọ:

 

Moses Ọláìyá employs Yèyé in his plays in the manner of the Greek Satire to enable him publicly ridicule all social ills and deviant behaviour in contemporary Nigeria.

         

          Asíwájú (1975:237) náà kò gbẹ́yìn nípa fífi èrò tirẹ̀ hàn nípa irúfẹ́ iṣẹ́ tí orin ẹ̀fẹ̀ máa ń ṣe láwùjọ àsùwàdà ènìyàn nígbà tí ó sọ pé:

         

Ẹ̀fẹ̀ poems are not always reportive … the songs are for the purpose of criticizing or ridiculing certain aspects of life in the community.

         

Ojú ti Vidal 91982:20) fi wo ohun tí a le pè ní orin ẹ̀fẹ̀ tún yàtọ̀ díẹ̀ sí ti àwọn ti mo ti mẹ́nu bà lókè yìí, nítorí pé, ó dàbí ẹni pé ìlànà ìpanilẹ́rìn-ín àti ìdárayá tí àwọn irúfẹ́ àwọn orin wọ̀nyí ń ṣe fún àwọn òǹwòran ló tọ́ka sí. Ò sọ pé:

 

Satiric and derisive songs evoke laughter from spectators and in a way constitute some form of amusement and entertainment.

 

Ó dájú pé iṣẹ́ pàtàkì ni orin ẹ̀fẹ̀ ń ṣe bí ẹ̀ka lítíréṣọ̀ ní ilẹ̀ Èkìtì àti ní gbogbo àgbáyé. Díẹ̀ nínú àwọn orin ẹ̀fẹ̀ nílẹ̀ Èkìtì ni orin Àjàgbó, orin Ùrómọ̀, orin Òkóróbò, orin Ìmórè, orin Agúlẹ́lẹ́, orin Ọlúa, orin Ọdè àti orin Gbóhùngbóko.

 

(3)     Orin Ayẹyẹ

          Orin yìí máa ń wáyé níbi ayẹyẹ pàtàkì nílẹ̀ Èkìtì. A máa ń kọrin yìí láìsí ẹ̀tanú rárá nítorí pé ìdárayá àti ìgbádùn ni orin yìí wà fún. Orin yìí máa ń mú ìlù lílù àti ijó jíjó lọ́wọ́, ó sì tún jẹ́ kí a mọ ọ̀kọrin tó bá pegedé láwùjọ Èkìtì. Àwọn ibi ayẹyẹ tí a ti máa ń kọ àwọn orin wọ̀nyí ní ibi ayẹyẹ ìṣílé, ìsìnkú, ìgbeyàwó, ìsọmọlórúkọ, ìwúyè àti ibi ìpolówó ìbò òṣèlú. Àwọn àpẹẹrẹ orin ayẹyẹ tí a le tọ́ka sí ní orin obìnrin-ilé, orin ìsìnkú, orin òṣẹ̀lú, ọbintun, ọgbẹlẹ, olorì àti àwọn orin eré ìbìlẹ̀ bí eré ajé, ìjẹ̀bú, ìpíìrì, alájẹ̀ǹgbẹ́dẹ̀, kèrègún, àyúù, òsírìgì àti iréṣọ̀.

 

(4)     Orin Ogun

          A le rí àwọn ènìyàn kan tọ́ka sí ní ilẹ̀ Èkìtì lóde òní tó jé pé wọ́n mọ àwọn oríṣìíríṣìí orin ogun tí wọn máa ń kọ nígbà láéláé. Orúkọ ti a ń pè ìsọ̀rí àwọn ènìyàn wọ́nyí yàtọ̀ láti ìlú kan sí èkèjì. Fún àpẹẹrẹ, Ùpàyé  ni á máa ń pé wọ́n ní Òkè-Ìmẹ̀sí-Èkìtì, Elẹ́gbẹ́ ni a mọ̀ wọ́n sí ní Ìlawẹ̀-Èkìtì. Nígbà tí ó jẹ́ pẹ́ akíkanjú jagunjagun ni àwọn Èkìtì tẹ́lẹ̀, wọ́n ni ìlú kan lọ́tọ̀ tí a ń pè ní “Ìlù Ogun”. Ìgbà ogun nìkan ni a máa ń lu ìlù yìí. Ṣùgbọ́n lóde òní nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ti kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá, àkókò ọdún ògún nìkan ní a sábáà máa ń lu ìlù yìí láti fi ṣe ìrántí àwọn akọni àti láti fi ṣe àpọ́nlé ògún gẹ́gẹ́ bí òrìṣà ogun. Orin àti ìlù ogun yìí máa ń mú àwọn jagunjagun ìbílẹ̀ lọ́kàn le, ó sì tún máa ń fún wọn ní ìṣírí láti dojú kọ gbogbo ìṣòro tó bá wáyé lójú ogun. Ọ̀kan-ò-jòkan sì ní àwọn orin wọ̀nyí nítorí pé orin ogun tí a máa ń kọ nígbà tí a bá ń múra ogun lọ́wọ́ yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń kọ lójú ogun; èyí tí a ń kọ nígbà ọwọ́ bá tẹ àwọn ọ̀tá yàtọ̀ gédégédé sí oríṣìí méjèèjì àkọ́kọ́.

          Ogun kan pàtàkì tí àwọn Èkìtì jà ni a ń pé ní “Ogun Èkìtì-parapọ”, èyí tó wáyé láàrin ọdún 1879 sí 1886. Àwọn Èkìtì àti Ìjẹ̀ṣà ló para pọ̀ láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wọn bí i àwọn Ìbàdàn, Ìlọrin tàbí Fúlàní.

 

(5)     Orin Amúséyá

          Ìwúlò orin yìí láwùjo Èkìtì ni láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn pèmí pọ́ siṣẹ́ kárakára. Orin yìí kì í jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìyí ìṣòro tó rọ̀ mọ́ iṣẹ́ ti wọ́n ń ṣe lọ́wọ́, ó sì tún máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ yá kíákíá. Ibi iṣẹ́ ọ̀wẹ̀ àti àáró ni orin yìí ti sábáà máa ń wáyé. Nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń kọrin yìí lẹ́ẹ̀kan náà máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ lọ nílẹ̀ wéréwéré. Èlé àti ègbè wà nínú orin yìí ṣùgbọ́n kò sí aṣáájú kan pàtó fún orin yìí nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ìmísí iṣẹ́ tí a ń ṣe lọ́wọ́ bá tọ̀ lára ló le kọ́kọ́ lé orin kí àwọn ìyókù tó máa gbè é.

 

          Àlàyé Finnegan (1970:239-240) nípa irúfẹ́ orin yìí jẹ́ ẹ̀rí pàtàkì tí a le tọ́ka sí. Ó sọ pé:

 

Work songs stand out from others in their directly functional relationship to the activity they accompany.  .  .  The joint singing co-ordinates the action and lead the workers to feel and work as part of a co-operating group, not as separate individuals. Such co-operation may be essential to the job in hand … The function of rhythmical music in encouraging people to work harder, faster and with more enjoyment has frequently been noted. Work songs can also comment on life in general, on local events or local characters and can express ideas of love, friendship or even obscenity. In short, work songs lighten the labour and give an opportunity, however, limited, for poetic and musical expression in the midst of work.

         

Àṣà iṣẹ́ àdáwọ́jọpọ̀ ṣe yìí sí wọ́pọ̀ láàrin àwọn Èkìtì. Nítorí náà, orin amúṣẹ́yá tó ń rìn papọ̀ pẹ̀lú ọ̀wẹ́ tàbí àáró yìí sì bóde mu. Ìwọ́hùn orin amúṣẹ́yá yìí ló máa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn pẹ̀mí pọ̀ láti siṣẹ́ àṣekára. Ó dájú sáká pé ìlànà ìpẹ́mìpọ̀ siṣẹ́ kò níí kùnà láàrin àwọn Èkìtì tó bá jẹ́ pé orí ìlànà ètò ọ̀wẹ̀ àti àáró ni wọ́n bá ń gbé ètè ìdàgbàsókè àwùjọ wọn kà yàtọ̀ sí ìlànà ètò òwò àjọṣe (commercial partnership) tí a jogún láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Yàtọ̀ sí àkíyèsí Finnegan (1970) yìí, ó dájú pé kì í ṣe ìbí iṣẹ́ àdáwọ́jọpọ̀ ṣe nìkan ni irúfẹ́ orin yìí ti máa ń wáyé nílẹ̀ Èkìtì. Orin amúsẹ́yá máa ń wáyé níbi iṣẹ́ àdánìkan ṣe bákan náà. Orin ìfẹ́ àti orin kẹ́numádilẹ̀¸jẹ́ ara ẹ̀yà orin amúṣẹ́yá nílẹ̀ Èkìtì.

 

(6)     Orin Arẹmọ

          Orin arẹmọ gbajúmọ̀ púpọ̀ nílẹ̀ Èkìtì. Bákan náà sì ni ìwúlò rẹ̀ ṣe pàtàkì jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá. Fún àpẹẹrẹ, Short Oxfprd English Dictionary on Historical Principles (161 T. 247) ki orin arẹmọ báyìí pé: “a song sung to a child to put it to sleep”. Ẹ̀wẹ̀, àwọn onímọ̀ bí i Finnegan (1970:98), Oyésakin (1981:43), Adéyanjú (1983:35) àti Sheba (1988:23-25) ní èrò kan náà nípa nípa arẹmọ. Wọ́n gbà pé, orin arẹmọ jẹ́ èyí ti àwọn ènìyàn máa ń kọ láti tu àwọn ọmọ ọwọ́, láti fi bá wọn ṣeré, láti fi mú inú wọn dùn, láti jẹ́ kí a mọ èrò ọkàn àwọn ọ̀kọrin wọ̀nyìí nípa àwọn ọmọ wọn àti ojú ti wọ́n fi n wo ayé lápápọ. A gba èrò àwọn onímọ̀ òkè yìí wọ̀lé nítorí pé bákan náà ní ìwúlò orin yìí nílẹ̀ Èkìtì. Ẹ̀wẹ̀, àsìkò tí a máa ń kọrin yìí ṣe pàtàkì fún ìtọjú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ àti ìgbé àyé àwọn Èkìtì.

          Orin ìbejì jẹ́ ẹ̀yà orin arẹmọ kan pàtàkì tí a fi ń ṣe àpọ́nlé àwọn ìbejì. Bákan náà ni orin Ọ̀ṣun kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹyìn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yá kan pàtàkì nínú orin arẹmọ. Orin yìí sì jẹ́ mọ́ Ọ̀ṣun tí ó jẹ́ òrìṣà arẹmọ ní ilẹ̀ Èkìtì àti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀, gẹ́gẹ́ bí àlàyé Ilésanmí (1986). Orin ìbeji àti orin Ọ̀ṣun tún wúlò kọjá ká fi bọ́mọ ṣeré lọ.

 

(7)     Orin Òwe

          Àwọn Ẹ̀kìtì máa ń lo orin yìí láti dojú ọ̀rọ̀ kọ àwọn orogún wọn nígbà tí ẹ̀dẹ̀ àìyẹ́dè bá wáyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í dárúkọ ẹni kankan nínú orin yìí, síbẹ̀, àwọn tí ọ̀rọ̀ bá dojú kọ máa ń mọ̀ lọ́gàn. Orin òwe wúlò láti tọ́ka sí àìlera àti àìṣedeédé láwùjọ gẹ́gẹ́ bí àlàyé Rájí (1987:9). Èrò wa ni pé, kò di ìgbà tí ọlọ́rọ̀ méjì bá fojú-ko-ojú kí wọ́n tó kọrin òwe bú ara wọn.

 

          Àwọn obìnrin àti àwọn eléré ni wọ́n sába máa ń kọrin yìí nílè Èkìtì. Àpẹẹrẹ àwọn orin òwe tí a le tọ́ka sí ni orin èébú, orin èpè àti orin ỵẹ̀yẹ́.

 

(8)     Orin Eré Òṣùpá

          Àwọn ọmọdé ló sábàá máa ń kọrin yìí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe eré òṣùpá lójúde wọn lálẹ́. Nígbà tí àwọn ọmọdé bá jẹun alẹ́ tán ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn máa ń tú jáde láti péjọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbé wọn ní àdúgbò, wọ́n a jọ ṣeré papọ̀ kí oníkálùkù wọn tó padà lọ sílé láti sùn. Ní àsìkò eré òṣùpá yìí, àwọn ọmọdé máa ń gbìyànjú láti yẹra fún gbogbo àwọn nǹkan tó le da agbo eré wọn rú.

          Orin eré òṣùpá máa ń mú ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìsọ̀kan gbilẹ̀ láàrin àwọn ọmọdé. Ó tún wà fún ìgbàdùn, ìdárayà àti ìlera àwọn ọmọdẹ́. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọdé wọ̀nyí yóò máa lé orin, àwọn ìyókù yóò sì máa gbè é. Àkọpọ̀ orin yìí máa jẹ́ kí àwọm ọmọdé pẹ̀mí pọ̀ sí eré tí wọn ń ṣe. Orin àlọ́ àpagbè; orin bóólo àti orin alálọ̀ọ́mọ́tan jẹ́ àwọn àpẹẹrẹ pàtàkì lábẹ̀ ìsọ̀rí yìí.

 

Àgbálọgbábọ̀

          Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Orin jẹ́ ẹ̀ka kan pàtàkà nínú lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá gẹ́gẹ́ bí àwọn asáájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Yorùbá ti kọ́ gbé e hàn. Iṣẹ́ yìí tún fi I hàn pé a le ṣe àtúpín orin sí ìsọ̀rí, nítorí náà ni a ṣe mu ìlànà ohun tí a ń lo orin fún (functional mode) lò láti pín orin ìbílẹ̀ Èkìtì sí ìsọ̀rí mẹ́jọ.

 

Ìwé Ìtọkásí

Adébáyọ̀, T. A (1985), “Orin Olori ni Àwọn Àsàyàn Ìlú ní Agbègbè Ẹ̀rọ́ ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó.”, B. A Long Essay, Department of Linguistics and Nigerian Languages, Unversity of Ìlọrin, Ìlọrin.

Adékọ̀gbà, O.M. (1983), “Orin Ìbílẹ̀ Èkìtì.”, B.A. Long Essay, Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ìlọrin, Ìlọrin.

Adéyanjú, G.O. (1983), “Orin Arẹmọ ní Agbègbè Ọ̀yọ́.”, Draft of M.A. Thesis, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Afẹ́nifọ́rọ̀, O. (1982), “Ewì Tí Àwọn Obìnrin ń Ké ní Ìlú Òsi-Èkìtì.”, N.C.E. Long Essay, Department of Yorùbá, College of Education, Ikẹrẹ-Èkìtì.

Aládésurú, A. (1985), “Àyẹ̀wò Orin Olorì ní Ìgèdè-Èkìtì.”, B.A. Long Essay, Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Asíwájú, A.I. (1975), “Gelede Songs As Sources of Western Yoruba History”, in Yoruba Oral Tradition, edited by ‘Wande Abimbola, pp. 199-266 Ife: Department of African Languages and Literatures, Unversity of Ife.

Babalọ́lá, A. (1966), The Content and Form of Yorùbá Ìjálá. London: Oxford University Press.

Barricelli, J. and Gibaldi, J. (1982) (eds.) Interrelations of Literature. New York: The Modern Language Association. of America.

Beier, U. (1956), “Yorùbá Vocal Music”, African Music 1, 3.

Beier, U, and gbadamọsi (1959), Yorùbá Poetry. Ìbàdàn: Government Printers. .

Euba, A. (1975), ‘The Interrelationship of Music and Poetry in Yorùbá Tradition” in Yorùbá Oral Tradition, edited by ‘Wande Abimbọla. pp. 471-487 Ile-Ife Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ilé-Ifẹ̀.

Finnegan, R. (1970), Oral Literarure in Africa. Nairobi: Oxford University Press.

Ilésanmí; T.M. (1985), “Heartstones: A Cultural Study of Songs in Ìjẹ̀ṣàland.”, Doctoral Thesis, Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.

Ilésanmí; T.M. (1986), ‘Ìsàré àti Orin Ọ̀ṣun”, nínú LAANGBÀSÀ Jọ́nà Iṣẹ́ Akáda ti Yunifásítì Èkó 2.

Olúkòjú, E. O. (1978), “The Place of Chants in Yorùbá Traditional Oral Literature.”, Doctoral Thesis, Department of Linguistics and Nigerian Lanugauges, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.

Olútóyè, O. (1976), “An Introduction to Àsamọ̀: A Type of Oral Poetry of Èkìtì Yorùbá”, Paper Presented at 12th West African Languages Congress, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Olútóyè O. (1981), “An Expository Analysis of Ujamẹsẹ̀ Religious Chants of the Èkìtì Yorùbá.”, Doctoral Thesis, University of Lagos, Lagos.

Oyeṣakin, A. (1981), “Categories and Functions of Yorùbá Oral Poetry for Children”, The Nigerian Language Teacher 4, 2:37-46.

Ọbafemi, O. (1984) “Theatre of Farce: The Yèyé Tradition in Moses Ọláìya’s Plays, Issues of Theatre and Social Relevance”, Seminar Paper, Department of Literature in English,. University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Ọlájubù, O. (1987), “The Place of Music in Yorùbá Oral Poetry”, Seminar Paper,. Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Ọlátúnjí, O. (1984), Features of  Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: University Press Limited.

Rájí, S.M 91987), ‘Orin Ọ̀tẹ̀.”, M. A. Thesis, Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ilé-Ifẹ̀.

Scher, S.D. (1982), “Literature and Music”, in Interrelations of Literature, edited by Barricalli, J. and Gibaldi, J., pp. 225-250.

Sheba, J.O. (1988), “Orin Arẹmọ ni Àárin Ifẹ̀ àti Ìjẹ̀ṣà.”, M.A. Thesis Department of African Languages and Literatures, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ile-Ifẹ̀.

Shorter Oxford English Dictionary on Historical Principles, Vol. 1, p. 247.

Vidal, T. (1982), “The Role of Music at Yorùbá Festivals”, Seminar Paper Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.

Wolff, H. (1962), “Rárá: A Yorùbá Chant.” Journal of African Languages, 1, 1: 45-56

 



[1] This paper was published as Agbaje, Bọde (1989), ‘Ìpín-sí-ìsọ̀rí Orin Ìbílẹ̀ Èkìtì’, Seminar Series 2, edited by T.M. Ilesanmi, L.O. Adewole and B.A. Oyetade, pp. 83-107. Ile-Ife, Nigeria: Department of African Languages and Literatures.
[2] Àmìí dúrú fún wọnúwọ̀de orin àti ìsàré.
[3] Àmìyìí dúró fún orin pọ́nńbélé.

No comments:

Post a Comment