Saturday, 15 August 2015

Dance

(N/OR): (i) ijó. yíyí ẹsẹ̀ àti ara wa padà sí orin. We had a dance. A jó (ijó).
(ii) oríṣi ìyí-ẹsẹ tàbí ara padà kan tí a máa n ṣe sí àwọn orin kan. Ó sì lè jẹ́ orin tí a máa n ṣe irú ìyí-ẹsẹ̀ padà tàbí ìyí-ara padà bẹ́ẹ̀ sí. The Juju musician played a slow dance. Olórin Jùjú náà kọ orin àfẹ̀ṣọ̀ jó.
(iii) ibi ìgbafẹ́ níbi tí àwọn ènìyàn ti maa n jó, ní pàtàkì, ní ibi àṣeyẹ òpin sáà. They are having an end-of-term dance. Wón n ṣe àṣeyẹ òpin sáà.
(iv) ọ̀nà ìgbà jó ijó, ní pàtàkì, láti fi dá àwọn ènìyàn lára yá. He told the story through song and dance. Orin àti ijó ni ó fi sọ ìtàn náà.
(V/IṢ): jó. Yí ẹsẹ̀ àti ara ní ipò padà sí orin tí a n gbọ́. Can you dance ‘palongo’? Ṣé o lè jó (ijó) pàlóngò?
(ii) ajẹmọ́ lítírésọ̀. rọra mi ara ní kíá. She watched the sunlight dancing on the water. Ó n wo bí ìtànsàn oòrùn ṣe n jó ní ojú omi.
dance attendance on somebody. ṣe gbogbo ohun tí ẹni kan ní kí á ṣe kí á sì máa ṣe ẹni náà bí ènìyàn pàtàkì. He wants to have someone dancing attendance on him. Ó n fẹ́ kí ẹnì kan wà tí yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún un
be dancing on the street (informal/gbẹ̀fẹ́): kí inú ènìyàn máa dùn fún nnkan kan tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i. They were dancing on the street about the second pay rise. Inú wọn n dùn fún ẹ̀kúnwó kejì tí wọ́n fún wọn.
dance to somebody’s tune. ṣe ohun tí ẹni kan n fẹ́ kí á ṣe. He had to dance to her tune at the meeting in order to get the money after the meeting. Gbogbo ohun tí ó ní kí ó ṣe níbi ìpàdé náà ni ó ṣe kí ó lè rí owó náà gbà lẹ́yìn ìpàdé.
dance floor (N/OR): ibi kan, ní pàtàkì, bí ilé ọtí, tí ó wà fún ijó. Have you see him on the dance floor? Ṣé o ti rí  tí o´n jó?
dance hall (N/OR): ilé pàtàkì kan tàbí yàrá títóbi  kan níbi tí a ti a ti máa n jó, ní pàtàkì, ní ayé àtijọ́. We paid to dance at the dance hall. A sanwó láti lọ jó ní inú gbọ̀gàn ijó.
dance music (N/OR): orin kan tí ó lágbára tí àwọn ènìyàn máa n jó sí ní ilé ìgbafẹ́. It was an era of dance music. Àsìkò ijó tí ó lágbára ni.
dancer (N/OR): oníjó. Ẹni tí ó n jó fún ìgbádùn tàbí tí ó fi ijó jíjó ṣe iṣẹ́ ṣe. He is a dancer in our hotel. Oníjó ni ní òòtẹ́ẹ̀lì wa.

No comments:

Post a Comment