Saturday, 28 November 2015

Ẹ JÍ GÌRÌ

Mo ní ẹ̀yin ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ yí
Ẹ dide, ẹ jí gìrì
Ẹ ta ṣàṣà gbédèe wa ga
Ọ̀pọ̀ọ kùsà la à tíì wà
Tí kò jẹ́ ká mọ àṣàa Yoòbá dunra     5
Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ọ wa ni kò sí
Nínú-un gbédègbẹyọ̀ kankan nílẹ̀ yìí
Bí a bá sọ ọ sí wa
Yóò pa wá lákọsẹ̀
Nítorí Ìbàdàn nìkan la mọ̀                           10
A ò mọ láyípo
Ìṣín nìkan la mọ̀ ọ́n jẹ
A kò mọkú ojú rẹ̀ẹ́ yọ
Ègùn nìkan la gbọ́
A kò gbọ́ wọ́yọ̀wọ́yọ̀               15
Mo kí ọ kí ọ nìkan la mọ̀
A ò mèrò ò wájà
Nítorí a kò kọra sédèe wa
Òfeerefé la mọ̀, a ò mọ̀jìnlẹ̀ ọ̀rọ̀
Ẹni lédèe wa ò jọjú                  20
Asẹ́ ló fi ń gbèjò un
Ara rẹ̀ ló ń tàn-án jẹ
Ọwọ́ ara ẹni lèmí mọ̀
Tá a fi ń túnwà ara ẹni ṣe
Bá a bá dúró dỌlọ́run fẹ́ẹ̀ẹ́ ṣe é       25
Yóò pẹ́ wa tọ́pẹ
Ẹní dákẹ́ tiẹ̀ á ba dákẹ́
Torí náà
Ẹ jẹ́ á dìde lónìí
Ká gbédèe wa ga                   30
Àgbájọ ọwọ, n là á fií sọ̀yà
Ẹní pe ti ẹ̀ lákísà ẹlẹ́gbin
Laráyé ń bá a pè é bẹ́ẹ̀
Aṣọ àlà ni tiwa
Ẹ má jẹ́ wọn ó tapo sí i            35
Torí náà, ẹ dìde
Ẹ dìde ká jọ fọwọ́ tì í
Ká gbédèe wa débi ògo
Ẹ má jé kó dàbí ejò tó wọnú àgé
Agbá dọwọ́ọ wa.                      40


No comments:

Post a Comment