O.O.
Oyelaran[1]
“Àsọ̀rọ̀ọ̀yanrọ̀
ló pa Eléǹpe”
Òwe àwọn
àgbà ni o.
Substantives are broadly
distinguished as having a more special signification, and adjectives as having
a more general signification, because the former connote the possession of a
complexity of qualities, and the latter the possession of one single quality.
It is usual to consider the
modification of the meaning of a noun as adjectival and that of a verb as
adverbial… the grammar of Yorùbá should not be related rigidly to that of a
European language. In discussing adverbial relationship, this is most
important. Yorùbá modifies or extends the meaning of a verb in many ways.
(Ida C.
Ward 1952: 51)
I
O ṣòro gbáà fún mi láti ṣe àpèjúwe
ohun tí ọpọ̀ àwọn onímò gírámà ti ń pè ní “adverb” fún èdè Yorùbá. Ìdi kan
pàtàkì tí èyí sì firí bẹ́ẹ̀ ni pé ní ìwọ̀nba bí àkíyèsí mi àti ìwádìí tí mo ti
dáwọ́lé lórí síńtáasì Yorùbá ṣe mọ, n kò tíì lè fi ọwọ́ tọ́ kókó ìlànà kan
tí ènìyàn lè fi ṣe ògún lu orí pé nǹkan tí ó bá rí báyìí báyìí, tàbí tí ó bá
dún bákan ni a lè pè ni ‘adverb’. Iyẹn ni pé àti ìlànà fọnọ́lọ́jì ni o, àti
ti mọfọ́lọ́jì ni o, n ò rí eyí tí a rí tọ́ka sí pé ó ya ìṣọ̀rí ọ̀rọ̀ yìí
sọ́tọ sí òmíràn ní èdè Yorùbá. Bí a bá sì kọjú sí síńtáàsì náà, kò dájú pé a
lè fi ìpò ọ̀rọ̀ nínú gbólóhun yanjú rẹ̀. Bí àpẹrẹ, bí a bá wo gbólóhùn kìíni
kejì yìí
(1) Ò
jẹ iṣu bí ahun
(2) Ò
kọ ebè gákugàku.
Ó dájú pé bí a kò bá bèèrè òun tí
ẹni tí ó bá sọ wọ́n ní lọ́kàn, àríyàn-jiyàn lè wà lórí bóyá iṣu àti ahun ni a fi ń we ara wọn ní o, tàbí ìṣẹnu-jẹun ẹnikan àti tí
alábahun, nínú gbólóhun (1); bẹ́ẹ̀ sì ni bọ́yá èbè ni a ń yán ni o, tàbí ìdáwọ́ ọkọ́ ìgbẹ́-ò-léwú,
atilé-bẹ̀rẹ̀-roko kan tí ẹ̀yìn rè kò bẹ̀rẹ̀ kọbè nínú gbólóhun (2). Ohun tí ó
fa ìsòro irú èyí sì pé méjì, bí ko bá jù bẹ́ẹ̀ lọ: Lákọ̀ọ́kọ́, nínú gbólóhun
bíi (1) àti (2), àti ọ̀rọ̀ tí ó ń yán ọ̀rọ̀-orúkọ o, àti èyí tí ó ń yán
ọ̀rọ̀-ìwà (ọ̀rọ̀-ìṣe)[2],
ìpò kan-ùn ní wọn í wà nínú gbólóhun. Ekejì náà sì fẹ́rẹ̀ dà bí rẹ̀: àti
ọ̀rọ̀-orúkọ àti ọ̀rọ̀-ìṣé, kò sí èyí tí a ò lè fí àpólà “bí ahun”, tàbí ọ̀rọ̀ bí “gáku-gàku”yáǹ.
Ti a bá bá wáá wo ọ̀ràn náà dáadáa,
a ó ṣàkíyèsí kin ní kan, iyẹn ni pé,
àwọn ọ̀rọ̀ bí “ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí
ọ̀rọ̀-ìṣe ní èdè Yorùbá – bóyá bí èdè yòókù náà – ní oríṣìí- ríṣìí ìhà tí à
lè gbà wò wọ́n. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé kò wọ́ pọ̀ kí Yorùbá ó máa sọ̀rọ̀ kí ó
máà gbìyànjú láti sọ ohun ti ó ní lọ́kàn ní àsọyé. Ọ̀nà kan tí Yorùbá sì í
gbàá ṣe èyí ni nípa lílo àpólà gbólóhùn, tàbí ẹyọ ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ pé ọ̀nà kan
náà ní wọn lè gbà yéni, láti kín ara rẹ̀ lẹ́yìn. Nígbà tí ènìyàn bá ṣe báyìí
ní a lè sọ pé o ń yán ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe.
Oríṣìíríṣìí àkíyèsí ni a sì tún lè
ri fà yọ láti ara ohun tí mo ti ń sọ bọ̀ yìí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn ìsọ̀rí
ọ̀rọ̀ kan wà
tí ó jẹ́ pé ní ti ìrírí àwọn elédè, orísìí-ríṣìí nǹkan ní í máa sọ sí
ènìyàn lọ́kàn bí a bá ti mẹ́nu bà wọ́n. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀-orúkọ àti
ọ̀rọ̀-iṣe ní èdè Yorùbà. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni a sì lè fi àwọn ọ̀rọ̀ tàbí
àpólà gbólóhùn tí mo pè ní oníhàkan lẹ́ẹ̀kan yán. Irú ọ̀rọ̀ tí a ba lè lò bàyìí
ní mo da lábàá pé kí a máa pè ní ọ̀rọ̀-èyán tàbí ẹ̀yánrọ̀[3].
Ohun kejì tí ó ṣe pàtàkì tí kò sì yẹ kí a gbàgbé ni pé kò sí ìlànà
fọnọ́lọ́jì tàbí ti mọfọ́lọ́jì kan tí a lè fi ya èyí tí a fi í yán ọ̀rọ̀-orúkọ
sọ́tọ̀ sí ti ọ̀rọ̀-iṣe. Ìdí nìyí tí kò fi wúlò ní èdè Yorùbá láti wonkoko mọ́
ààlà tí àwọn onímọ wa gbogbo ń pa láàrin ẹ̀yánrọ̀-ìṣe (ọ̀rọ̀-àpọ́nlé) àti
èyánrọ̀-orúkọ (ọ̀rọ-àpèjúwe), bí ó ti wà nínú èdè mìíràn bíi Gẹ̀ẹ́sì, ti wọn
ń pè ọ̀kan ní “adverb”, èkejì ní “adjective”. Ẹyánrọ̀ Yorùbá kò ní àdàpé kan
tí a fi lè mọ ti ọ̀rọ̀-orúkò yàtọ̀ sí ti ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bí a ṣe
sẹ̀sẹ̀ là á sílẹ̀ yìí, ǹjẹ́ bá wo ni Yorùbá kì í ṣe í lo ẹ̀yánrọ̀ ìṣọ̀rí kan
fún òmíràn? A ó padà sórí ìbéèrè yìí níwájú. Níbi tí a dé yìí, ó yẹ kí a yẹ
ohùn tí àwọn ara ìwájú ti fi sílẹ̀ lórì ọ̀rọ̀ yìí wò.
II
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìwé gírámà
kan lórí Yorùbá láti ìgbà Alùfáà Ajayi Crowther títí di òní tí ọ̀ràn ẹ̀yánrọ̀
iṣe (ọ̀rọ̀-àpọ́nlé) kò jẹ lógún, síbẹ̀ nǹkan náà kò dà bí ẹni pé ó tí ì
lójútùú. Bẹ́ẹ̀ sì ni àìpẹ́ yìí ni ìyèméjì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lórí pé èdè Yorùbá ní ẹ̀yánrọ̀-iṣe
(ọ̀rọ̀-àpọ́nlé)[4]
tàbí kò ní. Bí ó bá ní, ọ̀nà mélòó ni a lè gbà yán ọ̀rọ̀-iṣe? Yàtọ̀ sí àpólà
ẹ̀yán, tàbí gbólóhùn ẹ̀yán, oríṣìí
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe mélòó ni a rí dìmú nínú èdè náà? Irú àwọn ìbéèrè báwọ̀nyí
tí ẹnikan kì í tí í bèèrè tẹ́lẹ̀ lò ti ṣọ gbogbo wa di òpè nídìí
ẹ̀yánrọ̀-ìse. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn elédè sì ń lo èdè wọn lọ. Ó wá dà bí ẹni pé apá
ìmọ̀-èdè (lìǹguísíìkì) òní ni kò ká èdè Yorùbá, tí àwọn onímọ kọ ọ̀rọ̀ sí
ara iwájú lẹ́nú, ti wọn ò rójú mọ́.
Fún Crowther (1852), Bowen (1858),
de Gaye òun Beecroft (1964), ọ̀ rọ̀ yìí kò nira tó bẹ́ẹ̀. Àwọn kúkú gbà pé
Yorùbá ní ẹ̀yánrọ̀-ìṣe. Ní tiwọn, lóòótọ́, nítorí pé kò sí àmì mọfọ́lọ́jì
tàbí àdàpè kan, ìṣọrí ọ̀rọ̀ yìí ṣóro í ṣàpèjúwe (Crowther, 30), a lè fi ipò
rẹ̀ nínú gbólóhun àti ìtumọ̀ mọ̀ ọ́n. Orísìí ìtumọ̀ bàyìí pín sí bí ọ̀nà
mẹ́jọ̀: àṣìkò, àyè, ọ̀nà a-gbà-ṣe- nǹkan tàbí bí nǹkan ṣe rí, iye tàbí
ìwọ̀n, ìdí àti àyọrísí ọ̀rọ̀, àfiwé, ẹ̀kọ̀ òun àfaramọ́ àti ìbéèrè. Àwọn
tètèdè nínú ìmọ̀ èdè Yorùbá wọ̀nyí tún sọ síwájú sí i pé, ìgbà míràn, bí
Yorùbá kò bá ní ẹ̀yánrọ-ìṣe pọ́nńbélé[5]
fún àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyí, a máa lo ọ̀rọ̀ láti ìsọ̀rí-ọ̀rọ́ mìíràn bí ọ̀rọ̀-ìṣe,
tàbí ọ̀rọ̀-orúkọ. Àpẹẹrẹ:
(3) Ó
ka ìwé dáadàa
(4) Asọ
náà pọ́n rokírokí
(5) Wọ́n
panu pọ̀ ṣọ̀kan
(6) Kò
sí àwìn lónìí
(7) Kò
sí òlòsì níbí
(8) Wọ́n
pín iṣẹ́ náà lọ́gbọọgba
Àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà sí nídìí
yẹn ni wọn máa ń sábà pè ní ẹ̀yánrọ̀-íṣe; wọn a sì tọ́kà sí i pé bí wọn ò
bá tẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe ní síṣẹ̀-n-tẹ̀lé nínú
gbólóhun, a sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀-orúkọ tí ọ̀rọ̀-ìṣe yẹn jẹ mọ́ ni wọn
tẹ̀lé. Dáadáa (3) rokírokí (4) jẹ́
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe pọ́nńbélé. Ṣùgbọ́n ó ṣe í ṣe pé láti ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe ni a ti
í ṣẹ̀dá irú àwọn ẹ̀yánrọ̀-ìṣe alápètúnpè báyìí (Crowther, 49). Ṣòkan (5) jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀-ìṣe tí
awọn yòókù, lónìí (6), níbí (7), àti lọ́gbọ̀ọ́gbà (8) jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀-orúkọ̀ tí á lò bí
èyánrọ̀-ìṣe. Bí a bá sì wáá fi ojú ìtumọ̀ wo àwọn àpẹẹrẹ òkè wọ̀nyí, (6) ń
tọ́ka sí àṣìkò, (7) sí àyè, (8) sí àfisé;[6]
àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àkọ́kọ́, (3), (4), (5), ń fi bí ìṣe ṣe rí hàn.
Awọn
onígírámá mẹ́tẹ̀èṭa yìí ni wọ́n sì fi ọwọ́ sí àkíyèsí Alufáà Vidal pé ní èdè
Yorùbá,
Speaking in general terms, we may say that each individual
adverb of qualification possesses an idiosyncrasy of its own which altogether
incapacitates it from supplying the place of another. It contains within itself
the idea of the word which it is employed to qualify, although, as to form and
derivation, totally unconnected with that word[7].
Bí àpẹẹrẹ ohun tí Yorùbá bá sọ pé
(9) Ò ga roro
kò dájú pé ó lè sọ nípa nǹkan kan náà pé
(10) Ó ga tíantían
Ṣùgbọ́n a ó tún fi
abọ̀ sí orí ọrọ̀ báwọ̀nyí.
Ida C. Ward (1952) àti Ayọ
Bamgboṣe (1966, 1967, 1972b, 1972c) yàtọ̀ sí àwọn tètèdé yìí díẹ̀. Awọn
méjèèjì gbà pé ẹ̀yanrọ̀-ìṣe ni àwọn ọ̀rọ̀ bíi kíákía, kúkúrú, péré, nini, wẹ́lẹ́,
díẹ̀díẹ̀ àti lọ́ọ̀ótọ́, ṣùgbọ́n wọn ka àwọn ọ̀rọ̀
bí tètè, fẹ́rẹ̀, jàjà, kúkú, ṣẹ̀ṣẹ̀
kún ọ̀rọ̀-ìṣe. Ṣé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀
tó kányìn yìí ní àwọn ará ìṣaájú ti tò mọ́ “auxiliary” tàbí ẹ̀yánrọ̀-ìṣe. Àwọn gbólóhùn wọ̀nyí yóò fi
bí Yorùbá ṣé ń lo àwọn ọ̀rọ̀ náà hàn:
(11) Alákìíṣà tí ń jó lóru gbàgbé
pé ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́.
(12) Bíbọ́ tí ọmọ yẹn jàjà bọ́ lọ́wọ́ baba rẹ̀ tí ó ń lù ú,
kò yọjú sílé fún bí ọjọ́ mẹ́ta.
(13) Ẹni a ti ń dúró dè láti
ìjíǹjí orí ẹní wáá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ní
òòrùn-kàntàrí.
Ìdí tí Ida Ward (1952) fi pè àwọn
irú àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ ní dúdú ni ọ̀rọ̀-ìṣe kò ju pé àwọn ọ̀rọ̀ bí ti,
yóò lè saájú wọn lọ nítorí pé, lójú rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó bá ti lè
tẹ̀lé ti, yóò (tàbí àwọn àdàpè rẹ), àti ń (òun àdàpè
rẹ̀, máa) níláti jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe. Ìdí ti Bámgbósé fi ka àwọn ọ̀rọ̀ bí tètè
kún ọ̀rọ̀-ìṣe jọjú gan-an ni. Bí n kò bá ṣi àlàye rẹ̀ kà, kókó ohun tí ó rí
tí ó fi pè wọ́n ní ọrọ-ìṣe ni pé ilò wọn nínú gbólóhùn kò sé kò ya tí àwọn
ọ̀rọ̀ bí yára, rọra, lò, jù, jọ, pàápàá
nígbà tí a lo àwọn tibí pẹ̀lú ọ̀rò-ìṣe mìíràn nínú gbólóhùn kan náà.
(14) Ọ̀gá
ń rọra tẹlẹ̀ bí ẹni pé ilẹ̀ yóò lu tó bá tè ̣ẹ́ gìrì.
Lójú Bamgboṣe, bó bá yẹ̀ ní pé
Yorùbá kì í ṣábà dá ọ̀rọ̀ bí ṣẹ̀ṣẹ̀
lò nínú gbólóhùn, wọn kò yàtọ̀ sí lo,
rọra, abbl. nígbà tí a kò bá
dá wọn lò, Ìgbà tí a kò bá dá wọn lò ni Bamgboṣe ní àwọn ọ̀rọ̀ bíi lọ, rọra máa ń yán ọ̀rọ̀-ìṣe mìíràn tí ó bá wà nínú gbólóhun kan náà.
Idi nìyí tí ó kúkú fi pè wọ́n ni ọ̀rọ̀-ìṣe èyán (modifying verbs); tí
ọ̀rọ̀-ìṣe èyán wáá jẹ́ oríṣìí méjì: àwọn tí a tún lè dá lò.
(15) Aago
mi yára: ọ̀ṣán kò tí ì pọ́n tí ó fi lu mẹ́rin-ààbọ̀;
àti àwọn tí a kò lè dá lò:
(16) *[8]
Aago mi ṣẹ̀ṣẹ̀.
Ìdí tí mo fi ranrí pé dandan kí ń
sọ díẹ̀ nípa àlàyé Bámgbóṣé ni pé ibi tí òun àti Ida Ward (1952) fá sí kọ́ ni
onígiràmà bí Awóbùlúyì (1972, 1973, 1974) fá sí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀yánrọ̀-ìṣe ní èdè
Yorùbá. Ní tí Awobúluyi, ìsọ̀rí-gírámà bí ọ̀rọ̀-ìṣe ẹ̀yán kò ní ìtumọ̀. Ara
àlàyé rẹ̀ ni pé kòṣeku-kòṣẹyẹ ìsọ̀rí bí ọ̀rọ̀-ìṣe ẹ̀yán kò wọ̀ nínú gírámà
tí ó yẹ kí àlàyé tí ó yé kooro wà lórí bí àwọn elédè ṣe ń lò ó, tí kò sì yẹ
kí ó fa tàbí-ṣùgbọ́n lọ́wọ́ bì ìsọ̀rí titun yìí. Awóbùlúyì tún wáá gbìyànjú
nínú àwọn ìṣẹ rẹ̀, pàápàá jù lọ méji tó gbẹ̀yìn (1973, 1974), láti fi í hàn
pé àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe bí lọ, yára, ti Bámgbósée ní wọn ń yán
ọ̀rọ̀-ìṣe tí a bá lò wọ́n mọ́ kò yàtọ̀ sí àkànpọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe méjì tàbí jù
bẹ́ẹ̀ lọ tí gbogbo ayé gbà ní àkànpọ̀ àsinpọ̀-ìṣe (tí a ń pè ní ọ̀rọ̀-ìṣe ẹlẹ́sìín-ìlẹ̀kẹ̀
tẹ́lẹ̀). Nínú gbólóhùn bẹ́ẹ̀, bí (17)
(17) Òrùngbẹ
ń gbẹ mí; mo dé ilé; mo bu omi mu
iye ọ̀rọ̀-ìṣe tí a bá kàn pọ̀ ni
iye gbólóhùn tí ó yé ẹni tí a bá ń bá sọ̀rọ̀: làti (17),
(18) Mo
bu omi; mo mu omi.
ni ó yé ẹni tí bá ń bá sọ̀rọ̀. Lójú
Awóbùlúyì, bẹ́ẹ̀ náà ni gbólóhùn méjì méjì (21), (22), yé ẹni ti ó bá gba (19)
àti (20).
(19) Ni aago mẹ́wàá tí o wí yẹn mo
ti ń jẹun lọ.
(20) Mo yára ṣíwọ́ bí o ti wọlé
(21) …mo ti ń jẹun, (onjẹ́) jíjẹ́
(náà) ń lọ lọ́wọ́.
(22) Mo yara láti ṣíwọ́…
Ọ̀rọ̀ náà dà bí ẹni pé bí a bá gbà
pé kò sí inú gbólóhùn tí Yorùbá kìí ti í fi ọ̀rọ̀-ìṣe yán ara wọn, a jẹ́ pé
kò sí ọ̀rọ̀-ìṣe tí a lè fi tètè, ṣẹ̀ṣẹ̀ wé ju pé kí a
fi orúkọ ìlò wọn kan náà tí a mọ̀ wọ́n mọ̀ pè wọn lọ: èyí nnì ni
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe. Idí nìyí tí Awobuluyi fi fi àáké kọ́rí pe ẹ̀yánrọ̀-ìṣe ni àwọn
ọ̀rọ̀ bíi tètè, ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú gbólóhùn bí (11), (12), (13).
Ṣùgbọ́n
Awobuluyi kò dúró níbẹ̀un. Ó jọhun pé lójú rẹ̀ náà kò bójú mu kí a pé orìṣìí
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe méjì ni ó wà nínú èdè Yorùbá, papàá ju lọ, nígbà tí ó jẹ́ pé
ọ̀kan yòókù kúkú fi ìlò jọ ìṣorí-ọ̀rọ̀ mìíràn lórísìíríṣìí ọ̀nà tí kò ṣeé
fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn gbólóhùn wọ̀nyí wò:
(23)
Mo tà gìrì
(24) Ọ̀yà yẹn kò rú fín-ín nìgbà ti mo
kàn án ní àáké.
(2) Ó kọ ebè gákugàku.
(3) Ó ka ìwé dáadáa
(4) Aṣọ naà pọ́n rokírokí
Àlàyé mẹ́rin pàtàkì ni Awóbùlúyì là
lélẹ̀ tí ó fi í hàn lójú tirẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà sí nídìí lókè wọ̀nyí:
gìrì, fíín, gákugàku,
dáadáa àti rokírokí, pé wọn kì í
ṣe ẹ̀yánrọ̀-ìṣe kankan; àti pé ọ̀rọ̀-orúkọ paraku ni wọ́n. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó
ní ó jọhun pé àsán pé ọ̀rọ̀ tí àwọn onígírámà èdè Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní “adverb” ni
a máa ń ṣábà lò nínú gbólóhùn tí a lè túmọ̀ irú gbólóhùn òkè wọ̀nyí sí ní
Gẹ̀ẹ́sì ló jẹ́ kí àwọn onímọ̀ èdè Yorùbá fi maá pe ọ̀rọ̀ bí dáadáa àti kíákía ní “adverb”. Ṣùgbọ́n bí a bá yẹ ọ̀rọ̀ náà wò dáadáa, ọ̀pọ̀
ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí ni a kò lè rí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ wọn, a fi bi ènìyán ó bá dà á
sì gbólóhùn wòòròwẹ̣ẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, “adverb” Gẹ̀ẹ́sì wo ni ó túmọ̀ fín-ín, wòòrò wẹẹrẹ, gìrì, gákugàku, àti rokiroki
náà pàápàá? Awobuluyi ní ohun tí ó fa èyí ni pé àgbọ́mọ̀tumọ̀ (àgbọ́mọ-ìtumọ̀)
ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
…it will be found that such words have no meanings in
themselves, but instead, convey meanings by their sounds. In other words, they
are onomatopoeic in character, and this is why only a few of them can be
directly glossed in English, and only for convenience at that (1974: 3)
Awóbùlúyì wáá pe àkíyèsí sí i pé
ọ̀rọ̀-orúkọ wà kítikìti ní èdè Yorùbá tí wọ́n jẹ́ àgbọ́mọ̀tumọ̀ bíi àwọn
ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Nínú gbólóhùn wọ̀nyí:
(25) Ewo ni kẹ̀tẹ̀kẹ̀tẹ̀ lẹ́sẹ̀
kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ [14]
(26) Jàgídíjàgan rẹ ti pọ̀ jù [15]
(27) Ayé ń lo ńí mẹ̀lọmẹ̀lọ [16][9]
ọ̀rọ̀-orúkọ ni kẹ̀tẹ̀kẹ̀tẹ̀, jàgídijàgan,
àti mẹ̀lọmẹ̀lọ. Kò sì tọ́ kí a wáá
to ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ pa pọ̀ báyìí sí abẹ́ ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ní
ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, nínú gbólóhùn Yorùbá, ọ̀rọ̀-orúkọ nìkan ni ó máa ń ṣábà tẹ̀lé
ọ̀rọ̀ bí ní bí a ṣe lò ó nínú àwọn
àpẹrẹ bi (27), ní mẹ́lọmẹ́lọ,
àti (28) àti (6).
(28)
Ṣe ara rẹ ní òjòwò bí o kè bá fẹ́ẹ́ tẹ́.
(6) Kò sí àwìn lónìí.
Níwọ̀n ìgbá tí a sì ti lè lo àwọn tí àwọn ènìyàn ń pé ní
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe lẹ́yìn ní báyìí,
(29)
Adé jáde ní kíákíá
(30) Ní kété ti àwọn olè jáde ni
ariwo sọ
A jẹ́ péọ̀rọ̀-orúkọ ni kíákíá,
àti kété
náà. Gbogbo ìgbà tí a bá sì lò wọ́n láìsí ni
níwájú, ní yẹn yé ẹni à ń báá
sọ̀rọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé kẹta, Awóbùlúyì tún fi ìka tọ́ ọ
pé ọ̀rọ̀-orúko nìkan ni a máa ń fi gbólóhùn ẹ̀yán “tí-” (31) àti gbólóhùn
àkíyèsí (32) í yán.
(31) Oko
tí ó lọ jìnà
(32) Oko
ni ó lọ ni kò jẹ́ kí a rí ì.
Bẹ́ẹ̀ náà sì ni a kì í fi ẹ̀yánrọ̀
tí a ṣẹ̀dá láti ara arópọ̀-orúkọ yán nǹkan mìíràn ju ọ̀rọ̀-orùkọ lọ (33)
(33)
Oko rẹ ọ̀la, àkànpọ̀
Gbògbò ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí náà ni a
lè gbà yán àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń yẹ̀ wò wọ̀nyí. Ẹ wo àwọn gbólóhùn bí:
(34) Wàá tí ó da obì náà sílẹ̀ báyìí,[10]
peregede
ni ó yàn. (Fálétí; 161)
(35) Jùàjùà
rẹ̀ kò jẹ́ ó ríran rí ọmọ
tí
ó sùn sílẹ̀.
(36) Gákugàku
kan báyìí ni o rí …(Fálétí; 137)
Àwọn àpẹẹrẹ báyìí tún fi í hàn
pé ọ̀rọ̀-orúkọ ni wàá, peregede, jùàjùà,
gákugáku àti àwọn bí wọn.
Àlàyé Awóbùlúyì kẹrin ni pé
ọ̀rọ̀-orúkọ nìkan ni a lè lò bí orísun
ọ̀rọ̀-ìṣe nínú gbólóhùn, òun náà sì ni ọ̀rọ̀-ìṣe lè dá lé lórí. Nínú gbólóhùn
bí (35), jùàjùà ni orisun, bẹ́ẹ́ ni òun náà ni ọ̀rọ̀ kàn
nínú gbólóhùn (37).
(37) Bi o kò bà fẹ́ẹ́ kan
àbùkù pa jùàjuà rẹ̀ tì
Nítorí gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí,
Awóbùlúyì kò rí ìdí kan ti àwọn ọ̀rọ̀ bí jùàjùà,
kíákíá, rokírokí, fín-ín, fi le jẹ́ nǹkan mìíràn ju ọ̀rọ̀-orúkọ̀ lọ. Ó ní
bí ẹ bá fi wọ́n wé àwọn ọ̀rọ̀ bí tètè àti sẹ̀sẹ̀ tí a kò lè lò bí
ọ̀rọ̀-orúkọ̀, ẹ̀tọ́ ni kí a pe àwọn tibí ni ẹ̀yánrọ̀-ìṣe, pàápàá ju lọ nígbà
tì wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀-ìṣe bí a ti ṣe àlàyé rẹ̀ ṣaájú, tí èdè kan kì í sì í
wà kó má ní ẹ̀yánrọ̀-ìṣe (1974 :11).
Kí èmi náà tóó sọ gbólóhùn méjì
tàbí mẹ́ta lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fa àríyànjiyàn wọ̀nyí, mo tún fẹ́ẹ́ mẹ́nu bà á
ní ṣókí òhun tí E. C. Rowlands (1969), 1970) rí wí ní tirẹ̀. Emi pàápàá ì bá
tí ṣòpò sọ ti Rowlands, ṣùgbọ́n ó dá mi lójú pé ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò tí ì ka
ìwé rẹ̀ Teach Yourself Yorùbá (1969) ni yíò kà á. Ṣùgbọ́n
ọ̀pọ̀ lè máa ní àǹfààní láti ka ti 1970 nínú African Language Studies
XI. Bẹ́ẹ̀ sì ni iṣẹ́ Alufáà yìí, lórí Yorùbá, kò seé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.
Bíi díẹ̀ nínú àwọn tètèdé nínú
gírámà Yorùbá àti Ayọ Bamgboṣe, Rowlands (1969149-150) gbà pé orísìí
ọ̀rọ̀-ìsẹ kan ni àwọn ọ̀rọ̀ bí sì,
kọ́kọ́, tètè, sáà, fẹ́rẹ̀ẹ́ (sic), dédé,
kààn, abbl.; àfi pé “auxiliary” ni ó pè wọ́n, tí ó sì kó wọn pọ̀ mọ́ yíò, ti, ń, máa tí Bámgbóṣé (1972) àti
àwọn ará ìṣáajú náà pè ní “auxiliary” Nítorí náà a lè sọ pé Rowlands kò gbà
pé ẹ̀yánrọ̀-ìṣe ni ọ̀rọ̀ bí sì, kọ́kọ́ àti tètè. Òun àti àwọn yòóku fi èyí yàtọ
sí Awobuluyi.
Ní ti ọ̀rọ̀ bí pẹ̀lẹ́pẹ́lẹ́, dáadáa, fín-ín, rokírokí, ní 1969, Rowlands gbà pé
ẹ̀yánrò-ìṣe ni wọ́n. O ní:
…Yorùbá has no special class of words, like English words
ending in ‘–ly’, which we can obviously label ‘adverbs’. What we are dealing
with in this chapter are words and expressions which can be used to define or qualify verbs or adjectives. Such words and expressions, … follow, the verb
or adjective except, of course,
when they are emphatic, in which case they are placed at the head of the
sentence with a following ni.
(1969: 145) There is a very large number of phonoaesthetic
words which are used to emphasise or define more closely the meanings of verbs
and adjectives… Many of the words
which function thus as adverbs also function as adjectives. (146). Àpẹẹrẹ:
(38) (a) Ó han gooro
(b)
Ohùn gooro
(39) (a) Ó kọ ọ́ wúruwùru
(b) yàrá wúruwúru
Ṣùgbọ́n nínú iṣé rẹ̀ 1970 àkíyèsí
rẹ̀ nípa wọn kò sé kò ya ti Awobuluyi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yẹ̀ wò tán yìí. Awóbùlúyì,
Rowlands náà ní àgbọ́mọ̀tumọ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ bí gooro, wúruwúru, kíákíá,
àti pé, nítorí irú àlàyé ti Awobuluyi náà ṣe nípa bí ilò àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe
jọ ọ̀rọ̀-orúkọ, kò sí ohun mìíràn tí a lè pè wọ́n jú ọ̀rọ̀-orúkọ tí a lè lò
nípò ẹ̀yán. Ó ní nítorí náà:
…all ideophones and some rather small number of
non-ideophonic ‘adverbs’ can be regarded as a sub-class of nominals which can
occur in the adjunct position, while the remainder can be regarded as verbs,
with the exception of a few whose status is doubtful (1970: 289)[11]
Nígbà tí Rowland kò sì kúkú ka ọ̀rọ̀
bíi ṣẹ̀ṣẹ̀,
kúkú, kààn kún ẹ̀yánrọ̀-ìṣe tẹ́lẹ́, ibi tí ó fi orí gbogbo rẹ̀ tì sí
ni pé:
The absence of a completely satisfactory solution in the
above case in Yorùbá does not seriously weaken the general argument that the
category of ‘adverb’ in this language may well be eliminated.
Iyẹn ni pé, lójú Rowlands, kò wúlò
kí a pé Yorùbá ní ìsọ̀rí-ọ̀rọ̀ tí a lè pè ní ẹ̀yánrọ̀-ìṣe pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀.
III
Ní tèmi alára wàyí o, mo gbà pé
àwọn ọ̀rọ̀ bíi kúkú, ṣẹ̀ṣẹ̀, kààn,
kì í ṣe ọ̀rọ̀-ìṣe. Ṣùgbọ́n, fún ìdí tí n ó mẹ́nu bà láìpẹ́ yìí, kò dá mi
lójú pé a lè kà wọ́n kún ẹ̀yánrò-ìṣe lọ́nà tí Awóbùlúyù gbé kalẹ̀. Ní ìdà keji
ẹ̀wẹ̀, bí a bá wo èdè Yorùbá dáadáa, ó dà bí ẹni pé nǹkan kan wà tí ọ̀wọ́
àwọn ọ̀rọ̀ bíí fín-ín, rokírokí, kíákíá
ní, tí àwọn ìsọrí-ọ̀rọ̀ mìíràn kò ní. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kò ní í dà bí ẹni pé
ènìyàn jẹ ayò pa tí a bá kó wọn sí ìsọ̀rí-gírámà kan lọ́tọ̀, orúkọ yóówù kí a pe ìsọ̀rí
bẹ́ẹ̀.
Ní orí àwọn èkejì yìí ní n ó ti
bẹ̀rẹ̀. Ohun tí mo sì fẹ́ẹ́ kọ́ ṣe ni kí n yẹ àwọn àlàyé Awóbùlúyì
mẹ́rẹ̀ẹ̀rìn wò, àwọn tí ó fi ṣe èèkàn fi àbá rẹ̀ rọ̀ sí pé ọ̀rọ̀-orúkọ̀ ni rókírokí òun kíákíá. Kí a kọ́ mú
ti ìtumọ̀ tí ó ní ó pa wọ́n pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ. Ẹ rántí pé kì í ṣe gbogbo
ọ̀rọ̀-orúkọ ni ìtumọ̀ pa wọn pọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ tí àwọn náà jẹ́ agbọ́mọ́tumọ̀ (onomatopoeic), ti
wọn “convey meaning by their sounds”. Ibéèrè mi wáá ni pé:
Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń
yẹ̀ wò wọ̀nyí jẹ́ àgbọ́mọ̀tumọ̀?
Ẹ ṣàkíyèsí pé kí a tóó le pe ọ̀rọ̀
kan ni àgbọ́mọ́tumọ̀, ó yẹ kí ó jẹ́ pé ohun tí ó ń tọka sí níláti jẹ́ ariwo
tàbí ohun tí ó ń pariwo tí ó jọ ọ̀rọ̀ náà ní gbígbọ́ sétí. Bi ó bá rí bẹ́ẹ̀,
ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn gbólóhùn wọ̀nyí wò. (Eyí tí a bá kọ iye ojú iwé sí, lati
isẹ́ Falétí, (1969) ló ti wá.)
(40) A
pàdà sẹ́hìn (144)
(41) Àṣé
ọkùnrin kan gúọ́gúó
báyìí ni (137)
(42) Àgbàdo
títa tí wọ́n bá lọ̀ lábúlúbú ni à ń pè ní àádùn lóko wa.
(43) Òórùn
òkú ajá náà ń já kánmú ni fún bí ọjọ́ mẹ́wàá.
(44) Bí
o ba jẹ àgbáyun, gbogbo ohun tútù tí ó bá fi sẹ́nu lẹ́yìn rẹ̀
ní
yóò máa dùn yùngbà
(45) Bí
ó ti rẹ̀ mi tó, ṣe ni mo lulẹ̀ lulọ̀ wọ̀bò bí saka èkùrọ́.
(46) Àpótí
náà wúwo rinrin.
Nínú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà
sí nídìí wọ̀nyí, lójú tèmi, bó bá yẹ̀ ní wọ̀bọ̀
(45), èmi kò rí èyí tí a tún lè pè ni àgbọ́mọ̀tumọ̀ mọ̀, lọ́nà tí a gbà ṣe
àpèjúwe àgbọ́mọ̀tumọ̀ ṣaájú yẹn. Arún ojú ni guọ́gúọ́ (41); lúbúlúbú
(42) gba ìfọwọ́kàn, kánmú (43),
òórùn; yùngbà (44), ìtọ́wò; tí bìrí (39) sì ń tọ́ka sí bí nǹkan
ṣe ṣẹlẹ̀. Rinrin (45) ní tirẹ̀ jẹ́
mọ́ ìwọ̀n. Ọ̀nà wo wáá ni a lè gbà pe gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní
àgbọ́mọ̀tumọ̀? Bí a bá sọ pé irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí máa ń tọ́ka sí orìṣìí ọ̀nà
tí ènìyàn ń gbà mọ nǹkan, n kò níí jiyàn. Ṣùgbọ́n pé àgbọ́mọ̀tumọ̀ ni gbogbo
wọn, kò tọ̀nà. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò wúlò kí a sọ pé nítorí pe bí irú àwọn ọ̀rọ̀
wọ̀nyí bá ti wọ ‘ni léti ni ọ̀nà mímọ̀
kan pàtó í ti
í sọ sí’ni lọ́kan. Idí ni pé kò ní ọ̀nà mìíràn tí ọ̀rọ̀ yòówú kí ó jẹ́ fi í
yéni.
Bi a bá tilẹ̀ tún wo ọ̀rọ̀ bí wọ̀bọ̀ (45), gooro (38), ó dájú pé ààrin àwa tí a gbọ́ Yorùbá nìkan ni wọn ti
lè jẹ́ àgbọ́mọ̀tumọ̀. Iyẹn ní pé bí ènìyàn kò bá gbọ́ Yorùbá, kò lè mọ̀ pé
ẹyọ ìyẹ́ kan
kò lè bọ́ lulẹ̀ wọ̀bọ̀, àfi túẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ kí a sẹ̀ṣẹ̀ tún máa júwe àgbọ̀mọ̀tumọ̀
gidi han ẹ̀ni yòówù tí ó bá lutí. Bí àpẹẹrẹ [gbà] tí ìlẹ̀kùn Yorùbá í ró jọ
[bang] ti Gẹ̀ẹ́sì, bẹ́ẹ̀ ni [baawao] tí Gẹ̀ẹ́sì kò jìnà si [wááwòó] tí ajá í
dún.
Lẹ́nu kan, pàtàkì pípè tí Awobuluyi
pe àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni àgbọ́mọ̀tumọ̀ kò yé mi tó. Ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn gbólóhùn
wọ̀nyí wò.
(47) (a)
Mọ̀nọ̀mọ́nọ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní
a
fi ṣe àtùpà délé lóru ojọ́ náà.
(b) Alùfáà náà ní pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ ni
nàsíà òun,
kí
ẹni tí ó bá ta bá fi orí ji òun.
(c) kòlòkòlò jẹ wá ládìẹ́ tán lóko
ẹgàn.
(d) kò mọ ẹ̀wà lóńjẹ ajẹ̀sùn, ó ní òun ò
jẹ
jàgbáńjọ̀gbọ́.
(48) (a)
Nígbà tí wọn fa orí gbogbo wa
bẹ́ẹ̀
tán porongodo, wọ́n wáá bẹ̀rẹ̀
sí
í dè wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. (158)
(b) Ara mi ń bù máṣo kẹ̀ù (141)
(c) Gbogbo ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi dúdú yunyun
(142)
(d) Mo ń làágùn yọ̀bọ̀ (142)
(e) Gbogbo wa dákẹ́ lọ gbári (168)
(49) (a)
Àwọn ọmọwọ́ rẹ̀ bí mélòó kan
sì
rọ̀ọ̀rì
sí inú náà. (143)
(b) Okùn gbọọrọ́ ni wọn wa; wọn kọ́kọ́
pojóbó
rẹ̀, wọn fi í bọ̀ mi lọ́rùn (159)
(c) Ọba titun náà gbọ̀rọ̀gẹ̀jìgẹ̀
(d) Ó tin lápá, tin lẹ́sẹ̀ bí tiíntìín
(e) Ọwọ́ rẹ̀ tíínrín bí fọ́nrán òwú.
(50) (a) Wọ́n fi okùn gìdigbàgìdìgbà
dè
mí lọ́wọ́. (136).
(b) Lákòókò yíí kan náà ni àwọn
Baálẹ̀
ìlú kéréje-kéréje ti kò
jìnà
sì Òkò ń wọ ààfin wá
láti
kí Olúmókò (137).
(c) Ewé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan ni ó fí kó.
iyán
kóńkó tí ó pín mí.
(d)
Ọna tíínrín kan báyìí ní ó
kù
wá kù.
Ẹ ó ri pé àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà
sí nídìí wọ̀ǹyí pín sí olóríjorí: Ọ̀rọ̀-orúkọ (47), ọ̀rọ̀-ìṣe (49),
èyánrúkọ (50). Lójú tèmi, bí àwọn ọ̀rọ̀ (47) bá jẹ́ àgbọ́mọ̀tumọ̀, a jẹ́ pé
àgbọ́mọ̀tumọ̀ ni ti (49) àti (50) náà. Awóbùlúyì sì ní ìtorí pé (47) àti (48)
jọ jẹ́ àgbọ́mọ̀tumọ̀ ni wọ́n fi fi ìtumọ̀ jọ ara wọn. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a
jẹ́ pé ọ̀rọ̀-orúkọ̀ nìkan kọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ bí roboto, yọ̀bọ̀, kíákíá fi ìtumọ̀ jọ. Nítorí náà, bí a bá máa torí ìtumọ̀ pé wọ́n ní ọ̀rọ̀-orúkọ,
kò sí ìdí tí a kò lè fi ìtorí ìtumọ̀ pè wọ́n ní ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí ẹ̀yánrúkọ.
Awóbùlúyì àti Rowlands (1970) tún fi
oríṣìíríṣìí àpẹẹrẹ ṣe àlàyé pá ọ̀nà pọ̀ tí ìlò kíákíá fi jọ ti àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ. Iyẹn sì jẹ́ pàtàkì ìdí tí
wọ́ń fi tò ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́ ìṣọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ. Wọ́n ní::
Whether to classify a particular word as a Noun or a Verb or
a Qualifier or a Modifier, etc. in Yorùbá depends not on the shape or length or
meaning of the word, but rather on its function with grammatical sentences in
the language (Awobuluyi 1974:9).
Nínú gbólóhùn (51)
(51)
Ọmọ oówù jẹ kù tíínrín
tíínrín fi ìlò jo
àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń yẹ̀ wò ní (48). Ṣùgbọ́n a rí pé ọ̀rọ̀-ìṣe ni tínínrín ní (49); á sì lò ó bí
ẹ̀yánrúkọ ní (50). Iyẹn ni pé ní ti ìlò o, kò yẹ kí ó ya ni lẹ́nu bí a bá rí
irú ọ̀rọ̀ (48) tí ó ń siṣẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe. Rowlands (1970) sáà ti fi hàn wá pé
ìrú ọ̀rọ̀ (48) tí ó seé lò bí ẹ̀yánrúkọ pọ̀ yanturu, papàá jù lọ àwọn tí
wọ́n lè tẹ̀lẹ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe rí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó ha yẹ kí a ti ìtorí àpẹẹrẹ
bí tíínrin (51), àti ti àpẹẹrẹ
Rowlands sọ pé ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí ẹ̀yánrúkọ ní kíákíá, rokírókí bí?
Ìdí mìíràn tí èmi kò lè tún fi fi
gbogbo ẹnu sọ pé ọ̀rọ̀-orúkọ ní kíákíá,
roro, abbl. ni pé kì í ṣe
gbogbo ìrú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a lè lò ní gbogbo ọ̀nà tí Awobuluyi fi fi wọ́n wé
ọ̀rọ̀-orúkọ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, lóòótọ
a lè fi gbólóhùn “tí ____”, àti gbólóhùn àkíyèsí (“___ ni”) yán àwọn ọ̀rọ̀
(48), kò sí èyí tí a lè fi ọ̀rọ̀ bíi rẹ̀
yán nínú wọn. Bí a kò bá sì fi gbólóhùn “tí ____” yán wọn, wọn kò ṣeé lò bì
oríṣun tàbí bí ohun tí ọ̀rọ̀-ìṣe kàn. Àpẹẹrẹ wọ̀nyí, (52, 53), yóò fi ohun
tí mo ń báá bọ̀ hàn:
(52) (a) gbári
tí ó dákẹ́ ń kọ mí lóminu.
(b) * Gbárí ń kọ ni lóminu
(c) * Gbárí rẹ̀ kò yé mi.
(53) (a) Mo
kíyèsí yunyun tí ó dúdú.
(b) * Mo kíyèsí yunyun rẹ̀.
(c) *Mo kíyèsí yunyun
(54) Àrá tí ó sán lu àgbọn náà jẹ́ki ọwọ́ rẹ
wálẹ̀ rọ̀ọ̀rì
Eyí nìkan kọ́, tíínrin (51), bí rọ̀ọ̀rì
(54), kò tilẹ̀ seé lò bí ọ̀rọ̀-orúkọ lọ́nàkọna láìjẹ́ pé a kọ́ sọ ọ́ di
ọ̀rọ̀-orúkọ ná. Bí ó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀-orúkọ ni ọ̀rọ̀ bí rokírokí, roro àti kíákíá
lóòótọ̀, kò yẹ ki wọn ó múkùn-ún báyìí ní lílò.
Ohun tí ó tilẹ̀ yà mí lẹ́nu díẹ̀ ni
àbá pé ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ àti ọ̀rọ̀-ìṣe ní Yorùbá lè pe àkíyèsí tàbí kí ó fi
gbólóhùn míràn yán. Idí ìyàlẹ́nu yìí sì ni pé níwọ̀n bí mo ṣe mọ̀ mọ, ọ̀rọ̀
yòówù tí a fẹ́ẹ́ pe àkíyèsí sí nínú gbólóhùn Yorùbá, a níláti kọ́ sọ ọ́ di
ọ̀rọ̀-orúkọ ná. Eyí hàn dáadáa fún ọ̀rọ̀-ìṣe. Òun ló fà á tí (55) fi tọ̀nà,
ṣùgbọ́n tí (56) kò bọ́ sí i.
(55)
(a) Títíínrín
tí ọwọ́ rẹ̀ tíínrín bí
fọ́nrán
òwú kò jẹ a mọ ibi a ti
lè
gbá a mú.
(b)
Títíínrín ni ó yọ ọ́ lọ́wọ́ ìyà.
(56) (a) *
Tíínrín tí ọwọ́ rẹ̀ tíínrín…
(b) * Tíínrín ni ó yọ ọ́
Tíínrín kò lè jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe kí a lò ó
bí 56(a) àti (b). Bákan náà ni ó sì rí fún gbogbo ọ̀rọ̀-ìṣe.
Ìbéèrè kan pàtàkì wáá súyọ láti ara
àyẹ̀wò wa yìí. Ara ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ mélòó ni Yorùbá ti lè ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ? Bí ó
bá jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìlànà tàbi àmì ìsọdorúkọ ìṣọ̀rí kọ̀ọ̀kàn, kí ni
àwọn àmì wọ̀nyí? A mọ̀ pé Yorùbá le sẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-orúkọ
mìíran nípa lílo àwọn mọ́fíìmù àfòmọ́ bí oní – : igi ->onígi; ti -: igi -> tigi[12].
Àfòmọ́ àti àwọn ìlànà mìíràn sì pọ̀ rẹrẹ tí Yorùbá í lò láti ṣẹ̀dá
ọ̀rọ̀-orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe, tí kì í sì í se ohun tí ó yẹ kí a tún
sẹ̀ṣẹ̀ máa tò sílẹ̀ níbí. Ohun tí mo kàn fẹ́ẹ́ sọ ní pé, bí ó ti wà nínú èdè
mìíràn náà ní ó wà nínú èdè Yorùbá, pé ara gbogbo ìṣọ̀rí ọ̀rọ̀ kọ̀ ni Yorùbá
ti í sẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ; bẹ́ẹ̀ sì ni ó ní àmì tàbí mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá. Fún irú
àwọn tí kò bá ní mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá báyìí, ìlò nínú gbólóhùn nìkan ní ìlànà tí a
lè rí tọ́ka sí bí àmì àyípadà yìí. Bí apẹrẹ, gbogbo èyánrọ̀ (50) gìdìgbàgìdìgbà, kéréje kéréje, fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, kóńkọ́ àti tíínrín ní a lè lò bí ọ̀rọ̀-orùkọ.
Àbá mi ni wí pé kí a tóó lé lo ọ̀rọ̀ kan tí kì í ṣe ọ̀rọ̀-orúkọ tẹ́lẹ̀ bí
ọ̀rọ̀-orùkọ, a níláti kọ́ sọ ọ́ di ọ̀rọ̀-orúko ná; akáṣe, kì í ṣe gbogbo
ìsọ̀rì ọ̀rọ̀ ni ó ní àmì tàbí mọ́fíìmù (tàbí àfòmọ́) ìṣọ̀dorúkọ. Bí mo bá sọ
pé
(57) (a) Títíínrín yọ bọ́
(b) Gìdìgbàgìdìgbà kò wù mí
(c)
Fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ yẹn bo gbogbo
rẹ
ó dájú pé Yorùbá gbà pé ọ̀rọ̀-orúkọ̀
ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fa ìlà sí nidìí wọ̀nyẹn. Àbá mi yìí sì fi àyè sílẹ̀ pé irú
àkàndá ọ̀rọ̀-orúkọ bàyíì lè máà péye bí àwọn tí wọn jẹ̣ ọ̀rọ̀-orúkọ láti
ilẹ̀ wá. Idí ni pé kò sí bí a ṣe lè ṣe ebòlò kò máà run àyán. Ni kúkúrú,
ọ̀rọ̀ bi kíákíá, rokírokí, roro, kẹ̀ù, kì í ṣe
ọ̀rọ̀-orúkọ láti ìlẹ̀ wa; ìgbà tí a bá fẹ́ pé àkíyèsí sí wọn nínú gbólóhùn ni
a máa sọ wọ́n dì ọ̀rọ̀-orúkọ tààrà, ó lójú bí a ṣe lè lò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ,
a ò lè fi wọn yán ọ̀rọ̀-orúkọ mìíran kí wọn ó sì fa àfàgùn fáwẹ̀lì tí ó máa
ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀-orúkọ àkọ́kọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni
wọn kì í sàbá fa kí ọ̀rọ̀-ìṣe olóhùn ìlẹ̀ sọ dídún fáwẹ̀lì da tí àárín bí tí ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn
nígbà tí wọ̀n bá tẹ̀lẹ́ e láìyán nínú gbólóhùn. Awọn ẹ̀yánrọ̀ sì ni gbogbo
àwọn àkíyèsí wọ̀nyí bá mu. Nítorí náà, ní tèmi o, bí ọ̀rọ̀ bíi léńjeléńje, kéréje-kéréje, fẹ̀ǹfẹ̀ àti gìdìgbàgìdìgbà bá jẹ́ ẹ̀yánrúkọ, èyánrọ̀-ìṣe ni àwọn bí kíákíá, rokírokí àti roro.
Kí n tóó pa àkíyèsí mi lórí àwọn
ẹ̀yánrọ-ìṣe wọ̀nyí tì, mo tún fẹ́ ṣe bí àkìyèsí kékeré kan sí i. Ẹ ó ránti
pé a ní Awóbùlúyì dá a lábàá pé ní irú àwọn gbólóhùn 48(a) – (e), àgékù àpòlà
orúkọ tí ní bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n tí a ti
gé ní yẹn kúrò ni porongodo ( < ní porongodo), kẹ̀ù ( < ní kẹ̀ù), yunyun (< ní yunyun), yọ̀bọ̀ (< ní yọ̀bọ̀), àti gbári (< ni gbári). Bí a ba fi ojú
lìǹgúísíìkì òdé òni wo ọ̀rọ̀ náà, kò tọ̀nà kí a ti ìtorí ìlànà kan dábà pé ọ̀rọ̀ kan tí a kì í ṣàbàá gbọ́ máa ń ṣiṣẹ́ ní
ipò kan nínú
gbólóhùn. Eyí ni àwọn onímọ lìǹgúísíìkì ń pè ní “absolute neutralization” ni
Gẹ̀ẹ́sì. Ẹni tí ó bá sì fi àáké kọ́rí pé ní
ṣá wà dandan, kí ó ṣàlàyé ìtumọ̀ tí
àyolò ẹsẹ Ifá yìí (58) yóò ní tí a ba fi ní
dì í làdìrẹ lọ (59):
(58) a díá fún Riri
níjọ́
tí ń fomi ojú ṣògbérè ọmọ.
wọ́n
ní ó réku méjì òlùwéré;
kó
rẹ́ja méjì àbìwẹ̀gbàdà;
kó
rú obídìẹ méjì abẹ̀dọ̀lùkẹ́lùkẹ́;
ewúrẹ́
méjì abàmú rẹdẹrẹdẹ
(Wande
Abimbọla, 1969)
“Eji
Ògbe”. 7-12)
(59) a díá fún Riri
níjọ́
tí ń fomi ojú ṣògbérè ọmọ
wọ́n
ní ó rẹ́ku mẹ́jì olúníwéré;
kó
rẹ́ja méjì abìwẹ̀nígbàdà
kó
rú obídìẹ méjì abẹ̀dọnílùkẹ́lùkẹ́
ewúrẹ́
méjì abàmú ní rẹdẹrẹdẹ[13]
Àkíyèsí kéjì ni pé àwọn
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe wọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ oníhà kọ̀ọ̀kan tí mo mẹ́nu bá ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé
yìí. Idí nìyí tí ó fi jẹ́ pé bí a bá fẹ́ẹ́ pọ́ ìfun ọ̀rọ̀-ìṣe kan ní ọ̀nà tí
Goodenough (1956) dá sílẹ̀, tí wọn ń pè ní “Componential analysis”, ohun tí ó yẹ
kí a máa wá kiri ní gbogbo ẹ̀yánrọ̀-ìṣe tí Yorùbá lè lò mọ́ on. Ẹ jẹ kí a mú
ọ̀rọ̀-ìṣe ga bí àpẹẹrẹ, a lè pé:
ọ̀rọ̀-ìṣe
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe
nǹkan kan ga ráńpẹ́
kútúpẹ́
fíofío
tíantían
roro
gbọ̀ngbọ̀nrọ̀n
gogoro
gàǹgà
gèlètè
gulutu
gègèrè
lọ́nà tí ó jẹ́ pé bí a bá ní nǹkan ga
ráńpẹ́, èkú káká ní a tún fi lè pé ó ga lọ́nà mìíràn tí a ó yàn láàrìn
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe àpà ọ̀tún yẹn láìjẹ pé nǹkan náà ti yìí padà tí kò sì ga
ráńpẹ́ mọ́. Ẹ̀yánrọ̀ nìkan, pàpàá, èyánrọ̀-ìṣe ní èdè Yorùbá ni àpẹẹrẹ
oníhà kan tí ó pé tí Yorùbá sì fi í yán ọ̀rọ̀, kí ihà tí ó bá ohun tí ó ní
lọ́kàn mu máà baà ṣàìyé ẹni tí ó ń bá a sọ̀rọ̀. Ẹyí ní ó jọ Vidal àti àwọn
tètèdé nínú ìmọ̀ gírámà Yorùbá lójú bí mo ti mẹ́nu bà á ṣíwájú.
Bí ọ̀rọ̀ bá wa rí bá yìí, tí a gbà
pé ẹ̀yánrọ̀-ìṣe ni rokírokí, kí ni
kí a pe kúkú, tètè, kààn? Kò yẹ̀ kí ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí àwọn
wọ̀nyí mọ́. Lákọ̀ọ́kọ ná, wọn jẹ́ oríṣìí ọ̀rọ̀ tí a kì í sẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ
lára wọn; kò sì dájú pé ìlànà kan wa tí
a fí lè sẹ̀dá ìru ọ̀rọ̀ bí irú tiwọn kún àwọn tí a tí mọ̀ (Bamgboṣe, 1967);
bẹ́ẹ̀ sì ni kò dájú pé àpólà kankan wà tí a lè lò dípò wọn bí ti ẹ̀yánrọ̀-ìṣe
tàbí ẹ̀yánrúkọ. Nitorí náà, ó yẹ́ kí a kà wọn kún ọ̀rọ̀ gírámà ni. Iṣẹ́ wọn
nínú gbólóhùn kò ju kí wọ́n sọ bí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọ̀rọ̀-ìṣe ń tọ́ka sí ṣe wà sí
lọ. Èyí dàbí mọ́fíìmù “aspect” ní èdè Rọ́síà. Tí ó bá sì tún kúkú wáá jẹ́ pé
òtítọ̀ ni pé túlàásì ọ̀rọ̀-ìṣe nìkan ni a lè lò wọ́n mọ́ bí Awobuluyi tí wí pé
in relations to the verbs with
which they must co-occur
(1974:11)
a kò lè tò wọ́n pọ̀ mọ́
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe tí ó jẹ́ pé, bí a ti rí i lókè yìí, a lè lò bí ìsọ̀rí-ọ̀rọ̀ míràn
nínú gbólóhùn Yorùbá.
IV
Nínu àyẹ̀wó yìí mo ti gbìyànjú láti
ṣe àlàyé oríṣìí àbà tí àwọn onímọ̀ gíràmà Yorùbá ti dá lórí ẹ̀yánrọ̀-ìṣe.
Gbogbo wọn ni wọn gbà pé a máa ń fi oríṣìí àpólà tàbí gbólóhùn kan yán ọ̀rọ̀-ìṣe.
Ṣùgbọ́n àríyànjìyàn wà lórí bí ẹ̀yánrọ̀-ìṣe gidi wà tàbí kò sí; bí ó bá sì wà,
orìṣì mélòó ni? A rí i pé àbá bí mẹ́rin ló wà nílẹ̀: àwọn àra ìwájú
(Crowther, Bowen, de Gaye òun Beecroft) tí wọn pe fíofío, kíakía, abbl.. ni ẹ̀yánrọ̀-ìṣe, ṣùgbọ́n tí wọn ò fi ẹnu
kò lórí àwọn ọ̀rọ̀ bíi kúkú, tile àti sẹ̀sẹ̀. Awobuluyi ní tirẹ̀ kò rí
ìyàtọ̀ láàrin fíofío, kíákíá, àti àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ; Ó rò pé
ẹ̀yánrọ̀-ìṣe èdè Yorùbá kò tayọ ọ̀rọ̀ bíi kúkú, tile àti ṣẹ̀ṣẹ̀.
R.C. Rowlands kò tilẹ́ gbà pé Yorùbá ni ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan tí a lè pè ní èyánrọ̀-ìṣe.
Abà
tèmi ni pé bí èdè Yorùbá ṣe ń lò àwọn ọ̀rọ̀ bí fíofío, kíakía, abbl. bó ti gbà kí á pè é ní ọ̀rọ̀-orúkọ, bẹ́ẹ̀
náà ni ó gbà kí a pè é ni ọ̀rọ̀-ìṣe. Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí kì í ṣe
èkíní-kejì, kò yaní lẹ́nu pé ìwọ̀n ni ìlò rẹ̀ bá ti wọn mu mọ. A kò sì rí
nǹkan mìíràn pe fíofío ju
ẹ̀yánrọ̀-ìṣẹ nítorí iṣẹ́ tí ó ń ṣe gan-an nínú gbólóhùn niyẹn. Ọ̀rọ̀
gíramà àwọn ọ̀rọ̀ bíi ti, yóò, ń, kúkú,
sẹ̀ṣẹ̀ ní tìwọn. Ọ̀rọ̀-ìṣe ni a sì lò wọn mọ́.
Ìwé tí a yẹ̀wò
Abímbọ́lá, Wándé (1969), Ìjìnlè Ohùn Ẹnu Ifa Apa Keji. Collins, Glasgow.
Awóbùlúyì, A. O. (1971), ‘The Verb
in Yorùbá’, Afrikanische Sprachen and
Kulturen- Ein Querschnitt (Hamburger Beitrage zur Afrika-kunde) Band
14, 59 – 65.
Awóbùlúyì, A. O. (1972), ‘On the Classification of Yorùbá Verbs’, in Yoruba Verb Phrase, edited by A.
Bamgbose, pp. 119-134: Ibadan: Unversity Press.
Awóbùlúyì, O. (1973), ‘The Modifying Serial Construction : A
Critique’, Studies in African Linguistics
4, 1: 87-111.
Awóbùlúyì, O. (1974), ‘Some
Traditional Yorùbá “Adverbs” In True Perspective’, Paper Presented at the
Linguistics & Nigerian Languages Seminar University of Ibadan (Feb. 14).
Awóbùlúyì, O. (1975),
“Nominalization or Relativization”? mimeo.
Bámgbóṣé, A. (1967),
A Short Yoruba Grammar. Ibadan:
Heinemann Nigeria Publishers Limited..
Bámgbóṣé, A (1972a), (ed.) The
Yorùbá Verb Phrase. Ibadan: University Press for Institute of African
Studies.
Bámgbóṣé, A. (1972b), ‘What is a Verb in Yorùbá?’,
in Yoruba Verb Phrase, edited by A. Bamgboṣe, pp. 17-59. Ibadan: University
Press.
Bámgbóṣé, A. (1972c), ‘On Serial Verbs and Verbal
Status’, Mimeographed. Read at the 10th West African Languages
Congress, University
of Ghana , Legon, Ghana .
Bowen, T. J. (1858), Grammar and
Dictionary of theYoruba Language. Washington, D.C.: Smithsonian
Institution.
Crowther, Samuel (Rev) (1852a), A Grammar of the Yorùbá Language.
London: Seeleys
Crowther, S. (Rev) (1852b)
A Vocabulary of the Yorùbá
Language. London: Seeleys.
De Geye, J.A. and W-S Beecroft
(1964), Yoruba Grammar. London :
Routledge and Kegan Paul.
Fálétí, A. (1969), Ọmọ Olókùn-Ẹsin. London :University of London Press Ltd.
Goodenough Ward H. (1956),
‘Componential Analysis and the Study of Meaning’, Language 32: 195 -216
Jespersen, Otto (1924), The Philosophy of Grammer.(9th
Impression).London: George Allen & Union
Ltd.
Ọ̀kẹ́, D.O. (1974), ‘Syntactic
Correlates of Notionally Defined Adverbial Types in Yorùbá”, Studies in African Linguistics (Supplement) 233-252.
Rowlands, E.C. (1969), Yoruba
(Teach Yourself Books) London: The English University Press Ltd.
Rowlands, E. C. (1970), ‘Ideophones
in Yorùbá”, African Language Studies
XI: 289-297
Vidal, O. E. (Rev) (1852),
‘Introductory Remarks’ in A Grammar of
the Yoruba by Rev. S. Crowther London: Seeley.
Ward, Ida
C. (1952), An Introduction to the
Yoruba Language.
Cambridge: Heffer & Sons Ltd.
[1] Àkíyèsí:
Níbi ìpàdé Ẹgbé Akọ́mọlédè Yorùbá
Nàìjíríà tí ó wáyé ní st Leo’s Teacher Training College, Ibara, Abeokuta ní
12-14 Oṣù Ọ́gọ́ọ̀sì, 1976 ni a ti ka ìwé yìí.
[2] Nínú ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, n ó máà lo “Ọ̀rọ̀-ìṣe” nitorí
pe gbogbo wa ni ó dà bí ẹni pé a ti gbà á
bí àkànlò ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ kó ìṣe (jó, ṣápẹ́), ìwà (bẹ́, gbọ́n),
ìrísì (ga, tin), tí ó kó gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí pọ̀ síbẹ̀ náà, ẹ ó sàkíyèsì
pé, ẹni tí ó gbọ́n, tàbí tí ó ga kò gbé nǹkan ṣe. Ọ̀rọ̀ bí ìwà si nìyí, ó ní
ìtumọ̀ ìṣe, ìrísí, àti àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, tí a tí mọ̀ mọ‘ni’ tí kì í ṣe ìsẹ̀lẹ̀ bí gbọ́n, mọ̀, rí, lé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n n kò dá a làbàá pé kí a
pa “ọ̀rọ̀-ìṣe” tì kí a mú “ọ̀rọ̀-ìwa” lò dípò rẹ̀. Àpérò ló gbà.
[3]
Àpòlà gbólóhùn tí a bá fi yán ọ̀rọ̀ ní a máa pè ní àpólà
ẹ̀yán. Bí a sì ti ni àpólà ẹ̀yán náà a rí gbólóhùn ẹ̀yán; bì àpẹẹrẹ
(i) Ẹyẹ
ò sọkà, ó ti lọ
(ii) Bí ọlọ́pàá ti wọlé ló wọ̀ sin bí ọbẹ̀
páànù
Gbólóhùn
ẹ̀yán ní Ẹyẹ ò sọkà àti bí ọlọ́pàá ti
wolé.
Bí a ò bá bèèrè ohun tí o yé‘ni, a
lè pe bí obẹ̀ páànù ní àpólà ẹ̀yán
lásán. Ṣùgbọ̀n nígbà tí ó jẹ́ pé bí
ọbẹ̀ páànù ṣe wò ni a ní lọ́kàn, tí ó sì yé ọ̀mọ̀ràn tí a bá ń bá sọ̀rọ̀,
a lè pe bí ọbẹ̀ páànù àti ìrú àpólà
bẹ́ẹ̀ náà ní gbólóhùn ẹ̀yán. A ó tún mẹ́nu ba àpólà ẹ̀yán níwájú
[5] Irú àkíyèsí ìgbẹ̀yin yìí ló fà á ti de Gaye àti Beecroft fi kúkú sọ pé ẹ̀yánrọ̀-ìṣe tí kì í ṣe àtọ̀wọ́dà kò
ju àwọn mẹ́fa wọ̀nyí lọ lédè Yorùbá láí,
ẹn, náà, rí, tó (p. 52).
[6] Níwọ̀n ìgbà tí kò ti sí àríyànjiyàn kan dan-índan-ín lórí
àwọn àpólà ẹ̀yán tàbí gbólóhùn ẹ̀yán, ọ̀wọ́ ẹ̀yánrọ̀-ìṣe pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀
yòókù yíò dá lé lórí.
[7] Vidal. (1852)
[8] Itumọ̀ ìràwọ̀ yìí “*” ni “kò tọ̀nà”.
[10] Bámgboṣe (1975) gbìyànjú láti ṣe àlàyé pé ilò ìrú gbólóhùn
bí tí ó da obì náà sílẹ̀ báyìí
ni (33) yàtọ̀ sí ilò rẹ̀ ní
(i) Mo fẹ́ẹ́ rí ẹni tí ó da obì náà sílè
báyìí.
O
ní tí (i) nìkan ni a lè pè ní gbólóhùn ẹ̀yán.
Emi papàá rò pé àlàyé Bamgboṣe kù
díẹ̀ ká à tó, nítorí pé a ò le máa fi ìtumọ̀ nìkan pín ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn sí
ìsọ̀rí. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ pọ̀ níbẹ̀ bí ẹ ó ti rí ì nínú ìwé Awobuluyi (1975).
[11] Àpẹẹrẹ “non-ideophonic adverbs” Rowlands ni (i) díẹ̀, púpọ̀, yẹn, yìí (Ibadan laa dé
yìí)
(ii)
Ọ̀rọ̀-ìṣe bí mọ́ (n ò jẹ mọ́), ná, rí (a ṣé ìwọ́ ni rí?)
(iii) káríkárí, dájúdájú.
[12] Àlàyé kíkùn yíò wáyé lórí Àtọwọ́dá ọ̀rọ̀-orúkọ yìí nínú
iṣẹ́ tí a ń múra rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí. A kààn fẹ́ẹ́ pé àkíyèsí yín sí i níyìín pé
òdì (tí àwọn onílọ́gíìkì ń pè ni converse ni Gẹ̀ésì), “oní –“ ni
“ti-“.
[13] Ẹ sì tún wo àwọn àtọ́wọ́dà ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
Abì
ga fíofío - Ábi ga ní fíofío
abara
íbùmáṣọ kẹ̀rì - *abaraíbùmáṣọ ní kẹ̀ri
abìfunfun
láú - *abìfunfun ní láú
abọmọẹsẹ
bí ìṣù ẹ̀lú - *abọmọẹsẹ̀ ní bí ìṣù ẹ̀lú.
Kí
a tilẹ̀ wáá bèèrè: kí ni ìtumọ̀ ní
náà?
Ó dájú pé kò lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kan náà ni ní ti lónìí, níṣàlẹ̀, àbí? Bí ó bá jẹ́ mófíìmù ìsọdórúkọ, a jẹ́ pé
lílè rẹ̀ níwájù àwọn ọ̀rọ̀ kì í ṣe dandan (“ní dandan”?) àti pé kò lè pe
gbogbo ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a lè fi ní sọ
di ọ̀rọ̀-orúkọ.
No comments:
Post a Comment