Thursday 21 July 2016

Ainu àti Àwọn Àkójọ Mìíràn


 

Ainu

            Èdè kan tí ó dá dúró ní òun nìkan ni èdè yìí. A kò mọ iye ẹni tí ó ń sọ ọ ṣùgbọ́n ètò ìkànìyàn ọdún 1996 so pe márùndínlógún ni wọ́n. Hokkaido, Japan àti ní Sakhalin àti Erékùsù kuril. Ní ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì ogún, púpọ̀ núnú àwọn ohun tí ó se pàtàkì nínú èdè àti àṣa Ainu ni Jepaníìsì ti gba ipò wọn

 

Akan

            Àwọn ènìyàn bíi mílíọ̀nù méjè ni ó ń sọ èdè yìí ní pàtàkì ní orílẹ̀-èdè Ghana. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní Cote d’lvoire àti Tógò. A máa ń lo Akan fún àwọn èdè tí ó fara pera wọ̀nyí Ashante, fante àti iwì tí àwọn tó ń sọ wọ́n gbọ́ ara wọn ní àgbóyé dáàyè kan ṣùgbọ́n tí wọ́n kà sí èdè òtọ̀ọ̀lọ̀ nítorí àṣà àti ọ̀nà ìgbà kọ nǹkan sílẹ̀ wọn tí kò bára mu. Èdè ìṣèjọba Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n lò láti kọ ọ́ sílẹ̀.

 

Akkadian

            Èdè sẹ̀mítíìkì kan ni eléyìí tí wọ́n ń sọ ní ilè Mesopotámà láàárín sẹ́ńtúrù 2300 sí 500 sáájú ìbí kírísítì (c2300 to c500). A tún máa ń pe èdè yìí ní Accadian. Ìgbà mìíràn a tún máa ń pè é ní Assyro-Babylonian. A mú orúkọ tí ó gbèyìn yìí láti ara àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ̀ méjèèjì (Assyrian àti Babylonian). Èdè yìí ni ó rọ́pò Sumerian tí wọ́n ti ń sọ ní ìpínlẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka-èdè Babylonian ni wọ́n ti ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ìfiṣejọbí (lingua france) láti ìbẹ̀rẹ̀ pèpẹ̀ láti nǹkan bíi mìlẹ́níọ̀nù kìíní sáájú ìbí kírísítì (1st millennium B.C) ṣùgbọ́n láàárín sẹ́ńtúrì díẹ̀ èdè Aramaic ti gba ipò rẹ̀ síbẹ̀ Babylonian sì tì jẹ́ èdè tí wọ́n ń lò fún ìwé kíkọ àti kíkà tí di mìléníọ̀nù kìíní lẹ́yìn ikú kírísítì (1st Millenium A.D). Àkọtọ́ kúnífọ́ọ̀mù (Cuineform script) ni wọ́n fi kọ Akkadian sílẹ̀. Sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún (19th century) ni wọ́n tú u palẹ̀ (decipher) sí èdè tó yé tawo-tọ̀gbèrì.

 

Albania

            Orílẹ̀-èdè kan ni eléyìí. Àwọn ènìyàn inú orílẹ̀-èdè nínú ìkànìyàn 1995 lé ní mílónù mẹ́ta àbọ̀ (3, 549,000). Èdè tí wọ́n ń sọ ní orílè-èdè yìí ni Albanian. Ní àfikún, a tún ní àwọn díẹ̀ kan tí wọ́n ń sọ Gíríìkì (Greek)  Masẹdóníà (Macedonian) Ròmáníà (romani). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ó wá n lo èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè òwò.

 

Albanian

            Èdè ìndo-European’ ken ni eléyìí. Òun ni èdè ìjọba fún orílẹ̀-èdè Alabania. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí tó mílíọ̀nù márùn-ún ní àwọn àdúgbò wọ̀nyí; Albania (ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta (3.2 million) ), àdúgbò Kosovo ní Yugoslavia (nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àbọ̀ (c. 1.5 million)) àti ní apá kan  Gíríìkì (Greek), ítálì (Italy) àti Bọ̀lùgéríà (Bulgaria). Ohun tí ó sẹ pàtàkì nípa èdè yìí ni pé òun nìkan ni ó dá dúró  nínú ìpín tí wọ́n pín èdè ‘Indo-European’ sí Ẹ̀ka-èdè méjì ni ó ní. Àwọn  ẹ̀ka-èdè méjèèjì náà ni a ń pè ní ‘Gheg’ (ní apá àríwá) àti ‘Tosk’ (ní apá gúúsù). Àwọn ẹ̀ka-èdè méjì yìí ni a tún pín sí àwọn ẹ̀ka-èdè mìíràn tí wọn kìí fi gbogbo ìgbà gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. Àwọn èdè tí ó yí èdè yìí ká tí ń ràn án ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ní pàtàkì nípa ọ̀rọ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ díẹ̀ ni ó wà lórí èdè yìí tí ọjọ́ àkọsílẹ̀ wọn kò ju sẹ́ńtúrì karùndínlógún lọ. Álífábẹ́ẹ̀tì Látìnì di mímúlò láti Ọdún 1909 fún èdè yìí. Orí ẹ̀ka-èdè ‘Tosk’ ni wọ́n gbé èdè àjùmọ̀lò èdè yìí lé.

 

 

 

Algeria

            Orílẹ̀-èdè kan ni eléyìí ní ilẹ̀ Aáfíríkà. Ètò ìkànìyàn 1995 sọ pé àwọn ènìyàn ibẹ̀ lé ní Mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n àbọ̀ (28,523,000). Èdè Lárúbáwá (Arabic) ni èdè ìṣẹ̀jọba orílẹ̀-èdè náà. Àwọn tí ó ń sọ ọ tó ìwọ̀n ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún  (80%). Àwọn èdè  mìíràn tí wọ́n ń sọ ní Orílẹ̀-èdè náà ni ‘Kabyle’ tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ ju mílíọ̀nù méjì àbọ̀ lọ (over 2.5. million), ‘Tamashek’ àti àwọn èdè bíi méjìlá mìíràn. Èdè faransé ṣe pàtàkì fún òwò àti fún àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò sí ìlú náà (tourism) ṣùgbọ́n láti nǹken bí ọdún 1996, èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gba ipò èdè Faransé gẹ́gẹ́ bí èdè tí ó gbajúmọ̀ jù tí wọ́n ń kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́.

 

Algonkian or Algonquian

            Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹbí èdè tí a ń pè ní Algonkian tó ogbọ́n. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ààrin gbùngbùn dé ìlà-oòrùn Kánádà (Canada) títí dé ààrìn gbùngbùn dé gúsù Àmẹ́ríkà (USA). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà ni ó ń sọ èdè yìí. Àwọn aṣojú àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí ni ‘Arapaho, Blackfoot, Cheyenne, Cree, Fox, Micnac, Ojibwa àti Shawnee’.  Cree tí ó ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta tí ó ń sọ ọ́ (c. 60,000) àti Ojibwa tí ó ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláàádóta tí ó ń sọ ọ́ (c. 45, 000) ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ wọ́n pọ̀ jù. Sípẹ̀lì ‘Algonkin’ ń tọ́ka sí ẹ̀ka-èdè Ojibwa. Púpọ̀ nínú àwọn èdè tí wọ́n ń sọ nítòsí Algonkian ni wọ́n ti jọ kó wọ́n papọ̀ sínú ẹbí ńlá kan tí wọ́n ń pè ní ‘Macro-Algonkian’ lára wọn ni àwọn èdè ‘Muskogean’ tí Choktaw àti Muskogee wà nínú wọn. Àkọkọ́ Rọ́mánì ni wọ́n ń lò fún kíkọ àwọn èdè yìí sílẹ̀.

 

Altaic

            Àkójọpọ̀  èdè tí ó tó ọgọ́ta tí nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-dínlọ́gọ́fà ènìyàn ń sọ ni a ń pè ní  ‘Altaic’. Wọ́n ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ní Penisula Balkan (Balkan Penisula) ní ìlà-oòrùn àríwá ilẹ̀ Asia. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹgbẹ́ Turkic, Mongolian àti Manchus-Tungus. Àkọsílẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àkọsílẹ̀ lórí Turkic wà ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹ́jọ (8th Century) ṣùgbọ́n a kọ̀ mọ nǹkan kan nípa Mongolian ṣáájú sẹ́ńtúrì kẹtàlá (13th Century). Ó tó sẹ́ńtúrì kẹtàdúnlógún (17th Century) kí a tó rí  àkọsílẹ̀ kanka nípa Manchu. Ní sẹ́ńtúrì ogún (20th Century), ìgbìyànjú tó ga wáyé láti sọ àwọn èdè yìí di èdè òde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó wuyì ni ó ń jáde tí a fi àwọn èdè àdúgbò kọ, bí àpẹẹrẹ, Uzbek. Wọ́n tún ṣe àtúnse sí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ Turkish.

 

 American Samoa

            Orílẹ̀-èdè kan ni ó ń jẹ́ American Samoa. Ètò ìkànìyàn 1995 sọ pé àwọn ènìyàn ibè jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ojójì ó lé mẹ́ta (43, 00). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba. Ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibẹ̀ ni ó ń sọ Samoan. Àwọn kan tún ń sọ Tongan àti Tokelau.

 

Amerindian

            Àkójọpọ̀ èdè kan bí ẹgbẹ̀rún ni a ń pè ní Ameridian. Àríwá ààrin gbùngbùn àti gúsù ilẹ̀ Àmẹ́ríkà ni wọ́n ti ń sọ ọ́. Wọ́n tún máa ń pe àwọn èdè wọ̀nyí ní American Indian. Oríṣíríṣi ẹbí àwọn èdè ni ó wà nínú Ameridian tí a kò lè sọ bí wọ́n ṣe sẹ̀. Àdúgbò ibi tí wọ́n ti ń sọ wọ́n ni wọ́n fi máa ń ṣe àpèjúwe wọn ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ àwọn ẹbí kan lára wọn ní àdúgbò púpọ̀, bí àpẹẹrẹ Penutian àti Hokan. Ẹbí tí a lè pín àwọn èdè Ameridian sí tó àádọ́tà. A tún lè pín àwọn àádọ́ta ẹbí yìí sí ìpín mẹ́rin pàtàkì. Àwọn náà ni Eskimo-Aleut, Na-Dene, Algonkian àti Macro-Siouan. Àwọn èdè kan tún wà tí wọ́n tó ọgbọ̀n tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dá wà fúnrarẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni àwọn èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn èdè Úróòpù mìíràn tí ó dé sí àdúgbò wọn ti dà láàmú tí wọn kò lè fẹsẹ múlẹ̀ mọ́. Àwọn tí ó wá ń sọ èdè Ameridian gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ báyìí kò ju mílíọ̀nù méjìlélógún lọ. meso-American (tàbí àdúgbò ààrin gbùngùn America ní àwọn èdè tí a lè pín sí abẹ́ ẹbí àwọn èdè àríwá àti gúsù Àméríkà. A tún lè pín  wọn sí abẹ́ ẹbí Oto-Manguean tí ó wà ní ìpìnlẹ̀ ààrun gbùngùn. Ẹsí àwọn èdè tí ó wà ní gúsù Àméríkà to ọgọ́rùn-ún. Wọ́n máa ń pín wọn sí oríṣìí mẹ́ta. Ìpín yìí ni Macro-Chinchan, Ge-Pano Carib àti Andean-Equatorial. Ní ayé àtijọ́ àwọn èdè tí wọn yóò ti máa sọ ní ilẹ̀ (Continent) yìí ní láti tó ẹgbẹ̀rún méjì. Nínú èyí, àwọn eléyìí tí a ti yẹ̀ wò to ẹgbẹ̀ta. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ẹnikẹ́ni kò tíì ṣe àpèjúwe. Nígbà tí ọ̀làjú àwọn Òyìnbó dé ni èdè pànyán-án (Spanish) èdè Potokí (Portuguese) di èdè tí ó gbajúgbajà ní àdígbò yìí. Lékè. Èyí, gúsù Àméríkà wà lára  àwọn ibi tí èdè ti pọ̀ jù ní àgbáyé. Nínú àtúnpín tí Greenberg ṣe ní ọdún 1985 (tí kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó gbà á wọlé), ó kó gbogbo àwọn èdè yìí pọ̀ sí abẹ́ ẹbí mẹ́ta: Na-Dene, Eskimo-Aleut àti Amerind.

            Ara ẹbí ńlá ‘Euro-anatic’ ni ó fi Eskimo-Aleut sí. Àwọn tí ó tún wà ní abẹ́ ìpín yìí ni Indo-European, Altaic, Japanese, Korean àti àwọn púpọ̀ míìràn. Amerind ni ó sọ pé ó ní ẹbí tí ó ní ẹgbẹ́ (group) bí gba nínú tí àwọn èdè wọ̀nyí sì wà ní gúsù àti ààrin gbùngbùn Àmẹ́ríkà

 

Olusesan Ajewole (1986), Ògèdèǹgbé Agbógungbórò. Ibadan, Nigeria: Heinemann Educational Books, (Nig) Ltd. ISBN 978 1292261 ojú-ìwé 78

ERÉ NÁÀ NÍ ṢÓKÍ

            À ó rí i pé ìṣẹ́gun àwọn Ìbàdàn àkọ́kọ́ lórí àwọn Ìjẹ̀ṣà ni ó fún Ògèdèǹgbé  ní agbára àti àníyàn láti gbàradì láti gbẹ̀san lára wọn. Ìdi niyi tí ó fi kó ìba àwọn ọmọ ogun béréte tí ó kù jọ́, tí ó sì fi orí lé ọ̀nà ibi tí ó gbọ́ pé àwọn Ìbàdàn wà, tí ó fi gbọ̀nà Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, Arámọkọ dé Ùyìn ní ibi tí ó ti pàdé àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn, nibi tí ó ti ṣẹ́gun wọn ní Òkè-Tòrò pẹ̀lú ìsowọ́pọ̀ àwọn ọmọ ogun Ùyìn.

            Ògèdèǹgbé ò kúkù dúró níbí yìí nìkan, ó tún gbọ̀nà Ìgbàrà-òkè jáde sí Àkúrẹ́. Bí ó ti ń lọ yìí náà ni ó ń jagun lọ rabindun tí ó sì ń ṣẹ́gun. Ta ni tó kò ó lójú? Ó fẹ́ ja Àkúrẹ́ lógun àìròtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àṣírí rẹ̀ tú, ó jẹwọ́, wọ́n sì di ọ̀rẹ́, kódà ó ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa bí bá wọn jagun Ìsẹ̀.

            Lẹ́yìn tí Ògèdèǹgbé kúrò ní Àkúrẹ́, ó fi orí lé ọ̀nà Àkókó tí ó sì ń jà lọ bí ààrá kí ó tó lu jáde sí Ifọ́n lẹ́ba Ọ̀wọ̀. Ifọ́n yìí ni ó gbà padà sí Ìta-ògbólú tí ó wá fi ṣe ibùjoko rẹ̀.

            Ìgboyà, akíkanjú, ifaradà, ìfàyàrán, aáyan, làálàá àti ọgbọ́n Ògèdèǹgbé yọ nínú eré yìí gedegbe. Àwọn nǹkan  wọ̀nyí náà ni ó sì fún un ní àwọn ìṣẹ́gun rẹ̀ gbogbo lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.  

 

Afọlábí Ọlábímtán (1973), Àyànmọ́ . Ìlúpéjú, Nigeria: Macmillan Nigeria Publishers Ltd. ISBN: 978 132 238 1. ojú-ìwé  127.

Ọ̀RỌ̀ ÌṢAÁJÚ

            Apa keji KÉKERÉ ẸKÚN ni ìtàn yí, mo si pe àkọlé rẹ̀ ni ÀYÀNMỌ́. Lori Alabi ni o tun da le lati igba ti o ti fi Aiyéró ìlú rẹ̀ silẹ lọ si Èkó ti o ńlákàkà lati fi iṣẹ olukọ silẹ titi di igba ti o kọṣẹ dókítà ti o si yege ni ilu ‘ọba’.

T.A.A. Ládélé (1978), Ìgbì Ayé ń Yí.  Ìkẹjà, Nigeria: Longman (Nig.) Ltd. ISBN: O 582 63848-8. Ojú-ìwé   112

 

           

            Awọn Yorùbá ni ọ̀wọ̀ t’ó kọyọyọ lati bù fun ọba wọn. Àní igbagbọ wọn ni pe Ọ̀lọrun l’ayé yi’ ni ọba jẹ fun ìlú, bẹ́ẹ̀ ni baálẹ̀ jẹ fun ìletò, bẹ́ẹ̀ ni baálé jẹ fun ọmọ-ilé. Ọ̀wọ̀ yi ati igbagbọ yi win awọn ọba miran sí de ibi pe ìlò ẹran-ọ̀sìn ni wọn nlo awọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ilu. Eyi náà l’ó mu Tẹ́ní-ọlá ti a fi jẹ oye Olú Òtólú ìlú Òtólú di àríì-gbọdọ̀-wí, aṣebi-mé-l’ó mbéèrè fun gbogbo awọn mẹ̀kúnnú abẹ́ rẹ̀. Ṣe òwú ti iya gbọ̀n ni ọmọ ọ́ ran, bi Tẹ́ní-ọlá ti nfòòró ẹ̀mí gbogbo ìlú àmọ́nà rẹ̀ tó, ti ó ni ayé ọba ni oun njẹ, bẹ́ẹ̀ ni awọn ọmọ rẹ̀ ńlálàṣí wọn tó, ti wọn ni ayé baba awọn ni awọn njẹ.

            A kò wa le ṣe ki a má ri awọn kọ̀wọ̀sí bii Bánkárere ati Bàkó ti Ọlọrun dá ni Májìyàgbé. Bi a ba sọ pe ìyà tọ́ si Bánkárere nitori ti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jù ú lọ, èwo ni ti Bàkó ti ọba ni ó ku ọna ti yó tọ̀? Ìyá ti a fi jẹ awọn meji yi l’ó tanná ran ọba nidi ti awọn èèbó ti wọn mu àṣà ‘bí a ti bí ẹrú ni a bí ọmọ’ wa fi gbọ ti wọn sì tako iwa Tẹ́ní-ọlá ati awọn ọmọ rẹ̀.

            A ju Tẹ́ní-ọlá ati Déegbé, ọmọ rẹ̀ s’ẹwọn lati jẹ́ ẹ̀kọ́ fun ọba iyowu ti yó ba tun jẹ. Ṣùgbọ́n bayi ni baba-baba mi í de é, ng kò ni ṣàì-ṣe é bẹ́ẹ̀ tun kó ba Lábándé ti a fi jẹ oye  ṣipo Tẹ́ní-ọlá. Eyi náà l’ó sì mu ki a fi ọgbọn yọ̀rọ̀ ètò ijọba ati eto iṣelu kuro lọwọ ọba, ti ó fi bọ s’ọwọ mẹ̀kúnnù.

 

Láwuyì Ògúnnìran (1993), Ààrò Mẹ́ta Àtọ̀runwá. Ibadan, Nigeria: Ventase Publishers (Int) Ltd. ISBN 978-2458-24-4.  Ojú-ìwé 107.

 

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

            Ohun tí ènìyàn yóó gbé ilé-ayé jẹ́, ní kékeré ni yóó ti máa hàn lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ilé-ayé gan-an, nígbànígbà ni: ìgbà ríríṣe, ìgbà àìríṣe, ìgbà àlàáfíà, ìgbà pákáleke, ìgbà ìrọra, ìgbà ìnira, ìgbà ìṣẹ́, ìgbà ọrọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

            Ìgbà ìṣẹ́ ayé dé, ó dojú ìṣẹ́ kọ wọ́n: Àdìó, Àbẹ̀ó àti àwọn ọmọ wọn ní apá kan; Láyínká, Adékémi àti àwọn ọmọ wọn ní apá kejì; Ládọ́gba, Ládọjà àti àwọn ọmọ wọn ní apá kẹta – gbogbo wọn ń bá ìṣẹ́ wọ̀yá ìjà.

            Ìṣẹ́ ń fẹ́ borí wọn, àwọn náà ń fẹ́ borí ìṣẹ́. oníkálukú ń gbọ́wọ́ ìjà tí ó mọ̀ láti le borí ìṣẹ́. Ẹni tí ó tọ ará lọ kí ó lè ràn án lọwọ pẹ̀lú ẹni tí ó ko aya, ọmọ ati òun tìkálarẹ̀ jọ tí ó fi wọn ṣe ará tirẹ̀ lati le bori ìjà náà. Àwọn ni ‘Ààrò mẹ́ta àtọ̀runwá’. Àsèyìnwá, àsẹ̀yìnbọ̀, ìjà náà fi orí tì síbìkan. Ọpẹ́lọpẹ́ ààrò mẹ́ta tí kò jẹ́ kọ́bẹ̀ ó dànù.

 

M.A. Adérìnkòmí (1978) Gbé Wiri ìlúpéjú, Nigeria: Macmillan Nigeria Publishers Ltd. ISBN: 978-132-272- 1  ojú-ìwé   89.

ÀṢAMỌ̀

 

            Ìtàn tí a  ó kà nínú ìwé yìí fi díẹ̀ nínú ọgbọ́n àdákàǹdeke ti àwọn olè ń lò láti fi pa ọmọnìkejì wọn lẹ́kún hàn, àti ìyà ti ó dúró de òṣìkà àti aláìláàánú-lójú l’ọ́jọ́ iwájú. Ó sì tún fi irú ènìyàn tí ó wà ní àwùjọ wa hàn: àwọn bíi alọ́nilọ́wọ́gbà, àwọn tí ń fẹ́ owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọn tó ṣiṣẹ́ ti wọn gbà wọn fún, tí wọ́n sì ń sanwó lé lórí fún wọn.

            Èrò ẹni t’ó kọ ìwé yìí ni láti tú àṣírí àwọn jàgùdà tí ó ń gbé ìlú ńláńlá àti láti fi ìṣọ́ra kọ́ àwọn ènìyàn nípa rírìn tìfura tìfura nínú bọ́ọ̀sì àti ní ibùdó ọkọ́ èrò kí wọn ó má baà ṣòfò ohun ìní wọn ni ibi tí a dárúkọ wọ̀nyí. Èrò ẹni ti ó kọ̀wé yìí náà sì tún ni l;ati fi hàn pé bí ó ti burú tó nnì l’áyé òde òní, síbẹ̀síbẹ̀ a ń rí àwọn olóòótọ́ kọ̀ọ̀kan ti ìwà wọn àti ìṣe wọn ṣeé fi ṣe àfarawé tàbí àríkọ́gbọ́n.

           

 

Babátúndé Ọlátúnjí (1978). Egbìnrìn Ọ̀tẹ̀. Ibadan, Nigeria: University Press Limited ISBN. 978 154041 9. Ojú-ìwé  155.

 

 

            Eré yìí fi oríṣiiriṣi ìyọnu ti ń bẹ fún olórí hàn. Ìyọnu wọnyí bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí olúwarẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ j’oyè ati lẹhin tí ó bá j’oyè tán. Bi ìlú bá dara oun ni, bí kò sì tún dara oun náà ni. Bẹ́ẹ̀ ni awọn tí wọ́n bá a du oyè kò ní pada lẹ́hin rẹ̀. Eyi l’ó fà á tí awọn ọ̀tá Oyènìan ń fi olè bá ìlú Ìdómògùn jà.

            Ni ilẹ̀ Yorùbá, ibi ni a fi ń jẹ oyè ṣugbọ́n ìwà ni a fi ń lò ó. Bi ènìyàn bá ní ahun bi ó dé adé owó kò wu ‘yì. Oriṣiriṣi ohun tí kò tọ́ sí olóyè ni yóò máa sábà bá a. Ìlú pàápàá yóò gbìyànjú láti kọ ẹhin sí olúwarẹ̀. Ipò kò le yí ìwà ènìyàn dà. A ó rí eyi bẹ́ẹ̀ nínú eré onítàn yìí nibi tí ìwà ahun, anìkànjẹ ati àmọ̀tán mú kí baálẹ̀ rìnrìn àwàsà ti wọn fi fi èkùrọ́ lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n baálẹ̀ l’áhun l’ásán ni kìí ṣe aláìṣòdodo. Eléyìí náà l’ó yọ ọ́ nigba ti ó ku ìṣísẹ̀ kan ki ó wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n.

 

 

Kọ́lá Akínlàdé (1986),Ta ló gbin igi oró. Ibadan, Nigeria: Erans Brother (Nigeria Publishes) Limited ISBN 978 167 173 4. Ojú-ìwé  179.

 

            Jọbí ló ń ṣílé tí gbogbo ará àti ọ̀rẹ́ wá bá a ṣe àṣeyẹ. Dàpọ̀ tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Jọbí kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ náà. Dókítà ni Dàpọ̀, ó sì ní láti padà sí ẹnu iṣẹ́ kí ilẹ̀ tó mọ́ ní ọjọ́ ìyí. Ojú ọ̀nà ni olubi kan lu Dàpọ̀ pa sí.

            Ṣé, ẹní máa ríre á yọ̀ fóníre. A wá lè sọ pé Dàpọ̀ jẹ̀bi pé ó lọ bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílé bí, àbí ibi iṣẹ́ rẹ̀ ni ò yẹ kí ó lọ?

            Ta ló ṣe iṣẹ́ ibi yìí ni ìbéèrè tí àwọn ọlọ́pàá kò lè tètè dáhùn tí Jọbí fi ránṣẹ́ pe Akin Olúṣinà tí ó jẹ́ àgbà ọ̀tẹlẹ̀múyé.

           

 

Olágòkè Morẹ́nikẹ́ (1991), Tọlọ́runlàṣẹ.  Ìkẹjà, Nigeria: Logman Nigeria Limited ISBN 978 139-889-2 ACR 2. Ojú-ìwé  76

 

 

            Ìkà á koníkà, rere a bẹ́ni rere. Etí ọbá parọ́ mọ́ Tọlọ́runlàṣẹ láti wá ojú rere ọba. Ọbá gbógun, ìjòyè gbógun, ìyàwó Tọlọ́runlàṣẹ náà tún lẹ̀dí àpò pọ̀ máwọn ọlọ̀tẹ̀.

            Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ẹlẹ́kọ ọ̀run ń polówó fún Tọlọ́runlàṣẹ…

            Nínú eré aládùn yìí, Olágòkè Morẹ́nikẹ́ fi ẹwà-èdè, àṣà àti ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá hàn, ó sì wá fi ìbéèrè kan sílẹ̀ fóníkálukú láti dáhùn rẹ̀. Ti ta làṣẹ? TỌlọ́run ni àbí tọba?

 

 

 

Oyètúndé Awóyẹlé (1993), Àjẹkú L’ayé. Ìkẹjà, Nigeria: Longman Nig. Plc. ISBN 978. 139-907-4. Ojú-ìwé 68.

 

 

Àlàyé l’órí ìtàn-àròsọ Àjẹkú L’ayé ati àhunpọ̀-ìtàn t’ó níbẹ̀

Ìtàn náà pín sí apé méjì: Apá kinní sọ nípa ìgbésí-ayé Àlàní ní abúlé Alágbàáà àti abúlé Ológògó nígbà tí Apá kejì fi ìgbésí-ayé Àlàní hàn ní Èkó àti bí ó ṣe lo ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀ ní Ológògó.

            Ìtàn-àròsọ Àjẹkú L’ayé  jẹ́ ìtàn kan tí òǹkọ̀wé pilẹ̀ rẹ̀ sí inú abúlé tí ó jinnà sí ìlú. Nínú àbúlé tí a ń pè ni Ológògó, a rí i pé àwọn ènìyàn kò ní iṣẹ́ mìíràn bíkòṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣíṣe. Èyí  hàn ní ilà kinní orí kinní níbi tí a ti kà pé ‘Àlàní tọrọ oko dá lọ́wọ́ alàgbà Bámgbélùú láti máa gbin ọkà, ẹ̀wà, erèé, ìṣu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.’ Oríṣiríṣi nǹkan t’ẹ́nu ń jẹ ni a gbọ́ pé Àlàní ń gbìn. Yàtọ̀ sí èyí, Àlàní a máa bá Olóko roko, a máa bá wọn ká kòkó, a sì má a bá

 

 

Kọ́lá  Akínlàdé 91982), Aṣenibánidárò.  Ìbàdàn, Nigeria: Heinemann Educational Books (Nig.) Ltd. ISBN: 978 129 217 2. Ojú-ìwé   71.

 

            Wọ́n ṣe àìsùn òkú ìyá Adégùn mọju ni apoti tí owó wà nínú rẹ̀ bá sọnù, ó sọnù towítowó! Ipayà wá dé bá Adégún; ó ku àádọta náira ti yoo san fun ọlọti, awọn abániṣẹ̀yẹ sì ti mu ọti tán, ọlọti fẹ́ gbowó, apoti sì sọnù towótowo! Èèmọ̀; ogun ń lé wọn bọ̀, odò kún! Ọpẹ́lọpẹ́ Adeogun ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló fún ọlọ́ti ni àádọta náira, oun ni kò jẹ́ ki Adegun ṣẹ̀sín.

            Ta ní jí apoti ọmọ-olókùú gbé towótowo? A lè pe ni wá jẹbọ kò sì di ọ̀ràn?

            Àkanbi agbèrò wà nibi àìsùn naa, oun sì jẹ́ “firì nídìí ọ̀kẹ́, a lọ k’ólóhun kígbe.” Oun ni wọ́n kọkọ fura sí. Wọ́n sì tún fura si Arìyìíbí awakọ̀.

            Akin Oluṣina, ògbóǹtagí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, wá bọ́ sẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu. Ẹ̀rí tó kọkọ ri na ìka ẹ̀sùn sí Níran ati Olúdé, awọn mejeeji wọnyi sì jẹ́ awakọ̀ pẹlú. Ṣùgbọ́n ohun tó wà lẹ́hìn ọ̀fà ju òje lọ.

            Jẹ́ kí a tẹle àgbà ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa, Akin Oluṣina, bó ti n fi ọgbọ́n iṣẹ́ ati ọ̀pọ̀ làákàyè tọpa ọ̀rọ̀ náà títí ọwọ́ fi tẹ òkúùgbẹ́ aṣenibánidárò.

 

Adékanmi Oyedele (1981), Ki ni mo ṣe?  Ìlúpéjú, Nigeria: Macmillan Nigerian Publishers Ltd. ISBN: 978 132 563 1. Ojú-ìwé 110.

 

            Gbọ́látutù dé orí oyè pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìyá rẹ̀, nípa sísọ Adédọlápọ̀ ọmọ orogún rẹ̀ di alábùkù-ara nítorí ó mọ̀ pé alábùkù-ara kì í joyè. Ẹ̀san kò pẹ́, ojú Ọba fọ́ ó sì ran àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ̀bánà àti Gbégbáọlá jáde láti wá ìwòsàn lọ.

            Ẹ̀wà Ẹ̀bánà wo Dúródọlá tíí ṣe oníwòsàn lójú, ó pinnu pé òun yóò wo ojú sàn bí Ẹ̀bánà bá lè fẹ́ òun Ògúndáre tíí ṣe ọ̀rẹ́ Dúródọlá ni ó ṣe ìwòsàn náà. Ìdánwò dé, a dá ẹjọ́ ikú fún Dúródọlá. Báwo ni ẹni gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ ṣe lè di ọkọ ọmọọba?

 

 

 

Láwuyì Ògúnníran (1977), Ààrẹ-Àgò Aríkúyẹrí. Ìlúpéjú, Nigeria: Macmillan Nigeria Publishers Ltd. ISBN: 978-132-256-x. Ojú-ìwé 112.

            Ọmọ méjì wọ́kú l’ẹ́ẹ̀kan náà fún Ààrẹ-Àgò. Ò ní kí wọn lọ wádìí ta l’ó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ náà. Ìyáálé fi ọ̀ràn bọ ìyàwọ́ rẹ̀ l’ọ́run. T’ohùn-t’ẹnurẹ̀, ọmọ kẹta wọ́kú. Ààrẹ-Àgò fa ìbínú yọ. Òkú sùn! Ọ̀ràn de! Ẹjọ́ dé iwájú Baṣọ̀run Ògúnmọ́lá. Ìdájọ́ ńlá sẹlẹ̀! Bóyá ni a le fir í eré tí enìkan ti kọ s’ẹ́hìn lórí ìtàn Yorùbá ní ìlú kan tàbí òmíràn tí ó ta eré yìí yọ.

 

Olú Owólabí (1981), Àbíkú Solóògùn Dèké.  Ìlúpéjú, Nigeria: Macmillan Nigeria Publishers Ltd. ISBN: 978 132 586 0. Ojú-ìwé 94.

 

            Yoruba bọ̀, wọ́n ní, ‘Òjò àrọ̀jù ni í mú eégún sá wọ̀’lé aró…’ Àgbákò àbíkú léra-léra ni ó mú Sunmọnu Ọmọniósimí ati ìyàwó rẹ̀, Raliatu, di ẹni tí ń tọ ilé babalawo ká, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Musulumi hán-rán-ún ni wọ́n.  Ṣùgbọ́n kàkà kí ó sàn fún ìyá àjẹ́, ṣe ni ó tún ń bí obinrin l’ọ́mọ. Bayii ni tọkọ, taya ṣe sún kan oníṣègùn, Ṣẹ̀gbẹ̀jí Ajírọ́sanyìn, ti èṣù wá tún ta’po sí ọ̀ràn.

 

 

Ọládẹ̀jọ Òkédìjì (1971), Àgbàlagbà Akàn. Ìkẹja, Nigerai: Longman Nigeria Ltd. ISBN 978-139-095-6. Ojú-ìwé.

 

            Ìpàǹpá awọ́n ogboju ọlọṣa kan nṣe bí nwọn ti fẹ, lati Ibadan titi de Origbo, apá awọn ọlọpa ko si ká wọn. Lapade wá gbà a kanri lati ṣe àwárí ibùba awọn ìgárá ole yi, ki oun si kó wọn le ijọba lọwọ. Enia mẹta ọ̀tọ̀tọ̀ ni iku òjijì pa ní ọjọ ti ìwadi naa bẹ̀rẹ̀, oniruuru àjálù miran sit un nyọju ní ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé; ṣugbọn kàkà kí Lapade já ǹkan wọnyi kúnra, ó worímọ́ iwadi naa ni. Awọn ọlọpa kò dunnú si atojúbọ̀ tí Lapade nṣe si iṣẹ wọn, nitorinaa nwọn hàn án ni kugú èmmọ̀. Awọn ọlọṣa si ńsa gbogbo ipá wọn lati ṣí i lọwọ. Ṣàṣà enia ni yio le pa ìwé yi dé lai tii kà ìtàn inu rẹ̀ tán.

 

ÀGBÀLAGBÀ AKÀNni ekeji ninu awọn ìtàn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ti njẹ Lapade. Orukọ ìtàn kínní ni ÀJÀ L’Ó L’ẸRÙ. Òwe àtàtà, ijinlẹ ọrọ, àgbà ọ̀rọ̀, àwàdà, ati ídaraya oriṣiriṣi ni ó dá awọn ìtàn Lapade lọ́wọ́ awọn ti o kundun Yorùbá kíkà. Ogunlọgọ òǹkàwé l’ó ńkan sáárá si Ọladẹjọ Okekdiji fun dídá irú itan yi silẹ ní ede Yorùbá, ati fun bírà gbogbo ti o nfi ede naa dá.

 

 

ISBN 0 582 63839 9

ISBN 978-139-095-6 (NIG).

 

 

 

D.O. Fagunwa (1950), Igbó Olódùmarè. Nelson Publisher Ltd in association with Evans Brothers (Nigeria) Publishers Ltd; Ìbàdàn, Nigeria. ISBN: 978 126 241 9. Ojú-ìwé 165.

 

            Eléyìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìtàn àròso tí D.O. Fagunwa kọ. Ó sọ ìtàn Olówó-ayé àti ìrìnàjò rẹ̀ ní Igbó olódùmarè. Ó sọ bí ó ṣe dé ọ̀dọ̀ bàbá-onírùngbọ̀n yẹnkẹ àti bí ó ṣe rí òpin Òjòlá-ìbínú

 

 

 

D.O. Fagunwa (1951), Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀.  Nelson Publishers Limited in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Ltd, Ibadan, Nigeria. ISBN: 978 126 237 0. Ojú-ìwé 102.

           

            Ìwé ìtàn-àròsọ yìí dá lé orí Àkàrà-ogun àti ìrìnàjò rẹ̀ sí inú Igbó Irúnmọlẹ̀.

            Nínú ìwé yìí, a ó ka nípa Àkàrà-ogun àti Lámọ́rin, àwọn èro ọ̀kè Láńgbòdó, Àkàrà-ogun lọ́dọ̀ Ìrágbèje nílé olújúléméje àti àbọ̀ òkè Láńgbòdó

 

 

 

D.O. Fagunwa (1955), Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje. Nelson Publishers Ltd in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Ltd; Ìbàdàn, Nigeria. ISBN: 978 126 240 0. Ojú-ìwé 117.

 

          Ìrìnkèrindò ni ìwé ìtàn-àròsọ yìí dá lé lórí. Ìwé yìí ni D. O. Fagunwa pè ní Apá Kẹ́ta Ògbójú  Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Nínú Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje, a rí ìbẹ̀rẹ̀ ìrììnàjò sí òkè ìrònú, alábàápàdé ẹlẹ́gbára, ìtàn òmùgọ́diméjì àti Òmùgọ́dimẹ́ta ìtàn wèrédìran àti ìgbéyàwó Ìrìnkèrindò

 

 

D.O. Fagunwa (1962), Àdììtú Olódùmarè. Nelson Publishers Ltd in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Ltd; Ìbàdàn, Nigeria. ISBN: 978 126 239 7 Ojú-ìwé 148

           

Ìwé ìtán-àròsọ yìí dá lé orí Àdììtú-Olódùmarè. Ìwé náà sọ̀rọ̀ nípa bí Àdììtú-Olódùmare ṣe pàdé ìjàngbọ̀n bí ó ṣe di èrò inú igbó, bí ó ṣe lá àlá ìyanu, bí ó ṣe agbéyàwó àti bí ìgbẹ̀yìn rẹ ṣe rí

 

 

Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé (1998), Ìgbà Lonígbàá kà. Lagos: The Capstone Publication. ISBN: 978 34284-7-0-. Ojú-ìwé 77.

            Àkọ́jọpọ̀  ewì ni ìwé yìí. Ewì mọkànlélọ́gbọ̀n ni ó wà nínú rẹ̀. Òǹkọ̀wé yìí gbà wí pé ìwé èwí yìí ni ìwé ewì àkọ́kọ́ tí obìnrin yóò gbé jáde láti fi èrò wọn sí gbogbo ohun tí ó ń lọ han. Ọ̀ken-ò-jọ̀kan ni àwọn ewì tí ó wà nínú ìwé náà.

 

J.F. Ọdúnjọ (1961), Àkójọpọ̀ Ewì Aládùn. Ìkẹjà, Nigeria: Longman Nigeria Ltd. ISBN: O 582 63845 3; (Nigeria) 978 139 031 x Ojú-ìwé 58.

            Àwọn ewì mẹ́rìnlélógún ni ó wà nínú ìwé yìí. Wọ́n kún fún ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀. Kí àwọn ewì náà lè yé tawo-tọ̀gbẹ̀rì,àwọn  àlàyé ọ̀rọ̀ wà nínú ìwé náà fún ewì kọ̀ọ̀kan

 

University Press PLc (1991), A Dictionary of the Yoruba Language. Ìbàdàn, Nigeria: University Press PLC. ISBN: 978 030 760 5 Ojú-ìwé  218+242’

 

Ìwé atúmọ̀-èdè ni ìwé yìí. Apá kìíní  túmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Yorùbá. Apá kejì túmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó kópa nínú kíkọ ìwé yìí. Ọdún 1913 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde. Ó sọ̀rọ̀ nípa lẹ́tà Yorùbá. Ö sọ̀rọ̀ nípa ewé àti igi. Ó sọ̀rọ̀ nípa ẹyẹ. Ìwé atúmọ̀-èdè tí ó wúlò gan-an ni.

 

Malọmọ́ babajamu (1959),  Yorubá Literature. Ilorin: Nigerian Publications Service. Ojú-ìwé 306.

           

            Lékè pé Lítírésọ̀ Yorùbá ni orúkọ ìwé yìí, ó sọ̀rọ̀ nípa gírámà àti àṣà Yorùbá náà. Àwọn oníwèé mẹ́wàá àti àwọn tí ó ń lọ sí ilé ìkósé olùkọ́ni ni ìwé náà wà fún.

            Àwọn ohun tí ó wà nínú sílábọ́ọ̀sì Yorùbá ni ìwé yìí kọ́kọ́ mẹ́nu bà ó sì sọ̀rọ̀ nípa wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

 

J.F. Ọdúnjọ (1964), Ọmọ Òkú Ọ̀run. Lagos, Nigeria: African Universities Press. Ojú-ìwé 52.

            Orí wálé ti gbogbo ènìyàn ń pè ní ọmọ òkú ọ̀run ni ìwé yìí dá lé. Gbogbo ìyà tí wálé jẹ láti ọwọ́ Àbẹ̀kẹ́, ìyàwó baba rẹ̀, ni ìwé yìí mẹ́nu bà. Ìwé yìí kò ṣàìmẹ́nu ba bí ẹni tí a pè ní òkú ọ̀run tún ṣe di alààyè. Ìwé yìí ní àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí ó kún fún ìbéèrè tí ó lè jẹ́ kí ohun tí àwọn òǹkàwé kà yé wọn.

 

R.C. Abraham (1946), Dictionary of Modern Yorùbá. London: Hodder and Stoughton. ISBN: 0 340 17657  1. Ojú-ìwé  776  

           

            Ìwé atúmọ̀-èdè yìí ni a lè sọ pé ó kún jù nínú gbogbo àwọn atúmọ̀-èdè tí ó wà lórí àtẹ ní a kọ lórí èdè Yorùbá.

            Yàtọ̀ sí pé o ṣàlàyé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àkọtọ́, àmì orí ọ̀rọ̀, ìró, gírámà àti àsìkò nínú èdè Yorùbá.

            Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán ẹyẹ, igi àti àwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀ ni ó kún inú rẹ̀

 

J. Adé Àjàyí and Rober Smith (1971),  Yoruba Warfare in the 19th Century. Ibadan, Nigeria: Ibadan University Press in association with the Institute of African Studies, University of Ibadan and the Cambridge University Press. Ojú-ìwé 172.

 

            Orí àwọn ogun tí ó wáyé ní sẹ́ńtúrì kọkàndín lógún ni ìwé yìí dá lé. Apá méjì ni ìwé yìí pín sí. Robert Smith ni ó kọ apá kìíní tí ó sọ̀rọ̀ lórí oríṣiríṣI agun tí ó wáyé ní ilẹ̀ Yorùbá láàrin 1820 sí 1893. J. Adé Àjàyí ni ó kọ apá kejì. Níbẹ̀, ó sọ̀rọ̀ lórí ogun ìjàyè.

            Àfikún méjì ni ìwé náà ní. Àfikún àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ọ̀gágun jone sọ nípa ogun Ẹ̀gbá. Àfikún kejì sọ̀rọ̀ nípa ogun ọ̀sà (Lagoon warfare). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ máàpù àti àwọn ìwé ìtọ́kasí ni ìwé náà ní.

 

Sir Olaniwun Ajayi (2005), This House of Oduduwa must no fall. Ibadan, Nigeria: Y-Books. ISBN: 978-2659-37-1. Ojú-ìwé 351

 

            Ọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ìwé yìí dá lé ṣùgbọ́n tí Sir Àjàyí fi ojú ọmọ Yorùbá kọ. Ojú ọmọ Yorùbá ni ó fi wo bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe rí lóni.

            Ó bẹ̀rẹ̀ láti orí ìgbà tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣe ìjọba lé wa lóri dé orí wàlálà òṣèlú tí a ní ní ilẹ̀ Nììjíríà títí di odun 2005.

            Ìwé tí ó yẹ kí gbogbo ọmọ Yorùbá kà ni.

           

 

Kínyọ̀ Bọ́lọ́rundúró (1982) Ìlànà àti Ètò ìkọ́ni ní Èdè Yorùbá. Ilé-Ifẹ̀, Nigeria: Bọ́lọ́rundúró Publico. ISBN: 932 2113-48-1. Ojú-ìwé 112.

 

            Ìwé yìí wà fún ìlò àwọn akẹ́kọ̀ọ́-olùkọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kóṣẹ́. Olùkọ́ onípò kejì, onípò kìíní àti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí ó ga jù lọ.

            Ó sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe ń kọ́ni ní ìwé kíkà, gírámà àti lítírẹ́sọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ìperí Yorùbá wà ní òpin ìwé náà.

 

A. Adégbìtẹ́ (1997), ‘The Effect of Acculturation on the Contemporay Popular Music; Research in Yoruba Language and Literature: (Burbank www-researchin yoruba.com) ojú-ìwé  1 -5. (ISSN: 1115-4322.)

 

            Orí orin ni iṣẹ́ yìí dá lé. Lẹ́yìn ìfáárà, ó mẹ́nu ba àwọn ohun tí ó ń mú àyí padà wá bíi ẹ̀sìn Mùsùlùmí, ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ àti ọ̀làjú tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì mú dé ilẹ̀ àwọn ènìyàn dúdú. Lẹ́yìn èyí ni ó wá sọ àyípadà tí ó dé bá tìlùfìfọn. Ní ìparí, ó mẹ́nu ba ìdí tí àwọn èwe fi fẹ́ràn àwọn orin tí ó ti òkè òkun wá ju ti ilẹ̀ wa lọ.

 

Bọ̀dé Agbájé (1997), A Socio-Historical Appraisal of the Yorùbá Orature: The Èkìtì folksongs or a Case Study’, Research Yorùbá Language and Literature 9 (Burbank (research in yoruba.com): ojú-ìwé  6-12 (ISSN: 1115 – 4322).

           

            Lítírésọ̀ alohùn ní ilẹ̀ Èkìtì ni iṣẹ́ yìí dá lé. Àwọn nǹkan tí ó jẹ iṣẹ́ yìí lógún ni àwọn ohun tí a máa ń bá pàdé nínú orin ìbílẹ̀ Èkìtì. Lára àwọn ohun tí òǹkọ̀wé mẹ́nu bà ni àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ara ẹni gẹ́gẹ́ bí ẹni kọ̀ọ̀ken. Òǹkọ̀wé tún mẹ́nu ba àwọn ohun tí ó kó gbogbo àwùjọ pọ̀ tí a máa n bá pàdé nínú  àwọn orin wọ̀nyí.

            Ní ìpari, òǹkọ̀wé sọ pé ìrírí àwọn ènìyàn ni ó bí púpọ̀ nínú àwọn orin wọ̀nyí.

 

Bádé Àjàyí (1997), ‘The Language and Style in Ifá Literary Corpus’, Research in Yoruba Language and Literature 9 (Burbank www-researchinyoruba.com)), ojú-ìwé: 13-16. ISSN: 1115-4322.

           

            Èdè àti sítáì ẹsẹ Ifá ni iṣẹ́ yìí dá lé. Lẹ́yìn ìfáárà, òǹkọ̀wé mẹ́nu ba fọ́múlà sítáì inú ẹsẹ Ifá. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àfiwé tààrà àti àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ kí ó tó wá sọ̀rọ̀ nípa ìsohundènìyàn. Àwọn ọnà èdè yìí ni ó ń jẹ́ kí ó rọ babaláwo lọ́rùn láti bá Ọ̀rúnmìlà sọ̀rọ̀.

 

Javier Perez dé Cuellar (1997), ‘A Marshall Plan for Culture and Development Culture: Key to the 21st Century’, Research in Yoruba Language and Literature 9 (Burbank (www.researchinyoruba.com), ojú-ìwé 17-19. ISSN: 1115-4322

           

            Perez de Cueller ni Baba Isale (President) World Communication on Culture and Development. Òun kan náà ni ó jẹ́ Secretary-General United Nation tẹ́lẹ̀. Ìdí tí wọ́n fid a World Communication on culture and Development ni ó jẹ iṣẹ́ yìí Lógún.

            Ó sọ èròǹgbà ẹgbẹ́ yìí àti ètò tí ẹgbẹ́ náà ní fún àṣà àti ìdàgbàsókè àṣà ní sẹ́ńtúrì kọkànlélógún 

 

Research in Yoruba Language and Literature  9. Burbank: Technicians of  the Sacred. ISSN: 1115-4322. Website: researchinyoruba.com

           

            Nínú nọ́ńbà yìí, àwọn òǹkọ̀wé mẹ́rìnlá ni ó kọ átíkù sínú rẹ̀.  = = A. Adégbìtẹ́ = = tí ó wà ní Dept of Music, OAU, Ife, Nigeria kọ nǹkan lórí tìlùtìfọn. Ó pe átíkù rẹ̀ ní ‘The Effect of Acculturation on the Contemporary Popular Music”, ==Bọ̀dé Agbájé== tí òun náà wà ní Dept of African Languages and Literatures, OAU, Ifẹ Nigeria kọ nǹkan lé orí ‘A Socio-Historical Appraisal the Yoruba Orature”, ==Bádè Àjàyí== (Dept of Linguistics and Nigeria Languages, University of Ìlọ́rin Nigeria kọ nǹkan lórí Ifá tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ ‘The Language and Style of Ifa Literary Corpus”, = = Javier Perez de Cuellar = = kọ nǹkan lé orí ‘A marshall Plan for Culture and Development Culture’,  = = O. Olúránkinṣé = = (Adéyẹmí College of Education, Oǹdó, Nigeria) kọ nǹkan lórí ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀. Ó pe àkọlé iṣẹ́ rẹ̀ ní ‘Element of Prognosis  Kọ́lá Akínlàdé’s Yorùbá Novels’,. P.S.O. Àrẹ̀mú àti T.Y. Ògúnsiakin (Dept of Fine Arts, OAU, Ifẹ̀, Nigeria) kọ nǹkan lé orí ‘Red, Black and White Inevitable Currencies in Yorùbá Traditional Religion”, ‘African-American spirituals; A Study of Bi-cultural Influence ni àkòrí ohun tí O. Ọláníyan (Dept of Music, OAU, Ifẹ̀, Nigeria) kọ  nǹkan lé lórí. O.O. Bátẹ̀yẹ (Dept of Music, OAU, Ifẹ̀, Nigeria) kọ nǹkan lérí ‘Mood Setting/Pictorial Imagery in the Nigerian Art Song’, B.O. Ọláyinká (Dept of Religious Studies, OAU, Ifẹ̀, Nigeria) kọ nǹkan lérí òwe. Ó pe iṣẹ́ rẹ̀ ní ‘Proverbs: Issues of Yoruba Femininity from a feminist Hermeneutical Perspective’. O. Adébọ̀wálé (Dept of Languages and Liguistics, Adékúnlé Ajásin University, Àkùngbá-Àkókó, pe àkòrí iṣẹ́ rẹ̀ ní ‘Political Communication in Yorùbá Novels’. Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀sà ni ni Kinyọ̀ Bọ́lọ́rundúró (Ọ̀ṣun State College of Education, Iléṣà, Nigeria kọ nǹkan lé lórí. Ó pe àkọ̀rí iṣẹ́ rẹ̀ ní ‘The “Language” of the Ìjèṣà’. O. Oyèṣakin (Dept of Yorùbá and Communication Arts, Lagos State University, Lagos, Nigeria) kọ nǹkan lórí ewì ìbílẹ̀. Ó pe àkọlé iṣẹ́ náà ní ‘Performance in Yoruba Poetry Revisited’. Lérè Adéyẹmí (Dept of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ìlọ́rin, Nigeria) kọ nǹkan lórí àwọn obìnrin. Ó pe àkòrí iṣẹ́ rẹ̀ ní ‘Yoruba Family Life as a Theme in Wester narratives: A Feminist Approach’. Ṣọlá Owóníbi (Ládòkè Akíntọ́lá University of Technology, Ògbómọ̀ṣọ́, Nigeria) kọ nǹkan lérí àwọn obìnrin nínú iṣẹ́ tí ó pe àkòrí rẹ̀ ní ‘The Semantic of Women Oppression: A Linguistic Analysis’.

 

A lè wá pín àwọn iṣẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá yìí sí [[Tìlùtìfọn, orin (Music) – A. Adégbìtẹ́ àti O. Oláníyan, O. O. Bátẹ́yẹ ]]

[[Lítírésọ̀ alohùn (Orature) - Bọ̀dé Agbájé ]]

[[ Culture (Àṣà) – Javier Perez de Cueller, O. Oláníyan

[[Novels (Ìwé ìtàn-àròsọ) – O. Olúránkinṣẹ́, O. Adébọ̀wálé]]

[[ Prognosis (Ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀) – O. Olúránkinsẹ́]]

[[Ẹ̀sìn (Religion)- P.S.O. Àrẹ̀mú àti T.Y. Ogunsiakin]]

[[Iṣẹ́ ọnà (Arts) – P.S.O. Àrẹ̀mú àti T.Y. Ogunsiakin]]

[[Ọ̀rọ̀ nípa obìnrin (Fẹmenism) – B.O. Ọláyínká, Lérè Adéyẹmí, Sọlá Owóníbi]]

[[Òwe (Proverb) – B.O. Olayinka]]

[[Ẹ̀ka-èdè (Dialect) - Kínyọ̀ Bọ́lọ́rundúró]]

[[Òṣèlú (Politics) – O. Adébọ̀wálé]]

[[Ewì (Poetry) – O. Oyèsakìn]]

[[Ẹbí (Family) – Lére Adéyemí]]

[[Ìtumọ̀ (Semantics) - Ṣọlá Owóníbi]]

 

 

O.Olúránkínṣeẹ́ (1997), ‘Elements of Prognosis in Kọ́lá Akínlade’s Yorùbá Novels’, Research in Yorùbá Language and Literature 9 (Burbank (www.researchinyoruba.com)), ojú-ìwé= 20-31. ISSN: 1115-4322.

           

            Ọ̀rọ̀ nípa ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀ ni òǹkọ̀wé sọ nínú iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn ìfáárà, ó sọ̀rọ̀, nípa iṣẹ́ tí ó ti wà nílè lórí ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀. Ó sọ ohun tí ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ ó sì wá sọ àwọn ọ̀nà tí Kọ́lá Akínlàdé fi fi ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀ hàn nínú ìwé rè nípa (1) àkòrí ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀ (ii) orúkọ ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀, àmì ìmúnimọ̀tẹ́lẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 

P.S.O. Àrẹ̀mú and T. Y. Ogunsiakin (1997), ‘The Red, Black and White Inevitable Currencies in Yorùbá Traditional Religion’, Research in Yorùbá Language and Literature 9 (Burbank (www.researchinyoruba.com)), ojú-ìwé 32-40. ISSN: 1115-4322.

 

            Bí àwọn àwọ̀ mẹ́ta – Funfun, dúdú, àti Pupa - ṣe ń bá àwọn òrìṣà ṣe pọ̀ ni ó jẹ iṣẹ́ yìí. Àwọn òǹkọ̀wé sọ àwọ̀ tí ó jẹ́ ti òrìṣà kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àwọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí. Àwọn òǹkọ̀wé mẹ́nu ba ibi tí àwọ̀ ti ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Ifá àti ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnu Yorùbá ni àwọn òǹkọ̀wé lò láti fi  jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń sọ.

 

Orin

O. O. Bátẹ́yẹ (1977), ‘Mood Setting/Pictorial Imagery in the Nigerian Art Song’, Research in Yorùbá Language and Literature 9 (Burbank www.researchinyoruba.com )), ojú-ìwé=47-51. ISSN: 1115-4322.

            Lẹ́yìn ìfáárà, ó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ‘art song’ jẹ́ àti bí ó ṣe dé ilẹ̀ wa. Lẹ́yìn èyí ni ó wá ṣe àtúpalẹ̀ ‘Night in the Deseart’(Fọlá Ṣówándé) àti ‘Àtètè sùn làtètèjí’, ‘Òjò máa rọ̀’, ‘Kìnìún’àti ‘Já ìtàná’ (Ayọ̀ Bánkọ́lé). Ó tún wo ‘Ọmọ jọ̀wọ̀’(Akin Euba) àti ‘Ain-gala’(Adamfiberesema).

 

Òwe

B. O. Ọláyínká (1997), ‘Proverbs: Issues of Yorùbá femininity from a feminist Hermeneutical Prespective’, Research in Yorùbá Language and Literature 9 (Burbank (www.researchinyoruba.com)), ojú-ìwé = 52-58 ISSN : 1115-4322.

            Àwọn òwe tí ó tàbùkù obìnrin ni iṣẹ́ yìí yẹ̀ wò. Lẹ́yìn ìfáárà, ó wo àwọn òwe tí ó jẹ mọ́ ìgbéyàwó, ìbálópò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe ni òǹkọ̀wé náà mú lò nínú iṣẹ́ náà.

 

 

J.D.Y. Peel (2003),  Religious Encounter and the Making of the Yoruba. Bloomington: Indiana University Press. ISBN: 0-253-21588-9(pk). Ojú-ìwé = 420.

 

            Lára àwọn ohun tí òǹkọ̀wé mẹ́nu bà nínú ìwé yìí ni ẹ̀sìn, ogun, àwọn ìjọ Ọlọ́run onígbàgbọ́ ati bí wọ́n ṣe ń tan ìlìnrere ká. Òǹkọ̀wé náà kò sàìmẹ́nu ba ẹ̀sìn Mùsùlùmí àti bí wọn ṣe ń yí ènìyàn padà sí ẹ̀sìn wọn.

 

W.I. Ward (1949), W.I. Ward (1949), An Introduction to the Yoruba Language. Cambridge: W. Heffer and Sons. Ojú-ìwé= 255.

           

            Ìpìlẹ̀ tuntun ni ìwé yìí fi lélẹ̀ lórí gírámà èdè Yorùbá. Púpọ̀ nínú àwọn ìwé tí ó ṣáájú rẹ̀ lórí èdè Yorùbá ló jẹ́ wí pé èdè elédè ni wọ́n ń wò tí wọ́n fi ń ṣe òdiwọ̀n fún Yorùbá. Ìwé yìí kò ṣe èyí. Gbogbo ohun tí ó yẹ kí onímọ̀ gírámà mú ẹnu bà lórí èdè Yorùbá ni ó mẹ́nu bà. Àkọtọ́ rẹ̀ péye gan-an ni. Ó mú àmì orí ọ̀rọ̀ lò dáadáa.

 

Babátúndé Ọlátúnjí (1980), Yorùbá Òde Òní: Ìwé kìíní. Ìkẹjà, Nigeria: Thomas Nelson (Nigeria) Limited. ISBN: 978 126 023 8. Ojú-ìwé -121

 

            Ìwé yìí ni èkíní nínú àwọn ìwé tí òǹkọ̀wé yìí ṣe fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kóńdírì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé kíkà àti ìbéèrè ni ó wà nínú rẹ̀. Ó sọ́rọ̀ nípa gírámà Yorùbá àti àròkọ. Yorùbá òde òní ni ó fi kọ ìwé náà.

 

J. Ọmọ́ṣadé Awólàlú (1979), Yorùbá Beliefs and Sacrificial Bits. London: Longman Groups Limited. ISBN: 0 582 642035 (cased) àti 0 582 64244 2 (paper) Ojú-ìwé = 201

            Ìwé yìí dá lé orí ìgbàgbọ́ àti ẹbọ ṣíṣe ní àárín àwọn Yorùbá. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Olódùmarè, àwọn ìbọ àti àwọn baba wa. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi ẹbọ àti ìdí tí a fi ń ṣe wọn. Kò ṣàìmẹnu ba àwọn nǹkan tí ó ń ṣe adínà fún ẹbọ náà.

 

Olúfúnmiláyọ̀ M. Ògúnkẹ́yẹ (2001), ‘A Lexicalist Approach to the study of Aspects of Yorùbá Morphology.’, Àpilẹ̀kọ fún Óyè Ph.D; University of Ibadan, Ibadan. Ojú-ìwé- 262

           

            Orí mofọ́lọ́jì Yorùbá ni àpilẹ̀kọ yìí dá lé lórí. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti yẹ oríṣiríṣi lítíréṣọ̀ tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ rẹ̀ wò tán ni ó tó wo ìhun ọ̀rọ̀. Ó wo àpètúnpè àti ìfi-àfòmọ́ ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbá tuntun ni ó dá nínú iṣẹ́ náà.

 

I. A. Akínjọ̀gbìn (1979), Seminar Papers. Ife, Nigeria: Department of History. Ojú-ìwé: 559.

           

            Púpọ̀  níuú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó wà nínú ìwé yìí ni ó dá lé orí Yorùbá. A rí ẹni tí ó sọ̀rọ̀ lórí ifá. Ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ lórí obìnrin  bẹ́ẹ̀ ni a sì rí ẹni tí ó sọ̀rọ̀ lórí òwò. Àwọn ọ̀mọ̀wé tí ó sì sọ̀rọ̀ níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ni àwọn bíi I.A. Akínjọ̀gbìn, I. Ọlọ́mọ́là, Tóyìn Fálọlá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 

Mákánjúọlá Ilésanmí (1998), Aroko Létí Ọpọ́n Ifá.  Ilé-Ifẹ̀, Nigeria: Amat Printing and Publishing. ISBN: 978- 34849-3-1. Ojú-ìwé = 52

           

            Ìwé ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni ìwé yìí lórí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin Ifá, Èṣù àti Odù. Ìlànà Ẹ́píìkì ni òǹkọ̀wé fi gbé ìtàn olú-ẹ̀dá-ìtàn kalẹ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni ìwé náà kọ́ wa ní pàtàkì, òǹkọ̀wé fá kí á kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìsubú olú-ẹ̀dá-ìtàn kí àwa náà lè yẹra fún irú ìsubú bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Ọládojúdé ní ìwé náà.

 

Ọládẹ̀jọ Òkédijì (1981), Atótó Arére. Ìbàdàn, Nigeria: University Press Ltd. ISBN: 978 154550x    0 19 575672x.   Ojú-ìwé = 263.

 

            Ìwé ìtàn-àròsọ ni ìwé yìí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìtàn-àròṣọ Yorùbá tí ó tóbi jù. Ìtàn Àlàbá labalábá ni ìwé náà dá lé tí abẹ̀bẹ̀ rẹ̀ ń fi gbogbo ìgbà fi ibi pẹlẹbẹ lẹ́lẹ̀.

            Òwe, ìjìnlẹ̀, ọ̀rọ̀, àfiwé àti ògidì èdè Yorùbá ni ó kún inú ìwé náà dẹ́nu.

 

Táíwò Olúnládé (2002), Ewì Ìgbàlódé  Ìbàdàn, Nigeria: Clemev Media Consult. ISBN: 978 33102-6-7. Ojú-ìwé = 118.

 

            Àkójọpọ̀ ewì ni ìwé yìí. Ewì tí ó wà nínú rẹ̀ jẹ́ ogójì. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ni àwọn ewì náà. Òǹkọ̀wé sọ pé ó gba òun tó ọdún méjìlá tí òun fi ṣe àkójọpọ̀ àwọn ewì náà. Àkọtọ́ ayé òde òní ni wọ́n fi kọ gbogbo àwọn ewì náà. Ìbéèrè wà nínú ìwé náà fún ìdánrawò. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ta kókó ni òǹkọ̀wé sì ṣe àlàyé.

 

 

            O. Adébọ̀wálé (1997), ‘Political Communication in Yorùbá Novels’, Research in Yorùbá Languag and Literature 9 (Burbank (www.researchinyoruba.com)), ojú-ìwé = 59-66. ISSN: 1115-4322

           

            Ọ̀rọ̀ nípa ìṣèlú nínú ìtàn-àròsọ Yorùbá ni ó jẹ òǹkọ̀wé yìí lógún. Àwọn ìwé tí òǹkọ̀wé  yìí wò ni Ṣàngbá fọ́ (Kọ́lá Akínlàdé), Baba Rere (Afọlabí Olábímtán), Ọ̀tẹ̀ Nìbò (O. Owólabí) àti Gbọ́baníyì (O. Yemitan). Ara àwọn ohun tí ó lò láti ṣe àtúpalẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́rọ̀ àti ọ̀rọ̀ àgbàsọ.

 

 

 

Austrolian

Austrolian ni a orúkọ fún ẹgbẹ́ àwọn èdè kan tí àwọn aborigine ń sọ. Àwọn èdè yìí fi bí obọ̀n lé ní igba (230) síbè àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n lọ.

            Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹbí bí ọgbọ̀n ó dún méjì nítorí wí pé wọ́n ní wọ́n bá ara wọn tan. Gbogbo àwọn èdè wọ̀nyí, yàtọ̀ sí ọ̀kan nínú wọn ni ó wà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Australia àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá (Northern Territory) àti Queensland. Gbogbo ilẹ̀ tí  a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò ju ìdá mẹ́jọ ilẹ̀ Austrolia lọ. Ṣùgbọ́n èdè tí a ń pe ẹbí rẹ̀ ní Pama-Nyunga ni ó gba gbogbo ilẹ̀ yòókú ní Austrolia. Àwọn èdè tí ó wà nínú ebí yìí tó àádọ́ta tí àwọn ènìyàn sì ń lò wọ́n dáadáa.

            Àwọn èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ jù ni twi, Wapiri, Aranda, Mabuyng àti Western Desert. Àwọn tí ó ń sọ òkọ̀ọ̀kan wọn lé tàbí kí ó dún díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún. Láti nǹkan búséńtúrì kejìdúnlógún àwọn èdè tí ó ní àwọn tí ó ń sọ wọ́n ti ń dínkù jọjọ. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó sẹ́kì yìí ti ń parẹ́.

            Kò sí ẹni tí ó lè sọ bí ọjọ́ iwájú àwọn èdè aborigine yìí yóò ṣe rí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́ gidigidi lórí wọn báyìí láti nǹkan bí ọdún 1960 tí àwọn kan ti dìde láti jà fún fífún gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin. Púpọ̀ nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni ó ti ń ní àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi àkọtọ́ Rómáànù (Roman alphabet) kọ. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sì ti ń lo èdè méjì., èdè mìíràn àti èdè mìíràn.

 

Australia

            Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Australia  lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún (19,089,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ibẹ̀. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ìdá márùn dínlógórùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún. Àwọn tí èdè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ èdè àkọ́kọ́ fún tó ìdá méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ètò ìkànìyàn 1991.

            Àwọn èdè, tí àwọn tí ó ń se àtìpó ń sọ tó ọgọ́rùn-ún. Lára wọn ni Italian, Chenese, Arabic, Greek, Vietramese. Wọ́n sì tún ń pọ̀ sí i ní pàtàkì àwọn ènìyàn tí ó ń wọ ilẹ̀ náà láti ìlà-oòrùn Asai.

            Àwọn tí ó ń sọ èdè Aborigine kò tó ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún

 

Austria

            Nínú ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yìí lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ (8, 097,000), Jámànì ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ń lo ẹ̀ka-èdè Bavarian German. Slovene ni èdè ìṣè jọba ìpínlẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn gúsù, ní gúsù carinthia. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n.

            Àwọn èdè mìíràn tí àwọn péréte péréte ń sọ ni czeck, Hungarian, Romani, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà Serbo-Crotian àti Sorbian. Wọ́n ti ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa báyìí fún òwò àgbáyé àti láti máa bá àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wo sí ìlú náà (tourism) Sọ̀rọ̀. Wọ́n ń lo Gẹ̀ẹ́sì mọ́ Jámánì fún àwọn nǹkan méjì wọ̀nyí.

 

Austro-Asiatic

            Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹbí èdè yìí tó àádọ́sàn-án. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin. Gúsù ìlà-oòrùn Asia ní pàtàkì ní China àti Indonesia ni wọ́n ti ń sọ wọ́n jù. Àwọn kan sì tún ń sọ wọ́n ní apá ìwọ̀-oòrùn àríwá India àti ní Erékùsù Nicobar (Nicobar Island). Àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ẹbí èdè yìí tí ó ṣe pàtàkì ni Mon-Khmer (tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni àwọn èdè pọ̀ sí jù), Munda àti nicobarese. Àwọn méjèèjì tó gbẹ̀yìn yìí ni wọ́n ń sọ ní ìwọ̀-oòrùn àdúgbò Mon-khmer.

            Láti fi ìmọ̀ ẹ̀dá èdè pín àwọn èdè yìí sòro díẹ̀ nítorí pé díẹ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó ní àkọsílẹ̀ àti pé ìbáṣepọ̀ tí ó wà ní àárín àwọn ẹbí èdè yìí àti àwọn ẹbí èdè mìíràn kò yé èèyàn tó.

 

Austronesian

            Ẹbí àwọn èdè kan nìyí tí èdè tí ó wà nínú rẹ̀ tó ọgọ́fà. Àwọn tí ó ń sọ àwọn èdè yìí tó àádọ́rin lé ní igba mílíọ̀nù (270 million). Wọ́n ń sọ wọ́n láti MadagascarEastern Island: Wọ́n tún ń sọ wọ́n láti Taiwan dé hawal títí dé New Zealand. Wọ́n tún máa ń pe Austronesian yìí ní Malayo-Polynesian. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹbí èdè tí ó tóbi jù.

            Ohun tí kò jẹ́ kí àwọn onímọ̀ mọ̀ dájú sáká iye èdè tí ó wà nínú ẹbí yìí ni pé ọ̀pò ìgbà ni wọn kì í lè dá èdè mọ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀ka-èdè. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn èdè yìí ti ń wọ inú ara. Ìyẹn ni pé ẹnì kan lè máa so èdè A àti B papọ̀ nítorí òwò tí ó ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn pàdé ara wọn.

            Ìpín mẹ́ta pàtàkì ni a máa ń sábì pín ẹbí yìí sí. Àwọn ìpín mẹ́ta náàs ni Western Austronesian, Eastern Austronesian àti Central Austronesian.

            Àwọn ẹgbẹ́ èdè tí ó wà nínú Western Austronesian tó ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta. Wọ́n ń bọ wọ́n ní Madagascar, Malaysia, àwọn Erékùsù Indonesia, Phillipines, Taiwan àti apá kan Vietnam àti Cambodia àti igun ìwọ̀-oòrùn New Guinea. Ara wọn máà ni àwọn èdè méjì Micronesia (tí wọ́n ń fẹ́ chamorro àti Palauan).

            Àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ Eastern Austronesian náà tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èdè. Wọ́n tún máa ń pe ẹgbẹ́ Eastern Austronesian ní oceanic. Wọ́n ń sọ wọ́n ní New Guinea, gbogbo àwọn erékùsù bí ẹgbẹ̀rún méwàá ní Melanesia, Micronesia àti Polynesia ṣùgbọ́n àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju mílíọ̀nù méjì àbọ̀ lọ (2.5million).

            Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹgbẹ́ Central Austronesian jẹ́ àádọ́jọ (150). Àwọn tí ó ń sọ wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rin àbọ̀ ní ààrin gbùngbùn àwọn erékùsù Indonesia.

 

Avar

            Ọmọ ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ń pè ní Dagestanian ni eléyìí. Dangestanian yìí tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ fún àwọn èdè tí wọ́n ń pè ní Caucasian. Àwọn tí ó ń sọ Caucasian yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀tà ní Caucasus ní pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Dagestan ní Rọ́síà àti Azerbaijan. Àkọtọ́ Cyrillic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà ní àdúgbò yìí ni wọ́n ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣèjọba. Àwọn Andi àti Dido náà wà lára àwọn ẹ̀yà tí ó ń lò wọ́n.

 

Aymara

            Ọmọ ẹgbẹ́ Quechumaran ni Aymara. Quechumaran fúnrarẹ̀ náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ fún àwọn èdè Andea-Equatorial. Àwọn tí ó ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù méjì (2.2.million). Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ wọ́n wà ní Bolivia (1.8 million) ó dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù méjì. Wọ́n tún ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ní Peru àti apá ken Angentina. Àkọ́tọ́ Rómáànù ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀. Ní ìgbà kan rí, Aymara jẹ́ èdè kan tí ó ṣe pàtàkì ní ààrin gbùngbùn Andes tí wọ́n jẹ́ apá kan Ẹ́nípáyà Inca (Inca Empire)

 

 

 

Azerbaijan

            Ní ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń sọ èdè yìí jẹ́ mílíọ̀nù méjè àbọ̀. Òun ni ó jẹ́ èdè ìjọba fún Azerbaijani níbi tí àwọn ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ ti ń sọ ọ́. Àwọn ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Rọ́sía ni ó ń sọ èdè yìí. Àwọn èdè bú méjìlà mìíràn tún wà èyí tí Avar àti Armerican wà lára wọn.

 

Azerbaijani

            Ọmọ ẹgbẹ́ ni èdè yìí jẹ́ fún ẹgbẹ́ èdè tí a ń pè ní Turkic. Ẹgbẹ́ èdè Turkic yìí jẹ́ ọmọ ẹbí Altaic. Àwọn tí ó ń sọ Azerbaijani tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ní Azerbaijan ní ibi tí wọ́n ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣe ìjọbi. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní Turkey, Syria àti Afgloanistan. Wọ́n tún máa ń pe èdè yìí ni Azeri. Àkọtọ́  Cyrillic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Azerbaijan ṣùgbọ́n àkọtọ́ Arabic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Iran.  Wọ́n fi ojú èdá èdè pín wọn sí Swuthern Azerbaijani) àti Northern Azerbaijani tí mílíọ̀nù méje ènìyàn ń sọ.

 

Azores

            Ètò ìkànìyàn 1995 sọ pé ẹgbẹ̀rún lónà ogójì lé ní igba ènìyàn ló ń gbé Azores. Èdè Potokí (Portuguese) ni èdè ìṣe ìjọba ibẹ̀. Wọ́n ti ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì báyìí sí i sá fún èdè ìgbafẹ́ (tourism).

 

 

Aztec-Tanoan

            Ẹgbẹ́ èdè kan tí ó ní ọgbọ̀n èdè nínú ni a ń pè ní Azter-Tanoan. Wọ́n ń sọ ọ ní ìwọ̀-òorùn àti gúsù ìwọ̀-oòrùn Àmẹ́ríkà (USA). Wọ́n tún ń sọ ní ìwò-oòrùn mexico. Àwọn tí ó ń sọ àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹgbẹ́ yìí ni Comanche, Paiute Shoshone àti Hopi. Èdè ilẹ̀ Mixico mẹ́ta ni wọ́n ń sọ jù. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni Nahuat (tí wọ́n tún ń pè ní Aztec; ó ní ẹ̀yà púpọ̀. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àbọ̀ 1.4. million). Èkejì ni Tarahumar (bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì). Papágo-Pima tí ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ń sọ ni ẹ̀kẹ́ta. Gbogbo àwọn èdè yìí ni ó ń lo àkọsílẹ̀ Rómáànù (Roman alphabet)

 

 

Anguilla

            Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tó wa ní Anguilla jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún (7,100). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni wọ́n ń sọ èdè Kirió tí wọ́n gbé ka èdè Gẹ̀ẹ́sì (English based Creole). Kirió yìí ni ó wọ́pọ̀ jù ní Áńtílẹ́ẹ̀sì (Lesser Antilles)

 

Amharic

            Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni eléyìí tí nǹkan bú mílíọ̀nu márùndínlógún ń sọ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ ní Ethopia (ìtópíà). Níbẹ̀, wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí tí ìjọba ń mú lò. Àwọn bú  mílíọ̀nù márùn-ún ni ó ń sọ èdè yìí ní agbègbè Ethiopia nígbà tí ̣ àwọn ọ̀pọ̀lọpò mílíọ̀nù mìíràn ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì àkọ́kúntẹnu ní Ethiopia àti Sudan (Sùdáànù). Láti nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹrìnlá (14th Century) ni èdè yìí ti ní àkọsílẹ̀. Àkọtọ́ Amharic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àkọtọ́ yìí ní Kóńsónáǹtì mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ẹ̀dà méjeméje. Ẹ̀dà kóńsónáǹtì tí ènìyàn yóò mú lò dúró lóró fáwẹ̀lì tí kóńsónáǹtì náà yóò bá jẹ yọ. Àbá ti ń wáyé nípa pé kí àtúnṣe wà fún àkọtọ́ yìí. Àwọn kan sì ti kóra wọn jọ fún ìpolongo láti sọ èdè yìí di àjùmọ̀lò (Standardisc).

 

Amorite

            Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni Amóráìtì (Amorite) tí wọ́n ń sọ ní agbègbè àríwá Síríà (Syria) òde òní ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sí ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ṣáájú ìbí Kírísítì. Díẹ̀ ni a mọ̀ nípa èdè yìí nítorí pé láti inú orúkọ ènìyàn àti àwọn àkọ́sílẹ̀ díẹ̀ tí a rí tí wọ́n opẹ́ sí ara òkúta nìkan ni a mọ̀ nípa èdè yìí.

           

Andean-Equatorial

            Àgbáyọ èdè bí igba ó lé àádọ́ta nì yí lára èdè Àmẹ́rídíànù (Ameridian) tí wọ́n ń sọ ní apá Gúúsù Àmẹ́ríkà. A pín àwọn èdè yìí sí àgbájọ èdè Andean (Áńdíanù) àti Equatorial (Ikuitóríàlì) ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì yìí sì ní ẹbí tí ó pọ̀. Àwọn tí ó ṣe pàtàkì lára wọn ni ẹbí Áráwákáànù (Arawakan family) tí ó tàn dé Àríwà Àmẹ́ríkà nígbà kan rí tí wọ́n sì tún ti ń sọ ní ibi tí ó pọ̀ báyìí. Wọ́n ń sọ ọ́ ní ààrin gbùngbùn Àmẹ́ríkà títí dé Gúúsù Bùràsíìlì (Brazil).

            Ọ̀kan nínú àwọn èdè yìí tí ó ṣe pàtàkì ni Góájíírò (Goajiro) tí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ́fà ènìyàn ń sọ. Àgbájọ Quechumaran (Kueṣumáráànù) ni ó wọ́pọ̀ tí wọ́n ń sọ ní orí-òkè Áńdéesì (Andes highlands) ní àárín Kòlóńbíà (Columbia) àti Ajẹntínà (Argentina). Kúénṣua (Quenchia) àti Aymará (Ayamáárà) hi wọ́n ṣe pàtàkì jù ní àwọn ibí wọ̀nyí.

Ní Gíísù, ní inú Pàrágúè (Paraguay) àti agbègbè rẹ̀ Guarani ni ó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ọmọ ẹbí Tùpíànù (Tupìan). Gbogbo àwọn èdè wọ̀nyí ló jẹ́ pé àkọtọ́ Rómanù (Roman alphabet) ni wọ́n fi ń kọ wọ́n sílẹ̀.

 

Andora

            Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń gbé Andora jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dún-láàádọrin (68,000). Àwọn èdè tí ó jẹ́ ti ìjọba níbẹ̀ ni Kàtáláànù (Catalan) tí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ń sọ (60%) àti èdè faransé. Wọ́n tún ń sọ Kàsìtílíànù ti àwọn Pànyán-àn-àn (Castilian Spanish) gan-an fún òwò àgbáyé àti láti fi bá àwọn tí ó bá wá yẹ ìlú wọn wo sọ̀rọ̀ (tourism).

 

 

Angola

            Nínú ètò ìkànìyàn, 1995, àwọn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlá àti ààbọ̀ ó lé díẹ̀ (11, 539, 000). Potokí ni èdè ìṣèjọba ní orìlẹ̀-èdè yìí. Àwọn èdè bí ogójì mìíràn tún wà tí wọ́n tún ń sọ ní ibẹ̀. Àwọn eléyìí tí ó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn bí ogójì yìí ni Umbundu (Bíi mílíọ̀nù mẹ́rin ló ń sọ ọ́) – tí wọ́n tún máa ń lò bí èdè ìṣèjọba, Mbundu (nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ni ó ń sọ ọ́) àti Kóńgò (Mílíọ̀nù kan ó lé díẹ̀ (1.1 million) ló ń sọ ọ́). Wọ́n ti ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa báyìí ní orílẹ̀-èdè yìí fún òwò àgbáyé àti àwọn tí ó bá wá bẹ ìlu wọn wò (International trade and tourism).

 

Anomia

            Orúkọ àìsàn kan tí ó ń bá ọ̀rọ̀ sísọ jà ni ó ń jẹ́ anomia. Ẹni tí ó bá ní anomia yóò máa gbàgbé ọ̀rọ̀ ní pàtàkì, kò ní í máa tètè rántí orúkọ ènìyàn, ibi àti nǹkan. Àwọn tí ó bá ní àìsàn Afasíà (Aphasca) ni ó sábà máa ń ní àìsàn yìí. Ó jẹ́ àìsàn àléébù èdè.

 

Antigua and Barbuda

            Àwọn ènìyàn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí nínú ìkànìyàn 1995 jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ta lé ní ọgọ́ta (63, 000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè ìṣèjọba ibẹ̀. púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni ó máa ń sọ Kiriyó tí wọ́n gbé ka èdè Gẹ̀ẹ́sì (English based Creole). Èdè Kiriyó yìí tàn kálẹ̀ ni Áṣílẹ́ẹ̀sì (Lesser Achilles).

 

Arabic (Èdì Lárúbááwá)

            Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí.

            Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí.

            Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé.

            Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).

 

Aramaic

            Ara èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) ni Árámáìkì (Aramaic). Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti sẹ́ńtúrì kẹfà ni wọ́n ti ń fi Árámáìkì àtijọ́ (Classical Aramaic) kọ nǹkan sílẹ̀ ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èdè tí àwọn júù ń sọ.

            Ẹ̀ka-èdè ìwọ̀-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kirisitì àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń sọ. Ẹ̀ka-èdè kán tí ó wá láti ara ẹ̀ka-èdè yìí ni wọ́n sì ń sọ ní àwọn abúlé kan ní ilẹ̀ Síríà àti Lẹ́bálọ́ọ̀nù.

            Ní nǹkan  bíi sẹ́ńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Ẹ̀ka-èdè apá ìwọ-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwọn ìjọ Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò.

            Álúfábẹ́ẹ̀tì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí ṣì ṣe pàtàkì nítorí pé láti ara rẹ̀ ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwọn èdè mìíràn ti dìde.

 

Argentina

            Nínú ètò ìkànìyàn 1995, iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà (Argentiana) lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì àti àti ààbọ̀ (34, 513, 000). Èdè Pànyán-àn ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní orílè-èdè yìí lé ní ogún. Lára àwọn ogún èdè yìí ni àwọn èdẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Àmẹ́rídíánà (Ameridian Languages) wà. Ara àwọn èdè.

            Àmérídíánà yìí ni ‘Guarani, Araucanian, Metaco àti Quechua’.

            Àwọn èdè tí ó tún wà lára ogún yìí ni èdè tí àwọn tí ó wá se àtìpó ń sọ. Lára wọn ni èdè Ítílì (Ìtahàn) àti Jámánì (herman). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè fún òwò àgbáyé àti èdè àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò wá sí ibẹ̀ (International trade and tourism). Wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí pẹ̀lú èdè Pànyán-àn.

 

Armenia

            Nínú ètò ìkànìyàn tí wọ́n ṣe ní ọdún 1995, ó lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́ta àbọ̀ ènìyàn ni ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí (3, 671, 000). Èdè Àmẹ́níà (Armenian) ni èdè tí ìjọba ń lò. Ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún (90%) àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yìí ní ó ń sọ ọ́. Èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní ibẹ̀ ni èdè Rọ́síà (Russian). A tún rí àwọn tí ó ń sọ Kúdíìṣì (Kardish) àti Azerbayani.

 

 

Armenian

            Ara èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà.

            Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jéésù Kirisitì. Èdè Grabar yìí ni wọn ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní,

            Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí.

            Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.

 

Assamese

            Ara ẹgbẹ́ ti ìlà-oòrùn àwọn èdè Indo-Aryan (Indo-Aryan languages ni Assamese. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ to mílíọ̀nù mẹ́rìnlá àbọ̀ (14.5 million). Orílẹ̀-èdè Asam ni wọ́n ti ń sọ èdè yìí jù. Ìlà-oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè India ni Asam wà. Àwọn tí ó ń sọ èdè Assamese yìí tún wà ní Bhutan àti Bangladesh. Àkọtọ́ Bengah ni wọ́n fi ń kọ Assamese sílẹ̀. Ìbátan sì ni òun àti èdè Bengah:

 

 

Baluto-Síláfíìkì

Balto-slavic

            Ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ní Baltic ati Slavic ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wá ń pe àwọn méjèèjì papọ̀ ní Balto-Slavic. Ọmọ ẹgbẹ́ ni àwọn èdè wọ̀nyí jẹ́ fún àwọn ẹ̀yà èdè (branch) tí a ń pè ní Indo-European (In-indo-Yùrópíànù). Àwọn tí ó ń sọ Baluto-Sìláfíìkì yìí tí mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn (300 million people). Eléyìí tí ó ju ìlàjì lọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń sọ èdè Rọ́síà (Russian)

            Èdè àìyedè díẹ̀ wà lórí pé bíyá ibi kan náà ni gbogbo àwọn èdè yìí ti ṣẹ̀ tàbí pé nítorí pé wọ́n jọ wà pọ̀ tí wọ́n sì jọ ń ṣe pọ̀ ló jẹ́ kí ìjọra wà láàrin wọn.

 

Bàlúṣì tàbí Bàlóṣì

Baluchi or Balochi

            Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó múlíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye.

 

 

 

 

Bátíníìsì

Balinese

            Ọmọ ẹgbẹ́ ẹbí èdè Austronesian ni èdè yìí. Àwọn tí ó n sọ ọ́ fẹ́rẹ́ẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin (3.8 million) ní erékùsù Báálì (Bali) ní In-indoníísíà (Indonesia). Àkọtọ́ Bálíníìsì àti ti Rómáànù (Balinese and Roman alphabet)ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀.

 

 

Bàhámáàsì

Bahamas

            Ní ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ó wà ní Báhámáàsì tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin lé ní igba (274,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè ìṣèjọba ní ilẹ̀ yìí. Àwọn bíi ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún (85%) àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ yìí ní ó ń lo èdè Kiriyó (Creole) tí wọ́n gbé ka èdè Gẹ̀ẹ́sì (English-based Creole).

 

Báháráìnì

Bahrain

            Ní ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta àti ààbọ̀ (555,000). Èdè Lárúbááwá (Arabic) ni èdè ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè kan tún wà tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Àwọn èdè náà ni fáàsì (farsi) tí àwọn tí ó ń sọ ó ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́ta (48, 000); Úúdù (Urdu) tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) àti àwọn èdè fílípíìnì (Phillipine) mìíràn tí àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbayì ní ilẹ̀ yìí sí i gẹ́gẹ́ bí èdè òwò àti èdè ìṣe àbẹ̀wò sí ìlú (tourism).

 

Bálútíìkì

Baltic

            Ẹ̀yà àwọn ẹbí èdè Bálító-Síláfíìkì (Balto-Slavic) ni èdè Bàlútíìkì (Baltic). Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí tó mílíọ̀nù márùn-ún ní etí omi Bálútíìkì (Baltic Coast). Àwọn bí mílíọ̀nù kan tí ó ṣe àtìpó lọ sí ìlú ọ̀kèèrè, ní pàtàkì ilẹ̀ Àmẹ́ríkà (USA), tún ń sọ èdè náà. Àwọn èdè Bálútíìkì tí àwọn ènìyàn ń sọ jù ni Látífíànù (Lativian) àti Lítúaníànù (Lithuanian). Ní ara àwọn èdè Bálútíìkì yìí ni èdè Púrúsíànù àtijọ́ (Old Prussian) tí ó jẹ́ pé àkọsílẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ó wà ní àrowótó ní òde òná. Gbogbo àwọn èdè yòókù tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Bálútíìkì ni wọ́n ti paré.

 

 

 

No comments:

Post a Comment